---
title: "ترجمة سورة إبراهيم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/14/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/14/book/2001"
surah_id: "14"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة إبراهيم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/14/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة إبراهيم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/14/book/2001*.

Translation of Surah إبراهيم from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 14:1

> الر ۚ كِتَابٌ أَنْزَلْنَاهُ إِلَيْكَ لِتُخْرِجَ النَّاسَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِ رَبِّهِمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ [14:1]

’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè mú àwọn ènìyàn kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa wọn. (Wọn yó sì bọ́) sí ọ̀nà Alágbára, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí),

### الآية 14:2

> ﻿اللَّهِ الَّذِي لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَوَيْلٌ لِلْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ شَدِيدٍ [14:2]

Allāhu, Ẹni tí Ó ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ègbé ni fún àwọn aláìgbàgbọ́ níbi ìyà líle.

### الآية 14:3

> ﻿الَّذِينَ يَسْتَحِبُّونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا عَلَى الْآخِرَةِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ بَعِيدٍ [14:3]

Àwọn t’ó ń fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju tọ̀run, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́; àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà t’ó jìnnà.

### الآية 14:4

> ﻿وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ رَسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوْمِهِ لِيُبَيِّنَ لَهُمْ ۖ فَيُضِلُّ اللَّهُ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ [14:4]

A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè ìjọ rẹ̀1 nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.2
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
1 “Èdè ìjọ rẹ̀” nínú āyah yìí dúró fún “èdè abínibí rẹ̀” tàbí “èdè ìlú tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán an níṣẹ́ sí”. Èyí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà nítorí ìdí pàtàkì méjì. Ìdí àkọ́kọ́: Èdè abínibí Ànábì kọ̀ọ̀kan àti Òjíṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn níṣẹ́. Ìdí kejì: Ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.) ni Ọlọ́hun rán níṣẹ́ sí àwọn elédè abínibí rẹ̀ nìkan àyàfi Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo elédè rẹ̀ àti elédè mìíràn ni Allāhu rán Ànábì wa nìkan níṣẹ́ sí. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà ẹ̀wẹ̀, Allāhu kò fi èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè abínibí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rán an níṣẹ́. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Allāhu kò tìtorí àwọn elédè mìíràn t’ó wà láyìíká rẹ̀ fi èdè mìíràn kún èdè abínibí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú ìmísí Rẹ̀. Èdè abínibí rẹ̀ náà sì ni èdè Lárúbáwá. Dípò kí Allāhu tún lo èdè mìíràn fún ìmísí Rẹ̀ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àwọn ògbifọ̀ ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń lo nígbàkígbà tí iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ bá kan elédè mìíràn. Lẹ́yìn àlàyé yìí, àwọn n̄ǹkan mẹ́ta wọ̀nyí gbọ́dọ̀ yé wa dáradára. Àkọ́kọ́: Èyíkéyìí èdè tí ẹnikẹ́ni bá túmọ̀ al-Ƙur’ān sí, kò lè ṣe dọ́gba sí al-Ƙur’ān. Kò sì lè rọ́pò rẹ̀. Nítorí náà, tí àléébù kan tàbí òmíràn bá jẹyọ nínú iṣẹ́ atúmọ̀ èdè al-Ƙur’ān, kò kó àlèébú kan kan bá al-Ƙur’ān rárá tí àtúnṣe bá padà dé bá ìtúmọ̀-òdì náà nítorí pé ọ̀rọ̀ tí Allāhu sọ gẹ́lẹ́ sì wà nínú tákàǹdá tí kò yinjẹ. Kò sì túmọ̀ sí pé al-Ƙur’ān ti pé méjì lórí igbá. Ìkejì: Àwọn tírà sánmọ̀ mìíràn bíi Zabūr, Taorāt àti ’Injīl ti wọ ipò aláìsí nítorí pé kò sí ẹyọ kan nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí èdè ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀ (èdè ìfihàn rẹ̀) kò tí ì dòkú. Ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn akọ̀tàn nìkan l’ó kù wọ́n kù. Ìkẹta: Olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah tako bí ó ṣe jẹ́ pé èdè abínibí nìkan ni Allāhu fi máa ń bá ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sọ̀rọ̀. Mirza Ghulam Ahmad, ìyẹn olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah, parọ́ ńlá mọ́ Allāhu pé Allāhu fi èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè abínibí òun rán òun níṣẹ́ sáyé. Àpapọ̀ àwọn èdè náà sì jẹ́ mẹ́fà; èdè Gẹ̀ẹ́sì, Punjabi, Hébérù, Paṣian, Lárúbáwá àti Urudu. Èdè Urudu nìkan sì ni èdè abínibí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òpùrọ́ pọ́nńbélé t’ó pe ara rẹ̀ ní Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun sí gbogbo ayé ni ọ̀gbẹni náà, ó tún ti ṣàì gbàgbọ́ nínú āyah yìí “A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè ìjọ rẹ̀“. Kò sì wulẹ̀ tún sí ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí mímọ́ ti Allāhu mọ́ fún ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ikú Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àfi àwọn onímìísí èṣù bíi ti mirza Ghulam Ahmad, àwọn onisūfīy àti àwọn ẹlẹ́mìí-gbígbé. Allāhu là wá lọ́wọ́ gbogbo àwọn asòòkùn-sẹ́sìn. 
2 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:12.

