---
title: "ترجمة سورة الأنبياء - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/21/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/21/book/2001"
surah_id: "21"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الأنبياء - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/21/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الأنبياء - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/21/book/2001*.

Translation of Surah الأنبياء from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 21:1

> اقْتَرَبَ لِلنَّاسِ حِسَابُهُمْ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ مُعْرِضُونَ [21:1]

Ìṣírò-iṣẹ́ súnmọ́ fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì wà nínú ìfọ́núfọ́ra, tí wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo).

### الآية 21:2

> ﻿مَا يَأْتِيهِمْ مِنْ ذِكْرٍ مِنْ رَبِّهِمْ مُحْدَثٍ إِلَّا اسْتَمَعُوهُ وَهُمْ يَلْعَبُونَ [21:2]

Kò sí ìrántí titun kan tí ó máa dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àfi kí wọ́n gbọ́ ọ pẹ̀lú eré ṣíṣe.

### الآية 21:3

> ﻿لَاهِيَةً قُلُوبُهُمْ ۗ وَأَسَرُّوا النَّجْوَى الَّذِينَ ظَلَمُوا هَلْ هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ ۖ أَفَتَأْتُونَ السِّحْرَ وَأَنْتُمْ تُبْصِرُونَ [21:3]

Wọ́n fọ́núfọ́ra ni. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì fi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (ààrin ara wọn) pamọ́ pé: "Ṣé èyí tayọ abara bí irú yín ni? Ṣé ẹ máa tẹ̀lé idán ni, nígbà tí ẹ̀yin náà ríran?"

### الآية 21:4

> ﻿قَالَ رَبِّي يَعْلَمُ الْقَوْلَ فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ [21:4]

Ó sọ pé: “Olúwa mi mọ ọ̀rọ̀ t’ó ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”

### الآية 21:5

> ﻿بَلْ قَالُوا أَضْغَاثُ أَحْلَامٍ بَلِ افْتَرَاهُ بَلْ هُوَ شَاعِرٌ فَلْيَأْتِنَا بِآيَةٍ كَمَا أُرْسِلَ الْأَوَّلُونَ [21:5]

Rárá, wọ́n tún wí pé: “Àwọn àlá tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ́pọ̀ mọ́ra wọn ni (al-Ƙur’ān.” Wọ́n tún wí pé): “Rárá, ó hun ún ni.” (Wọ́n tún wí pé): “Rárá, eléwì ni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó mú àmì kan wá fún wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi rán àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

### الآية 21:6

> ﻿مَا آمَنَتْ قَبْلَهُمْ مِنْ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا ۖ أَفَهُمْ يُؤْمِنُونَ [21:6]

Kò sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ṣíwájú wọn nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́ (lẹ́yìn ìsọ̀kalẹ̀ àmì). Ṣé àwọn sì máa gbàgbọ́ (nígbà tí àmì bá dé)?
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yūsuf: 12:109 àti sūrah an-Nahl; 16:43.

### الآية 21:7

> ﻿وَمَا أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ إِلَّا رِجَالًا نُوحِي إِلَيْهِمْ ۖ فَاسْأَلُوا أَهْلَ الذِّكْرِ إِنْ كُنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ [21:7]

A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.

### الآية 21:8

> ﻿وَمَا جَعَلْنَاهُمْ جَسَدًا لَا يَأْكُلُونَ الطَّعَامَ وَمَا كَانُوا خَالِدِينَ [21:8]

