Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fun yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo (tí ìjọ́sìn tọ́ sí). Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó.
____________________
Kíyè sí i, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní orúkọ mẹ́rin wọ̀nyí nínú āyah yìí: “mọsīh”, “rọsūlullāh”, “kalmọtu-llāh” àti “rūhu-llāh”. Àwọn kristiẹni sì ń tìràn mọ́ “mọsīh”, “kalmọtu-llāh” àti “rūhu-llah” bí ẹni pé orúkọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí túmọ̀ sí pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni olùgbàlà, ọlọ́run, ẹlẹ́dàá àti olúwa. Èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní àkọ́kọ́ náà, nínú èdè Lárúbáwá kò sí èyí tí ó túmọ̀ sí olùgbàlà tàbí ọlọ́run tàbí ẹlẹ́dàá tàbí olúwa nínú àwọn orúkọ àti ìròyìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà tí al-Ƙur’ān fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìtúmọ̀ “mọsīh” nínú èdè Lárúbáwá nìwọ̀nyí: ẹni tí kò ní kòjẹ̀gbin, alárìnká tí kò ní ibùgbé kan ní pàtó, ẹni tí wọ́n fi òróró pa lára, ẹni tí ó máa ń fọwọ́ àdúà pa aláìlera láti tọrọ ìwòsàn fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́hun, olódodo, ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ rẹ́. Ní ti “kalmọtu-llāh”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ọ̀rọ̀ Allāhu / ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. Ọ̀rọ̀ Allāhu ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣẹ̀dá rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn “kun fayakūn”. Nígbà tí Allāhu ń sọ nípa ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ìtúmọ̀ yìí sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rinlẹ̀ fúnra Rẹ̀ nínú sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:45, 47 àti 59 pẹ̀lú sūrah Mọryam; 19:35. Kódà pípè tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pe ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní “kalmọtu-llāh” jẹ́ àpọ́nlé fún un ni nítorí pé, kò wúlẹ̀ sí ẹ̀dá kan, yálà ẹlẹ́mìí tàbí aláìlẹ́mìí, àfi kí ó jẹ́ “kalmọtu-llāh”. Ìyẹn ni pé, gbogbo ẹ̀dá tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀ l’Ó sọ “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” fún ṣíwájú kí irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ tó máa bẹ. Allāhu nìkan ṣoṣo l’Ó sì ni “Jẹ́ bẹ́ẹ̀”, kì í ṣe ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tàbí ẹlòmíìràn. Bákan náà, ní ti “rūhu-llāh”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ẹ̀mí Allāhu / ẹ̀mí Ọlọ́hun ”. Ẹ̀mí Allāhu ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀ sínú ikùn ìyá rẹ̀, Ó sì ní kí mọlāika Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wá fẹ́ atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ sára ìyá rẹ̀ nítorí kí ‘Īsā lè di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí. Àti ẹ̀mí mímọ́ àti ẹ̀mí àìmọ́ tàbí ẹ̀mí òkùnkùn, Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá ìkíní kejì wọn. Kì í ṣe Èṣù. Èṣù kò dá ohun kan kan. Èṣù gan-an fúnra rẹ̀, ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá tí Allāhu ṣẹ̀dá l’ó wà. Wòóore, fúnra Allāhu l’Ó kúkú fẹ́ atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ kan sára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nígbà tí Ó mọ ọ́n kalẹ̀ tán ní ọ̀bọrọgidi gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah Sọ̄d; 38:72 àti sūrah al-Hijr; 15:29. Ìyẹn kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa lẹ́yìn Allāhu. Báwo ni ‘Īsā ọmọ Mọryam tí wọ́n fi atẹ́gùn ẹ̀mí rẹ̀ rán mọlāika Jibril ṣe máa wá di olúwa? Rárá, kò lè di olúwa. Tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá wá pe ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní “rūhu-llāh” àpọ́nlé ni fún un nítorí pé, kò sí ẹ̀dá ẹlẹ́mìí kan níbikíbi àfi kí ó jẹ́ pé “rūhu-llāh” ni òun náà. Síwájú sí i, lílo “Ọlọ́hun” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán fún ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá Ọlọ́hun kò sọ ohun náà di ọlọ́hun tàbí olúwa tàbí ẹlẹ́dàá tàbí olùgbàlà, àmọ́ àpọ́nlé ni fún ẹ̀dá náà. Wòye sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kí ó tún lè yé ọ yékéyéké: Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ Mọryam di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ Èṣù di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Èsì kan náà ni gbogbo wọn ní. Èsì náà sì ni pé, “Ẹ̀mí Ọlọ́hun “rūhu-llāh” ni.” Èyí tí ó túmọ̀ sí pé Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá ẹ̀mí t’ó wà lára ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Síwájú sí i, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ràkúnmí kan ní “nọ̄ƙọtu-llāh”, ìtúmọ̀ “ràkúnmí Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé, “ràkúnmí ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ràkúnmí ìyanu tí ó jáde tòhun ti ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti inú àpáta. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún orúkọ ràkúnmí náà ni. Bákan náà, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ilé kan ní “Baetu-llāh”, ìtúmọ̀ “ilé Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé “ilé ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ilé tí àwọn ẹ̀dá ti ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun, ìyẹn sì ni mọ́sálásí. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún orúkọ ilé náà ni. Bákan náà, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pe ẹ̀dá kan ní “’abdullāh”, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé “ẹrú ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ẹ̀dá tí ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun, tí ó sì wà lábẹ́ òfin Ọlọ́hun pẹ̀lú ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ pátápátá fún Ọlọ́hun. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún ẹ̀dá náà ni ni nítorí pé gbogbo wa ni ẹrú Ọlọ́hun, a fẹ́ tàbí a kọ̀. Báwo wá ni “kalmọtu-llāh” ṣe máa túmọ̀ sí “kalmọh ni Ọlọ́hun / ọ̀rọ̀ ni Ọlọ́hun”? Àní sẹ́ báwo ni “rūhu-llāh” ṣe máa túmọ̀ sí “rūhu ni Ọlọ́hun / ẹ̀mí ni Ọlọ́hun”? Ìròrí àwọn kristiẹni lásán ni ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ náà, tí wọ́n ti mú wọ inú bíbélì wọn pé “Láti ìṣẹ̀ṣẹ̀kọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ ti wà. Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọlọ́run sì ni ọ̀rọ̀ náà.” Láéláé, Ọlọ́hun àwa mùsùlùmí kì í ṣe ọ̀rọ̀. Ọlọ́hun wa kì í ṣe ẹ̀mí. Nítorí náà, kò sí ẹ̀dá kan àfi kí ó di bíbẹ nígbà tí Allāhu bá sọ pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, mọ̀ dájú pé àpọ́nlé ni Mọ́là, Haúsá l’a Haúsá ń jẹ́. Nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ (noun phrase), ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ẹ̀yán-ajórúkọ (nominal modifier) fún ọ̀rọ̀-orúkọ kan ìyẹn ni pé, ìgbàkígbà tí Allāhu bá ṣe àfitì ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tì sọ́dọ̀ ara Rẹ̀, bí irú èyí “kalmọtu-llāh, rūhu-llāh, nāƙọtu-llāh, baetu-llāh, kitābu-llāh, ‘abdu-llāh, nabiyyu-llāh, rọsūlu-llāh” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe àpọ́nlé fún ọ̀rọ̀-orúkọ agbẹ̀yán náà, kò tún ní ìtúmọ̀ mìíràn bí kò ṣe láti fi “ìbátan ìní” hàn (possessive genitive). Nínú àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn, ẹ̀hun oníbàátan ìní (possessive genitive construction) ni ìtúmọ̀ t’ó máa ń wà níbikíbi tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ti lo orúkọ ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán-ajórúkọ nínú àpólà orúkọ, kì í sì ní ìtúmọ̀ alálàjẹ́ (appositive). Pẹ̀lú èyí ìtúmọ̀ “kalmọtu-llāh” ni “kalmọh ti Allāhu / kalmọh tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ kalmọh nítorí pé, kalmọh kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”; rūhu-llāh, “rūhu ti Allāhu / rūhu tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ rūhu nítorí pé, rūhu kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”; nāƙọtu-llāh “nāƙọh ti Allāhu / nāƙọh tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ nāƙọh nítorí pé nāƙọh kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”; baetu-llāh, “baeutu ti Allāhu / baetu tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ baetu nítorí pé, baetu kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí a sì ti sọ síwájú pé àpọ́nlé láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó jẹ́ fún ẹ̀dá kan nígbàkígbà tí Allāhu bá fi orúkọ ara Rẹ̀ (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ẹ̀yán ajórúkọ fún un. Nítorí náà, kò wúlẹ̀ sí kiní kan láyé àti lọ́run, yálà ipò ọlá tàbí ipò ìjọba, àfi kí ó jẹ́ ohun ìní fún Allāhu nítorí pé, ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ gbogbo wọn. Báwo wá ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá ṣe lè jẹ́ ohun ìní, tí ohun ìní sì máa tún jẹ́ Allāhu, Ọlọ́hun Olúwa? Kò lè ṣẹlẹ̀ láéláé. Nítorí náà, èyíkéyìí orúkọ ipò tí Allāhu bá lò fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), kò fi ibì kan kan túmọ̀ sí pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni olúwa tàbí olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu. Ṣebí àràkárà tí alágbẹ̀dẹ bá fi irin dá, kò lè sọ irin di alágbẹ̀dẹ.