---
title: "ترجمة سورة غافر - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/index.php/surah/1/40/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/index.php/surah/1/40/book/2001"
surah_id: "40"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة غافر - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/index.php/surah/1/40/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة غافر - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/index.php/surah/1/40/book/2001*.

Translation of Surah غافر from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 40:1

> حمٓ [40:1]

Hā mīm.

### الآية 40:2

> تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ [40:2]

Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀,

### الآية 40:3

> غَافِرِ ٱلذَّنۢبِ وَقَابِلِ ٱلتَّوۡبِ شَدِيدِ ٱلۡعِقَابِ ذِي ٱلطَّوۡلِۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ إِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ [40:3]

Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

### الآية 40:4

> مَا يُجَٰدِلُ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَا يَغۡرُرۡكَ تَقَلُّبُهُمۡ فِي ٱلۡبِلَٰدِ [40:4]

Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ.

### الآية 40:5

> كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحࣲ وَٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۖ وَهَمَّتۡ كُلُّ أُمَّةِۭ بِرَسُولِهِمۡ لِيَأۡخُذُوهُۖ وَجَٰدَلُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّ فَأَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ عِقَابِ [40:5]

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!

### الآية 40:6

> وَكَذَٰلِكَ حَقَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ [40:6]

Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná."

### الآية 40:7

> ٱلَّذِينَ يَحۡمِلُونَ ٱلۡعَرۡشَ وَمَنۡ حَوۡلَهُۥ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْۖ رَبَّنَا وَسِعۡتَ كُلَّ شَيۡءࣲ رَّحۡمَةࣰ وَعِلۡمࣰا فَٱغۡفِرۡ لِلَّذِينَ تَابُواْ وَٱتَّبَعُواْ سَبِيلَكَ وَقِهِمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ [40:7]

Àwọn t’ó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n gba Allāhu gbọ́. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): "Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.

### الآية 40:8

> رَبَّنَا وَأَدۡخِلۡهُمۡ جَنَّٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدتَّهُمۡ وَمَن صَلَحَ مِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَأَزۡوَٰجِهِمۡ وَذُرِّيَّٰتِهِمۡۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ [40:8]

Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni t’ó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 40:9

> وَقِهِمُ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ وَمَن تَقِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ يَوۡمَئِذࣲ فَقَدۡ رَحِمۡتَهُۥۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ [40:9]

Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá."

### الآية 40:10

> إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُنَادَوۡنَ لَمَقۡتُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُ مِن مَّقۡتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡ إِذۡ تُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلۡإِيمَٰنِ فَتَكۡفُرُونَ [40:10]

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): " Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́."

### الآية 40:11

> قَالُواْ رَبَّنَآ أَمَتَّنَا ٱثۡنَتَيۡنِ وَأَحۡيَيۡتَنَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَٱعۡتَرَفۡنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلۡ إِلَىٰ خُرُوجࣲ مِّن سَبِيلࣲ [40:11]

Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Nítorí náà, a sì jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?"

Àwọn kan lérò pé, ìtúmọ̀ āyah yìí ni pé, ènìyàn máa wáyé ní ẹ̀ẹ̀ méjì, ó sì máa kú ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, ènìyàn wà ní ipò òkú nígbà tí ó jẹ́ aláìsí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyẹn ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ìyẹn ni ikú àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa wà ní ipò alààyè nígbà tí ó bá délé ayé. Ìyẹn ni ìṣẹ̀mí àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa di aláìsí nígbà tí ó bá parí òǹkà àkókò tí Allāhu pèbùbù fún un láti lò nílé ayé. Ìyẹn sì ni ikú kejì. Lẹ́yìn náà, ó máa di alààyè ní ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí kú mọ́. Ìyẹn sì ni ìṣẹ̀mí kejì. Èyí ni ìtúmọ̀ āyah náà. Irú āyah yìí sì kúkú ti ṣíwájú nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:28.

