---
title: "ترجمة سورة هود - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/11/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/11/book/2001"
surah_id: "11"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة هود - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/11/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة هود - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/11/book/2001*.

Translation of Surah هود from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 11:1

> الر ۚ كِتَابٌ أُحْكِمَتْ آيَاتُهُ ثُمَّ فُصِّلَتْ مِنْ لَدُنْ حَكِيمٍ خَبِيرٍ [11:1]

’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.

### الآية 11:2

> ﻿أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ ۚ إِنَّنِي لَكُمْ مِنْهُ نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ [11:2]

(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú emi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

### الآية 11:3

> ﻿وَأَنِ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ يُمَتِّعْكُمْ مَتَاعًا حَسَنًا إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى وَيُؤْتِ كُلَّ ذِي فَضْلٍ فَضْلَهُ ۖ وَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ كَبِيرٍ [11:3]

(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé kí ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó máa fun yín ní ìgbádùn dáadáa títí di gbèdéke àkókò kan. Ó máa fún oníṣẹ́-àṣegbọrẹ ní ẹ̀san iṣẹ́ àṣegbọrẹ rẹ̀. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá fun yín.

### الآية 11:4

> ﻿إِلَى اللَّهِ مَرْجِعُكُمْ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ [11:4]

Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí yín. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 11:5

> ﻿أَلَا إِنَّهُمْ يَثْنُونَ صُدُورَهُمْ لِيَسْتَخْفُوا مِنْهُ ۚ أَلَا حِينَ يَسْتَغْشُونَ ثِيَابَهُمْ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ [11:5]

Gbọ́, dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bo ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà wọn láti lè fara pamọ́ fún Allāhu. Kíyè sí i, nígbà tí wọ́n ń yíṣọ wọn bora, Allāhu mọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi pamọ́ àti n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

### الآية 11:6

> ﻿۞ وَمَا مِنْ دَابَّةٍ فِي الْأَرْضِ إِلَّا عَلَى اللَّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا ۚ كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُبِينٍ [11:6]

Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan t’ó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú.

### الآية 11:7

> ﻿وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ وَكَانَ عَرْشُهُ عَلَى الْمَاءِ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۗ وَلَئِنْ قُلْتَ إِنَّكُمْ مَبْعُوثُونَ مِنْ بَعْدِ الْمَوْتِ لَيَقُولَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ [11:7]

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) – nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín l’ó dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

### الآية 11:8

> ﻿وَلَئِنْ أَخَّرْنَا عَنْهُمُ الْعَذَابَ إِلَىٰ أُمَّةٍ مَعْدُودَةٍ لَيَقُولُنَّ مَا يَحْبِسُهُ ۗ أَلَا يَوْمَ يَأْتِيهِمْ لَيْسَ مَصْرُوفًا عَنْهُمْ وَحَاقَ بِهِمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ [11:8]

Dájúdájú tí A bá sún ìyà ṣíwájú fún wọn di ìgbà t’ó ní òǹkà, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Kí l’ó ń dá a dúró ná?” Gbọ́, ní ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, kò níí ṣe é gbé kúrò fún wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po.

### الآية 11:9

> ﻿وَلَئِنْ أَذَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنَّا رَحْمَةً ثُمَّ نَزَعْنَاهَا مِنْهُ إِنَّهُ لَيَئُوسٌ كَفُورٌ [11:9]

Àti pé dájúdájú tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò láti ọ̀dọ̀ Wa, lẹ́yìn náà, tí A bá gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, dájúdájú ó máa di olùsọ̀rètínù, aláìmoore.

### الآية 11:10

> ﻿وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ نَعْمَاءَ بَعْدَ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ السَّيِّئَاتُ عَنِّي ۚ إِنَّهُ لَفَرِحٌ فَخُورٌ [11:10]

Dájúdájú tí A bá sì fún un ní ìdẹ̀ra tọ́wò lẹ́yìn ìnira t’ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Àwọn aburú ti kúrò lọ́dọ̀ mi.” Dájúdájú ó máa di aláyọ̀pọ̀rọ́, onífáàrí.

### الآية 11:11

> ﻿إِلَّا الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَٰئِكَ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ [11:11]

Àyàfi àwọn t’ó bá ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn, ti wọn ni àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi.

### الآية 11:12

> ﻿فَلَعَلَّكَ تَارِكٌ بَعْضَ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ وَضَائِقٌ بِهِ صَدْرُكَ أَنْ يَقُولُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ كَنْزٌ أَوْ جَاءَ مَعَهُ مَلَكٌ ۚ إِنَّمَا أَنْتَ نَذِيرٌ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ [11:12]

Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?” Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 11:13

> ﻿أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ فَأْتُوا بِعَشْرِ سُوَرٍ مِثْلِهِ مُفْتَرَيَاتٍ وَادْعُوا مَنِ اسْتَطَعْتُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ [11:13]

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

### الآية 11:14

> ﻿فَإِلَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّمَا أُنْزِلَ بِعِلْمِ اللَّهِ وَأَنْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ مُسْلِمُونَ [11:14]

Nígbà náà tí wọn kò bá da yín lóhùn, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Allāhu. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin yóò di mùsùlùmí?

### الآية 11:15

> ﻿مَنْ كَانَ يُرِيدُ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيْهِمْ أَعْمَالَهُمْ فِيهَا وَهُمْ فِيهَا لَا يُبْخَسُونَ [11:15]

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé.

### الآية 11:16

> ﻿أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَيْسَ لَهُمْ فِي الْآخِرَةِ إِلَّا النَّارُ ۖ وَحَبِطَ مَا صَنَعُوا فِيهَا وَبَاطِلٌ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [11:16]

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 11:17

> ﻿أَفَمَنْ كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّهِ وَيَتْلُوهُ شَاهِدٌ مِنْهُ وَمِنْ قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ أُولَٰئِكَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۚ وَمَنْ يَكْفُرْ بِهِ مِنَ الْأَحْزَابِ فَالنَّارُ مَوْعِدُهُ ۚ فَلَا تَكُ فِي مِرْيَةٍ مِنْهُ ۚ إِنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ [11:17]

Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì s.a.w.), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur’ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasara, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur’ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́.

### الآية 11:18

> ﻿وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا ۚ أُولَٰئِكَ يُعْرَضُونَ عَلَىٰ رَبِّهِمْ وَيَقُولُ الْأَشْهَادُ هَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ كَذَبُوا عَلَىٰ رَبِّهِمْ ۚ أَلَا لَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الظَّالِمِينَ [11:18]

Àti pé ta ni ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu? Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n yóò kó wá síwájú Olúwa wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí (ìyẹn, àwọn mọlāika) yó sì máa sọ pé: "Àwọn wọ̀nyí ni àwọn t’ó parọ́ mọ́ Olúwa wọn." Gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí,

### الآية 11:19

> ﻿الَّذِينَ يَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا وَهُمْ بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ [11:19]

àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

### الآية 11:20

> ﻿أُولَٰئِكَ لَمْ يَكُونُوا مُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ وَمَا كَانَ لَهُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ أَوْلِيَاءَ ۘ يُضَاعَفُ لَهُمُ الْعَذَابُ ۚ مَا كَانُوا يَسْتَطِيعُونَ السَّمْعَ وَمَا كَانُوا يُبْصِرُونَ [11:20]

Àwọn wọ̀nyẹn kò lè mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀ àti pé kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. A ó sì ṣe àdìpèlé ìyà fún wọn. Wọn kò lè gbọ́. Àti pé wọn kì í ríran (rí òdodo).

