---
title: "ترجمة سورة مريم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/19/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/19/book/2001"
surah_id: "19"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة مريم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/19/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة مريم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/19/book/2001*.

Translation of Surah مريم from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 19:1

> كهيعص [19:1]

Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni sọ pé: “Fífi sūrah yìí sọrí Mọryam, ìyá Jésù Kristi àti fífi sūrah kẹta, ìyẹn sūrah āli ‘Imrọ̄n, sọrí mọ̀lẹ́bí Mọryam ti fi hàn kedere pé, kò sí irú Mọryam nínú àwọn ẹ̀dá nítorí pé, kò tún sí sūrah kan kan mọ́ nínú al-Ƙur’ān tí Allāhu fi sọrí obìnrin mìíràn.” Wọ́n tún fi kún un pé, “Ṣebí kò sí sūrah tí wọ́n fi sọrí ìyá Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí ìyàwó rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀.”
Èsì: Kí ni ìbátan orúkọ Mọryam, ìyá Jésù pẹ̀lú ìjọ́sìn fún Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo? Kò sí. Ọlọ́hun t’ó dá Mọryam, ìyá ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), Òun l’Ó ṣà á lẹ́ṣà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Ọlọ́hun kò ṣe Mọryam ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀. 
Dípò kí òye àwọn kristiẹni lọ síbi pé, tí kò bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ òdodo pọ́nńbélé t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, ìbá tí sọ àwọn òdodo wọ̀nyẹn nípa Mọryam, ìyá Jésù. Ṣebí wọ́n kúkú fi ẹnu àbùkù kan Mọryam, ìyá ‘Īsā nínú Bíbélì, níbi tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Josẹfu gbẹ́nàgbẹ́nà, ẹni tí wọ́n kà kún ọkọ rẹ̀? 
Tí ó bá jẹ́ pé fífi orúkọ sọrí sūrah kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé bá sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, kì í kúkú ṣe Mọryam nìkan ni ẹ̀dá tí wọ́n fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Kò sì pọn dandan láti rí orúkọ obìnrin mìíràn yàtọ̀ sí Mọryam nínú al-Ƙur’ān. Ṣebí ẹ̀dá ni Mọryam, ẹ̀dá ni àwọn mìíràn tí Allāhu fi sọrí àwọn sūrah ọ̀rọ̀ Rẹ̀. A kúkú rí sūrah Muhammad, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí sūrah Mọryam. Àmọ́, kò sí sūrah ‘Īsā. Níwọ̀n ìgbà tí kò sì sūrah ‘Īsā, tí kò sì tàbùkù Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), bẹ́ẹ̀ náà ni kò tàbùkù obìnrin kan kan tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú fi òdidi sūrah kan sọrí gbogbo àwọn obìnrin, ìyẹn “sūrah an-Nisā’”. Tún wò ó, kò sì sí sūrah àwọn ọkùnrin. Ǹjẹ́ èyí yọ àwọn ọkùnrin kúrò nípò tí Allāhu fi ṣe àjùlọ fún wa lórí àwọn obìnrin bí? Rárá.
Ẹ jẹ́ kí á bi àwọn kristiẹni léèrè ìbéèrè pé, ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó máa sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di olúwa àti olùgbàlà? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun ọmọ? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ kristiẹniti di ojúlówó ẹ̀sìn Ọlọ́hun, nígbà tí àwọn méjèèjì gan-an kò dá kristiẹniti mọ̀ lójú ayé wọn? 
Tí ó bá jẹ́ pé nítorí pé wọ́n fi sūrah kan sọrí Mọryam, ìyá ‘Īsā lágbára tayọ “fífẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́hun”, kí ni àwọn kristiẹni máa sọ nípa àwọn sūrah wọ̀nyí:
Sūrah al-Baƙọrah – sūrah 2, sūrah tí wọ́n fi sọrí màálù tí ìjọ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pa láti fi jí òkú dìde?
Sūrah an-Nahl – sūrah 16, sūrah tí wọ́n fi sọrí àwọn kòkòrò oyin?
Sūrah an-Naml – sūrah 27, sūrah tí wọ́n fi sọrí kòkòrò àwúrèbe (èèrà)?
Sūrah al-’Ankabūt – sūrah 29, sūrah tí wọ́n fi sọrí aláǹtakùn?
Sūrah al-Fīl – sūrah 105, sūrah tí wọ́n fi sọrí àwọn erin tí ìjọ Abraha gùn wá ja Kaabah lógun, àmọ́ tí Allāhu pa wọ́n rẹ́?
Ṣé sūrah Màálù sọ màálù di bùrọ̀dá ni tàbí súrah erin sọ erin di bàbá? Ṣé sūrah kòkòrò òyin sọ kòkòrò oyin di òrìṣà ni tàbí sūrah aláǹtakùn sọ aláǹtakùn di ọmọ ọlọ́hun ni? Rárá o!
Kókó ọ̀rọ̀ wa ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò pe Mọryam ní orúkọ kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tayọ olódodo. Bákan náà, ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam ní ẹ̀ṣà ènìyàn, àmọ́ tí Allāhu kò ṣe ìyá àti bàbá Ànábì wa bẹ́ẹ̀, kò sọ ọmọ Mọryam di olúwà àti olùgbàlà. Ìyá àti bàbá Ànábì ’Ibrọ̄him ńkọ́? Kò sí ẹni t’ó tàbùkù Ànábì ’Ibrọ̄hīm lórí ẹ̀sùn pé, wọn kò dárúkọ ìyá rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tàbí pé wọn kò fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ànábì Mūsā ńkọ́? Kò sí ẹni t’ó tàbùkù Ànábì Mūsā lórí ẹ̀sùn pé, wọn kò dárúkọ ìyá àti bàbá rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tàbí pé wọn kò fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. 
Tí wọ́n bá dárúkọ wọn nínú rẹ̀ ńkọ́ tàbí tí wọ́n bá fi orúkọ wọn sọrí àwọn sūrah kan nínú rẹ̀ ńkọ́, kí ni ìwọ̀nyí níí ṣe pẹ̀lú bí a ṣe fẹ́ jọ́sìn fún Allāhu? Bí a ṣe rí sūrah āli ‘Imrọ̄n, tí Allāhu fi sọrí ẹbí Mọryam, a kúkú rí sūrah Ƙuraeṣ, tí Allāhu fi sọrí ẹbí Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ ẹnikẹ́ni di ọmọ Ọlọ́hun. Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ ẹnikẹ́ni di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu. Ṣíṣa ẹ̀dá kan lẹ́ṣà kò sì sí lọ́wọ́ ẹ̀dá. Allāhu l’Ó ń ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. 
Kíyè sí i, tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fi orúkọ ẹ̀dá kan sọrí sūrah kan tàbí Ó dárúkọ ẹ̀dá kan nínú al-Ƙur’ān, n̄ǹkan mẹ́ta kan gbọ́dọ̀ yé wa nípa rẹ̀ dáadáa.
Ìkíní: Kò gbọ́dọ̀ sí ẹ̀sùn fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí dídárúkọ àti àìdárúkọ ẹnì kan nínú al-Ƙur’ān rẹ̀. Bí Ó ṣe fẹ́ l’Ó ṣe. 
Ìkejì: Òdodo tí kò ṣe é jà níyàn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa ẹ̀dá tí orúkọ rẹ̀ wà nínú al-Ƙur’ān nítorí pé, òdodo lọ̀rọ̀ Ọlọ́hun.
Ìkẹta: Ẹ̀kọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́ kọ́ wa lára ẹ̀dá Rẹ̀ náà ni orí ire tiwa nínú rẹ̀, kì í ṣe pé kí ẹnì kan wá lò ó lódì láti fi tako Ọlọ́hun.

