Ẹ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín.
____________________
Lẹ́yìn tí ìtayọ ẹnu-àlà ti wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb sí àwa mùsùlùmí, tí wọ́n ti fọwọ́ ara wọn fa ogun, tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ti pa á láṣẹ fún àwa mùsùlùmí láti jàjà gbára fún ẹ̀sìn wa, ẹ̀mí wa àti dúkìá wa, ogun ẹ̀sìn kò níí kásẹ̀ nílẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé àfi pẹ̀lú ọ̀kan nínú n̄ǹkan méjì; yálà kí àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn gba ’Islām nítorí pé, òhun nìkan ni ẹ̀sìn òdodo tàbí kí wọ́n máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām láì níí fi ẹ̀sìn irọ́ wọn dí àwa mùsùlùmí lọ́wọ́. Èyí ni òfin tí ó máa múlẹ̀ ní èyíkéyìí orílẹ̀-èdè ’Islām. Àmọ́ nígbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ kò níí sí owó ìsákọ́lẹ̀ mọ́ àfi gbígba ’Islām nìkan.