---
title: "ترجمة سورة يس - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/36/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/36/book/2001"
surah_id: "36"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة يس - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/36/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة يس - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/36/book/2001*.

Translation of Surah يس from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 36:1

> يس [36:1]

Yā sīn

### الآية 36:2

> ﻿وَالْقُرْآنِ الْحَكِيمِ [36:2]

(Allāhu) búra pẹ̀lú Al-Ƙur’ān tírà ọgbọ́n.

### الآية 36:3

> ﻿إِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ [36:3]

Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

### الآية 36:4

> ﻿عَلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ [36:4]

(O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām).

### الآية 36:5

> ﻿تَنْزِيلَ الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ [36:5]

(Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

### الآية 36:6

> ﻿لِتُنْذِرَ قَوْمًا مَا أُنْذِرَ آبَاؤُهُمْ فَهُمْ غَافِلُونَ [36:6]

nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọsọs; 28;46.

### الآية 36:7

> ﻿لَقَدْ حَقَّ الْقَوْلُ عَلَىٰ أَكْثَرِهِمْ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ [36:7]

Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́.

### الآية 36:8

> ﻿إِنَّا جَعَلْنَا فِي أَعْنَاقِهِمْ أَغْلَالًا فَهِيَ إِلَى الْأَذْقَانِ فَهُمْ مُقْمَحُونَ [36:8]

Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn. Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè.

### الآية 36:9

> ﻿وَجَعَلْنَا مِنْ بَيْنِ أَيْدِيهِمْ سَدًّا وَمِنْ خَلْفِهِمْ سَدًّا فَأَغْشَيْنَاهُمْ فَهُمْ لَا يُبْصِرُونَ [36:9]

Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran.

### الآية 36:10

> ﻿وَسَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَأَنْذَرْتَهُمْ أَمْ لَمْ تُنْذِرْهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ [36:10]

Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o ò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.

### الآية 36:11

> ﻿إِنَّمَا تُنْذِرُ مَنِ اتَّبَعَ الذِّكْرَ وَخَشِيَ الرَّحْمَٰنَ بِالْغَيْبِ ۖ فَبَشِّرْهُ بِمَغْفِرَةٍ وَأَجْرٍ كَرِيمٍ [36:11]

Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìṣítí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé.

### الآية 36:12

> ﻿إِنَّا نَحْنُ نُحْيِي الْمَوْتَىٰ وَنَكْتُبُ مَا قَدَّمُوا وَآثَارَهُمْ ۚ وَكُلَّ شَيْءٍ أَحْصَيْنَاهُ فِي إِمَامٍ مُبِينٍ [36:12]

Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan t’ó yanjú.

### الآية 36:13

> ﻿وَاضْرِبْ لَهُمْ مَثَلًا أَصْحَابَ الْقَرْيَةِ إِذْ جَاءَهَا الْمُرْسَلُونَ [36:13]

Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn.

### الآية 36:14

> ﻿إِذْ أَرْسَلْنَا إِلَيْهِمُ اثْنَيْنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزْنَا بِثَالِثٍ فَقَالُوا إِنَّا إِلَيْكُمْ مُرْسَلُونَ [36:14]

(Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”

### الآية 36:15

> ﻿قَالُوا مَا أَنْتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا وَمَا أَنْزَلَ الرَّحْمَٰنُ مِنْ شَيْءٍ إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا تَكْذِبُونَ [36:15]

Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”

### الآية 36:16

> ﻿قَالُوا رَبُّنَا يَعْلَمُ إِنَّا إِلَيْكُمْ لَمُرْسَلُونَ [36:16]

Wọ́n sọ pé: "Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.

### الآية 36:17

> ﻿وَمَا عَلَيْنَا إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ [36:17]

Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kọ̀ ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé.”

### الآية 36:18

> ﻿قَالُوا إِنَّا تَطَيَّرْنَا بِكُمْ ۖ لَئِنْ لَمْ تَنْتَهُوا لَنَرْجُمَنَّكُمْ وَلَيَمَسَّنَّكُمْ مِنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ [36:18]

Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ ò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.”

### الآية 36:19

> ﻿قَالُوا طَائِرُكُمْ مَعَكُمْ ۚ أَئِنْ ذُكِّرْتُمْ ۚ بَلْ أَنْتُمْ قَوْمٌ مُسْرِفُونَ [36:19]

Wọ́n sọ pé: "Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fun yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni."

