---
title: "ترجمة سورة القصص - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/28/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/28/book/2001"
surah_id: "28"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة القصص - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/28/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة القصص - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/28/book/2001*.

Translation of Surah القصص from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 28:1

> طسم [28:1]

Tọ̄ sīn mīm.

### الآية 28:2

> ﻿تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ [28:2]

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

### الآية 28:3

> ﻿نَتْلُو عَلَيْكَ مِنْ نَبَإِ مُوسَىٰ وَفِرْعَوْنَ بِالْحَقِّ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ [28:3]

À ń ké nínú ìró (Ànábì) Mūsā àti Fir‘aon fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí ìjọ t’ó gbàgbọ́ lódodo.

### الآية 28:4

> ﻿إِنَّ فِرْعَوْنَ عَلَا فِي الْأَرْضِ وَجَعَلَ أَهْلَهَا شِيَعًا يَسْتَضْعِفُ طَائِفَةً مِنْهُمْ يُذَبِّحُ أَبْنَاءَهُمْ وَيَسْتَحْيِي نِسَاءَهُمْ ۚ إِنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُفْسِدِينَ [28:4]

Dájúdájú Fir‘aon ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Ó ṣe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìjọ-ìjọ. Ó ń dá igun kan nínú wọn lágara; ó ń pa àwọn ọmọkùnrin wọn, ó sì ń dá àwọn obìnrin wọn sí. Dájúdájú ó wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 28:5

> ﻿وَنُرِيدُ أَنْ نَمُنَّ عَلَى الَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا فِي الْأَرْضِ وَنَجْعَلَهُمْ أَئِمَّةً وَنَجْعَلَهُمُ الْوَارِثِينَ [28:5]

A sì fẹ́ ṣèdẹ̀ra fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín lórí ilẹ̀, A (fẹ́) ṣe wọ́n ní aṣíwájú. A sì (fẹ́) kí wọ́n jogún (ilẹ̀).

### الآية 28:6

> ﻿وَنُمَكِّنَ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَنُرِيَ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَجُنُودَهُمَا مِنْهُمْ مَا كَانُوا يَحْذَرُونَ [28:6]

A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn.

### الآية 28:7

> ﻿وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ أُمِّ مُوسَىٰ أَنْ أَرْضِعِيهِ ۖ فَإِذَا خِفْتِ عَلَيْهِ فَأَلْقِيهِ فِي الْيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحْزَنِي ۖ إِنَّا رَادُّوهُ إِلَيْكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ الْمُرْسَلِينَ [28:7]

A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú agbami odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́.

### الآية 28:8

> ﻿فَالْتَقَطَهُ آلُ فِرْعَوْنَ لِيَكُونَ لَهُمْ عَدُوًّا وَحَزَنًا ۗ إِنَّ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَجُنُودَهُمَا كَانُوا خَاطِئِينَ [28:8]

Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe.

### الآية 28:9

> ﻿وَقَالَتِ امْرَأَتُ فِرْعَوْنَ قُرَّتُ عَيْنٍ لِي وَلَكَ ۖ لَا تَقْتُلُوهُ عَسَىٰ أَنْ يَنْفَعَنَا أَوْ نَتَّخِذَهُ وَلَدًا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ [28:9]

Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura.

### الآية 28:10

> ﻿وَأَصْبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَارِغًا ۖ إِنْ كَادَتْ لَتُبْدِي بِهِ لَوْلَا أَنْ رَبَطْنَا عَلَىٰ قَلْبِهَا لِتَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ [28:10]

Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 28:11

> ﻿وَقَالَتْ لِأُخْتِهِ قُصِّيهِ ۖ فَبَصُرَتْ بِهِ عَنْ جُنُبٍ وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ [28:11]

Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọpa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi t’ó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i).

### الآية 28:12

> ﻿۞ وَحَرَّمْنَا عَلَيْهِ الْمَرَاضِعَ مِنْ قَبْلُ فَقَالَتْ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ أَهْلِ بَيْتٍ يَكْفُلُونَهُ لَكُمْ وَهُمْ لَهُ نَاصِحُونَ [28:12]

A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) Arábìnrin rẹ̀ sì wí pé: “Ṣé kí n̄g fi ará ilé kan hàn yín, tí ó máa gbà á tọ́ fun yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.”

### الآية 28:13

> ﻿فَرَدَدْنَاهُ إِلَىٰ أُمِّهِ كَيْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ وَلِتَعْلَمَ أَنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [28:13]

A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

### الآية 28:14

> ﻿وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَاسْتَوَىٰ آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ [28:14]

Nígbà t’ó dàgbà, t’ó di géńdé, A fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san

### الآية 28:15

> ﻿وَدَخَلَ الْمَدِينَةَ عَلَىٰ حِينِ غَفْلَةٍ مِنْ أَهْلِهَا فَوَجَدَ فِيهَا رَجُلَيْنِ يَقْتَتِلَانِ هَٰذَا مِنْ شِيعَتِهِ وَهَٰذَا مِنْ عَدُوِّهِ ۖ فَاسْتَغَاثَهُ الَّذِي مِنْ شِيعَتِهِ عَلَى الَّذِي مِنْ عَدُوِّهِ فَوَكَزَهُ مُوسَىٰ فَقَضَىٰ عَلَيْهِ ۖ قَالَ هَٰذَا مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ ۖ إِنَّهُ عَدُوٌّ مُضِلٌّ مُبِينٌ [28:15]

Ó wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀). Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ Èṣù. Dájúdájú (èṣù) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”

### الآية 28:16

> ﻿قَالَ رَبِّ إِنِّي ظَلَمْتُ نَفْسِي فَاغْفِرْ لِي فَغَفَرَ لَهُ ۚ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ [28:16]

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Nítorí náà, foríjìn mí.” Ó sì foríjìn ín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 28:17

