---
title: "ترجمة سورة فصّلت - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/41/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/41/book/2001"
surah_id: "41"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة فصّلت - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/41/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة فصّلت - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/41/book/2001*.

Translation of Surah فصّلت from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 41:1

> حم [41:1]

Hā mīm.

### الآية 41:2

> ﻿تَنْزِيلٌ مِنَ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ [41:2]

Ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí kan (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 41:3

> ﻿كِتَابٌ فُصِّلَتْ آيَاتُهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ [41:3]

(Èyí ni) Tírà kan tí Wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀; al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá ni fún ìjọ t’ó nímọ̀.

### الآية 41:4

> ﻿بَشِيرًا وَنَذِيرًا فَأَعْرَضَ أَكْثَرُهُمْ فَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ [41:4]

(Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i.

### الآية 41:5

> ﻿وَقَالُوا قُلُوبُنَا فِي أَكِنَّةٍ مِمَّا تَدْعُونَا إِلَيْهِ وَفِي آذَانِنَا وَقْرٌ وَمِنْ بَيْنِنَا وَبَيْنِكَ حِجَابٌ فَاعْمَلْ إِنَّنَا عَامِلُونَ [41:5]

Wọ́n sì wí pé: "Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa."

### الآية 41:6

> ﻿قُلْ إِنَّمَا أَنَا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ فَاسْتَقِيمُوا إِلَيْهِ وَاسْتَغْفِرُوهُ ۗ وَوَيْلٌ لِلْمُشْرِكِينَ [41:6]

Sọ pé: "Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í, kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ,

### الآية 41:7

> ﻿الَّذِينَ لَا يُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُمْ بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ [41:7]

àwọn tí kò yọ Zakāh. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

### الآية 41:8

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ [41:8]

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín ń bẹ fún wọn.

### الآية 41:9

> ﻿۞ قُلْ أَئِنَّكُمْ لَتَكْفُرُونَ بِالَّذِي خَلَقَ الْأَرْضَ فِي يَوْمَيْنِ وَتَجْعَلُونَ لَهُ أَنْدَادًا ۚ ذَٰلِكَ رَبُّ الْعَالَمِينَ [41:9]

Sọ pé: "Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ fún Un?" Ìyẹn sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 41:10

> ﻿وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ مِنْ فَوْقِهَا وَبَارَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَا أَقْوَاتَهَا فِي أَرْبَعَةِ أَيَّامٍ سَوَاءً لِلسَّائِلِينَ [41:10]

Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin. (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀). 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni lérò pé āyah yìí tako àwọn āyah t’ó ń fi ọjọ́ mẹ́fà rinlẹ̀ fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Wọ́n ni āyah yìí pè é ní ọjọ́ mẹ́jọ, àwọn āyah yòókù pè é ní ọjọ́ mẹ́fà. Àwọn kristiẹni tún sọ pé, yálà ọjọ́ mẹ́fà tàbí ọjọ́ mẹ́jọ, ìkíní kejì tún tako àwọn āyah kunfayakūn t’ó wà nínú al-Ƙur’ān. Wọ́n ní, “Kò wulẹ̀ yẹ kí Allāhu lo ọjọ́ mẹ́fà tàbí ọjọ́ mẹ́jọ kan kan mọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé Ó ti sọ nínú al-Ƙur’ān pé nígbà tí Òun bá gbèrò láti ṣẹ̀dá n̄ǹkan, gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀-ó-sì-máa-jẹ́-bẹ́ẹ̀” ni Òun máa ń sọ.” 
Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni èyí. Kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé ọ̀rọ̀ nìyí. Ní ti òǹkà ọjọ́ fún ìṣẹ̀dá sánmọ̀ àti ilẹ̀, àyè mẹ́jọ ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ní àyè mẹ́rin nínú wọn, ó jẹyọ nínú wọn pé, “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:54, sūrah Yūnus; 10:3, sūrah Hūd; 11:7 àti sūrah al-Hadīd; 57:4. Ní àyè mẹ́ta nínú wọn, ó jẹyọ nínú wọn pé, “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Furƙọ̄n; 25:59, sūrah as-Sajdah; 32:4 àti sūrah Ƙọ̄f; 50:38. Kíyè sí awẹ́ gbólóhùn “àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì”. Ìyẹn ti fi hàn pé, ọjọ́ méjì ni Allāhu lò fún ìṣẹ̀dá sánmọ̀ méje, ọjọ́ méjì fún ìṣẹ̀dá ilẹ̀ méje, ọjọ́ méjì fún ìṣẹ̀da ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì sì ń túmọ̀ sí gbogbo ohun t’ó wà lórí ilẹ̀. Èyí tí já sí pé, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà lórí ilẹ̀ kó ọjọ́ mẹ́rin nínú ọjọ́ mẹ́fà. Àtúpalẹ̀ ìṣírò yìí ni Allāhu fún ara Rẹ̀ fi rinlẹ̀ nínú āyah tí à ń ṣe ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún yìí, sūrah Fussilat 41; 9-10. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ èdè Lárúbáwá àti àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām fi ṣàlàyé āyah 10 pé ọjọ́ mẹ́rin yẹn kó ọjọ́ méjì tí Allāhu dárúkọ nínú āyah 9 sínú. Wọ́n ní àpapọ̀ ọjọ́ ìṣẹ̀dá ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ ni òǹkà ọjọ́ mẹ́rin náà dúró fún, kì í ṣe fún ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ nìkan, gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn àwọn aláìnímọ̀ nípa ìlò èdè Lárúbáwá. Irúfẹ́ ìṣírò yìí l’ó tún jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 àti Fātir; 35:1. Ní ti gbólóhùn “kunfayakūn” tí í ṣe “Jẹ́ bẹ́ẹ̀-ó-sì-máa-jẹ́-bẹ́ẹ̀”, kò rújú rárá pé, Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ t’òhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Allāhu kì í ṣe n̄ǹkan pẹ̀lú ìkánjú. Àti pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí ṣe ìṣe kan tí ó máa mú kí ìtakora ṣẹlẹ̀ láààrin àwọn orúkọ Rẹ̀ t’ó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn Rẹ̀ t’ó ga jùlọ. Ẹ̀dá l’ó lè jẹ́ alágbára-mámèrò, kì í ṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó wà lábẹ́ lílo òǹkà ọjọ́ mẹ́fà fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run. 
Ipò tí gbólóhùn “kunfayakūn” wà nínú ìṣẹ̀dá ni ipò ìparí ọ̀rọ̀ àti àṣẹ dídi bíbẹ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn ìkójọ èròjà ìṣẹ̀dá, n̄ǹkan náà kò níí dòhun àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. Àwọn ẹ̀dá tí kò bá sì jẹmọ́ èròjà ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ nípa èròjà ìṣẹ̀dá wọn fún wa, Allāhu l’Ó kúkú nímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, ìkíní kejì kò níí di ẹ̀dá àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. 
Pẹ̀lú àlàyé yìí, ó ń túmọ̀ sí pé, àwọn ẹ̀dá kan di ẹ̀dá pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” nìkan. Àwọn ẹ̀dá kan sì di ẹ̀dá nípasẹ̀ èròjà ìṣẹ̀dá àti gbólóhùn “kunfayakūn”. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀nà tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, gbólóhùn “kunfayakūn” t’ó jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoṣo kò lè sọ Allāhu di olùkánjú. Ìkánjú kì í ṣe ìròyìn rere fún Allāhu. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”, bẹ́ẹ̀ náà l’Ó ṣe gbàròyìn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, èyí tí í ṣe ìdà kejì ìkánjú. Nítorí náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lágbára láti ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run láààrin ohun tí ó kéré jùlọ sí ìṣẹ́jú kan. Bí Ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò kúkú sí ẹni tí Ó lè pè É lẹ́jọ́. Bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá sì lo ọjọ́ mẹ́fà fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àṣẹ “Jẹ́-bẹ́ẹ̀” kò jẹ́ tiRẹ̀. Òun l’Ó kúkú ni gbogbo ìjọba, gbogbo agbára àti gbogbo ògo.

### الآية 41:11

> ﻿ثُمَّ اسْتَوَىٰ إِلَى السَّمَاءِ وَهِيَ دُخَانٌ فَقَالَ لَهَا وَلِلْأَرْضِ ائْتِيَا طَوْعًا أَوْ كَرْهًا قَالَتَا أَتَيْنَا طَائِعِينَ [41:11]

Lẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: "Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀." Àwọn méjèèjì sọ pé: "A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀." 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Anbiyā’; 21:30.

### الآية 41:12

> ﻿فَقَضَاهُنَّ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ فِي يَوْمَيْنِ وَأَوْحَىٰ فِي كُلِّ سَمَاءٍ أَمْرَهَا ۚ وَزَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَحِفْظًا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ [41:12]

Ó sì parí (ìṣẹ̀dá) rẹ̀ sí sánmọ̀ méje fún ọjọ́ méjì. Ó sì fi iṣẹ́ sánmọ̀ kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sínú rẹ̀. A sì fi àwọn àtùpà (ìràwọ̀) ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ àti ààbò (fún un). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.

