---
title: "ترجمة سورة التكوير - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/81/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/81/book/2001"
surah_id: "81"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة التكوير - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/81/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة التكوير - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/81/book/2001*.

Translation of Surah التكوير from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 81:1

> إِذَا ٱلشَّمۡسُ كُوِّرَتۡ [81:1]

Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,

### الآية 81:2

> وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتۡ [81:2]

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

### الآية 81:3

> وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ سُيِّرَتۡ [81:3]

àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),

### الآية 81:4

> وَإِذَا ٱلۡعِشَارُ عُطِّلَتۡ [81:4]

àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,

### الآية 81:5

> وَإِذَا ٱلۡوُحُوشُ حُشِرَتۡ [81:5]

àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,

### الآية 81:6

> وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ سُجِّرَتۡ [81:6]

àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,

### الآية 81:7

> وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتۡ [81:7]

àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

### الآية 81:8

> وَإِذَا ٱلۡمَوۡءُۥدَةُ سُئِلَتۡ [81:8]

àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

### الآية 81:9

> بِأَيِّ ذَنۢبࣲ قُتِلَتۡ [81:9]

ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,

### الآية 81:10

> وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتۡ [81:10]

àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,

### الآية 81:11

> وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتۡ [81:11]

àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,

### الآية 81:12

> وَإِذَا ٱلۡجَحِيمُ سُعِّرَتۡ [81:12]

àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,

### الآية 81:13

> وَإِذَا ٱلۡجَنَّةُ أُزۡلِفَتۡ [81:13]

àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),

### الآية 81:14

> عَلِمَتۡ نَفۡسࣱ مَّآ أَحۡضَرَتۡ [81:14]

(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).

### الآية 81:15

> فَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلۡخُنَّسِ [81:15]

Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán,

### الآية 81:16

> ٱلۡجَوَارِ ٱلۡكُنَّسِ [81:16]

(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.

### الآية 81:17

> وَٱلَّيۡلِ إِذَا عَسۡعَسَ [81:17]

Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ.

### الآية 81:18

> وَٱلصُّبۡحِ إِذَا تَنَفَّسَ [81:18]

Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀.

### الآية 81:19

> إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولࣲ كَرِيمࣲ [81:19]

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,

Wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hāƙƙọh; 69:40.

### الآية 81:20

> ذِي قُوَّةٍ عِندَ ذِي ٱلۡعَرۡشِ مَكِينࣲ [81:20]

alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,

### الآية 81:21

> مُّطَاعࣲ ثَمَّ أَمِينࣲ [81:21]

ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.

### الآية 81:22

> وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجۡنُونࣲ [81:22]

Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè.

### الآية 81:23

> وَلَقَدۡ رَءَاهُ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡمُبِينِ [81:23]

Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.

Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Najm; 53:13.

### الآية 81:24

> وَمَا هُوَ عَلَى ٱلۡغَيۡبِ بِضَنِينࣲ [81:24]

Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).

### الآية 81:25

> وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَيۡطَٰنࣲ رَّجِيمࣲ [81:25]

Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.

### الآية 81:26

> فَأَيۡنَ تَذۡهَبُونَ [81:26]

Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?

### الآية 81:27

> إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرࣱ لِّلۡعَٰلَمِينَ [81:27]

Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 81:28

> لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَسۡتَقِيمَ [81:28]

(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.

### الآية 81:29

> وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ [81:29]

Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/81.md)
- [كل تفاسير سورة التكوير
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/81.md)
- [ترجمات سورة التكوير
](https://quranpedia.net/translations/81.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/81/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
