---
title: "ترجمة سورة المؤمنون - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/23/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/23/book/2001"
surah_id: "23"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة المؤمنون - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/23/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة المؤمنون - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/23/book/2001*.

Translation of Surah المؤمنون from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 23:1

> قَدْ أَفْلَحَ الْمُؤْمِنُونَ [23:1]

Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè.

### الآية 23:2

> ﻿الَّذِينَ هُمْ فِي صَلَاتِهِمْ خَاشِعُونَ [23:2]

Àwọn t’ó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn,

### الآية 23:3

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ عَنِ اللَّغْوِ مُعْرِضُونَ [23:3]

àti àwọn t’ó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ,

### الآية 23:4

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ لِلزَّكَاةِ فَاعِلُونَ [23:4]

àti àwọn t’ó ń yọ Zakāh,

### الآية 23:5

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَافِظُونَ [23:5]

àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,

### الآية 23:6

> ﻿إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ [23:6]

àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn),

### الآية 23:7

> ﻿فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ [23:7]

nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-àlà, 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Lára wíwá òmíràn súnmọ́ yàtọ̀ sí ìyàwó àti ẹrúbìnrin ni sísúnmọ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ’Islām ṣe ní èèwọ̀ fúnni láti fẹ́ (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní sūrah an-Nisā’; 4: 22-24), sísúnmọ́ ẹranko, ìbásùn láààrin ọkùnrin méjì, ìbásùn láààrin obìnrin méjì, fífí ọwọ́ fa àtọ̀-ẹni jáde. Kíyè sí i, ọ̀tọ̀ ni ẹrú, ọ̀tọ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀. Ẹrúbìnrin ni olówó-ẹrú lè fi tura, kì í ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀.

### الآية 23:8

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ لِأَمَانَاتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَاعُونَ [23:8]

àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn,

### الآية 23:9

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَوَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ [23:9]

àti àwọn t’ó ń ṣọ́ ìrun wọn;

### الآية 23:10

> ﻿أُولَٰئِكَ هُمُ الْوَارِثُونَ [23:10]

àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún,

### الآية 23:11

> ﻿الَّذِينَ يَرِثُونَ الْفِرْدَوْسَ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ [23:11]

àwọn t’ó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

### الآية 23:12

> ﻿وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ سُلَالَةٍ مِنْ طِينٍ [23:12]

Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú erùpẹ̀ amọ̀.

### الآية 23:13

> ﻿ثُمَّ جَعَلْنَاهُ نُطْفَةً فِي قَرَارٍ مَكِينٍ [23:13]

Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ).

### الآية 23:14

> ﻿ثُمَّ خَلَقْنَا النُّطْفَةَ عَلَقَةً فَخَلَقْنَا الْعَلَقَةَ مُضْغَةً فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَامًا فَكَسَوْنَا الْعِظَامَ لَحْمًا ثُمَّ أَنْشَأْنَاهُ خَلْقًا آخَرَ ۚ فَتَبَارَكَ اللَّهُ أَحْسَنُ الْخَالِقِينَ [23:14]

Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.1 Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).2 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
1\. Ìyẹn ni pé, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn tí ó ní ẹ̀mí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà sókè bẹ̀rẹ̀ láti òpóǹló títí di ọjọ́ ikú. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

### الآية 23:15

> ﻿ثُمَّ إِنَّكُمْ بَعْدَ ذَٰلِكَ لَمَيِّتُونَ [23:15]

Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yó sì di òkú.

### الآية 23:16

> ﻿ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ تُبْعَثُونَ [23:16]

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde Wọ́n máa gbe yín dìde.

### الآية 23:17

> ﻿وَلَقَدْ خَلَقْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعَ طَرَائِقَ وَمَا كُنَّا عَنِ الْخَلْقِ غَافِلِينَ [23:17]

Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá.

### الآية 23:18

> ﻿وَأَنْزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً بِقَدَرٍ فَأَسْكَنَّاهُ فِي الْأَرْضِ ۖ وَإِنَّا عَلَىٰ ذَهَابٍ بِهِ لَقَادِرُونَ [23:18]

À ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ.