### الآية 36:20

> ﻿وَجَاءَ مِنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ رَجُلٌ يَسْعَىٰ قَالَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُوا الْمُرْسَلِينَ [36:20]

Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà.

### الآية 36:21

> ﻿اتَّبِعُوا مَنْ لَا يَسْأَلُكُمْ أَجْرًا وَهُمْ مُهْتَدُونَ [36:21]

Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n.

### الآية 36:22

> ﻿وَمَا لِيَ لَا أَعْبُدُ الَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [36:22]

Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

### الآية 36:23

> ﻿أَأَتَّخِذُ مِنْ دُونِهِ آلِهَةً إِنْ يُرِدْنِ الرَّحْمَٰنُ بِضُرٍّ لَا تُغْنِ عَنِّي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا وَلَا يُنْقِذُونِ [36:23]

Ṣé kí n̄g sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là.

### الآية 36:24

> ﻿إِنِّي إِذًا لَفِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [36:24]

(Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

### الآية 36:25

> ﻿إِنِّي آمَنْتُ بِرَبِّكُمْ فَاسْمَعُونِ [36:25]

Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.”

### الآية 36:26

> ﻿قِيلَ ادْخُلِ الْجَنَّةَ ۖ قَالَ يَا لَيْتَ قَوْمِي يَعْلَمُونَ [36:26]

Wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀

### الآية 36:27

> ﻿بِمَا غَفَرَ لِي رَبِّي وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُكْرَمِينَ [36:27]

nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).”

### الآية 36:28

> ﻿۞ وَمَا أَنْزَلْنَا عَلَىٰ قَوْمِهِ مِنْ بَعْدِهِ مِنْ جُنْدٍ مِنَ السَّمَاءِ وَمَا كُنَّا مُنْزِلِينَ [36:28]

A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A ò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn).

### الآية 36:29

> ﻿إِنْ كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً فَإِذَا هُمْ خَامِدُونَ [36:29]

(Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀.

### الآية 36:30

> ﻿يَا حَسْرَةً عَلَى الْعِبَادِ ۚ مَا يَأْتِيهِمْ مِنْ رَسُولٍ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ [36:30]

Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà; òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

### الآية 36:31

> ﻿أَلَمْ يَرَوْا كَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُمْ مِنَ الْقُرُونِ أَنَّهُمْ إِلَيْهِمْ لَا يَرْجِعُونَ [36:31]

Ṣé wọn kò rí i pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò rí i pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni?

### الآية 36:32

> ﻿وَإِنْ كُلٌّ لَمَّا جَمِيعٌ لَدَيْنَا مُحْضَرُونَ [36:32]

Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni wọ́n máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

### الآية 36:33

> ﻿وَآيَةٌ لَهُمُ الْأَرْضُ الْمَيْتَةُ أَحْيَيْنَاهَا وَأَخْرَجْنَا مِنْهَا حَبًّا فَمِنْهُ يَأْكُلُونَ [36:33]

Àmì ni òkú ilẹ̀ jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di àyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i! Nínú ìlò èdè Yorùbá, kò sí “òkú ilẹ̀” tàbí pé “ilẹ̀ kú”. Dípò bẹ́ẹ̀, Yorùbá máa sọ pé, “Kàkà kí ilẹ̀ kú, ilẹ̀ yó yà sá ni.” Àmọ́ ìlò èdè Lárúbáwá kò tako pípe ilẹ̀ ní “òkú ilẹ̀”.

### الآية 36:34

> ﻿وَجَعَلْنَا فِيهَا جَنَّاتٍ مِنْ نَخِيلٍ وَأَعْنَابٍ وَفَجَّرْنَا فِيهَا مِنَ الْعُيُونِ [36:34]

A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sínú ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́ yọ láti inú rẹ̀

### الآية 36:35

> ﻿لِيَأْكُلُوا مِنْ ثَمَرِهِ وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ [36:35]

nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe! Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ Tafsīr túmọ̀ “mọ̄” t’ó jẹyọ nínú 
“وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ” yìí sí “mọ̄-maosūlah’. Ìtúmọ̀ yìí l’a lò nínú āyah yìí. Ìtúmọ̀ náà sì dúró lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn mìíràn sì túmọ̀ “mọ̄” yìí sí “mọ̄-nnāfiyah. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbólóhùn náà máa túmọ̀ sí pé, “nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀, kì í sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?” Ìtúmọ̀ kejì dúró lé iṣẹ́ Allāhu lórí ìṣẹ̀dá n̄ǹkan oko. Ìyẹn ni pé, àdáyébá ni gbogbo èso. Kò sí èso kan tí ìṣẹ̀dá rẹ wá láti ọwọ́ àgbẹ̀.

