---
title: "ترجمة سورة الرعد - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/13/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/13/book/2001"
surah_id: "13"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الرعد - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/13/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الرعد - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/13/book/2001*.

Translation of Surah الرعد from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 13:1

> المر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ ۗ وَالَّذِي أُنْزِلَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ الْحَقُّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ [13:1]

’Alif lām mīm rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà. Àti pé òdodo ni ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò gbàgbọ́.

### الآية 13:2

> ﻿اللَّهُ الَّذِي رَفَعَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ۖ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُسَمًّى ۚ يُدَبِّرُ الْأَمْرَ يُفَصِّلُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ بِلِقَاءِ رَبِّكُمْ تُوقِنُونَ [13:2]

Allāhu ni Ẹni tí Ó gbé àwọn sánmọ̀ ga sókè láì sí àwọn òpó kan (fún un) tí ẹ lè fojú rí. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Ó ń ṣe àlàyé àwọn āyah nítorí kí ẹ lè mọ àmọ̀dájú nípa ìpàdé Olúwa yín.

### الآية 13:3

> ﻿وَهُوَ الَّذِي مَدَّ الْأَرْضَ وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنْهَارًا ۖ وَمِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ جَعَلَ فِيهَا زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ ۖ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ [13:3]

Òun ni Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ. Ó sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ àti àwọn odò. Àti pé nínú gbogbo àwọn èso, Ó ṣe é ní oríṣi méjì-méjì. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.

### الآية 13:4

> ﻿وَفِي الْأَرْضِ قِطَعٌ مُتَجَاوِرَاتٌ وَجَنَّاتٌ مِنْ أَعْنَابٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَىٰ بِمَاءٍ وَاحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَىٰ بَعْضٍ فِي الْأُكُلِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ [13:4]

Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) t’ó wà nítòsí ara wọn àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù t’ó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fi omi ẹyọ kan wọn. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi jíjẹ. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Bíi ilẹ̀ yanrìn nítòsí ilẹ̀ amọ̀, ilẹ́ yangí nítòsí ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ yangí, ilẹ̀ t’ó lọ́ràá nítòsí ilẹ̀ t’ó sá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

### الآية 13:5

> ﻿۞ وَإِنْ تَعْجَبْ فَعَجَبٌ قَوْلُهُمْ أَإِذَا كُنَّا تُرَابًا أَإِنَّا لَفِي خَلْقٍ جَدِيدٍ ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ الْأَغْلَالُ فِي أَعْنَاقِهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ [13:5]

Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

### الآية 13:6

> ﻿وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالسَّيِّئَةِ قَبْلَ الْحَسَنَةِ وَقَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِمُ الْمَثُلَاتُ ۗ وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ لِلنَّاسِ عَلَىٰ ظُلْمِهِمْ ۖ وَإِنَّ رَبَّكَ لَشَدِيدُ الْعِقَابِ [13:6]

Wọ́n tún ń kán ọ lójú pé kí aburú ṣẹlẹ̀ ṣíwájú rere. Àwọn àpẹ̀ẹrẹ ìyà kúkú ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú wọn. Àti pé dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn fún àwọn ènìyàn lórí àbòsí (ọwọ́) wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ le níbi ìyà.

### الآية 13:7

> ﻿وَيَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۗ إِنَّمَا أَنْتَ مُنْذِرٌ ۖ وَلِكُلِّ قَوْمٍ هَادٍ [13:7]

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Olùkìlọ̀ mà ni ìwọ. Olùtọ́sọ́nà sì wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.

### الآية 13:8

> ﻿اللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنْثَىٰ وَمَا تَغِيضُ الْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ ۖ وَكُلُّ شَيْءٍ عِنْدَهُ بِمِقْدَارٍ [13:8]

Allāhu mọ ohun tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní lóyún àti ohun tí ilé ọmọ yóò fi dín kù (nínú ọjọ́ ìbímọ) àti ohun tí ó máa fi lékún. N̄ǹkan kọ̀ọ̀kan l’ó sì ní òdíwọ̀n lọ́dọ̀ Rẹ̀.