> ﻿قَالَ رَبِّ بِمَا أَنْعَمْتَ عَلَيَّ فَلَنْ أَكُونَ ظَهِيرًا لِلْمُجْرِمِينَ [28:17]

Ó sọ pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe ìkẹ́ fún mi, èmi kò níí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

### الآية 28:18

> ﻿فَأَصْبَحَ فِي الْمَدِينَةِ خَائِفًا يَتَرَقَّبُ فَإِذَا الَّذِي اسْتَنْصَرَهُ بِالْأَمْسِ يَسْتَصْرِخُهُ ۚ قَالَ لَهُ مُوسَىٰ إِنَّكَ لَغَوِيٌّ مُبِينٌ [28:18]

Nítorí náà, ó di ẹni t’ó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”

### الآية 28:19

> ﻿فَلَمَّا أَنْ أَرَادَ أَنْ يَبْطِشَ بِالَّذِي هُوَ عَدُوٌّ لَهُمَا قَالَ يَا مُوسَىٰ أَتُرِيدُ أَنْ تَقْتُلَنِي كَمَا قَتَلْتَ نَفْسًا بِالْأَمْسِ ۖ إِنْ تُرِيدُ إِلَّا أَنْ تَكُونَ جَبَّارًا فِي الْأَرْضِ وَمَا تُرِيدُ أَنْ تَكُونَ مِنَ الْمُصْلِحِينَ [28:19]

Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: “Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe.”

### الآية 28:20

> ﻿وَجَاءَ رَجُلٌ مِنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ يَسْعَىٰ قَالَ يَا مُوسَىٰ إِنَّ الْمَلَأَ يَأْتَمِرُونَ بِكَ لِيَقْتُلُوكَ فَاخْرُجْ إِنِّي لَكَ مِنَ النَّاصِحِينَ [28:20]

Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Mūsā, dájúdájú àwọn ìjòyè ń dá ìmọ̀ràn lórí rẹ láti pa ọ́. Nítorí náà, jáde (kúrò nínú ìlú), dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn rere fún ọ.”

### الآية 28:21

> ﻿فَخَرَجَ مِنْهَا خَائِفًا يَتَرَقَّبُ ۖ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [28:21]

Ó sì jáde kúrò nínú (ìlú) pẹ̀lú ìpáyà, tí ó ń retí (ẹ̀hónú wọn), ó sì sọ pé: “Olúwa mi, là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”

### الآية 28:22

> ﻿وَلَمَّا تَوَجَّهَ تِلْقَاءَ مَدْيَنَ قَالَ عَسَىٰ رَبِّي أَنْ يَهْدِيَنِي سَوَاءَ السَّبِيلِ [28:22]

Nígbà tí ó sì dojú kọ ọ̀kánkán ìlú Mọdyan, ó sọ pé: “Ó súnmọ́ kí Olúwa mi fọ̀nà tààrà (sí ìlú Mọdyan) mọ̀ mí.”

### الآية 28:23

> ﻿وَلَمَّا وَرَدَ مَاءَ مَدْيَنَ وَجَدَ عَلَيْهِ أُمَّةً مِنَ النَّاسِ يَسْقُونَ وَوَجَدَ مِنْ دُونِهِمُ امْرَأَتَيْنِ تَذُودَانِ ۖ قَالَ مَا خَطْبُكُمَا ۖ قَالَتَا لَا نَسْقِي حَتَّىٰ يُصْدِرَ الرِّعَاءُ ۖ وَأَبُونَا شَيْخٌ كَبِيرٌ [28:23]

Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: “Kí l’ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?” Wọ́n sọ pé: “A ò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlagbà arúgbó sì ni bàbá wa.”

### الآية 28:24

> ﻿فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰ إِلَى الظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَا أَنْزَلْتَ إِلَيَّ مِنْ خَيْرٍ فَقِيرٌ [28:24]

Ó sì bá wọn fún (ẹran-ọ̀sìn) wọn ní omi mu. Lẹ́yìn náà, ó padà síbi ibòji, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi bùkátà sí ohun tí O bá sọ̀kalẹ̀ fún mi nínú oore.”

### الآية 28:25

> ﻿فَجَاءَتْهُ إِحْدَاهُمَا تَمْشِي عَلَى اسْتِحْيَاءٍ قَالَتْ إِنَّ أَبِي يَدْعُوكَ لِيَجْزِيَكَ أَجْرَ مَا سَقَيْتَ لَنَا ۚ فَلَمَّا جَاءَهُ وَقَصَّ عَلَيْهِ الْقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفْ ۖ نَجَوْتَ مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [28:25]

Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì wá bá a, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìtìjú, ó sọ pé: “Dájúdájú bàbá mi ń pè ọ́ nítorí kí ó lè san ọ́ ní ẹ̀san omi tí o fún (àwọn ẹran-ọ̀sìn) wa mu.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ ìtàn (ara rẹ̀) fún un. (Bàbá náà) sọ pé: “Má bẹ̀rù. O ti là lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”

### الآية 28:26

> ﻿قَالَتْ إِحْدَاهُمَا يَا أَبَتِ اسْتَأْجِرْهُ ۖ إِنَّ خَيْرَ مَنِ اسْتَأْجَرْتَ الْقَوِيُّ الْأَمِينُ [28:26]

Ọ̀kan nínú (àwọn ọmọbìnrin) méjèèjì sọ pé: “Bàbá mi o, gbà á síṣẹ́. Dájúdájú ẹni t’ó dára jùlọ tí o lè gbà síṣẹ́ ni alágbára, olùfọkàntán.”