### الآية 40:12

> ذَٰلِكُم بِأَنَّهُۥٓ إِذَا دُعِيَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُۥ كَفَرۡتُمۡ وَإِن يُشۡرَكۡ بِهِۦ تُؤۡمِنُواْۚ فَٱلۡحُكۡمُ لِلَّهِ ٱلۡعَلِيِّ ٱلۡكَبِيرِ [40:12]

(Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.

### الآية 40:13

> هُوَ ٱلَّذِي يُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ رِزۡقࣰاۚ وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ [40:13]

Òun ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àfi ẹni t’ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).

### الآية 40:14

> فَٱدۡعُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡكَٰفِرُونَ [40:14]

Nítorí náà, ẹ pe Allāhu ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀.

### الآية 40:15

> رَفِيعُ ٱلدَّرَجَٰتِ ذُو ٱلۡعَرۡشِ يُلۡقِي ٱلرُّوحَ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ لِيُنذِرَ يَوۡمَ ٱلتَّلَاقِ [40:15]

(Allāhu) Ẹni t’Ó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí (al-Ƙur’ān) ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.

### الآية 40:16

> يَوۡمَ هُم بَٰرِزُونَۖ لَا يَخۡفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِنۡهُمۡ شَيۡءࣱۚ لِّمَنِ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَۖ لِلَّهِ ٱلۡوَٰحِدِ ٱلۡقَهَّارِ [40:16]

Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní? Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni."

### الآية 40:17

> ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡۚ لَا ظُلۡمَ ٱلۡيَوۡمَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ [40:17]

Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

### الآية 40:18

> وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡأٓزِفَةِ إِذِ ٱلۡقُلُوبُ لَدَى ٱلۡحَنَاجِرِ كَٰظِمِينَۚ مَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ حَمِيمࣲ وَلَا شَفِيعࣲ يُطَاعُ [40:18]

Àti pé ṣèkìlọ̀ ọjọ́ tí ó súnmọ́ fún wọn. Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí.

### الآية 40:19

> يَعۡلَمُ خَآئِنَةَ ٱلۡأَعۡيُنِ وَمَا تُخۡفِي ٱلصُّدُورُ [40:19]

(Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́.

Ojú ìjàǹbá ni ojú t’ó ń yọ́ obìnrin wò. Ìyẹn ni pé, ìjàǹbá ni fún ọkùnrin kan láti máa yọ́ obìnrin olóbìnrin wò. Ohun tí ọkàn sì fi pamọ́ ni èrò-ọkàn ọkùnrin náà nípa obìnrin t’ó ń yọ́ wò àti ohun mìíràn t’ó wà nínú ọkàn rẹ̀.

### الآية 40:20

> وَٱللَّهُ يَقۡضِي بِٱلۡحَقِّۖ وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَقۡضُونَ بِشَيۡءٍۗ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ [40:20]

Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.

### الآية 40:21

> ۞ أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُواْ هُمۡ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةࣰ وَءَاثَارࣰا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقࣲ [40:21]

Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.

### الآية 40:22

> ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانَت تَّأۡتِيهِمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَكَفَرُواْ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ قَوِيࣱّ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ [40:22]

Ìyẹn nítorí pé àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà.

### الآية 40:23

> وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنࣲ مُّبِينٍ [40:23]

Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí t’ó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́

### الآية 40:24

> إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَقَٰرُونَ فَقَالُواْ سَٰحِرࣱ كَذَّابࣱ [40:24]

sí Fir‘aon, Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: "Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā)."

### الآية 40:25

> فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلۡحَقِّ مِنۡ عِندِنَا قَالُواْ ٱقۡتُلُوٓاْ أَبۡنَآءَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ وَٱسۡتَحۡيُواْ نِسَآءَهُمۡۚ وَمَا كَيۡدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلࣲ [40:25]

Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀." Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.

### الآية 40:26

> وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ذَرُونِيٓ أَقۡتُلۡ مُوسَىٰ وَلۡيَدۡعُ رَبَّهُۥٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمۡ أَوۡ أَن يُظۡهِرَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡفَسَادَ [40:26]

Fir‘aon wí pé: "Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀."