### الآية 11:21

> ﻿أُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ [11:21]

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́.

### الآية 11:22

> ﻿لَا جَرَمَ أَنَّهُمْ فِي الْآخِرَةِ هُمُ الْأَخْسَرُونَ [11:22]

Ní ti òdodo, dájúdájú àwọn gan-an ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

### الآية 11:23

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَأَخْبَتُوا إِلَىٰ رَبِّهِمْ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ [11:23]

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sì dúnní mọ́ ìronúpìwàdà sọ́dọ̀ Olúwa wọn, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

### الآية 11:24

> ﻿۞ مَثَلُ الْفَرِيقَيْنِ كَالْأَعْمَىٰ وَالْأَصَمِّ وَالْبَصِيرِ وَالسَّمِيعِ ۚ هَلْ يَسْتَوِيَانِ مَثَلًا ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ [11:24]

Àfiwé ìjọ méjèèjì dà bí afọ́jú àti adití pẹ̀lú olùríran àti olùgbọ́rọ̀. Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì dọ́gba ní àfiwé bí? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

### الآية 11:25

> ﻿وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ إِنِّي لَكُمْ نَذِيرٌ مُبِينٌ [11:25]

A sì kúkú ti rán (Ànábì) Nūh sí ìjọ rẹ̀ (láti sọ pé) dájúdájú olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni mo jẹ́ fun yín.

### الآية 11:26

> ﻿أَنْ لَا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ ۖ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ أَلِيمٍ [11:26]

(Mò ń kìlọ̀) pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ẹlẹ́ta-eléro fun yín.

### الآية 11:27

> ﻿فَقَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ قَوْمِهِ مَا نَرَاكَ إِلَّا بَشَرًا مِثْلَنَا وَمَا نَرَاكَ اتَّبَعَكَ إِلَّا الَّذِينَ هُمْ أَرَاذِلُنَا بَادِيَ الرَّأْيِ وَمَا نَرَىٰ لَكُمْ عَلَيْنَا مِنْ فَضْلٍ بَلْ نَظُنُّكُمْ كَاذِبِينَ [11:27]

Àwọn aṣíwájú t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ sì wí pé: "Àwa kò mọ̀ ọ́ sí ẹnì kan tayọ abara bí irú wa. Àwa kò sì mọ àwọn t’ó tẹ̀lé ọ sí ẹnì kan kan tayọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ nínú wa, ọlọ́pọlọ bín-íntín. Àti pé àwa kò ri yín sí ẹni t’ó fi ọ̀nà kan kan ní àjùlọ lórí wa, ṣùgbọ́n a kà yín kún òpùrọ́."

### الآية 11:28

> ﻿قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كُنْتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَآتَانِي رَحْمَةً مِنْ عِنْدِهِ فَعُمِّيَتْ عَلَيْكُمْ أَنُلْزِمُكُمُوهَا وَأَنْتُمْ لَهَا كَارِهُونَ [11:28]

(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí mo bá wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí Ó sì fún mi ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọn kò sí jẹ́ kí ẹ ríran rí (òdodo náà), ǹjẹ́ a óò fi dandan mu yín bí, nígbà tí ẹ̀mí yín kọ̀ ọ́?

### الآية 11:29

> ﻿وَيَا قَوْمِ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مَالًا ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى اللَّهِ ۚ وَمَا أَنَا بِطَارِدِ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ إِنَّهُمْ مُلَاقُو رَبِّهِمْ وَلَٰكِنِّي أَرَاكُمْ قَوْمًا تَجْهَلُونَ [11:29]

Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì níí le àwọn t’ó gbàgbọ́ dànù. Dájúdájú wọn yóò pàdé Olúwa wọn, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ń ri yín sí ìjọ aláìmọ̀kan.

### الآية 11:30

> ﻿وَيَا قَوْمِ مَنْ يَنْصُرُنِي مِنَ اللَّهِ إِنْ طَرَدْتُهُمْ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ [11:30]

Ẹ̀yin ìjọ mi, ta ni ó máa ràn mí lọ́wọ́ níbi (ìyà) Allāhu tí mo bá lé wọn dànù? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

### الآية 11:31

> ﻿وَلَا أَقُولُ لَكُمْ عِنْدِي خَزَائِنُ اللَّهِ وَلَا أَعْلَمُ الْغَيْبَ وَلَا أَقُولُ إِنِّي مَلَكٌ وَلَا أَقُولُ لِلَّذِينَ تَزْدَرِي أَعْيُنُكُمْ لَنْ يُؤْتِيَهُمُ اللَّهُ خَيْرًا ۖ اللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا فِي أَنْفُسِهِمْ ۖ إِنِّي إِذًا لَمِنَ الظَّالِمِينَ [11:31]

Èmi kò sì sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí."

### الآية 11:32

> ﻿قَالُوا يَا نُوحُ قَدْ جَادَلْتَنَا فَأَكْثَرْتَ جِدَالَنَا فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ [11:32]

Wọ́n wí pé: "Ìwọ Nūh, O mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo."

### الآية 11:33

> ﻿قَالَ إِنَّمَا يَأْتِيكُمْ بِهِ اللَّهُ إِنْ شَاءَ وَمَا أَنْتُمْ بِمُعْجِزِينَ [11:33]

(Ànábì Nūh) sọ pé: "Allāhu l’Ó máa mú un wá ba yín tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.

### الآية 11:34

> ﻿وَلَا يَنْفَعُكُمْ نُصْحِي إِنْ أَرَدْتُ أَنْ أَنْصَحَ لَكُمْ إِنْ كَانَ اللَّهُ يُرِيدُ أَنْ يُغْوِيَكُمْ ۚ هُوَ رَبُّكُمْ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [11:34]

Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."

### الآية 11:35

> ﻿أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَعَلَيَّ إِجْرَامِي وَأَنَا بَرِيءٌ مِمَّا تُجْرِمُونَ [11:35]

Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni." Sọ pé: "Tí mó bá hun ún, èmi ni mo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń dá lẹ́ṣẹ̀."