A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kò níí jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn t’ó gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú sọ pé, “Āyah yìí àti āyah 34 níwájú tako àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé. Nítorí náà, Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú”. 
Èsì: Kíyè sí i! Gbígbé tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lọ sínú sánmọ̀ kò túmọ̀ sí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò níí kú. Rárá o, ó máa kú lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ nítorí pé, abara ni, kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu, Ọlọ́hun nìkan ni kò níí kú láéláé. Yàtọ̀ sí āyah “ƙọbla maotih” nínú sūrah an-Nisā’; 4:159, àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti fi rinlẹ̀ pé, ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹ̀yìn ìgbà tí ó bá t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀, ìyẹn ní òpin ayé. Ohun tí ó kàn jẹ́ ìṣòro fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ṣíwájú àsìkò yìí ni pé, bí wọ́n bá sọ pé kò sí āyah tààrà kan lórí àìtíìkú rẹ̀ àti ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀ láti ojú sánmọ̀ lópin ayé, kò sí ìmọ̀ t’ó yè kooro fún wọn lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Nítorí pé, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀kọ́ t’ó yè kooro lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), wọn ìbá mọ̀ pé dájúdájú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní òmìnira láti sọ ọ̀rọ̀ tí kò sí nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ní òdíwọ̀n ìgbà tí hadīth bẹ́ẹ̀ bá sì ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa hadīth, ẹnu aláìmọ̀kan tàbí aláààbọ̀ ẹ̀kọ́ kan kan kò sì gbà á láti tako irúfẹ́ àwọn hadīth náà. Bí ó bá dán an wò pẹ̀rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti bàjẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4: 115. 
Bí àpẹẹrẹ, al-Ƙur’ān fi rinlẹ̀ pé, àwọn òkú kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè ní ìbámu sí sūrah an-Naml; 27:80, sūrah ar-Rūm; 30:52 àti sūrah Fātir; 35:22. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì padà di òkú tí wọ́n bò mọ́ inú sàréè nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:30. Kò sì sí āyah tààrà kan nínú al-Ƙur’ān tí ó yọ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sílẹ̀ nínú àwọn òkú tí kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè. Àmọ́ hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń dá sálámọ̀ padà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá sálámọ̀ sí i nídìí sàréè rẹ̀. Kódà hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ tún wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, ní gbogbo ọjọ́ Jímọ̀, àwọn mọlāika ń gbé ìtọrọ-ìkẹ́ àti ìtọrọ-ìbùkún fún Ànábì wa Muhammad sí etí ìgbọ́ rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀ láti ibikíbi nílé ayé tí wọ́n bá ti ń tọrọ rẹ̀ fún un (sollalāhu 'alayhi wa sallam). 
Hadīth kìíní: Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé, “Kò sí ẹnì kan tí ó máa sálámọ̀ sí mi àfi kí Allāhu dá ẹ̀mí mi padà sí mi lára títí mo máa fi dá sálámọ̀ náà padà fún un.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb ziyāratul-ƙubūr. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà dára”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Hadīth kejì: Láti ọ̀dọ̀ ’Aos ọmọ ’Aos (rọdiyallāhu 'anhu), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé, “Dájúdájú ọjọ́ Jum‘ah wà nínú àwọn ọjọ́ yín t’ó lóore jùlọ; Wọ́n ṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú rẹ̀, Wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ nínú rẹ̀, ìfọn àkọ́kọ́ sínú ìwo máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Ikú gbogbo ẹ̀dá sì máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ asọlātu fún mi nínú rẹ̀ nítorí pé, wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn asọlātu yín sí ọ̀dọ̀ mi.” ’Aos sọ pé, àwọn Sọhābah wí pé, “Òjíṣẹ́ Allāhu, báwo ni wọ́n ṣe máa kó àwọn asọlātu wa wá bá ọ, ó ó má ti derùpẹ̀!?” Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ('azza wa jall.) ṣe ẹran ara àwọn Ànábì ní èèwọ̀ fún ilẹ̀.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb fọdli yaomil-Jum‘ah walaelatil-Jum‘ah. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà ní àlàáfíà”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Àpẹẹrẹ mìíràn ni àwọn hadīth tààrà t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ènìyàn hóró kan ṣoṣo tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pè ní “Mọsīhu-ddajjāl”. Ẹni yìí má yọjú sáyé lópin ayé. Ó sì máa fòòró ayé ní ìfòòró kan tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí. 
Àmọ́ tòhun ti bí “Mọsīhu-ddajjāl” ṣe jẹ́ ẹyọ kan nínú àwọn àmì ńlá fún òpin ayé, kò sí āyah kan tààrà lórí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan l’ó jẹ́ kí á mọ̀ pé ènìyàn kan ń bọ̀ lópin ayé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mọsīhu-ddajjāl. 
Èyí sì ni ìgbàgbọ́ àti àdìsọ́kàn àwa mùsùlùmí, tòhun ti bí kò ṣe sí āyah t’ó gbè é lẹ́sẹ̀ tààrà nínú al-Ƙur’ān. Nígbà tí gbogbo àwa mùsùlùmí ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn irúfẹ́ àwọn hadīth òkè wọ̀nyẹn, ní ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó tayọ òye wa, àmọ́ tí ó tẹnu Ànábì wa Muhammad olódodo (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jáde, nígbà náà ta ni ẹni tí ó máa lórí láyà tako àwọn hadīth Bukọ̄riy àti hadith Muslim t’ó wá lórí àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé? Ẹnikẹ́ni tí ó bá takò ó ti tako Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ọ̀kan nìyí nínú àwọn hadīth náà.
Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Báwo ni ẹ̀yin máa wà nígbà tí Ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá sọ̀kalẹ̀ sáààrin yín, tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín.” Ẹnì kan nínú àwọn t’ó gba hadīth yìí wá sọ pé, “Kí ni ìtúmọ̀ “tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín”? Tàbí kí ni ìtúmọ̀ “tí ohun tí ó máa fi darí yín sì máa wá láti ọ̀dọ̀ yín?” Ibnu Abī Thanb sì fèsì pé, “Ó máa fi tírà Olúwa yín (tabāraka wa ta'ālā) àti sunnah Ànábì yín (sollalāhu 'alayhi wa sallam) darí yín.” Ni ìtúmọ̀ rẹ̀. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni “imām” dúró fún nínú hadīth yìí, gẹ́gẹ́ bí “imām” ṣé dúró fún “tírà” nínú sūrah Hūd; 11:17, sūrah al-’Ahƙọ̄f; 46:12 àti sūrah Yāsīn, 36:12.

### الآية 21:9

> ﻿ثُمَّ صَدَقْنَاهُمُ الْوَعْدَ فَأَنْجَيْنَاهُمْ وَمَنْ نَشَاءُ وَأَهْلَكْنَا الْمُسْرِفِينَ [21:9]

Lẹ́yìn náà, A mú àdéhùn Wa ṣẹ fún wọn. A sì gba àwọn Òjíṣẹ́ àti àwọn tí A bá fẹ́ là. A sì pa àwọn olùtayọ ẹnu-àlà run.

### الآية 21:10

> ﻿لَقَدْ أَنْزَلْنَا إِلَيْكُمْ كِتَابًا فِيهِ ذِكْرُكُمْ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ [21:10]

Dájúdájú A ti sọ tírà kan kalẹ̀ fun yín, tí ìrántí nípa ọ̀rọ̀ ara yín wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?

### الآية 21:11

> ﻿وَكَمْ قَصَمْنَا مِنْ قَرْيَةٍ كَانَتْ ظَالِمَةً وَأَنْشَأْنَا بَعْدَهَا قَوْمًا آخَرِينَ [21:11]

Mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́, tí ó jẹ́ alábòsí! A sì gbé àwọn ìjọ mìíràn dìde lẹ́yìn wọn.

### الآية 21:12

> ﻿فَلَمَّا أَحَسُّوا بَأْسَنَا إِذَا هُمْ مِنْهَا يَرْكُضُونَ [21:12]

Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa (t’ó ń bọ̀), wọ́n sì ń sá lọ fún un.

### الآية 21:13

> ﻿لَا تَرْكُضُوا وَارْجِعُوا إِلَىٰ مَا أُتْرِفْتُمْ فِيهِ وَمَسَاكِنِكُمْ لَعَلَّكُمْ تُسْأَلُونَ [21:13]

Ẹ má ṣe sá lọ. Ẹ padà síbi n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fun yín àti àwọn ibùgbé yín nítorí kí A lè bi yín ní ìbéèrè.

