Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) t’ó ń kírun;
____________________
Àwọn kristiẹni kan ń sọ pé, “Ìrun túmọ̀ sí ohun tí ó máa run ènìyàn.” Wọ́n ní, “Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ pé “ègbé ni fún àwọn olùkírun.”
Èsì: Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìkẹ́ àti ìbùkún ni ìrun kíkí jẹ́ fún olùkírun. Ní àkọ́kọ́ ná, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀tá Allāhu máa ń fún àwọn ọ̀rọ̀ kan ní ìtúmọ̀ t’ó ń tàbùkù ẹ̀sìn ’Islām. Ọ̀kan ni bí wọ́n ṣe túmọ̀ “ìrun” sí “ohun t’ó ń run ènìyàn”. Òmíràn ni bí wọ́n ṣe ń sọ pé “ẹlẹ́hàá” túmọ̀ sí “ẹni t’ó bọ́ há” tàbí kí wọ́n sọ pé “ẹ̀há híhá wà fún àwọn obìnrin onísìná” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti ṣàlàyé nípa ọ̀rọ̀ “ẹ̀há híhá” nínú sūrah an-Nisā’; 4:15 àti sūrah an-Nūr; 24:31. Ní ti “ìrun”, kò túmọ̀ sí “ohun t’ó ń run ènìyàn”. Àmọ́ ìtúmọ̀ “ìrun” ni “ohun t’ó ń run ẹ̀ṣẹ̀ olùkírun” nítorí pé, tí olùkírun bá ti ṣe àlùwàlá ni ó ti ṣan gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí ó ti fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe ṣíwájú. Bákan náà, ìrun kan sí ìrun kejì máa run gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí olùkírun dá láààrin ìrun àkọ́kọ́ sí ìrun kejì. Pẹ̀lú ìrun wákàtí márààrún lójoojúmọ́, ó ti run gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ rẹ̀ dànù. Ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ-àforíjìn l’ó máa run àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá dànù. Kíyè sí i! Nínú èdè Yorùbá, “ẹ̀run” ni “ohun tí ó ń run ènìyàn”, àmọ́ “ìrun” ni “ohun tí ó ń run ẹ̀ṣẹ̀”.
Ní ti āyah tí wọ́n ń tìràn mọ́, kò rújú rárá pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ ìrun tí àwọn munāfiki ń kí lẹ́yìn tí àsìkò ìrun náà ti kọjá àti ìrun ṣekárími. Āyah (5) sí āyah (7) t’ó tẹ̀lé āyah (4) ti fi èyí hàn kedere nítorí pé, “àwọn tí” tí í ṣe atọ́ka awẹ́-gbólóhùn aṣàpèjúwe l’ó bẹ̀rẹ̀ āyah (5) àti āyah (6).


الصفحة التالية
Icon