### الآية 40:27

> وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِنِّي عُذۡتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرࣲ لَّا يُؤۡمِنُ بِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ [40:27]

(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò gba Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́ gbọ́.

### الآية 40:28

> وَقَالَ رَجُلࣱ مُّؤۡمِنࣱ مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَكۡتُمُ إِيمَٰنَهُۥٓ أَتَقۡتُلُونَ رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّيَ ٱللَّهُ وَقَدۡ جَآءَكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ مِن رَّبِّكُمۡۖ وَإِن يَكُ كَٰذِبࣰا فَعَلَيۡهِ كَذِبُهُۥۖ وَإِن يَكُ صَادِقࣰا يُصِبۡكُم بَعۡضُ ٱلَّذِي يَعِدُكُمۡۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ مُسۡرِفࣱ كَذَّابࣱ [40:28]

Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan t’ó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: "Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, ‘Allāhu ni Olúwa mi.’ Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fun yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́.

### الآية 40:29

> يَٰقَوۡمِ لَكُمُ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَ ظَٰهِرِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَن يَنصُرُنَا مِنۢ بَأۡسِ ٱللَّهِ إِن جَآءَنَاۚ قَالَ فِرۡعَوۡنُ مَآ أُرِيكُمۡ إِلَّا مَآ أَرَىٰ وَمَآ أَهۡدِيكُمۡ إِلَّا سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ [40:29]

Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, ẹ̀yin sì ni alásẹ lórí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?" Fir‘aon wí pé: "Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà."

### الآية 40:30

> وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُم مِّثۡلَ يَوۡمِ ٱلۡأَحۡزَابِ [40:30]

Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà t’ó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín;

### الآية 40:31

> مِثۡلَ دَأۡبِ قَوۡمِ نُوحࣲ وَعَادࣲ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۚ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلۡمࣰا لِّلۡعِبَادِ [40:31]

Irú ìṣe (ìparun t’ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn t’ó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà.

### الآية 40:32

> وَيَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ يَوۡمَ ٱلتَّنَادِ [40:32]

Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fun yín.

Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde ni Ọjọ́ ìpè. Ìyẹn ni pé, ọjọ́ tí àwọn mọlāika máa pe àwọn ènìyàn àti àlùjànnú láti sọ fún wọn pé, tí ẹ bá lè sá lọ báyìí, ẹ sá lọ wò. Éyí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:33. Bákan náà, ìpè máa wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sí ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Iná. Èyí wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:44. Ìpè tún máa wá láti ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Iná sí ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Èyí tún wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:50.

### الآية 40:33

> يَوۡمَ تُوَلُّونَ مُدۡبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنۡ عَاصِمࣲۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادࣲ [40:33]

Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fun yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.

### الآية 40:34

> وَلَقَدۡ جَآءَكُمۡ يُوسُفُ مِن قَبۡلُ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا زِلۡتُمۡ فِي شَكࣲّ مِّمَّا جَآءَكُم بِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا هَلَكَ قُلۡتُمۡ لَن يَبۡعَثَ ٱللَّهُ مِنۢ بَعۡدِهِۦ رَسُولࣰاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَنۡ هُوَ مُسۡرِفࣱ مُّرۡتَابٌ [40:34]

Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ t’ó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: "Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù.

### الآية 40:35

> ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡۖ كَبُرَ مَقۡتًا عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلۡبِ مُتَكَبِّرࣲ جَبَّارࣲ [40:35]

Àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.”

### الآية 40:36

> وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَٰهَٰمَٰنُ ٱبۡنِ لِي صَرۡحࣰا لَّعَلِّيٓ أَبۡلُغُ ٱلۡأَسۡبَٰبَ [40:36]

Fir‘aon wí pé: "Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà.

### الآية 40:37

> أَسۡبَٰبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ كَٰذِبࣰاۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَصُدَّ عَنِ ٱلسَّبِيلِۚ وَمَا كَيۡدُ فِرۡعَوۡنَ إِلَّا فِي تَبَابࣲ [40:37]

Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́." Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.

### الآية 40:38

> وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُونِ أَهۡدِكُمۡ سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ [40:38]

Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.

