Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan t’ó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan t’ó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.


الصفحة التالية
Icon