### الآية 13:9

> ﻿عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْكَبِيرُ الْمُتَعَالِ [13:9]

(Allāhu ni) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti- gban̄gba. Ó tóbi, Ó ga.

### الآية 13:10

> ﻿سَوَاءٌ مِنْكُمْ مَنْ أَسَرَّ الْقَوْلَ وَمَنْ جَهَرَ بِهِ وَمَنْ هُوَ مُسْتَخْفٍ بِاللَّيْلِ وَسَارِبٌ بِالنَّهَارِ [13:10]

Bákan náà ni (lọ́dọ̀ Allāhu), ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ pamọ́ sínú nínú yín àti ẹni tí ó sọ ọ́ síta pẹ̀lú ẹni tí ó fi òru bojú àti ẹni tí ó ń rìn kiri ní ọ̀sán.

### الآية 13:11

> ﻿لَهُ مُعَقِّبَاتٌ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ يَحْفَظُونَهُ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يُغَيِّرُ مَا بِقَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا مَا بِأَنْفُسِهِمْ ۗ وَإِذَا أَرَادَ اللَّهُ بِقَوْمٍ سُوءًا فَلَا مَرَدَّ لَهُ ۚ وَمَا لَهُمْ مِنْ دُونِهِ مِنْ وَالٍ [13:11]

Ó ń bẹ fún ènìyàn (kọ̀ọ̀kan) àwọn mọlāika tí ń gbaṣẹ́ fúnra wọn; wọ́n wà níwájú (ènìyàn) àti lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n ń ṣọ́ (iṣẹ́ ọwọ́) rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà n̄ǹkan t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ ìjọ kan títí wọn yóò fi yí n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn padà. Nígbà tí Allāhu bá gbèrò aburú kan ro ìjọ kan, kò sí ẹni t’ó lè dá a padà. Kò sì sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.

### الآية 13:12

> ﻿هُوَ الَّذِي يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنْشِئُ السَّحَابَ الثِّقَالَ [13:12]

Òun ni Ẹni t’ó ń fi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ìbẹ̀rù àti ní ìrètí (fun yín). Ó sì ń ṣẹ̀dá ẹ̀ṣújò t’ó ṣú dẹ̀dẹ̀.

### الآية 13:13

> ﻿وَيُسَبِّحُ الرَّعْدُ بِحَمْدِهِ وَالْمَلَائِكَةُ مِنْ خِيفَتِهِ وَيُرْسِلُ الصَّوَاعِقَ فَيُصِيبُ بِهَا مَنْ يَشَاءُ وَهُمْ يُجَادِلُونَ فِي اللَّهِ وَهُوَ شَدِيدُ الْمِحَالِ [13:13]

Àrá ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Un, àwọn mọlāika ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. Ó ń rán iná àrá níṣẹ́. Ó sì ń fi kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Síbẹ̀ wọ́n ń jiyàn nípa Allāhu. Ó sì le níbi gbígbá-ẹ̀dá-mú.

### الآية 13:14

> ﻿لَهُ دَعْوَةُ الْحَقِّ ۖ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ لَا يَسْتَجِيبُونَ لَهُمْ بِشَيْءٍ إِلَّا كَبَاسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى الْمَاءِ لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَالِغِهِ ۚ وَمَا دُعَاءُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ [13:14]

TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Gọ̄fir;40:50.

### الآية 13:15

> ﻿وَلِلَّهِ يَسْجُدُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَظِلَالُهُمْ بِالْغُدُوِّ وَالْآصَالِ ۩ [13:15]