### الآية 11:36

> ﻿وَأُوحِيَ إِلَىٰ نُوحٍ أَنَّهُ لَنْ يُؤْمِنَ مِنْ قَوْمِكَ إِلَّا مَنْ قَدْ آمَنَ فَلَا تَبْتَئِسْ بِمَا كَانُوا يَفْعَلُونَ [11:36]

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni t’ó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 11:37

> ﻿وَاصْنَعِ الْفُلْكَ بِأَعْيُنِنَا وَوَحْيِنَا وَلَا تُخَاطِبْنِي فِي الَّذِينَ ظَلَمُوا ۚ إِنَّهُمْ مُغْرَقُونَ [11:37]

Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí. Dájúdájú A máa tẹ̀ wọ́n rì ni.

### الآية 11:38

> ﻿وَيَصْنَعُ الْفُلْكَ وَكُلَّمَا مَرَّ عَلَيْهِ مَلَأٌ مِنْ قَوْمِهِ سَخِرُوا مِنْهُ ۚ قَالَ إِنْ تَسْخَرُوا مِنَّا فَإِنَّا نَسْخَرُ مِنْكُمْ كَمَا تَسْخَرُونَ [11:38]

Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: "Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọmọr; 54:9.

### الآية 11:39

> ﻿فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ مَنْ يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُقِيمٌ [11:39]

Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí."

### الآية 11:40

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ قُلْنَا احْمِلْ فِيهَا مِنْ كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلَّا مَنْ سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ وَمَنْ آمَنَ ۚ وَمَا آمَنَ مَعَهُ إِلَّا قَلِيلٌ [11:40]

(Báyìí ni ọ̀rọ̀ wà) títí di ìgbà tí àṣẹ Wa dé, omi sì ṣẹ́yọ gbùú láti ojú-àrò (tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì). A sọ pé: "Kó gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ sínú ọkọ̀ ojú-omi - àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí (fún ìparun) - àti ẹnikẹ́ni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì sí ẹni t’ó ní ìgbàgbọ́ òdodo pẹ̀lú rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀.

### الآية 11:41

> ﻿۞ وَقَالَ ارْكَبُوا فِيهَا بِسْمِ اللَّهِ مَجْرَاهَا وَمُرْسَاهَا ۚ إِنَّ رَبِّي لَغَفُورٌ رَحِيمٌ [11:41]

(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ wọ inú ọkọ̀ ojú-omi náà. Ó máa rìn, ó sì máa gúnlẹ̀ ní orúkọ Allāhu. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."

### الآية 11:42

> ﻿وَهِيَ تَجْرِي بِهِمْ فِي مَوْجٍ كَالْجِبَالِ وَنَادَىٰ نُوحٌ ابْنَهُ وَكَانَ فِي مَعْزِلٍ يَا بُنَيَّ ارْكَبْ مَعَنَا وَلَا تَكُنْ مَعَ الْكَافِرِينَ [11:42]

Ó sì ń gbé wọn lọ nínú ìgbì omi t’ó dà bí àpáta. (Ànábì Nūh) sì ké sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó ti yara rẹ̀ sọ́tọ̀: "Ọmọkùnrin mi, gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú wa. Má sì ṣe wà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́."

### الآية 11:43

> ﻿قَالَ سَآوِي إِلَىٰ جَبَلٍ يَعْصِمُنِي مِنَ الْمَاءِ ۚ قَالَ لَا عَاصِمَ الْيَوْمَ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ إِلَّا مَنْ رَحِمَ ۚ وَحَالَ بَيْنَهُمَا الْمَوْجُ فَكَانَ مِنَ الْمُغْرَقِينَ [11:43]

Ó wí pé: “Èmi yóò forí pamọ́ síbi àpáta kan tí ó máa là mí níbi omi.” (Ànábì Nūh) sọ pé: "Kò sí aláàbò kan ní òní níbi àṣẹ Allāhu àfi ẹni tí Allāhu bá ṣàánú." Ìgbì omi sì la àwọn méjèèjì láààrin. Ó sì di ara àwọn olùtẹ̀rì sínú omi.

### الآية 11:44

> ﻿وَقِيلَ يَا أَرْضُ ابْلَعِي مَاءَكِ وَيَا سَمَاءُ أَقْلِعِي وَغِيضَ الْمَاءُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ وَاسْتَوَتْ عَلَى الْجُودِيِّ ۖ وَقِيلَ بُعْدًا لِلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [11:44]

A sọ pé: "Ilẹ̀, fa omi rẹ mu. Sánmọ̀, dáwọ́ (òjò) dúró." Wọ́n sì dín omi kù. Ọ̀rọ̀ ìparun wọn sì wá sí ìmúṣẹ. (Ọkọ̀ ojú-omi) sì gúnlẹ̀ sórí àpáta Jūdī. A sì sọ pé: “Ìjìnnà réré sí ìkẹ́ Allāhu ni ti ìjọ alábòsí.”

### الآية 11:45

> ﻿وَنَادَىٰ نُوحٌ رَبَّهُ فَقَالَ رَبِّ إِنَّ ابْنِي مِنْ أَهْلِي وَإِنَّ وَعْدَكَ الْحَقُّ وَأَنْتَ أَحْكَمُ الْحَاكِمِينَ [11:45]

(Ànábì) Nūh pe Olúwa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú ọmọ mi wà nínú ará ilé mi. Àti pé dájúdájú àdéhùn Rẹ, òdodo ni. Ìwọ l’O sì mọ ẹjọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́.

### الآية 11:46

> ﻿قَالَ يَا نُوحُ إِنَّهُ لَيْسَ مِنْ أَهْلِكَ ۖ إِنَّهُ عَمَلٌ غَيْرُ صَالِحٍ ۖ فَلَا تَسْأَلْنِ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ ۖ إِنِّي أَعِظُكَ أَنْ تَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ [11:46]

Allāhu sọ pé: “Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nínú èdè Lárúbáwá, wọ́n lè pe ọmọ ẹni ní iṣẹ́ ọwọ́ ẹni. Ní èdè Lárúbáwá èyí lè jẹ́ ‘amal tàbí kasb. Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Dájúdájú n̄ǹkan t’ó dára jùlọ ni n̄ǹkan tí ẹ bá jẹ nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín. Dájúdájú nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín ni àwọn ọmọ yín wà. (Sunan at-Tirmithiy; 1358. Abu ‘Īsā at-Tirmithiy sọ pé: “Èyí ni hadīth t’ó dára, t’ó fẹsẹ̀ rìnlẹ̀.)

### الآية 11:47

> ﻿قَالَ رَبِّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ أَنْ أَسْأَلَكَ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ ۖ وَإِلَّا تَغْفِرْ لِي وَتَرْحَمْنِي أَكُنْ مِنَ الْخَاسِرِينَ [11:47]

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń sá di Ọ́ níbi kí n̄g bi Ọ́ léèrè n̄ǹkan tí èmi kò ní ìmọ̀ rẹ̀. Tí O ò bá foríjìn mí, kí O sì ṣàánú mi, èmi yóò wà lára àwọn ẹni òfò."

