Àwọn t’ó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn nínú yín, àwọn ìyàwó kì í ṣe ìyá wọn. Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ìyá wọn bí kò ṣe ìyá tí ó bí wọn lọ́mọ. Dájúdájú wọ́n ń sọ aburú nínú ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ irọ́. Dájúdájú Allāhu ni Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
____________________
Kíyè sí i, òfin t’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún ọkọ láti fi ẹ̀yìn ìyàwó rẹ̀ wé ẹ̀yìn ìyá rẹ̀, òfin náà l’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un láti fi wé ẹ̀yìn ìyá t’ó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já l’ẹ́nu ọyàn.


الصفحة التالية
Icon