Allāhu ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn sūfī (Tijāniyyah) ṣi āyah yìí àti tinú sūrah an-Nahl; 16:49 tú lábẹ́ àdìsọ́kàn wọn tí wọ́n ń pè ní “‘Ilmu bātiniy” – “Ìmọ̀ Awo-inú”. Àwọn sūfī (Tijāniyyah) sọ pé, pẹ̀lú àwọn āyah méjèèjì wọ̀nyẹn, “gbogbo olùjọ́sìn tàbí olùforíkanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu lójú-ìta, kò jọ́sìn kò sì forí kanlẹ̀ fún kiní kan àfi Allāhu (ta‘ālā) nítorí pé Òun l’Ó wà nínú àwọn aṣọ wọ̀nyẹn.” Irọ́ ńlá nìyí. Mímọ́ sì ni fún Allāhu tayọ ìsọkúsọ wọn yẹn. Āyah onípọ́n-na ni āyah méjèèjì wọ̀nyẹn. Pọ́n-na inú wọn ni pé, kò sí ẹni tí kì í forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Èyí ni àwọn sūfī ṣe àfikún rẹ̀ pé, “Kódà kí ó forí kanlẹ̀ fún òrìṣà, Allāhu nínú àwòrán òrìṣà l’ó ń forí kanlẹ̀ fún!” Kíyè sí i, ìgbàkígbà tí a bá rí āyah onípọ́n-na, āyah aláìnípọ́n-na ni a máa fi yanjú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi èyí rinlẹ̀ nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7. Nítorí náà, sūrah al-Hajj;22:18 àti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98 ti yọ pọ́n-na tí ó jẹyọ nínú āyah méjèèjì náà. Ní ti sūrah al-Hajj;22:18, òhun fi rinlẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Ní ti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98, òhun sì fi rinlẹ̀ pé àwọn t’ó ń forí kanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, àti àwọn àti òrìṣà wọn l’ó máa wọ inú Iná nítorí pé, wọn kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu, wọn kò sì jọ́sìn fún Un. Èyí ti túmọ̀ sí pé, sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49 kò kan olùforíkanlẹ̀ àti olùjọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu. Nítorí náà, gbólóhùn “wọ́n fẹ́” dúró fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo; “wọ́n kọ̀” sì dúró fún àwọn munāfiki. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Rūm; 30:26.

### الآية 13:16

> ﻿قُلْ مَنْ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ قُلِ اللَّهُ ۚ قُلْ أَفَاتَّخَذْتُمْ مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ لَا يَمْلِكُونَ لِأَنْفُسِهِمْ نَفْعًا وَلَا ضَرًّا ۚ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ أَمْ هَلْ تَسْتَوِي الظُّلُمَاتُ وَالنُّورُ ۗ أَمْ جَعَلُوا لِلَّهِ شُرَكَاءَ خَلَقُوا كَخَلْقِهِ فَتَشَابَهَ الْخَلْقُ عَلَيْهِمْ ۚ قُلِ اللَّهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ [13:16]

Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

### الآية 13:17

> ﻿أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَسَالَتْ أَوْدِيَةٌ بِقَدَرِهَا فَاحْتَمَلَ السَّيْلُ زَبَدًا رَابِيًا ۚ وَمِمَّا يُوقِدُونَ عَلَيْهِ فِي النَّارِ ابْتِغَاءَ حِلْيَةٍ أَوْ مَتَاعٍ زَبَدٌ مِثْلُهُ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ اللَّهُ الْحَقَّ وَالْبَاطِلَ ۚ فَأَمَّا الزَّبَدُ فَيَذْهَبُ جُفَاءً ۖ وَأَمَّا مَا يَنْفَعُ النَّاسَ فَيَمْكُثُ فِي الْأَرْضِ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ اللَّهُ الْأَمْثَالَ [13:17]

Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Àwọn ojú-odò sì ń ṣàn pẹ̀lú òdiwọ̀n rẹ̀. Àgbàrá sì ń gbé ìfòfó orí-omi lọ. Bákan náà, nínú n̄ǹkan tí wọ́n ń yọ́ nínú iná láti fi ṣe n̄ǹkan-ọ̀ṣọ́ tàbí n̄ǹkan-èlò, òhun náà ní ìfòfó bí irú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àpèjúwe òdodo àti irọ́ wá. Ní ti ìfòfó, ó máa bá pàǹtí lọ. Ní ti èyí tí ó sì máa ṣe ènìyàn ní àǹfààní, ó máa dúró sí orí ilẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àpèjúwe wá.

### الآية 13:18

> ﻿لِلَّذِينَ اسْتَجَابُوا لِرَبِّهِمُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَالَّذِينَ لَمْ يَسْتَجِيبُوا لَهُ لَوْ أَنَّ لَهُمْ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُ مَعَهُ لَافْتَدَوْا بِهِ ۚ أُولَٰئِكَ لَهُمْ سُوءُ الْحِسَابِ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمِهَادُ [13:18]

Ohun rere wà fún àwọn t’ó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Aburú ìṣírò-iṣẹ́ ni kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá lé e lọ́wọ́ àti kí Allāhu má ṣàforíjìn fún un nítorí pé ẹ̀dá náà kú sórí ẹbọ ṣíṣe tàbí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu àfọkànṣe.

### الآية 13:19

> ﻿۞ أَفَمَنْ يَعْلَمُ أَنَّمَا أُنْزِلَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ الْحَقُّ كَمَنْ هُوَ أَعْمَىٰ ۚ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُولُو الْأَلْبَابِ [13:19]

Ǹjẹ́ ẹni tí ó mọ̀ pé òdodo kúkú ni n̄ǹkan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹni tí ó fọ́jú (nípa rẹ̀)? Àwọn onílàákàyè l’ó ń lo ìrántí.

### الآية 13:20

> ﻿الَّذِينَ يُوفُونَ بِعَهْدِ اللَّهِ وَلَا يَنْقُضُونَ الْمِيثَاقَ [13:20]

(Àwọn ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn.

### الآية 13:21

> ﻿وَالَّذِينَ يَصِلُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَنْ يُوصَلَ وَيَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ وَيَخَافُونَ سُوءَ الْحِسَابِ [13:21]

(Àwọn ni) àwọn t’ó ń da ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀ pọ̀. Wọ́n ń páyà Olúwa wọn. Wọ́n sì ń páyà aburú ìṣírò-iṣẹ́.

### الآية 13:22

> ﻿وَالَّذِينَ صَبَرُوا ابْتِغَاءَ وَجْهِ رَبِّهِمْ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَأَنْفَقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عُقْبَى الدَّارِ [13:22]

(Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere ti aburú lọ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún.

### الآية 13:23

> ﻿جَنَّاتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا وَمَنْ صَلَحَ مِنْ آبَائِهِمْ وَأَزْوَاجِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ يَدْخُلُونَ عَلَيْهِمْ مِنْ كُلِّ بَابٍ [13:23]

Inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ̀, (àwọn) àti ẹni t’ó bá ṣe rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.

### الآية 13:24

> ﻿سَلَامٌ عَلَيْكُمْ بِمَا صَبَرْتُمْ ۚ فَنِعْمَ عُقْبَى الدَّارِ [13:24]

(Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fun yín nítorí ìfaradà yín.” Àtubọ̀tán Ilé náà sì dára.

### الآية 13:25

> ﻿وَالَّذِينَ يَنْقُضُونَ عَهْدَ اللَّهِ مِنْ بَعْدِ مِيثَاقِهِ وَيَقْطَعُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَنْ يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ ۙ أُولَٰئِكَ لَهُمُ اللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوءُ الدَّارِ [13:25]

Àwọn t’ó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn.

### الآية 13:26

> ﻿اللَّهُ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ وَفَرِحُوا بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا فِي الْآخِرَةِ إِلَّا مَتَاعٌ [13:26]

Allāhu ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́). Wọ́n sì dunnú sí ìṣẹ̀mí ilé ayé! Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé ní ẹ̀gbẹ́ ti ọ̀run bí kò ṣe ìgbádùn bín-íntín.

### الآية 13:27

> ﻿وَيَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۗ قُلْ إِنَّ اللَّهَ يُضِلُّ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي إِلَيْهِ مَنْ أَنَابَ [13:27]

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ṣẹ́rí sọ́dọ̀ Rẹ̀.”

### الآية 13:28

> ﻿الَّذِينَ آمَنُوا وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُمْ بِذِكْرِ اللَّهِ ۗ أَلَا بِذِكْرِ اللَّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ [13:28]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:152.

### الآية 13:29

> ﻿الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ طُوبَىٰ لَهُمْ وَحُسْنُ مَآبٍ [13:29]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, orí ire àti àbọ̀ rere wà fún wọn.