### الآية 19:2

> ﻿ذِكْرُ رَحْمَتِ رَبِّكَ عَبْدَهُ زَكَرِيَّا [19:2]

(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀, (Ànábì) Zakariyyā.

### الآية 19:3

> ﻿إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ نِدَاءً خَفِيًّا [19:3]

(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.

### الآية 19:4

> ﻿قَالَ رَبِّ إِنِّي وَهَنَ الْعَظْمُ مِنِّي وَاشْتَعَلَ الرَّأْسُ شَيْبًا وَلَمْ أَكُنْ بِدُعَائِكَ رَبِّ شَقِيًّا [19:4]

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.

### الآية 19:5

> ﻿وَإِنِّي خِفْتُ الْمَوَالِيَ مِنْ وَرَائِي وَكَانَتِ امْرَأَتِي عَاقِرًا فَهَبْ لِي مِنْ لَدُنْكَ وَلِيًّا [19:5]

Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,

### الآية 19:6

> ﻿يَرِثُنِي وَيَرِثُ مِنْ آلِ يَعْقُوبَ ۖ وَاجْعَلْهُ رَبِّ رَضِيًّا [19:6]

(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi."

### الآية 19:7

> ﻿يَا زَكَرِيَّا إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَامٍ اسْمُهُ يَحْيَىٰ لَمْ نَجْعَلْ لَهُ مِنْ قَبْلُ سَمِيًّا [19:7]

Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A ò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀).

### الآية 19:8

> ﻿قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَكَانَتِ امْرَأَتِي عَاقِرًا وَقَدْ بَلَغْتُ مِنَ الْكِبَرِ عِتِيًّا [19:8]

Ó sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an."

### الآية 19:9

> ﻿قَالَ كَذَٰلِكَ قَالَ رَبُّكَ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٌ وَقَدْ خَلَقْتُكَ مِنْ قَبْلُ وَلَمْ تَكُ شَيْئًا [19:9]

(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”

### الآية 19:10

> ﻿قَالَ رَبِّ اجْعَلْ لِي آيَةً ۚ قَالَ آيَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ النَّاسَ ثَلَاثَ لَيَالٍ سَوِيًّا [19:10]

(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi."

### الآية 19:11

> ﻿فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوْمِهِ مِنَ الْمِحْرَابِ فَأَوْحَىٰ إِلَيْهِمْ أَنْ سَبِّحُوا بُكْرَةً وَعَشِيًّا [19:11]

Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.

### الآية 19:12

> ﻿يَا يَحْيَىٰ خُذِ الْكِتَابَ بِقُوَّةٍ ۖ وَآتَيْنَاهُ الْحُكْمَ صَبِيًّا [19:12]

Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré.

### الآية 19:13

> ﻿وَحَنَانًا مِنْ لَدُنَّا وَزَكَاةً ۖ وَكَانَ تَقِيًّا [19:13]

(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).

### الآية 19:14

> ﻿وَبَرًّا بِوَالِدَيْهِ وَلَمْ يَكُنْ جَبَّارًا عَصِيًّا [19:14]

(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa.

