---
title: "ترجمة سورة الزمر - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/39/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/39/book/2001"
surah_id: "39"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الزمر - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/39/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الزمر - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/39/book/2001*.

Translation of Surah الزمر from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 39:1

> تَنْزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ [39:1]

Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà (ṣẹlẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 39:2

> ﻿إِنَّا أَنْزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ فَاعْبُدِ اللَّهَ مُخْلِصًا لَهُ الدِّينَ [39:2]

Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu ní olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.

### الآية 39:3

> ﻿أَلَا لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ ۚ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَىٰ إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِي مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ كَاذِبٌ كَفَّارٌ [39:3]

Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́. Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): "A ò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni." Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.

### الآية 39:4

> ﻿لَوْ أَرَادَ اللَّهُ أَنْ يَتَّخِذَ وَلَدًا لَاصْطَفَىٰ مِمَّا يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ سُبْحَانَهُ ۖ هُوَ اللَّهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ [39:4]

Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

### الآية 39:5

> ﻿خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۖ يُكَوِّرُ اللَّيْلَ عَلَى النَّهَارِ وَيُكَوِّرُ النَّهَارَ عَلَى اللَّيْلِ ۖ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُسَمًّى ۗ أَلَا هُوَ الْعَزِيزُ الْغَفَّارُ [39:5]

Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn.

### الآية 39:6

> ﻿خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَأَنْزَلَ لَكُمْ مِنَ الْأَنْعَامِ ثَمَانِيَةَ أَزْوَاجٍ ۚ يَخْلُقُكُمْ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ خَلْقًا مِنْ بَعْدِ خَلْقٍ فِي ظُلُمَاتٍ ثَلَاثٍ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ [39:6]

Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fun yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ-tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

### الآية 39:7

> ﻿إِنْ تَكْفُرُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ عَنْكُمْ ۖ وَلَا يَرْضَىٰ لِعِبَادِهِ الْكُفْرَ ۖ وَإِنْ تَشْكُرُوا يَرْضَهُ لَكُمْ ۗ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ۗ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ مَرْجِعُكُمْ فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ [39:7]

Tí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fun yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

### الآية 39:8

> ﻿۞ وَإِذَا مَسَّ الْإِنْسَانَ ضُرٌّ دَعَا رَبَّهُ مُنِيبًا إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُ نِعْمَةً مِنْهُ نَسِيَ مَا كَانَ يَدْعُو إِلَيْهِ مِنْ قَبْلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَنْدَادًا لِيُضِلَّ عَنْ سَبِيلِهِ ۚ قُلْ تَمَتَّعْ بِكُفْرِكَ قَلِيلًا ۖ إِنَّكَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ [39:8]

Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ ní olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun t’ó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ (’Islām). Sọ pé: "Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná."

### الآية 39:9

> ﻿أَمَّنْ هُوَ قَانِتٌ آنَاءَ اللَّيْلِ سَاجِدًا وَقَائِمًا يَحْذَرُ الْآخِرَةَ وَيَرْجُو رَحْمَةَ رَبِّهِ ۗ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الَّذِينَ يَعْلَمُونَ وَالَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ ۗ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُولُو الْأَلْبَابِ [39:9]

Ǹjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (t’ó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, t’ó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, t’ó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l’ó ń lo ìrántí.

### الآية 39:10

> ﻿قُلْ يَا عِبَادِ الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا رَبَّكُمْ ۚ لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا حَسَنَةٌ ۗ وَأَرْضُ اللَّهِ وَاسِعَةٌ ۗ إِنَّمَا يُوَفَّى الصَّابِرُونَ أَجْرَهُمْ بِغَيْرِ حِسَابٍ [39:10]

Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn t’ó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò. Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn láì la ìṣírò lọ."

### الآية 39:11

> ﻿قُلْ إِنِّي أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ اللَّهَ مُخْلِصًا لَهُ الدِّينَ [39:11]

Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu ní ti olùṣe-àfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.

### الآية 39:12

> ﻿وَأُمِرْتُ لِأَنْ أَكُونَ أَوَّلَ الْمُسْلِمِينَ [39:12]

Wọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)." 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.

### الآية 39:13

> ﻿قُلْ إِنِّي أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّي عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ [39:13]

Sọ pé: "Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi."

### الآية 39:14

> ﻿قُلِ اللَّهَ أَعْبُدُ مُخْلِصًا لَهُ دِينِي [39:14]

Sọ pé: "Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún (mo máa jẹ́) olùṣe-àfọ̀mọ́-ẹ̀sìn mi fún Un.