### الآية 40:39

> يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا مَتَٰعࣱ وَإِنَّ ٱلۡأٓخِرَةَ هِيَ دَارُ ٱلۡقَرَارِ [40:39]

Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí jẹ́ ìgbádùn lásán. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére.

### الآية 40:40

> مَنۡ عَمِلَ سَيِّئَةࣰ فَلَا يُجۡزَىٰٓ إِلَّا مِثۡلَهَاۖ وَمَنۡ عَمِلَ صَٰلِحࣰا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنࣱ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ يُرۡزَقُونَ فِيهَا بِغَيۡرِ حِسَابࣲ [40:40]

Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè àrísìkí fún wọn nínú rẹ̀ láì la ìṣírò lọ.

### الآية 40:41

> ۞ وَيَٰقَوۡمِ مَا لِيٓ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلنَّجَوٰةِ وَتَدۡعُونَنِيٓ إِلَى ٱلنَّارِ [40:41]

Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná?

### الآية 40:42

> تَدۡعُونَنِي لِأَكۡفُرَ بِٱللَّهِ وَأُشۡرِكَ بِهِۦ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمࣱ وَأَنَا۠ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡغَفَّٰرِ [40:42]

Ẹ̀ ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un. Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn.

Sísọ n̄ǹkan tí ẹ̀dá kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) túmọ̀ sí pé sísọ n̄ǹkan tí Allāhu kò fi mọ ẹ̀dá gẹ́gẹ́ bí akẹgbẹ́ Rẹ̀ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).

### الآية 40:43

> لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِ لَيۡسَ لَهُۥ دَعۡوَةࣱ فِي ٱلدُّنۡيَا وَلَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَآ إِلَى ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ [40:43]

Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-àlà, àwọn ni èrò inú Iná.

### الآية 40:44

> فَسَتَذۡكُرُونَ مَآ أَقُولُ لَكُمۡۚ وَأُفَوِّضُ أَمۡرِيٓ إِلَى ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ [40:44]

Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fun yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn."

### الآية 40:45

> فَوَقَىٰهُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِ مَا مَكَرُواْۖ وَحَاقَ بِـَٔالِ فِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ ٱلۡعَذَابِ [40:45]

Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po.

### الآية 40:46

> ٱلنَّارُ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا غُدُوࣰّا وَعَشِيࣰّاۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ أَدۡخِلُوٓاْ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ أَشَدَّ ٱلۡعَذَابِ [40:46]

Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): "Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná t’ó le jùlọ."

### الآية 40:47

> وَإِذۡ يَتَحَآجُّونَ فِي ٱلنَّارِ فَيَقُولُ ٱلضُّعَفَٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعࣰا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا نَصِيبࣰا مِّنَ ٱلنَّارِ [40:47]

(Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?”

### الآية 40:48

> قَالَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُلࣱّ فِيهَآ إِنَّ ٱللَّهَ قَدۡ حَكَمَ بَيۡنَ ٱلۡعِبَادِ [40:48]

Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: "Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀.” Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà."

### الآية 40:49

> وَقَالَ ٱلَّذِينَ فِي ٱلنَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ٱدۡعُواْ رَبَّكُمۡ يُخَفِّفۡ عَنَّا يَوۡمࣰا مِّنَ ٱلۡعَذَابِ [40:49]

Àwọn t’ó wà nínú Iná tún wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: "Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan."

### الآية 40:50

> قَالُوٓاْ أَوَلَمۡ تَكُ تَأۡتِيكُمۡ رُسُلُكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ قَالُواْ بَلَىٰۚ قَالُواْ فَٱدۡعُواْۗ وَمَا دُعَٰٓؤُاْ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٍ [40:50]

Wọ́n yóò sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín bí?" Wọ́n wí pé: “Rárá, (wọ́n ń mú un wá).” Wọ́n sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.

Nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:186, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi kalmọh “rọṣād” parí àdúà àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ìyẹn, “la‘llahum yẹrṣudūn”) àmọ́ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:14 àti sūrah yìí, Ó fi kalmọh “dọlāl” parí àdúà àwọn aláìgbàgbọ́. “Rọṣād” túmọ̀ sí “ìmọ̀nà”, “dọlāl” sì túmọ̀ sí “ìṣìnà”. Àdúà t’ó wà lórí ìmọ̀nà ni àdúà t’ó máa lọ tààrà =
= sọ́dọ̀ Allāhu. Àdúà náà sì máa jẹ́ àtẹ́wọ́gbà. Èyí ni Allāhu fi rinlẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:26. Àmọ́ àdúà t’ó wà lórí ìṣìnà, kò níí lọ sọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó ń gba àdúà lẹ́yìn Allāhu. Ìdí nìyí tí àdúà náà fi máa gúnlẹ̀ sí èbúté-anù àti òfò. Wàyí, ọ̀nà wo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń gbà rí oore láyé? Kò sí oore ayé kan tí ó lè tẹ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ bí kò ṣe ìpín rẹ̀ nínú kádàrá. Àmọ́ ní ti onígbàgbọ́ òdodo, oore inú kádàrá àti oore àdúà l’ó wà fún un níwọ̀n ìgbà tí àdúà rẹ̀ bá ti bá sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mu.

### الآية 40:51

> إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَيَوۡمَ يَقُومُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ [40:51]

Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde).

### الآية 40:52

> يَوۡمَ لَا يَنفَعُ ٱلظَّٰلِمِينَ مَعۡذِرَتُهُمۡۖ وَلَهُمُ ٱللَّعۡنَةُ وَلَهُمۡ سُوٓءُ ٱلدَّارِ [40:52]

Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn.

### الآية 40:53

> وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡهُدَىٰ وَأَوۡرَثۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ [40:53]

Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

### الآية 40:54

> هُدࣰى وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ [40:54]

(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.

### الآية 40:55

> فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقࣱّ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ [40:55]

Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.