### الآية 36:36

> ﻿سُبْحَانَ الَّذِي خَلَقَ الْأَزْوَاجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنْبِتُ الْأَرْضُ وَمِنْ أَنْفُسِهِمْ وَمِمَّا لَا يَعْلَمُونَ [36:36]

Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáẹ̀nsì tako āyah yìí nítorí pé, àìmọ̀ye n̄ǹkan l’ó wà tí kò ṣe é pín sí ìsọ̀rí akọ àti abo.” 
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, mùsùlùmí kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀tàn pẹ̀lú àbá tàbí irọ́. Àbá àti irọ́ ni èyíkéyìí ọ̀rọ̀ tàbí ìròrí t’ó bá yapa sí al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ìpasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sáẹ̀nsì kan, tàbí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ kan tàbí ìmọ̀ ìròrí kan tàbí èyíkéyìí ìmọ̀ kan lòdì sí āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé.
Ó ṣuwọ̀n kí àwọn kristiẹni dákẹ́ ẹnu wọn nípa ìtúmọ̀ āyah al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí pé, ńṣe ni wọ́n ń dá ọ̀ràn kún ọ̀ràn. Wọ́n sì ń fira wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aláìmọ̀kan t’ó gbópọn. Nínú al-Ƙur’ān kalmọh “zaoj” jẹyọ ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àpapọ̀ rẹ̀ lé ní ọgbọ̀n. “’Azwāj” ni ọ̀pọ̀, “zaoj” ni ẹyọ. “Zaoj” sì ń túmọ̀ sí akọ tàbí abo nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn tàbí ọmọ bíbí, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Najm; 53:45 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:39. 
Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí ọkọ tàbí aya nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó. Ìtúmọ̀ ti “aya” l’ó sì pọ̀ jùlọ fún zaoj nínú al-Ƙur’ān. 
Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí ìkíní-kejì tàbí ẹnì kejì nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ènìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:102. 
Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí èjì ọ̀kán-yà (n̄ǹkan kan náà méjì, àmọ́ tí ìkíní kejì yàtọ̀ síra wọn ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí akọ àti abo, n̄ǹkan dídùn àti n̄ǹkan kíkorò, n̄ǹkan tútù àti n̄ǹkan gbígbóná, n̄ǹkan mímu àti n̄ǹkan jíjẹ) tàbí èjì onídàkejì (n̄ǹkan méjì tí ìkíní kejì dúró fún ọ̀rọ̀ àti ìdà kejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sánmọ̀ àti ilẹ̀, ènìyàn àti àlùjọ̀nnú, ọ̀sán àti òru, ìmọ́lẹ̀ àti òòkùn, ìṣìnà àti ìmọ̀nà, òòrùn àti òṣùpá. Ìtúmọ̀ wọ̀nyí ni zaoj mú wá nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ àti sūrah ath-Thāriyāt; 51:49 àti nínú ar-Rahmọ̄n; 55:45. 
Síwájú sí i, “zaoj” tún túmọ̀ sí oníran-ànran tàbí oríṣiríṣi. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí èso mímu tàbí èso jíjẹ kan tí ó máa jẹ́ oríṣiríṣi. Ìtúmọ̀ olóríṣiríṣi tún lọ lábẹ́ āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Nítorí náà, zaoj kò pọn dandan kí ó ní ìtúmọ̀ akọ àti abo nìkan. Oríṣiríṣi ni “zaoj”; akọ jẹ oríṣi kan, abo jẹ́ oríṣi kan, àwọ̀ jẹ oríṣi kan, èdè jẹ́ oríṣi kan, adùn jẹ́ oríṣi kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. “Zaoj” ni n̄ǹkan oríṣi méjì, “ ’azwāj” ni n̄ǹkan oríṣiríṣi.