### الآية 14:5

> ﻿وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا أَنْ أَخْرِجْ قَوْمَكَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ وَذَكِّرْهُمْ بِأَيَّامِ اللَّهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ [14:5]

A kúkú fi àwọn āyah Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ pé: “Mú ìjọ rẹ kúrò láti inú àwọn òkùnkùn bọ́ sínú ìmólẹ̀. Kí o sì rán wọn létí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu (lórí wọn).” Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.

### الآية 14:6

> ﻿وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ أَنْجَاكُمْ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ وَيُذَبِّحُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُمْ بَلَاءٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَظِيمٌ [14:6]

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé ẹ rántí ìkẹ́ Allāhu lórí yín nígbà tí Ó gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín; wọ́n ń dúnńbú àwọn ọmọkùnrin yín, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

### الآية 14:7

> ﻿وَإِذْ تَأَذَّنَ رَبُّكُمْ لَئِنْ شَكَرْتُمْ لَأَزِيدَنَّكُمْ ۖ وَلَئِنْ كَفَرْتُمْ إِنَّ عَذَابِي لَشَدِيدٌ [14:7]

(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa Ẹlẹ́dàá yín sọ ọ́ di mímọ̀ (fun yín pé): "Dájúdájú tí ẹ bá dúpẹ́, Èmi yóò ṣàlékún fun yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣàìmoore, dájúdájú ìyà Mi mà le."

### الآية 14:8

> ﻿وَقَالَ مُوسَىٰ إِنْ تَكْفُرُوا أَنْتُمْ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا فَإِنَّ اللَّهَ لَغَنِيٌّ حَمِيدٌ [14:8]

(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Tí ẹ bá ṣàìmoore, ẹ̀yin àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́."

### الآية 14:9

> ﻿أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَبَأُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ ۛ وَالَّذِينَ مِنْ بَعْدِهِمْ ۛ لَا يَعْلَمُهُمْ إِلَّا اللَّهُ ۚ جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَرَدُّوا أَيْدِيَهُمْ فِي أَفْوَاهِهِمْ وَقَالُوا إِنَّا كَفَرْنَا بِمَا أُرْسِلْتُمْ بِهِ وَإِنَّا لَفِي شَكٍّ مِمَّا تَدْعُونَنَا إِلَيْهِ مُرِيبٍ [14:9]

Ṣé ìró àwọn t’ó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n ti ọwọ́ wọn bọ ẹnu wọn (ní ti ìbínú), wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí."

### الآية 14:10

> ﻿۞ قَالَتْ رُسُلُهُمْ أَفِي اللَّهِ شَكٌّ فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يَدْعُوكُمْ لِيَغْفِرَ لَكُمْ مِنْ ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرَكُمْ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى ۚ قَالُوا إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا تُرِيدُونَ أَنْ تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُنَا فَأْتُونَا بِسُلْطَانٍ مُبِينٍ [14:10]

Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ pé: “Ṣé iyèméjì kan ń bẹ níbi (bíbẹ) Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó ń pè yín nítorí kí Ó lè forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín àti nítorí kí Ó lè lọ yín lára di gbèdéke àkókò kan.” Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan tayọ abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.”

