Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.
____________________
“Ọ̀rọ̀ òjíṣẹ́” ni ìtúmọ̀ “ƙọolu rọsūl, àmọ́ al-Ƙur’ān kì í ṣe ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ bí kò ṣe “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. Àgbékalẹ̀ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ni ṣíṣe àfitì ọ̀rọ̀ sí ọ̀dọ̀ alágbàsọ. Bákan náà, āyah yìí jọ āyah 19 nínú sūrah at-Tẹkwīr ní ìsọ, àmọ “Òjíṣẹ́” tí wọ́n gbàlérò nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh ni Òjíṣẹ́ abara, ìyẹn Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Òjíṣẹ́ mọlāika ni wọ́n sì gbàlérò nínú āyah ti sūrah at-Tẹkwīr. Sàkánì ti ìkọ̀ọ̀kan ti jẹyọ l’ó ṣàfi hàn èyí bẹ́ẹ̀.