### الآية 13:30

> ﻿كَذَٰلِكَ أَرْسَلْنَاكَ فِي أُمَّةٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهَا أُمَمٌ لِتَتْلُوَ عَلَيْهِمُ الَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَهُمْ يَكْفُرُونَ بِالرَّحْمَٰنِ ۚ قُلْ هُوَ رَبِّي لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ مَتَابِ [13:30]

Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, (èyí tí) àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn, nítorí kí o lè máa kà fún wọn n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: “Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”

### الآية 13:31

> ﻿وَلَوْ أَنَّ قُرْآنًا سُيِّرَتْ بِهِ الْجِبَالُ أَوْ قُطِّعَتْ بِهِ الْأَرْضُ أَوْ كُلِّمَ بِهِ الْمَوْتَىٰ ۗ بَلْ لِلَّهِ الْأَمْرُ جَمِيعًا ۗ أَفَلَمْ يَيْأَسِ الَّذِينَ آمَنُوا أَنْ لَوْ يَشَاءُ اللَّهُ لَهَدَى النَّاسَ جَمِيعًا ۗ وَلَا يَزَالُ الَّذِينَ كَفَرُوا تُصِيبُهُمْ بِمَا صَنَعُوا قَارِعَةٌ أَوْ تَحُلُّ قَرِيبًا مِنْ دَارِهِمْ حَتَّىٰ يَأْتِيَ وَعْدُ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُخْلِفُ الْمِيعَادَ [13:31]

Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú Ƙur’ān, wọ́n fi mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn), tàbí wọ́n fi gélè (láti yanu), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn t’ó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn.

### الآية 13:32

> ﻿وَلَقَدِ اسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِنْ قَبْلِكَ فَأَمْلَيْتُ لِلَّذِينَ كَفَرُوا ثُمَّ أَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ عِقَابِ [13:32]

Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!

### الآية 13:33

> ﻿أَفَمَنْ هُوَ قَائِمٌ عَلَىٰ كُلِّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ ۗ وَجَعَلُوا لِلَّهِ شُرَكَاءَ قُلْ سَمُّوهُمْ ۚ أَمْ تُنَبِّئُونَهُ بِمَا لَا يَعْلَمُ فِي الْأَرْضِ أَمْ بِظَاهِرٍ مِنَ الْقَوْلِ ۗ بَلْ زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا مَكْرُهُمْ وَصُدُّوا عَنِ السَّبِيلِ ۗ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ [13:33]

Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ń mójútó ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí ó ṣe (dà bí ẹni tí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Síbẹ̀) ẹ tún bá Allāhu wá àwọn akẹgbẹ́ kan! Sọ pé: “Ẹ dárúkọ wọn ná.” Tàbí ẹ̀yin yóò fún (Allāhu) ní ìró ohun tí kò mọ̀ lórí ilẹ̀ tàbí (ẹ̀yin yóò pa) irọ́ funfun báláú ni? Wọ́n kúkú ti ṣe ète ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà òdodo. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sì níí sí olùtọ́sọ́nà kan fún un.

### الآية 13:34

> ﻿لَهُمْ عَذَابٌ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَشَقُّ ۖ وَمَا لَهُمْ مِنَ اللَّهِ مِنْ وَاقٍ [13:34]

Ìyà wà fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Ìyà ti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kúkú gbópọn jùlọ. Kò sì níí sì aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.

### الآية 13:35

> ﻿۞ مَثَلُ الْجَنَّةِ الَّتِي وُعِدَ الْمُتَّقُونَ ۖ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ أُكُلُهَا دَائِمٌ وَظِلُّهَا ۚ تِلْكَ عُقْبَى الَّذِينَ اتَّقَوْا ۖ وَعُقْبَى الْكَافِرِينَ النَّارُ [13:35]

Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (ni èyí tí) àwọn odò ń ṣàn kọjá nísàlẹ̀ rẹ̀. Èso rẹ̀ àti ibòji rẹ̀ yó sì máa wà títí láéláé. Ìyẹn ni ìkángun àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu). Iná sì ni ìkángun àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 13:36

