---
title: "ترجمة سورة السجدة - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/32/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/32/book/2001"
surah_id: "32"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة السجدة - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/32/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة السجدة - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/32/book/2001*.

Translation of Surah السجدة from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 32:1

> الم [32:1]

’Alif lām mīm.

### الآية 32:2

> ﻿تَنْزِيلُ الْكِتَابِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ [32:2]

Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 32:3

> ﻿أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۚ بَلْ هُوَ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ لِتُنْذِرَ قَوْمًا مَا أَتَاهُمْ مِنْ نَذِيرٍ مِنْ قَبْلِكَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ [32:3]

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọsọs; 28:46.

### الآية 32:4

> ﻿اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ مَا لَكُمْ مِنْ دُونِهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا شَفِيعٍ ۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ [32:4]

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fun yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

### الآية 32:5

> ﻿يُدَبِّرُ الْأَمْرَ مِنَ السَّمَاءِ إِلَى الْأَرْضِ ثُمَّ يَعْرُجُ إِلَيْهِ فِي يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُ أَلْفَ سَنَةٍ مِمَّا تَعُدُّونَ [32:5]

Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hajj; 22:47.

### الآية 32:6

> ﻿ذَٰلِكَ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ [32:6]

Ìyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run,

### الآية 32:7

> ﻿الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ ۖ وَبَدَأَ خَلْقَ الْإِنْسَانِ مِنْ طِينٍ [32:7]

Ẹni t’ó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó dá ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú erùpẹ̀ amọ̀.

### الآية 32:8

> ﻿ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُ مِنْ سُلَالَةٍ مِنْ مَاءٍ مَهِينٍ [32:8]

Lẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ.

### الآية 32:9

> ﻿ثُمَّ سَوَّاهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِنْ رُوحِهِ ۖ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۚ قَلِيلًا مَا تَشْكُرُونَ [32:9]

Lẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá). Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fun yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá!
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ọ̀rọ̀ “ẹ̀mí” nínú āyah yìí ṣe wẹ́kú ọ̀rọ̀ “ẹ̀mí” t’ó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:171.

### الآية 32:10

> ﻿وَقَالُوا أَإِذَا ضَلَلْنَا فِي الْأَرْضِ أَإِنَّا لَفِي خَلْقٍ جَدِيدٍ ۚ بَلْ هُمْ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ كَافِرُونَ [32:10]

Wọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

### الآية 32:11

> ﻿۞ قُلْ يَتَوَفَّاكُمْ مَلَكُ الْمَوْتِ الَّذِي وُكِّلَ بِكُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ [32:11]

Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A fi tì yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni lérò pé àwọn āyah t’ó ń sọ nípa ẹ̀mí gbígbà tàbí ikú takora wọn nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n ní àwọn āyah náà ni: sūrah az-Zumọr; 39:42, sūrah al-’Anfāl; 8:50, sūrah al-’Ani‘ām; 6:61 àti sūrah as-Sajdah; 32:11. 
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu ni Ẹlẹ́dàá ìṣẹ̀mí àti ikú, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ìṣẹ̀mí wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Kò sì sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ikú wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nípa èyí, Allāhu l’Ó ń fi àṣẹ Rẹ̀ gba ẹ̀mí kúrò lára ẹ̀dá Rẹ̀ ní àkókò tí Ó ti kọ mọ́ ọn nínú kádàrá. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Bákan náà, Allāhu ṣẹ̀dá àwọn mọlāika gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti òjíṣẹ́ Rẹ̀ lórí gbogbo n̄ǹkan. Nípa èyí, àwọn mọlāika kan wà fún ẹ̀mí gbígbà. Ìyẹn l’ó jẹyọ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:50 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:61. Allāhu sì fi ẹnì kan ṣe ọ̀gá nínú àwọn mọlāika t’ó wà níbi ẹ̀mí gbígbà. Ọ̀gá yìí l’ó sì gbé orúkọ àti àwòrán ikú rù. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah as-Sajdah; 32:11. Níbo wá ni ìtakora wà? Kò sí. Al-hamdulillah.

### الآية 32:12

> ﻿وَلَوْ تَرَىٰ إِذِ الْمُجْرِمُونَ نَاكِسُو رُءُوسِهِمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ رَبَّنَا أَبْصَرْنَا وَسَمِعْنَا فَارْجِعْنَا نَعْمَلْ صَالِحًا إِنَّا مُوقِنُونَ [32:12]

(Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.”

### الآية 32:13

> ﻿وَلَوْ شِئْنَا لَآتَيْنَا كُلَّ نَفْسٍ هُدَاهَا وَلَٰكِنْ حَقَّ الْقَوْلُ مِنِّي لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ الْجِنَّةِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ [32:13]

Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.”