### الآية 21:14

> ﻿قَالُوا يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ [21:14]

Wọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”

### الآية 21:15

> ﻿فَمَا زَالَتْ تِلْكَ دَعْوَاهُمْ حَتَّىٰ جَعَلْنَاهُمْ حَصِيدًا خَامِدِينَ [21:15]

Igbe wọn yìí kò dúró títí A fi sọ wọ́n di koríko tí wọ́n gé, wọ́n sì dòkú kalẹ̀.

### الآية 21:16

> ﻿وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاءَ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَاعِبِينَ [21:16]

Àwa kò dá sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.

### الآية 21:17

> ﻿لَوْ أَرَدْنَا أَنْ نَتَّخِذَ لَهْوًا لَاتَّخَذْنَاهُ مِنْ لَدُنَّا إِنْ كُنَّا فَاعِلِينَ [21:17]

Tí ó bá jẹ́ pé A gbèrò láti ṣèré ni, ọ̀dọ̀ Wa ni A kúkú tí máa ṣe é tí A bá jẹ́ olùṣe-(eré).

### الآية 21:18

> ﻿بَلْ نَقْذِفُ بِالْحَقِّ عَلَى الْبَاطِلِ فَيَدْمَغُهُ فَإِذَا هُوَ زَاهِقٌ ۚ وَلَكُمُ الْوَيْلُ مِمَّا تَصِفُونَ [21:18]

Rárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. Ègbé sì ni fun yín nípa ohun tí ẹ ń fi ròyìn (Rẹ̀ ní ti irọ́).

### الآية 21:19

> ﻿وَلَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَمَنْ عِنْدَهُ لَا يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِهِ وَلَا يَسْتَحْسِرُونَ [21:19]

TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Àti pé wọ́n kò kọ́lẹ.

### الآية 21:20

> ﻿يُسَبِّحُونَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لَا يَفْتُرُونَ [21:20]

Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; kò sì rẹ̀ wọ́n.

### الآية 21:21

> ﻿أَمِ اتَّخَذُوا آلِهَةً مِنَ الْأَرْضِ هُمْ يُنْشِرُونَ [21:21]

Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tí wọ́n mú jáde láti ara ilẹ̀, tí wọ́n ń jí òkú dìde ni?

### الآية 21:22

> ﻿لَوْ كَانَ فِيهِمَا آلِهَةٌ إِلَّا اللَّهُ لَفَسَدَتَا ۚ فَسُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ [21:22]

Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

### الآية 21:23

> ﻿لَا يُسْأَلُ عَمَّا يَفْعَلُ وَهُمْ يُسْأَلُونَ [21:23]

Wọn kò níí bi (Allāhu) ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan tí Ó ń ṣe. Àwọn ni wọ́n máa bi ní ìbéèrè (nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn).

### الآية 21:24

> ﻿أَمِ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ آلِهَةً ۖ قُلْ هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ ۖ هَٰذَا ذِكْرُ مَنْ مَعِيَ وَذِكْرُ مَنْ قَبْلِي ۗ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ الْحَقَّ ۖ فَهُمْ مُعْرِضُونَ [21:24]

Tàbí wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wa.” (Al-Ƙur’ān) yìí ni ìrántí nípa àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi àti ìrántí nípa àwọn t’ó ṣíwájú mi. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ òdodo; wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.

### الآية 21:25

> ﻿وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدُونِ [21:25]

A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”

### الآية 21:26

> ﻿وَقَالُوا اتَّخَذَ الرَّحْمَٰنُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۚ بَلْ عِبَادٌ مُكْرَمُونَ [21:26]

Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un – Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n.

### الآية 21:27

> ﻿لَا يَسْبِقُونَهُ بِالْقَوْلِ وَهُمْ بِأَمْرِهِ يَعْمَلُونَ [21:27]

Wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀.

### الآية 21:28

> ﻿يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يَشْفَعُونَ إِلَّا لِمَنِ ارْتَضَىٰ وَهُمْ مِنْ خَشْيَتِهِ مُشْفِقُونَ [21:28]

(Allāhu) mọ ohun t’ó ń bẹ níwájú wọn àti ohun t’ó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀.

### الآية 21:29

> ﻿۞ وَمَنْ يَقُلْ مِنْهُمْ إِنِّي إِلَٰهٌ مِنْ دُونِهِ فَذَٰلِكَ نَجْزِيهِ جَهَنَّمَ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي الظَّالِمِينَ [21:29]

Àti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: “Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀.” Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.

### الآية 21:30

> ﻿أَوَلَمْ يَرَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ كَانَتَا رَتْقًا فَفَتَقْنَاهُمَا ۖ وَجَعَلْنَا مِنَ الْمَاءِ كُلَّ شَيْءٍ حَيٍّ ۖ أَفَلَا يُؤْمِنُونَ [21:30]

Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kò rí i pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀ pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀ pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti inú omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni? 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni sọ pé, sūrah Fussilat; 41:11 tako sūrah al-’Anbiyā’; 21:30. 
Èsì: Kò sí ìtakora kan kan nínú āyah méjèèjì. Àlàyé rẹ̀ nìyí, ìtúmọ̀ “rọtƙ” ni “ìlẹ̀pọ̀, lílẹ̀-papọ̀”, ìtúmọ̀ “fatƙ” sì ni “ẹ̀là, lílà, yíyà”. Ní ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀dá sánmọ̀ àti ilẹ̀, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò fi ojú kan kan sára ìkíní kejì tí n̄ǹkan kan lè gba jáde síta. Lẹ́yìn náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) la ojú sánmọ̀ nítorí kí omi òjò lè máa tinú rẹ̀ jáde sí orí ilẹ̀. Allāhu sì tún la ojú ilẹ̀ nítorí kí irúgbìn lè máa tinú rẹ̀ jáde. Tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò bá ṣe èyí fún ìkíní kejì ni, òjò ìbá tí rí ọ̀nà jáde nínú sánmọ̀, irúgbìn ilẹ̀ náà ìbá tí rí ọ̀nà wù jáde nínú ilẹ̀. Ìdí nìyí tí gbólóhùn “A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti ara omi” fi parí āyah yẹn. Kíyè sí i, kalmọh ìlẹ̀pọ̀ tí Allāhu lò fún sánmọ̀ àti ilẹ̀, kò túmọ̀ sí pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’ó lẹ̀ papọ̀ mọ́ra wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wí bẹ́ẹ̀. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìkíní kejì wà. Ìdí sì nìyí tí ó fi jẹ́ pé, ìkíní kejì wọn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa àṣẹ fún láti máa mú ohun tí ó wà nínú wọn jáde. Èyí sì ni ó mú ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ wá ní “èjì”, dípò “ẹyọ”, fún sánmọ̀ àti ilẹ̀ nítorí pé, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìkíní kejì wọn wà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èyí sì l’ó jẹyọ nínú sūrah Fussilat; 41:11. Nítorí náà, kò sí ìtakora nínú àwọn āyah náà. W-Allāhu ’a‘lam.