> ﻿وَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَفْرَحُونَ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْكَ ۖ وَمِنَ الْأَحْزَابِ مَنْ يُنْكِرُ بَعْضَهُ ۚ قُلْ إِنَّمَا أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ اللَّهَ وَلَا أُشْرِكَ بِهِ ۚ إِلَيْهِ أَدْعُو وَإِلَيْهِ مَآبِ [13:36]

Àwọn tí A fún ní Tírà ń dunnú sí ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sì wà nínú àwọn ìjọ kèfèrí-parapọ̀ t’ó ń ṣe àtakò sí apá kan rẹ̀. Sọ pé: “N̄ǹkan tí Wọ́n pa mí láṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu. Èmi kò sì gbọdọ̀ wá akẹgbẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni mò ń pèpè sí. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”

### الآية 13:37

> ﻿وَكَذَٰلِكَ أَنْزَلْنَاهُ حُكْمًا عَرَبِيًّا ۚ وَلَئِنِ اتَّبَعْتَ أَهْوَاءَهُمْ بَعْدَمَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ مَا لَكَ مِنَ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا وَاقٍ [13:37]

Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní ìdájọ́ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. Dájúdájú tí o bá fi lè tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn, lẹ́yìn n̄ǹkan tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kò sí aláàbò àti olùṣọ́ kan fún ọ mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.

### الآية 13:38

> ﻿وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِنْ قَبْلِكَ وَجَعَلْنَا لَهُمْ أَزْوَاجًا وَذُرِّيَّةً ۚ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَنْ يَأْتِيَ بِآيَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ لِكُلِّ أَجَلٍ كِتَابٌ [13:38]

Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.1 Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.2 Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ l’ó ní àkọsílẹ̀.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
1 Kíyè sí i, àwọn kan ń sọ pé gbólóhùn yìí “Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.” ń tọ́ka sí pé “Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ ìyàwó, ó sì ti bímọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Nítorí náà, ó ti kú. Kò sì níí padà wá sáyé mọ́.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ fífi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀. Àti pé, ìrònú wọn nípa gbólóhùn náà jẹ́ ìrònú ọpọlọ lásán, kò sì sí ìtọ́sọ́nà nínú rẹ̀ nítorí àwọn ìdí pàtàkì márùn-ún wọ̀nyí: Ìdí àkọ́kọ́; Kò kọ́kọ́ sí tírà tafsīr àwọn onisunnah t’ó sọ pé gbólóhùn náà dúró fún pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ ìyàwó tàbí pé ó ti bímọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah l’ó ń fá ìtúmọ̀ gbólóhùn náà síbẹ̀. Ìdí kejì: Gbólóhùn náà dúró sórí àdámọ́ tí Allāhu fi sára gbogbo ọmọ Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kì í ṣe àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nìkan ni wọn yóò máa fẹ́ ìyàwó tàbí bímọ. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ṣe gbogbo ẹ̀dá t’ó wá sáyé l’ó rí ìyàwó fẹ́? Tàbí ṣe gbogbo ẹni t’ó sì rí ìyàwó fẹ́ l’ó rí ọmọ bí? Ìdí kẹta; Kì í ṣe nítorí ìfirinlẹ̀ pé kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun tí kò fẹ́ ìyàwó rí tàbí tí kò bímọ rí ni Allāhu fi mú ọ̀rọ̀ náà wá nítorí pé, ó wà nínú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ tí kò fẹ́ ìyàwó, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa bímọ. Àpẹẹrẹ ni Ànábì Yahya ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú sūrah āli-’Imrọ̄n 3:39. Ìdí kẹrin; Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbólóhùn náà fọ èsì fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni. Àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó ń sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní òdodo ni kò yẹ kó jẹ́ òjíṣẹ́ abara tí ó máa fẹ́ ìyàwó, kò sì yẹ fún un láti máa bímọ.”, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe mú ọ̀rọ̀ wọn wá nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:94. Ìdí karùn-ún: Ìbá jẹ́ pé āyah náà jẹmọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ni, ìbá tí sí hadīth kan kan t’ó máa fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Hadīth lórí ìpadàbọ̀ rẹ̀ kò sì mọ ní ẹyọ kan. Nítorí náà, ṣé àwọn t’ó ń lo gbólóhùn náà fún àìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé mọ ìtúmọ̀ al-Ƙur’ān ju Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ ni tàbí wọ́n kàn jẹ́ asòòkùn-sẹ́sìn ni?! 2 “àmì kan” nínú āyah yìí dúró fún ìyà kan tàbí ìparun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Òjíṣẹ́ náà. Kíyè sí i, “àmì kan” láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún lè jẹ́ “iṣẹ́ ìyanu” tàbí “ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”.

