Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ni? Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn. Wọ́n kéré sí ìyẹn, wọ́n tún pọ̀ (ju ìyẹn) àfi kí Ó wà pẹ̀lú wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Āyah yìí tako sūrah Ƙọ̄f; 50:16.” Bákan náà, àwọn sūfī sọ pé, “Pẹ̀lú äyah yìí kò sí ibi tí Pàápàá Bíbẹ Ọlọ́hun kò sí!” Àwọn igun méjèèjì ti gbé e gbági. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bí wọ́n ti sọ.
Ní àkọ́kọ́ ná, kò sí àtakò láààrin āyah yìí àti sūrah Ƙọ̄f; 50:16. Bákan náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan. Tí Allāhu bá ṣe ìkejì ẹnì kan, tàbí Ó ṣe ìkẹta ẹni méjì, tí a sì mọ̀ pé Ọ̀kan ṣoṣo ni Pàápàá Bíbẹ Allāhu, tí àwa ẹ̀dá rẹ̀ sì pọ̀ ní òǹkà, èyí ti túmọ̀ sí pé gbólóhùn àkànlò ni gbólóhùn “Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn.” àti gbólóhùn “Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà.” (sūrah al-Hadīd; 57:4)
Wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ kò túmọ̀ sí sísọ Pàápàá Allāhu di púpọ̀ bí ẹ̀dá, kò sì túmọ̀ sí sísọ Allāhu di Ẹni tí kò níí wà lórí Ìtẹ́-Ọlá Rẹ̀ lókè sánmọ̀ keje, bí kò ṣe pé wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ ni pé, “Allāhu ń gbọ́ ohùn ẹ̀dá”, “Ó ń rí ẹ̀dá”, “Ó mọ ẹ̀dá”, “Ó ń ṣọ́ ẹ̀dá”. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:46, sūrah at-Tọlāƙ; 65:12 àti sūrah al-Mulk; 67: 16 àti 17.
Ṣíwájú sí i, nínú sūrah Ƙọ̄f; 50:16 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju isan ọrùn rẹ̀ lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbọ̀rọ̀-sílẹ̀ lẹ́nu ẹ̀dá ṣe súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 17 àti 18 nínú sūrah náà. Bákan náà, nínú sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:85 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju bí a ṣe súnmọ́ ara wa lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbẹ̀mí-ẹ̀dá ṣe máa súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí ẹ̀mí bá fẹ́ jáde lára ẹ̀dá. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 83 àti 84 nínú sūrah náà. Nítorí náà, ìsúnmọ́ tí Allāhu ń tọ́ka sí nínú àwọn āyah wọ̀nyẹn àti irú wọn mìíràn kò túmọ̀ sí ìsọ̀kalẹ̀ Allāhu wá sí inú isan ọrùn ẹ̀dá, bí kò ṣe pé àwọn mọlāika ni ọ̀rọ̀ náà kàn. Allāhu sì tún fi ìmọ̀ Rẹ̀, ìríran Rẹ̀, agbára Rẹ̀ àti ààbò Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn mọlāika náà. Wàyí, sūrah al-’Ani‘ām; 6:61 àti 62 ti yanjú gbogbo àlàyé ọ̀rọ̀ yìí.