### الآية 28:27

> ﻿قَالَ إِنِّي أُرِيدُ أَنْ أُنْكِحَكَ إِحْدَى ابْنَتَيَّ هَاتَيْنِ عَلَىٰ أَنْ تَأْجُرَنِي ثَمَانِيَ حِجَجٍ ۖ فَإِنْ أَتْمَمْتَ عَشْرًا فَمِنْ عِنْدِكَ ۖ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أَشُقَّ عَلَيْكَ ۚ سَتَجِدُنِي إِنْ شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ [28:27]

Ó sọ pé: “Dájúdájú mo fẹ́ fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì wọ̀nyí fún ọ ní aya lórí (àdéhùn) pé o máa bá mi ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣe é pé ọdún mẹ́wàá, láti ọ̀dọ̀ rẹ nìyẹn. Èmi kò sì fẹ́ kó ìnira bá ọ. Tí Allāhu bá fẹ́, o máa rí i pé mo wà nínú àwọn ẹni rere.”

### الآية 28:28

> ﻿قَالَ ذَٰلِكَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ ۖ أَيَّمَا الْأَجَلَيْنِ قَضَيْتُ فَلَا عُدْوَانَ عَلَيَّ ۖ وَاللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ [28:28]

(Mūsā) sọ pé: “(Àdéhùn) yìí wà láààrin èmi àti ìwọ. Èyíkéyìí tí mo bá mú ṣẹ nínú àdéhùn méjèèjì náà, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣàbòsí sí mi. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”

### الآية 28:29

> ﻿۞ فَلَمَّا قَضَىٰ مُوسَى الْأَجَلَ وَسَارَ بِأَهْلِهِ آنَسَ مِنْ جَانِبِ الطُّورِ نَارًا قَالَ لِأَهْلِهِ امْكُثُوا إِنِّي آنَسْتُ نَارًا لَعَلِّي آتِيكُمْ مِنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ جَذْوَةٍ مِنَ النَّارِ لَعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ [28:29]

Nígbà tí Mūsā parí àkókò náà, ó mú ará ilé rẹ̀ rin (ìrìn-àjò). Ó sì rí iná kan ní ẹ̀bá àpáta. Ó sọ fún ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró (síbí ná). Èmi rí iná kan. Ó ṣe é ṣe kí n̄g mú ìró kan wá ba yín láti ibẹ̀ tàbí (kí n̄g mú) ògúnná kan wá nítorí kí ẹ lè rí ohun yẹ́ná.”

### الآية 28:30

> ﻿فَلَمَّا أَتَاهَا نُودِيَ مِنْ شَاطِئِ الْوَادِ الْأَيْمَنِ فِي الْبُقْعَةِ الْمُبَارَكَةِ مِنَ الشَّجَرَةِ أَنْ يَا مُوسَىٰ إِنِّي أَنَا اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ [28:30]

Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é láti ẹ̀gbẹ́ àfonífojì ní ọwọ́ ọ̀tún (rẹ̀) ní àyè ìbùkún láti ibi igi náà. (A sọ pé): “Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 28:31

> ﻿وَأَنْ أَلْقِ عَصَاكَ ۖ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ أَقْبِلْ وَلَا تَخَفْ ۖ إِنَّكَ مِنَ الْآمِنِينَ [28:31]

Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” (Ó sì jù ú sílẹ̀). Nígbà tí ó rí i t’ó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìn dà, ó ń sá lọ́, kò sì padà. (Allāhu sọ pé): “Mūsā, máa bọ̀ padà, má sì ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn olùfàyàbalẹ̀.

### الآية 28:32

> ﻿اسْلُكْ يَدَكَ فِي جَيْبِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ وَاضْمُمْ إِلَيْكَ جَنَاحَكَ مِنَ الرَّهْبِ ۖ فَذَانِكَ بُرْهَانَانِ مِنْ رَبِّكَ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ [28:32]

Ti ọwọ́ rẹ bọ (abíyá láti ibi) ọrùn ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra sí (abíyá rẹ) níbi ẹ̀rù. Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, tí ọpá rẹ bá yí padà, t’ó di ejò níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ẹ̀rù sì ń ba ìwọ náà, pa ọwọ́ rẹ mọ́ra láti fi yọ ẹ̀rù náà kúrò nínú ọkàn rẹ.

### الآية 28:33

> ﻿قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلْتُ مِنْهُمْ نَفْسًا فَأَخَافُ أَنْ يَقْتُلُونِ [28:33]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pa ẹnì kan nínú wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.

### الآية 28:34

> ﻿وَأَخِي هَارُونُ هُوَ أَفْصَحُ مِنِّي لِسَانًا فَأَرْسِلْهُ مَعِيَ رِدْءًا يُصَدِّقُنِي ۖ إِنِّي أَخَافُ أَنْ يُكَذِّبُونِ [28:34]

Àti pé arákùnrin mi, Hārūn, ó dá láhọ́n jù mí lọ. Nítorí náà, rán an níṣẹ́ pẹ̀lú mi, kí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí yóò máa jẹ́rìí sí òdodo ọ̀rọ̀ mi. Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.”

### الآية 28:35

> ﻿قَالَ سَنَشُدُّ عَضُدَكَ بِأَخِيكَ وَنَجْعَلُ لَكُمَا سُلْطَانًا فَلَا يَصِلُونَ إِلَيْكُمَا ۚ بِآيَاتِنَا أَنْتُمَا وَمَنِ اتَّبَعَكُمَا الْغَالِبُونَ [28:35]

(Allāhu) sọ pé: “A máa fi arákùnrin rẹ kún ọ lọ́wọ́. A ó sì fún ẹ̀yin méjèèjì ní agbára, wọn kò sì níí lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀yin méjèèjì. Pẹ̀lú àwọn àmì Wa, ẹ̀yin méjèèjì àti àwọn t’ó bá tẹ̀lé ẹ̀yin méjèèjì l’ó máa borí.”