### الآية 19:15

> ﻿وَسَلَامٌ عَلَيْهِ يَوْمَ وُلِدَ وَيَوْمَ يَمُوتُ وَيَوْمَ يُبْعَثُ حَيًّا [19:15]

Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).

### الآية 19:16

> ﻿وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ مَرْيَمَ إِذِ انْتَبَذَتْ مِنْ أَهْلِهَا مَكَانًا شَرْقِيًّا [19:16]

Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn.

### الآية 19:17

> ﻿فَاتَّخَذَتْ مِنْ دُونِهِمْ حِجَابًا فَأَرْسَلْنَا إِلَيْهَا رُوحَنَا فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرًا سَوِيًّا [19:17]

Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:45.

### الآية 19:18

> ﻿قَالَتْ إِنِّي أَعُوذُ بِالرَّحْمَٰنِ مِنْكَ إِنْ كُنْتَ تَقِيًّا [19:18]

(Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù Allāhu, ìbẹ̀rù Allāhu kò níí jẹ́ kí o ṣe aburú tí mò ń ṣọ́ra fún lọ́dọ̀ rẹ.

### الآية 19:19

> ﻿قَالَ إِنَّمَا أَنَا رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَامًا زَكِيًّا [19:19]

(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni ń sọ pé Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ni al-Ƙur’ān pè ní “ẹni mímọ́” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah yìí. Èsì ní ṣókí ni pé, ní òdodo ẹni mímọ́ ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kì í ṣe òun nìkan ni ẹni mímọ́. Āayah 13 nínú sūrah yìí kan náà pe Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹni mímọ́. Bákan náà, ọmọ tí àsọọ́lẹ̀ wáyé lórí rẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 17:81, ẹni mímọ́ ni al-Ƙur’ān pe òun náà. Báwo ni jíjẹ́ ẹni mímọ́ Jésù ṣe máa sọ ọ́ di olúwa àti olùgbàlà nígbà tí jíjẹ́ ẹni mímọ́ àwọn méjèèjì wọ̀nyẹn kò sọ wọ́n di bẹ́ẹ̀. Sì kíyè sì i, gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nínú al-Ƙur’ān ni ẹni mímọ́. Àti pé ìdà kejì ẹni mímọ́ ni ẹni àìmọ́. Báwo ni Ọlọ́hun ṣe máa fi iṣẹ́ mímọ́ rán ẹni àìmọ́? Kò lè ṣẹlẹ̀. Ṣíwájú sí i, nínú èdè Lárúbáwá, ìsọdorúkọ olùṣe fún “ẹni mímọ́” ni “zakiyyun”, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ fún “mímọ́” ni “zakāt”. Ìgbà tí ìròyìn bá bùáyà tán lára ẹni tí a fẹ́ pọ́n ní àpọ́npo, dípò kí Lárúbáwá lo ìsọdorúkọ olùṣe fún irú ẹni náà, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ ni wọ́n máa lò. Ìyẹn ni pé, jíjẹ́ ẹni mímọ́ t’ó lágbára gan-an ni ìlò èdè tí aL-Ƙur’ān lò fún Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ọmọ alásọọ́lẹ̀ náà. Àfijọ èyí nínú ìlò èdè Yorùbá, bí àpẹẹrẹ, ni ìyàtọ̀ t’ó wà láààrin kí á pe ẹni kan ní olówó àti owó. Nígbà tí owó olówó kan bá ń pe àwọn olówó ńláńlá ránṣẹ́, l’a máa pe ẹni náà pé “Owó ni lágbájá.” Ta wá ni ó mọ́ jùlọ láààrin “zakiyyu” t’ó túmọ̀ sí “ẹni mímọ́” àti “zakāt” t’ó túmọ̀ sí “mímọ́”? Kò wa tán bí!

### الآية 19:20

> ﻿قَالَتْ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَلَمْ يَمْسَسْنِي بَشَرٌ وَلَمْ أَكُ بَغِيًّا [19:20]

Ó sọ pé: "Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè."

### الآية 19:21

> ﻿قَالَ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٌ ۖ وَلِنَجْعَلَهُ آيَةً لِلنَّاسِ وَرَحْمَةً مِنَّا ۚ وَكَانَ أَمْرًا مَقْضِيًّا [19:21]

(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn l’ó máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí.”

### الآية 19:22

> ﻿۞ فَحَمَلَتْهُ فَانْتَبَذَتْ بِهِ مَكَانًا قَصِيًّا [19:22]

Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan t’ó jìnnà.

### الآية 19:23

> ﻿فَأَجَاءَهَا الْمَخَاضُ إِلَىٰ جِذْعِ النَّخْلَةِ قَالَتْ يَا لَيْتَنِي مِتُّ قَبْلَ هَٰذَا وَكُنْتُ نَسْيًا مَنْسِيًّا [19:23]

Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”

### الآية 19:24

> ﻿فَنَادَاهَا مِنْ تَحْتِهَا أَلَّا تَحْزَنِي قَدْ جَعَلَ رَبُّكِ تَحْتَكِ سَرِيًّا [19:24]

Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ.

### الآية 19:25

> ﻿وَهُزِّي إِلَيْكِ بِجِذْعِ النَّخْلَةِ تُسَاقِطْ عَلَيْكِ رُطَبًا جَنِيًّا [19:25]

Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ.

