---
title: "ترجمة سورة الشعراء - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/26/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/26/book/2001"
surah_id: "26"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الشعراء - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/26/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الشعراء - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/26/book/2001*.

Translation of Surah الشعراء from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 26:1

> طسم [26:1]

Tọ̄ sīn mīm.

### الآية 26:2

> ﻿تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ [26:2]

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

### الآية 26:3

> ﻿لَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَفْسَكَ أَلَّا يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ [26:3]

Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:4

> ﻿إِنْ نَشَأْ نُنَزِّلْ عَلَيْهِمْ مِنَ السَّمَاءِ آيَةً فَظَلَّتْ أَعْنَاقُهُمْ لَهَا خَاضِعِينَ [26:4]

Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.

### الآية 26:5

> ﻿وَمَا يَأْتِيهِمْ مِنْ ذِكْرٍ مِنَ الرَّحْمَٰنِ مُحْدَثٍ إِلَّا كَانُوا عَنْهُ مُعْرِضِينَ [26:5]

Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.

### الآية 26:6

> ﻿فَقَدْ كَذَّبُوا فَسَيَأْتِيهِمْ أَنْبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ [26:6]

Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.

### الآية 26:7

> ﻿أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الْأَرْضِ كَمْ أَنْبَتْنَا فِيهَا مِنْ كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ [26:7]

Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?

### الآية 26:8

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:8]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:9

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:9]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:10

> ﻿وَإِذْ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰ أَنِ ائْتِ الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ [26:10]

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: "Lọ bá ìjọ alábòsí,

### الآية 26:11

> ﻿قَوْمَ فِرْعَوْنَ ۚ أَلَا يَتَّقُونَ [26:11]

ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé 'Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.'"

### الآية 26:12

> ﻿قَالَ رَبِّ إِنِّي أَخَافُ أَنْ يُكَذِّبُونِ [26:12]

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.

### الآية 26:13

> ﻿وَيَضِيقُ صَدْرِي وَلَا يَنْطَلِقُ لِسَانِي فَأَرْسِلْ إِلَىٰ هَارُونَ [26:13]

Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.

### الآية 26:14

> ﻿وَلَهُمْ عَلَيَّ ذَنْبٌ فَأَخَافُ أَنْ يَقْتُلُونِ [26:14]

Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí."

### الآية 26:15

> ﻿قَالَ كَلَّا ۖ فَاذْهَبَا بِآيَاتِنَا ۖ إِنَّا مَعَكُمْ مُسْتَمِعُونَ [26:15]

(Allāhu) sọ pé: "Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).

### الآية 26:16

> ﻿فَأْتِيَا فِرْعَوْنَ فَقُولَا إِنَّا رَسُولُ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:16]

Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: 'Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:17

> ﻿أَنْ أَرْسِلْ مَعَنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ [26:17]

(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.'"

### الآية 26:18

> ﻿قَالَ أَلَمْ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدًا وَلَبِثْتَ فِينَا مِنْ عُمُرِكَ سِنِينَ [26:18]

(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?

### الآية 26:19

> ﻿وَفَعَلْتَ فَعْلَتَكَ الَّتِي فَعَلْتَ وَأَنْتَ مِنَ الْكَافِرِينَ [26:19]

O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”

### الآية 26:20

> ﻿قَالَ فَعَلْتُهَا إِذًا وَأَنَا مِنَ الضَّالِّينَ [26:20]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláìmọ̀kan ni.

### الآية 26:21

> ﻿فَفَرَرْتُ مِنْكُمْ لَمَّا خِفْتُكُمْ فَوَهَبَ لِي رَبِّي حُكْمًا وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُرْسَلِينَ [26:21]

Mo sì sá fun yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Nítorí náà, Allāhu ti ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.