### الآية 11:48

> ﻿قِيلَ يَا نُوحُ اهْبِطْ بِسَلَامٍ مِنَّا وَبَرَكَاتٍ عَلَيْكَ وَعَلَىٰ أُمَمٍ مِمَّنْ مَعَكَ ۚ وَأُمَمٌ سَنُمَتِّعُهُمْ ثُمَّ يَمَسُّهُمْ مِنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ [11:48]

A sọ pé: "Nūh, sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Wa. Àti pé kí ìbùkún wà pẹ̀lú rẹ àti àwọn ìjọ nínú àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Àwọn ìjọ kan (tún ń bọ̀), tí A óò fún wọn ní ìgbádùn (oore ayé). Lẹ́yìn náà, ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ bà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Wa."

### الآية 11:49

> ﻿تِلْكَ مِنْ أَنْبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهَا إِلَيْكَ ۖ مَا كُنْتَ تَعْلَمُهَا أَنْتَ وَلَا قَوْمُكَ مِنْ قَبْلِ هَٰذَا ۖ فَاصْبِرْ ۖ إِنَّ الْعَاقِبَةَ لِلْمُتَّقِينَ [11:49]

Ìwọ̀nyí wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi (ìmísí rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ àti ìjọ rẹ kò nímọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ). Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú ìkángun rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

### الآية 11:50

> ﻿وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمْ هُودًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا مُفْتَرُونَ [11:50]

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran ‘Ād ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe aládàápa irọ́.

### الآية 11:51

> ﻿يَا قَوْمِ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى الَّذِي فَطَرَنِي ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ [11:51]

Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá mi. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

### الآية 11:52

> ﻿وَيَا قَوْمِ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ يُرْسِلِ السَّمَاءَ عَلَيْكُمْ مِدْرَارًا وَيَزِدْكُمْ قُوَّةً إِلَىٰ قُوَّتِكُمْ وَلَا تَتَوَلَّوْا مُجْرِمِينَ [11:52]

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olùwa Ẹlẹ́dàá yín, lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè rọ̀jò fun yín ní púpọ̀ láti sánmọ̀ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún agbára kún agbára yín. Ẹ má ṣe pẹ̀yìn dà láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ (sínú àìgbàgbọ́)."

### الآية 11:53

> ﻿قَالُوا يَا هُودُ مَا جِئْتَنَا بِبَيِّنَةٍ وَمَا نَحْنُ بِتَارِكِي آلِهَتِنَا عَنْ قَوْلِكَ وَمَا نَحْنُ لَكَ بِمُؤْمِنِينَ [11:53]

Wọ́n wí pé: "Hūd, o ò mú ẹ̀rí kan t’ó yanjú wá fún wa. Àwa kò sì níí gbé àwọn òrìṣà wa jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ. Àti pé àwa kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ.

### الآية 11:54

> ﻿إِنْ نَقُولُ إِلَّا اعْتَرَاكَ بَعْضُ آلِهَتِنَا بِسُوءٍ ۗ قَالَ إِنِّي أُشْهِدُ اللَّهَ وَاشْهَدُوا أَنِّي بَرِيءٌ مِمَّا تُشْرِكُونَ [11:54]

ǹkan tí à ń sọ fún ọ ni pé àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (l’ó fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn)." Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ

### الآية 11:55

> ﻿مِنْ دُونِهِ ۖ فَكِيدُونِي جَمِيعًا ثُمَّ لَا تُنْظِرُونِ [11:55]

dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára.

### الآية 11:56

> ﻿إِنِّي تَوَكَّلْتُ عَلَى اللَّهِ رَبِّي وَرَبِّكُمْ ۚ مَا مِنْ دَابَّةٍ إِلَّا هُوَ آخِذٌ بِنَاصِيَتِهَا ۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ [11:56]

Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà.

### الآية 11:57

> ﻿فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقَدْ أَبْلَغْتُكُمْ مَا أُرْسِلْتُ بِهِ إِلَيْكُمْ ۚ وَيَسْتَخْلِفُ رَبِّي قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّونَهُ شَيْئًا ۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ حَفِيظٌ [11:57]

Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fun yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan t’ó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ ò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan."

### الآية 11:58

> ﻿وَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا هُودًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَنَجَّيْنَاهُمْ مِنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ [11:58]

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà t’ó nípọn.

### الآية 11:59

> ﻿وَتِلْكَ عَادٌ ۖ جَحَدُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ وَعَصَوْا رُسُلَهُ وَاتَّبَعُوا أَمْرَ كُلِّ جَبَّارٍ عَنِيدٍ [11:59]

Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo.

### الآية 11:60

> ﻿وَأُتْبِعُوا فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا لَعْنَةً وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ أَلَا إِنَّ عَادًا كَفَرُوا رَبَّهُمْ ۗ أَلَا بُعْدًا لِعَادٍ قَوْمِ هُودٍ [11:60]

A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd.

### الآية 11:61

> ﻿۞ وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ هُوَ أَنْشَأَكُمْ مِنَ الْأَرْضِ وَاسْتَعْمَرَكُمْ فِيهَا فَاسْتَغْفِرُوهُ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ ۚ إِنَّ رَبِّي قَرِيبٌ مُجِيبٌ [11:61]

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l’Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fun yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá).”

### الآية 11:62

> ﻿قَالُوا يَا صَالِحُ قَدْ كُنْتَ فِينَا مَرْجُوًّا قَبْلَ هَٰذَا ۖ أَتَنْهَانَا أَنْ نَعْبُدَ مَا يَعْبُدُ آبَاؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكٍّ مِمَّا تَدْعُونَا إِلَيْهِ مُرِيبٍ [11:62]

Wọ́n wí pé: “Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí.”

### الآية 11:63

> ﻿قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كُنْتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَآتَانِي مِنْهُ رَحْمَةً فَمَنْ يَنْصُرُنِي مِنَ اللَّهِ إِنْ عَصَيْتُهُ ۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيْرَ تَخْسِيرٍ [11:63]

Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun.

### الآية 11:64

> ﻿وَيَا قَوْمِ هَٰذِهِ نَاقَةُ اللَّهِ لَكُمْ آيَةً فَذَرُوهَا تَأْكُلْ فِي أَرْضِ اللَّهِ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابٌ قَرِيبٌ [11:64]

Ẹ̀yin ìjọ mi, èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. Ó jẹ́ àmì fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ́ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ìnira kàn án nítorí kí ìyà t’ó súnmọ́ má báa jẹ yín."

### الآية 11:65

> ﻿فَعَقَرُوهَا فَقَالَ تَمَتَّعُوا فِي دَارِكُمْ ثَلَاثَةَ أَيَّامٍ ۖ ذَٰلِكَ وَعْدٌ غَيْرُ مَكْذُوبٍ [11:65]

Wọ́n sì gún un pa. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ̀gbádùn nínú ilé yín fún ọjọ́ mẹ́ta (kí ìyà yín tó dé). Ìyẹn ni àdéhùn tí kì í ṣe irọ́.”