Irú gbólóhùn yìí tún wà nínú sūrah Muhammad; 47:19. Ẹ̀̀ṣẹ̀ wo ni Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dá? Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kì í ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn tàbí olùyapa àṣẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Àmọ́ nítorí pé kì í ṣe mọlāika, kì í sì ṣe ọlọ́hun, ó ṣeé ṣe kí ó ṣe ìṣe kan tí Allāhu máa pè ní ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Irúfẹ́ àwọn ìṣe náà kò tàbùkù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì yọ ọ́ kúrò nípò àwòkọ́ṣe rere fún gbogbo ẹ̀da. 
Allāhu kì í kúkú ṣe Ọba alábòsí, Ó ṣàfi hàn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dá. 
Àṣìṣe kìíní t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Títú tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú àwọn ẹrú ogun Badr sílẹ̀ dípò pípa wọ́n, ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn nítorí pé, àwọn tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú sílẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rò t’ó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé, àwùjọ mùsùlùmí bùkátà sí owó àti ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrú kan nínú àwọn ẹrú ogun náà, nígbà tí àwọn ẹrú mìíràn rí ìtúsílẹ̀ gbà nípasẹ̀ kíkọ́ àwọn Sọhābah kan ní ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ní òdodo ni pé, ìgbésẹ̀ yìí dára. Àmọ́ Allāhu kà á kún àṣìṣe. Ó sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé pípa wọn lásìkò náà l’ó lóore ju ìtúsílẹ̀ wọn lọ nítorí pé, àìpa wọ́n l’ó padà bí àwọn ogun mìíràn. Ńṣe ni àwọn ọ̀ṣẹbọ náà lọ túnra mú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ogun mìíràn dìde. Wọn ìbá ti pa wọ́n nígbà àkọ́kọ́, ogun ìbá ti dáwọ́ dúró. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:67-71. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì padà yọ̀ǹda ìtúsílẹ̀ ẹrú ogún pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ tàbí ní ọ̀fẹ́ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú sūrah Muhammad; 47:4.
Àṣìṣe kejì t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Àìtètè gbà kí Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu) kọ Zaenab ọmọ Jahṣ (rọdiyallāhu 'anhā) sílẹ̀ lẹ́yìn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé Zaed ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí kò bùkátà sí i mọ́. Ohun tí ó sì mú kí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kóra ró ni pé, ó ń páyà pé àwọn aláìsàn-ọkàn yóò máa sọ pé, ‘Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, ó sì fi ṣaya!’. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu) kì í ṣe ọmọbíbí inú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àti pé kò sí èèwọ̀ nínú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fẹ́ Zaenab ọmọ Jahṣ lẹ́yìn tí Allāhu ti pa á láṣẹ fún un láti fi ṣaya. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Ahzāb; 33:37-38. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ṣẹ́rí padà síbi ohun tí Allāhu yàn fún un. 
Àṣìṣe kẹta t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Sísọ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ fún ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ pé òun kò níí fi ẹrúbìnrin rẹ̀ kan ṣaya. Sísọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣìṣe fún un nítorí pé, ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un ni òun fẹ́ ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ láti fi wá ìyọ́nú ìyàwó rẹ̀ kan. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Tahrīm; 66:1.
Àṣìṣe kẹ́rin t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Fífajúro tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fajú ro sí afọ́jú kan tí Allāhu ti ṣípayá ọkàn rẹ̀ fún gbígba ’Islām. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wà pẹ̀lú ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, tí ó ń ṣe wáàsí fún lọ́wọ́ nígbà tí afọ́jú yìí ń sáré bọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ti kó ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ léyà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi fẹ́ kí afọ́jú t’ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé di òun lọ́wọ́. Ṣíṣẹ bẹ́ẹ̀ l’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi ìdí èyí náà múlẹ̀ nínú sūrah ‘Abas; 80:1-11. 
Ìwọ̀nyẹn ni àwọn àṣìṣe t’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ́rùn. Kì í ṣe pé Ànábì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn. Tòhun tí bí ó ṣe mọ yìí, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò yé tọrọ àforíjìn lórí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kódà Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè má tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí ìwọ̀nyẹn nígbà ọgọ́rùn-ún lójúmọ́. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó yẹ kí èyí kọ́ èmi àti ẹ̀yin ni pé, a ò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu, Aláforíjìn. Kò sí ohun t’ó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa, irú èyí tí Allāhu ṣe fún Ànábì wa Muhammad yìí (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí Allāhu sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún gbogbo ayé nínú sūrah al-Fath; 48:1-2. 
Ìyẹn ni abala èyí t’ó jẹmọ́ àṣìṣe Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́yìn tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣẹrh; 94:3 fún abala kejì, èyí t’ó jẹmọ́ àṣìṣe rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam).

### الآية 40:56

> إِنَّ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡ إِن فِي صُدُورِهِمۡ إِلَّا كِبۡرࣱ مَّا هُم بِبَٰلِغِيهِۚ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ [40:56]

Dájúdájú àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.

### الآية 40:57

> لَخَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَكۡبَرُ مِنۡ خَلۡقِ ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ [40:57]

Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀.

### الآية 40:58

> وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَلَا ٱلۡمُسِيٓءُۚ قَلِيلࣰا مَّا تَتَذَكَّرُونَ [40:58]

Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

### الآية 40:59

> إِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةࣱ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ [40:59]

Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́.

### الآية 40:60

> وَقَالَ رَبُّكُمُ ٱدۡعُونِيٓ أَسۡتَجِبۡ لَكُمۡۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِي سَيَدۡخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ [40:60]

Olúwa yín sọ pé: "Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ."

### الآية 40:61

> ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ [40:61]

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un).

### الآية 40:62

> ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءࣲ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ [40:62]

Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

### الآية 40:63

> كَذَٰلِكَ يُؤۡفَكُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ [40:63]

Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn t’ó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn).

