Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn , dájúdájú Àwa ni Alágbára
____________________
Ìyẹn ni pé, Èmi, Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn ń fi ara Mi búra. Wòóore: Èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pẹ̀lú “mọṣriƙ” àti “mọgrib” nínú sūrah al-Muzzammil; 73:9 ni agbègbè ibùyọ òòrùn àti agbègbè ibùwọ̀ òòrùn. Èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pẹ̀lú “mọṣriƙọen” nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:17 ni ibùyọ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùyọ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, “mọgribaen” ibùwọ̀ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùwọ̀ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pẹ̀lú “mọṣāriƙ àti mọgārib” ni àwọn ọ̀ọ́dúnrún àti ọgọ́ta ibùyọ òòrùn (360) ni agbègbè ibùyọ òòrùn àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún àti ọgọ́ta ibùwọ̀ òòrùn (360) ni agbègbè ibùwọ̀ òòrùn. (Tafsīr Bagawiy)


الصفحة التالية
Icon