### الآية 14:11

> ﻿قَالَتْ لَهُمْ رُسُلُهُمْ إِنْ نَحْنُ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَمُنُّ عَلَىٰ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۖ وَمَا كَانَ لَنَا أَنْ نَأْتِيَكُمْ بِسُلْطَانٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ [14:11]

Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: “Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fun yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé, Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

### الآية 14:12

> ﻿وَمَا لَنَا أَلَّا نَتَوَكَّلَ عَلَى اللَّهِ وَقَدْ هَدَانَا سُبُلَنَا ۚ وَلَنَصْبِرَنَّ عَلَىٰ مَا آذَيْتُمُونَا ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُتَوَكِّلُونَ [14:12]

Kí ni ó máa ṣe wá tí a ò níí gbáralé Allāhu, Ó kúkú ti fi àwọn ọ̀nà wa mọ̀ wá. Dájúdájú a máa ṣe sùúrù lórí ohun tí ẹ bá fi kó ìnira bá wa. Allāhu sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”

### الآية 14:13

> ﻿وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِرُسُلِهِمْ لَنُخْرِجَنَّكُمْ مِنْ أَرْضِنَا أَوْ لَتَعُودُنَّ فِي مِلَّتِنَا ۖ فَأَوْحَىٰ إِلَيْهِمْ رَبُّهُمْ لَنُهْلِكَنَّ الظَّالِمِينَ [14:13]

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn Òjíṣẹ́ wọn pé: “Dájúdájú àwa yóò le yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa tàbí kí ẹ kúkú padà sínú ẹ̀sìn wa.” Nígbà náà, Olúwa wọn fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn pé: “Dájúdájú A máa pa àwọn alábòsí run.

### الآية 14:14

> ﻿وَلَنُسْكِنَنَّكُمُ الْأَرْضَ مِنْ بَعْدِهِمْ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَافَ مَقَامِي وَخَافَ وَعِيدِ [14:14]

Dájúdájú A sì máa fun yín ní ibùgbé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn. ” Ìyẹn wà fún ẹni tí ó bá páyà ìdúró (níwájú) Mi, tí ó tún páyà ìlérí Mi.

### الآية 14:15

> ﻿وَاسْتَفْتَحُوا وَخَابَ كُلُّ جَبَّارٍ عَنِيدٍ [14:15]

Wọ́n sì tọrọ àrànṣe (Allāhu lórí ìjọ wọn). Gbogbo aláfojúdi, olóríkunkun sì pàdánù.

### الآية 14:16

> ﻿مِنْ وَرَائِهِ جَهَنَّمُ وَيُسْقَىٰ مِنْ مَاءٍ صَدِيدٍ [14:16]

Iná Jahanamọ ń bẹ lẹ́yìn (ìparun) rẹ̀; A ó sì máa fún un ní omi àwọyúnwẹ̀jẹ̀ mu.

### الآية 14:17

> ﻿يَتَجَرَّعُهُ وَلَا يَكَادُ يُسِيغُهُ وَيَأْتِيهِ الْمَوْتُ مِنْ كُلِّ مَكَانٍ وَمَا هُوَ بِمَيِّتٍ ۖ وَمِنْ وَرَائِهِ عَذَابٌ غَلِيظٌ [14:17]

Ó máa sáré mu ún díẹ̀díẹ̀, kò sì níí fẹ́ẹ̀ lè gbé e mì. (Ìnira) ikú yó sì máa yọ sí i ní gbogbo àyè, síbẹ̀ kò níí kú. Ìyà t’ó nípọn tún wà fún un lẹ́yìn rẹ̀.

### الآية 14:18

> ﻿مَثَلُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ ۖ أَعْمَالُهُمْ كَرَمَادٍ اشْتَدَّتْ بِهِ الرِّيحُ فِي يَوْمٍ عَاصِفٍ ۖ لَا يَقْدِرُونَ مِمَّا كَسَبُوا عَلَىٰ شَيْءٍ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الضَّلَالُ الْبَعِيدُ [14:18]

Àfiwé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn: àwọn iṣẹ́ wọn dà bí eérú tí atẹ́gùn fẹ́ dànù pátápátá ní ọjọ́ ìjì atẹ́gùn. Wọn kò ní agbára kan lórí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ìyẹn ni ìṣìnà t’ó jìnnà.

