Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa. A sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn àti òṣùwọ̀n nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). A tún sọ irin kalẹ̀. Ohun ìjagun t’ó lágbára àti àwọn àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni t’ó ń ran (ẹ̀sìn) Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí.


الصفحة التالية
Icon