### الآية 23:19

> ﻿فَأَنْشَأْنَا لَكُمْ بِهِ جَنَّاتٍ مِنْ نَخِيلٍ وَأَعْنَابٍ لَكُمْ فِيهَا فَوَاكِهُ كَثِيرَةٌ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ [23:19]

Lẹ́yìn náà, A dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fun yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fun yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.

### الآية 23:20

> ﻿وَشَجَرَةً تَخْرُجُ مِنْ طُورِ سَيْنَاءَ تَنْبُتُ بِالدُّهْنِ وَصِبْغٍ لِلْآكِلِينَ [23:20]

Àti igi kan t’ó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā’; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn t’ó ń jẹ ẹ́.

### الآية 23:21

> ﻿وَإِنَّ لَكُمْ فِي الْأَنْعَامِ لَعِبْرَةً ۖ نُسْقِيكُمْ مِمَّا فِي بُطُونِهَا وَلَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ كَثِيرَةٌ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ [23:21]

Àti pé dájúdájú àríwòye wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fun yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn àǹfààní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (mìíràn) tún wà fun yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.

### الآية 23:22

> ﻿وَعَلَيْهَا وَعَلَى الْفُلْكِ تُحْمَلُونَ [23:22]

Ẹ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi.

### الآية 23:23

> ﻿وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ أَفَلَا تَتَّقُونَ [23:23]

Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

### الآية 23:24

> ﻿فَقَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ قَوْمِهِ مَا هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ يُرِيدُ أَنْ يَتَفَضَّلَ عَلَيْكُمْ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَأَنْزَلَ مَلَائِكَةً مَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي آبَائِنَا الْأَوَّلِينَ [23:24]

Àwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.

### الآية 23:25

> ﻿إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ بِهِ جِنَّةٌ فَتَرَبَّصُوا بِهِ حَتَّىٰ حِينٍ [23:25]

Kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná.”

### الآية 23:26

> ﻿قَالَ رَبِّ انْصُرْنِي بِمَا كَذَّبُونِ [23:26]

(Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́."

### الآية 23:27

> ﻿فَأَوْحَيْنَا إِلَيْهِ أَنِ اصْنَعِ الْفُلْكَ بِأَعْيُنِنَا وَوَحْيِنَا فَإِذَا جَاءَ أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ ۙ فَاسْلُكْ فِيهَا مِنْ كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلَّا مَنْ سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ مِنْهُمْ ۖ وَلَا تُخَاطِبْنِي فِي الَّذِينَ ظَلَمُوا ۖ إِنَّهُمْ مُغْرَقُونَ [23:27]

Nítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni.

### الآية 23:28

> ﻿فَإِذَا اسْتَوَيْتَ أَنْتَ وَمَنْ مَعَكَ عَلَى الْفُلْكِ فَقُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي نَجَّانَا مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [23:28]

Nígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: 'Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí.'"

### الآية 23:29

> ﻿وَقُلْ رَبِّ أَنْزِلْنِي مُنْزَلًا مُبَارَكًا وَأَنْتَ خَيْرُ الْمُنْزِلِينَ [23:29]

Sọ pé: “Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọffāt; 37:125.

### الآية 23:30

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ وَإِنْ كُنَّا لَمُبْتَلِينَ [23:30]

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò.

### الآية 23:31

> ﻿ثُمَّ أَنْشَأْنَا مِنْ بَعْدِهِمْ قَرْنًا آخَرِينَ [23:31]

Lẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.

### الآية 23:32

> ﻿فَأَرْسَلْنَا فِيهِمْ رَسُولًا مِنْهُمْ أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ أَفَلَا تَتَّقُونَ [23:32]

A tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

### الآية 23:33

> ﻿وَقَالَ الْمَلَأُ مِنْ قَوْمِهِ الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِلِقَاءِ الْآخِرَةِ وَأَتْرَفْنَاهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا مَا هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ يَأْكُلُ مِمَّا تَأْكُلُونَ مِنْهُ وَيَشْرَبُ مِمَّا تَشْرَبُونَ [23:33]

Àwọn olórí t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn t’ó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu.

