Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
____________________
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lérò pé àlá lílá ni ìrìn-àjò òru tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rìn, ohun tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ jùlọ ni pé, ìrìn-àjò òru náà jẹ́ ìrìn-àjò ẹ̀mí àti ara. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ ọ̀rọ̀ ìrìn-àjò náà ní ìsọ àlá lílá páàpáà. Ẹ wo àgbékalẹ̀ āyah ìrìn-àjò ẹ̀mí àti ara yìí sí àgbékalẹ̀ àwọn āyah àlá lílá wọ̀nyí nínú sūrah Yūsuf; 12:4 & 43, sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:102 àti sūrah al-Fat-h; 48:27. Bákan náà, ìrìn-àjò náà ìbá jẹ́ àlá lílá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbá tí ṣe àtakò sí i. Àti pé ṣíṣe àtakò sí ìrìn-àjò náà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa bí àwọn ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ìrìn-àjò òru náà ṣe ga tayọ òye wọn ló kó wọn sínú àdánwò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa rẹ̀ nínú āyah 60 nínú sūrah yìí. Kíyè sí i, gbólóhùn “subhān-llathī” ìbá tí bẹ̀rẹ̀ āyah yìí, Tí ó bá jẹ́ pé ìrìn-àjò ojú àlá lásán ni. Síwájú sí i, àwọn n̄ǹkan pàtàkì pàtàkì ni Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fojú rí nínú àwọn sánmọ̀ àti lókè sánmọ̀ keje lórí ìrìn-àjò òru rẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú un rìn. Nínú ìrìn-àjò òru náà ni Allāhu sì ti fún un ní àwọn ìrun wákàtí márùn-ún. Àmọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò fojú rí Allāhu rárá (subhānahu wa ta'ālā) ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ ìyá wa ‘Ā’iṣah (r.ah) tí ó sọ pé: “Dájúdájú òpùrọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé (Ànábì) Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fojú rí Olúwa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìyá wa, ‘Ā’iṣah (r.ah) fi sūrah al-’An‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:51 ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ náà.” (al-Bukāriy)