### الآية 28:36

> ﻿فَلَمَّا جَاءَهُمْ مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا بَيِّنَاتٍ قَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُفْتَرًى وَمَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي آبَائِنَا الْأَوَّلِينَ [28:36]

Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé bá wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àdáhun. A kò sì gbọ́ èyí (rí) láààrin àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

### الآية 28:37

> ﻿وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَنْ جَاءَ بِالْهُدَىٰ مِنْ عِنْدِهِ وَمَنْ تَكُونُ لَهُ عَاقِبَةُ الدَّارِ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ [28:37]

(Ànábì) Mūsā sì sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ẹni tí àtubọ̀tán ilé (ìkẹ́) máa jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

### الآية 28:38

> ﻿وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ مَا عَلِمْتُ لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرِي فَأَوْقِدْ لِي يَا هَامَانُ عَلَى الطِّينِ فَاجْعَلْ لِي صَرْحًا لَعَلِّي أَطَّلِعُ إِلَىٰ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ مِنَ الْكَاذِبِينَ [28:38]

Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi! Nítorí náà, Hāmọ̄n, dá iná fún mi, kí o fi mọ amọ̀, kí o sì kọ́ ilé gíga kan fún mi nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā. (Nítorí pé) dájúdájú mò ń rò ó sí ara àwọn òpùrọ́.”

### الآية 28:39

> ﻿وَاسْتَكْبَرَ هُوَ وَجُنُودُهُ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَظَنُّوا أَنَّهُمْ إِلَيْنَا لَا يُرْجَعُونَ [28:39]

Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì rò pé dájúdájú A ò níí dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Wa.

### الآية 28:40

> ﻿فَأَخَذْنَاهُ وَجُنُودَهُ فَنَبَذْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ ۖ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الظَّالِمِينَ [28:40]

Nítorí náà, A gbá òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú; A jù wọ́n sínú agbami odò. Wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ti rí.

### الآية 28:41

> ﻿وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ لَا يُنْصَرُونَ [28:41]

A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń pèpè sínú Iná. Tí ó bá sì di Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

### الآية 28:42

> ﻿وَأَتْبَعْنَاهُمْ فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا لَعْنَةً ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ هُمْ مِنَ الْمَقْبُوحِينَ [28:42]

Àti pé A fi ègún tọpa wọn ní ilé ayé yìí. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yó sì wà nínú àwọn ẹni ìparun.

### الآية 28:43

> ﻿وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ مِنْ بَعْدِ مَا أَهْلَكْنَا الْقُرُونَ الْأُولَىٰ بَصَائِرَ لِلنَّاسِ وَهُدًى وَرَحْمَةً لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ [28:43]

Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà lẹ́yìn ìgbà tí A ti pa àwọn ìjọ àkọ́kọ́ rẹ́. (Tírà náà jẹ́) àríwòye fún àwọn ènìyàn, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

### الآية 28:44

> ﻿وَمَا كُنْتَ بِجَانِبِ الْغَرْبِيِّ إِذْ قَضَيْنَا إِلَىٰ مُوسَى الْأَمْرَ وَمَا كُنْتَ مِنَ الشَّاهِدِينَ [28:44]

Ìwọ kò sí ní ẹ̀bá ìwọ̀-òòrùn nígbà tí A fi ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā. Àti pé ìwọ kò sí nínú àwọn t’ó wà níbẹ̀.

### الآية 28:45

> ﻿وَلَٰكِنَّا أَنْشَأْنَا قُرُونًا فَتَطَاوَلَ عَلَيْهِمُ الْعُمُرُ ۚ وَمَا كُنْتَ ثَاوِيًا فِي أَهْلِ مَدْيَنَ تَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا وَلَٰكِنَّا كُنَّا مُرْسِلِينَ [28:45]

Ṣùgbọ́n A ṣẹ̀dá àwọn ìran kan tí ẹ̀mí wọn gùn. O ò kúkú gbé láààrin ará ìlú Mọdyan, tí ò ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, ṣùgbọ́n Àwa l’à ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.

### الآية 28:46

> ﻿وَمَا كُنْتَ بِجَانِبِ الطُّورِ إِذْ نَادَيْنَا وَلَٰكِنْ رَحْمَةً مِنْ رَبِّكَ لِتُنْذِرَ قَوْمًا مَا أَتَاهُمْ مِنْ نَذِيرٍ مِنْ قَبْلِكَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ [28:46]

Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti àkọ́bí rẹ̀, Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) dé ìlú Mọkkah ṣíwájú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àmọ́ kì í ṣe pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí ará ìlú Mọkkah. Bẹ́ẹ̀ náà ni èyíkéyìí Ànábì Ọlọ́hun tí ìtàn bá sọ nípa rẹ̀ pé ó dé ìlú Mọkkah tàbí ìlú mìíràn nínú àwọn ìlú Lárúbáwá. Ó lè dé ibẹ̀ rí, àmọ́ tí Allāhu kò sì níí rán an níṣẹ́ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ànábì ‘Ismā‘īl gan-an ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tí wọ́n gbé wá wò láti òpóǹló nínú ìlú Mọkkah, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò kúkú rán an níṣẹ́ sí ìran Lárúbáwá ní àpapọ̀ tàbí sí ìlú kan nínú ìlú àwọn Lárúbáwá. Àmọ́ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán an níṣẹ́ sí ọ̀wọ́ ẹbí rẹ̀ nínú ìdílé ìyàwó rẹ̀ t’ó jẹ́ Lárúbáwá. Ìyẹn sì ni àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Mọryam; 19:54-55. 
Bákan náà, tòhun ti bí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n fún ní tírà Taorāt, iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ kò kúkú kan àwọn ènìyàn Kidr (rọdiyallāhu 'anhu). Kódà Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ìbá tí mọ̀ pé àwọn ènìyàn kan tún wà ní àyè mìíràn lábẹ́ Kidr tí kò bá jẹ́ pé Allāhu pa á láṣẹ láti ṣàbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wàyí bí a ṣe rí àwọn āyah kan t’ó ń fi rinlẹ̀ pé kò sí ìjọ tí Allāhu kò rán Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan sí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:7, sūrah an-Nahl; 16:36 àti sūrah Fātir; 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:46, sūrah Saba’; 34:44, sūrah as-Sajdah; 32:3 àti sūrah Yāsīn; 36:6.) 
Ẹ rántí àlàyé tí mo mú wá lórí iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ’Isma‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Lẹ́yìn náà, àgbọ́yé t’ó wà nínú àwọn āyah t’ó wá lórí àìsí Òjíṣẹ́ fún àwọn Lárúbáwá ni pé, kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan, àti pé àwọn méjèèjì ni wọ́n mọ Ilé Kaaba ga sókè, àwọn ìran Lárúbáwá tún ní àǹfààní láti rìn kan àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. Nípasẹ̀ èyí, wọ́n tún gbúròó gbọ́ nípa òǹkà púpọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ ọmọ ’Isrọ̄’īl, ní pàtàkì jùlọ nípa Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kì í ṣe pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ Ànábì Lárúbáwá. Paríparí rẹ̀ ni pé, ìgbà pípẹ́ gbọọrọ tún wà láààrin ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gun sánmọ̀ lọ láàyè àti ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ìkẹ́yìn dìde, ìyẹn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:19. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn fi sọ pé, irúfẹ́ àwọn ènìyàn t’o ṣẹ̀mí láààrin ìgbà náà ni wọ́n ń pè ní “’ahlu-l-fatrah”. Ọjọ́ Àjíǹde sì ni Allāhu máa tó yanjú ọ̀rọ̀ wọn. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú nímọ̀ nípa ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ àti ẹni tí kò níí tẹ̀lé e nínú wọn bí Ó bá jẹ́ pé Allāhu tètè rán Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí wọn. Àpẹẹrẹ wọn tún ni àwọn ọmọdé t’ó kú ṣíwájú bíbàlágà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti nímọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá dágbà. Èyí ni òdodo ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ àwọn “’ahlu-l-fatrah”, ìyẹn àwọn t’ó ti kú ṣíwájú iṣẹ́ jíjẹ́ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn ènìyàn mìíràn t’ó ti kú ṣíwájú tiwọn àti ṣíwájú kí Allāhu tó gbé Ànábì dìde fún wọn. 
Kíyè sí i, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fi àdámọ́ òye àtinúwá sára gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ láti jìnnà sí jíjọ̀sìn fún òrìṣà nítorí gbogbo ẹ̀dá l’ó ní òye pé kì í ṣe òrìṣà ni ẹlẹ́dàá àwọn, àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu, Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan t’ó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé, dípò kí ó jẹ́ Ànábì fún ìran Lárúbáwá nìkan gẹ́gẹ́ bí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì t’ó ṣíwájú rẹ̀ ṣe jẹ́, ńṣe ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú ọlá Rẹ̀ ṣe é ni Ànábì gbogbo ayé pátápátá. Allāhu tí Ó ṣe ìṣẹ̀dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ àìlo àtọ̀ ọkùnrin kan kan fún ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ìyàtọ̀ sí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ̀, Òun náà (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó kúkú ṣe Ànábì Muhammad ní Òjíṣẹ́ gbogbo ayé, tí kò sì sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ rí fún ṣíwájú rẹ̀. Nítorí náà, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Ànábì àti Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́ fún ẹbí rẹ̀ àti ìran rẹ̀, ìran Lárúbáwá, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ìkẹ́yìn fún àpapọ̀ Lárúbáwá àti àwọn elédè mìíràn pátápátá.

### الآية 28:47

> ﻿وَلَوْلَا أَنْ تُصِيبَهُمْ مُصِيبَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ فَيَقُولُوا رَبَّنَا لَوْلَا أَرْسَلْتَ إِلَيْنَا رَسُولًا فَنَتَّبِعَ آيَاتِكَ وَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ [28:47]

Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

### الآية 28:48

> ﻿فَلَمَّا جَاءَهُمُ الْحَقُّ مِنْ عِنْدِنَا قَالُوا لَوْلَا أُوتِيَ مِثْلَ مَا أُوتِيَ مُوسَىٰ ۚ أَوَلَمْ يَكْفُرُوا بِمَا أُوتِيَ مُوسَىٰ مِنْ قَبْلُ ۖ قَالُوا سِحْرَانِ تَظَاهَرَا وَقَالُوا إِنَّا بِكُلٍّ كَافِرُونَ [28:48]

Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?" Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: “Òpìdán méjì t’ó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n).” Wọ́n sì tún wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn).”

### الآية 28:49

> ﻿قُلْ فَأْتُوا بِكِتَابٍ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ هُوَ أَهْدَىٰ مِنْهُمَا أَتَّبِعْهُ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ [28:49]

Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, t’ó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

### الآية 28:50

> ﻿فَإِنْ لَمْ يَسْتَجِيبُوا لَكَ فَاعْلَمْ أَنَّمَا يَتَّبِعُونَ أَهْوَاءَهُمْ ۚ وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنِ اتَّبَعَ هَوَاهُ بِغَيْرِ هُدًى مِنَ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ [28:50]

Tí wọn kò bá jẹ́pè rẹ, mọ̀ pé wọ́n kàn ń tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni. Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni t’ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, láì sí ìmọ̀nà (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu! Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

### الآية 28:51

> ﻿۞ وَلَقَدْ وَصَّلْنَا لَهُمُ الْقَوْلَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ [28:51]

Àti pé dájúdájú A ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

### الآية 28:52

> ﻿الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِهِ هُمْ بِهِ يُؤْمِنُونَ [28:52]

Àwọn tí A fún ní Tírà ṣíwájú rẹ̀, wọ́n gba al-Ƙur’ān gbọ́.