### الآية 19:26

> ﻿فَكُلِي وَاشْرَبِي وَقَرِّي عَيْنًا ۖ فَإِمَّا تَرَيِنَّ مِنَ الْبَشَرِ أَحَدًا فَقُولِي إِنِّي نَذَرْتُ لِلرَّحْمَٰنِ صَوْمًا فَلَنْ أُكَلِّمَ الْيَوْمَ إِنْسِيًّا [19:26]

Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: "Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, mi ò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní."

### الآية 19:27

> ﻿فَأَتَتْ بِهِ قَوْمَهَا تَحْمِلُهُ ۖ قَالُوا يَا مَرْيَمُ لَقَدْ جِئْتِ شَيْئًا فَرِيًّا [19:27]

Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: "Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá.

### الآية 19:28

> ﻿يَا أُخْتَ هَارُونَ مَا كَانَ أَبُوكِ امْرَأَ سَوْءٍ وَمَا كَانَتْ أُمُّكِ بَغِيًّا [19:28]

Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè."

### الآية 19:29

> ﻿فَأَشَارَتْ إِلَيْهِ ۖ قَالُوا كَيْفَ نُكَلِّمُ مَنْ كَانَ فِي الْمَهْدِ صَبِيًّا [19:29]

Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni t’ó wà lórí ìtẹ́, t’ó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”

### الآية 19:30

> ﻿قَالَ إِنِّي عَبْدُ اللَّهِ آتَانِيَ الْكِتَابَ وَجَعَلَنِي نَبِيًّا [19:30]

(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: "Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ni Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹrú Allāhu ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ àwọn kristiẹni kò gbàgbọ́ pé ẹrú Allāhu ni. Wọ́n ní, “ọmọ Ọlọ́hun ni.” Kódà àwọn náà sọra wọn di ọmọ Ọlọ́hun. Kí ni ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò sí ọ̀rọ̀ mìíràn fún ìdàkejì ẹrú bí kò ṣe “ọmọ”. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “Bí ẹrú bá pẹ́ títí ẹrú á dọmọ”. Dọmọ ta ni? Ẹrú a dọmọ bàbá rẹ̀ nítorí pé, “ọ̀nà ló jìn, ẹrú ní baba”. Kí wá ni ọ̀rọ̀ mìíràn fún “ọmọ”? Ọmọ ni ẹni tí kò sí lóko-ẹrú. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ mìíràn fún ọmọ àti òbí tí kò sí lóko ẹrú ni “olómìnira”.
Ní ọ̀dọ̀ àwa mùsùlùmí, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” nìyí: “Ẹ̀dá tí ó ń tẹ̀lé ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn t’ó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn, ó ti sọra rẹ̀ di ẹrú rẹ̀, láì la wíwà ní oko-ẹrú lọ bíi ti ẹrú àfowórà tàbí ẹrú ogun. Èyí fi hàn pé, ẹrú ẹ̀dá yàtọ̀ sí ẹrú Ọlọ́hun. 
Àwọn òǹkọ-bíbèlí mọ̀ọ́mọ̀ yọ “ẹrú Ọlọ́hun” kúrò nínú bíbélì òde-òní. Wọ́n sì fi “ọmọ Ọlọ́hun” rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe lè sin òkú àbòsí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò níí yọ sílẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi rí ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” kà nínú ìwé Róòmù 7:25 báyìí pé: “So then, with my mind I am a slave to the law of God, but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà, pẹ̀lú ẹ̀mí mi, ẹrú ni mi sí òfin Ọlọ́hun, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹran ara mi, ẹrú ni mi sí òfin ẹ̀ṣẹ̀. (New Revised Standard Version àti New International Version) Ìyẹn ni pé, tí ìwọ bá tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin Ọlọ́hun. Tí ìwọ bá sì tẹ̀lé òfin ẹ̀ṣẹ̀, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Jésù Kristi ti tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú Ọlọ́hun ni Jésù Kristi. Tàbí ẹnu àwọn kristiẹni gbà á láti sọ pé Jésù Kristi kò lo òfin àti ìlànà Ọlọ́hun? Rárá. Tàbí ẹnu àwọn kristiẹni gbà á láti sọ pé òfin ẹ̀ṣẹ̀ ni Jésù Kristi tẹ̀lé? Rárá. Kò kúkú sí ìkẹta, lẹ́yìn òfin Ọlọ́hun, òfin èṣù ló tún kù. Jésù Kristi kò sì lo òfin Èṣù rí nínú ayé rẹ̀.
Àwa mùsùlùmí kú orí ire. Ọpẹ́ sì ni fún Ọlọ́hun t’ó jẹ́ kí á dá bàbá wa mọ̀ lọ́tọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́hun. Bákan náà, ẹ̀rù kò bà wá láti pe ara wa ní ẹrú Ọlọ́hun níbikíbi nítorí pé, pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn, ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn, Olùgba-ìrònúpìwàdà sì ni Allāhu.

### الآية 19:31

> ﻿وَجَعَلَنِي مُبَارَكًا أَيْنَ مَا كُنْتُ وَأَوْصَانِي بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ مَا دُمْتُ حَيًّا [19:31]

Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé).

### الآية 19:32

> ﻿وَبَرًّا بِوَالِدَتِي وَلَمْ يَجْعَلْنِي جَبَّارًا شَقِيًّا [19:32]

(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú.

### الآية 19:33

> ﻿وَالسَّلَامُ عَلَيَّ يَوْمَ وُلِدْتُ وَيَوْمَ أَمُوتُ وَيَوْمَ أُبْعَثُ حَيًّا [19:33]

Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)."