### الآية 39:15

> ﻿فَاعْبُدُوا مَا شِئْتُمْ مِنْ دُونِهِ ۗ قُلْ إِنَّ الْخَاسِرِينَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ أَلَا ذَٰلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ [39:15]

Nítorí náà, kí ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn lófò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé."

### الآية 39:16

> ﻿لَهُمْ مِنْ فَوْقِهِمْ ظُلَلٌ مِنَ النَّارِ وَمِنْ تَحْتِهِمْ ظُلَلٌ ۚ ذَٰلِكَ يُخَوِّفُ اللَّهُ بِهِ عِبَادَهُ ۚ يَا عِبَادِ فَاتَّقُونِ [39:16]

Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi."

### الآية 39:17

> ﻿وَالَّذِينَ اجْتَنَبُوا الطَّاغُوتَ أَنْ يَعْبُدُوهَا وَأَنَابُوا إِلَى اللَّهِ لَهُمُ الْبُشْرَىٰ ۚ فَبَشِّرْ عِبَادِ [39:17]

Àwọn tí wọ́n yàgò fún àwọn òrìṣà láti jọ́sìn fún un, wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú.

### الآية 39:18

> ﻿الَّذِينَ يَسْتَمِعُونَ الْقَوْلَ فَيَتَّبِعُونَ أَحْسَنَهُ ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ هَدَاهُمُ اللَّهُ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمْ أُولُو الْأَلْبَابِ [39:18]

Àwọn t’ó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí t’ó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè.

### الآية 39:19

> ﻿أَفَمَنْ حَقَّ عَلَيْهِ كَلِمَةُ الْعَذَابِ أَفَأَنْتَ تُنْقِذُ مَنْ فِي النَّارِ [39:19]

Ṣé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l’ó máa la ẹni t’ó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni?

### الآية 39:20

> ﻿لَٰكِنِ الَّذِينَ اتَّقَوْا رَبَّهُمْ لَهُمْ غُرَفٌ مِنْ فَوْقِهَا غُرَفٌ مَبْنِيَّةٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَعْدَ اللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللَّهُ الْمِيعَادَ [39:20]

Ṣùgbọ́n àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà.

### الآية 39:21

> ﻿أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَسَلَكَهُ يَنَابِيعَ فِي الْأَرْضِ ثُمَّ يُخْرِجُ بِهِ زَرْعًا مُخْتَلِفًا أَلْوَانُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَجْعَلُهُ حُطَامًا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ [39:21]

Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà bọ́ sínú àwọn òpópónà odò nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.

### الآية 39:22

> ﻿أَفَمَنْ شَرَحَ اللَّهُ صَدْرَهُ لِلْإِسْلَامِ فَهُوَ عَلَىٰ نُورٍ مِنْ رَبِّهِ ۚ فَوَيْلٌ لِلْقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمْ مِنْ ذِكْرِ اللَّهِ ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [39:22]

Ǹjẹ́ ẹni tí Allāhu gba ọkàn rẹ̀ láàyè fún ẹ̀sìn ’Islām, tí ó sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (dà bí aláìgbàgbọ́ bí)? Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọn le sí ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

### الآية 39:23

> ﻿اللَّهُ نَزَّلَ أَحْسَنَ الْحَدِيثِ كِتَابًا مُتَشَابِهًا مَثَانِيَ تَقْشَعِرُّ مِنْهُ جُلُودُ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ ثُمَّ تَلِينُ جُلُودُهُمْ وَقُلُوبُهُمْ إِلَىٰ ذِكْرِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُدَى اللَّهِ يَهْدِي بِهِ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ [39:23]

Allāhu l’Ó sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára jùlọ kalẹ̀, (ó jẹ́) Tírà, tí (àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀) jọra wọn ní ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ, tí awọ ara àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn yó sì máa wárìrì nítorí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, awọ ara wọn àti ọkàn wọn yóò máa rọ̀ níbi ìrántí Allāhu. Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sí níí sí afinimọ̀nà kan fún un.

### الآية 39:24

> ﻿أَفَمَنْ يَتَّقِي بِوَجْهِهِ سُوءَ الْعَذَابِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ وَقِيلَ لِلظَّالِمِينَ ذُوقُوا مَا كُنْتُمْ تَكْسِبُونَ [39:24]

Ǹjẹ́ ẹni tí ó máa fojú ara rẹ̀ ko aburú ìyà Iná ní Ọjọ́ Àjíǹde (dà bí ẹni tí ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ́ọ́rọ́wọ́)? Wọn yó sì sọ fún àwọn alábòsí pé: "Ẹ tọ́ ìyà ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò."

### الآية 39:25

> ﻿كَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ فَأَتَاهُمُ الْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ [39:25]

Àwọn t’ó ṣíwájú wọn pe òdodo nírọ́. Nítorí náà, ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.

### الآية 39:26

> ﻿فَأَذَاقَهُمُ اللَّهُ الْخِزْيَ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ [39:26]

Allāhu fún wọn ní àbùkù ìyà tọ́ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.

### الآية 39:27

> ﻿وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِنْ كُلِّ مَثَلٍ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ [39:27]

A sì ti ṣe gbogbo àkàwé fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

### الآية 39:28

> ﻿قُرْآنًا عَرَبِيًّا غَيْرَ ذِي عِوَجٍ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ [39:28]

Al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá, èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò dojú rú (l’A sọ̀kalẹ̀) nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).

### الآية 39:29

> ﻿ضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا رَجُلًا فِيهِ شُرَكَاءُ مُتَشَاكِسُونَ وَرَجُلًا سَلَمًا لِرَجُلٍ هَلْ يَسْتَوِيَانِ مَثَلًا ۚ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [39:29]

Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀; ẹrúkùnrin kan t’ó wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gá púpọ̀ tí wọ́n ń fà á kiri (kò sì mọ ta ni ó máa dá lóhùn nínú àwọn ọ̀gá rẹ̀) àti (àkàwé) ẹrúkùnrin kan t’ó dá wà gédégbé lábẹ́ ọ̀gákùnrin kan. Ǹjẹ́ àwọn (ẹrú) méjèèjì dọ́gba ní àkàwé bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

### الآية 39:30

> ﻿إِنَّكَ مَيِّتٌ وَإِنَّهُمْ مَيِّتُونَ [39:30]

Dájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú.

### الآية 39:31

> ﻿ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عِنْدَ رَبِّكُمْ تَخْتَصِمُونَ [39:31]

Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

### الآية 39:32

> ﻿۞ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ كَذَبَ عَلَى اللَّهِ وَكَذَّبَ بِالصِّدْقِ إِذْ جَاءَهُ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِلْكَافِرِينَ [39:32]

Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó parọ́ mọ́ Allāhu, t’ó tún pe òdodo nírọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé kì í ṣe Iná ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?

### الآية 39:33

> ﻿وَالَّذِي جَاءَ بِالصِّدْقِ وَصَدَّقَ بِهِ ۙ أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُتَّقُونَ [39:33]

Ẹni tí ó sì mú òdodo wá (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) àti (àwọn) ẹni t’ó gbà á gbọ́ ní òdodo; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùbẹ̀rù (Allāhu).

### الآية 39:34

> ﻿لَهُمْ مَا يَشَاءُونَ عِنْدَ رَبِّهِمْ ۚ ذَٰلِكَ جَزَاءُ الْمُحْسِنِينَ [39:34]

Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn ẹni rere

### الآية 39:35

> ﻿لِيُكَفِّرَ اللَّهُ عَنْهُمْ أَسْوَأَ الَّذِي عَمِلُوا وَيَجْزِيَهُمْ أَجْرَهُمْ بِأَحْسَنِ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ [39:35]

nítorí kí Allāhu lè bá wọn pa aburú tí wọ́n ṣe rẹ́ àti (nítorí) kí Ó lè fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn.

### الآية 39:36

> ﻿أَلَيْسَ اللَّهُ بِكَافٍ عَبْدَهُ ۖ وَيُخَوِّفُونَكَ بِالَّذِينَ مِنْ دُونِهِ ۚ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ [39:36]

Ṣé Allāhu kò tó fún ẹrúsìn Rẹ̀ ni? Wọ́n sì ń fi àwọn ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́! Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.

### الآية 39:37

> ﻿وَمَنْ يَهْدِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ مُضِلٍّ ۗ أَلَيْسَ اللَّهُ بِعَزِيزٍ ذِي انْتِقَامٍ [39:37]

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), kò lè sí aṣinilọ́nà fún un. Ṣé Allāhu kọ́ ni Alágbára, Olùgba-ẹ̀san?

