---
title: "ترجمة سورة الأحزاب - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/index.php/surah/1/33/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/index.php/surah/1/33/book/2001"
surah_id: "33"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الأحزاب - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/index.php/surah/1/33/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الأحزاب - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/index.php/surah/1/33/book/2001*.

Translation of Surah الأحزاب from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 33:1

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ ٱتَّقِ ٱللَّهَ وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمࣰا [33:1]

Ìwọ Ànábì, bẹ̀rù Allāhu. Má sì tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 33:2

> وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرࣰا [33:2]

Tẹ̀lé ohun tí A ń mú wá fún ọ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 33:3

> وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلࣰا [33:3]

Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.

### الآية 33:4

> مَّا جَعَلَ ٱللَّهُ لِرَجُلࣲ مِّن قَلۡبَيۡنِ فِي جَوۡفِهِۦۚ وَمَا جَعَلَ أَزۡوَٰجَكُمُ ٱلَّٰٓـِٔي تُظَٰهِرُونَ مِنۡهُنَّ أُمَّهَٰتِكُمۡۚ وَمَا جَعَلَ أَدۡعِيَآءَكُمۡ أَبۡنَآءَكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ قَوۡلُكُم بِأَفۡوَٰهِكُمۡۖ وَٱللَّهُ يَقُولُ ٱلۡحَقَّ وَهُوَ يَهۡدِي ٱلسَّبِيلَ [33:4]

Allāhu kò fún ènìyàn kan ní ọkàn méjì nínú ikùn rẹ̀. (Allāhu) kò sì sọ àwọn ìyàwó yín, tí ẹ̀ ń fi ẹ̀yìn wọn wé ẹ̀yìn ìyá yín, di ìyá yín. Àti pé (Allāhu) kò sọ àwọn ọmọ-ọlọ́mọ tí ẹ̀ ń pè ní ọmọ yín di ọmọ yín. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ẹnu yín. Allāhu ń sọ òdodo. Àti pé Òun l’Ó ń fi (ẹ̀dá) mọ̀nà.

### الآية 33:5

> ٱدۡعُوهُمۡ لِأٓبَآئِهِمۡ هُوَ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِۚ فَإِن لَّمۡ تَعۡلَمُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَمَوَٰلِيكُمۡۚ وَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحࣱ فِيمَآ أَخۡطَأۡتُم بِهِۦ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتۡ قُلُوبُكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورࣰا رَّحِيمًا [33:5]

Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ ò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ bá ṣàṣìṣe rẹ̀, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Àṣẹ pípe ẹrú pẹ̀lú orúkọ bàbá rẹ̀, tí fífi orúkọ olówó-ẹrú pe ẹrú kò sì dára, èyí ti fi hàn kedere pé, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún obìnrin láti fi orúkọ ọkọ rẹ̀ pààrọ̀ orúkọ bàbá rẹ̀. Àṣà àwọn aláìgbàgbọ́ ni àṣà fífi orúkọ ọkọ pààrọ̀ orúkọ bàbá. Yàtọ̀ sí pé, àṣà náà jẹ́ àṣà àwọn aláìgbàgbọ́, ó tún jẹ́ àbòsí láti ọ̀dọ̀ ọmọ sí bàbá rẹ̀ nítorí pé, òfin t’ó ní kí ọkùnrin máa jẹ́ orúkọ bàbá rẹ lọ, ìbáà di ọkọ ìyàwó, òfin yìí náà l’ó ní kí ọmọbìnrin máa jẹ́ orúkọ bàbá rẹ̀ lọ, ìbáà di ìyàwó. Nítorí náà, yálà kí obìnrin dárúkọ ara rẹ̀ báyìí “lágbájá ọmọ lámọrín” tàbí kí ó sọ pé “lágbájá aya tàmẹ̀dò”. Àgbékalẹ̀ orúkọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ìbátan t’ó wà láààrin orúkọ rẹ̀ àti orúkọ ọkùnrin t’ó pè mọ́ra rẹ̀. Wọn kò sì gbọ́dọ̀ dárúkọ ọkọ nìkan láti fi pe ìyàwó, gẹ́gẹ́ bí wọ́n kò ṣe gbọ́dọ̀ dárúkọ bàbá nìkan láti fi pe ọmọ. Ẹ pe ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú orúkọ rẹ̀.

### الآية 33:6

> ٱلنَّبِيُّ أَوۡلَىٰ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَأَزۡوَٰجُهُۥٓ أُمَّهَٰتُهُمۡۗ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضࣲ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ إِلَّآ أَن تَفۡعَلُوٓاْ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِكُم مَّعۡرُوفࣰاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورࣰا [33:6]

Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀). Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn t’ó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀). Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀.

Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), mùsùlùmí gbọ́dọ̀ fẹ́ràn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ju ẹ̀mí ara rẹ̀. Bákan náà, nípa ìdájọ́, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ tẹ ìfẹ́-inú rẹ̀ ba fún ìdájọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam).

### الآية 33:7

> وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِيثَٰقَهُمۡ وَمِنكَ وَمِن نُّوحࣲ وَإِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَۖ وَأَخَذۡنَا مِنۡهُم مِّيثَٰقًا غَلِيظࣰا [33:7]

(Rántí) nígbà tí A gba àdéhùn ní ọwọ́ àwọn Ànábì àti ní ọwọ́ rẹ, àti ní ọwọ́ (Ànábì) Nūh, ’Ibrọ̄hīm, Mūsā àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. A gba àdéhùn ní ọwọ́ wọn ní àdéhùn t’ó nípọn

### الآية 33:8

> لِّيَسۡـَٔلَ ٱلصَّٰدِقِينَ عَن صِدۡقِهِمۡۚ وَأَعَدَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابًا أَلِيمࣰا [33:8]

nítorí kí (Allāhu) lè bèèrè (òdodo) àwọn olódodo nípa òdodo wọn. Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 33:9

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ جَآءَتۡكُمۡ جُنُودࣱ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحࣰا وَجُنُودࣰا لَّمۡ تَرَوۡهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرًا [33:9]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ ò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.

Ọmọ ogun oníjọ ni àwọn ọmọ ogun ìjọ mẹ́ta kan tó para pọ̀ lórí ìjọ ọmọ ogun Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam): ìjọ ọmọ ogun Ƙuraeṣi, ìjọ ọmọ ogun Gatfān àti ìjọ ọmọ ogun Yẹhudi tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Nadīr. Gbogbo àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ní àpapọ̀ ni à ń pè ní ’ahzāb “ọmọ ogun oníjọ”.

### الآية 33:10

> إِذۡ جَآءُوكُم مِّن فَوۡقِكُمۡ وَمِنۡ أَسۡفَلَ مِنكُمۡ وَإِذۡ زَاغَتِ ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَبَلَغَتِ ٱلۡقُلُوبُ ٱلۡحَنَاجِرَ وَتَظُنُّونَ بِٱللَّهِ ٱلظُّنُونَا۠ [33:10]

(Ẹ rántí) nígbà tí wọ́n dé ba yín láti òkè yín àti ìsàlẹ̀ yín, àti nígbà tí àwọn ojú yẹ̀ (sọ́tùn-ún sósì), tí àwọn ọkàn sí dé ọ̀nà-ọ̀fun (ní ti ìpáyà). Ẹ sì ń ro àwọn èrò kan nípa Allāhu.

### الآية 33:11

> هُنَالِكَ ٱبۡتُلِيَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَزُلۡزِلُواْ زِلۡزَالࣰا شَدِيدࣰا [33:11]

Níbẹ̀ yẹn ni wọ́n ti fi àdánwò kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n sì milẹ̀ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ní ìmìtìtì líle.

### الآية 33:12

> وَإِذۡ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضࣱ مَّا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ إِلَّا غُرُورࣰا [33:12]

(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àìsàn wà nínú ọkàn wọn ń wí pé: “Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kò ṣe àdéhùn kan fún wa bí kò ṣe ẹ̀tàn.”