### الآية 21:31

> ﻿وَجَعَلْنَا فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَنْ تَمِيدَ بِهِمْ وَجَعَلْنَا فِيهَا فِجَاجًا سُبُلًا لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ [21:31]

A sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀.

### الآية 21:32

> ﻿وَجَعَلْنَا السَّمَاءَ سَقْفًا مَحْفُوظًا ۖ وَهُمْ عَنْ آيَاتِهَا مُعْرِضُونَ [21:32]

A tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀.

### الآية 21:33

> ﻿وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ [21:33]

Òun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto t’ó ń tọ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah kẹjọ.

### الآية 21:34

> ﻿وَمَا جَعَلْنَا لِبَشَرٍ مِنْ قَبْلِكَ الْخُلْدَ ۖ أَفَإِنْ مِتَّ فَهُمُ الْخَالِدُونَ [21:34]

A kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí?

### الآية 21:35

> ﻿كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۗ وَنَبْلُوكُمْ بِالشَّرِّ وَالْخَيْرِ فِتْنَةً ۖ وَإِلَيْنَا تُرْجَعُونَ [21:35]

Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan l’ó máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fun yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.

### الآية 21:36

> ﻿وَإِذَا رَآكَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا الَّذِي يَذْكُرُ آلِهَتَكُمْ وَهُمْ بِذِكْرِ الرَّحْمَٰنِ هُمْ كَافِرُونَ [21:36]

Nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ bá rí ọ, wọn kò sì níí kà ọ́ kún kiní kan bí kò ṣe oníyẹ̀yẹ́ pé: “Ṣé èyí ni ẹni t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́hun yín?” Aláìgbàgbọ́ sì ni àwọn náà nípa ìrántí Àjọkẹ́-ayé.

### الآية 21:37

> ﻿خُلِقَ الْإِنْسَانُ مِنْ عَجَلٍ ۚ سَأُرِيكُمْ آيَاتِي فَلَا تَسْتَعْجِلُونِ [21:37]

Wọ́n fi ìkánjú ṣe ènìyàn. Mo máa fi àwọn àmì Mi hàn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe kán Mi lójú.

### الآية 21:38

> ﻿وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ [21:38]

Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni ìlérí yìí yóò ṣẹ ná, tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

### الآية 21:39

> ﻿لَوْ يَعْلَمُ الَّذِينَ كَفَرُوا حِينَ لَا يَكُفُّونَ عَنْ وُجُوهِهِمُ النَّارَ وَلَا عَنْ ظُهُورِهِمْ وَلَا هُمْ يُنْصَرُونَ [21:39]

Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mọ ìgbà tí wọn kò níí dá Iná dúró níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn, tí A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́, (wọn ìbá tí wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú).

### الآية 21:40

> ﻿بَلْ تَأْتِيهِمْ بَغْتَةً فَتَبْهَتُهُمْ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ رَدَّهَا وَلَا هُمْ يُنْظَرُونَ [21:40]

Ṣùgbọ́n (ìyà Iná) yóò bá wọn ní òjijì, nígbà náà ó máa kó ìdààmú bá wọn; wọn kò sì níí lè dá a padà. A ò sì níí sún (ìyà náà) síwájú fún wọn.

### الآية 21:41

> ﻿وَلَقَدِ اسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِنْ قَبْلِكَ فَحَاقَ بِالَّذِينَ سَخِرُوا مِنْهُمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ [21:41]

Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí àwọn t’ó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.

### الآية 21:42

> ﻿قُلْ مَنْ يَكْلَؤُكُمْ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ مِنَ الرَّحْمَٰنِ ۗ بَلْ هُمْ عَنْ ذِكْرِ رَبِّهِمْ مُعْرِضُونَ [21:42]

Sọ pé: "Ta ni ẹni tí ó ń ṣọ yín ní òru àti ní ọ̀sán níbi ìyà Àjọkẹ́-ayé?" Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọkẹ́-ayé.

### الآية 21:43

> ﻿أَمْ لَهُمْ آلِهَةٌ تَمْنَعُهُمْ مِنْ دُونِنَا ۚ لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَ أَنْفُسِهِمْ وَلَا هُمْ مِنَّا يُصْحَبُونَ [21:43]

Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan t’ó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa.

### الآية 21:44

> ﻿بَلْ مَتَّعْنَا هَٰؤُلَاءِ وَآبَاءَهُمْ حَتَّىٰ طَالَ عَلَيْهِمُ الْعُمُرُ ۗ أَفَلَا يَرَوْنَ أَنَّا نَأْتِي الْأَرْضَ نَنْقُصُهَا مِنْ أَطْرَافِهَا ۚ أَفَهُمُ الْغَالِبُونَ [21:44]

Bẹ́ẹ̀ ni, A fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn títí ìṣẹ̀mí ayé wọn fi gùn. Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọnú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn). Nítorí náà, ṣé àwọn ni olùborí ni?