### الآية 11:66

> ﻿فَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا صَالِحًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَمِنْ خِزْيِ يَوْمِئِذٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْقَوِيُّ الْعَزِيزُ [11:66]

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Sọ̄lih àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. (A tún gbà wọ́n là) nínú àbùkù ọjọ́ yẹn. Dájúdájú Olúwa Rẹ, Òun ni Alágbára, Olùborí (ẹ̀dá).

### الآية 11:67

> ﻿وَأَخَذَ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ [11:67]

Ohùn igbe líle gbá àwọn t’ó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.

### الآية 11:68

> ﻿كَأَنْ لَمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۗ أَلَا إِنَّ ثَمُودَ كَفَرُوا رَبَّهُمْ ۗ أَلَا بُعْدًا لِثَمُودَ [11:68]

Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí. Gbọ́, dájúdájú ìran Thamūd ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìjọ Thamūd.

### الآية 11:69

> ﻿وَلَقَدْ جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ ۖ فَمَا لَبِثَ أَنْ جَاءَ بِعِجْلٍ حَنِيذٍ [11:69]

Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ti mú ìró ìdùnnú wá bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Wọ́n sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Ó sọ pé: “Àlàáfíà (fun yín).” Kò sì pẹ́ rárá t’ó fi gbé ọmọ màálù àyangbẹ wá.

### الآية 11:70

> ﻿فَلَمَّا رَأَىٰ أَيْدِيَهُمْ لَا تَصِلُ إِلَيْهِ نَكِرَهُمْ وَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۚ قَالُوا لَا تَخَفْ إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمِ لُوطٍ [11:70]

Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ, ó f’ojú òdì wo (àìjẹun) wọn. Ìbẹ̀rù wọn sí wà nínú ọkàn rẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí.”

### الآية 11:71

> ﻿وَامْرَأَتُهُ قَائِمَةٌ فَضَحِكَتْ فَبَشَّرْنَاهَا بِإِسْحَاقَ وَمِنْ وَرَاءِ إِسْحَاقَ يَعْقُوبَ [11:71]

Ìyàwó rẹ̀ wà ní ìdúró, ó rẹ́rìn-ín. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (pé ó máa bí) ’Ishāƙ. Àti pé lẹ́yìn ’Ishāƙ ni Ya‘ƙūb (ìyẹn, ọmọọmọ). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àsìkò tí àwọn mọlāika fẹ́ pa ìjọ Ànábì Lūt ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) rẹ́ ni àsìkò tí ìró ìdùnnú àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbí Ànábì ’Ishāƙ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bọ́ sí. Èyí túmọ̀ sí pé, lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ fi àkọ́bí rẹ̀, Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jọ́sìn fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbí Ànábì ’Ishāƙ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣẹlẹ̀. Ìdí ni pé, ọlá àdúà tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe láti tọrọ ọmọ l’ó jẹ́ sábàbí fún bíbí Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àmọ́ ọlá ìtẹ̀lé àṣẹ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi “ọmọ àdúà náà”, Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jọ́sìn fún Òun l’ó jẹ́ sábàbí fún bíbí Ànábì ’Ishāƙ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kíyè sí i, àdúà “ìrawọ́rasẹ̀” sí Allāhu tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe láti fi tọrọ Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò la ìjẹ́jẹ̀ẹ́ kan kan lọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe lérò. Ẹ ka sūrah ‘Ibrọ̄hīm; 14:39 àti sūrah as-Sọ̄ffāt; 37: 100-113.

### الآية 11:72

> ﻿قَالَتْ يَا وَيْلَتَىٰ أَأَلِدُ وَأَنَا عَجُوزٌ وَهَٰذَا بَعْلِي شَيْخًا ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ عَجِيبٌ [11:72]

Ó sọ pé: “Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ? Arúgbóbìnrin ni mi, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu.”

### الآية 11:73

> ﻿قَالُوا أَتَعْجَبِينَ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ ۖ رَحْمَتُ اللَّهِ وَبَرَكَاتُهُ عَلَيْكُمْ أَهْلَ الْبَيْتِ ۚ إِنَّهُ حَمِيدٌ مَجِيدٌ [11:73]

Wọ́n sọ pé: “Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fun yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́, Ẹlẹ́yìn.”

### الآية 11:74

> ﻿فَلَمَّا ذَهَبَ عَنْ إِبْرَاهِيمَ الرَّوْعُ وَجَاءَتْهُ الْبُشْرَىٰ يُجَادِلُنَا فِي قَوْمِ لُوطٍ [11:74]

Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a, ó sì ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt.

### الآية 11:75

> ﻿إِنَّ إِبْرَاهِيمَ لَحَلِيمٌ أَوَّاهٌ مُنِيبٌ [11:75]

Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà.

### الآية 11:76

> ﻿يَا إِبْرَاهِيمُ أَعْرِضْ عَنْ هَٰذَا ۖ إِنَّهُ قَدْ جَاءَ أَمْرُ رَبِّكَ ۖ وَإِنَّهُمْ آتِيهِمْ عَذَابٌ غَيْرُ مَرْدُودٍ [11:76]

(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá.

### الآية 11:77

> ﻿وَلَمَّا جَاءَتْ رُسُلُنَا لُوطًا سِيءَ بِهِمْ وَضَاقَ بِهِمْ ذَرْعًا وَقَالَ هَٰذَا يَوْمٌ عَصِيبٌ [11:77]

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ t’ó le púpọ̀.”

### الآية 11:78

> ﻿وَجَاءَهُ قَوْمُهُ يُهْرَعُونَ إِلَيْهِ وَمِنْ قَبْلُ كَانُوا يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ ۚ قَالَ يَا قَوْمِ هَٰؤُلَاءِ بَنَاتِي هُنَّ أَطْهَرُ لَكُمْ ۖ فَاتَّقُوا اللَّهَ وَلَا تُخْزُونِ فِي ضَيْفِي ۖ أَلَيْسَ مِنْكُمْ رَجُلٌ رَشِيدٌ [11:78]

Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bíi ìbálòpọ̀ láààrin ọkùnrin àti ọkùnrin). Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyẹn ni ọmọbìnrin mi, wọ́n mọ́ jùlọ fun yín (láti fi ṣaya). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin olùmọ̀nà kan nínú yín ni?"

### الآية 11:79

> ﻿قَالُوا لَقَدْ عَلِمْتَ مَا لَنَا فِي بَنَاتِكَ مِنْ حَقٍّ وَإِنَّكَ لَتَعْلَمُ مَا نُرِيدُ [11:79]

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò lẹ́tọ̀ọ́ kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́.”

### الآية 11:80

> ﻿قَالَ لَوْ أَنَّ لِي بِكُمْ قُوَّةً أَوْ آوِي إِلَىٰ رُكْنٍ شَدِيدٍ [11:80]

Ó sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan t’ó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín)."

### الآية 11:81

> ﻿قَالُوا يَا لُوطُ إِنَّا رُسُلُ رَبِّكَ لَنْ يَصِلُوا إِلَيْكَ ۖ فَأَسْرِ بِأَهْلِكَ بِقِطْعٍ مِنَ اللَّيْلِ وَلَا يَلْتَفِتْ مِنْكُمْ أَحَدٌ إِلَّا امْرَأَتَكَ ۖ إِنَّهُ مُصِيبُهَا مَا أَصَابَهُمْ ۚ إِنَّ مَوْعِدَهُمُ الصُّبْحُ ۚ أَلَيْسَ الصُّبْحُ بِقَرِيبٍ [11:81]

(Àwọn mọlāika) sọ pé: “(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru. Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú àdánwò rẹ̀ ni ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni?
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Abala kan nínú òru nínú āyah yìí dúró fún abala ìparí òru, tí í ṣe àsìkò sààrì gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:34.

### الآية 11:82

> ﻿فَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا جَعَلْنَا عَالِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهَا حِجَارَةً مِنْ سِجِّيلٍ مَنْضُودٍ [11:82]

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.

### الآية 11:83

> ﻿مُسَوَّمَةً عِنْدَ رَبِّكَ ۖ وَمَا هِيَ مِنَ الظَّالِمِينَ بِبَعِيدٍ [11:83]

(Àwọn òkúta náà) ti ní àmì (orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lára) láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Wọn kò sì jìnnà sí àwọn alábòsí.

### الآية 11:84

> ﻿۞ وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ وَلَا تَنْقُصُوا الْمِكْيَالَ وَالْمِيزَانَ ۚ إِنِّي أَرَاكُمْ بِخَيْرٍ وَإِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ مُحِيطٍ [11:84]

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Mọdyan ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣua‘eb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe dín kóńgò àti òṣùwọ̀n kù. Mo rí yín pẹ̀lú dáadáa (tí Allāhu ṣe fun yín). Dájúdájú èmi sì ń páyà ìyà ọjọ́ kan tí ó máa yi yín po.

### الآية 11:85

> ﻿وَيَا قَوْمِ أَوْفُوا الْمِكْيَالَ وَالْمِيزَانَ بِالْقِسْطِ ۖ وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ [11:85]

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gbadọ́gba. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe balẹ̀ jẹ́ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 11:86

> ﻿بَقِيَّتُ اللَّهِ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ ۚ وَمَا أَنَا عَلَيْكُمْ بِحَفِيظٍ [11:86]

Ohun tí Allāhu bá ṣẹ́kù fun yín (nínú halāl) lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Èmi kì í sì ṣe olùṣọ́ lórí yín."

### الآية 11:87

> ﻿قَالُوا يَا شُعَيْبُ أَصَلَاتُكَ تَأْمُرُكَ أَنْ نَتْرُكَ مَا يَعْبُدُ آبَاؤُنَا أَوْ أَنْ نَفْعَلَ فِي أَمْوَالِنَا مَا نَشَاءُ ۖ إِنَّكَ لَأَنْتَ الْحَلِيمُ الرَّشِيدُ [11:87]

Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, ṣé ìrun rẹ l’ó ń pa ọ́ láṣẹ pé kí á gbé ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún jù sílẹ̀, tàbí (ìrun rẹ ló ń kọ̀ fún wa) láti ṣe ohun tí a bá fẹ́ nínú dúkìá wa? Dájúdájú ìwọ mà ni aláfaradà, olùmọ̀nà (lójú ara rẹ nìyẹn)."

### الآية 11:88

> ﻿قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كُنْتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَرَزَقَنِي مِنْهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أُخَالِفَكُمْ إِلَىٰ مَا أَنْهَاكُمْ عَنْهُ ۚ إِنْ أُرِيدُ إِلَّا الْإِصْلَاحَ مَا اسْتَطَعْتُ ۚ وَمَا تَوْفِيقِي إِلَّا بِاللَّهِ ۚ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ أُنِيبُ [11:88]

Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé mo wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí (Olúwa mi) sì fún mi ní arísìkí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní arísìkí t’ó dára (ṣé kí n̄g máa jẹ harāmu pẹ̀lú rẹ̀ ni?). Èmi kò sì fẹ́ yapa yín nípa n̄ǹkan tí mò ń kọ̀ fun yín (ìyẹn ni pé, èmi náà ń lo ohun tí mò ń sọ fun yín). Kò sí ohun tí mo fẹ́ bí kò ṣe àtúnṣe pẹ̀lú bí mo ṣe lágbára mọ. Kò sí kòǹgẹ́ ìmọ̀nà kan fún mi bí kò ṣe pẹ̀lú (ìyọ̀ǹda) Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí sí (fún ìronúpìwàdà).

### الآية 11:89

> ﻿وَيَا قَوْمِ لَا يَجْرِمَنَّكُمْ شِقَاقِي أَنْ يُصِيبَكُمْ مِثْلُ مَا أَصَابَ قَوْمَ نُوحٍ أَوْ قَوْمَ هُودٍ أَوْ قَوْمَ صَالِحٍ ۚ وَمَا قَوْمُ لُوطٍ مِنْكُمْ بِبَعِيدٍ [11:89]

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí (bí) ẹ ṣe ń yapa mi mu yín lùgbàdì irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ (Ànábì) Nūh tàbí ìjọ (Ànábì) Hūd tàbí ìjọ (Ànábì) Sọ̄lih. Ìjọ (Ànábì) Lūt kò sì jìnnà si yín.

### الآية 11:90

> ﻿وَاسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ ۚ إِنَّ رَبِّي رَحِيمٌ وَدُودٌ [11:90]

Kí ẹ sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá).”

### الآية 11:91

> ﻿قَالُوا يَا شُعَيْبُ مَا نَفْقَهُ كَثِيرًا مِمَّا تَقُولُ وَإِنَّا لَنَرَاكَ فِينَا ضَعِيفًا ۖ وَلَوْلَا رَهْطُكَ لَرَجَمْنَاكَ ۖ وَمَا أَنْتَ عَلَيْنَا بِعَزِيزٍ [11:91]

Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, a ò gbọ́ àgbọ́yé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ò ń sọ. Dájúdájú àwa sì ń rí ọ ní ọ̀lẹ láààrin wa. Tí kò bá jẹ́ pé nítorí ti ẹbí rẹ ni, a ìbá ti kù ọ́ lókò pa; ìwọ kò sì níí lágbára kan lórí wa."