### الآية 33:13

> وَإِذۡ قَالَت طَّآئِفَةࣱ مِّنۡهُمۡ يَٰٓأَهۡلَ يَثۡرِبَ لَا مُقَامَ لَكُمۡ فَٱرۡجِعُواْۚ وَيَسۡتَـٔۡذِنُ فَرِيقࣱ مِّنۡهُمُ ٱلنَّبِيَّ يَقُولُونَ إِنَّ بُيُوتَنَا عَوۡرَةࣱ وَمَا هِيَ بِعَوۡرَةٍۖ إِن يُرِيدُونَ إِلَّا فِرَارࣰا [33:13]

(Ẹ rántí) nígbà tí igun kan nínú wọn wí pé: “Ẹ̀yin ará Yẹthrib, kò sí àyè (ìṣẹ́gun) fun yín, nítorí náà, ẹ ṣẹ́rí padà (lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́).” Apá kan nínú wọn sì ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ Ànábì, wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú ilé wa dá páropáro ni.” (Ilé wọn) kò sì dá páropáro. Wọn kò sì gbèrò ohun kan tayọ síságun.

Yẹthrib ni orúkọ ìlú Mọdīnah ṣíwájú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tó ṣe hijrah wá sí ibẹ̀.

### الآية 33:14

> وَلَوۡ دُخِلَتۡ عَلَيۡهِم مِّنۡ أَقۡطَارِهَا ثُمَّ سُئِلُواْ ٱلۡفِتۡنَةَ لَأٓتَوۡهَا وَمَا تَلَبَّثُواْ بِهَآ إِلَّا يَسِيرࣰا [33:14]

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé (ọmọ ogun oníjọ) wọlé tọ̀ wọ́n wá láti àwọn ìloro ìlú (Mọdīnah), lẹ́yìn náà, kí wọ́n pe (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) sínú ẹbọ ṣíṣe, wọn ìbá ṣẹbọ. Wọn kò sì níí gbé nínú ìlú mọ́ tayọ ìgbà díẹ̀ (tí wọn yóò fi parẹ́).

### الآية 33:15

> وَلَقَدۡ كَانُواْ عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ مِن قَبۡلُ لَا يُوَلُّونَ ٱلۡأَدۡبَٰرَۚ وَكَانَ عَهۡدُ ٱللَّهِ مَسۡـُٔولࣰا [33:15]

Dájúdájú wọ́n ti bá Allāhu ṣe àdéhùn ṣíwájú pé àwọn kò níí pẹ̀yìndà (láti ságun). Àdéhùn Allāhu sì jẹ́ ohun tí wọ́n máa bèèrè (lọ́wọ́ wọn).

### الآية 33:16

> قُل لَّن يَنفَعَكُمُ ٱلۡفِرَارُ إِن فَرَرۡتُم مِّنَ ٱلۡمَوۡتِ أَوِ ٱلۡقَتۡلِ وَإِذࣰا لَّا تُمَتَّعُونَ إِلَّا قَلِيلࣰا [33:16]

Sọ pé: “Síságun yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí ẹ bá sá fún ikú tàbí pípa (sí ojú ogun ẹ̀sìn. Tí ẹ bá sì ságun) nígbà náà, A ò níí fun yín ní ìgbádùn ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.

### الآية 33:17

> قُلۡ مَن ذَا ٱلَّذِي يَعۡصِمُكُم مِّنَ ٱللَّهِ إِنۡ أَرَادَ بِكُمۡ سُوٓءًا أَوۡ أَرَادَ بِكُمۡ رَحۡمَةࣰۚ وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيࣰّا وَلَا نَصِيرࣰا [33:17]

Sọ pé: “Ta ni ẹni tí ó lè dá ààbò bò yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá fẹ́ fi aburú kàn yín tàbí tí Ó bá fẹ́ kẹ yín?” Wọn kò sì lè rí aláàbò tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.

### الآية 33:18

> ۞ قَدۡ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ ٱلۡمُعَوِّقِينَ مِنكُمۡ وَٱلۡقَآئِلِينَ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ هَلُمَّ إِلَيۡنَاۖ وَلَا يَأۡتُونَ ٱلۡبَأۡسَ إِلَّا قَلِيلًا [33:18]

Dájúdájú Allāhu ti mọ àwọn t’ó ń fa ènìyàn sẹ́yìn nínú yín àti àwọn t’ó ń wí fún àwọn arakùnrin wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa.” Wọn kò sì níí lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn àfi (ogun) díẹ̀.

### الآية 33:19

> أَشِحَّةً عَلَيۡكُمۡۖ فَإِذَا جَآءَ ٱلۡخَوۡفُ رَأَيۡتَهُمۡ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ تَدُورُ أَعۡيُنُهُمۡ كَٱلَّذِي يُغۡشَىٰ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡمَوۡتِۖ فَإِذَا ذَهَبَ ٱلۡخَوۡفُ سَلَقُوكُم بِأَلۡسِنَةٍ حِدَادٍ أَشِحَّةً عَلَى ٱلۡخَيۡرِۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَمۡ يُؤۡمِنُواْ فَأَحۡبَطَ ٱللَّهُ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرࣰا [33:19]

Wọ́n ní ahun si yín (láti ṣe ìrànlọ́wọ́). Nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá dé, o máa rí wọn tí wọn yóò máa wò ọ́. Ojú wọn yó sì máa yí kiri ràkọ̀ràkọ̀ (ní ti ìbẹ̀rù) bí ẹni tí ó fẹ́ dákú, ṣùgbọ́n nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá lọ, (tí ìkógun bá dé), wọn yóò máa fi àwọn ahọ́n kan t’ó mú bérébéré ba yín sọ̀rọ̀ ní ti ṣíṣe ọ̀kánjúà sí oore náà. Àwọn wọ̀nyẹn kò gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.

### الآية 33:20

> يَحۡسَبُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ لَمۡ يَذۡهَبُواْۖ وَإِن يَأۡتِ ٱلۡأَحۡزَابُ يَوَدُّواْ لَوۡ أَنَّهُم بَادُونَ فِي ٱلۡأَعۡرَابِ يَسۡـَٔلُونَ عَنۡ أَنۢبَآئِكُمۡۖ وَلَوۡ كَانُواْ فِيكُم مَّا قَٰتَلُوٓاْ إِلَّا قَلِيلࣰا [33:20]

Wọ́n ń lérò pé àwọn ọmọ ogun oníjọ kò tí ì lọ, (wọ́n sì ti túká). Tí àwọn ọmọ ogun oníjọ bá (sì padà) dé, dájúdájú (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò fẹ́ kí àwọn ti wà ní oko láààrin àwọn Lárúbáwá oko, kí wọ́n máa bèèrè nípa àwọn ìró yín (pé ṣé ẹ ti kú tán tàbí ẹ sì wà láyé). Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n wà láààrin yín, wọn kò níí jagun bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.

### الآية 33:21

> لَّقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِي رَسُولِ ٱللَّهِ أُسۡوَةٌ حَسَنَةࣱ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَ وَذَكَرَ ٱللَّهَ كَثِيرࣰا [33:21]

Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fun yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí (ẹ̀san) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (ìgbà).

### الآية 33:22

> وَلَمَّا رَءَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ قَالُواْ هَٰذَا مَا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَصَدَقَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥۚ وَمَا زَادَهُمۡ إِلَّآ إِيمَٰنࣰا وَتَسۡلِيمࣰا [33:22]

Nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo rí àwọn ọmọ ogun oníjọ, wọ́n sọ pé: “Èyí ni ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní àdéhùn fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ti sọ òdodo ọ̀rọ̀.” (Rírí wọn) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe (àlékún) ìgbàgbọ́ òdodo àti ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ (fún àṣẹ Allāhu).

Àdéhùn náà wà nínú àwọn sūrah bí sūrah al-Baƙọrah; 2:214 àti sūrah al-‘Ankabūt; 29:1-3.

### الآية 33:23

> مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ رِجَالࣱ صَدَقُواْ مَا عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ عَلَيۡهِۖ فَمِنۡهُم مَّن قَضَىٰ نَحۡبَهُۥ وَمِنۡهُم مَّن يَنتَظِرُۖ وَمَا بَدَّلُواْ تَبۡدِيلࣰا [33:23]

Ó wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ olódodo nípa àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe; ó wà nínú wọn ẹni tí ó pé àdéhùn rẹ̀ (t’ó sì kú sójú ogun ẹ̀sìn), ó sì wà nínú wọn ẹni t’ó ń retí (ikú tirẹ̀). Wọn kò sì yí (àdéhùn) padà rárá.

