Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè ni." Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Gbólóhùn ìparí āyah yìí ń sọ pé, ‘ìjọ Nūh lé Nūh jáde kúrò nínú ìlú’. Àmọ́ sūrah Hūd; 11:38 ń sọ pé, ‘Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.” Wọ́n ní, “Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ Nūh tí wọ́n ti lé jáde kúrò nínú ìlú ni ẹni tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́!”
Èsì: Kò sí ìtakora kan nínú rẹ̀. Al-Ƙur’ān kò fi rinlẹ̀ níbì kan kan pé, ìjọ Nūh lé Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jáde kúrò nínú ìlú. Ìpìlẹ̀ “wa-zdujir” ni “zajara” láti ara “zajr” – kíkọ n̄ǹkan àti híhánnà n̄ǹkan pẹ̀lú ohùn líle. Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran. Ìtúmọ̀ “wa-zdujir” yìí ni Allāhu ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣu‘arā’; 26:116 pé wọ́n ń fi lílẹ̀ lókò halẹ̀ mọ́ ọn. Ìtúmọ̀ kíkọ̀ náà ni ìtúmọ̀ t’ó jẹyọ nínú “muzdajar” t’ó parí āyah 4 ṣíwájú. Ìtúmọ̀ àkànlò fún “zajr” sì jẹyọ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:2. Kókó ọ̀rọ̀ ni pé, ìjọ Nūh fi ohùn líle kọ ọ̀rọ̀ sí Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lẹ́nu ni, kì í ṣe pé wọ́n lé e jáde kúrò nínú ìlú. Wọ́n kọ ìtẹ̀lé Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sílẹ̀ pẹ̀lú sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i. Àmọ́ Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nínú ìlú pẹ̀lú wọn títí ó fi kan ọkọ̀ ojú omi. W-Allāhu ’a‘lam.