### الآية 23:34

> ﻿وَلَئِنْ أَطَعْتُمْ بَشَرًا مِثْلَكُمْ إِنَّكُمْ إِذًا لَخَاسِرُونَ [23:34]

Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn.

### الآية 23:35

> ﻿أَيَعِدُكُمْ أَنَّكُمْ إِذَا مِتُّمْ وَكُنْتُمْ تُرَابًا وَعِظَامًا أَنَّكُمْ مُخْرَجُونَ [23:35]

Ṣé ó ń ṣe àdéhùn fun yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú Wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)?

### الآية 23:36

> ﻿۞ هَيْهَاتَ هَيْهَاتَ لِمَا تُوعَدُونَ [23:36]

Ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo).

### الآية 23:37

> ﻿إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ [23:37]

Kò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Kò sì sí pé Wọn yóò gbé wa dìde mọ́.

### الآية 23:38

> ﻿إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا وَمَا نَحْنُ لَهُ بِمُؤْمِنِينَ [23:38]

(Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́."

### الآية 23:39

> ﻿قَالَ رَبِّ انْصُرْنِي بِمَا كَذَّبُونِ [23:39]

(Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́."

### الآية 23:40

> ﻿قَالَ عَمَّا قَلِيلٍ لَيُصْبِحُنَّ نَادِمِينَ [23:40]

(Allāhu) sọ pé: “Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀.”

### الآية 23:41

> ﻿فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ بِالْحَقِّ فَجَعَلْنَاهُمْ غُثَاءً ۚ فَبُعْدًا لِلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [23:41]

Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn lọ́nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí.

### الآية 23:42

> ﻿ثُمَّ أَنْشَأْنَا مِنْ بَعْدِهِمْ قُرُونًا آخَرِينَ [23:42]

Lẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.

### الآية 23:43

> ﻿مَا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ [23:43]

Ìjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) síwájú.

### الآية 23:44

> ﻿ثُمَّ أَرْسَلْنَا رُسُلَنَا تَتْرَىٰ ۖ كُلَّ مَا جَاءَ أُمَّةً رَسُولُهَا كَذَّبُوهُ ۚ فَأَتْبَعْنَا بَعْضَهُمْ بَعْضًا وَجَعَلْنَاهُمْ أَحَادِيثَ ۚ فَبُعْدًا لِقَوْمٍ لَا يُؤْمِنُونَ [23:44]

Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n ń pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ lódodo.

### الآية 23:45

> ﻿ثُمَّ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ وَأَخَاهُ هَارُونَ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُبِينٍ [23:45]

Lẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé.

### الآية 23:46

> ﻿إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا عَالِينَ [23:46]

(A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba.

### الآية 23:47

> ﻿فَقَالُوا أَنُؤْمِنُ لِبَشَرَيْنِ مِثْلِنَا وَقَوْمُهُمَا لَنَا عَابِدُونَ [23:47]

Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?”

### الآية 23:48

> ﻿فَكَذَّبُوهُمَا فَكَانُوا مِنَ الْمُهْلَكِينَ [23:48]

Nítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn ẹni- ìparun.

### الآية 23:49

> ﻿وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ [23:49]

Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.

### الآية 23:50

> ﻿وَجَعَلْنَا ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ آيَةً وَآوَيْنَاهُمَا إِلَىٰ رَبْوَةٍ ذَاتِ قَرَارٍ وَمَعِينٍ [23:50]

A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, t’ó ní ibùgbé, t’ó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Anbiyā’ 21;91

### الآية 23:51

> ﻿يَا أَيُّهَا الرُّسُلُ كُلُوا مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَاعْمَلُوا صَالِحًا ۖ إِنِّي بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ [23:51]

Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 23:52

> ﻿وَإِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاتَّقُونِ [23:52]

Àti pé dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.