### الآية 39:38

> ﻿وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ مَنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۚ قُلْ أَفَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ أَرَادَنِيَ اللَّهُ بِضُرٍّ هَلْ هُنَّ كَاشِفَاتُ ضُرِّهِ أَوْ أَرَادَنِي بِرَحْمَةٍ هَلْ هُنَّ مُمْسِكَاتُ رَحْمَتِهِ ۚ قُلْ حَسْبِيَ اللَّهُ ۖ عَلَيْهِ يَتَوَكَّلُ الْمُتَوَكِّلُونَ [39:38]

Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, tí Allāhu bá gbèrò ìnira kan rò mí, ǹjẹ́ wọ́n lè mú ìnira Rẹ̀ kúrò fún mi? Tàbí tí Ó bá gbèrò ìkẹ́ kan sí mi, ǹjẹ́ wọ́n lè dá ìkẹ́ Rẹ̀ dúró bí?" Sọ pé: "Allāhu tó fún mi. Òun sì ni àwọn olùgbáralé ń gbáralé."

### الآية 39:39

> ﻿قُلْ يَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ [39:39]

Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣe tiyín ní àyè yín. Èmi náà ń ṣe tèmi. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ

### الآية 39:40

> ﻿مَنْ يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُقِيمٌ [39:40]

ẹni tí ìyà tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀ máa dé bá, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí."

### الآية 39:41

> ﻿إِنَّا أَنْزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ لِلنَّاسِ بِالْحَقِّ ۖ فَمَنِ اهْتَدَىٰ فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۖ وَمَا أَنْتَ عَلَيْهِمْ بِوَكِيلٍ [39:41]

Dájúdájú Àwa sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo (kí o lè fi ṣe ìrántí) fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.

### الآية 39:42

> ﻿اللَّهُ يَتَوَفَّى الْأَنْفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا ۖ فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَىٰ عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الْأُخْرَىٰ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ [39:42]

Allāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀.

### الآية 39:43

> ﻿أَمِ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِ اللَّهِ شُفَعَاءَ ۚ قُلْ أَوَلَوْ كَانُوا لَا يَمْلِكُونَ شَيْئًا وَلَا يَعْقِلُونَ [39:43]

Tàbí wọ́n mú àwọn olùṣìpẹ̀ mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: "(Wọ́n mú wọn ní olùṣìpẹ̀) t’ó sì jẹ́ pé wọn kò ní agbára kan kan, wọn kò sì níí làákàyè!"

### الآية 39:44

> ﻿قُلْ لِلَّهِ الشَّفَاعَةُ جَمِيعًا ۖ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [39:44]

Sọ pé: "Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá. TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí."

### الآية 39:45

> ﻿وَإِذَا ذُكِرَ اللَّهُ وَحْدَهُ اشْمَأَزَّتْ قُلُوبُ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ ۖ وَإِذَا ذُكِرَ الَّذِينَ مِنْ دُونِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ [39:45]

Nígbà tí wọ́n bá dárúkọ Allāhu nìkan ṣoṣo, ọkàn àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa sá kúrò (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Nígbà tí wọ́n bá sì dárúkọ àwọn mìíràn (tí wọ́n ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa dunnú.

### الآية 39:46

> ﻿قُلِ اللَّهُمَّ فَاطِرَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ عَالِمَ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ أَنْتَ تَحْكُمُ بَيْنَ عِبَادِكَ فِي مَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ [39:46]

Sọ pé: "Allāhu, Olúpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Ìwọ l’O máa dájọ́ láààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí."

### الآية 39:47

> ﻿وَلَوْ أَنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُ مَعَهُ لَافْتَدَوْا بِهِ مِنْ سُوءِ الْعَذَابِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ وَبَدَا لَهُمْ مِنَ اللَّهِ مَا لَمْ يَكُونُوا يَحْتَسِبُونَ [39:47]

Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú gbogbo n̄ǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ ti àwọn alábòsí àti irú rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ (tún jẹ́ tiwọn ni), wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn) níbi aburú ìyà ní Ọjọ́ Àjíǹde. (Nígbà yẹn) ohun tí wọn kò lérò máa hàn sí wọn ní ọ̀dọ̀ Allāhu;

### الآية 39:48

> ﻿وَبَدَا لَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا وَحَاقَ بِهِمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ [39:48]

Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ máa hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po.