### الآية 36:37

> ﻿وَآيَةٌ لَهُمُ اللَّيْلُ نَسْلَخُ مِنْهُ النَّهَارَ فَإِذَا هُمْ مُظْلِمُونَ [36:37]

Òru jẹ́ àmì kan fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kókó inú āyah yìí ni pé, òru l’ó ń ṣíwájú ọ̀sán nínú ọjọ́, bí àpẹẹrẹ, òru Jímọ̀ mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Nítorí náà, kò sí òru Àlàmísì mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Bákan náà, wíwọ̀ òòrùn ni ìparí ọjọ́ kan àti ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ mìíràn. Ìyẹn ni pé, níkété tí òòrùn bá ti wọ̀, a ti parí ọjọ́ tí à ń lò bọ̀, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ titun. Ní ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, ni ọjọ́ kan ń parí, tí ọjọ́ titun ń bẹ̀rẹ̀ ní aago méjìlá òru. Ìyẹn kì í ṣe ìlànà ti Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Síwájú sí i, tí obìnrin bá bímọ, ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìparan súná ọmọ náà. Báwo ni a ó ṣe ka ọjọ́ méje náà? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn kan lérò pé, ọjọ́ mẹ́jọ ni ọjọ́ súná ọmọ. Èyí sì tako hadīth súná ọmọ ṣíṣe tí Samrah ọmọ Jundub (rọdiyallāhu 'anhu) gbà wá pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: كُلُّ غُلاَمٍ رَهِينَةٌ بِعَقِيقَتِهِ تُذْبَحُ عَنْهُ يَوْمَ سَابِعِهِ وَيُحْلَقُ وَيُسَمَّى Ìtúmọ̀: “Ọmọ titun kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ti fi ẹran ‘aƙīkọh kan dógò fún tí wọ́n máa bá a pa ní ọjọ́ keje rẹ̀ (t’ó dáyé). Wọ́n máa fá irun orí rẹ̀. Wọ́n sì máa fún un ní orúkọ.” (Abu Dāud) Irú ẹ̀gbàwá yìí wà nínú An-Nasā’iy, Ahmad àti Baehaƙiy. 
Àṣìṣe tí àwọn ọlọ́jọ́ mẹ́jọ fún súná ọmọ ṣíṣe ṣe ni pé, wọn kì í ka ọjọ́ ìbímọ mọ́ ọn. Dandan sì ni kí ọjọ́ ìbímọ jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọjọ́ méje náà, kódà kí ọjọ́ ìbímọ ku ìṣẹ́jú kan tí a ó fi bọ́ sínú ọjọ́ titun. Bí àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan bá bímọ ní ọ̀sán Alaadi, ní àkókò bíi kó ku ìṣẹ́jú díẹ̀ tí òòrùn máa wọ̀ ní ọjọ́ náà, ọjọ́ Alaadi ni ọjọ́ ìbímọ̀ rẹ̀. Ọjọ́ Sabt l’ó sì máa jẹ́ ọjọ́ keje, tí ó máa jẹ́ ọjọ́ súná ọmọ náà. Ṣebí nínú ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n, tí obìnrin kan bá rí n̄ǹkan oṣù rẹ̀ ní bíi kó ku ìsẹ́jú díẹ̀ tí òòrùn máa wọ̀, ọ́ máa mú ọjọ́ yẹn kà mọ́ iye òǹkà ọjọ́ tí ó máa san padà lẹ́yìn oṣù Rọmọdọ̄n. Nítorí náà, ọjọ́ keje súná ọmọ kò gbọ́dọ̀ di ọjọ́ kẹjọ mọ́ wa lọ́wọ́. Bákan náà, àdádáálẹ́ ni ṣíṣe ìjókòó aláláàfáà fún súná ọmọ ṣíṣe. Súná ọmọ ṣíṣe kò tayọ bí ó ṣe wà nínú hadīth yẹn. Àti pé dandan ni fún òbí láti fá irun orí ọmọ titun náà ní ọjọ́ keje, yálà ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Ọmọ kó gbọ́dọ̀ di dàda nítorí pé irun ọ̀bùn àti irun ẹbọ ni irun dàda.

### الآية 36:38

> ﻿وَالشَّمْسُ تَجْرِي لِمُسْتَقَرٍّ لَهَا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ [36:38]

Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀.

### الآية 36:39

> ﻿وَالْقَمَرَ قَدَّرْنَاهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَالْعُرْجُونِ الْقَدِيمِ [36:39]

Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi ọ̀gọ́mọ̀ ọ̀pẹ t’ó ti pẹ́.

### الآية 36:40

> ﻿لَا الشَّمْسُ يَنْبَغِي لَهَا أَنْ تُدْرِكَ الْقَمَرَ وَلَا اللَّيْلُ سَابِقُ النَّهَارِ ۚ وَكُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ [36:40]

Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó t’ó ń tọ̀.