### الآية 13:39

> ﻿يَمْحُو اللَّهُ مَا يَشَاءُ وَيُثْبِتُ ۖ وَعِنْدَهُ أُمُّ الْكِتَابِ [13:39]

Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kí ni n̄ǹkan tí Allāhu ń parẹ́?. Ki sì ni n̄ǹkan tí Ó ń mú ṣẹ? Ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan náà. Àgbọ́yé kìíní tí ó tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ ni pé, āyah náà jẹ́ àlàyé fún āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀. Ìdí ni pé, āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀ ń tọ́ka sí bí ó ṣe jẹ́ pé ọjọ́ ìyà, tí ó jẹ́ “àmì kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā)”, èyí tí ó máa kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ti ṣe wà nínú àkọsílẹ̀. Āyah 39 yìí wá ń sọ pé ní ọjọ́kọ́jọ́ tí ìyà náà bá ń dé sí àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́rùn, ó ń bẹ nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó máa bá ìyà náà lọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tí ìyà náà yóò dá sí títí dí ọjọ́ mìíràn. Àti ẹni tí ó máa bá ìyà lọ àtí ẹni tí ọjọ́ ìyà rẹ̀ yóò sún ṣíwájú, gbogbo rẹ̀ ni ó kúkú ti wà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ, tí í ṣe àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá bá ìyà lọ ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá ru ìyà náà là títí di ọjọ́ mìíràn ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Lẹ́yìn àgbọ́yé yìí ní ọ̀rọ̀ kan àwọn àgbọ́yé tí ó dá āyah náà tú lọ́tọ̀, láì sopọ̀ mọ́ āyah 38.
Àgbọ́yé kejì: Inú àkọsílẹ̀ méjì ni kádàrá ẹ̀dá wà. Àkọsílẹ̀ kan wà lọ́dọ̀ àwọn mọlāika. Àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika ni àkọsílẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń gbé fún wọn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ní ọdọọdún nínú Òru Abiyì (Laelatul-Ƙọdr). Ìyípadà lè ṣẹlẹ̀ sí kádàrá ẹ̀dá nínú àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika nípa ki ohun titun tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ lórí àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá kan. Bákàn náà, àwọn àlámòrí kan lè wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín. Àkọsílẹ̀ kejì ni àkọsílẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àkọsílẹ̀ yìí l’ó kó gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá sínú tán pátápátá, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ẹ̀dá kò tí ì máa jẹ́ ẹ̀dá títí dé ìkángun ẹ̀dá nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra tàbí nínú Iná. Nínú àkọsílẹ̀ yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ń yọ àkọsílẹ̀ ọlọ́dọọdún fún àwọn mọlāika Rẹ̀. Nítorí náà, ohun titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ohun tí ó bá wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Àmọ́ àti ohun titun àti èyí tí kò titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika, ìkíní kejì l’ó wà bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. 
Àgbọ́yé kẹta: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, kí ọkùnrin kan ti máa tẹ̀lé àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìyapa àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìṣìnà àìgbàgbọ́. Onítọ̀ún ni ẹni tí Allāhu pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ nínú ìmọ̀nà. Irúfẹ́ ẹni yìí l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí Allāhu fí orúkọ rẹ̀ rinlẹ̀ sínú ìmọ̀nà ni kí ọkùnrin kan ti máa yapa àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìmọ̀nà ’Islām. Onítọ̀ún l’ó wà ní abẹ́ “wa yuthbit”. 
Àgbọ́yé kẹrin: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn mọlāika yóò máa kọ gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ̀dá sílẹ̀ ní ojoojúmọ́. Nígbà tí ó bá dí ọjọ́ Àlàmísì, wọn yóò yọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mo jẹ; mo mu; mo sùn; mo jí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ”. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’” Wọn yó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yòókù tí ó la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀dá. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé karùn-ún: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn āyah kan ń bẹ lásìkò tí al-Ƙur’ān ń sọ̀kalẹ̀ lọ́wọ́ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí Allāhu yóò pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ sì l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn āyah kan sì ń bẹ tí Allāhu kò níí pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ l’ó sì wà ní abẹ́ “wa yuthbit”. 
Àgbọ́yé kẹfà: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yóò máa ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan fún ẹ̀dá. Èyí sì ni "yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’". Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yó sì fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan mú ẹ̀dá. Èyí sì ni "wa yuthbit".
Gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí wà nínú tafsīr at-Tọbarīy. Nítorí náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí yíyí kádàrá ẹ̀dá padà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Ó sì kúkú ti rinlẹ̀ nínú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé: “ A ti gbé gègé sókè kúrò lórí kíkọ kádàrá. Àwọn àkọsílẹ̀ sì ti gbẹ.” Ìyẹn nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Èyí sì l’ó ko gbogbo kádàrá ẹ̀dá sínú pátápátá àti gbogbo àwọn tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w.). Fún ìdí èyí àdúà tí ẹ̀dá yóò ṣe àti ọ̀nà tí àdúà náà yó fi gbà, méjèèjì ti wà nínú kádàrá ẹ̀dá tí ó wà nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àti pé kò sí ẹ̀dá t’ó nímọ̀ èwo nínú àwọn oore ayé àti tọ̀run l’ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àdúà. Èyí jẹ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ní abala kan. Ó tún jẹ́ ọlá fún àdúà ṣíṣe lábala kan nítorí pé oore àdúà ọ̀tọ̀, oore ẹ̀bùn Ọlọ́hun ọ̀tọ̀. Nítorí náà, gbogbo gbígbà àdúà wà ní abẹ́ àkọsílẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti kọ lé ẹ̀dá lórí nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀.

### الآية 13:40

> ﻿وَإِنْ مَا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ الَّذِي نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِنَّمَا عَلَيْكَ الْبَلَاغُ وَعَلَيْنَا الْحِسَابُ [13:40]

Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), iṣẹ́-jíjẹ́ nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa.

### الآية 13:41

> ﻿أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا نَأْتِي الْأَرْضَ نَنْقُصُهَا مِنْ أَطْرَافِهَا ۚ وَاللَّهُ يَحْكُمُ لَا مُعَقِّبَ لِحُكْمِهِ ۚ وَهُوَ سَرِيعُ الْحِسَابِ [13:41]

Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọ inú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn)? Allāhu l’Ó ń ṣe ìdájọ́. Kò sí ẹnì kan tí ó lè dá ìdájọ́ Rẹ̀ padà (fún Un). Òun sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

### الآية 13:42

> ﻿وَقَدْ مَكَرَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ فَلِلَّهِ الْمَكْرُ جَمِيعًا ۖ يَعْلَمُ مَا تَكْسِبُ كُلُّ نَفْسٍ ۗ وَسَيَعْلَمُ الْكُفَّارُ لِمَنْ عُقْبَى الدَّارِ [13:42]

Dájúdájú àwọn t’ó ṣíwájú wọn déte. Ti Allāhu sì ni gbogbo ète pátápátá. Ó mọ ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ń ṣe níṣẹ́. Àti pé àwọn aláìgbàgbọ́ ń bọ̀ wá mọ ẹni tí àtubọ̀tán Ilé (rere) wà fún. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.

### الآية 13:43

> ﻿وَيَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَسْتَ مُرْسَلًا ۚ قُلْ كَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ وَمَنْ عِنْدَهُ عِلْمُ الْكِتَابِ [13:43]

Àwọn aláìgbàgbọ́ ń wí pé: “Ìwọ kì í ṣe Òjíṣẹ́.” Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹni tí ìmọ̀ Tírà ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/13.md)
- [كل تفاسير سورة الرعد
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/13.md)
- [ترجمات سورة الرعد
](https://quranpedia.net/translations/13.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/13/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