### الآية 23:53

> ﻿فَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُمْ بَيْنَهُمْ زُبُرًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ [23:53]

Ṣùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun t’ó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn.

### الآية 23:54

> ﻿فَذَرْهُمْ فِي غَمْرَتِهِمْ حَتَّىٰ حِينٍ [23:54]

Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná.

### الآية 23:55

> ﻿أَيَحْسَبُونَ أَنَّمَا نُمِدُّهُمْ بِهِ مِنْ مَالٍ وَبَنِينَ [23:55]

Ṣé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn,

### الآية 23:56

> ﻿نُسَارِعُ لَهُمْ فِي الْخَيْرَاتِ ۚ بَلْ لَا يَشْعُرُونَ [23:56]

ni A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni! 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ èsì fún ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn aláìgbàgbọ́ tí wọ́n lérò pé ẹni ayé bá yẹ ni ọ̀run yóò yẹ. Àmọ́ kò yé wọn pé, oore ilé ayé yìí wà ní abẹ́ oore Àjọkẹ́-ayé (ar-rahmāniyyah) fún gbogbo ẹ̀dá láì fi tẹ̀sìn ṣe.Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, oore ọ̀run wà ní abẹ́ oore Àṣàkẹ́ ọ̀run (ar-rahīmiyyah) fún ọ̀wọ́ àwa onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, oore ẹ̀dẹ tí kò lè dé ọ̀run ni oore ọwọ́ aláìgbàgbọ́ àti ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí.

### الآية 23:57

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ هُمْ مِنْ خَشْيَةِ رَبِّهِمْ مُشْفِقُونَ [23:57]

Dájúdájú àwọn t’ó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) fún ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn;

### الآية 23:58

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ بِآيَاتِ رَبِّهِمْ يُؤْمِنُونَ [23:58]

àti àwọn t’ó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́;

### الآية 23:59

> ﻿وَالَّذِينَ هُمْ بِرَبِّهِمْ لَا يُشْرِكُونَ [23:59]

àti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn,

### الآية 23:60

> ﻿وَالَّذِينَ يُؤْتُونَ مَا آتَوْا وَقُلُوبُهُمْ وَجِلَةٌ أَنَّهُمْ إِلَىٰ رَبِّهِمْ رَاجِعُونَ [23:60]

àti àwọn t’ó ń ṣe ohun rere (nínú iṣẹ́) tí wọ́n ṣe, pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;

### الآية 23:61

> ﻿أُولَٰئِكَ يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَهُمْ لَهَا سَابِقُونَ [23:61]

àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà.

### الآية 23:62

> ﻿وَلَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۖ وَلَدَيْنَا كِتَابٌ يَنْطِقُ بِالْحَقِّ ۚ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ [23:62]

Àti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan t’ó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

### الآية 23:63

> ﻿بَلْ قُلُوبُهُمْ فِي غَمْرَةٍ مِنْ هَٰذَا وَلَهُمْ أَعْمَالٌ مِنْ دُونِ ذَٰلِكَ هُمْ لَهَا عَامِلُونَ [23:63]

Àmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur’ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn. Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
"Iṣẹ́ rere yẹn" ni àwọn iṣẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ròyìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ṣíwájú nínú āyah 57 sí āyah 61.

### الآية 23:64

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا أَخَذْنَا مُتْرَفِيهِمْ بِالْعَذَابِ إِذَا هُمْ يَجْأَرُونَ [23:64]

títí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa ké gbàjarì.

### الآية 23:65

> ﻿لَا تَجْأَرُوا الْيَوْمَ ۖ إِنَّكُمْ مِنَّا لَا تُنْصَرُونَ [23:65]

Ẹ má kèé gbàjarì lónìí. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa.

### الآية 23:66

> ﻿قَدْ كَانَتْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنْتُمْ عَلَىٰ أَعْقَابِكُمْ تَنْكِصُونَ [23:66]

Wọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fun yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo).