### الآية 19:34

> ﻿ذَٰلِكَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ ۚ قَوْلَ الْحَقِّ الَّذِي فِيهِ يَمْتَرُونَ [19:34]

Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasara) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.

### الآية 19:35

> ﻿مَا كَانَ لِلَّهِ أَنْ يَتَّخِذَ مِنْ وَلَدٍ ۖ سُبْحَانَهُ ۚ إِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ [19:35]

Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

### الآية 19:36

> ﻿وَإِنَّ اللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُسْتَقِيمٌ [19:36]

Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

### الآية 19:37

> ﻿فَاخْتَلَفَ الْأَحْزَابُ مِنْ بَيْنِهِمْ ۖ فَوَيْلٌ لِلَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ مَشْهَدِ يَوْمٍ عَظِيمٍ [19:37]

Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasara) sì yapa ẹnu (sí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba lọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde).

### الآية 19:38

> ﻿أَسْمِعْ بِهِمْ وَأَبْصِرْ يَوْمَ يَأْتُونَنَا ۖ لَٰكِنِ الظَّالِمُونَ الْيَوْمَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [19:38]

Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa! Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ kò bá lo ìgbọ́rọ̀ wọn fún gbígbọ́ òdodo, tí wọn kò sì lo ìríran wọn fún rírí òdodo ní ilé ayé yìí, wọn yóò fi ìgbọ́rọ̀ wọn gbọ́ òdodo ketekete, wọn yó sì fi ìríran wọn rí òdodo kedere pẹ̀lú àbámọ̀ ní ọ̀run nítorí pé, Ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ náà.

### الآية 19:39

> ﻿وَأَنْذِرْهُمْ يَوْمَ الْحَسْرَةِ إِذْ قُضِيَ الْأَمْرُ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ وَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ [19:39]

Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́.

### الآية 19:40

> ﻿إِنَّا نَحْنُ نَرِثُ الْأَرْضَ وَمَنْ عَلَيْهَا وَإِلَيْنَا يُرْجَعُونَ [19:40]

Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.

### الآية 19:41

> ﻿وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِبْرَاهِيمَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صِدِّيقًا نَبِيًّا [19:41]

Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.

### الآية 19:42

> ﻿إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ يَا أَبَتِ لِمَ تَعْبُدُ مَا لَا يَسْمَعُ وَلَا يُبْصِرُ وَلَا يُغْنِي عَنْكَ شَيْئًا [19:42]

Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan.

### الآية 19:43

> ﻿يَا أَبَتِ إِنِّي قَدْ جَاءَنِي مِنَ الْعِلْمِ مَا لَمْ يَأْتِكَ فَاتَّبِعْنِي أَهْدِكَ صِرَاطًا سَوِيًّا [19:43]

Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́.

### الآية 19:44

> ﻿يَا أَبَتِ لَا تَعْبُدِ الشَّيْطَانَ ۖ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلرَّحْمَٰنِ عَصِيًّا [19:44]

Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé.

### الآية 19:45

> ﻿يَا أَبَتِ إِنِّي أَخَافُ أَنْ يَمَسَّكَ عَذَابٌ مِنَ الرَّحْمَٰنِ فَتَكُونَ لِلشَّيْطَانِ وَلِيًّا [19:45]

Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná)."

### الآية 19:46

> ﻿قَالَ أَرَاغِبٌ أَنْتَ عَنْ آلِهَتِي يَا إِبْرَاهِيمُ ۖ لَئِنْ لَمْ تَنْتَهِ لَأَرْجُمَنَّكَ ۖ وَاهْجُرْنِي مَلِيًّا [19:46]

(Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná.”

### الآية 19:47

> ﻿قَالَ سَلَامٌ عَلَيْكَ ۖ سَأَسْتَغْفِرُ لَكَ رَبِّي ۖ إِنَّهُ كَانَ بِي حَفِيًّا [19:47]

(’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi.

### الآية 19:48

> ﻿وَأَعْتَزِلُكُمْ وَمَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَأَدْعُو رَبِّي عَسَىٰ أَلَّا أَكُونَ بِدُعَاءِ رَبِّي شَقِيًّا [19:48]

Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi."

### الآية 19:49

> ﻿فَلَمَّا اعْتَزَلَهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ ۖ وَكُلًّا جَعَلْنَا نَبِيًّا [19:49]

Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Hūd; 11:71.

### الآية 19:50

> ﻿وَوَهَبْنَا لَهُمْ مِنْ رَحْمَتِنَا وَجَعَلْنَا لَهُمْ لِسَانَ صِدْقٍ عَلِيًّا [19:50]

Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì ní kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa.

### الآية 19:51

> ﻿وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ مُوسَىٰ ۚ إِنَّهُ كَانَ مُخْلَصًا وَكَانَ رَسُولًا نَبِيًّا [19:51]

Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.

### الآية 19:52

> ﻿وَنَادَيْنَاهُ مِنْ جَانِبِ الطُّورِ الْأَيْمَنِ وَقَرَّبْنَاهُ نَجِيًّا [19:52]

A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀.

### الآية 19:53

> ﻿وَوَهَبْنَا لَهُ مِنْ رَحْمَتِنَا أَخَاهُ هَارُونَ نَبِيًّا [19:53]

Láti inú ìkẹ́ Wa A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ.

### الآية 19:54

> ﻿وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِسْمَاعِيلَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صَادِقَ الْوَعْدِ وَكَانَ رَسُولًا نَبِيًّا [19:54]

Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.