### الآية 14:19

> ﻿أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِنْ يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ [14:19]

Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo? Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.

### الآية 14:20

> ﻿وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ بِعَزِيزٍ [14:20]

Ìyẹn kò sì lè dá Allāhu lágara.

### الآية 14:21

> ﻿وَبَرَزُوا لِلَّهِ جَمِيعًا فَقَالَ الضُّعَفَاءُ لِلَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُنَّا لَكُمْ تَبَعًا فَهَلْ أَنْتُمْ مُغْنُونَ عَنَّا مِنْ عَذَابِ اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ ۚ قَالُوا لَوْ هَدَانَا اللَّهُ لَهَدَيْنَاكُمْ ۖ سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَجَزِعْنَا أَمْ صَبَرْنَا مَا لَنَا مِنْ مَحِيصٍ [14:21]

Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?” Wọn yóò wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa.”

### الآية 14:22

> ﻿وَقَالَ الشَّيْطَانُ لَمَّا قُضِيَ الْأَمْرُ إِنَّ اللَّهَ وَعَدَكُمْ وَعْدَ الْحَقِّ وَوَعَدْتُكُمْ فَأَخْلَفْتُكُمْ ۖ وَمَا كَانَ لِيَ عَلَيْكُمْ مِنْ سُلْطَانٍ إِلَّا أَنْ دَعَوْتُكُمْ فَاسْتَجَبْتُمْ لِي ۖ فَلَا تَلُومُونِي وَلُومُوا أَنْفُسَكُمْ ۖ مَا أَنَا بِمُصْرِخِكُمْ وَمَا أَنْتُمْ بِمُصْرِخِيَّ ۖ إِنِّي كَفَرْتُ بِمَا أَشْرَكْتُمُونِ مِنْ قَبْلُ ۗ إِنَّ الظَّالِمِينَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ [14:22]

Èṣù yó sì wí nígbà tí A bá ṣèdájọ́ (ẹ̀dá) tán, pé: “Dájúdájú Allāhu ṣe àdéhùn fun yín ní àdéhùn òdodo. Èmi náà ṣe àdéhùn fun yín. Mo sì yapa àdéhùn tí mo ṣe fun yín. Èmi kò sì ní agbára kan lórí yín bí kò ṣe pé mo pè yín ẹ sì jẹ́pè mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe bú mi; ara yín ni kí ẹ bú. Èmi kò lè ràn yín lọ́wọ́ (níbi ìyà), Ẹ̀yin náà kò sì lè ràn mí lọ́wọ́ (níbi ìyà). Dájúdájú èmi ti lòdì sí ohun tí ẹ fi sọ mí di akẹgbẹ́ Allāhu ṣíwájú.” Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn.

### الآية 14:23

> ﻿وَأُدْخِلَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا بِإِذْنِ رَبِّهِمْ ۖ تَحِيَّتُهُمْ فِيهَا سَلَامٌ [14:23]

Wọ́n sì máa mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni ‘àlàáfíà’.

### الآية 14:24

> ﻿أَلَمْ تَرَ كَيْفَ ضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا كَلِمَةً طَيِّبَةً كَشَجَرَةٍ طَيِّبَةٍ أَصْلُهَا ثَابِتٌ وَفَرْعُهَا فِي السَّمَاءِ [14:24]

Ṣé o ò rí bí Allāhu ti ṣàkàwé ọ̀rọ̀ dáadáa pẹ̀lú igi dáadáa, tí gbòǹgbò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tí ẹka rẹ̀ sì wà nínú sánmọ̀,

### الآية 14:25

> ﻿تُؤْتِي أُكُلَهَا كُلَّ حِينٍ بِإِذْنِ رَبِّهَا ۗ وَيَضْرِبُ اللَّهُ الْأَمْثَالَ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ [14:25]

tó sì ń so èso (jíjẹ) rẹ̀ ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀? Allāhu ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn àkàwé nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

### الآية 14:26

> ﻿وَمَثَلُ كَلِمَةٍ خَبِيثَةٍ كَشَجَرَةٍ خَبِيثَةٍ اجْتُثَّتْ مِنْ فَوْقِ الْأَرْضِ مَا لَهَا مِنْ قَرَارٍ [14:26]

Àkàwé ọ̀rọ̀ tí kò dára sì dà bí igi tí kò dára, tí wọ́n fà tu láti òkè lórí ilẹ̀, tí kò sì ní àyè kan lórí ilẹ̀.

