(Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd." Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, wọ́n á wí pé: "Idán pọ́nńbélé ni èyí."
____________________
Láti ọ̀dọ̀ Jubaer ọmọ Mut‘im, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hī, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún Àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim).