---
title: "ترجمة سورة الرّوم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/30/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/30/book/2001"
surah_id: "30"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الرّوم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/30/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الرّوم - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/30/book/2001*.

Translation of Surah الرّوم from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 30:1

> الم [30:1]

’Alif lām mīm.

### الآية 30:2

> ﻿غُلِبَتِ الرُّومُ [30:2]

Wọ́n ṣẹ́gun Rōmu
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn ará ilẹ̀ Fārisi (ìyẹn ̓Irān)

### الآية 30:3

> ﻿فِي أَدْنَى الْأَرْضِ وَهُمْ مِنْ بَعْدِ غَلَبِهِمْ سَيَغْلِبُونَ [30:3]

ní àwọn ilẹ̀ t’ó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá). Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ní ilẹ̀ Siria, ‘Irāƙ, Jọdan àti Palẹstin

### الآية 30:4

> ﻿فِي بِضْعِ سِنِينَ ۗ لِلَّهِ الْأَمْرُ مِنْ قَبْلُ وَمِنْ بَعْدُ ۚ وَيَوْمَئِذٍ يَفْرَحُ الْمُؤْمِنُونَ [30:4]

ní ọdún mẹ́wàá (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣaájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú

### الآية 30:5

> ﻿بِنَصْرِ اللَّهِ ۚ يَنْصُرُ مَنْ يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [30:5]

sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 30:6

> ﻿وَعْدَ اللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللَّهُ وَعْدَهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ [30:6]

(Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

### الآية 30:7

> ﻿يَعْلَمُونَ ظَاهِرًا مِنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الْآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ [30:7]

Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

### الآية 30:8

> ﻿أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا فِي أَنْفُسِهِمْ ۗ مَا خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُسَمًّى ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِنَ النَّاسِ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ لَكَافِرُونَ [30:8]

Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

### الآية 30:9

> ﻿أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَأَثَارُوا الْأَرْضَ وَعَمَرُوهَا أَكْثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ [30:9]

Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

### الآية 30:10

> ﻿ثُمَّ كَانَ عَاقِبَةَ الَّذِينَ أَسَاءُوا السُّوأَىٰ أَنْ كَذَّبُوا بِآيَاتِ اللَّهِ وَكَانُوا بِهَا يَسْتَهْزِئُونَ [30:10]

Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣaburú nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́.

### الآية 30:11

> ﻿اللَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [30:11]

Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.

### الآية 30:12

> ﻿وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُبْلِسُ الْمُجْرِمُونَ [30:12]

Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù.

### الآية 30:13

> ﻿وَلَمْ يَكُنْ لَهُمْ مِنْ شُرَكَائِهِمْ شُفَعَاءُ وَكَانُوا بِشُرَكَائِهِمْ كَافِرِينَ [30:13]

Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn.

### الآية 30:14

> ﻿وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَتَفَرَّقُونَ [30:14]

Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

### الآية 30:15

> ﻿فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَهُمْ فِي رَوْضَةٍ يُحْبَرُونَ [30:15]

Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àyè t’ó rẹwà jùlọ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí wọn yó sì máa dunnú.

### الآية 30:16

> ﻿وَأَمَّا الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَلِقَاءِ الْآخِرَةِ فَأُولَٰئِكَ فِي الْعَذَابِ مُحْضَرُونَ [30:16]

Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pé àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò kó wá sínú Iná.

### الآية 30:17

> ﻿فَسُبْحَانَ اللَّهِ حِينَ تُمْسُونَ وَحِينَ تُصْبِحُونَ [30:17]

Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní alẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀.

### الآية 30:18

> ﻿وَلَهُ الْحَمْدُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَعَشِيًّا وَحِينَ تُظْهِرُونَ [30:18]

TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán.

### الآية 30:19

> ﻿يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ وَيُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ وَكَذَٰلِكَ تُخْرَجُونَ [30:19]

(Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde.