### الآية 33:24

> لِّيَجۡزِيَ ٱللَّهُ ٱلصَّٰدِقِينَ بِصِدۡقِهِمۡ وَيُعَذِّبَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ إِن شَآءَ أَوۡ يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورࣰا رَّحِيمࣰا [33:24]

(Ìwọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi (òdodo) àwọn olódodo san wọ́n ní ẹ̀san òdodo wọn, àti nítorí kí Ó lè jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìyà tí Ó bá fẹ́ tàbí nítorí kí Ó lè gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 33:25

> وَرَدَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِغَيۡظِهِمۡ لَمۡ يَنَالُواْ خَيۡرࣰاۚ وَكَفَى ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلۡقِتَالَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزࣰا [33:25]

Allāhu sì dá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ padà tòhun ti ìbínú wọn; ọwọ́ wọn kò sì tẹ oore kan. Allāhu sì tó àwọn onígbàgbọ́ òdodo níbi ogun náà. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Olùborí.

### الآية 33:26

> وَأَنزَلَ ٱلَّذِينَ ظَٰهَرُوهُم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن صَيَاصِيهِمۡ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَ فَرِيقࣰا تَقۡتُلُونَ وَتَأۡسِرُونَ فَرِيقࣰا [33:26]

(Allāhu) sì mú àwọn t’ó ṣèrànlọ́wọ́ fún (àwọn ọmọ ogun oníjọ) nínú àwọn ahlul-kitāb sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú àwọn odi wọn. Ó sì ju ẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Ẹ̀ ń pa igun kan (nínú wọn), ẹ sì ń kó igun kan lẹ́rú.

Àwọn ahlul-kitāb wọ̀nyẹn ni àwọn yẹhudi tí wọ́n ń jẹ́ banū Ƙuraeṭḥọh, tí wọ́n ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àwọn wọ̀nyí mọ odi ńlá ńlá yípo àwọn ilé wọn fún ààbò ogun. Àwọn wọ̀nyí l’ó ṣe agbódegbà fún àwọn ọmọ ogun oníjọ. Lẹ́yìn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì dójú ti àwọn ọmọ ogun oníjọ tán, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fàbọ̀ sórí wọn.

### الآية 33:27

> وَأَوۡرَثَكُمۡ أَرۡضَهُمۡ وَدِيَٰرَهُمۡ وَأَمۡوَٰلَهُمۡ وَأَرۡضࣰا لَّمۡ تَطَـُٔوهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءࣲ قَدِيرࣰا [33:27]

(Allāhu) sì jogún ilẹ̀ wọn, ilé wọn, dúkìá wọn àti ilẹ̀ tí ẹ ò tẹ̀ rí fun yín. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 33:28

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّأَزۡوَٰجِكَ إِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا فَتَعَالَيۡنَ أُمَتِّعۡكُنَّ وَأُسَرِّحۡكُنَّ سَرَاحࣰا جَمِيلࣰا [33:28]

Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn ìyàwó rẹ pé: “Tí ẹ bá fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ẹ wá níbí kí n̄g fun yín ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀, kí n̄g sì fi yín sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà.

Ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀ ni ohunkóhun ní owó tàbí n̄ǹkan mìíràn tí ọkọ yóò fún ìyàwó tí ó fẹ́ kọ̀ sílẹ̀. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:236.

### الآية 33:29

> وَإِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَ فَإِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡمُحۡسِنَٰتِ مِنكُنَّ أَجۡرًا عَظِيمࣰا [33:29]

Tí ẹ bá sì fẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ilé Ìkẹ́yìn, dájúdájú Allāhu ti pèsè ẹ̀san ńlá sílẹ̀ de àwọn olùṣe-rere lóbìnrin nínú yín.”

### الآية 33:30

> يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ مَن يَأۡتِ مِنكُنَّ بِفَٰحِشَةࣲ مُّبَيِّنَةࣲ يُضَٰعَفۡ لَهَا ٱلۡعَذَابُ ضِعۡفَيۡنِۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرࣰا [33:30]

Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ìbàjẹ́ t’ó fojú hàn, A máa di àdìpèlé ìyà ìlọ́po méjì fún un. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.

### الآية 33:31

> ۞ وَمَن يَقۡنُتۡ مِنكُنَّ لِلَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتَعۡمَلۡ صَٰلِحࣰا نُّؤۡتِهَآ أَجۡرَهَا مَرَّتَيۡنِ وَأَعۡتَدۡنَا لَهَا رِزۡقࣰا كَرِيمࣰا [33:31]

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nínú yín, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, A máa fún un ní ẹ̀san ìlọ́po méjì. A sì ti pèsè ìjẹ-ìmu alápọ̀n-ọ́nlé sílẹ̀ dè é.”

### الآية 33:32

> يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ لَسۡتُنَّ كَأَحَدࣲ مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِنِ ٱتَّقَيۡتُنَّۚ فَلَا تَخۡضَعۡنَ بِٱلۡقَوۡلِ فَيَطۡمَعَ ٱلَّذِي فِي قَلۡبِهِۦ مَرَضࣱ وَقُلۡنَ قَوۡلࣰا مَّعۡرُوفࣰا [33:32]

Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹ ò dà bí ẹnì kan kan nínú àwọn obìnrin, tí ẹ bá ti bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ má ṣe dínhùn (sí àwọn ọkùnrin létí) nítorí kí ẹni tí àrùn wà nínú ọkàn rẹ̀ má baá jẹ̀rankàn. Kí ẹ sì máa sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára.

### الآية 33:33

> وَقَرۡنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجۡنَ تَبَرُّجَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ ٱلۡأُولَىٰۖ وَأَقِمۡنَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتِينَ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِعۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُذۡهِبَ عَنكُمُ ٱلرِّجۡسَ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِ وَيُطَهِّرَكُمۡ تَطۡهِيرࣰا [33:33]

Ẹ fìdí mọ́lé yín. Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ t’ó di mùsùlùmí). Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu kàn ń gbèrò láti mú ẹ̀gbin kúrò lára yín, ẹ̀yin ará ilé (Ànábì). Àti pé Ó (kàn ń gbèrò láti) fọ̀ yín mọ́ tónítóní ni.

### الآية 33:34

> وَٱذۡكُرۡنَ مَا يُتۡلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ وَٱلۡحِكۡمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا [33:34]

Ẹ rántí ohun tí wọ́n ń ké nínú ilé yín nínú àwọn āyah Allāhu àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah Ànábì). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀.