### الآية 14:27

> ﻿يُثَبِّتُ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا بِالْقَوْلِ الثَّابِتِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۖ وَيُضِلُّ اللَّهُ الظَّالِمِينَ ۚ وَيَفْعَلُ اللَّهُ مَا يَشَاءُ [14:27]

Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ó sì máa ṣi àwọn alábòsí lọ́nà. Àti pé Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.

### الآية 14:28

> ﻿۞ أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ بَدَّلُوا نِعْمَتَ اللَّهِ كُفْرًا وَأَحَلُّوا قَوْمَهُمْ دَارَ الْبَوَارِ [14:28]

Ṣé o ò rí àwọn t’ó yí ìdẹ̀ra Allāhu padà sí àìgbàgbọ́, tí wọ́n sì mú ìjọ wọn gúnlẹ̀ sí ilé ìparun?

### الآية 14:29

> ﻿جَهَنَّمَ يَصْلَوْنَهَا ۖ وَبِئْسَ الْقَرَارُ [14:29]

Iná Jahanamọ ni wọn yóò gúnlẹ̀ sí; ibùgbé náà sì burú.

### الآية 14:30

> ﻿وَجَعَلُوا لِلَّهِ أَنْدَادًا لِيُضِلُّوا عَنْ سَبِيلِهِ ۗ قُلْ تَمَتَّعُوا فَإِنَّ مَصِيرَكُمْ إِلَى النَّارِ [14:30]

Wọ́n sọ (àwọn kan di) akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò nínú ẹ̀sìn Rẹ̀. Sọ pé: “Ẹ máa gbádùn ǹsó, nítorí pé dájúdájú àbọ̀ yín ni Iná.”

### الآية 14:31

> ﻿قُلْ لِعِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا يُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُنْفِقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا بَيْعٌ فِيهِ وَلَا خِلَالٌ [14:31]

Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò níí sí títà-rírà kan àti yíyan ọ̀rẹ́ kan nínú rẹ̀.

### الآية 14:32

> ﻿اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَأَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَكُمْ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ الْفُلْكَ لِتَجْرِيَ فِي الْبَحْرِ بِأَمْرِهِ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ الْأَنْهَارَ [14:32]

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì fi ń mú àwọn èso jáde; (ó jẹ́) arísìkí fun yín. Ó sì rọ ọkọ̀ ojú-omi fun yín kí ó lè rìn lójú omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Ó tún rọ àwọn odò fun yín.

### الآية 14:33

> ﻿وَسَخَّرَ لَكُمُ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ دَائِبَيْنِ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ [14:33]

Ó rọ òòrùn àti òṣùpá fun yín, tí méjèèjì ń rìn láì sinmi. Ó tún rọ òru àti ọ̀sán fun yín.

### الآية 14:34

> ﻿وَآتَاكُمْ مِنْ كُلِّ مَا سَأَلْتُمُوهُ ۚ وَإِنْ تَعُدُّوا نِعْمَتَ اللَّهِ لَا تُحْصُوهَا ۗ إِنَّ الْإِنْسَانَ لَظَلُومٌ كَفَّارٌ [14:34]

Àti pé Ó ń fun yín nínú gbogbo n̄ǹkan tí ẹ tọrọ lọ́dọ̀ Rẹ̀. Tí ẹ bá ṣe òǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú ènìyàn ni alábòsí aláìmoore.

### الآية 14:35

> ﻿وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ اجْعَلْ هَٰذَا الْبَلَدَ آمِنًا وَاجْنُبْنِي وَبَنِيَّ أَنْ نَعْبُدَ الْأَصْنَامَ [14:35]

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì mú èmi àti àwọn ọmọ mi jìnnà sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà.

### الآية 14:36

> ﻿رَبِّ إِنَّهُنَّ أَضْلَلْنَ كَثِيرًا مِنَ النَّاسِ ۖ فَمَنْ تَبِعَنِي فَإِنَّهُ مِنِّي ۖ وَمَنْ عَصَانِي فَإِنَّكَ غَفُورٌ رَحِيمٌ [14:36]

Olúwa mi, dájúdájú àwọn òrìṣà ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn sọnù. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé mi, dájúdájú òun ni ẹni mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa mi, dájúdájú Ìwọ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́.