### الآية 11:92

> ﻿قَالَ يَا قَوْمِ أَرَهْطِي أَعَزُّ عَلَيْكُمْ مِنَ اللَّهِ وَاتَّخَذْتُمُوهُ وَرَاءَكُمْ ظِهْرِيًّا ۖ إِنَّ رَبِّي بِمَا تَعْمَلُونَ مُحِيطٌ [11:92]

Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé ẹbí mi ló lágbára lójú yin ju Allāhu? Ẹ sì sọ Allāhu di Ẹni tí ẹ kọ̀yìn kọ̀pàkọ́ sí! Dájúdájú Olúwa mi ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 11:93

> ﻿وَيَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ سَوْفَ تَعْلَمُونَ مَنْ يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَمَنْ هُوَ كَاذِبٌ ۖ وَارْتَقِبُوا إِنِّي مَعَكُمْ رَقِيبٌ [11:93]

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín, dájúdájú èmi yóò máa bá ẹ̀sìn mi lọ. Láìpẹ́ ẹ̀yin yóò mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, (ẹ̀yin yó sì mọ) ta ni òpùrọ́. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín tí mò ń retí (ìkángun ọ̀rọ̀ yín).”

### الآية 11:94

> ﻿وَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا شُعَيْبًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَأَخَذَتِ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ [11:94]

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.

### الآية 11:95

> ﻿كَأَنْ لَمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۗ أَلَا بُعْدًا لِمَدْيَنَ كَمَا بَعِدَتْ ثَمُودُ [11:95]

Àfi bí ẹni pé wọn kò gbé inú ìlú náà rí. Gbọ́, ìjìnnà sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran Mọdyan gẹ́gẹ́ bí ìran Thamūd ṣe jìnnà sí ìkẹ́.

### الآية 11:96

> ﻿وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُبِينٍ [11:96]

Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā

### الآية 11:97

> ﻿إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاتَّبَعُوا أَمْرَ فِرْعَوْنَ ۖ وَمَا أَمْرُ فِرْعَوْنَ بِرَشِيدٍ [11:97]

sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà.

### الآية 11:98

> ﻿يَقْدُمُ قَوْمَهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَأَوْرَدَهُمُ النَّارَ ۖ وَبِئْسَ الْوِرْدُ الْمَوْرُودُ [11:98]

Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú.

### الآية 11:99

> ﻿وَأُتْبِعُوا فِي هَٰذِهِ لَعْنَةً وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ بِئْسَ الرِّفْدُ الْمَرْفُودُ [11:99]

A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn ègún tí A fún wọn sì burú.

### الآية 11:100

> ﻿ذَٰلِكَ مِنْ أَنْبَاءِ الْقُرَىٰ نَقُصُّهُ عَلَيْكَ ۖ مِنْهَا قَائِمٌ وَحَصِيدٌ [11:100]

Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí ó ti parẹ́.

### الآية 11:101

> ﻿وَمَا ظَلَمْنَاهُمْ وَلَٰكِنْ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ ۖ فَمَا أَغْنَتْ عَنْهُمْ آلِهَتُهُمُ الَّتِي يَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ لَمَّا جَاءَ أَمْرُ رَبِّكَ ۖ وَمَا زَادُوهُمْ غَيْرَ تَتْبِيبٍ [11:101]

A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun.

### الآية 11:102

> ﻿وَكَذَٰلِكَ أَخْذُ رَبِّكَ إِذَا أَخَذَ الْقُرَىٰ وَهِيَ ظَالِمَةٌ ۚ إِنَّ أَخْذَهُ أَلِيمٌ شَدِيدٌ [11:102]

Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le.

### الآية 11:103

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِمَنْ خَافَ عَذَابَ الْآخِرَةِ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمٌ مَجْمُوعٌ لَهُ النَّاسُ وَذَٰلِكَ يَوْمٌ مَشْهُودٌ [11:103]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni t’ó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí.

### الآية 11:104

> ﻿وَمَا نُؤَخِّرُهُ إِلَّا لِأَجَلٍ مَعْدُودٍ [11:104]

A ò sì fi falẹ̀ bí kò ṣe di àkókò t’ó lọ́jọ́.

### الآية 11:105

> ﻿يَوْمَ يَأْتِ لَا تَكَلَّمُ نَفْسٌ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۚ فَمِنْهُمْ شَقِيٌّ وَسَعِيدٌ [11:105]

Ní ọjọ́ t’ó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà).

### الآية 11:106

> ﻿فَأَمَّا الَّذِينَ شَقُوا فَفِي النَّارِ لَهُمْ فِيهَا زَفِيرٌ وَشَهِيقٌ [11:106]

Ní ti àwọn t’ó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò.

### الآية 11:107

> ﻿خَالِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ إِلَّا مَا شَاءَ رَبُّكَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ فَعَّالٌ لِمَا يُرِيدُ [11:107]

Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo àlàyé lórí àgbọ́yé "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’An‘ām; 6:128.

### الآية 11:108

> ﻿۞ وَأَمَّا الَّذِينَ سُعِدُوا فَفِي الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ إِلَّا مَا شَاءَ رَبُّكَ ۖ عَطَاءً غَيْرَ مَجْذُوذٍ [11:108]

Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ,1 àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.2 (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
1 Bíbẹ nínú Iná àti bíbẹ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ kò túmọ̀ sí pé òpin yóò dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra gẹ́gẹ́ bí òpin yóò ṣe dé bá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìbátan níbi àfiwé tí ń bẹ láààrin àwọn méjéèjì ni pé, ó jẹ́ ara ẹwà èdè láti ṣe àfihàn ìgbà pípẹ́ fún n̄ǹkan. Lára irúfẹ èyí náà ni, bí àpẹẹrẹ, kí ọkùnrin kan sọ pé, "Èmi yóò máa jẹ́ ọkúnrin ní òdiwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ bá ń ṣú, tí ilẹ̀ bá ń mọ́." Ṣíwájú sí i, ìgbàgbọ́ àwa mùsùlùmí ahlu-sunnah wal-janmọ̄n‘ah ni pé, kò sí òpin ìgbà fún Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ já sí pé, àwọn kan lè kọ́kọ́ wọ inú Iná, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yó sì padà mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú àánú Rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ìṣìpẹ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lẹ́yìn náà, ó máa ṣẹ́ ku kìkìdá àwọn ọmọ Iná Gbére, wọn yó sì ṣe gbére nínú Iná. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ni. Kò sì níí sí ẹnì kan tí ó máa ti inú Ọgbà Ìdẹ̀ra bọ́ sínú Iná Gbére. Ẹ̀rí nínú sunnah Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí á tún lè fi ní àgbọ́yé àwọn āyah wọ̀nyí dáradára ni hadīth Abu-Sa‘īd al-Kudri (rọdiyallāhu 'anhu). Ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ pé: "Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò mú Ikú wá ní ìrísí àgbò funfun, tí ó ní dúdú lára. Olùpèpè kan yó sì pèpè báyìí pé, 'Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra'. Àwọn ará Ọgbà Ìdẹ̀ra yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: 'Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?' Wọn yóò sọ pé: 'Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.' Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Lẹ́yìn náà, olùpèpè máa pèpè báyìí pé, 'Ẹ̀yin ará Iná'. Àwọn ará Iná yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: 'Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?' Wọn yóò wí pé: 'Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.' Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Nígbà náà, A óò pa Ikú. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan yóò sọ pé: 'Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra, gbére (ni tiyín báyìí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), kò sì sí Ikú mọ́. Olùpèpè yóò tún sọ pé: 'Ẹ̀yin ará Iná, gbére (ni tiyín báyìí nínú Iná), kò sì sí Ikú mọ́." Al-Bukāriy; Kitāb at-Tafsīr. 2 Awẹ́ gbólóhùn yìí "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́", àgbọ́yé rẹ̀ ni pípẹ́ tí àwọn kan yóò pẹ́ kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó kúkú ti hàn kedere pé àwọn kan yóò ṣíwájú àwọn mìíràn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra látára bí ìrìn-àjò ẹ̀dá bá ṣe rí lórí afárá Iná. Bákàn náà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan yóò kọ́kọ́ wọ inú Iná, ṣíwájú kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àti pé àwọn kan wulẹ̀ ti wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde ẹ̀dá. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kú sí ipò ṣẹhīd, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mú hadīth wá lórí èyí nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:154. Nítorí náà, nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra, "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" túmọ̀ sí "àfi pípẹ́ tí Olúwa rẹ bá fẹ́ fún àwọn kan láti pẹ́ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Nígbà tí gbogbo wọn bá sì péjú pésẹ̀ tán sínú rẹ̀, wọn yó sì máa wà nínú rẹ̀ títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá pa Ikú. Kí Allāhu jẹ́ kí á tètè wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ní ìsọníṣókí, ìyàtọ̀ wà nínú àgbọ́yé "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nípa ti èrò Iná àti "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àmọ́ àgbọ́yé àwọn méjèèjì kò jẹmọ́ pé òpin máa dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ọgbà gbére ni méjèèjì.