### الآية 26:22

> ﻿وَتِلْكَ نِعْمَةٌ تَمُنُّهَا عَلَيَّ أَنْ عَبَّدْتَ بَنِي إِسْرَائِيلَ [26:22]

Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń fọ èsì fún Fir ‘aon pé, tí o bá sọ pé o ṣoore alágbàtọ́ fún mi, ṣebí o tún sọ àwọn ènìyàn mi di ẹrú rẹ?! Ìyẹn ni pé, tí Fir ‘aon bá mọ ìrègún oore síṣe alágbàtọ́ òun í ṣe, kó rántí aburú ńlá t’ó wà nínú bí ó ṣe sọ àwọn ènìyàn t’òun náà di ẹrú rẹ̀. Nítorí náà, kí Fir ‘aon má ṣe lérò pé gbígba ẹnì kan wò tẹ̀wọ̀n ju sísọ àwọn yòókù rẹ̀ di ẹrú. Fir‘aon sì mẹ́nu kúrò níbẹ̀. Ó bọ́ sórí ọ̀rọ̀ mìíràn.

### الآية 26:23

> ﻿قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ الْعَالَمِينَ [26:23]

Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”

### الآية 26:24

> ﻿قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِنْ كُنْتُمْ مُوقِنِينَ [26:24]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni)
Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”

### الآية 26:25

> ﻿قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُ أَلَا تَسْتَمِعُونَ [26:25]

(Fir‘aon) wí fún àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (t’ó ń sọ ni)?”

### الآية 26:26

> ﻿قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ [26:26]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

### الآية 26:27

> ﻿قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ [26:27]

(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”

### الآية 26:28

> ﻿قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِنْ كُنْتُمْ تَعْقِلُونَ [26:28]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”

### الآية 26:29

> ﻿قَالَ لَئِنِ اتَّخَذْتَ إِلَٰهًا غَيْرِي لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ الْمَسْجُونِينَ [26:29]

(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”

### الآية 26:30

> ﻿قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكَ بِشَيْءٍ مُبِينٍ [26:30]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan t’ó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”

### الآية 26:31

> ﻿قَالَ فَأْتِ بِهِ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ [26:31]

(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”

### الآية 26:32

> ﻿فَأَلْقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعْبَانٌ مُبِينٌ [26:32]

Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.

### الآية 26:33

> ﻿وَنَزَعَ يَدَهُ فَإِذَا هِيَ بَيْضَاءُ لِلنَّاظِرِينَ [26:33]

Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.

### الآية 26:34

> ﻿قَالَ لِلْمَلَإِ حَوْلَهُ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ عَلِيمٌ [26:34]

(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.

### الآية 26:35

> ﻿يُرِيدُ أَنْ يُخْرِجَكُمْ مِنْ أَرْضِكُمْ بِسِحْرِهِ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ [26:35]

Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:109- 110, gbólóhùn "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa. Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni.", ó jáde láti ẹnu àwọn ìjòyè Fir‘aon. Àmọ́ nínú sūrah yìí, sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26: 34-35, gbólóhùn yẹn jáde láti ẹnu Fir‘aon. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, Fir‘aon sọ gbólóhùn náà, àwọn ìjòyè rẹ̀ náà gbè é lẹ́sẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà sì di àgbàsọ láààrin wọn.

### الآية 26:36

> ﻿قَالُوا أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَابْعَثْ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ [26:36]

Wọ́n wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú

### الآية 26:37

> ﻿يَأْتُوكَ بِكُلِّ سَحَّارٍ عَلِيمٍ [26:37]

(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ."

### الآية 26:38

> ﻿فَجُمِعَ السَّحَرَةُ لِمِيقَاتِ يَوْمٍ مَعْلُومٍ [26:38]

Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.

### الآية 26:39

> ﻿وَقِيلَ لِلنَّاسِ هَلْ أَنْتُمْ مُجْتَمِعُونَ [26:39]

Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: "Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?

### الآية 26:40

> ﻿لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ السَّحَرَةَ إِنْ كَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ [26:40]

Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí."

