Ní ọjọ́ tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin yóò wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Ẹ dúró fún wa ná, ẹ jẹ́ kí á mú nínú ìmọ́lẹ̀ yín." A óò sọ fún wọn pé: "Ẹ padà s’ẹ́yìn yín, kí ẹ lọ mú ìmọ́lẹ̀.” Wọ́n sì máa fi ògiri kan, t’ó ní ìlẹ̀kùn sáàrin wọn. Ìkẹ́ wà nínú rẹ̀, ìyà sì wà ní òde rẹ̀ ní ọwọ́ iwájú rẹ̀.
Èyí ni ọjọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa tan àwọn munāfiki gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe sọ ṣíwájú nínú sūrah an-Nisā’; 4:142. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
الترجمة اليورباوية