### الآية 30:20

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُمْ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنْتُمْ بَشَرٌ تَنْتَشِرُونَ [30:20]

Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé).

### الآية 30:21

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُمْ مِنْ أَنْفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُمْ مَوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ [30:21]

Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fun yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó láròjinlẹ̀.

### الآية 30:22

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِلْعَالِمِينَ [30:22]

Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀.

### الآية 30:23

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُمْ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُمْ مِنْ فَضْلِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَسْمَعُونَ [30:23]

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀.

### الآية 30:24

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ [30:24]

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè.

### الآية 30:25

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ تَقُومَ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنْتُمْ تَخْرُجُونَ [30:25]

Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀.

### الآية 30:26

> ﻿وَلَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَهُ قَانِتُونَ [30:26]

TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Āyah yìí jọ sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49 nítorí pé, wọ́n dì jọ jẹ́ oní-pọ́nna. Ní ti āyah òkè yìí, pọ́n-na inú rẹ̀ ni pé, kò sí ẹni tí kò tẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Irú àṣẹ tí wọ́n ń tọ́ka sí nínú āyah yìí l’ó mú pọ́n-na lọ́wọ́. Àṣẹ méjì l’ó wà lórí ẹ̀dá. Àṣẹ àdámọ́ àti àṣẹ ìjọ́sìn. Àṣẹ àdámọ́ l’ó jẹmọ́ wíwá sáyé, lílọ sọ́run àti gbogbo ohun tí ọmọnìyàn kò lè ríbi yẹ̀ ẹ́ sí bí ebi, òǹgbẹ, oorun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwọ̀nyẹn ni àṣẹ Allāhu lára ẹnì kọ̀ọ̀kan, yálà onígbàgbọ́ òdodo tàbí aláìgbàgbọ́. Nítorí náà, gbogbo wa ni à ń tẹ̀lé àṣẹ Allāhu t’ó jẹmọ́ àdámọ́ nígbàkígbà tí àṣẹ náà bá dé sí wá lára. Kódà tí ìdíwọ́ kan bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láti tẹ̀lé àṣẹ náà, ìnira máa gbá a mú títí ó máa fi tẹ̀lé àṣẹ náà. Àmọ́ ní ti àṣẹ ìjọ́sìn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan l’ó ń tẹ̀lé àṣẹ Allāhu lórí rẹ̀. Ní ti àwọn aláìgbàgbọ́, àṣẹ Èṣù àti àṣẹ ìfẹ́-inú wọn ni wọ́n ń tẹ̀lé. Irú āyah òkè yìí tún wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:116, Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ t’ó ṣíwájú nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:15.

### الآية 30:27

> ﻿وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ ۚ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَىٰ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ [30:27]

Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn t’ó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìròyìn t’ó ga jùlọ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ròyìn ara Rẹ̀ ni gbolóhùn “Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.” Àti gbólóhùn yìí :“Kò sí kiní kan t’ó dà bí Rẹ̀…” (at-Tọbariy)

### الآية 30:28

> ﻿ضَرَبَ لَكُمْ مَثَلًا مِنْ أَنْفُسِكُمْ ۖ هَلْ لَكُمْ مِنْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ مِنْ شُرَكَاءَ فِي مَا رَزَقْنَاكُمْ فَأَنْتُمْ فِيهِ سَوَاءٌ تَخَافُونَهُمْ كَخِيفَتِكُمْ أَنْفُسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ [30:28]

(Allāhu) ṣàkàwé kan fun yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fun yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gbadọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń páyà ẹ̀yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Èsì sí àkàwé yìí ni pé, kò sí olówó ẹrú tí ó máa sọ ẹrú rẹ̀ di ẹgbẹ́ rẹ̀ lórí dúkìá rẹ̀. Ṣebí dúkìá náà ni ẹrú jẹ́ fún olówó ẹrú. Nítorí náà, kò lè sí ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa sọ di ẹgbẹ́ Rẹ̀ láààrin gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Ẹrú Rẹ̀ sì ni gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀.