### الآية 26:41

> ﻿فَلَمَّا جَاءَ السَّحَرَةُ قَالُوا لِفِرْعَوْنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجْرًا إِنْ كُنَّا نَحْنُ الْغَالِبِينَ [26:41]

Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”

### الآية 26:42

> ﻿قَالَ نَعَمْ وَإِنَّكُمْ إِذًا لَمِنَ الْمُقَرَّبِينَ [26:42]

(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”

### الآية 26:43

> ﻿قَالَ لَهُمْ مُوسَىٰ أَلْقُوا مَا أَنْتُمْ مُلْقُونَ [26:43]

(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”

### الآية 26:44

> ﻿فَأَلْقَوْا حِبَالَهُمْ وَعِصِيَّهُمْ وَقَالُوا بِعِزَّةِ فِرْعَوْنَ إِنَّا لَنَحْنُ الْغَالِبُونَ [26:44]

Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”

### الآية 26:45

> ﻿فَأَلْقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ [26:45]

Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.

### الآية 26:46

> ﻿فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سَاجِدِينَ [26:46]

Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

### الآية 26:47

> ﻿قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ الْعَالَمِينَ [26:47]

Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,

### الآية 26:48

> ﻿رَبِّ مُوسَىٰ وَهَارُونَ [26:48]

Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn."

### الآية 26:49

> ﻿قَالَ آمَنْتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ فَلَسَوْفَ تَعْلَمُونَ ۚ لَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُمْ مِنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ أَجْمَعِينَ [26:49]

Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”

### الآية 26:50

> ﻿قَالُوا لَا ضَيْرَ ۖ إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنْقَلِبُونَ [26:50]

(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.

### الآية 26:51

> ﻿إِنَّا نَطْمَعُ أَنْ يَغْفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَايَانَا أَنْ كُنَّا أَوَّلَ الْمُؤْمِنِينَ [26:51]

Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú ìjọ Fir‘aon. Kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú àwọn ènìyàn. Ṣebí ìjọ-ìjọ onígbàgbọ́ òdodo ti ré kọjá ṣíwájú wọn.

### الآية 26:52

> ﻿۞ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِي إِنَّكُمْ مُتَّبَعُونَ [26:52]

A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé) dájúdájú wọn yóò lépa yín.”

### الآية 26:53

> ﻿فَأَرْسَلَ فِرْعَوْنُ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ [26:53]

Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):

### الآية 26:54

> ﻿إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَشِرْذِمَةٌ قَلِيلُونَ [26:54]

"Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.

### الآية 26:55

> ﻿وَإِنَّهُمْ لَنَا لَغَائِظُونَ [26:55]

Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun t’ó ń bí wa nínú.

### الآية 26:56

> ﻿وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَاذِرُونَ [26:56]

Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura."

### الآية 26:57

> ﻿فَأَخْرَجْنَاهُمْ مِنْ جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ [26:57]

Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,

### الآية 26:58

> ﻿وَكُنُوزٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ [26:58]

àti àwọn àpótí-ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.

### الآية 26:59

> ﻿كَذَٰلِكَ وَأَوْرَثْنَاهَا بَنِي إِسْرَائِيلَ [26:59]

Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

### الآية 26:60

> ﻿فَأَتْبَعُوهُمْ مُشْرِقِينَ [26:60]

Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.

### الآية 26:61

> ﻿فَلَمَّا تَرَاءَى الْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَابُ مُوسَىٰ إِنَّا لَمُدْرَكُونَ [26:61]

Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”

### الآية 26:62

> ﻿قَالَ كَلَّا ۖ إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهْدِينِ [26:62]

(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”

### الآية 26:63

> ﻿فَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنِ اضْرِبْ بِعَصَاكَ الْبَحْرَ ۖ فَانْفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرْقٍ كَالطَّوْدِ الْعَظِيمِ [26:63]

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà á). Ó sì pín (sí ọ̀nà méjìlá). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.

### الآية 26:64

> ﻿وَأَزْلَفْنَا ثَمَّ الْآخَرِينَ [26:64]

A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.

### الآية 26:65

> ﻿وَأَنْجَيْنَا مُوسَىٰ وَمَنْ مَعَهُ أَجْمَعِينَ [26:65]

A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.