### الآية 40:64

> ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ قَرَارࣰا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءࣰ وَصَوَّرَكُمۡ فَأَحۡسَنَ صُوَرَكُمۡ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡۖ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ [40:64]

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ibùgbé. Ó mọ sánmọ̀ (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 40:65

> هُوَ ٱلۡحَيُّ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱدۡعُوهُ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَۗ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ [40:65]

Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 40:66

> ۞ قُلۡ إِنِّي نُهِيتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَمَّا جَآءَنِيَ ٱلۡبَيِّنَٰتُ مِن رَّبِّي وَأُمِرۡتُ أَنۡ أُسۡلِمَ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ [40:66]

Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 40:67

> هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابࣲ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةࣲ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةࣲ ثُمَّ يُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلࣰا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡ ثُمَّ لِتَكُونُواْ شُيُوخࣰاۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبۡلُۖ وَلِتَبۡلُغُوٓاْ أَجَلࣰا مُّسَمࣰّى وَلَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ [40:67]

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

### الآية 40:68

> هُوَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ فَإِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرࣰا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ [40:68]

Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

### الآية 40:69

> أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ أَنَّىٰ يُصۡرَفُونَ [40:69]

Ṣé o ò rí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!

### الآية 40:70

> ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِٱلۡكِتَٰبِ وَبِمَآ أَرۡسَلۡنَا بِهِۦ رُسُلَنَاۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ [40:70]

Àwọn t’ó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa nírọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

### الآية 40:71

> إِذِ ٱلۡأَغۡلَٰلُ فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ وَٱلسَّلَٰسِلُ يُسۡحَبُونَ [40:71]

Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn

### الآية 40:72

> فِي ٱلۡحَمِيمِ ثُمَّ فِي ٱلنَّارِ يُسۡجَرُونَ [40:72]

sínú omi gbígbóná. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná.

### الآية 40:73

> ثُمَّ قِيلَ لَهُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تُشۡرِكُونَ [40:73]

Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa sọ fún wọn pé: "Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà?"

### الآية 40:74

> مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا بَل لَّمۡ نَكُن نَّدۡعُواْ مِن قَبۡلُ شَيۡـࣰٔاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلۡكَٰفِرِينَ [40:74]

"(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?" Wọ́n á wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.

### الآية 40:75

> ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمۡ تَفۡرَحُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَمۡرَحُونَ [40:75]

Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́).

### الآية 40:76

> ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ [40:76]

Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga.

### الآية 40:77

> فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقࣱّۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ [40:77]

Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.

### الآية 40:78

> وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلࣰا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ فَإِذَا جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قُضِيَ بِٱلۡحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ [40:78]

Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A ò sì sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.

Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Ra‘d; 13:38 lórí ìtúmọ̀ “àmì”.

### الآية 40:79

> ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمَ لِتَرۡكَبُواْ مِنۡهَا وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ [40:79]

Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fun yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.

### الآية 40:80

> وَلَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَلِتَبۡلُغُواْ عَلَيۡهَا حَاجَةࣰ فِي صُدُورِكُمۡ وَعَلَيۡهَا وَعَلَى ٱلۡفُلۡكِ تُحۡمَلُونَ [40:80]

Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fun yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn t’ó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ ó sì máa fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.

### الآية 40:81

> وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ فَأَيَّ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُنكِرُونَ [40:81]

(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò?

### الآية 40:82

> أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِنۡهُمۡ وَأَشَدَّ قُوَّةࣰ وَءَاثَارࣰا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ [40:82]

Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

### الآية 40:83

> فَلَمَّا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرِحُواْ بِمَا عِندَهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ [40:83]

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun t’ó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po.

### الآية 40:84

> فَلَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥ وَكَفَرۡنَا بِمَا كُنَّا بِهِۦ مُشۡرِكِينَ [40:84]

Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un."

### الآية 40:85

> فَلَمۡ يَكُ يَنفَعُهُمۡ إِيمَٰنُهُمۡ لَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَاۖ سُنَّتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ فِي عِبَادِهِۦۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡكَٰفِرُونَ [40:85]

Ìgbàgbọ́ wọn kò ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/index.php/surah/1/40.md)
- [كل تفاسير سورة غافر
](https://quranpedia.net/index.php/surah-tafsir/40.md)
- [ترجمات سورة غافر
](https://quranpedia.net/index.php/translations/40.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/index.php/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/index.php/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/index.php/surah/1/40/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