Àwọn àkíyèsí méjì kan ń bẹ lára gbogbo gbólóhùn àṣẹ tí ó wà nínú sūrah yìí láti āyah 28 sí 34. Àkíyèsí kìíní ni pé, àwọn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) dojú àwọn àṣẹ náà kọ ni àwọn ìyàwó Ànábì (kí Allāhu yọ́nú sí wọn), ṣùgbọ́n kò sí àṣẹ kan nínú rẹ̀ tí ó yọ àwọn mùsùlùmí lóbìnrin yòókù sílẹ̀. Ìdí ni pé, àgbékalẹ̀ àwọn àṣẹ náà dúró fún gbígbèrò gbogbogbò pẹ̀lú dídojú-ọ̀rọ̀ kọ aṣíwájú. Nítorí náà, ẹ wo ìṣerẹ́gí láààrin gbólóhùn yìí “Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ tó di mùsùlùmí)....” àti gbólóhùn yìí “Kí wọ́n má ṣe ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀…” èyí tí ó wà nínú sūrah an-Nūr; 24:31. 
Àkíyèsí kejì ni pé, èdè Lárúbáwá jẹ́ èdè jẹ́ńdà. Èdè jẹ́ńdà ni èdè t’ó ni ìhun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún akọ àti abo. Ìyẹn ni pé, tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ, èdè Lárúbáwá ti ní ìhun akọ fún akọ. Bákan náà, tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ obìnrin tàbí n̄ǹkan abo tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa obìnrin tàbí n̄ǹkan abo, èdè Lárúbáwá ti ní ìhun abo fún abo. Irúfẹ́ àbùdá yìí kò sí fún èdè Yorùbá. Ìhun akọ kò yàtọ̀ sí ìhun abo. Nítorí náà, gbogbo àwọn gbólóhùn àṣẹ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú wá nínú sūrah yìí láti āyah 28 sí 34 jẹ́ gbólóhùn àṣẹ fún ìhun abo nítorí pé, àwọn obìnrin ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa wọn. Àwọn sì ni Ó ń dojú gbólóhùn àṣẹ náà kọ. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a fẹ́ rí kọ́ nínú èyí ni pé, bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe pàṣẹ ìjọ́sìn fún àwọn ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ náà ni Ó ṣe pàṣẹ rẹ̀ fún àwọn obìnrin. Àti pé èèwọ̀ ni ohunkóhun tí ó bá lè sọ mùsùlùmí lóbìnrin di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ níní ọkọ nítorí pé, obìnrin ní ẹ̀sìn. ’Islām sì ni ẹ̀sìn rẹ̀, ẹ̀sìn Allāhu. Ẹ̀rí apayànjẹ (= ẹ̀rí t’ó ń pa iyàn jíjà jẹ) ni bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ń sọ nípa ẹ̀san àwọn olújọ́sìn; Ó ń sọ ọ́ pẹ̀lú ìhun akọ àti ìhun abo láì fi àwọn obìnrin ṣe olùjọ́sìn afarahẹ. Ẹ wo āyah 35 nínú sūrah yìí àti sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:195, sūrah an-Nisā’; 4:124, sūrah an-Nahl; 16:97, sūrah Gọ̄fir; 40:40 àti sūrah al-Hujurāt; 49:13.

### الآية 33:35

> إِنَّ ٱلۡمُسۡلِمِينَ وَٱلۡمُسۡلِمَٰتِ وَٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡقَٰنِتَٰتِ وَٱلصَّٰدِقِينَ وَٱلصَّٰدِقَٰتِ وَٱلصَّٰبِرِينَ وَٱلصَّٰبِرَٰتِ وَٱلۡخَٰشِعِينَ وَٱلۡخَٰشِعَٰتِ وَٱلۡمُتَصَدِّقِينَ وَٱلۡمُتَصَدِّقَٰتِ وَٱلصَّٰٓئِمِينَ وَٱلصَّٰٓئِمَٰتِ وَٱلۡحَٰفِظِينَ فُرُوجَهُمۡ وَٱلۡحَٰفِظَٰتِ وَٱلذَّٰكِرِينَ ٱللَّهَ كَثِيرࣰا وَٱلذَّٰكِرَٰتِ أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُم مَّغۡفِرَةࣰ وَأَجۡرًا عَظِيمࣰا [33:35]

Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùpáyà Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùpáyà Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n.

### الآية 33:36

> وَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنࣲ وَلَا مُؤۡمِنَةٍ إِذَا قَضَى ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ أَمۡرًا أَن يَكُونَ لَهُمُ ٱلۡخِيَرَةُ مِنۡ أَمۡرِهِمۡۗ وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلࣰا مُّبِينࣰا [33:36]

Kò tọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, nígbà tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bá ti parí ọ̀rọ̀ kan, láti ní ẹ̀ṣà (ọ̀rọ̀ mìíràn) fún ọ̀rọ̀ ara wọn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé.

### الآية 33:37

> وَإِذۡ تَقُولُ لِلَّذِيٓ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَأَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِ أَمۡسِكۡ عَلَيۡكَ زَوۡجَكَ وَٱتَّقِ ٱللَّهَ وَتُخۡفِي فِي نَفۡسِكَ مَا ٱللَّهُ مُبۡدِيهِ وَتَخۡشَى ٱلنَّاسَ وَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخۡشَىٰهُۖ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيۡدࣱ مِّنۡهَا وَطَرࣰا زَوَّجۡنَٰكَهَا لِكَيۡ لَا يَكُونَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ حَرَجࣱ فِيٓ أَزۡوَٰجِ أَدۡعِيَآئِهِمۡ إِذَا قَضَوۡاْ مِنۡهُنَّ وَطَرࣰاۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولࣰا [33:37]

(Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fún1 pé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ.2

1. Ẹni yìí ni Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu). Ìdẹ̀ra Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí rẹ̀ ni pé, Allāhu ṣe é ní mùsùlùmí. Ìdẹ̀ra Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí rẹ̀ ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mú un kúrò lóko ẹrú. Ó sọ ọ́ di olómìnira. 2. Ohun tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀ ni gbólóhùn yìí: "Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ …". Àmọ́ kàkà kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kéde gbólóhùn yìí fún àwọn mùsùlùmí, kí ó sì jíṣẹ́ fún Zaed, ńṣe ni Ànábì ń sọ fún un pé: "Mú ìyàwó rẹ dání..." Ohun tí ó sì fa èyí fún Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni pé, kí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn aláìgbàgbọ́ má baà wí pé: "Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) l’ó fi Zaenab fún Zaed, ọmọ rẹ̀. Ó tún fi ìyàwó tí ọmọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ṣaya…". Zaed kì í sì ṣe ọmọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Hārithah ni bàbá t’ó bí Zaed lọ́mọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ìdí tí àwọn aṣíwájú rere (r.ahm) fi sọ pé, nínú gbogbo āyah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé kò sí èyí tí ó lágbára lára Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti fi jíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn t’ó tó āyah: "Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ …". Nítorí náà, ẹ jìnnà sí àwọn ìtànkítàn tí àwọn kristiẹni bá ń sọ kiri nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kò sí èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú rẹ̀ àfi èyí tí A sọ sókè yìí. Kíyè sí i, bóyá ni Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (a.s.w.) wà tí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn ’Islām kì í sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀. Ìṣe àti àṣà wọn nìyẹn. Ẹni tí a sì lérò pé àwọn kristiẹni máa pọ́nlé, ohun tí wọ́n tún sọ nípa rẹ̀ ju fífi ẹ̀sùn ìyàwó púpọ̀ kan Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti fífẹ́ tí ó fẹ́ Zaenab tí Zaed kọ̀ sílẹ̀. Pípè tí àwọn kristiẹni ń pe Ànábì ‘Īsā ni ọmọ Allāhu, pípè tí wọ́n ń pè é ní ọlọ́hun ọmọ, pípè tí wọ́n ń pè é ní olúwa àti olùgbàlà, ó burú yéye ju fífi ẹ̀sùn ìyàwó púpọ̀ kan Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ṣe pe àkíyèsí wa sí aburú rẹ̀ nínú sūrah Mọryam; 19:88-95. Àmọ́ àwọn kristiẹni kò fura!

### الآية 33:38

> مَّا كَانَ عَلَى ٱلنَّبِيِّ مِنۡ حَرَجࣲ فِيمَا فَرَضَ ٱللَّهُ لَهُۥۖ سُنَّةَ ٱللَّهِ فِي ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلُۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قَدَرࣰا مَّقۡدُورًا [33:38]

Kò sí láìfí fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nípa ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un. (Ó jẹ́) ìlànà Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. Àti pé àṣẹ Allāhu jẹ́ àkọọ́lẹ̀ kan t’ó gbọ́dọ̀ ṣẹ.

### الآية 33:39

> ٱلَّذِينَ يُبَلِّغُونَ رِسَٰلَٰتِ ٱللَّهِ وَيَخۡشَوۡنَهُۥ وَلَا يَخۡشَوۡنَ أَحَدًا إِلَّا ٱللَّهَۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبࣰا [33:39]

(Kọ́ṣe àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́) àwọn t’ó ń jẹ́ iṣẹ́ Allāhu, tí wọ́n ń páyà Rẹ̀, tí wọn kò sì páyà ẹnì kan àyàfi Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.