### الآية 26:66

> ﻿ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ [26:66]

Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).

### الآية 26:67

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:67]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:68

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:68]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:69

> ﻿وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ إِبْرَاهِيمَ [26:69]

Ka ìròyìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.

### الآية 26:70

> ﻿إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا تَعْبُدُونَ [26:70]

Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”

### الآية 26:71

> ﻿قَالُوا نَعْبُدُ أَصْنَامًا فَنَظَلُّ لَهَا عَاكِفِينَ [26:71]

Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”

### الآية 26:72

> ﻿قَالَ هَلْ يَسْمَعُونَكُمْ إِذْ تَدْعُونَ [26:72]

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?

### الآية 26:73

> ﻿أَوْ يَنْفَعُونَكُمْ أَوْ يَضُرُّونَ [26:73]

Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní oore tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”

### الآية 26:74

> ﻿قَالُوا بَلْ وَجَدْنَا آبَاءَنَا كَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ [26:74]

Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa, tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”

### الآية 26:75

> ﻿قَالَ أَفَرَأَيْتُمْ مَا كُنْتُمْ تَعْبُدُونَ [26:75]

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,

### الآية 26:76

> ﻿أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمُ الْأَقْدَمُونَ [26:76]

ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ìṣaájú?

### الآية 26:77

> ﻿فَإِنَّهُمْ عَدُوٌّ لِي إِلَّا رَبَّ الْعَالَمِينَ [26:77]

Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:78

> ﻿الَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهْدِينِ [26:78]

(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;

### الآية 26:79

> ﻿وَالَّذِي هُوَ يُطْعِمُنِي وَيَسْقِينِ [26:79]

Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu;

### الآية 26:80

> ﻿وَإِذَا مَرِضْتُ فَهُوَ يَشْفِينِ [26:80]

Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;

### الآية 26:81

> ﻿وَالَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحْيِينِ [26:81]

Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;

### الآية 26:82

> ﻿وَالَّذِي أَطْمَعُ أَنْ يَغْفِرَ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ [26:82]

Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.

### الآية 26:83

> ﻿رَبِّ هَبْ لِي حُكْمًا وَأَلْحِقْنِي بِالصَّالِحِينَ [26:83]

Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.

### الآية 26:84

> ﻿وَاجْعَلْ لِي لِسَانَ صِدْقٍ فِي الْآخِرِينَ [26:84]

Jẹ́ kí àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn (mi) máa sọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú dáadáa.

### الآية 26:85

> ﻿وَاجْعَلْنِي مِنْ وَرَثَةِ جَنَّةِ النَّعِيمِ [26:85]

Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.

### الآية 26:86

> ﻿وَاغْفِرْ لِأَبِي إِنَّهُ كَانَ مِنَ الضَّالِّينَ [26:86]

Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.

### الآية 26:87

> ﻿وَلَا تُخْزِنِي يَوْمَ يُبْعَثُونَ [26:87]

Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.

### الآية 26:88

> ﻿يَوْمَ لَا يَنْفَعُ مَالٌ وَلَا بَنُونَ [26:88]

Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.

### الآية 26:89

> ﻿إِلَّا مَنْ أَتَى اللَّهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ [26:89]

Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́." 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ọkàn mímọ́ ni ọkàn tí ó là kúrò nínú ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn.

### الآية 26:90

> ﻿وَأُزْلِفَتِ الْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ [26:90]

A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

### الآية 26:91

> ﻿وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِلْغَاوِينَ [26:91]

Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,

### الآية 26:92

> ﻿وَقِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنْتُمْ تَعْبُدُونَ [26:92]

wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”

### الآية 26:93

> ﻿مِنْ دُونِ اللَّهِ هَلْ يَنْصُرُونَكُمْ أَوْ يَنْتَصِرُونَ [26:93]

(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?

