Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gba Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́ ní òdodo, nítorí kí (Allāhu) lè fun yín ní ìlọ́po méjì nínú ìkẹ́ Rẹ̀ àti nítorí kí Ó lè fun yín ní ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn àti nítorí kí Ó lè forí jìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Gbólóhùn yìí: "Ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn" ó túmọ̀ sí ìmọ̀ nípa al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tí a ó fi máa rí ẹ̀sìn ṣe dáadáa. Ìmọ̀ ni ìmọ́lẹ̀, àìmọ̀ sì ni òkùnkùn.


الصفحة التالية
Icon