### الآية 28:53

> ﻿وَإِذَا يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ قَالُوا آمَنَّا بِهِ إِنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّنَا إِنَّا كُنَّا مِنْ قَبْلِهِ مُسْلِمِينَ [28:53]

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n tì wà ní ipò mùsùlùmí lórí sunnah Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tún dé bá wọn láyé, tí wọ́n sì gbà fún sunnah tirẹ̀ náà. Wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.

### الآية 28:54

> ﻿أُولَٰئِكَ يُؤْتَوْنَ أَجْرَهُمْ مَرَّتَيْنِ بِمَا صَبَرُوا وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ [28:54]

Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.

### الآية 28:55

> ﻿وَإِذَا سَمِعُوا اللَّغْوَ أَعْرَضُوا عَنْهُ وَقَالُوا لَنَا أَعْمَالُنَا وَلَكُمْ أَعْمَالُكُمْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ لَا نَبْتَغِي الْجَاهِلِينَ [28:55]

Àti pé nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ burúkú, wọ́n á ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì sọ pé: “Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kí àlàáfíà máa ba yín. A kò wá àwọn aláìmọ̀kan (ní alábàáṣepọ̀).”

### الآية 28:56

> ﻿إِنَّكَ لَا تَهْدِي مَنْ أَحْبَبْتَ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۚ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ [28:56]

Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
"Hidāyah" túmọ̀ sí ìwọ̀nyí: (1) Ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn ’Islām, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú àdúà nínú sūrah al-Fātihah; 1:6. (2) Ṣíṣí ọkàn ẹ̀dá payá fún gbígba ẹ̀sìn ’Islām. Kò sí èyí lọ́wọ́ ẹnì kan àfi Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nítorí pé, ọwọ́ Rẹ̀ ni ọkàn ẹ̀dá wà. Hidayah t’ó ń túmọ̀ sí ìṣípayá ọkàn fún gbígbà ẹ̀sìn ’Islām l’ó jẹyọ ní àyè yìí, ìyẹn sūrah al-Ƙọs̱ọs̱; 28:56 àti nínú sūrah al-Hajj; 22:24 pẹ̀lú sūrah az-Zukruf; 43:40. (3) Fífi al-Ƙur’ān àti sunnah ṣàlàyé ìmọ̀nà sí ọ̀nà tààrà ’Islām, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52. (4) Títọ́ka ènìyàn sí ibì kan tàbí fífi ojú-ọ̀nà kan mọ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú sūrah as-Sọffāt; 37:23. Nítorí náà, kókó ọ̀rọ́ ni pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ olùtọ́ni-sọ́nà pẹ̀lú al-Ƙur’ān àti sunnah rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá, ṣùgbọ́n Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Olùtọ́ni-sọ́nà pẹ̀lú ìṣípayá-ọkàn fún ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́ nítorí pé, àdéhùn Rẹ̀ ni pé, igun kan fún Ọgbà Ìdẹ̀ra, igun kan fún Ọgbà Iná.

### الآية 28:57

> ﻿وَقَالُوا إِنْ نَتَّبِعِ الْهُدَىٰ مَعَكَ نُتَخَطَّفْ مِنْ أَرْضِنَا ۚ أَوَلَمْ نُمَكِّنْ لَهُمْ حَرَمًا آمِنًا يُجْبَىٰ إِلَيْهِ ثَمَرَاتُ كُلِّ شَيْءٍ رِزْقًا مِنْ لَدُنَّا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [28:57]

Wọ́n wí pé: “Tí a bá (fi lè) tẹ̀lé ìmọ̀nà pẹ̀lú rẹ, àwọn ọ̀ṣẹbọ yóò kó wa kúrò lórí ilẹ̀ wa.” Ṣé A ò fún wọn ní ibùgbé (tí ó jẹ́) àyè ọ̀wọ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì ń kó àwọn èso gbogbo ìlú wá síbẹ̀, tí ó jẹ́ èsè láti ọ̀dọ̀ Wa? Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

### الآية 28:58

> ﻿وَكَمْ أَهْلَكْنَا مِنْ قَرْيَةٍ بَطِرَتْ مَعِيشَتَهَا ۖ فَتِلْكَ مَسَاكِنُهُمْ لَمْ تُسْكَنْ مِنْ بَعْدِهِمْ إِلَّا قَلِيلًا ۖ وَكُنَّا نَحْنُ الْوَارِثِينَ [28:58]

Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún.

### الآية 28:59

> ﻿وَمَا كَانَ رَبُّكَ مُهْلِكَ الْقُرَىٰ حَتَّىٰ يَبْعَثَ فِي أُمِّهَا رَسُولًا يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا ۚ وَمَا كُنَّا مُهْلِكِي الْقُرَىٰ إِلَّا وَأَهْلُهَا ظَالِمُونَ [28:59]

Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí.

### الآية 28:60

> ﻿وَمَا أُوتِيتُمْ مِنْ شَيْءٍ فَمَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَزِينَتُهَا ۚ وَمَا عِنْدَ اللَّهِ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ [28:60]

Kò sí ohun tí A fun yín bí kò ṣe nítorí ìgbádùn ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

### الآية 28:61

> ﻿أَفَمَنْ وَعَدْنَاهُ وَعْدًا حَسَنًا فَهُوَ لَاقِيهِ كَمَنْ مَتَّعْنَاهُ مَتَاعَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ثُمَّ هُوَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ مِنَ الْمُحْضَرِينَ [28:61]

Ǹjẹ́ ẹni tí A bá ṣàdéhùn ní àdéhùn t’ó dára, tí ó sì máa pàdé rẹ̀, dà bí ẹni tí A fún ní ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé bí, lẹ́yìn náà ní Ọjọ́ Àjíǹde tí ó máa wà nínú àwọn tí wọn yóò mú wá (fún ìyà Iná)?