### الآية 36:41

> ﻿وَآيَةٌ لَهُمْ أَنَّا حَمَلْنَا ذُرِّيَّتَهُمْ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ [36:41]

Ó tún jẹ́ àmì fún wọn pé dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́.

### الآية 36:42

> ﻿وَخَلَقْنَا لَهُمْ مِنْ مِثْلِهِ مَا يَرْكَبُونَ [36:42]

A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.

### الآية 36:43

> ﻿وَإِنْ نَشَأْ نُغْرِقْهُمْ فَلَا صَرِيخَ لَهُمْ وَلَا هُمْ يُنْقَذُونَ [36:43]

Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là.

### الآية 36:44

> ﻿إِلَّا رَحْمَةً مِنَّا وَمَتَاعًا إِلَىٰ حِينٍ [36:44]

Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀.

### الآية 36:45

> ﻿وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّقُوا مَا بَيْنَ أَيْدِيكُمْ وَمَا خَلْفَكُمْ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ [36:45]

(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: "Ẹ ṣọ́ra fún ohun t’ó wà níwájú yín àti ohun t’ó wà lẹ́yìn yín nítorí kí A lè kẹ yín."

### الآية 36:46

> ﻿وَمَا تَأْتِيهِمْ مِنْ آيَةٍ مِنْ آيَاتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ [36:46]

Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.

### الآية 36:47

> ﻿وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ أَنْفِقُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا أَنُطْعِمُ مَنْ لَوْ يَشَاءُ اللَّهُ أَطْعَمَهُ إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [36:47]

Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: "Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fun yín.", àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

### الآية 36:48

> ﻿وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ [36:48]

Wọ́n sì ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"

### الآية 36:49

> ﻿مَا يَنْظُرُونَ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً تَأْخُذُهُمْ وَهُمْ يَخِصِّمُونَ [36:49]

Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́.

### الآية 36:50

> ﻿فَلَا يَسْتَطِيعُونَ تَوْصِيَةً وَلَا إِلَىٰ أَهْلِهِمْ يَرْجِعُونَ [36:50]

Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.

### الآية 36:51

> ﻿وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَإِذَا هُمْ مِنَ الْأَجْدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمْ يَنْسِلُونَ [36:51]

Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.

### الآية 36:52

> ﻿قَالُوا يَا وَيْلَنَا مَنْ بَعَثَنَا مِنْ مَرْقَدِنَا ۜ ۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ الرَّحْمَٰنُ وَصَدَقَ الْمُرْسَلُونَ [36:52]

Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?" Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).

### الآية 36:53

> ﻿إِنْ كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً فَإِذَا هُمْ جَمِيعٌ لَدَيْنَا مُحْضَرُونَ [36:53]

Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Wa.

### الآية 36:54

> ﻿فَالْيَوْمَ لَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا وَلَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ [36:54]

Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 36:55

> ﻿إِنَّ أَصْحَابَ الْجَنَّةِ الْيَوْمَ فِي شُغُلٍ فَاكِهُونَ [36:55]

Dájúdájú ní òní àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn.

### الآية 36:56

> ﻿هُمْ وَأَزْوَاجُهُمْ فِي ظِلَالٍ عَلَى الْأَرَائِكِ مُتَّكِئُونَ [36:56]

Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn.

### الآية 36:57

> ﻿لَهُمْ فِيهَا فَاكِهَةٌ وَلَهُمْ مَا يَدَّعُونَ [36:57]

Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú.

### الآية 36:58

> ﻿سَلَامٌ قَوْلًا مِنْ رَبٍّ رَحِيمٍ [36:58]

Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 36:59

> ﻿وَامْتَازُوا الْيَوْمَ أَيُّهَا الْمُجْرِمُونَ [36:59]

Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní.

### الآية 36:60

> ﻿۞ أَلَمْ أَعْهَدْ إِلَيْكُمْ يَا بَنِي آدَمَ أَنْ لَا تَعْبُدُوا الشَّيْطَانَ ۖ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُبِينٌ [36:60]

Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún Èṣù? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín.

### الآية 36:61

> ﻿وَأَنِ اعْبُدُونِي ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُسْتَقِيمٌ [36:61]

Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

### الآية 36:62

> ﻿وَلَقَدْ أَضَلَّ مِنْكُمْ جِبِلًّا كَثِيرًا ۖ أَفَلَمْ تَكُونُوا تَعْقِلُونَ [36:62]

Àti pé (Èṣù) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

### الآية 36:63

> ﻿هَٰذِهِ جَهَنَّمُ الَّتِي كُنْتُمْ تُوعَدُونَ [36:63]

Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín.