### الآية 32:14

> ﻿فَذُوقُوا بِمَا نَسِيتُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا إِنَّا نَسِينَاكُمْ ۖ وَذُوقُوا عَذَابَ الْخُلْدِ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ [32:14]

Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín sínú Iná. Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe onígbàgbé. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.

### الآية 32:15

> ﻿إِنَّمَا يُؤْمِنُ بِآيَاتِنَا الَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُوا بِهَا خَرُّوا سُجَّدًا وَسَبَّحُوا بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ ۩ [32:15]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga.

### الآية 32:16

> ﻿تَتَجَافَىٰ جُنُوبُهُمْ عَنِ الْمَضَاجِعِ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ خَوْفًا وَطَمَعًا وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ [32:16]

Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn kúrò lórí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.

### الآية 32:17

> ﻿فَلَا تَعْلَمُ نَفْسٌ مَا أُخْفِيَ لَهُمْ مِنْ قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [32:17]

Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).

### الآية 32:18

> ﻿أَفَمَنْ كَانَ مُؤْمِنًا كَمَنْ كَانَ فَاسِقًا ۚ لَا يَسْتَوُونَ [32:18]

Ǹjẹ́ ẹni t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni t’ó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba.

### الآية 32:19

> ﻿أَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَلَهُمْ جَنَّاتُ الْمَأْوَىٰ نُزُلًا بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [32:19]

Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).

### الآية 32:20

> ﻿وَأَمَّا الَّذِينَ فَسَقُوا فَمَأْوَاهُمُ النَّارُ ۖ كُلَّمَا أَرَادُوا أَنْ يَخْرُجُوا مِنْهَا أُعِيدُوا فِيهَا وَقِيلَ لَهُمْ ذُوقُوا عَذَابَ النَّارِ الَّذِي كُنْتُمْ بِهِ تُكَذِّبُونَ [32:20]

Ní ti àwọn t’ó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè nírọ́ wò.”

### الآية 32:21

> ﻿وَلَنُذِيقَنَّهُمْ مِنَ الْعَذَابِ الْأَدْنَىٰ دُونَ الْعَذَابِ الْأَكْبَرِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ [32:21]

Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà t’ó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà t’ó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn).

### الآية 32:22

> ﻿وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ ذُكِّرَ بِآيَاتِ رَبِّهِ ثُمَّ أَعْرَضَ عَنْهَا ۚ إِنَّا مِنَ الْمُجْرِمِينَ مُنْتَقِمُونَ [32:22]

Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí t’ó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 32:23

> ﻿وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَلَا تَكُنْ فِي مِرْيَةٍ مِنْ لِقَائِهِ ۖ وَجَعَلْنَاهُ هُدًى لِبَنِي إِسْرَائِيلَ [32:23]

Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀). A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

### الآية 32:24

> ﻿وَجَعَلْنَا مِنْهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا لَمَّا صَبَرُوا ۖ وَكَانُوا بِآيَاتِنَا يُوقِنُونَ [32:24]

Àti pé A ṣe àwọn aṣíwájú kan nínú wọn ní afinimọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù. Wọ́n sì ń ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.

### الآية 32:25

> ﻿إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ [32:25]

Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí.

### الآية 32:26

> ﻿أَوَلَمْ يَهْدِ لَهُمْ كَمْ أَهْلَكْنَا مِنْ قَبْلِهِمْ مِنَ الْقُرُونِ يَمْشُونَ فِي مَسَاكِنِهِمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ ۖ أَفَلَا يَسْمَعُونَ [32:26]

Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)?

### الآية 32:27

> ﻿أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا نَسُوقُ الْمَاءَ إِلَى الْأَرْضِ الْجُرُزِ فَنُخْرِجُ بِهِ زَرْعًا تَأْكُلُ مِنْهُ أَنْعَامُهُمْ وَأَنْفُسُهُمْ ۖ أَفَلَا يُبْصِرُونَ [32:27]

Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni?

### الآية 32:28

> ﻿وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْفَتْحُ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ [32:28]

Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

### الآية 32:29

> ﻿قُلْ يَوْمَ الْفَتْحِ لَا يَنْفَعُ الَّذِينَ كَفَرُوا إِيمَانُهُمْ وَلَا هُمْ يُنْظَرُونَ [32:29]

Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ wọn kò níí ṣàǹfààní fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nínú Allāhu). A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”

### الآية 32:30

> ﻿فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَانْتَظِرْ إِنَّهُمْ مُنْتَظِرُونَ [32:30]

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀).

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/32.md)
- [كل تفاسير سورة السجدة
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/32.md)
- [ترجمات سورة السجدة
](https://quranpedia.net/translations/32.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/32/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