### الآية 23:67

> ﻿مُسْتَكْبِرِينَ بِهِ سَامِرًا تَهْجُرُونَ [23:67]

Ẹ̀ sì ń fi Kaaba ṣègbéraga, ẹ tún ń fi òru yín sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur’ān)!

### الآية 23:68

> ﻿أَفَلَمْ يَدَّبَّرُوا الْقَوْلَ أَمْ جَاءَهُمْ مَا لَمْ يَأْتِ آبَاءَهُمُ الْأَوَّلِينَ [23:68]

Ṣé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun t’ó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni?

### الآية 23:69

> ﻿أَمْ لَمْ يَعْرِفُوا رَسُولَهُمْ فَهُمْ لَهُ مُنْكِرُونَ [23:69]

Tàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀?

### الآية 23:70

> ﻿أَمْ يَقُولُونَ بِهِ جِنَّةٌ ۚ بَلْ جَاءَهُمْ بِالْحَقِّ وَأَكْثَرُهُمْ لِلْحَقِّ كَارِهُونَ [23:70]

Tàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo.

### الآية 23:71

> ﻿وَلَوِ اتَّبَعَ الْحَقُّ أَهْوَاءَهُمْ لَفَسَدَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ وَمَنْ فِيهِنَّ ۚ بَلْ أَتَيْنَاهُمْ بِذِكْرِهِمْ فَهُمْ عَنْ ذِكْرِهِمْ مُعْرِضُونَ [23:71]

Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn t’ó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.

### الآية 23:72

> ﻿أَمْ تَسْأَلُهُمْ خَرْجًا فَخَرَاجُ رَبِّكَ خَيْرٌ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ [23:72]

Tàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

### الآية 23:73

> ﻿وَإِنَّكَ لَتَدْعُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ [23:73]

Àti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni.

### الآية 23:74

> ﻿وَإِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ عَنِ الصِّرَاطِ لَنَاكِبُونَ [23:74]

Àwọn tí kò sì gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà.

### الآية 23:75

> ﻿۞ وَلَوْ رَحِمْنَاهُمْ وَكَشَفْنَا مَا بِهِمْ مِنْ ضُرٍّ لَلَجُّوا فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ [23:75]

Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-àlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).

### الآية 23:76

> ﻿وَلَقَدْ أَخَذْنَاهُمْ بِالْعَذَابِ فَمَا اسْتَكَانُوا لِرَبِّهِمْ وَمَا يَتَضَرَّعُونَ [23:76]

Dájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I

### الآية 23:77

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا فَتَحْنَا عَلَيْهِمْ بَابًا ذَا عَذَابٍ شَدِيدٍ إِذَا هُمْ فِيهِ مُبْلِسُونَ [23:77]

títí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù.

### الآية 23:78

> ﻿وَهُوَ الَّذِي أَنْشَأَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۚ قَلِيلًا مَا تَشْكُرُونَ [23:78]

(Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fun yín, ìdúpẹ́ yín sì kéré.

### الآية 23:79

> ﻿وَهُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ [23:79]

Òun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí.

### الآية 23:80

> ﻿وَهُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ وَلَهُ اخْتِلَافُ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ [23:80]

Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

### الآية 23:81

> ﻿بَلْ قَالُوا مِثْلَ مَا قَالَ الْأَوَّلُونَ [23:81]

Rárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí.

### الآية 23:82

> ﻿قَالُوا أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ [23:82]

Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni?

### الآية 23:83

> ﻿لَقَدْ وُعِدْنَا نَحْنُ وَآبَاؤُنَا هَٰذَا مِنْ قَبْلُ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ [23:83]

Wọ́n kúkú ti ṣe àdéhùn yìí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

### الآية 23:84

> ﻿قُلْ لِمَنِ الْأَرْضُ وَمَنْ فِيهَا إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ [23:84]

Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”

### الآية 23:85

> ﻿سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ [23:85]

Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?”

### الآية 23:86

> ﻿قُلْ مَنْ رَبُّ السَّمَاوَاتِ السَّبْعِ وَرَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ [23:86]

Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?”

