Àwọn méjèèjì sọ pé: "Olúwa wa, a ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí wa. Tí O ò bá foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa, dájúdájú a máa wà nínú àwọn ẹni òfò."
____________________
Láti āyah 19 sí 24 nínú sūrah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó ṣẹlẹ̀ sí bàbá ńlá wa Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá ńlá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) nípa bí àwọn méjèèjì ṣe jẹ èso igi tí Allāhu kọ̀ fún wọn láti jẹ. Ó tún wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:35-39 àti sūrah Tọ̄hā; 20:120-123. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn okùnfà ìṣìnà fún gbogbo àwọn kristiẹni pátápátá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ìgbàgbọ́ wọn fi forí sánpọ́n láti ìpìlẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò kúkú ṣàdédé pe àwọn kristiẹni ní olùṣìnà nínú sūrah al-Fātihah, Allāhu kò sì ṣàdédé kọ̀ fún àwa mùsùlùmí láti mú wọn ní ọ̀rẹ́, yálà ọ̀rẹ́ àyò tàbí ọ̀rẹ́ lásán, tí kì í bá ṣe pé ìgbàgbọ́ wọn dúró sórí àwọn ìṣìnà gban̄kọgban̄kọ méje kan.
Ìkíní; àwọn kristiẹni di olùṣìnà bẹ̀rẹ̀ láti ara sísọ pé gbogbo àwọn ọmọ Ànábì Ādam jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam jẹ láti ọjọ́ ìbí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Ìkejì; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé wọ́n kan Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mọ́ igi àgbélébùú. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé “wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ àgbélébùú…” Ìkẹta; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé ìgbàlà wà nínú ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú àti pé ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ànábì Ādam tí wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ ègún èso tí òun àti ìyàwó rẹ̀ jẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n tún ṣe gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú ti pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rẹ́ fún gbogbo àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí igi àgbélébùú. Allāhu sì sọ pé ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmìíràn mọ́ tirẹ̀. Ìkẹrin; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún nítorí pé, wọ́n gbà pé ìkíní kejì wọn nìkan ni kò ní ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àti pé wọ́n tún gbàgbọ́ pé, ìkíní kejì wọn ni kò dá ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rí. Allāhu sì sọ pé kò sí ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Òun. Ìkarùn-ún; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ọmọ Ọlọ́hun. Allāhu sì sọ pé Òun kò bímọ, Òun kò sì fi ẹnì kan kan ṣọmọ. Ìkẹfà: àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹ̀yàmẹ̀yà láààrin àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ṣàì gbàgbọ́ nínú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí wọ́n sì ń fi ẹnu àbùkù t’ó lágbára kàn òun pẹ̀lú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ mìíràn tí Allāhu rán níṣẹ́ sáyé. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé àwọn t’ó ń ṣẹ̀yàmẹ̀yà láààrin àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ ni ojúlówó aláìgbàgbọ́. Ìkeje: àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe ń tọwọ́bọ tírà tí Allāhu fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti tírà tí Allāhu fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lójú, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí oríṣiríṣi tírà méjèèjì náà fi pọ̀ lórí igbá, tí wọn kò sì yé yí wọn padà sí ìfẹ́-inú wọn lórúkọ “àtúnṣe” látìgbàdégbà. Allāhu sì sọ pé ègbé ni fún àwọn t’ó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun.
Wàyí nípa ìṣìnà àwọn kristiẹni lórí èso tí Ànábì Ādam àti Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ, kókó mẹ́fà wọ̀nyí ni òdodo nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kókó kìíní: bàbá ńlá wa Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá ńlá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ èso igi náà. Jíjẹ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn àwọn méjèèjì nìkan, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àwọn ọmọ wọn kan kan. Kókó kejì: àwọn méjèèjì tọrọ àforíjìn lórí àṣìṣe náà, Allāhu sì foríjìn àwọn méjèèjì. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:37 àti sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:19-23. Kókó kẹta: Allāhu ti forí jìn àwọn méjèèjì pátápátá ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó ṣọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:120-123. Kókó kẹrin: ìsọ̀kalẹ̀ àwọn méjèèjì sórí ilẹ̀ ayé yìí wá sí ìmúṣẹ nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Allāhu pé Òun fẹ́ dá àrólé kan sórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:30. Kókó karùn-ún: kò sí ẹnì kan kan t’ó jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ náà láti ara àwọn méjèèjì nítorí pé, Allāhu ti forí jìn àwọn méjèèjì pátápátá. Kókó kẹfà: àdámọ́ tí Allāhu dámọ́ ìṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ṣoṣo ni àwọn ọmọ rẹ̀ jogún pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nítorí pé, Allāhu ti fi àdámọ́ ìtẹ̀lé-àṣẹ àti ìyapa àṣẹ sínú ìṣẹ̀dá wa láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àdámọ́ méjèèjì náà sì ti wà lára Ànábì Ādam láti ọjọ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti ṣíwájú ọjọ́ èso t’ó jẹ́. Nítorí náà, tí a bá tẹ̀lé àṣẹ Allāhu, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá yapa àṣẹ Allāhu, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn ìyapa àṣẹ Rẹ̀, tí a sì tọrọ àforínjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá lo ìkápá tí Allāhu fún wa láti lè tẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá sì lo ìkápá tí Allāhu fún wa láti tẹ̀lé ìfẹ́-inú wa, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àmọ́ tí a bá kùnà láti ronú pìwàdà lórí ìyapa àṣẹ Allāhu, tí a ò sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, kì í ṣe Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’a fi jọ. Nítorí náà, ìyàtọ̀ wà láààrin sísọ pé a jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti sísọ pé a jogún àwọn àdámọ́ ìyapa àṣẹ àti ìtọrọ-àforíjìn láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ní ti jíjẹ ogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, ìyẹn ń fi dídi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ru ẹlòmíìràn rinlẹ̀. Àbòsì ńlá sì nìyẹn. Allāhu kì í sì ṣe Ọba alábòsí. Ní ti jíjẹ ogún àdámọ́ ìyapa àṣẹ àti ìtọrọ-àforíjìn láti ara Ànábì Ādam, ìyẹn ń fi dídi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ru ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn. Déédé àti dọ́gba sì nìyẹn. Allāhu sì ni Ọba Onídéédé.
Síwájú sí i, lára ohun t’ó ń ṣàfi hàn ìṣìnà àwọn kristiẹni lórí èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, tí wọ́n sì sọ gbogbo ọmọ rẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀ èso nípasẹ̀ rẹ̀, òhun ni pé, àwọn ìjọ tí Allāhu parẹ́ ṣíwájú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ṣé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ādam àti ìyàwó rẹ̀ jẹ ni tàbí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn dá lẹ́ṣẹ̀? Allāhu kò pa ìjọ kan run rí bí kò ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọwọ́ wọn. Bákan náà, àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò ì bàlágà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan lọ́rùn wọn títí wọ́n fi máa bàlágà. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá nígbà náà nìkan lẹ́ṣẹ̀ tí ó máa wà lọ́rùn wọn. Nítorí náà, kò sí ègún kan kan lórí àwọn ọmọ Ànábì Ādam nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ. Bákan náà, kò sí ẹni tí kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tara tirẹ̀ rí nínú gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, kódà t’ó fi mọ́ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, ọmọ ènìyàn ni, kì í ṣe ọmọ Ọlọ́hun. Àrọ́mọdọ́mọ Ànábì Ādam ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), kò ṣàì jogún àwọn àdámọ́ lára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé al-Ƙur’ān kò sí fún kíka ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ lọ́rùn - ṣebí ẹni ẹ̀ṣà jùlọ ni gbogbo wọn, - ọ̀wọ́ ohun tí Allāhu bá sọ fún wa nípa wọn nìkan l’ó kúkú kàn wá jùlọ nínú ọ̀rọ̀ wọn. Tí a ò bá rí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan nípa ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú al-Ƙur’ān, kò túmọ̀ sí pé òun náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kan kan rí. Ṣebí a ò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan kà nínú al-Ƙur’ān nípa àwọn Ànábì mìíràn, gẹ́gẹ́ bí Ànábì Lūt, Ànábì Sọ̄lih, Ànábì Ṣu‘aeb, Ànábì Ya‘ƙūb, Ànábì ’Ishāƙ, Ànábì ’Ismọ‘īl, Ànábì Yahyā, Ànábì Yūṣa‘u àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ (aleehim salām). Bákan náà, èyí kò túmọ̀ sí pé wọn kò jogún àwọn àdámọ́ òkè wọ̀nyẹn lára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), bẹ́ẹ̀ sì ni pé, àìrí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan kà nípa wọn kò sọ wọ́n di olúwa àti olùgbàlà. Kíyè sí i, ẹ̀dá Ọlọ́hun kúkú ni àwọn mọlā’ika, àmọ́ kò sí àdámọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá nínú ìṣẹ̀dá tiwọn. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ìyẹn kò sọ ẹnikẹ́ni nínú wọn di olúwa àti olùgbàlà, yálà mọlāika Jibrīl, ẹni tí àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ “Ẹ̀mí Mímọ́” tàbí mọlāika mìíràn. Nítorí náà, olùtàbùkù Ànábì Ādam ni ẹni tí ó bá ń sọ pé àwa ọmọ rẹ̀ jogún ègún èso t’ó jẹ lára rẹ̀. Irú ẹni náà kì í ṣọmọ rere. W-Allāhu ’a‘lam.


الصفحة التالية
Icon