### الآية 26:94

> ﻿فَكُبْكِبُوا فِيهَا هُمْ وَالْغَاوُونَ [26:94]

Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn sínú Iná; àwọn àti èṣù wọn,

### الآية 26:95

> ﻿وَجُنُودُ إِبْلِيسَ أَجْمَعُونَ [26:95]

àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá.

### الآية 26:96

> ﻿قَالُوا وَهُمْ فِيهَا يَخْتَصِمُونَ [26:96]

(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:

### الآية 26:97

> ﻿تَاللَّهِ إِنْ كُنَّا لَفِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [26:97]

"A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

### الآية 26:98

> ﻿إِذْ نُسَوِّيكُمْ بِرَبِّ الْعَالَمِينَ [26:98]

nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:99

> ﻿وَمَا أَضَلَّنَا إِلَّا الْمُجْرِمُونَ [26:99]

Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (èṣù) ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 26:100

> ﻿فَمَا لَنَا مِنْ شَافِعِينَ [26:100]

Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa.

### الآية 26:101

> ﻿وَلَا صَدِيقٍ حَمِيمٍ [26:101]

Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.)

### الآية 26:102

> ﻿فَلَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ [26:102]

Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."

### الآية 26:103

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:103]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:104

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:104]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:105

> ﻿كَذَّبَتْ قَوْمُ نُوحٍ الْمُرْسَلِينَ [26:105]

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

### الآية 26:106

> ﻿إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ [26:106]

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

### الآية 26:107

> ﻿إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ [26:107]

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.

### الآية 26:108

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:108]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:109

> ﻿وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:109]

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:110

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:110]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”

### الآية 26:111

> ﻿۞ قَالُوا أَنُؤْمِنُ لَكَ وَاتَّبَعَكَ الْأَرْذَلُونَ [26:111]

Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”

### الآية 26:112

> ﻿قَالَ وَمَا عِلْمِي بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [26:112]

Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).

### الآية 26:113

> ﻿إِنْ حِسَابُهُمْ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّي ۖ لَوْ تَشْعُرُونَ [26:113]

Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.

### الآية 26:114

> ﻿وَمَا أَنَا بِطَارِدِ الْمُؤْمِنِينَ [26:114]

Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.

### الآية 26:115

> ﻿إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُبِينٌ [26:115]

Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

### الآية 26:116

> ﻿قَالُوا لَئِنْ لَمْ تَنْتَهِ يَا نُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمَرْجُومِينَ [26:116]

Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”

### الآية 26:117

> ﻿قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوْمِي كَذَّبُونِ [26:117]

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.

### الآية 26:118

> ﻿فَافْتَحْ بَيْنِي وَبَيْنَهُمْ فَتْحًا وَنَجِّنِي وَمَنْ مَعِيَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ [26:118]

Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

### الآية 26:119

> ﻿فَأَنْجَيْنَاهُ وَمَنْ مَعَهُ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ [26:119]

A la òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́.

### الآية 26:120

> ﻿ثُمَّ أَغْرَقْنَا بَعْدُ الْبَاقِينَ [26:120]

Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn t’ó ṣẹ́kù rì sínú omi.

### الآية 26:121

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:121]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:122

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:122]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:123

> ﻿كَذَّبَتْ عَادٌ الْمُرْسَلِينَ [26:123]

Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

### الآية 26:124

> ﻿إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ [26:124]

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

### الآية 26:125

> ﻿إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ [26:125]

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.

### الآية 26:126

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:126]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:127

> ﻿وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:127]

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:128

> ﻿أَتَبْنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ آيَةً تَعْبَثُونَ [26:128]

Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?

### الآية 26:129

> ﻿وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمْ تَخْلُدُونَ [26:129]

Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).

### الآية 26:130

> ﻿وَإِذَا بَطَشْتُمْ بَطَشْتُمْ جَبَّارِينَ [26:130]

Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.

### الآية 26:131

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:131]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:132

> ﻿وَاتَّقُوا الَّذِي أَمَدَّكُمْ بِمَا تَعْلَمُونَ [26:132]

Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;

### الآية 26:133

> ﻿أَمَدَّكُمْ بِأَنْعَامٍ وَبَنِينَ [26:133]

Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,

### الآية 26:134

> ﻿وَجَنَّاتٍ وَعُيُونٍ [26:134]

àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.