### الآية 23:87

> ﻿سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ أَفَلَا تَتَّقُونَ [23:87]

Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

### الآية 23:88

> ﻿قُلْ مَنْ بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيْهِ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ [23:88]

Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?” Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”

### الآية 23:89

> ﻿سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ فَأَنَّىٰ تُسْحَرُونَ [23:89]

Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?”

### الآية 23:90

> ﻿بَلْ أَتَيْنَاهُمْ بِالْحَقِّ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ [23:90]

Àmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́.

### الآية 23:91

> ﻿مَا اتَّخَذَ اللَّهُ مِنْ وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَٰهٍ ۚ إِذًا لَذَهَبَ كُلُّ إِلَٰهٍ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلَا بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ [23:91]

Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá t’ó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).

### الآية 23:92

> ﻿عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ [23:92]

(Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.

### الآية 23:93

> ﻿قُلْ رَبِّ إِمَّا تُرِيَنِّي مَا يُوعَدُونَ [23:93]

Sọ pé: “Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn hàn mí,

### الآية 23:94

> ﻿رَبِّ فَلَا تَجْعَلْنِي فِي الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [23:94]

Olúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí.”

### الآية 23:95

> ﻿وَإِنَّا عَلَىٰ أَنْ نُرِيَكَ مَا نَعِدُهُمْ لَقَادِرُونَ [23:95]

Dájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́.

### الآية 23:96

> ﻿ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ السَّيِّئَةَ ۚ نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَصِفُونَ [23:96]

Fi èyí t’ó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa).

### الآية 23:97

> ﻿وَقُلْ رَبِّ أَعُوذُ بِكَ مِنْ هَمَزَاتِ الشَّيَاطِينِ [23:97]

Sọ pé: "Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t’àwọn èṣù.

### الآية 23:98

> ﻿وَأَعُوذُ بِكَ رَبِّ أَنْ يَحْضُرُونِ [23:98]

Mò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi."

### الآية 23:99

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُونِ [23:99]

(Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: “Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)

### الآية 23:100

> ﻿لَعَلِّي أَعْمَلُ صَالِحًا فِيمَا تَرَكْتُ ۚ كَلَّا ۚ إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَائِلُهَا ۖ وَمِنْ وَرَائِهِمْ بَرْزَخٌ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ [23:100]

nítorí kí n̄g lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (99 àti 100) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú. Irú āyah yìí tún wà nínú sūrah az-Zumọr; 39:58 àti 59. 
Síwájú sí i, àkúdàáyà kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ète àlùpàyídà láti ọ̀dọ̀ àwọn èṣù àlùjànnú. Irú ètekéte yìí náà ni àwọn olówò àlùjànnú máa ń lo láti fi ṣe àwọn òògùn ẹbọ bíi àfẹ́ẹ̀rí, ayẹta, òkígbẹ́, ìṣíjú, ọ̀wọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, kì í ṣe òkú gan-an gan-an ní wọ́n tún lè rí mọ́ níbikíbi nílé ayé, àmọ́ àwọn èṣù àlùjànnú kan lè gbé àwọ̀ àti àwòrán òkú kan wọ̀ láti tan àwọn aláìgbàgbọ́ jẹ. Èyí sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òye t’ó wà nínú mọ̀mí-n̄g-mọ̀ọ́ t’ó gbọ́dọ̀ wáyé láààrin àwọn ẹbí t’ó fẹ́ di tọkọ taya nítorí kí ẹnì kan má baà fi èṣù àlùjànnú ṣe ẹnì kejì rẹ̀.