### الآية 41:13

> ﻿فَإِنْ أَعْرَضُوا فَقُلْ أَنْذَرْتُكُمْ صَاعِقَةً مِثْلَ صَاعِقَةِ عَادٍ وَثَمُودَ [41:13]

Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ pé: "Èmi ń ṣèkìlọ̀ ìparun irú ìparun ìjọ ‘Ād àti Thamūd fun yín ni."

### الآية 41:14

> ﻿إِذْ جَاءَتْهُمُ الرُّسُلُ مِنْ بَيْنِ أَيْدِيهِمْ وَمِنْ خَلْفِهِمْ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ ۖ قَالُوا لَوْ شَاءَ رَبُّنَا لَأَنْزَلَ مَلَائِكَةً فَإِنَّا بِمَا أُرْسِلْتُمْ بِهِ كَافِرُونَ [41:14]

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn, (wọ́n sọ) pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu." Wọ́n wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́."
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
"níwájú wọn" túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ (ahm.s.s.) wá bá àwọn bàbá ńlá wọn, "lẹ́yìn wọn" sì túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ tún wá bá àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn lẹ́yìn ìparun àwọn bàbá ńlá wọn.

### الآية 41:15

> ﻿فَأَمَّا عَادٌ فَاسْتَكْبَرُوا فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَقَالُوا مَنْ أَشَدُّ مِنَّا قُوَّةً ۖ أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَهُمْ هُوَ أَشَدُّ مِنْهُمْ قُوَّةً ۖ وَكَانُوا بِآيَاتِنَا يَجْحَدُونَ [41:15]

Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: "Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?" Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni. Wọ́n sì ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Wa!

### الآية 41:16

> ﻿فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِي أَيَّامٍ نَحِسَاتٍ لِنُذِيقَهُمْ عَذَابَ الْخِزْيِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَخْزَىٰ ۖ وَهُمْ لَا يُنْصَرُونَ [41:16]

Nítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:19, Allāhu dárúkọ ọjọ́ kan fún ìparun ìjọ ‘Ād. Àmọ́ nínú sūrah al-Hāƙƙọh; 69:7, Allāhu dárúkọ òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ fún ìparun wọn. Nínú sūrah Fussilat; 41:16, Allāhu dárúkọ àwọn ọjọ́? Wọ́n ní, “Nítorí náà, ìtakora ti jẹyọ lórí òǹkà ọjọ́ ti Allāhu fi pa ìjọ ‘Ād run! 
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà. Àlàyé rẹ̀ nìyí, āyah ti sūrah al-Ƙọmọr t’ó pè é ní ọjọ́ kan sọ pé “ọjọ́ burúkú kan t’ó ń tẹ̀ síwájú.” Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé, àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú aláìmọ̀kan.

### الآية 41:17

> ﻿وَأَمَّا ثَمُودُ فَهَدَيْنَاهُمْ فَاسْتَحَبُّوا الْعَمَىٰ عَلَى الْهُدَىٰ فَأَخَذَتْهُمْ صَاعِقَةُ الْعَذَابِ الْهُونِ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [41:17]

Ní ti ìjọ Thamūd, A ṣàlàyé ìmọ̀nà fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àìríran dípò ìmọ̀nà. Nítorí náà, igbe ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá gbá wọn mú nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn nípasẹ̀ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí wọn.

### الآية 41:18

> ﻿وَنَجَّيْنَا الَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ [41:18]

A sì gba àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu) là.

### الآية 41:19

> ﻿وَيَوْمَ يُحْشَرُ أَعْدَاءُ اللَّهِ إِلَى النَّارِ فَهُمْ يُوزَعُونَ [41:19]

Ní ọjọ́ tí wọ́n máa kó àwọn ọ̀tá Allāhu jọ síbi Iná, wọn yó sì kó àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn papọ̀ mọ́ àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn

### الآية 41:20

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا مَا جَاءُوهَا شَهِدَ عَلَيْهِمْ سَمْعُهُمْ وَأَبْصَارُهُمْ وَجُلُودُهُمْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [41:20]

títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 41:21

> ﻿وَقَالُوا لِجُلُودِهِمْ لِمَ شَهِدْتُمْ عَلَيْنَا ۖ قَالُوا أَنْطَقَنَا اللَّهُ الَّذِي أَنْطَقَ كُلَّ شَيْءٍ وَهُوَ خَلَقَكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ [41:21]

Wọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: "Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?" Wọ́n yóò sọ pé: "Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l’Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."