### الآية 26:135

> ﻿إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ [26:135]

Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fun yín.”

### الآية 26:136

> ﻿قَالُوا سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَوَعَظْتَ أَمْ لَمْ تَكُنْ مِنَ الْوَاعِظِينَ [26:136]

Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o kìlọ̀ fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn olùkìlọ̀.

### الآية 26:137

> ﻿إِنْ هَٰذَا إِلَّا خُلُقُ الْأَوَّلِينَ [26:137]

Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.

### الآية 26:138

> ﻿وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ [26:138]

Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”

### الآية 26:139

> ﻿فَكَذَّبُوهُ فَأَهْلَكْنَاهُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:139]

Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:140

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:140]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:141

> ﻿كَذَّبَتْ ثَمُودُ الْمُرْسَلِينَ [26:141]

Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

### الآية 26:142

> ﻿إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ صَالِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ [26:142]

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

### الآية 26:143

> ﻿إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ [26:143]

Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.

### الآية 26:144

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:144]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:145

> ﻿وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:145]

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:146

> ﻿أَتُتْرَكُونَ فِي مَا هَاهُنَا آمِنِينَ [26:146]

Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀

### الآية 26:147

> ﻿فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ [26:147]

nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi.

### الآية 26:148

> ﻿وَزُرُوعٍ وَنَخْلٍ طَلْعُهَا هَضِيمٌ [26:148]

àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ tutù?

### الآية 26:149

> ﻿وَتَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا فَارِهِينَ [26:149]

Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́!

### الآية 26:150

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:150]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:151

> ﻿وَلَا تُطِيعُوا أَمْرَ الْمُسْرِفِينَ [26:151]

Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn aláṣejù,

### الآية 26:152

> ﻿الَّذِينَ يُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ [26:152]

àwọn t’ó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”

### الآية 26:153

> ﻿قَالُوا إِنَّمَا أَنْتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ [26:153]

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.

### الآية 26:154

> ﻿مَا أَنْتَ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا فَأْتِ بِآيَةٍ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ [26:154]

Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

### الآية 26:155

> ﻿قَالَ هَٰذِهِ نَاقَةٌ لَهَا شِرْبٌ وَلَكُمْ شِرْبُ يَوْمٍ مَعْلُومٍ [26:155]

Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀.

### الآية 26:156

> ﻿وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَظِيمٍ [26:156]

Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”

### الآية 26:157

> ﻿فَعَقَرُوهَا فَأَصْبَحُوا نَادِمِينَ [26:157]

Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.

### الآية 26:158

> ﻿فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:158]

Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:159

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:159]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:160

> ﻿كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ الْمُرْسَلِينَ [26:160]

Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

### الآية 26:161

> ﻿إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ [26:161]

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

### الآية 26:162

> ﻿إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ [26:162]

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.

### الآية 26:163

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:163]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:164

> ﻿وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:164]

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:165

> ﻿أَتَأْتُونَ الذُّكْرَانَ مِنَ الْعَالَمِينَ [26:165]

Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?

### الآية 26:166

> ﻿وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمْ رَبُّكُمْ مِنْ أَزْوَاجِكُمْ ۚ بَلْ أَنْتُمْ قَوْمٌ عَادُونَ [26:166]

Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fun yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”

### الآية 26:167

> ﻿قَالُوا لَئِنْ لَمْ تَنْتَهِ يَا لُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمُخْرَجِينَ [26:167]

Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”

### الآية 26:168

> ﻿قَالَ إِنِّي لِعَمَلِكُمْ مِنَ الْقَالِينَ [26:168]

Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùbínú sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.

### الآية 26:169

> ﻿رَبِّ نَجِّنِي وَأَهْلِي مِمَّا يَعْمَلُونَ [26:169]

Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú)."

### الآية 26:170

> ﻿فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ [26:170]

Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.