### الآية 30:29

> ﻿بَلِ اتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَهْوَاءَهُمْ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۖ فَمَنْ يَهْدِي مَنْ أَضَلَّ اللَّهُ ۖ وَمَا لَهُمْ مِنْ نَاصِرِينَ [30:29]

Ńṣe ni àwọn t’ó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn.

### الآية 30:30

> ﻿فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا ۚ فِطْرَتَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا ۚ لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ [30:30]

Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sì sí ìyípadà fún ẹ̀dá Allāhu. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yūnus; 10:105.

### الآية 30:31

> ﻿۞ مُنِيبِينَ إِلَيْهِ وَاتَّقُوهُ وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُشْرِكِينَ [30:31]

(Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kírun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

### الآية 30:32

> ﻿مِنَ الَّذِينَ فَرَّقُوا دِينَهُمْ وَكَانُوا شِيَعًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ [30:32]

(Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn t’ó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.

### الآية 30:33

> ﻿وَإِذَا مَسَّ النَّاسَ ضُرٌّ دَعَوْا رَبَّهُمْ مُنِيبِينَ إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا أَذَاقَهُمْ مِنْهُ رَحْمَةً إِذَا فَرِيقٌ مِنْهُمْ بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ [30:33]

Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn

### الآية 30:34

> ﻿لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ [30:34]

nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

### الآية 30:35

> ﻿أَمْ أَنْزَلْنَا عَلَيْهِمْ سُلْطَانًا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُوا بِهِ يُشْرِكُونَ [30:35]

Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?

### الآية 30:36

> ﻿وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً فَرِحُوا بِهَا ۖ وَإِنْ تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ إِذَا هُمْ يَقْنَطُونَ [30:36]

Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù.

### الآية 30:37

> ﻿أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ [30:37]

Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́.

### الآية 30:38

> ﻿فَآتِ ذَا الْقُرْبَىٰ حَقَّهُ وَالْمِسْكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لِلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجْهَ اللَّهِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [30:38]

Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò tí agara dá (ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.

### الآية 30:39

> ﻿وَمَا آتَيْتُمْ مِنْ رِبًا لِيَرْبُوَ فِي أَمْوَالِ النَّاسِ فَلَا يَرْبُو عِنْدَ اللَّهِ ۖ وَمَا آتَيْتُمْ مِنْ زَكَاةٍ تُرِيدُونَ وَجْهَ اللَّهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُضْعِفُونَ [30:39]

Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀bùn, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san.

### الآية 30:40

> ﻿اللَّهُ الَّذِي خَلَقَكُمْ ثُمَّ رَزَقَكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۖ هَلْ مِنْ شُرَكَائِكُمْ مَنْ يَفْعَلُ مِنْ ذَٰلِكُمْ مِنْ شَيْءٍ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ [30:40]

Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fun yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

### الآية 30:41

> ﻿ظَهَرَ الْفَسَادُ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِي النَّاسِ لِيُذِيقَهُمْ بَعْضَ الَّذِي عَمِلُوا لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ [30:41]

Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú).

### الآية 30:42

> ﻿قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلُ ۚ كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُشْرِكِينَ [30:42]

Sọ pé: “Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ.”

### الآية 30:43

> ﻿فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ الْقَيِّمِ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا مَرَدَّ لَهُ مِنَ اللَّهِ ۖ يَوْمَئِذٍ يَصَّدَّعُونَ [30:43]

Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná).