### الآية 21:45

> ﻿قُلْ إِنَّمَا أُنْذِرُكُمْ بِالْوَحْيِ ۚ وَلَا يَسْمَعُ الصُّمُّ الدُّعَاءَ إِذَا مَا يُنْذَرُونَ [21:45]

Sọ pé: “Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fun yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn.”

### الآية 21:46

> ﻿وَلَئِنْ مَسَّتْهُمْ نَفْحَةٌ مِنْ عَذَابِ رَبِّكَ لَيَقُولُنَّ يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ [21:46]

Àti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”

### الآية 21:47

> ﻿وَنَضَعُ الْمَوَازِينَ الْقِسْطَ لِيَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا ۖ وَإِنْ كَانَ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِنْ خَرْدَلٍ أَتَيْنَا بِهَا ۗ وَكَفَىٰ بِنَا حَاسِبِينَ [21:47]

A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò.

### الآية 21:48

> ﻿وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَىٰ وَهَارُونَ الْفُرْقَانَ وَضِيَاءً وَذِكْرًا لِلْمُتَّقِينَ [21:48]

Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ọ̀rọ̀-ìpínyà, ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí nínú āyah yìí dúró fún àwọn ìròyìn t’ó wà lára tírà kan ṣoṣo tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tírà náà ni at-Taorāt. Lẹ́yìn náà, ìwọ̀nyẹn ni àwọn ìròyìn t’ó máa ń wà lára ìkọ̀ọ̀kan tírà tí Allāhu máa ń sọ̀kalẹ̀ fún àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w.). Kíyè sí i, gbogbo tírà t’ó ṣíwájú ti parí iṣẹ́ wọn. Ní àsìkò yìí, tírà ìkẹ́yìn nìkan l’ó ku gbogbo ayé kù. Ìyẹn sì ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Kódà bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá padà sọ̀kalẹ̀ lópin ayé, kò níí tẹ̀lé tírà kan yàtọ̀ sí al-Ƙur’ān gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 8.

### الآية 21:49

> ﻿الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ بِالْغَيْبِ وَهُمْ مِنَ السَّاعَةِ مُشْفِقُونَ [21:49]

(Àwọn ni) àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà.

### الآية 21:50

> ﻿وَهَٰذَا ذِكْرٌ مُبَارَكٌ أَنْزَلْنَاهُ ۚ أَفَأَنْتُمْ لَهُ مُنْكِرُونَ [21:50]

Èyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni?

### الآية 21:51

> ﻿۞ وَلَقَدْ آتَيْنَا إِبْرَاهِيمَ رُشْدَهُ مِنْ قَبْلُ وَكُنَّا بِهِ عَالِمِينَ [21:51]

Dájúdájú A ti fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.

### الآية 21:52

> ﻿إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا هَٰذِهِ التَّمَاثِيلُ الَّتِي أَنْتُمْ لَهَا عَاكِفُونَ [21:52]

(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì lọ́rùn ṣe jẹ́ ná?”

### الآية 21:53

> ﻿قَالُوا وَجَدْنَا آبَاءَنَا لَهَا عَابِدِينَ [21:53]

Wọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.”

### الآية 21:54

> ﻿قَالَ لَقَدْ كُنْتُمْ أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمْ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [21:54]

Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

### الآية 21:55

> ﻿قَالُوا أَجِئْتَنَا بِالْحَقِّ أَمْ أَنْتَ مِنَ اللَّاعِبِينَ [21:55]

Wọ́n wí pé: “Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà lára àwọn ẹlẹ́fẹ̀.”

### الآية 21:56

> ﻿قَالَ بَلْ رَبُّكُمْ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ الَّذِي فَطَرَهُنَّ وَأَنَا عَلَىٰ ذَٰلِكُمْ مِنَ الشَّاهِدِينَ [21:56]

Ó sọ pé: "Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

### الآية 21:57

> ﻿وَتَاللَّهِ لَأَكِيدَنَّ أَصْنَامَكُمْ بَعْدَ أَنْ تُوَلُّوا مُدْبِرِينَ [21:57]

Àti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ."

### الآية 21:58

> ﻿فَجَعَلَهُمْ جُذَاذًا إِلَّا كَبِيرًا لَهُمْ لَعَلَّهُمْ إِلَيْهِ يَرْجِعُونَ [21:58]

Ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ àfi àgbà (òrìṣà) wọn nítorí kí wọ́n lè padà dé bá a.

### الآية 21:59

> ﻿قَالُوا مَنْ فَعَلَ هَٰذَا بِآلِهَتِنَا إِنَّهُ لَمِنَ الظَّالِمِينَ [21:59]

Wọ́n wí pé: “Ta ni ó ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa? Dájúdájú onítọ̀un wà nínú àwọn alábòsí.”

### الآية 21:60

> ﻿قَالُوا سَمِعْنَا فَتًى يَذْكُرُهُمْ يُقَالُ لَهُ إِبْرَاهِيمُ [21:60]

Wọ́n wí pé: “A gbọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Wọ́n ń pe (ọmọ náà) ní ’Ibrọ̄hīm.”

### الآية 21:61

> ﻿قَالُوا فَأْتُوا بِهِ عَلَىٰ أَعْيُنِ النَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَشْهَدُونَ [21:61]

Wọ́n wí pé: “Ẹ mú un wá han àwọn ènìyàn kí wọ́n lè jẹ́rìí lé e lórí.”

### الآية 21:62

> ﻿قَالُوا أَأَنْتَ فَعَلْتَ هَٰذَا بِآلِهَتِنَا يَا إِبْرَاهِيمُ [21:62]

Wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ l’o ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, ’Ibrọ̄hīm?”

### الآية 21:63

> ﻿قَالَ بَلْ فَعَلَهُ كَبِيرُهُمْ هَٰذَا فَاسْأَلُوهُمْ إِنْ كَانُوا يَنْطِقُونَ [21:63]

Ó sọ pé: “Rárá o, àgbà wọn yìí l’ó ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:78.

