ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé āyah t’ó pín ẹ̀dá sí mẹ́ta ní ọjọ́ Àjíǹde tako āyah t’ó pín wọn sí ìjọ méjì.
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin wọn. Nínú sūrah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ pé oríṣi ìjọ mẹ́ta ni àwọn ẹ̀dá máa pín sí ní ọjọ́ Àjíǹde. Ìjọ ọ̀tún, ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18-19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6-8, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run, ìjọ ọ̀tún àti ìjọ òsì nítorí pé, Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún ìjọ ọ̀tún, Ọgbà Iná sì wá fún ìjọ òsì. Àmọ́, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe àtúnpín ìjọ ọ̀tún sí ìjọ ọ̀tún àti ìjọ aṣíwájú nítorí pé, ìgbádùn ìkíní kejì yàtọ̀ gan-an síra wọn. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ nípa ìgbádùn ìjọ aṣíwájú láti āyah 10 sí āyah 26. Ó sọ nípa ìgbádùn ìjọ ọ̀tún láti āyah 27 sí āyah 40. Ó sì sọ nípa oníran-ànran ìyà ìjọ òsì láti āyah 41 sí āyah 56.