### الآية 28:62

> ﻿وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنْتُمْ تَزْعُمُونَ [28:62]

(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”

### الآية 28:63

> ﻿قَالَ الَّذِينَ حَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ رَبَّنَا هَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ أَغْوَيْنَا أَغْوَيْنَاهُمْ كَمَا غَوَيْنَا ۖ تَبَرَّأْنَا إِلَيْكَ ۖ مَا كَانُوا إِيَّانَا يَعْبُدُونَ [28:63]

Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí tí a kó ṣìnà, a kó wọn ṣìnà gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe ṣìnà. A yọwọ́ yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀ wọn) níwájú Rẹ (báyìí); kì í ṣe àwa ni wọ́n ń jọ́sìn fún.”

### الآية 28:64

> ﻿وَقِيلَ ادْعُوا شُرَكَاءَكُمْ فَدَعَوْهُمْ فَلَمْ يَسْتَجِيبُوا لَهُمْ وَرَأَوُا الْعَذَابَ ۚ لَوْ أَنَّهُمْ كَانُوا يَهْتَدُونَ [28:64]

A sọ (fún wọn) pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín.” Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n.)

### الآية 28:65

> ﻿وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ مَاذَا أَجَبْتُمُ الْمُرْسَلِينَ [28:65]

(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni ẹ fọ̀ ní èsì fún àwọn Òjíṣẹ́?”

### الآية 28:66

> ﻿فَعَمِيَتْ عَلَيْهِمُ الْأَنْبَاءُ يَوْمَئِذٍ فَهُمْ لَا يَتَسَاءَلُونَ [28:66]

Èsì ọ̀rọ̀ yó sì fọ́jú pọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ yẹn; wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:101.

### الآية 28:67

> ﻿فَأَمَّا مَنْ تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَعَسَىٰ أَنْ يَكُونَ مِنَ الْمُفْلِحِينَ [28:67]

Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ó súnmọ́ pé ó máa wà nínú àwọn olùjèrè.

### الآية 28:68

> ﻿وَرَبُّكَ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ وَيَخْتَارُ ۗ مَا كَانَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ ۚ سُبْحَانَ اللَّهِ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ [28:68]

Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà. Ṣíṣa ẹ̀ṣà kò tọ́ sí wọn. Mímọ́ ni fún Allāhu. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

### الآية 28:69

> ﻿وَرَبُّكَ يَعْلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمْ وَمَا يُعْلِنُونَ [28:69]

Olúwa rẹ sì mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀.

### الآية 28:70

> ﻿وَهُوَ اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ لَهُ الْحَمْدُ فِي الْأُولَىٰ وَالْآخِرَةِ ۖ وَلَهُ الْحُكْمُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [28:70]

Òun sì ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. TiRẹ̀ ni ọpẹ́ ní ilé ayé yìí àti ní ọ̀run. TiRẹ̀ sì ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

### الآية 28:71

> ﻿قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ اللَّيْلَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُمْ بِضِيَاءٍ ۖ أَفَلَا تَسْمَعُونَ [28:71]

Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ òru di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní ìmọ́lẹ̀? Ṣé ẹ ò gbọ́rọ̀ ni?”

### الآية 28:72

> ﻿قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ النَّهَارَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُمْ بِلَيْلٍ تَسْكُنُونَ فِيهِ ۖ أَفَلَا تُبْصِرُونَ [28:72]

Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ ọ̀sán di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní alẹ́ tí ẹ óò máa sinmi nínú rẹ̀? Ṣé ẹ ò ríran ni?”

### الآية 28:73

> ﻿وَمِنْ رَحْمَتِهِ جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ [28:73]

Nínú ìkẹ́ Rẹ̀ (ni pé) Ó ṣe òru àti ọ̀sán fun yín; nítorí kí ẹ lè sinmi nínú (òru) àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀ (ní ọ̀sán) àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

### الآية 28:74

> ﻿وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنْتُمْ تَزْعُمُونَ [28:74]

(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”

### الآية 28:75

> ﻿وَنَزَعْنَا مِنْ كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا فَقُلْنَا هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ فَعَلِمُوا أَنَّ الْحَقَّ لِلَّهِ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ [28:75]

A sì máa mú ẹlẹ́rìí kan jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. A máa sọ pé: “Ẹ mú ìdí ọ̀rọ̀ yín wá.” Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ń jẹ́ ti Allāhu. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ yó sì dòfo mọ́ wọn lọ́wọ́.

### الآية 28:76

> ﻿۞ إِنَّ قَارُونَ كَانَ مِنْ قَوْمِ مُوسَىٰ فَبَغَىٰ عَلَيْهِمْ ۖ وَآتَيْنَاهُ مِنَ الْكُنُوزِ مَا إِنَّ مَفَاتِحَهُ لَتَنُوءُ بِالْعُصْبَةِ أُولِي الْقُوَّةِ إِذْ قَالَ لَهُ قَوْمُهُ لَا تَفْرَحْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْفَرِحِينَ [28:76]

Dájúdájú Ƙọ̄rūn wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ṣùgbọ́n ó ṣègbéraga sí wọn. A sì fún un ní àwọn àpótí-ọrọ̀ èyí tí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ wúwo láti gbé fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn alágbára. (Rántí) nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ fún un pé: "Má ṣe yọ ayọ̀ àyọ̀jù. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn aláyọ̀jù.

### الآية 28:77

> ﻿وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الْآخِرَةَ ۖ وَلَا تَنْسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا ۖ وَأَحْسِنْ كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ ۖ وَلَا تَبْغِ الْفَسَادَ فِي الْأَرْضِ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ [28:77]

Fi n̄ǹkan tí Allāhu fún ọ wá ilé Ìkẹ́yìn. Má ṣe gbàgbé ìpín rẹ ní ilé ayé. Ṣe dáadáa gẹ́gẹ́ bí Allāhu ti ṣe dáadáa fún ọ. Má sì ṣe wá ìbàjẹ́ ṣe lórí ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn òbìlẹ̀jẹ́."

