Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni t’ó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i). Ànábì sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: "O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí."). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: "Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?" (Ànábì) sọ pé: "Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà."
____________________
Méjì ni ọ̀rọ̀ àṣírí náà. Ìkíní: bíbúra tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi Allāhu búra pé òun kò níí fẹ́ ẹrúbìnrin rẹ̀ kan, Mọ̄riyah Ƙibtiyyah (kí Allāhu yọ́nú sí i), ẹni t’ó bí ’Ibrọ̄hīm fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìkejì: sísọ tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé Abu Bakr Siddīƙ ni àrólé àkọ́kọ́, ‘Umọr ọmọ Kattọ̄b sì ni àrólé kejì (kí Allāhu yọ́nú sí wọn). Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì náà pamọ́ sí ọwọ́ Hafsọh. Àmọ́, Hafsọh fi tó ‘Ā’iṣah létí (kí Allāhu yọ́nú sí wọn).