### الآية 14:37

> ﻿رَبَّنَا إِنِّي أَسْكَنْتُ مِنْ ذُرِّيَّتِي بِوَادٍ غَيْرِ ذِي زَرْعٍ عِنْدَ بَيْتِكَ الْمُحَرَّمِ رَبَّنَا لِيُقِيمُوا الصَّلَاةَ فَاجْعَلْ أَفْئِدَةً مِنَ النَّاسِ تَهْوِي إِلَيْهِمْ وَارْزُقْهُمْ مِنَ الثَّمَرَاتِ لَعَلَّهُمْ يَشْكُرُونَ [14:37]

Olúwa wa, dájúdájú èmi wá ibùgbé fún àrọ́mọdọ́mọ mi sí ilẹ̀ àfonífojì, ilẹ̀ tí kò ní èso, nítòsí Ilé Rẹ Ọlọ́wọ̀. Olúwa wa, nítorí kí wọ́n lè kírun ni. Nítorí náà, jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn fà sọ́dọ̀ wọn. Kí O sì pèsè àwọn èso fún wọn nítorí kí wọ́n lè dúpẹ́ (fún Ọ).

### الآية 14:38

> ﻿رَبَّنَا إِنَّكَ تَعْلَمُ مَا نُخْفِي وَمَا نُعْلِنُ ۗ وَمَا يَخْفَىٰ عَلَى اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ [14:38]

Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O mọ ohun tí à ń fi pamọ́ àti ohun tí à ń ṣe àfihàn rẹ̀. Kò sì sí kiní kan nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀ t’ó pamọ́ fún Allāhu.

### الآية 14:39

> ﻿الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي وَهَبَ لِي عَلَى الْكِبَرِ إِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ ۚ إِنَّ رَبِّي لَسَمِيعُ الدُّعَاءِ [14:39]

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún mi ní ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ nígbà tí mo ti darúgbó. Dájúdájú, Olúwa mi ni Olùgbọ́ àdúà.

### الآية 14:40

> ﻿رَبِّ اجْعَلْنِي مُقِيمَ الصَّلَاةِ وَمِنْ ذُرِّيَّتِي ۚ رَبَّنَا وَتَقَبَّلْ دُعَاءِ [14:40]

Olúwa mi, ṣe èmi àti nínú àrọ́mọdọ́mọ mi ni olùkírun. Olúwa wa, kí O sì gba àdúà mi.

### الآية 14:41

> ﻿رَبَّنَا اغْفِرْ لِي وَلِوَالِدَيَّ وَلِلْمُؤْمِنِينَ يَوْمَ يَقُومُ الْحِسَابُ [14:41]

Olúwa mi, ṣàforíjìn fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọjọ́ tí ìṣírò-iṣẹ́ yóò ṣẹlẹ̀."

### الآية 14:42

> ﻿وَلَا تَحْسَبَنَّ اللَّهَ غَافِلًا عَمَّا يَعْمَلُ الظَّالِمُونَ ۚ إِنَّمَا يُؤَخِّرُهُمْ لِيَوْمٍ تَشْخَصُ فِيهِ الْأَبْصَارُ [14:42]

Má ṣe lérò pé Allāhu gbàgbé n̄ǹkan tí àwọn alábòsí ń ṣe níṣẹ́. Ó kàn ń lọ́ wọn lára dí ọjọ́ kan tí àwọn ojú yóò yọ síta ràngàndàn.

### الآية 14:43

> ﻿مُهْطِعِينَ مُقْنِعِي رُءُوسِهِمْ لَا يَرْتَدُّ إِلَيْهِمْ طَرْفُهُمْ ۖ وَأَفْئِدَتُهُمْ هَوَاءٌ [14:43]

Wọn yóò má sáré (lọ síbi àkójọ fún ìṣírò-iṣẹ́), wọn yóò gbé orí wọn sókè, ìpéǹpéjú wọn kò sì níí padà sọ́dọ̀ wọn, àwọn ọkàn wọn yó sì pa sófo pátápátá (fún ìbẹ̀rù).