### الآية 30:44

> ﻿مَنْ كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِأَنْفُسِهِمْ يَمْهَدُونَ [30:44]

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún

### الآية 30:45

> ﻿لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِنْ فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ [30:45]

nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 30:46

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ يُرْسِلَ الرِّيَاحَ مُبَشِّرَاتٍ وَلِيُذِيقَكُمْ مِنْ رَحْمَتِهِ وَلِتَجْرِيَ الْفُلْكُ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ [30:46]

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fun yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

### الآية 30:47

> ﻿وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَاءُوهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَانْتَقَمْنَا مِنَ الَّذِينَ أَجْرَمُوا ۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيْنَا نَصْرُ الْمُؤْمِنِينَ [30:47]

Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 30:48

> ﻿اللَّهُ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَيَبْسُطُهُ فِي السَّمَاءِ كَيْفَ يَشَاءُ وَيَجْعَلُهُ كِسَفًا فَتَرَى الْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَالِهِ ۖ فَإِذَا أَصَابَ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ [30:48]

Allāhu ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s’ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú.

### الآية 30:49

> ﻿وَإِنْ كَانُوا مِنْ قَبْلِ أَنْ يُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ مِنْ قَبْلِهِ لَمُبْلِسِينَ [30:49]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀.

### الآية 30:50

> ﻿فَانْظُرْ إِلَىٰ آثَارِ رَحْمَتِ اللَّهِ كَيْفَ يُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ [30:50]

Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yìí ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 30:51

> ﻿وَلَئِنْ أَرْسَلْنَا رِيحًا فَرَأَوْهُ مُصْفَرًّا لَظَلُّوا مِنْ بَعْدِهِ يَكْفُرُونَ [30:51]

Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀.

### الآية 30:52

> ﻿فَإِنَّكَ لَا تُسْمِعُ الْمَوْتَىٰ وَلَا تُسْمِعُ الصُّمَّ الدُّعَاءَ إِذَا وَلَّوْا مُدْبِرِينَ [30:52]

Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.

### الآية 30:53

> ﻿وَمَا أَنْتَ بِهَادِ الْعُمْيِ عَنْ ضَلَالَتِهِمْ ۖ إِنْ تُسْمِعُ إِلَّا مَنْ يُؤْمِنُ بِآيَاتِنَا فَهُمْ مُسْلِمُونَ [30:53]

Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni lérò pé, níwọ̀n ìgbà tí āyah 52 àti 53 òkè yìí ti fi rinlẹ̀ pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè bá òkú sọ̀rọ̀ kí ó gbọ́, kí ó sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jí òkú dìde; níwọ̀n ìgbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè la etí adití kí ó gbọ́rọ̀ àti níwọ̀n ìgbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè la ojú afọ́jú kí ó ríran gẹ́gẹ́ bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe la ojú afọ́jú, wọ́n ní nígbà náà kí l’ó fẹ́ sọ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) di aṣíwájú bíi ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àti pé, kò lè sí ìgbàlà lọ́dọ̀ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí pé, kò lè jí òkú dìde, kò lè la etí adití, kò sì lè la ojú afọ́jú. Wọ́n ní nítorí náà, ọ̀dọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ni ìgbàlà wà nítorí pé, ó ṣe gbogbo ìwọ̀nyẹn àti òmíràn fún ará ayé!
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, iṣẹ́ ìyanu kọ́ ni òṣùwọ̀n fún ta ni ó lè jẹ́ aṣíwájú àwọn ènìyàn. Ẹnì kan kan kò sì lè rọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan lóyè nípasẹ̀ àìṣe iṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan t’ó dá iṣẹ́ ìyanu ṣe láti ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ bí kò ṣe èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá yọ̀ǹda fún un láti ṣe nítorí pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan tí Allāhu kò fún ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe ní ìbámu sí ìgbà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni èyíkéyìí iṣẹ́ ìyanu tí ó bá tọwọ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan wáyé kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ náà di olúwa àti olùgbàlà. Allāhu nìkan ṣoṣo ní Olúwa àti Olùgbàlà ayé àti ọ̀run. Nítorí náà, fún àlékún lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mọ̄’idah; 5:110. 
Lẹ́yìn náà, kì í ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ní agbára láti fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní irúfẹ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu òkè wọ̀nyẹn ṣe, tí Allāhu bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ àwọn kristiẹni, gẹ́gẹ́ bí ìṣesí wọn, ńṣe ni wọ́n gbé àwọn āyah náà ka ibùgbékà òdì nítorí pé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ṣíṣe ni àkòrí àwọn āyah náà bí kò ṣe pé àpẹẹrẹ àti àpèjúwe àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ni kókó nínú àwọn āyah náà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà wé òkú, adití àti afọ́jú ni. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi yé Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé, lẹ́yìn tí ó bá ti ké àwọn āyah fún àwọn ènìyàn nípa òdodo ’Islām, ẹni tí ó bá tún takú sórí àìgbàgbọ́, kì í ṣe ènìyàn t’ó pé níye mọ́, onítọ̀ún ti wà nípò òkú, ẹni tí kò lè ṣe àtúnṣe kan kan mọ́ sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ti wà nípò adití nítorí pé, adití kì í gbọ́rọ̀. Bákan náà, aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ti wà nípò afọ́jú nítorí pé, afọ́jú kì í ríran, kò sì lè dárìn láì níí máa já sí kòtò àti gelemọ. Nítorí náà, àfiwé àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ní kókó àti àkòrí àwọn āyah náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu. 
Lẹ́yìn náà, irúfẹ́ àwọn āyah náà ń pa ìbànújẹ́ rẹ́ nínú ọkàn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni nítorí pé, bí ó ṣe ń wù ú tó àti bí ó ṣe ń jẹ̀rankàn tó ni pé, kí gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ gbàgbọ́ nínú Allāhu. Àmọ́ wọn kò gbàgbọ́, Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ń pàrọwà fún un pé, ọwọ́ Òun ni ìyẹn wà. Kí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) má wulẹ̀ fi ìrònú ìyẹn han ara rẹ̀ léèmọ̀.

### الآية 30:54

> ﻿۞ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ ضَعْفٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْ بَعْدِ ضَعْفٍ قُوَّةً ثُمَّ جَعَلَ مِنْ بَعْدِ قُوَّةٍ ضَعْفًا وَشَيْبَةً ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَلِيمُ الْقَدِيرُ [30:54]

Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára.

### الآية 30:55

> ﻿وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُقْسِمُ الْمُجْرِمُونَ مَا لَبِثُوا غَيْرَ سَاعَةٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَانُوا يُؤْفَكُونَ [30:55]

Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ.” Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń f’irọ́ tanra wọn jẹ.

### الآية 30:56

> ﻿وَقَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ وَالْإِيمَانَ لَقَدْ لَبِثْتُمْ فِي كِتَابِ اللَّهِ إِلَىٰ يَوْمِ الْبَعْثِ ۖ فَهَٰذَا يَوْمُ الْبَعْثِ وَلَٰكِنَّكُمْ كُنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ [30:56]

Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: “Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀.”

### الآية 30:57

> ﻿فَيَوْمَئِذٍ لَا يَنْفَعُ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَعْذِرَتُهُمْ وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ [30:57]

Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn t’ó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.

### الآية 30:58

> ﻿وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِنْ كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَلَئِنْ جِئْتَهُمْ بِآيَةٍ لَيَقُولَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا مُبْطِلُونَ [30:58]

A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur’ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Ẹ̀yin (mùsùlùmí) kò jẹ́ kiní kan tayọ òpùrọ́.”

### الآية 30:59

> ﻿كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ [30:59]

Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀.

### الآية 30:60

> ﻿فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ ۖ وَلَا يَسْتَخِفَّنَّكَ الَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ [30:60]

Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ dòpè.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/30.md)
- [كل تفاسير سورة الرّوم
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/30.md)
- [ترجمات سورة الرّوم
](https://quranpedia.net/translations/30.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/30/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