### الآية 39:49

> ﻿فَإِذَا مَسَّ الْإِنْسَانَ ضُرٌّ دَعَانَا ثُمَّ إِذَا خَوَّلْنَاهُ نِعْمَةً مِنَّا قَالَ إِنَّمَا أُوتِيتُهُ عَلَىٰ عِلْمٍ ۚ بَلْ هِيَ فِتْنَةٌ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [39:49]

Nígbà tí ìnira kan ba fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pè Wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí A bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa wí pé: "Wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ ni." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, àdánwò ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, òun mọ̀ ọ́n ṣe ni tòun fi gún. Dípò kí ó moore sí Allāhu, kí ó dúpẹ́ fún Un, kí ó sì mọ̀ pé Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá Rẹ̀.

### الآية 39:50

> ﻿قَدْ قَالَهَا الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [39:50]

Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú wí (irú) rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

### الآية 39:51

> ﻿فَأَصَابَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا ۚ وَالَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْ هَٰؤُلَاءِ سَيُصِيبُهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا وَمَا هُمْ بِمُعْجِزِينَ [39:51]

Aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì bá wọn. Àwọn alábòsí nínú àwọn wọ̀nyí náà, aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ yóò bá wọn. Wọn kò sì níí mórí bọ́.

### الآية 39:52

> ﻿أَوَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ [39:52]

Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 39:53

> ﻿۞ قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ لَا تَقْنَطُوا مِنْ رَحْمَةِ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعًا ۚ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ [39:53]

Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 39:54

> ﻿وَأَنِيبُوا إِلَىٰ رَبِّكُمْ وَأَسْلِمُوا لَهُ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَكُمُ الْعَذَابُ ثُمَّ لَا تُنْصَرُونَ [39:54]

Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà t’ó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.

### الآية 39:55

> ﻿وَاتَّبِعُوا أَحْسَنَ مَا أُنْزِلَ إِلَيْكُمْ مِنْ رَبِّكُمْ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَكُمُ الْعَذَابُ بَغْتَةً وَأَنْتُمْ لَا تَشْعُرُونَ [39:55]

Kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura.

### الآية 39:56

> ﻿أَنْ تَقُولَ نَفْسٌ يَا حَسْرَتَا عَلَىٰ مَا فَرَّطْتُ فِي جَنْبِ اللَّهِ وَإِنْ كُنْتُ لَمِنَ السَّاخِرِينَ [39:56]

Nítorí kí ẹ̀mí kan má baà wí pé: "Mo ká àbámọ̀ lórí bí mo ṣe jáfara lórí àìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Àti pé èmi wà nínú àwọn t’ó ń fi (ọ̀rọ̀ Rẹ̀) ṣe yẹ̀yẹ́."

### الآية 39:57

> ﻿أَوْ تَقُولَ لَوْ أَنَّ اللَّهَ هَدَانِي لَكُنْتُ مِنَ الْمُتَّقِينَ [39:57]

Tàbí kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fi ọ̀nà mọ̀ mí ni, dájúdájú èmi ìbá wà nínú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)."

### الآية 39:58

> ﻿أَوْ تَقُولَ حِينَ تَرَى الْعَذَابَ لَوْ أَنَّ لِي كَرَّةً فَأَكُونَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ [39:58]

Tàbí nígbà tí ó bá rí Iná kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé ìpadàsáyé wà fún mi ni, èmi ìbá sì wà nínú àwọn olùṣe-rere."

### الآية 39:59

> ﻿بَلَىٰ قَدْ جَاءَتْكَ آيَاتِي فَكَذَّبْتَ بِهَا وَاسْتَكْبَرْتَ وَكُنْتَ مِنَ الْكَافِرِينَ [39:59]

Rárá o! Àwọn āyah Mi kúkú ti dé bá ọ. O pè é nírọ́. O tún ṣègbéraga. O sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (58 àti 59) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:99-100.

### الآية 39:60

> ﻿وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ تَرَى الَّذِينَ كَذَبُوا عَلَى اللَّهِ وُجُوهُهُمْ مُسْوَدَّةٌ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِلْمُتَكَبِّرِينَ [39:60]

Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí àwọn t’ó parọ́ mọ́ Allāhu tí ojú wọn máa dúdú. Ṣé inú iná Jahnamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn onígbèéraga ni?

### الآية 39:61

> ﻿وَيُنَجِّي اللَّهُ الَّذِينَ اتَّقَوْا بِمَفَازَتِهِمْ لَا يَمَسُّهُمُ السُّوءُ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ [39:61]

Allāhu yóò gba àwọn t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) là sínú ilé ìgbàlà wọn (ìyẹn, Ọgbà Ìdẹ̀ra). Aburú kò níí fọwọ́ bà wọ́n. Wọn kò sì níí banújẹ́.