### الآية 26:171

> ﻿إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ [26:171]

Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Arúgbóbìnrin yẹn ni ìyàwó Ànábì Lūt ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, nínú sūrah Hūd; 11:81, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo “àyàfi ìyàwó rẹ”.

### الآية 26:172

> ﻿ثُمَّ دَمَّرْنَا الْآخَرِينَ [26:172]

Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.

### الآية 26:173

> ﻿وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ مَطَرًا ۖ فَسَاءَ مَطَرُ الْمُنْذَرِينَ [26:173]

A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.

### الآية 26:174

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:174]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:175

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:175]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:176

> ﻿كَذَّبَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ الْمُرْسَلِينَ [26:176]

Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

### الآية 26:177

> ﻿إِذْ قَالَ لَهُمْ شُعَيْبٌ أَلَا تَتَّقُونَ [26:177]

Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

### الآية 26:178

> ﻿إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ [26:178]

Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.

### الآية 26:179

> ﻿فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ [26:179]

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

### الآية 26:180

> ﻿وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:180]

Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:181

> ﻿۞ أَوْفُوا الْكَيْلَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُخْسِرِينَ [26:181]

Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn olùdóṣùwọ̀nkù.

### الآية 26:182

> ﻿وَزِنُوا بِالْقِسْطَاسِ الْمُسْتَقِيمِ [26:182]

Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọn n̄ǹkan.

### الآية 26:183

> ﻿وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ [26:183]

Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe hùwà aburú lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 26:184

> ﻿وَاتَّقُوا الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالْجِبِلَّةَ الْأَوَّلِينَ [26:184]

Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ìran àkọ́kọ́.”

### الآية 26:185

> ﻿قَالُوا إِنَّمَا أَنْتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ [26:185]

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.

### الآية 26:186

> ﻿وَمَا أَنْتَ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا وَإِنْ نَظُنُّكَ لَمِنَ الْكَاذِبِينَ [26:186]

Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a ò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé ó wà nínú àwọn òpùrọ́.

### الآية 26:187

> ﻿فَأَسْقِطْ عَلَيْنَا كِسَفًا مِنَ السَّمَاءِ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ [26:187]

Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

### الآية 26:188

> ﻿قَالَ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ [26:188]

Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 26:189

> ﻿فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمْ عَذَابُ يَوْمِ الظُّلَّةِ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ [26:189]

Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.

### الآية 26:190

> ﻿إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُؤْمِنِينَ [26:190]

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:191

> ﻿وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [26:191]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 26:192

> ﻿وَإِنَّهُ لَتَنْزِيلُ رَبِّ الْعَالَمِينَ [26:192]

Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 26:193

> ﻿نَزَلَ بِهِ الرُّوحُ الْأَمِينُ [26:193]

Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀

### الآية 26:194

> ﻿عَلَىٰ قَلْبِكَ لِتَكُونَ مِنَ الْمُنْذِرِينَ [26:194]

sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀

### الآية 26:195

> ﻿بِلِسَانٍ عَرَبِيٍّ مُبِينٍ [26:195]

pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.

### الآية 26:196

> ﻿وَإِنَّهُ لَفِي زُبُرِ الْأَوَّلِينَ [26:196]

Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) ti wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.

### الآية 26:197

> ﻿أَوَلَمْ يَكُنْ لَهُمْ آيَةً أَنْ يَعْلَمَهُ عُلَمَاءُ بَنِي إِسْرَائِيلَ [26:197]

Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?

### الآية 26:198

> ﻿وَلَوْ نَزَّلْنَاهُ عَلَىٰ بَعْضِ الْأَعْجَمِينَ [26:198]

Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,

### الآية 26:199

> ﻿فَقَرَأَهُ عَلَيْهِمْ مَا كَانُوا بِهِ مُؤْمِنِينَ [26:199]

199\. tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.

### الآية 26:200

> ﻿كَذَٰلِكَ سَلَكْنَاهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ [26:200]

Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 26:201

> ﻿لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ [26:201]

Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

### الآية 26:202

> ﻿فَيَأْتِيَهُمْ بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ [26:202]

(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.