### الآية 21:64

> ﻿فَرَجَعُوا إِلَىٰ أَنْفُسِهِمْ فَقَالُوا إِنَّكُمْ أَنْتُمُ الظَّالِمُونَ [21:64]

Nígbà náà, wọ́n yíjú síra wọn, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni alábòsí.”

### الآية 21:65

> ﻿ثُمَّ نُكِسُوا عَلَىٰ رُءُوسِهِمْ لَقَدْ عَلِمْتَ مَا هَٰؤُلَاءِ يَنْطِقُونَ [21:65]

Lẹ́yìn náà, wọ́n sorí kọ́ (wọ́n sì wí pé): “Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí kì í sọ̀rọ̀.”

### الآية 21:66

> ﻿قَالَ أَفَتَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنْفَعُكُمْ شَيْئًا وَلَا يَضُرُّكُمْ [21:66]

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira ba yín lẹ́yìn Allāhu?

### الآية 21:67

> ﻿أُفٍّ لَكُمْ وَلِمَا تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ [21:67]

Ṣíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni?"

### الآية 21:68

> ﻿قَالُوا حَرِّقُوهُ وَانْصُرُوا آلِهَتَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ فَاعِلِينَ [21:68]

Wọ́n wí pé: “Ẹ dáná sun ún; kí ẹ sì ran àwọn ọlọ́hun yín lọ́wọ́, tí ẹ̀yin bá níkan-án ṣe.”

### الآية 21:69

> ﻿قُلْنَا يَا نَارُ كُونِي بَرْدًا وَسَلَامًا عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ [21:69]

A sọ pé: “Iná, di tútù àti àlàáfíà lára ’Ibrọ̄hīm.”

### الآية 21:70

> ﻿وَأَرَادُوا بِهِ كَيْدًا فَجَعَلْنَاهُمُ الْأَخْسَرِينَ [21:70]

Wọ́n gbèrò ète sí i, ṣùgbọ́n A ṣe wọ́n ní olófò jùlọ.

### الآية 21:71

> ﻿وَنَجَّيْنَاهُ وَلُوطًا إِلَى الْأَرْضِ الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا لِلْعَالَمِينَ [21:71]

A sì gba òun àti Lūt là sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí fún gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 21:72

> ﻿وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ نَافِلَةً ۖ وَكُلًّا جَعَلْنَا صَالِحِينَ [21:72]

A ta á ní ọrẹ ọmọ, ’Is-hāƙ àti Ya‘ƙūb tí ó jẹ́ àlékún (ìyẹn, ọmọọmọ). Olúkùlùkù (wọn) ni A ṣe ní ẹni rere.

### الآية 21:73

> ﻿وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا وَأَوْحَيْنَا إِلَيْهِمْ فِعْلَ الْخَيْرَاتِ وَإِقَامَ الصَّلَاةِ وَإِيتَاءَ الزَّكَاةِ ۖ وَكَانُوا لَنَا عَابِدِينَ [21:73]

A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa.

### الآية 21:74

> ﻿وَلُوطًا آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا وَنَجَّيْنَاهُ مِنَ الْقَرْيَةِ الَّتِي كَانَتْ تَعْمَلُ الْخَبَائِثَ ۗ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمَ سَوْءٍ فَاسِقِينَ [21:74]

(Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 21:75

> ﻿وَأَدْخَلْنَاهُ فِي رَحْمَتِنَا ۖ إِنَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ [21:75]

A sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere.

### الآية 21:76

> ﻿وَنُوحًا إِذْ نَادَىٰ مِنْ قَبْلُ فَاسْتَجَبْنَا لَهُ فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ [21:76]

(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú (yín). A sì dá a lóhùn. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá.

### الآية 21:77

> ﻿وَنَصَرْنَاهُ مِنَ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمَ سَوْءٍ فَأَغْرَقْنَاهُمْ أَجْمَعِينَ [21:77]

A sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá.

### الآية 21:78

> ﻿وَدَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ إِذْ يَحْكُمَانِ فِي الْحَرْثِ إِذْ نَفَشَتْ فِيهِ غَنَمُ الْقَوْمِ وَكُنَّا لِحُكْمِهِمْ شَاهِدِينَ [21:78]

(Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn.

### الآية 21:79

> ﻿فَفَهَّمْنَاهَا سُلَيْمَانَ ۚ وَكُلًّا آتَيْنَا حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَسَخَّرْنَا مَعَ دَاوُودَ الْجِبَالَ يُسَبِّحْنَ وَالطَّيْرَ ۚ وَكُنَّا فَاعِلِينَ [21:79]

A sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l’A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀.

### الآية 21:80

> ﻿وَعَلَّمْنَاهُ صَنْعَةَ لَبُوسٍ لَكُمْ لِتُحْصِنَكُمْ مِنْ بَأْسِكُمْ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ شَاكِرُونَ [21:80]

A tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fun yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fun yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí?

### الآية 21:81

> ﻿وَلِسُلَيْمَانَ الرِّيحَ عَاصِفَةً تَجْرِي بِأَمْرِهِ إِلَى الْأَرْضِ الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا ۚ وَكُنَّا بِكُلِّ شَيْءٍ عَالِمِينَ [21:81]

A sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 21:82

> ﻿وَمِنَ الشَّيَاطِينِ مَنْ يَغُوصُونَ لَهُ وَيَعْمَلُونَ عَمَلًا دُونَ ذَٰلِكَ ۖ وَكُنَّا لَهُمْ حَافِظِينَ [21:82]

Nínú àwọn èṣù, àwọn t’ó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn.

### الآية 21:83

> ﻿۞ وَأَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ أَنِّي مَسَّنِيَ الضُّرُّ وَأَنْتَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ [21:83]

(Ẹ rántí Ànábì) ’Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú."

### الآية 21:84

> ﻿فَاسْتَجَبْنَا لَهُ فَكَشَفْنَا مَا بِهِ مِنْ ضُرٍّ ۖ وَآتَيْنَاهُ أَهْلَهُ وَمِثْلَهُمْ مَعَهُمْ رَحْمَةً مِنْ عِنْدِنَا وَذِكْرَىٰ لِلْعَابِدِينَ [21:84]

A sì jẹ́ ìpè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa).