### الآية 14:44

> ﻿وَأَنْذِرِ النَّاسَ يَوْمَ يَأْتِيهِمُ الْعَذَابُ فَيَقُولُ الَّذِينَ ظَلَمُوا رَبَّنَا أَخِّرْنَا إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ نُجِبْ دَعْوَتَكَ وَنَتَّبِعِ الرُّسُلَ ۗ أَوَلَمْ تَكُونُوا أَقْسَمْتُمْ مِنْ قَبْلُ مَا لَكُمْ مِنْ زَوَالٍ [14:44]

Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, àwọn t’ó ṣàbòsí yó sì wí pé: “Olúwa wa, lọ́ wa lára fún àsìkò díẹ̀ sí i, a máa jẹ́pè Rẹ, a sì máa tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́.” Ṣé ẹ̀yin kò ti búra ṣíwájú pé ẹ̀yin kò níí kúrò nílé ayé ni?

### الآية 14:45

> ﻿وَسَكَنْتُمْ فِي مَسَاكِنِ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ وَتَبَيَّنَ لَكُمْ كَيْفَ فَعَلْنَا بِهِمْ وَضَرَبْنَا لَكُمُ الْأَمْثَالَ [14:45]

Ẹ sì gbé nínú ibùgbé àwọn t’ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Ó sì hàn si yín bí A ti ṣe pẹ̀lú wọn. A tún fun yín ni àwọn àkàwé.

### الآية 14:46

> ﻿وَقَدْ مَكَرُوا مَكْرَهُمْ وَعِنْدَ اللَّهِ مَكْرُهُمْ وَإِنْ كَانَ مَكْرُهُمْ لِتَزُولَ مِنْهُ الْجِبَالُ [14:46]

Wọ́n kúkú ti dá ète wọn, ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ète wọn wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé (pẹ̀lú) ète wọn àpáta fẹ́ẹ̀ lè yẹ̀ lulẹ̀.

### الآية 14:47

> ﻿فَلَا تَحْسَبَنَّ اللَّهَ مُخْلِفَ وَعْدِهِ رُسُلَهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ ذُو انْتِقَامٍ [14:47]

Nítorí náà, má ṣe lérò pé Allāhu yóò yapa àdéhùn Rẹ̀ tí Ó ṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.

### الآية 14:48

> ﻿يَوْمَ تُبَدَّلُ الْأَرْضُ غَيْرَ الْأَرْضِ وَالسَّمَاوَاتُ ۖ وَبَرَزُوا لِلَّهِ الْوَاحِدِ الْقَهَّارِ [14:48]

Ní ọjọ́ tí A máa yí ilẹ̀ ayé padà sì n̄ǹkan mìíràn. (A máa yí) àwọn sánmọ̀ náà (padà. Àwọn ẹ̀dá) sì máa jáde (síwájú) Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

### الآية 14:49

> ﻿وَتَرَى الْمُجْرِمِينَ يَوْمَئِذٍ مُقَرَّنِينَ فِي الْأَصْفَادِ [14:49]

O sì máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí wọn yóò so wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn sínú sẹ́kẹ́sẹkẹ̀.

### الآية 14:50

> ﻿سَرَابِيلُهُمْ مِنْ قَطِرَانٍ وَتَغْشَىٰ وُجُوهَهُمُ النَّارُ [14:50]

Òjé Iná ni àwọn èwù wọn. Iná yó sì bo ojú wọn mọ́lẹ̀ bámúbámú

### الآية 14:51

> ﻿لِيَجْزِيَ اللَّهُ كُلَّ نَفْسٍ مَا كَسَبَتْ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ [14:51]

nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

### الآية 14:52

> ﻿هَٰذَا بَلَاغٌ لِلنَّاسِ وَلِيُنْذَرُوا بِهِ وَلِيَعْلَمُوا أَنَّمَا هُوَ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ وَلِيَذَّكَّرَ أُولُو الْأَلْبَابِ [14:52]

Èyí ni iṣẹ́-jíjẹ́ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè fi ṣe ìkìlọ̀, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé (Allāhu) Òun nìkan ni Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí, Ọ̀kan ṣoṣo, àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/14.md)
- [كل تفاسير سورة إبراهيم
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/14.md)
- [ترجمات سورة إبراهيم
](https://quranpedia.net/translations/14.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/14/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