### الآية 33:40

> مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدࣲ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمࣰا [33:40]

(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Ìtúmọ̀ “Ànábì” ni olùgba-wáhàyí, arímìsíígbà tàbí onímìísí. Ìmísí yìí náà sì ni ó máa fi jíṣẹ́ fún àwọn ìjọ rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé, kò sí ẹni tí ó lè di Òjíṣẹ́ Allāhu (afìmísíjíṣẹ́) àfi kí ó kọ́kọ́ jẹ́ Ànábì (arímìsíígbà). Ìmísí mímọ́ náà ni ó máa jẹ́ òfin ẹ̀sìn fún onímìísí náà àti ìjọ rẹ̀. Fún wí pé Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni “kātamu-nnabiyyīn” òpin àwọn arímìsíígbà, kò lè sí afìmísíjíṣẹ́ kan kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìtúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” nìyí nínú ẹ̀gbàwá Jubaer ọmọ Mut‘im, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hi, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim). Kíyè sí i, àwọn kan bíi ijọ Ahmadiyyah kò gbàgbọ́ pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n kọ́kọ́ fún “kātamu-nnabiyyīn” ní ìtúmọ̀ t’ó yàtọ̀ sí èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú āyah náà. Wọ́n ní “òrùka àwọn Ànábì” ni ìtúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn”. Lẹ́yìn náà, ìjọ Ahmadiyyah sọ pé, “Ànábì àti Òjíṣẹ́ Allāhu tí ó dìde nínú ìlú Ƙọ̄diyan, nílẹ̀ India tún ni olùdásílẹ́ ìjọ Ahmadiyyah, mirza ghulam Ahmad.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún ni Imam Mahdi tí à ń retí lópin ayé.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún ni Mọsīh, ‘Īsā ọmọ Mọryam tí à ń retí lópin ayé.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún sọ àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú ìjọ rẹ̀ di ànábì.” 
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, fúnra Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn Sọhābah (r.ahm) l’ó túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí “òpin àwọn Ànábì”. Ìṣìnà pọ́nńbélé ni fún ẹnikẹ́ni láti túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí n̄ǹkan mìíràn. “Òpin àwọn Ànábì” sì ni gbogbo tírà Tafsīr túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí. Kò sì sí ìyapa-ẹnu láààrin gbogbo àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām lórí títúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí “òpin àwọn Ànábì”. Dandan sì ni kí á gbógun ti ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa ìpanupọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām. 
Lẹ́yìn náà, ní ti arákùnrin tí wọ́n ń pè ní mirza ghulam Ahmad, òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn wulẹ̀ ni òun. Irọ́ ẹnu rẹ̀ ti pọ̀ jù. Alágbárí pọ́nńbélé sì ni pẹ̀lú. Irú iṣẹ́ aburú tí ṣeeu Ahmada Tijāni ṣe fún ’Islām gẹ́lẹ́ náà ni mirza ghulam Ahmad ṣe. Àwọn méjèèjì ni Pọ́ọ̀lù láààrin àwa mùsùlùmí. Ẹ wo díẹ̀ nínú irọ́ ńlá rẹ̀. Mirza ghulam Ahmad sọ pé: "Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé, bí ọmọ Mi ló ṣe wà sí Mi." (Tadhkirah, 362) Ṣé Allāhu bímọ ni? Ṣebí àwọn kristiẹni l’ó ń parọ́ mọ Ọlọ́hun pé Ó bímọ, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò bímọ, kò sì sọ ẹnì kan kan di ọmọ Rẹ̀. Irọ́ mìíràn nìyí láti ẹnu mirza ghulām Ahmad, ó sọ pé: "Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé, ìwọ wá láti ara Mi; Èmi náà wá láti ara rẹ." (Tadhkirah, ojú ewé 295) Ṣebí àwọn kristiẹni l’ó máa ń sọ pé ọlọ́hun t’ó wá láwòrán ọmọ ni Jésù Kristi! Ṣé ẹ̀ ń rí ìjọra láààrin ìjọ Ahmadiyyah àti àwọn kristiẹni báyìí. Irọ́ mìíràn nìyí láti ẹnu mirza ghulām Ahmad, ó sọ pé: "Nínú ìríran ẹ̀mí, mo rí ara mi pé èmi gan-an ni Allāhu. Mo sì ní ìgbàgbọ́ pé èmi gan-an nìyẹn." (Tadhkirah, 118) Ẹ wo bí ó ṣe sọra rẹ̀ di ọlọ́hun! Lẹ́yìn náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:158 kí ẹ rí bí ó ṣe sọra rẹ̀ di Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún òun àti ìjọ rẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Àti òun àti ṣeeu Ahmada Tijāniy, wọ́n wáyé láti wá tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ní ọ̀nà ẹkọrọ lórúkọ ’Islām. 
Síwájú sí i, àwọn kan tún sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun, kò yẹ fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti padà wá sáyé mọ́ lópin ayé.” Wọ́n tún sọ pé, “Ìgbàgbọ́ àwọn kristiẹni lásán ni ìgbàgbọ́ nínú ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Kì í ṣe ìgbàgbọ́ ’Islām rárá.” 
Èsì: Ní ti àwọn wọ̀nyí, wọ́n gbà pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun, àmọ́ ìṣòro tiwọn ni pé, wọn kò gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nípò ẹni tí kò ì kú, wọn kò sì gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń padà bọ̀ lópin ayé. Ọ̀gá ìṣòro àwọn wọ̀nyí ni pé, wọ́n wọ́gi lé gbogbo hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú Bukọ̄riy àti Muslim lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Àwọn hadith náà sì pọ̀ púpọ̀, wọ́n fẹsẹ̀ rinlẹ̀, wọn kò sì ní pọ́n-na rárá. Àmọ́ èrò-ọkàn àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn ni pé, àwọn hadīth náà tako āyah tí àwọn ń túmọ̀ sí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ẹ wo bí wọ́n ṣe ń tinú wàhálà kan bọ́ sínú wàhálà mìíràn lórí ọ̀rọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àdánwò kúkú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí Allāhu kó wa yọ. Àmọ́ sá, ẹ lọ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:55 àti sūrah an-Nisā’; 4:157 kí ẹ lè rí àlàyé apayànjẹ lórí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò ì kú, ó wà ní àyè, ó sì ń padà bọ̀ lópin ayé.

### الآية 33:41

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ ذِكۡرࣰا كَثِيرࣰا [33:41]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí Allāhu ní ìrántí púpọ̀.

### الآية 33:42

> وَسَبِّحُوهُ بُكۡرَةࣰ وَأَصِيلًا [33:42]

Ẹ ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

### الآية 33:43

> هُوَ ٱلَّذِي يُصَلِّي عَلَيۡكُمۡ وَمَلَٰٓئِكَتُهُۥ لِيُخۡرِجَكُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۚ وَكَانَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ رَحِيمࣰا [33:43]

(Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó ń kẹ yín, àwọn mọlāika Rẹ̀ (sì ń tọrọ àforíjìn fun yín), nítorí kí Allāhu lè mu yín kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àti pé Ó ń jẹ́ Àṣàkẹ́-ọ̀run fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 33:44

> تَحِيَّتُهُمۡ يَوۡمَ يَلۡقَوۡنَهُۥ سَلَٰمࣱۚ وَأَعَدَّ لَهُمۡ أَجۡرࣰا كَرِيمࣰا [33:44]

Ìkíni wọn ní ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Rẹ̀ ni "àlàáfíà." Ó sì ti pèsè ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlẹ́ sílẹ̀ dè wọ́n.

### الآية 33:45

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ شَٰهِدࣰا وَمُبَشِّرࣰا وَنَذِيرࣰا [33:45]

Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú, olùkìlọ̀,

### الآية 33:46

> وَدَاعِيًا إِلَى ٱللَّهِ بِإِذۡنِهِۦ وَسِرَاجࣰا مُّنِيرࣰا [33:46]

olùpèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ àti àtùpà ìmọ́lẹ̀.

### الآية 33:47

> وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ بِأَنَّ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَضۡلࣰا كَبِيرࣰا [33:47]

Fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú oore àjùlọ ńlá wà fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.

### الآية 33:48

> وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَدَعۡ أَذَىٰهُمۡ وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلࣰا [33:48]

Má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Fi bí wọ́n ṣe ń kó ìnira bá ọ sílẹ̀. Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì ń tó ní Alámòjúútó.

