A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí."


الصفحة التالية
Icon