### الآية 41:22

> ﻿وَمَا كُنْتُمْ تَسْتَتِرُونَ أَنْ يَشْهَدَ عَلَيْكُمْ سَمْعُكُمْ وَلَا أَبْصَارُكُمْ وَلَا جُلُودُكُمْ وَلَٰكِنْ ظَنَنْتُمْ أَنَّ اللَّهَ لَا يَعْلَمُ كَثِيرًا مِمَّا تَعْمَلُونَ [41:22]

Ẹ̀yin kò lè para yín mọ́ (kúrò níbi ẹ̀ṣẹ̀, nítorí) kí ìgbọ́rọ̀ yín, ìríran yín àti awọ ara yín má fi lè jẹ́rìí le yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ lérò pé dájúdájú Allāhu kò mọ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 41:23

> ﻿وَذَٰلِكُمْ ظَنُّكُمُ الَّذِي ظَنَنْتُمْ بِرَبِّكُمْ أَرْدَاكُمْ فَأَصْبَحْتُمْ مِنَ الْخَاسِرِينَ [41:23]

Ìyẹn, èrò yín tí ẹ lérò sí Olúwa yín ló kó ìparun ba yín. Ẹ sì di ẹni òfò.

### الآية 41:24

> ﻿فَإِنْ يَصْبِرُوا فَالنَّارُ مَثْوًى لَهُمْ ۖ وَإِنْ يَسْتَعْتِبُوا فَمَا هُمْ مِنَ الْمُعْتَبِينَ [41:24]

Tí wọ́n bá ṣe sùúrù (fún ìyà), Iná kúkú ni ibùgbé fún wọn. Tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣẹ́rí padà sí ṣíṣe ohun tí Allāhu yọ́nú sí (ní àsìkò yìí), A ò níí gbà wọ́n láyè láti ṣẹ́rí padà.

### الآية 41:25

> ﻿۞ وَقَيَّضْنَا لَهُمْ قُرَنَاءَ فَزَيَّنُوا لَهُمْ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَحَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِمْ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا خَاسِرِينَ [41:25]

Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn, tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ t’ó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò.

### الآية 41:26

> ﻿وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَسْمَعُوا لِهَٰذَا الْقُرْآنِ وَالْغَوْا فِيهِ لَعَلَّكُمْ تَغْلِبُونَ [41:26]

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Ẹ má ṣe tẹ́tí sí al-Ƙur’ān yìí. Kí ẹ sì sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀ kí ẹ lè borí."

### الآية 41:27

> ﻿فَلَنُذِيقَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا عَذَابًا شَدِيدًا وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَسْوَأَ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ [41:27]

Nítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí t’ó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san.

### الآية 41:28

> ﻿ذَٰلِكَ جَزَاءُ أَعْدَاءِ اللَّهِ النَّارُ ۖ لَهُمْ فِيهَا دَارُ الْخُلْدِ ۖ جَزَاءً بِمَا كَانُوا بِآيَاتِنَا يَجْحَدُونَ [41:28]

Iná, ìyẹn ni ẹ̀san àwọn ọ̀tá Allāhu. Ilé gbére wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ó jẹ́ ẹ̀san nítorí pé wọ́n ń tako àwọn āyah Wa.

### الآية 41:29

> ﻿وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا رَبَّنَا أَرِنَا اللَّذَيْنِ أَضَلَّانَا مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ نَجْعَلْهُمَا تَحْتَ أَقْدَامِنَا لِيَكُونَا مِنَ الْأَسْفَلِينَ [41:29]

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Olúwa wa, fi àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣì wá lọ́nà nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn hàn wá nítorí kí á lè fi àwọn méjèèjì sí abẹ́ gìgísẹ̀ wa, nítorí kí wọ́n lè wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá."

### الآية 41:30

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ قَالُوا رَبُّنَا اللَّهُ ثُمَّ اسْتَقَامُوا تَتَنَزَّلُ عَلَيْهِمُ الْمَلَائِكَةُ أَلَّا تَخَافُوا وَلَا تَحْزَنُوا وَأَبْشِرُوا بِالْجَنَّةِ الَّتِي كُنْتُمْ تُوعَدُونَ [41:30]

Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa." lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín.