### الآية 33:49

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نَكَحۡتُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ طَلَّقۡتُمُوهُنَّ مِن قَبۡلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمۡ عَلَيۡهِنَّ مِنۡ عِدَّةࣲ تَعۡتَدُّونَهَاۖ فَمَتِّعُوهُنَّ وَسَرِّحُوهُنَّ سَرَاحࣰا جَمِيلࣰا [33:49]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fun yín. Nítorí náà, ẹ fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀. Kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà.

Ìjọra wà láààrin āyah yìí àti sūrah al-Baƙọrah; 2:221 àti sūrah an-Nūr; 24:26.

### الآية 33:50

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِنَّآ أَحۡلَلۡنَا لَكَ أَزۡوَٰجَكَ ٱلَّٰتِيٓ ءَاتَيۡتَ أُجُورَهُنَّ وَمَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَ مِمَّآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَيۡكَ وَبَنَاتِ عَمِّكَ وَبَنَاتِ عَمَّٰتِكَ وَبَنَاتِ خَالِكَ وَبَنَاتِ خَٰلَٰتِكَ ٱلَّٰتِي هَاجَرۡنَ مَعَكَ وَٱمۡرَأَةࣰ مُّؤۡمِنَةً إِن وَهَبَتۡ نَفۡسَهَا لِلنَّبِيِّ إِنۡ أَرَادَ ٱلنَّبِيُّ أَن يَسۡتَنكِحَهَا خَالِصَةࣰ لَّكَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۗ قَدۡ عَلِمۡنَا مَا فَرَضۡنَا عَلَيۡهِمۡ فِيٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ وَمَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ لِكَيۡلَا يَكُونَ عَلَيۡكَ حَرَجࣱۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورࣰا رَّحِيمࣰا [33:50]

Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún ọ àwọn ìyàwó rẹ̀, tí o fún ní owó-orí wọn, àti àwọn ẹrú nínú àwọn tí Allāhu fí ṣe ìkógun fún ọ àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin bàbá rẹ àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin bàbá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin ìyá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin ìyá rẹ, àwọn t’ó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ìlú Mọdīnah pẹ̀lú rẹ, àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ó bá fi ara rẹ̀ tọrẹ fún Ànábì, tí Ànábì náà sì fẹ́ fi ṣe ìyàwó. Ìwọ nìkan ni (èyí) wà fún, kò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin. A ti mọ ohun tí A ṣe ní ọ̀ran-anyàn fún wọn nípa àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ẹrú wọn. (Èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ó má baà sí láìfí fún ọ. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ohun tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ní ọ̀ran-anyàn lé àwa lórí nípa ìgbéyàwó àwa ọmọlẹ́yìn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìwọ̀nyí; ìkíní: Fífẹ́ onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pẹ̀lú àṣẹ àti ìyọ̀ǹda aláṣẹ rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:25. Ìkejì: Fífẹ́ obìnrin pẹ̀lú sọ̀daàkí. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:4. Ìkẹta: Òǹkà ìyàwó mùsùlùmí kò gbọdọ̀ tayọ mẹ́rin ní abẹ́ àkóṣo rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:3.

### الآية 33:51

> ۞ تُرۡجِي مَن تَشَآءُ مِنۡهُنَّ وَتُـٔۡوِيٓ إِلَيۡكَ مَن تَشَآءُۖ وَمَنِ ٱبۡتَغَيۡتَ مِمَّنۡ عَزَلۡتَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكَۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن تَقَرَّ أَعۡيُنُهُنَّ وَلَا يَحۡزَنَّ وَيَرۡضَيۡنَ بِمَآ ءَاتَيۡتَهُنَّ كُلُّهُنَّۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا فِي قُلُوبِكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَلِيمࣰا [33:51]

Lọ́ra láti súnmọ́ ẹni tí o bá fẹ́ nínú wọn. Fa ẹni tí o bá fẹ́ mọ́ra. Àti pé ẹni kẹ́ni tí o bá tún wá (láti súnmọ́) nínú àwọn tí o ò pín oorun fún, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ (láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ojú wọn tutù ìdùnnú. Wọn kò sì níí banújẹ́. Gbogbo wọn yó sì yọ́nú sí ohunkóhun tí o bá fún wọn. Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Aláfaradà.

Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan ni èyí wà fún. Mùsùlùmí tí ó ní ìyàwó méjì sí mẹ́rin gbọ́dọ̀ máa pín oorun fún ìkọ̀ọ̀kan àwọn ìyàwó rẹ̀. Kò sí gbọdọ̀ ṣàì pín oorun fún ọ̀kan nínú wọn. Ẹ wo sūrah an-Nisā’;4:129.

### الآية 33:52

> لَّا يَحِلُّ لَكَ ٱلنِّسَآءُ مِنۢ بَعۡدُ وَلَآ أَن تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجࣲ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ حُسۡنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءࣲ رَّقِيبࣰا [33:52]

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn tí A ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ (nìkan l’o lè kọ̀ sílẹ̀ nínú àwọn ìyàwó rẹ). Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

Āyah yìí kò ní kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) má ṣe fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní àsìkò tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀, ṣùgbọ́n āyah yìí kọ̀ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti yọ èyíkéyìí ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ipò ìyá àwọn onígbàgbọ́ òdodo nípasẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ àfi ìyàwó tí ó bá jẹ́ ẹrú ogun ní ìpìlẹ̀. Ìyá wa ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā) sọ pé: “Òjíṣẹ́ Allāhu kò tí ì kú títí Allāhu fi ṣe àwọn obìnrin ayé ní ẹ̀tọ́ fún un láti fẹ́.” Ìyẹn ni pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fẹ́ ìyàwó lọ́ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Kíyè sí i, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kọ ìyá wa Hafsọh ọmọ ‘Umar sílẹ̀, lẹ́yìn náà ó fẹ́ ẹ padà. Bákan náà, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbèrò láti kọ ìyá wa Saodah sílẹ̀. Èyí sì ni ó ṣokùnfà tí Saodah (rọdiyallāhu 'anhā) fi yọ̀ǹda ọjọ́ tirẹ̀ fún ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā). Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ āyah yìí. (at-Tọbariy). Nítorí náà, kí Ànábì fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ láì ní ẹnu àlà, láì sì gbọdọ̀ tìtorí èyí kọ ọ̀kan sílẹ̀, àfi ẹrú ogun, èyí tún jẹ́ n̄ǹkan ẹ̀ṣà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣà á lẹ́ṣà. Ìdí ni pé, òǹkà ìyàwó mùsùlùmí kò gbọdọ̀ tayọ mẹ́rin ní abẹ́ àkóṣo rẹ̀. Tí òǹkà ìyàwó Mùsùlùmí bá sì pé mẹ́rin, mùsùlùmí lè kọ ọ̀kan sílẹ̀ láti lè fi òmíràn jìrọ̀ rẹ̀, ìyẹn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ wo sūrah an-Nisā’;4:3 àti 20-21.