### الآية 36:64

> ﻿اصْلَوْهَا الْيَوْمَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ [36:64]

Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.

### الآية 36:65

> ﻿الْيَوْمَ نَخْتِمُ عَلَىٰ أَفْوَاهِهِمْ وَتُكَلِّمُنَا أَيْدِيهِمْ وَتَشْهَدُ أَرْجُلُهُمْ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [36:65]

Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 36:66

> ﻿وَلَوْ نَشَاءُ لَطَمَسْنَا عَلَىٰ أَعْيُنِهِمْ فَاسْتَبَقُوا الصِّرَاطَ فَأَنَّىٰ يُبْصِرُونَ [36:66]

Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá sójú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná?

### الآية 36:67

> ﻿وَلَوْ نَشَاءُ لَمَسَخْنَاهُمْ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمْ فَمَا اسْتَطَاعُوا مُضِيًّا وَلَا يَرْجِعُونَ [36:67]

Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn.

### الآية 36:68

> ﻿وَمَنْ نُعَمِّرْهُ نُنَكِّسْهُ فِي الْخَلْقِ ۖ أَفَلَا يَعْقِلُونَ [36:68]

Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni!

### الآية 36:69

> ﻿وَمَا عَلَّمْنَاهُ الشِّعْرَ وَمَا يَنْبَغِي لَهُ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ وَقُرْآنٌ مُبِينٌ [36:69]

A ò kọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ewì. Kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn (láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé

### الآية 36:70

> ﻿لِيُنْذِرَ مَنْ كَانَ حَيًّا وَيَحِقَّ الْقَوْلُ عَلَى الْكَافِرِينَ [36:70]

nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 36:71

> ﻿أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا خَلَقْنَا لَهُمْ مِمَّا عَمِلَتْ أَيْدِينَا أَنْعَامًا فَهُمْ لَهَا مَالِكُونَ [36:71]

Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn.

### الآية 36:72

> ﻿وَذَلَّلْنَاهَا لَهُمْ فَمِنْهَا رَكُوبُهُمْ وَمِنْهَا يَأْكُلُونَ [36:72]

A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn.

### الآية 36:73

> ﻿وَلَهُمْ فِيهَا مَنَافِعُ وَمَشَارِبُ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ [36:73]

Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

### الآية 36:74

> ﻿وَاتَّخَذُوا مِنْ دُونِ اللَّهِ آلِهَةً لَعَلَّهُمْ يُنْصَرُونَ [36:74]

Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn!

### الآية 36:75

> ﻿لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَهُمْ وَهُمْ لَهُمْ جُنْدٌ مُحْضَرُونَ [36:75]

Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí A máa kó wọ inú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo sūrah Mọryam; 19:82 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98.

### الآية 36:76

> ﻿فَلَا يَحْزُنْكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّا نَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ [36:76]

Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.

### الآية 36:77

> ﻿أَوَلَمْ يَرَ الْإِنْسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِنْ نُطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُبِينٌ [36:77]

Ṣé ènìyàn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé.

### الآية 36:78

> ﻿وَضَرَبَ لَنَا مَثَلًا وَنَسِيَ خَلْقَهُ ۖ قَالَ مَنْ يُحْيِي الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ [36:78]

Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa. Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: "Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?"

### الآية 36:79

> ﻿قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنْشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ [36:79]

Sọ pé: "Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 36:80

> ﻿الَّذِي جَعَلَ لَكُمْ مِنَ الشَّجَرِ الْأَخْضَرِ نَارًا فَإِذَا أَنْتُمْ مِنْهُ تُوقِدُونَ [36:80]

(Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fun yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi ko iná.

### الآية 36:81

> ﻿أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَنْ يَخْلُقَ مِثْلَهُمْ ۚ بَلَىٰ وَهُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ [36:81]

Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Rárá (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

### الآية 36:82

> ﻿إِنَّمَا أَمْرُهُ إِذَا أَرَادَ شَيْئًا أَنْ يَقُولَ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ [36:82]

Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

### الآية 36:83

> ﻿فَسُبْحَانَ الَّذِي بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [36:83]

Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/36.md)
- [كل تفاسير سورة يس
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/36.md)
- [ترجمات سورة يس
](https://quranpedia.net/translations/36.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/36/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