### الآية 11:109

> ﻿فَلَا تَكُ فِي مِرْيَةٍ مِمَّا يَعْبُدُ هَٰؤُلَاءِ ۚ مَا يَعْبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعْبُدُ آبَاؤُهُمْ مِنْ قَبْلُ ۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمْ نَصِيبَهُمْ غَيْرَ مَنْقُوصٍ [11:109]

Nítorí náà, má ṣe wà nínú ròyíròyí nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí kù síbì kan.

### الآية 11:110

> ﻿وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَاخْتُلِفَ فِيهِ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ مُرِيبٍ [11:110]

A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kì í bá ṣe ọ̀rọ̀ kan tí ó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.

### الآية 11:111

> ﻿وَإِنَّ كُلًّا لَمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمْ رَبُّكَ أَعْمَالَهُمْ ۚ إِنَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ خَبِيرٌ [11:111]

Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 11:112

> ﻿فَاسْتَقِمْ كَمَا أُمِرْتَ وَمَنْ تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطْغَوْا ۚ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ [11:112]

Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 11:113

> ﻿وَلَا تَرْكَنُوا إِلَى الَّذِينَ ظَلَمُوا فَتَمَسَّكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ أَوْلِيَاءَ ثُمَّ لَا تُنْصَرُونَ [11:113]

Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fun yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.

### الآية 11:114

> ﻿وَأَقِمِ الصَّلَاةَ طَرَفَيِ النَّهَارِ وَزُلَفًا مِنَ اللَّيْلِ ۚ إِنَّ الْحَسَنَاتِ يُذْهِبْنَ السَّيِّئَاتِ ۚ ذَٰلِكَ ذِكْرَىٰ لِلذَّاكِرِينَ [11:114]

Kírun ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀sán (ìyẹn, ìrun Subh, Ṭḥuhr àti ‘Asr) àti ní ìbẹ̀rẹ̀ òru (ìyẹn, ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’). Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu).

### الآية 11:115

> ﻿وَاصْبِرْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ [11:115]

Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.

### الآية 11:116

> ﻿فَلَوْلَا كَانَ مِنَ الْقُرُونِ مِنْ قَبْلِكُمْ أُولُو بَقِيَّةٍ يَنْهَوْنَ عَنِ الْفَسَادِ فِي الْأَرْضِ إِلَّا قَلِيلًا مِمَّنْ أَنْجَيْنَا مِنْهُمْ ۗ وَاتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَا أُتْرِفُوا فِيهِ وَكَانُوا مُجْرِمِينَ [11:116]

Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ – àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn t’ó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 11:117

> ﻿وَمَا كَانَ رَبُّكَ لِيُهْلِكَ الْقُرَىٰ بِظُلْمٍ وَأَهْلُهَا مُصْلِحُونَ [11:117]

Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe.

### الآية 11:118

> ﻿وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَجَعَلَ النَّاسَ أُمَّةً وَاحِدَةً ۖ وَلَا يَزَالُونَ مُخْتَلِفِينَ [11:118]

Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, ìbá ṣe àwọn ènìyàn ní ìjọ ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo. (Àmọ́) wọn kò níí yé yapa ẹnu (sí ’Islām)

### الآية 11:119

> ﻿إِلَّا مَنْ رَحِمَ رَبُّكَ ۚ وَلِذَٰلِكَ خَلَقَهُمْ ۗ وَتَمَّتْ كَلِمَةُ رَبِّكَ لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ الْجِنَّةِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ [11:119]

àfi ẹni tí Olúwa rẹ bá kẹ́. Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn. Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ sì ti ṣẹ (báyìí pé): “Dájúdájú Èmi yóò mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kúnnú iná Jahanamọ.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Gbólóhùn yìí “Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn.”, ìyẹn ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) dá àwọn ènìyàn àti àlùjànnú kan fún dídúró ṣinṣin lórí ẹ̀sìn ’Islām àti wíwọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó sì dá àwọn mìíràn fún yíyapa ẹ̀sìn ’Islām àti wíwọ inú Iná.

### الآية 11:120

> ﻿وَكُلًّا نَقُصُّ عَلَيْكَ مِنْ أَنْبَاءِ الرُّسُلِ مَا نُثَبِّتُ بِهِ فُؤَادَكَ ۚ وَجَاءَكَ فِي هَٰذِهِ الْحَقُّ وَمَوْعِظَةٌ وَذِكْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ [11:120]

Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 11:121

> ﻿وَقُلْ لِلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنَّا عَامِلُونَ [11:121]

Kí o sì sọ fún àwọn tí kò gbàgbọ́ pé: "Ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín. Dájúdájú àwa náà yóò máa bá ẹ̀sìn wa lọ.

### الآية 11:122

> ﻿وَانْتَظِرُوا إِنَّا مُنْتَظِرُونَ [11:122]

Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí."

### الآية 11:123

> ﻿وَلِلَّهِ غَيْبُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَإِلَيْهِ يُرْجَعُ الْأَمْرُ كُلُّهُ فَاعْبُدْهُ وَتَوَكَّلْ عَلَيْهِ ۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ [11:123]

Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/11.md)
- [كل تفاسير سورة هود
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/11.md)
- [ترجمات سورة هود
](https://quranpedia.net/translations/11.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/11/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