### الآية 33:53

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَدۡخُلُواْ بُيُوتَ ٱلنَّبِيِّ إِلَّآ أَن يُؤۡذَنَ لَكُمۡ إِلَىٰ طَعَامٍ غَيۡرَ نَٰظِرِينَ إِنَىٰهُ وَلَٰكِنۡ إِذَا دُعِيتُمۡ فَٱدۡخُلُواْ فَإِذَا طَعِمۡتُمۡ فَٱنتَشِرُواْ وَلَا مُسۡتَـٔۡنِسِينَ لِحَدِيثٍۚ إِنَّ ذَٰلِكُمۡ كَانَ يُؤۡذِي ٱلنَّبِيَّ فَيَسۡتَحۡيِۦ مِنكُمۡۖ وَٱللَّهُ لَا يَسۡتَحۡيِۦ مِنَ ٱلۡحَقِّۚ وَإِذَا سَأَلۡتُمُوهُنَّ مَتَٰعࣰا فَسۡـَٔلُوهُنَّ مِن وَرَآءِ حِجَابࣲۚ ذَٰلِكُمۡ أَطۡهَرُ لِقُلُوبِكُمۡ وَقُلُوبِهِنَّۚ وَمَا كَانَ لَكُمۡ أَن تُؤۡذُواْ رَسُولَ ٱللَّهِ وَلَآ أَن تَنكِحُوٓاْ أَزۡوَٰجَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦٓ أَبَدًاۚ إِنَّ ذَٰلِكُمۡ كَانَ عِندَ ٱللَّهِ عَظِيمًا [33:53]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn inú ilé Ànábì àfi tí wọ́n bá yọ̀ǹda fun yín láti wọlé jẹun láì níí jẹ́ ẹni tí yóò máa retí kí oúnjẹ jinná, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pè yín (fún oúnjẹ) ẹ wọ inú ilé nígbà náà. Nígbà tí ẹ bá sì jẹun tán, ẹ túká, ẹ má ṣe jókòó kalẹ̀ tira yin fún ọ̀rọ̀ kan mọ́ (nínú ilé rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn ń kó ìnira bá Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì ń tijú yín. Allāhu kò sì níí tijú níbi òdodo. Nígbà tí ẹ bá sì fẹ́ bèèrè n̄ǹkan ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó rẹ̀, ẹ bèèrè rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn ní ẹ̀yìn gàgá. Ìyẹn jẹ́ àfọ̀mọ́ jùlọ fún ọkàn yín àti ọkàn wọn. Kò tọ́ fun yín láti kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu. (Kò sì tọ́ fun yín) láti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ láéláé. Dájúdájú ìyẹn jẹ́ n̄ǹkan ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu.

### الآية 33:54

> إِن تُبۡدُواْ شَيۡـًٔا أَوۡ تُخۡفُوهُ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمࣰا [33:54]

Tí ẹ bá ṣàfi hàn kiní kan tàbí ẹ fi pamọ́, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 33:55

> لَّا جُنَاحَ عَلَيۡهِنَّ فِيٓ ءَابَآئِهِنَّ وَلَآ أَبۡنَآئِهِنَّ وَلَآ إِخۡوَٰنِهِنَّ وَلَآ أَبۡنَآءِ إِخۡوَٰنِهِنَّ وَلَآ أَبۡنَآءِ أَخَوَٰتِهِنَّ وَلَا نِسَآئِهِنَّ وَلَا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُنَّۗ وَٱتَّقِينَ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءࣲ شَهِيدًا [33:55]

Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ìyàwó Ànábì nípa àwọn bàbá wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn àti àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn àti àwọn ẹrúkùnrin wọn (láti wọlé tì wọ́n.) Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 33:56

> إِنَّ ٱللَّهَ وَمَلَٰٓئِكَتَهُۥ يُصَلُّونَ عَلَى ٱلنَّبِيِّۚ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ صَلُّواْ عَلَيۡهِ وَسَلِّمُواْ تَسۡلِيمًا [33:56]

Dájúdájú Allāhu àti àwọn mọlāika Rẹ̀ ń kẹ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tọrọ ìkẹ́ fún un, kí ẹ sì kí i ní kíkí àlàáfíà.

Níkété tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ āyah yìí kalẹ̀ ni àwọn Sọhābah (r.ahm) bèèrè ohun tí àwọn náà yóò fi máa tọrọ ìkẹ́ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì kọ́ wọn ní sọlātu ’Ibrọ̄hīmiyyah. Ẹ̀gbàwá kan nìyí: 
اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ اللَّهُمَّ بَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ كَمَا بَارَكْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ.
Allahummọ sọlli ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin kamọ̄ sọllaeta ‘alā āli ’Ibrọ̄hīmọ ’innaka Hamīdun Mọjīd. Allahummọ bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin kamọ̄ bārọkta ‘alā āli ’Ibrọ̄hīmọ ’innaka Hamīdun Mọjīd. (Bukọ̄riy àti Muslim)
Gbólóhùn wọ̀nyí tún tọ súnà; “sọlla-llāhu ‘aleehi wa sallam” tàbí “‘aleehi sọlātun wa salām.” Kíyè sí i, kò sí aburú níbi kí mùsùlùmí máa sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ kí ó sì fi gbólóhùn kan ní ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ tọrọ ìkẹ́ àti ọlà fún Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tí ì dáràn nítorí pé, àwọn Sọhābah náa (r.ahm) máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí àwọn àáfà sunnah ṣe ń ṣe asọlātu fún Ànábì nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣaájú nínú àwọn tírà wọn. Kò sí aburú nínú èyí rárá. Ṣùgbọ́n mùsùlùmí yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìhun asọlātu dáràn tí ó bá fi lè kó sínú ọ̀kan nínú àwọn n̄ǹkan mẹ́fà kan. Ìkíní: Lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí òfin àti àdìsọ́kàn ’Islām nínú àwọn gbólóhùn asọlātu náà. Ìkejì: Sísọ gbólóhùn asọlātu yẹn gan-angan di ìlànà tí wọn yóò máa pèpè sí, tí irúfẹ́ gbólóhùn náà yóò fi wá dà bí ẹni pé hadīth kan l’ó gbà á wá, tí kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ìkẹta: Ṣíṣe àgbékalẹ̀ òǹkà kan tàbí àsìkò kan tàbí ọjọ́ kan ní pàtó fún ṣíṣe irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà. Ìkẹrin: Ṣíṣe àgbékalẹ̀ ìlànà kan ní pàtó fún ṣíṣe irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà, bí kí wọ́n wí pé ẹnì kan kò gbọdọ̀ kà á àfi pẹ̀lú àlùwàlá. Ìkarùn-ún: Ṣíṣe àgbékalẹ̀ láádá fún irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà, tí èyí yó sì bí níní àdìsọ́kàn nípa àwọn láádá àgbélẹ̀rọ náà. Ìkẹfà: Kíka irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà kún ìmísí mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tàbí ṣíṣe àfitì irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà sí ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ti irọ́. Àwọn n̄ǹkan mẹ́fẹ̀ẹ̀fà wọ̀nyí l’ó ṣe àkóbá ńlá fún àwọn asọlātu àdáhun kan bíi sọlātul-fātih, sọlātu tunjīnā, sọlātul-gaebiyyah, sọlātu rọf‘il-’a‘mọ̄l, sọlātul-kamsah, jaoharatul-kamọ̄l, dalā’ilul-kaerāt, sọlawātul-kibrītu al-’ahmọr àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn onisūfi ni wọ́n ṣe àdádáálẹ̀ àwọn asọlātu aburú wọ̀nyẹn sínú ẹ̀sìn. Ìṣìnà àti òfò pọ́nńbélé sì ni gbogbo wọn.

### الآية 33:57

> إِنَّ ٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمۡ عَذَابࣰا مُّهِينࣰا [33:57]

Dájúdájú àwọn t’ó ń fi ìnira kan Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn nílé ayé àti ní ọ̀run. Ó sì ti pèsè ìyà t’ó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ dè wọ́n.

Ọ̀nà tí ẹ̀dá ń gbà fi ìnira kan Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìwọ̀nyí; àìgbàgbọ́ nínú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), ìṣẹbọ sí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn Rẹ̀, ṣíṣe àfitì ìyàwó àti ọmọ bíbí tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, pípa irọ́ mọ́ Ọn àti bíbú ìgbà, yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kíyè sí i, fífi ìnira kan Allāhu, Ọbá tí kò sí ìnira fún, kò ní ìtúmọ̀ kan tayọ pé ẹ̀dá ń wá ìnira ọ̀run fún ẹ̀mí ara rẹ̀.

### الآية 33:58

> وَٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ بِغَيۡرِ مَا ٱكۡتَسَبُواْ فَقَدِ ٱحۡتَمَلُواْ بُهۡتَٰنࣰا وَإِثۡمࣰا مُّبِينࣰا [33:58]

Àwọn t’ó ń fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin nípa n̄ǹkan tí wọn kò ṣe, dájúdájú wọ́n ti ru ẹrù (ọ̀ràn) ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.