### الآية 21:85

> ﻿وَإِسْمَاعِيلَ وَإِدْرِيسَ وَذَا الْكِفْلِ ۖ كُلٌّ مِنَ الصَّابِرِينَ [21:85]

(Ẹ rántí Ànábì) ’Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) ’Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù.

### الآية 21:86

> ﻿وَأَدْخَلْنَاهُمْ فِي رَحْمَتِنَا ۖ إِنَّهُمْ مِنَ الصَّالِحِينَ [21:86]

A sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere.

### الآية 21:87

> ﻿وَذَا النُّونِ إِذْ ذَهَبَ مُغَاضِبًا فَظَنَّ أَنْ لَنْ نَقْدِرَ عَلَيْهِ فَنَادَىٰ فِي الظُّلُمَاتِ أَنْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا أَنْتَ سُبْحَانَكَ إِنِّي كُنْتُ مِنَ الظَّالِمِينَ [21:87]

(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn alábòsí." 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i, ohun tí Ànábì Yūnus ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kà kún àbòsí nínú àdúà rẹ̀ yìí kì í ṣe ìjàǹbá nítorí pé, kò sí Ànábì t’ó jẹ́ oníjàǹbá. Àmọ́ ohun tí ó ṣe ni pé, ó kánjú kúrò láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n tọrọ ìyà, tí ìyà náà sì fẹ́ sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí. Nítorí kí ìyà má baà kó òun náà sínú l’ó fi kánjú yẹra fún wọn. Ó sì yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun tí ó yẹ jùlọ fún un ni pé, kí ó gba àṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ṣebí Allāhu t’ó rán an níṣẹ́, Ó ń gbọ́ ọ. Ó sì ń rí i.

### الآية 21:88

> ﻿فَاسْتَجَبْنَا لَهُ وَنَجَّيْنَاهُ مِنَ الْغَمِّ ۚ وَكَذَٰلِكَ نُنْجِي الْمُؤْمِنِينَ [21:88]

A jẹ́ ìpè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.

### الآية 21:89

> ﻿وَزَكَرِيَّا إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ رَبِّ لَا تَذَرْنِي فَرْدًا وَأَنْتَ خَيْرُ الْوَارِثِينَ [21:89]

(Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọffāt; 37:125.

### الآية 21:90

> ﻿فَاسْتَجَبْنَا لَهُ وَوَهَبْنَا لَهُ يَحْيَىٰ وَأَصْلَحْنَا لَهُ زَوْجَهُ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَيَدْعُونَنَا رَغَبًا وَرَهَبًا ۖ وَكَانُوا لَنَا خَاشِعِينَ [21:90]

A jẹ́ ìpè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa.

### الآية 21:91

> ﻿وَالَّتِي أَحْصَنَتْ فَرْجَهَا فَنَفَخْنَا فِيهَا مِنْ رُوحِنَا وَجَعَلْنَاهَا وَابْنَهَا آيَةً لِلْعَالَمِينَ [21:91]

(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i! Ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá, kò túmọ̀ sí pé ìkíní kejì wọn jẹ́ olúwa àti olùgbàlà. Àmọ́ kí ẹ̀dá lè wòye sí agbára Allāhu pé, Ó máa ń ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀dá bí Ó bá ṣe fẹ́. Tí ẹnì kan bá wá tìtorí ìyẹn sọ ẹ̀dá kan di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu, Ọba Oníṣẹ́-ìyanu, onítọ̀ún ti sọnù jìnnà. Bákan náà, ẹ tún wo irú gbólóhùn yìí “àmì fún gbogbo ẹ̀dá” nínú sūrah al-’Ankabūt; 29:15.

### الآية 21:92

> ﻿إِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاعْبُدُونِ [21:92]

Dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.

### الآية 21:93

> ﻿وَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُمْ بَيْنَهُمْ ۖ كُلٌّ إِلَيْنَا رَاجِعُونَ [21:93]

(Àwọn yẹhudi àti nasara), wọ́n sì dá ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn) wọn sí kélekèle láààrin ara wọn; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) sì máa padà sí ọ̀dọ̀ Wa.

### الآية 21:94

> ﻿فَمَنْ يَعْمَلْ مِنَ الصَّالِحَاتِ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَا كُفْرَانَ لِسَعْيِهِ وَإِنَّا لَهُ كَاتِبُونَ [21:94]

Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un.

### الآية 21:95

> ﻿وَحَرَامٌ عَلَىٰ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا أَنَّهُمْ لَا يَرْجِعُونَ [21:95]

Èèwọ̀ ni fún ará ìlú kan tí A ti parẹ́ (pé kí ó tún padà sí ayé); dájúdájú wọn kò níí padà mọ́ (sí ilé ayé).

### الآية 21:96

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا فُتِحَتْ يَأْجُوجُ وَمَأْجُوجُ وَهُمْ مِنْ كُلِّ حَدَبٍ يَنْسِلُونَ [21:96]

(Wọn yóò wà nínú barsaku) títí A óò fi ṣí àwọn Ya’jūj àti Ma’jūj sílẹ̀. Àwọn (wọ̀nyí) yó sì máa sáré jáde láti inú gbogbo àyè gíga.

### الآية 21:97

> ﻿وَاقْتَرَبَ الْوَعْدُ الْحَقُّ فَإِذَا هِيَ شَاخِصَةٌ أَبْصَارُ الَّذِينَ كَفَرُوا يَا وَيْلَنَا قَدْ كُنَّا فِي غَفْلَةٍ مِنْ هَٰذَا بَلْ كُنَّا ظَالِمِينَ [21:97]

Àdéhùn òdodo náà súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò máa ranjú kalẹ̀ ràngàndàn, (wọ́n yó sì wí pé): “Ègbé ni fún wa! Dájúdájú àwa ti wà nínú ìgbàgbéra nípa èyí. Rárá, àwa jẹ́ alábòsí ni.”