### الآية 19:55

> ﻿وَكَانَ يَأْمُرُ أَهْلَهُ بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ وَكَانَ عِنْدَ رَبِّهِ مَرْضِيًّا [19:55]

Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀.

### الآية 19:56

> ﻿وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِدْرِيسَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صِدِّيقًا نَبِيًّا [19:56]

Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.

### الآية 19:57

> ﻿وَرَفَعْنَاهُ مَكَانًا عَلِيًّا [19:57]

A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀).

### الآية 19:58

> ﻿أُولَٰئِكَ الَّذِينَ أَنْعَمَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ مِنَ النَّبِيِّينَ مِنْ ذُرِّيَّةِ آدَمَ وَمِمَّنْ حَمَلْنَا مَعَ نُوحٍ وَمِنْ ذُرِّيَّةِ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْرَائِيلَ وَمِمَّنْ هَدَيْنَا وَاجْتَبَيْنَا ۚ إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُ الرَّحْمَٰنِ خَرُّوا سُجَّدًا وَبُكِيًّا ۩ [19:58]

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún.

### الآية 19:59

> ﻿۞ فَخَلَفَ مِنْ بَعْدِهِمْ خَلْفٌ أَضَاعُوا الصَّلَاةَ وَاتَّبَعُوا الشَّهَوَاتِ ۖ فَسَوْفَ يَلْقَوْنَ غَيًّا [19:59]

Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn yòdòyìndìn ẹ̀mí. Láìpẹ́ wọn máa pàdé ìparun (nínú Iná).

### الآية 19:60

> ﻿إِلَّا مَنْ تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَأُولَٰئِكَ يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ وَلَا يُظْلَمُونَ شَيْئًا [19:60]

Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn.

### الآية 19:61

> ﻿جَنَّاتِ عَدْنٍ الَّتِي وَعَدَ الرَّحْمَٰنُ عِبَادَهُ بِالْغَيْبِ ۚ إِنَّهُ كَانَ وَعْدُهُ مَأْتِيًّا [19:61]

(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn sí ìpamọ́ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ.

### الآية 19:62

> ﻿لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا إِلَّا سَلَامًا ۖ وَلَهُمْ رِزْقُهُمْ فِيهَا بُكْرَةً وَعَشِيًّا [19:62]

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.

### الآية 19:63

> ﻿تِلْكَ الْجَنَّةُ الَّتِي نُورِثُ مِنْ عِبَادِنَا مَنْ كَانَ تَقِيًّا [19:63]

Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa.

### الآية 19:64

> ﻿وَمَا نَتَنَزَّلُ إِلَّا بِأَمْرِ رَبِّكَ ۖ لَهُ مَا بَيْنَ أَيْدِينَا وَمَا خَلْفَنَا وَمَا بَيْنَ ذَٰلِكَ ۚ وَمَا كَانَ رَبُّكَ نَسِيًّا [19:64]

Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yìí. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbé.

### الآية 19:65

> ﻿رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا فَاعْبُدْهُ وَاصْطَبِرْ لِعِبَادَتِهِ ۚ هَلْ تَعْلَمُ لَهُ سَمِيًّا [19:65]

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀?

### الآية 19:66

> ﻿وَيَقُولُ الْإِنْسَانُ أَإِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيًّا [19:66]

Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, Wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”

### الآية 19:67

> ﻿أَوَلَا يَذْكُرُ الْإِنْسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِنْ قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئًا [19:67]

Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan?

### الآية 19:68

> ﻿فَوَرَبِّكَ لَنَحْشُرَنَّهُمْ وَالشَّيَاطِينَ ثُمَّ لَنُحْضِرَنَّهُمْ حَوْلَ جَهَنَّمَ جِثِيًّا [19:68]

Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀.

### الآية 19:69

> ﻿ثُمَّ لَنَنْزِعَنَّ مِنْ كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمْ أَشَدُّ عَلَى الرَّحْمَٰنِ عِتِيًّا [19:69]

Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan èyíkéyìí nínú wọn tí ó le jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé.

### الآية 19:70

> ﻿ثُمَّ لَنَحْنُ أَعْلَمُ بِالَّذِينَ هُمْ أَوْلَىٰ بِهَا صِلِيًّا [19:70]

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó lẹ́tọ̀ọ́ sí wíwọ inú Iná.

### الآية 19:71

> ﻿وَإِنْ مِنْكُمْ إِلَّا وَارِدُهَا ۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتْمًا مَقْضِيًّا [19:71]

Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀. Ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ dandan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

### الآية 19:72

> ﻿ثُمَّ نُنَجِّي الَّذِينَ اتَّقَوْا وَنَذَرُ الظَّالِمِينَ فِيهَا جِثِيًّا [19:72]

Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nígbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” bíi “A” tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ bíi “Àwa” fún Ara Rẹ̀, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àpọ́nlé fún Un, kì í ṣe pé Ẹni t’Ó ń jẹ́ “Allāhu” pé méjì tàbí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ “ọ̀pọ̀” náà ń dúró fún iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń dá ṣe pẹ̀lú gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀” tàbí iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa yan àwọn mọlāika Rẹ̀ láti ṣe. Ní ti āyah 68 àti 69, àwọn mọlāika ni Allāhu máa pàṣẹ iṣẹ́ wọ̀nyẹn fún lọ́jọ́ Àjíǹde. Àwọn mọlāika náà sì ni ẹ̀ṣọ́ Ina. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah at-Tahrim; 66:6 àti sūrah al-Mudaththir; 74:30-31. Bákan náà, kalmọh “wārid” t’ó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ méjì péré l’ó wà fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd; 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98-100. “Warada” tún túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, àmọ́ kò wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:23. Ìtúmọ̀ méjèèjì wọ̀nyí ti fi hàn kedere pé kò sí ẹ̀dá tí kò níí dé ibi tí Iná wà lọ́jọ́ Àjíǹde. Àmọ́ àwọn kan máa “débẹ̀ wọbẹ̀”, àwọn kan sì máa “débẹ̀ láì wọbẹ̀”. Ìdí tí gbogbo ẹ̀dá máa fi dé ibi tí Iná wà ni pé, ojú ọ̀nà tí a máa tọ̀ dé ibi tí Ọgbà Ìdẹ̀ra wà ni Iná wà. Ìsàlẹ̀ lọ́wọ́ iwájú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni Allāhu fi àyè Iná sí. Kódà, ọ̀nà tí a máa tọ̀ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sì jẹ́ afárá tẹ́ẹ́rẹ́ yíyọ̀ lórí Iná. Igun mẹ́ta sì ni àwọn ènìyàn àti àlùjọ̀nnú máa pín sí lórí ìrìn wọn lórí afárá Iná. Igun kìíní ni àwọn Ànábì, àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.) àti àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, t’ó máa rìn lórí afárá Iná láì níí jábọ́ sínú Iná títí wọ́n fi máa gúnlẹ̀ sínú ilé ìgbàlà wọn, Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Kí Allāhu fi àánú Rẹ̀ ta wá lọ́rẹ àrìnyè náà.). Igun yìí ni Allāhu ti ṣe àforíjìn fún pátápátá lórí àṣìṣe wọn. Ṣebí kò sí bí a ó ṣe rìn tí orí kò níí mì lọ̀rọ̀ ẹ̀dá nílé ayé. Allāhu sì ni Aláforíjìn ẹ̀dá. Igun kìíní yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa wọn nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:101-102 àti sūrah az-Zumọr; 39:61. Igun kejì ni àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, t’ó máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́ sínú Iná. Igun yìí ni wọ́n ní àwọn àṣìṣe kan lọ́rùn, àmọ́ tí Allāhu kò forí rẹ̀ jìn wọ́n. Sebí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú ti sọ pé kí ẹni tí ó bá ń dá ẹṣẹ̀, tí kò tọrọ àforíjìn tàbí ronú pìwàdà lórí rẹ̀ títí ó fi kú má ṣe fọkàn balẹ̀ pé Òun kúkú máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fìyà ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:116. Igun kejì yìí l’ó máa padà jáde kúrò nínú Iná lásìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́, yálà nípasẹ̀ ìṣìpẹ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí nípasẹ̀ àánú àti ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Igun kẹta ni igun gbogbo ẹni tí ó kú sórí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹbọ tàbí ìṣojúméjì pẹ̀lú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Igun kẹta yìí náà máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́, àmọ́ wọn kò níí jáde kúrò nínú rẹ̀ títí láéláé nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí ṣíjú àánú wò wọ́n rárá. Nítorí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí Iná kò níí jó nítorí gbólóhùn “wa ’in minkum ’illā wāriduhā”, ẹni náà ti sọ̀rọ̀ àìmọ̀kan t’ó gbópọn lẹnu nítorí pé, ó ti fi ìtúmọ̀ “warada” mọ sórí “ó débẹ̀ wọbẹ̀” nìkan, ó sì kọ̀yìn sí ìtúmọ̀ “warada” t’ó túmọ̀ sí “ó débẹ̀ kò wọbẹ̀”. Irú ẹni náà sì súnmọ́ kí ó jẹ́ kristiẹni, olùṣìnà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó bá sọ pé kò sí igun kan kan tí ó máa padà jáde kúrò nínú Iná. Kò sí ẹni tí ó máa sọ bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí ó máa wà nínú Iná gbére, irú ẹni náà ti sọ ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah t’ó ń fi Iná gbere rinlẹ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́. Irú ẹni náà súnmọ́ k’ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah. 
Lẹ́yìn náà, yálà igun tí ó máa rin àrìnyè lórí afárá Iná tàbí igun tí ó máa rin àrìnjábọ́ sínú Inȧ, igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé, àwọn mọlāika kan l’ó máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé, kò sí ẹ̀dá kan t’ó máa fẹ́ fínnú fíndọ̀ gba orí afárá Iná kọjá. Dándan sì ni fún gbogbo wọn láti gba orí rẹ̀ kọjá bọ́ sí àyè wọn. Àwọn mọlāika wọ̀nyẹn ni àwọn mọlāika agbèrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àwọn mọlāika agbèrò Iná. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún fi rinlẹ̀ nínú sūrah az-Zumọr; 39:71-73.

### الآية 19:73

> ﻿وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا أَيُّ الْفَرِيقَيْنِ خَيْرٌ مَقَامًا وَأَحْسَنُ نَدِيًّا [19:73]

Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) l’ó lóore jùlọ ní ibùgbé, l’ó sì dára jùlọ ní ìjókòó?”

### الآية 19:74

> ﻿وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُمْ مِنْ قَرْنٍ هُمْ أَحْسَنُ أَثَاثًا وَرِئْيًا [19:74]

Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí!