### الآية 26:203

> ﻿فَيَقُولُوا هَلْ نَحْنُ مُنْظَرُونَ [26:203]

Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?"

### الآية 26:204

> ﻿أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ [26:204]

Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?

### الآية 26:205

> ﻿أَفَرَأَيْتَ إِنْ مَتَّعْنَاهُمْ سِنِينَ [26:205]

Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!

### الآية 26:206

> ﻿ثُمَّ جَاءَهُمْ مَا كَانُوا يُوعَدُونَ [26:206]

Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn dé bá wọn.

### الآية 26:207

> ﻿مَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يُمَتَّعُونَ [26:207]

Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

### الآية 26:208

> ﻿وَمَا أَهْلَكْنَا مِنْ قَرْيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنْذِرُونَ [26:208]

A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.

### الآية 26:209

> ﻿ذِكْرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَالِمِينَ [26:209]

Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.

### الآية 26:210

> ﻿وَمَا تَنَزَّلَتْ بِهِ الشَّيَاطِينُ [26:210]

Kì í ṣe àwọn èṣù ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀.

### الآية 26:211

> ﻿وَمَا يَنْبَغِي لَهُمْ وَمَا يَسْتَطِيعُونَ [26:211]

Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.

### الآية 26:212

> ﻿إِنَّهُمْ عَنِ السَّمْعِ لَمَعْزُولُونَ [26:212]

Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).

### الآية 26:213

> ﻿فَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَتَكُونَ مِنَ الْمُعَذَّبِينَ [26:213]

Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.

### الآية 26:214

> ﻿وَأَنْذِرْ عَشِيرَتَكَ الْأَقْرَبِينَ [26:214]

Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ, t’ó súnmọ́ jùlọ.

### الآية 26:215

> ﻿وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ [26:215]

Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 26:216

> ﻿فَإِنْ عَصَوْكَ فَقُلْ إِنِّي بَرِيءٌ مِمَّا تَعْمَلُونَ [26:216]

Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”

### الآية 26:217

> ﻿وَتَوَكَّلْ عَلَى الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ [26:217]

Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;

### الآية 26:218

> ﻿الَّذِي يَرَاكَ حِينَ تَقُومُ [26:218]

Ẹni t’Ó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)

### الآية 26:219

> ﻿وَتَقَلُّبَكَ فِي السَّاجِدِينَ [26:219]

àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.

### الآية 26:220

> ﻿إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ [26:220]

Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 26:221

> ﻿هَلْ أُنَبِّئُكُمْ عَلَىٰ مَنْ تَنَزَّلُ الشَّيَاطِينُ [26:221]

Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn èṣù ń sọ̀kalẹ̀ wá bá?

### الآية 26:222

> ﻿تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٍ [26:222]

Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 26:223

> ﻿يُلْقُونَ السَّمْعَ وَأَكْثَرُهُمْ كَاذِبُونَ [26:223]

(Àwọn èṣù) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.

### الآية 26:224

> ﻿وَالشُّعَرَاءُ يَتَّبِعُهُمُ الْغَاوُونَ [26:224]

Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn.

### الآية 26:225

> ﻿أَلَمْ تَرَ أَنَّهُمْ فِي كُلِّ وَادٍ يَهِيمُونَ [26:225]

Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?

### الآية 26:226

> ﻿وَأَنَّهُمْ يَقُولُونَ مَا لَا يَفْعَلُونَ [26:226]

Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.

### الآية 26:227

> ﻿إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَذَكَرُوا اللَّهَ كَثِيرًا وَانْتَصَرُوا مِنْ بَعْدِ مَا ظُلِمُوا ۗ وَسَيَعْلَمُ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَيَّ مُنْقَلَبٍ يَنْقَلِبُونَ [26:227]

Àfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/26.md)
- [كل تفاسير سورة الشعراء
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/26.md)
- [ترجمات سورة الشعراء
](https://quranpedia.net/translations/26.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/26/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