### الآية 23:101

> ﻿فَإِذَا نُفِخَ فِي الصُّورِ فَلَا أَنْسَابَ بَيْنَهُمْ يَوْمَئِذٍ وَلَا يَتَسَاءَلُونَ [23:101]

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Āyah yìí tako sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:27 nípa ọ̀rọ̀ ìbéèrè.” Èsì: Kò sí ìtakora nínú rẹ̀. Ẹ wò ó, gbólóhùn yìí “wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè” ìyẹn ní kété tí olúkùlùkù bá kọ́kọ́ jí dìde láti inú sàréè rẹ̀. Iyè yóò pamọ́ àwọn ẹ̀dá nínú lásìkò náà ni, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọsọ; 28:66 àti sūrah az-Zumọr 39:68. Àmọ́ nígbà tí àwọn mọlāika bá da àwọn ẹ̀dá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), àwọn ẹ̀dá máa bẹ̀rẹ̀ sí i bira wọn léèrè ìbéèrè ní ti àbámọ̀ àti ìtakora, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:27. Nítorí náà, kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà gẹ́gẹ́ bí àwọn kristiẹni ṣe lérò.

### الآية 23:102

> ﻿فَمَنْ ثَقُلَتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [23:102]

Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.

### الآية 23:103

> ﻿وَمَنْ خَفَّتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ فِي جَهَنَّمَ خَالِدُونَ [23:103]

Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ.

### الآية 23:104

> ﻿تَلْفَحُ وُجُوهَهُمُ النَّارُ وَهُمْ فِيهَا كَالِحُونَ [23:104]

Iná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́.

### الآية 23:105

> ﻿أَلَمْ تَكُنْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنْتُمْ بِهَا تُكَذِّبُونَ [23:105]

Ṣé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fun yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é nírọ́?

### الآية 23:106

> ﻿قَالُوا رَبَّنَا غَلَبَتْ عَلَيْنَا شِقْوَتُنَا وَكُنَّا قَوْمًا ضَالِّينَ [23:106]

Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, orí burúkú l’ó kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà.

### الآية 23:107

> ﻿رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْهَا فَإِنْ عُدْنَا فَإِنَّا ظَالِمُونَ [23:107]

Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa."

### الآية 23:108

> ﻿قَالَ اخْسَئُوا فِيهَا وَلَا تُكَلِّمُونِ [23:108]

(Allāhu) sọ pé: “Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀.”

### الآية 23:109

> ﻿إِنَّهُ كَانَ فَرِيقٌ مِنْ عِبَادِي يَقُولُونَ رَبَّنَا آمَنَّا فَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا وَأَنْتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ [23:109]

Dájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

### الآية 23:110

> ﻿فَاتَّخَذْتُمُوهُمْ سِخْرِيًّا حَتَّىٰ أَنْسَوْكُمْ ذِكْرِي وَكُنْتُمْ مِنْهُمْ تَضْحَكُونَ [23:110]

Ṣùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín.

### الآية 23:111

> ﻿إِنِّي جَزَيْتُهُمُ الْيَوْمَ بِمَا صَبَرُوا أَنَّهُمْ هُمُ الْفَائِزُونَ [23:111]

Dájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn, àwọn ni olùjèrè.

### الآية 23:112

> ﻿قَالَ كَمْ لَبِثْتُمْ فِي الْأَرْضِ عَدَدَ سِنِينَ [23:112]

(Allāhu) sọ pé: "Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé?"

### الآية 23:113

> ﻿قَالُوا لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ فَاسْأَلِ الْعَادِّينَ [23:113]

Wọ́n wí pé: “A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò.”

### الآية 23:114

> ﻿قَالَ إِنْ لَبِثْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا ۖ لَوْ أَنَّكُمْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ [23:114]

(Allāhu) sọ pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”

### الآية 23:115

> ﻿أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ [23:115]

Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?”

### الآية 23:116

> ﻿فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ [23:116]

Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé.

### الآية 23:117

> ﻿وَمَنْ يَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ لَا بُرْهَانَ لَهُ بِهِ فَإِنَّمَا حِسَابُهُ عِنْدَ رَبِّهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ [23:117]

Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè.

### الآية 23:118

> ﻿وَقُلْ رَبِّ اغْفِرْ وَارْحَمْ وَأَنْتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ [23:118]

Sọ pé: “Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/23.md)
- [كل تفاسير سورة المؤمنون
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/23.md)
- [ترجمات سورة المؤمنون
](https://quranpedia.net/translations/23.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/23/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
