Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún ẹ̀sìn Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: "Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa ẹ̀sìn Allāhu?" Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: "Àwa ni alárànṣe fún ẹ̀sìn Allāhu." Igun kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbà á gbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āl ‘Imrọ̄n; 3:55.


الصفحة التالية
Icon