### الآية 28:78

> ﻿قَالَ إِنَّمَا أُوتِيتُهُ عَلَىٰ عِلْمٍ عِنْدِي ۚ أَوَلَمْ يَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ قَدْ أَهْلَكَ مِنْ قَبْلِهِ مِنَ الْقُرُونِ مَنْ هُوَ أَشَدُّ مِنْهُ قُوَّةً وَأَكْثَرُ جَمْعًا ۚ وَلَا يُسْأَلُ عَنْ ذُنُوبِهِمُ الْمُجْرِمُونَ [28:78]

Ó wí pé: "Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni." Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀.)

### الآية 28:79

> ﻿فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوْمِهِ فِي زِينَتِهِ ۖ قَالَ الَّذِينَ يُرِيدُونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا يَا لَيْتَ لَنَا مِثْلَ مَا أُوتِيَ قَارُونُ إِنَّهُ لَذُو حَظٍّ عَظِيمٍ [28:79]

Ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn t’ó ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí sì wí pé: “Háà! Kí á sì ní irú ohun tí wọ́n fún Ƙọ̄rūn. Dájúdájú ó ní ìpín ńlá nínú oore.”

### الآية 28:80

> ﻿وَقَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ وَيْلَكُمْ ثَوَابُ اللَّهِ خَيْرٌ لِمَنْ آمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا وَلَا يُلَقَّاهَا إِلَّا الصَّابِرُونَ [28:80]

Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ sọ pé: “Ègbé ni fun yín! Ẹ̀san Allāhu lóore jùlọ fún ẹni t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì sí ẹni tí ó máa rí (ẹ̀san náà) gbà àfi àwọn onísùúrù.”

### الآية 28:81

> ﻿فَخَسَفْنَا بِهِ وَبِدَارِهِ الْأَرْضَ فَمَا كَانَ لَهُ مِنْ فِئَةٍ يَنْصُرُونَهُ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَمَا كَانَ مِنَ الْمُنْتَصِرِينَ [28:81]

Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn t’ó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.

### الآية 28:82

> ﻿وَأَصْبَحَ الَّذِينَ تَمَنَّوْا مَكَانَهُ بِالْأَمْسِ يَقُولُونَ وَيْكَأَنَّ اللَّهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ ۖ لَوْلَا أَنْ مَنَّ اللَّهُ عَلَيْنَا لَخَسَفَ بِنَا ۖ وَيْكَأَنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ [28:82]

Àwọn t’ó ń rankàn ipò rẹ̀ ní àná sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ṣé ẹ rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu kẹ́ wa ni, ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ gbé àwa náà mì ni. Ṣé ẹ rí i pé àwọn aláìmoore kò níí jèrè.”

### الآية 28:83

> ﻿تِلْكَ الدَّارُ الْآخِرَةُ نَجْعَلُهَا لِلَّذِينَ لَا يُرِيدُونَ عُلُوًّا فِي الْأَرْضِ وَلَا فَسَادًا ۚ وَالْعَاقِبَةُ لِلْمُتَّقِينَ [28:83]

Ilé Ìkẹ́yìn yẹn, A máa fi fún àwọn tí kò fẹ́ máa ṣe ìgbéraga àti ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

### الآية 28:84

> ﻿مَنْ جَاءَ بِالْحَسَنَةِ فَلَهُ خَيْرٌ مِنْهَا ۖ وَمَنْ جَاءَ بِالسَّيِّئَةِ فَلَا يُجْزَى الَّذِينَ عَمِلُوا السَّيِّئَاتِ إِلَّا مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [28:84]

Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú iṣẹ́ rere wá, tirẹ̀ ni rere t’ó lóore jùlọ sí èyí t’ó mú wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wá, A ò sì níí san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san kan àfi ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 28:85

> ﻿إِنَّ الَّذِي فَرَضَ عَلَيْكَ الْقُرْآنَ لَرَادُّكَ إِلَىٰ مَعَادٍ ۚ قُلْ رَبِّي أَعْلَمُ مَنْ جَاءَ بِالْهُدَىٰ وَمَنْ هُوَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [28:85]

Dájúdájú Ẹni tí Ó ṣe al-Ƙur’ān ní ọ̀ran-anyàn fún ọ, Ó sì máa dá ọ padà sí èbúté kan. Sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá àti ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

### الآية 28:86

> ﻿وَمَا كُنْتَ تَرْجُو أَنْ يُلْقَىٰ إِلَيْكَ الْكِتَابُ إِلَّا رَحْمَةً مِنْ رَبِّكَ ۖ فَلَا تَكُونَنَّ ظَهِيرًا لِلْكَافِرِينَ [28:86]

Ìwọ kò sì retí pé A óò sọ tírà al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ (tẹ́lẹ̀), àmọ́ ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ jẹ́ alátìlẹ́yìn fún àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 28:87

> ﻿وَلَا يَصُدُّنَّكَ عَنْ آيَاتِ اللَّهِ بَعْدَ إِذْ أُنْزِلَتْ إِلَيْكَ ۖ وَادْعُ إِلَىٰ رَبِّكَ ۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكِينَ [28:87]

Má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́ ọ lórí kúrò níbi àwọn āyah Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí A ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ. Pèpè sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

### الآية 28:88

> ﻿وَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۘ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ كُلُّ شَيْءٍ هَالِكٌ إِلَّا وَجْهَهُ ۚ لَهُ الْحُكْمُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [28:88]

Má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Gbogbo n̄ǹkan l’ó máa parun àfi Ojú Rẹ̀ (àfi Òun). TiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/28.md)
- [كل تفاسير سورة القصص
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/28.md)
- [ترجمات سورة القصص
](https://quranpedia.net/translations/28.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/28/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