### الآية 39:62

> ﻿اللَّهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ [39:62]

Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 39:63

> ﻿لَهُ مَقَالِيدُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ [39:63]

TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ àpótí-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.

### الآية 39:64

> ﻿قُلْ أَفَغَيْرَ اللَّهِ تَأْمُرُونِّي أَعْبُدُ أَيُّهَا الْجَاهِلُونَ [39:64]

Sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan mìíràn yàtọ̀ sí Allāhu l’ẹ̀ ń pa mí lásẹ pé kí n̄g máa jọ́sìn fún, ẹ̀yin aláìmọ̀kan?

### الآية 39:65

> ﻿وَلَقَدْ أُوحِيَ إِلَيْكَ وَإِلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكَ لَئِنْ أَشْرَكْتَ لَيَحْبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ الْخَاسِرِينَ [39:65]

Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ (pé) "Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò."

### الآية 39:66

> ﻿بَلِ اللَّهَ فَاعْبُدْ وَكُنْ مِنَ الشَّاكِرِينَ [39:66]

Rárá (má ṣẹbọ). Allāhu nìkan ni kí o jọ́sìn fún. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un).

### الآية 39:67

> ﻿وَمَا قَدَرُوا اللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِ وَالْأَرْضُ جَمِيعًا قَبْضَتُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَالسَّمَاوَاتُ مَطْوِيَّاتٌ بِيَمِينِهِ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ [39:67]

Wọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

### الآية 39:68

> ﻿وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَصَعِقَ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ إِلَّا مَنْ شَاءَ اللَّهُ ۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخْرَىٰ فَإِذَا هُمْ قِيَامٌ يَنْظُرُونَ [39:68]

Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún ikú. Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn.

### الآية 39:69

> ﻿وَأَشْرَقَتِ الْأَرْضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ الْكِتَابُ وَجِيءَ بِالنَّبِيِّينَ وَالشُّهَدَاءِ وَقُضِيَ بَيْنَهُمْ بِالْحَقِّ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ [39:69]

Àti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A ó sì ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú òdodo. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

### الآية 39:70

> ﻿وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَا عَمِلَتْ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَا يَفْعَلُونَ [39:70]

Àti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 39:71

> ﻿وَسِيقَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا فُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ رُسُلٌ مِنْكُمْ يَتْلُونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِ رَبِّكُمْ وَيُنْذِرُونَكُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَلَٰكِنْ حَقَّتْ كَلِمَةُ الْعَذَابِ عَلَى الْكَافِرِينَ [39:71]

Wọn yó sì da àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahnamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fun yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fun yín?" Wọ́n wí pé: "Rárá (wọ́n wá bá wa)." Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni.

### الآية 39:72

> ﻿قِيلَ ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ [39:72]

A óò sọ pé: "Ẹ wọ ẹnu ọ̀nà iná Jahnamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn olùṣègbéraga sì burú.

### الآية 39:73

> ﻿وَسِيقَ الَّذِينَ اتَّقَوْا رَبَّهُمْ إِلَى الْجَنَّةِ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا وَفُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا سَلَامٌ عَلَيْكُمْ طِبْتُمْ فَادْخُلُوهَا خَالِدِينَ [39:73]

Àti pé A óò kó àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Ẹ̀yin ṣe iṣẹ́ t’ó dára. Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére (nínú rẹ̀)." 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni tún lérò pé āyah wọ̀nyí, āyah 71 títí dé āyah 73, tako sūrah Mọryam; 19:71. Èsì rẹ̀ ti wà nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 71 yẹn nínú sūrah Mọryam.

### الآية 39:74

> ﻿وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي صَدَقَنَا وَعْدَهُ وَأَوْرَثَنَا الْأَرْضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ الْجَنَّةِ حَيْثُ نَشَاءُ ۖ فَنِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِينَ [39:74]

Wọ́n á sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára."

### الآية 39:75

> ﻿وَتَرَى الْمَلَائِكَةَ حَافِّينَ مِنْ حَوْلِ الْعَرْشِ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ ۖ وَقُضِيَ بَيْنَهُمْ بِالْحَقِّ وَقِيلَ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ [39:75]

O máa sì rí àwọn Mọlāika tí wọ́n ń rọkiriká ní ẹ̀gbẹ́ Ìtẹ́-ọlá. Wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin àwọn ẹ̀dá. Wọ́n sì máa sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá."

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/39.md)
- [كل تفاسير سورة الزمر
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/39.md)
- [ترجمات سورة الزمر
](https://quranpedia.net/translations/39.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/39/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
