(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, ìjìnlẹ̀ òye, at-Taorāh àti al-’Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo kó àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ ró, nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
____________________
Nínú āyah alápọ̀n-ọ́nlé yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu kan tí Ó fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe ní àsìkò t’ó fi jíṣẹ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. Àwọn iṣẹ́ ìyanu náà nìwọ̀nyí; Ìkíní: Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló. Ìkejì: Ó fi amọ̀ mọ ẹyẹ, ó sì fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, ẹyẹ náà sì fò lọ. Ìkẹta: Ó wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn. Ìkẹrin: Ó mú àwọn òkú jáde ní alààyè láti inú sàréè, ìyẹn ni pé, ó jí òkú dìde. Iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 110 nínú sūrah yìí, sūrah al-Mọ̄’idah. Ìkarùn-ún: Ó sọ ọpọ́n oúnjẹ ńlá kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀, wọ́n sì jẹ oúnjẹ àtọ̀runwá nílé ayé. Ìyẹn wà nínú āyah 114, nínú sūrah yìí bákan náà. Iṣẹ́ ìyanu yìí gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi sọ sūrah yìí “al-Mọ̄’idah” lórúkọ. Ìkẹfà: Ó máa ń sọ àṣírí ohun tí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ lóúnjẹ àti èyí tí wọ́n gbé pamọ́ sínú ilé wọn. Ìyẹn wà nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:40. Èyí ni àwọn kristiẹni tún tìràn mọ́ gẹ́gẹ́ bi ìṣe wọn. Wọ́n sì ń wí pé “Nítorí tí Jésù la’jú afọ́jú, tí ó wo adẹ́tẹ̀ sàn, tí ó fún ẹyẹ amọ̀ àti okú ènìyàn ní ẹ̀mí, nítorí náà, ìyè wà nínú Jésù, òun sì ni olúwa àti olùgbàlà nítorí pé kò tún sí ẹlòmíìràn t’ó ṣe irú rẹ̀ rí, kódà Muhammad.” Èsì: Ní àkọ́kọ́ náà, al-Ƙur’ān kò sọ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi agbára ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára àti ìyọ̀ǹda Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá. Èyí sì ní awẹ́ gbólóhùn “bi’ithnī” t’ó ń jẹyọ nínú āyah náà. Àti pé awẹ́ gbólóhùn “bi’ithnī” yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú wá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:38, sūrah Gọ̄fir; 40:78 àti sūrah al ‘Ani‘ām; 6:34-35. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rí báyìí, ti ta ni ògo àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣé, ṣe tirẹ̀ ni tàbí t’Ọlọ́hun? Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá l’Ó ni ògo náà, kì í ṣe ti ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) rárá. Báwo wá ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe lè di olúwa nítorí iṣẹ́ tí Allāhu Ẹlẹ́dàá Rẹ̀ fún un ṣe! Bákan náà, àwọn onígbàgbọ́ òdodo t’ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn àwọn Ànábì (aleehim salām) kì í retí iṣẹ́ ìyanu, wọ́n kì í sì bèèrè fún un ṣíwájú kí wọ́n tó mọ Ọlọ́hun Òdodo ní Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ti tò wọn lórí ìgbàgbọ́ òdodo wọn àti ìjọ́sìn wọn. Àmọ́ nítorí àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn agbọ́mágbà, àwọn ọlọ́kàn-gíga tí wọ́n máa ń gbógun líle ti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ní àsìkò olúkùlùkù wọn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe máa ń fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní àǹfààní iṣẹ́ ìyanu ṣe. Bí ó tilẹ̀ já sí pé kò sí ẹ̀dá tí ìṣẹ̀dá rẹ̀ kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu Allāhu, àìláròjinlẹ̀ ènìyàn l’ó tún fi ń wá iṣẹ́ ìyanu mìíràn kiri kí ó tó lè mọ Allāhu ní Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Ìdí