### الآية 33:59

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّأَزۡوَٰجِكَ وَبَنَاتِكَ وَنِسَآءِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ يُدۡنِينَ عَلَيۡهِنَّ مِن جَلَٰبِيبِهِنَّۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن يُعۡرَفۡنَ فَلَا يُؤۡذَيۡنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورࣰا رَّحِيمࣰا [33:59]

Ìwọ Ànábì sọ fún àwọn ìyàwó rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti àwọn obìnrin onígbàgbọ́ òdodo pé kí wọ́n máa gbé àwọn aṣọ jilbāb wọn wọ̀ sí ara wọn bámúbámú. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti fi mọ̀ wọ́n (ní olùbẹ̀rù Allāhu). Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò níí fi ìnira kàn wọ́n. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 33:60

> ۞ لَّئِن لَّمۡ يَنتَهِ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضࣱ وَٱلۡمُرۡجِفُونَ فِي ٱلۡمَدِينَةِ لَنُغۡرِيَنَّكَ بِهِمۡ ثُمَّ لَا يُجَاوِرُونَكَ فِيهَآ إِلَّا قَلِيلࣰا [33:60]

Tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí, àti àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn túlétúlé nínú ìlú Mọdīnah kò bá jáwọ́ (níbi aburú), dájúdájú A máa dẹ ọ́ sí wọn, (o sì máa borí wọn). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí bá ọ gbé àdúgbò pọ̀ mọ́ àfi fún ìgbà díẹ̀.

### الآية 33:61

> مَّلۡعُونِينَۖ أَيۡنَمَا ثُقِفُوٓاْ أُخِذُواْ وَقُتِّلُواْ تَقۡتِيلࣰا [33:61]

Wọ́n di ẹni-ìṣẹ́bilé níbikíbi tí ọwọ́ bá ti bà wọ́n; wọ́n máa mú wọn, wọ́n sì máa pa wọ́n tààrà.

### الآية 33:62

> سُنَّةَ ٱللَّهِ فِي ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلُۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلࣰا [33:62]

(Ó jẹ́) ìṣe Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Allāhu.

Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hijr; 15:13

### الآية 33:63

> يَسۡـَٔلُكَ ٱلنَّاسُ عَنِ ٱلسَّاعَةِۖ قُلۡ إِنَّمَا عِلۡمُهَا عِندَ ٱللَّهِۚ وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّ ٱلسَّاعَةَ تَكُونُ قَرِيبًا [33:63]

Àwọn ènìyàn ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo ni ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà. Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́!”

### الآية 33:64

> إِنَّ ٱللَّهَ لَعَنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَأَعَدَّ لَهُمۡ سَعِيرًا [33:64]

Dájúdájú Allāhu ṣẹ́bi le àwọn aláìgbàgbọ́. Ó sì pèsè Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n.

### الآية 33:65

> خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدࣰاۖ لَّا يَجِدُونَ وَلِيࣰّا وَلَا نَصِيرࣰا [33:65]

Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé; wọn kò níí rí olùṣọ́ tàbí alárànṣe kan.

### الآية 33:66

> يَوۡمَ تُقَلَّبُ وُجُوهُهُمۡ فِي ٱلنَّارِ يَقُولُونَ يَٰلَيۡتَنَآ أَطَعۡنَا ٱللَّهَ وَأَطَعۡنَا ٱلرَّسُولَا۠ [33:66]

Ní ọjọ́ tí A óò yí ojú wọn padà nínú Iná, wọn yó sì wí pé: “Yéè! Àwa ìbá tẹ̀lé ti Allāhu, àwa ìbá sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́.”

### الآية 33:67

> وَقَالُواْ رَبَّنَآ إِنَّآ أَطَعۡنَا سَادَتَنَا وَكُبَرَآءَنَا فَأَضَلُّونَا ٱلسَّبِيلَا۠ [33:67]

Wọ́n wí pé: “Olúwa wa! Dájúdájú àwa tẹ̀lé àwọn aṣíwájú wa àti àwọn àgbààgbà wa. Wọ́n sì ṣì wá lọ́nà.

### الآية 33:68

> رَبَّنَآ ءَاتِهِمۡ ضِعۡفَيۡنِ مِنَ ٱلۡعَذَابِ وَٱلۡعَنۡهُمۡ لَعۡنࣰا كَبِيرࣰا [33:68]

Olúwa wa! Fún wọn ní ìlọ́po méjì nínú ìyà. Kí O sì ṣẹ́bi lé wọn ní ìṣẹ́bi t’ó tóbi.”

### الآية 33:69

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ ءَاذَوۡاْ مُوسَىٰ فَبَرَّأَهُ ٱللَّهُ مِمَّا قَالُواْۚ وَكَانَ عِندَ ٱللَّهِ وَجِيهࣰا [33:69]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó fi ìnira kan (Ànábì) Mūsā. Allāhu sì ṣàfọ̀mọ́ rẹ̀ nínú ohun tí wọ́n wí. Ó sì jẹ́ ẹni abiyì lọ́dọ̀ Allāhu.

### الآية 33:70

> يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَقُولُواْ قَوۡلࣰا سَدِيدࣰا [33:70]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì sọ ọ̀rọ̀ òdodo.

### الآية 33:71

> يُصۡلِحۡ لَكُمۡ أَعۡمَٰلَكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡ ذُنُوبَكُمۡۗ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَقَدۡ فَازَ فَوۡزًا عَظِيمًا [33:71]

(Allāhu) máa ṣàtúnṣe àwọn iṣẹ́ yín fun yín, Ó sì máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Àti pé ẹni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ó kúkú ti jèrè ní èrèǹjẹ ńlá.

### الآية 33:72

> إِنَّا عَرَضۡنَا ٱلۡأَمَانَةَ عَلَى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱلۡجِبَالِ فَأَبَيۡنَ أَن يَحۡمِلۡنَهَا وَأَشۡفَقۡنَ مِنۡهَا وَحَمَلَهَا ٱلۡإِنسَٰنُۖ إِنَّهُۥ كَانَ ظَلُومࣰا جَهُولࣰا [33:72]

Dájúdájú Àwa fi iṣẹ́ láádá lọ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àpáta. Wọ́n kọ̀ láti gbé e; wọ́n páyà rẹ̀. Ènìyàn sì gbé e. Dájúdájú (ènìyàn) jẹ́ alábòsí, aláìmọ̀kan.

Àgbàfipamọ́ ni ìtúmọ̀ “ ’amọ̄nah”. Èyí sì túmọ̀ sí ohun tí wọ́n gbé lé wa lọ́wọ́ fún ṣíṣọ́ àti àmójútó. Ohun tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gbé lé wa lọ́wọ́ tí a óò máa ṣọ́, tí a óò máa ṣe àmójútó rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀sìn Rẹ̀, ’Islām. Allāhu sì gbé ẹ̀sìn náà kalẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀san. Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá rí i ṣe gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe gbé e kalẹ̀, ó máa gba láádá lórí rẹ̀. Àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àpáta gbà láti máa ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu, àmọ́ wọ́n ní àwọn kò bùkátà sí láádá. Ènìyàn tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá tán, ó di wàhálà sí wọn lọ́rùn nítorí pé, wọn kò mọ̀ pé tí ṣíṣe n̄ǹkan bá la láádá lọ, àìṣe rẹ̀ máa la ìyà lọ. Ìbá ṣuwọ̀n fún ènìyàn àti àlùjànnú láti ṣe ẹ̀sìn láì retí láádà kan tayọ ìtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìkan ṣoṣo.

### الآية 33:73

> لِّيُعَذِّبَ ٱللَّهُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ وَٱلۡمُشۡرِكَٰتِ وَيَتُوبَ ٱللَّهُ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورࣰا رَّحِيمَۢا [33:73]

(Ènìyàn tẹ́rí gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá) nítorí kí Allāhu lè fi ìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn ọ̀sẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin àti nítorí kí Allāhu lè gba ìronúpìwàdà fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/index.php/surah/1/33.md)
- [كل تفاسير سورة الأحزاب
](https://quranpedia.net/index.php/surah-tafsir/33.md)
- [ترجمات سورة الأحزاب
](https://quranpedia.net/index.php/translations/33.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/index.php/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/index.php/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/index.php/surah/1/33/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