### الآية 21:98

> ﻿إِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنْتُمْ لَهَا وَارِدُونَ [21:98]

Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni ìkoná Jahanamọ; ẹ̀yin yó sì wọ inú rẹ̀.

### الآية 21:99

> ﻿لَوْ كَانَ هَٰؤُلَاءِ آلِهَةً مَا وَرَدُوهَا ۖ وَكُلٌّ فِيهَا خَالِدُونَ [21:99]

Tí ó bá jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni ọlọ́hun ni, wọn ìbá tí wọ inú Iná. Olùṣegbére sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú rẹ̀.

### الآية 21:100

> ﻿لَهُمْ فِيهَا زَفِيرٌ وَهُمْ فِيهَا لَا يَسْمَعُونَ [21:100]

Iná yóò máa kùn yùn-ùn sí wọn létí; wọn kò sì níí gbọ́ (ọ̀rọ̀ mìíràn).

### الآية 21:101

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ سَبَقَتْ لَهُمْ مِنَّا الْحُسْنَىٰ أُولَٰئِكَ عَنْهَا مُبْعَدُونَ [21:101]

Dájúdájú àwọn tí rere ti ṣíwájú fún láti ọ̀dọ̀ Wa, àwọn wọ̀nyẹn ni A óò gbé jìnnà sí Iná.

### الآية 21:102

> ﻿لَا يَسْمَعُونَ حَسِيسَهَا ۖ وَهُمْ فِي مَا اشْتَهَتْ أَنْفُسُهُمْ خَالِدُونَ [21:102]

Wọn kò sì níí gbọ́ kíkùn rẹ̀. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú ìgbádùn tí ẹ̀mí wọn ń fẹ́.

### الآية 21:103

> ﻿لَا يَحْزُنُهُمُ الْفَزَعُ الْأَكْبَرُ وَتَتَلَقَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ هَٰذَا يَوْمُكُمُ الَّذِي كُنْتُمْ تُوعَدُونَ [21:103]

Ìpáyà t’ó tóbi jùlọ kò níí bà wọ́n nínú jẹ́. Àwọn mọlāika yóò máa pàdé wọn, (wọn yóò sọ pé): “Èyí ni ọjọ́ yín tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín.”

### الآية 21:104

> ﻿يَوْمَ نَطْوِي السَّمَاءَ كَطَيِّ السِّجِلِّ لِلْكُتُبِ ۚ كَمَا بَدَأْنَا أَوَّلَ خَلْقٍ نُعِيدُهُ ۚ وَعْدًا عَلَيْنَا ۚ إِنَّا كُنَّا فَاعِلِينَ [21:104]

(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bí kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.

### الآية 21:105

> ﻿وَلَقَدْ كَتَبْنَا فِي الزَّبُورِ مِنْ بَعْدِ الذِّكْرِ أَنَّ الْأَرْضَ يَرِثُهَا عِبَادِيَ الصَّالِحُونَ [21:105]

Àti pé A ti kọ ọ́ sínú àwọn ìpín-ìpín Tírà (tí A sọ̀kalẹ̀) lẹ́yìn (èyí tí ó wà nínú) Tírà Ìpìlẹ̀ (ìyẹn, Laohul-Mahfūṭḥ) pé dájúdájú ilẹ̀ (Ọgbà Ìdẹ̀ra), àwọn ẹrúsìn Mi, àwọn ẹni rere, ni wọn yóò jogún rẹ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìtúmọ̀ yìí wà ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:74.

### الآية 21:106

> ﻿إِنَّ فِي هَٰذَا لَبَلَاغًا لِقَوْمٍ عَابِدِينَ [21:106]

Dájúdájú ohun t’ó tó mú ni gúnlẹ̀ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ti wà nínú (al-Ƙur’ān) yìí fún ìjọ olùjọ́sìn (fún Mi).

### الآية 21:107

> ﻿وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِلْعَالَمِينَ [21:107]

A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 21:108

> ﻿قُلْ إِنَّمَا يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ مُسْلِمُونَ [21:108]

Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí ni pé, Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin máa di mùsùlùmí?”

### الآية 21:109

> ﻿فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُلْ آذَنْتُكُمْ عَلَىٰ سَوَاءٍ ۖ وَإِنْ أَدْرِي أَقَرِيبٌ أَمْ بَعِيدٌ مَا تُوعَدُونَ [21:109]

Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ nígbà náà pé: "Èmi ń fi to yín létí pé èmi àti ẹ̀yin dì jọ dá dúró fún ogun ẹ̀sìn (tí ó máa ṣẹlẹ̀ láààrin wa báyìí). Èmi kò sì mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín ti súnmọ́ tàbí ó sì jìnnà.

### الآية 21:110

> ﻿إِنَّهُ يَعْلَمُ الْجَهْرَ مِنَ الْقَوْلِ وَيَعْلَمُ مَا تَكْتُمُونَ [21:110]

Dájúdájú (Allāhu) mọ ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.

### الآية 21:111

> ﻿وَإِنْ أَدْرِي لَعَلَّهُ فِتْنَةٌ لَكُمْ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ [21:111]

Èmi kò sì mọ̀ bóyá (lílọ́ yín lára) máa jẹ́ àdánwò àti ìgbádùn fun yín títí di ìgbà díẹ̀."

### الآية 21:112

> ﻿قَالَ رَبِّ احْكُمْ بِالْحَقِّ ۗ وَرَبُّنَا الرَّحْمَٰنُ الْمُسْتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ [21:112]

Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣèdájọ́ pẹ̀lú òdodo. Olúwa wa ni Àjọkẹ́-ayé, Olùrànlọ́wọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń fi ròyìn (Rẹ̀).”

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/21.md)
- [كل تفاسير سورة الأنبياء
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/21.md)
- [ترجمات سورة الأنبياء
](https://quranpedia.net/translations/21.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/21/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