### الآية 19:75

> ﻿قُلْ مَنْ كَانَ فِي الضَّلَالَةِ فَلْيَمْدُدْ لَهُ الرَّحْمَٰنُ مَدًّا ۚ حَتَّىٰ إِذَا رَأَوْا مَا يُوعَدُونَ إِمَّا الْعَذَابَ وَإِمَّا السَّاعَةَ فَسَيَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ شَرٌّ مَكَانًا وَأَضْعَفُ جُنْدًا [19:75]

Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun.

### الآية 19:76

> ﻿وَيَزِيدُ اللَّهُ الَّذِينَ اهْتَدَوْا هُدًى ۗ وَالْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ خَيْرٌ عِنْدَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ مَرَدًّا [19:76]

Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn t’ó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

### الآية 19:77

> ﻿أَفَرَأَيْتَ الَّذِي كَفَرَ بِآيَاتِنَا وَقَالَ لَأُوتَيَنَّ مَالًا وَوَلَدًا [19:77]

Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”

### الآية 19:78

> ﻿أَطَّلَعَ الْغَيْبَ أَمِ اتَّخَذَ عِنْدَ الرَّحْمَٰنِ عَهْدًا [19:78]

Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé?

### الآية 19:79

> ﻿كَلَّا ۚ سَنَكْتُبُ مَا يَقُولُ وَنَمُدُّ لَهُ مِنَ الْعَذَابِ مَدًّا [19:79]

Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun t’ó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà.

### الآية 19:80

> ﻿وَنَرِثُهُ مَا يَقُولُ وَيَأْتِينَا فَرْدًا [19:80]

A ó sì jogún ohun t’ó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan.

### الآية 19:81

> ﻿وَاتَّخَذُوا مِنْ دُونِ اللَّهِ آلِهَةً لِيَكُونُوا لَهُمْ عِزًّا [19:81]

Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára.

### الآية 19:82

> ﻿كَلَّا ۚ سَيَكْفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمْ وَيَكُونُونَ عَلَيْهِمْ ضِدًّا [19:82]

Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn.

### الآية 19:83

> ﻿أَلَمْ تَرَ أَنَّا أَرْسَلْنَا الشَّيَاطِينَ عَلَى الْكَافِرِينَ تَؤُزُّهُمْ أَزًّا [19:83]

Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Àwa ń rán àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń tì wọ́n ní ìtìkutì (síbi ẹ̀ṣẹ̀)?

### الآية 19:84

> ﻿فَلَا تَعْجَلْ عَلَيْهِمْ ۖ إِنَّمَا نَعُدُّ لَهُمْ عَدًّا [19:84]

Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà.

### الآية 19:85

> ﻿يَوْمَ نَحْشُرُ الْمُتَّقِينَ إِلَى الرَّحْمَٰنِ وَفْدًا [19:85]

(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn.

### الآية 19:86

> ﻿وَنَسُوقُ الْمُجْرِمِينَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ وِرْدًا [19:86]

A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì.

### الآية 19:87

> ﻿لَا يَمْلِكُونَ الشَّفَاعَةَ إِلَّا مَنِ اتَّخَذَ عِنْدَ الرَّحْمَٰنِ عَهْدًا [19:87]

Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé.

### الآية 19:88

> ﻿وَقَالُوا اتَّخَذَ الرَّحْمَٰنُ وَلَدًا [19:88]

Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ."

### الآية 19:89

> ﻿لَقَدْ جِئْتُمْ شَيْئًا إِدًّا [19:89]

Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá.

### الآية 19:90

> ﻿تَكَادُ السَّمَاوَاتُ يَتَفَطَّرْنَ مِنْهُ وَتَنْشَقُّ الْأَرْضُ وَتَخِرُّ الْجِبَالُ هَدًّا [19:90]

Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dà wó lulẹ̀ gbì

### الآية 19:91

> ﻿أَنْ دَعَوْا لِلرَّحْمَٰنِ وَلَدًا [19:91]

fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé.

### الآية 19:92

> ﻿وَمَا يَنْبَغِي لِلرَّحْمَٰنِ أَنْ يَتَّخِذَ وَلَدًا [19:92]

Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ.

### الآية 19:93

> ﻿إِنْ كُلُّ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ إِلَّا آتِي الرَّحْمَٰنِ عَبْدًا [19:93]

Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn.

### الآية 19:94

> ﻿لَقَدْ أَحْصَاهُمْ وَعَدَّهُمْ عَدًّا [19:94]

Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà.

### الآية 19:95

> ﻿وَكُلُّهُمْ آتِيهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَرْدًا [19:95]

Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan.

### الآية 19:96

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ سَيَجْعَلُ لَهُمُ الرَّحْمَٰنُ وُدًّا [19:96]

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn.

### الآية 19:97

> ﻿فَإِنَّمَا يَسَّرْنَاهُ بِلِسَانِكَ لِتُبَشِّرَ بِهِ الْمُتَّقِينَ وَتُنْذِرَ بِهِ قَوْمًا لُدًّا [19:97]

Nítorí náà, A kúkú ṣe kíké al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn (fún ọ) pẹ̀lú èdè abínibí rẹ nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ oníyàn-jíjà.

### الآية 19:98

> ﻿وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُمْ مِنْ قَرْنٍ هَلْ تُحِسُّ مِنْهُمْ مِنْ أَحَدٍ أَوْ تَسْمَعُ لَهُمْ رِكْزًا [19:98]

Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí?

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/19.md)
- [كل تفاسير سورة مريم
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/19.md)
- [ترجمات سورة مريم
](https://quranpedia.net/translations/19.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/19/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