nìyí tí al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé fi ń darí wa síbi wíwo àwọn iṣẹ́ ìyanu t’ara wa gan-an, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah ath-Thāriyāt; 51:21. “Nínú ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni?” Lẹ́yìn náà, kò fẹ́ẹ̀ sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu rán níṣẹ́, tí Allāhu kò níí fún un ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ máa jẹmọ́ àsìkò àti irú àwọn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ sí. Ẹ jẹ́ kí a wòye sí àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ: Al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, nínú sūrah Hūd; 11:37-48 àti sūrah al-Mu’minūn; 23: 27-30, ó fi iṣẹ́ ìyanu kíkan ọkọ̀ ojú-omi rinlẹ̀ fún Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́, Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ní àsìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kọ́kọ́ pa ilé ayé rẹ́ pẹ̀lú omi ìyanu. Ṣebí ọkọ̀ ojú-omi tí Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kàn nígbà náà ni Allāhu fi ṣe ìgbàlà fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lásìkò náà. Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni ìbá kúkú lẹ́tọ̀ọ́ sí oríkì olùgbàlà aráyé nípasẹ̀ ọ̀kọ̀ ìgbàlà rẹ̀. Àmọ́ a ò lè pè é ní olùgbàlà nítorí pé, pẹ̀lú ìyọ̀ǹda, àṣẹ, ògo àti agbára Allāhu l’ó lò fún kíkan ọkọ̀ ojú-omi ńlá náà àti wíwa ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sí èbúté ayọ̀, láì kọ́ ẹ̀kọ́ kíkàn àti wíwà tẹ́lẹ̀, - Allāhu ’akbar. Bákan náà, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé fi iṣẹ́ ìyanu méjì rinlẹ̀ fún ẹni tí àwọn kristiẹni mọ̀ sí “Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́”, Ọ̀rẹ́ Àyò Ọlọ́hun “kọlīlu-llāh”, Baba-ńlá àwọn Òjíṣẹ́, Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìkíní: Nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:68-69 láti ka ìtàn nípa bí àwọn ọ̀ṣẹbọ ṣe ju Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sínú iná ńlá láti gbẹ̀mí rẹ̀. Àmọ́ iná náà di ohun tútù àlàáfíà fún Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìkejì: Nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:260 láti ka ìṣẹ̀lẹ̀ kan nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pé, ó pa oríṣi ẹyẹ mẹ́rin, ó gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn, ó sọ wọ́n di lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, ó bù ú díẹ̀díẹ̀, ó sì bò wọ́n mọ́’nú ilẹ̀ ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí pe ẹyẹ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, eegun àti ẹran ara ẹyẹ kọ̀ọ̀kan sì bẹ̀rẹ̀ sí parapọ̀ lójú rẹ̀. Àwọn òkú ẹyẹ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó ti gún kúnná, tí ó sì ti bò mọ́lẹ̀ sì padà sípò aláàyè, - Allāhu ’akbar. - Ṣé ẹ rí i báyìí pé, Ànábì ’Ibrọ̄hīm náà ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe iṣẹ́ ìyanu. Òun náà jí òkú ẹyẹ dìde? Kódà Ànábì ’Ibrọ̄hīm kò wulẹ̀ mọ ọ̀bọrọgidi kan kan bí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) alámọ̀-ẹyẹ ti ṣe. Àní sẹ́, Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò kúkú ṣẹ̀ṣẹ̀ fátẹ́gùn kan kan sínú àwọn ẹyẹ náà kí wọ́n tó di aláàyè padà. Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kàn pè wọ́n ní ìkọ̀ọ̀kan, wọ́n sì jẹ́pè rẹ̀. Ti ta ni ògo àti agbára wọ̀nyí bí kò ṣe ti Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Lẹ́yìn náà, Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé fi àwọn iṣẹ́ ìyanu kan ròyìn òun náà. Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń lo ọ̀pá rẹ̀ láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá náà ṣe di ejò, tí ejò náà sì kó gbogbo idán kàbìtì-kàbìtì tí àwọn òpìdán Fir‘aon pa kalẹ̀. Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tún fi ọ̀pá yìí pín agbami odò ńlá sí méjì pẹ̀lú àwọn ojú-ọ̀nà gbòòrò láààrin rẹ̀ fún ìgbàlà àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ ìyà Fir‘aon. Ó sì tún fi pa odò náà dé papọ̀ mọ́ra wọn fún ìparun Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Bákan náà, Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi burè ẹran ara màálù “baƙọrah” jí òkú díde, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:73. Iṣẹ́ ìyanu yìí gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi sọ sūrah yìí ní “al-Baƙọrah” - “màálù”. – Sūrah yìí sì tún ni ọgbà ọ̀rọ̀ t’ó ní ẹsẹ ọ̀rọ̀ t’ó pọ̀ jùlọ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa àti olùgbàlà, tòhun ti bí ó tún ṣe gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn Fir‘aon. Síwájú sí i, ní ti Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Allāhu fún òun náà ní àwọn iṣẹ́ ìyanu kan ṣe, àmọ́ èyí t’ó ga jùlọ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu náà ni ààbò mímọ́ tí Allāhu fi bo al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Èyí ń jẹ́ iṣẹ́ ìyanu t’ó ga jùlọ nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí: Ìkíní ni pé, gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún àwọn Ànábì t’ó ṣíwájú l’ó ti lọ. Gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu wọn sì ti di ìtàn gẹ́gẹ́ bí àwọn fúnra wọn ti ṣe di ẹni-ìtàn rere. Al-Ƙur’ān nìkan ni kò níí di ìtàn láéláé. Ìkejì: òǹkà díẹ̀díẹ̀ ló kúkú gbà fún àwọn Ànábì oníṣẹ́-ìyanu wọ̀nyẹn. Ṣebí tòhun ti àwọn iṣẹ́ ìyanu ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bíi ènìyàn méjìlá lọmọ-lẹ́yìn rẹ̀ lójú ayé rẹ̀. Ẹ wo ọmọ-lẹ́yìn púpọ̀ tí al-Ƙur’ān mú wá fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lójú ayé rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu wo ni àwọn ènìyàn gbàgbọ́ nínú rẹ̀ tó báyìí? Kò sí. Tí mo bá tún wá mẹ́nu lé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ṣe, ó máa gba ojú-ewé púpọ̀. Àmọ́ èròǹgbà àwọn aláìmọ̀kan ni pé, nígbà tí wọn kò ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kà nínú al-Ƙur’ān, wọ́n ti lérò pé kò rí iṣẹ́ ìyanu kan kan ṣe, irú èyí tí wọ́n ń wá kiri bí ẹni tí ń wá ìwo ẹṣin kiri. Ẹ lọ ka àwọn tírà lórí rẹ̀. Òdidi tírà ni àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ṣe lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bákan náà, nínú sūrah Yūsuf; 12: 26-27 ni a ti ka ìtàn nípa ọmọ òpóǹló tí òun náà sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ nígbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìbàjẹ́ àti ìbani-lórúkọjẹ́ kan Ànábì Yūsuf ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ níbi ẹ̀sùn náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu ọmọ òpóǹló náà. Nítorí náà, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ló sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló. Wàyí, kókó ọ̀rọ̀ wa ni pé, iṣẹ́ ìyanu kan kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan di olúwa àti olùgbàlà. Èyí sì ni òdodo ọ̀rọ̀ pọ́nńbélé tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rinlẹ̀ nípa àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (aleehim sọlāt wa salām) fún àwọn tí kò bá fẹ́ tara wọn wọ inú Iná gbére l’ọ́jọ́ Àjíǹde. Ẹ kà á nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:79-80.


الصفحة التالية
Icon