### الآية 41:31

> ﻿نَحْنُ أَوْلِيَاؤُكُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۖ وَلَكُمْ فِيهَا مَا تَشْتَهِي أَنْفُسُكُمْ وَلَكُمْ فِيهَا مَا تَدَّعُونَ [41:31]

Àwa ni ọ̀rẹ́ yín nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní ọ̀run. Ohun tí ẹ̀mí yín ń fẹ́ ti wà fun yín nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún sì ti wà nínú rẹ̀.

### الآية 41:32

> ﻿نُزُلًا مِنْ غَفُورٍ رَحِيمٍ [41:32]

N̄ǹkan ìgbàlejò ni láti ọ̀dọ̀ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

### الآية 41:33

> ﻿وَمَنْ أَحْسَنُ قَوْلًا مِمَّنْ دَعَا إِلَى اللَّهِ وَعَمِلَ صَالِحًا وَقَالَ إِنَّنِي مِنَ الْمُسْلِمِينَ [41:33]

Ta ni ó dára jùlọ ní ọ̀rọ̀ sísọ t’ó tayọ ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí."

### الآية 41:34

> ﻿وَلَا تَسْتَوِي الْحَسَنَةُ وَلَا السَّيِّئَةُ ۚ ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ فَإِذَا الَّذِي بَيْنَكَ وَبَيْنَهُ عَدَاوَةٌ كَأَنَّهُ وَلِيٌّ حَمِيمٌ [41:34]

Rere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú). Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Fífi rere dènà aburú ni ṣíṣe sùúrù pẹ̀lú ẹni tí ó ń bínú sí wa, ṣíṣe rere sí ẹni tí ó ń ṣe aburú sí wa, kíkí ẹni tí ó ń yàn wá lódì, ṣíṣe àtẹ̀mọ́ra pẹ̀lú ẹni tí ó ń hùwà àìmọ̀kan sí wa, wíwo ẹni tí ó ń ṣépè fún wa níran, wíwo ẹni tí ó ń bú wa níran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwọ̀nyí ni kí mùsùlùmí fi ṣẹwà nítorí kí àwa náa má baà di ẹni aburú àti nítorí kí èṣù má baà rí wa lò.

### الآية 41:35

> ﻿وَمَا يُلَقَّاهَا إِلَّا الَّذِينَ صَبَرُوا وَمَا يُلَقَّاهَا إِلَّا ذُو حَظٍّ عَظِيمٍ [41:35]

A ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn t’ó ṣe sùúrù. A ò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá.

### الآية 41:36

> ﻿وَإِمَّا يَنْزَغَنَّكَ مِنَ الشَّيْطَانِ نَزْغٌ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ ۖ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ [41:36]

Àti pé tí èròkérò kan láti ọ̀dọ̀ Èṣù bá fẹ́ ṣẹ́ ọ lórí (kúrò níbi ìwà rere yìí), sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 41:37

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ ۚ لَا تَسْجُدُوا لِلشَّمْسِ وَلَا لِلْقَمَرِ وَاسْجُدُوا لِلَّهِ الَّذِي خَلَقَهُنَّ إِنْ كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ [41:37]

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ ò gbọdọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni t’ó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo.

### الآية 41:38

> ﻿فَإِنِ اسْتَكْبَرُوا فَالَّذِينَ عِنْدَ رَبِّكَ يُسَبِّحُونَ لَهُ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَهُمْ لَا يَسْأَمُونَ ۩ [41:38]

Tí wọ́n bá sì ṣègbéraga, àwọn t’ó wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní alẹ́ àti ní ọ̀sán; wọn kò sì kágara.

### الآية 41:39

> ﻿وَمِنْ آيَاتِهِ أَنَّكَ تَرَى الْأَرْضَ خَاشِعَةً فَإِذَا أَنْزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ ۚ إِنَّ الَّذِي أَحْيَاهَا لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۚ إِنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ [41:39]

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó jí i, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 41:40

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي آيَاتِنَا لَا يَخْفَوْنَ عَلَيْنَا ۗ أَفَمَنْ يُلْقَىٰ فِي النَّارِ خَيْرٌ أَمْ مَنْ يَأْتِي آمِنًا يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ اعْمَلُوا مَا شِئْتُمْ ۖ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ [41:40]

Dájúdájú àwọn t’ó ń yẹ àwọn āyah Wa (síbi òmíràn), wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nínú yíyẹ āyah al-Ƙur’ān síbi òmíràn ni fífún āyah kan ní ìtúmọ̀ òdì, fífi āyah kan tako āyah mìíràn, lílo āyah kan ní àyè tí kò jẹmọ́ ọn, fífi āyah kan ṣe ẹ̀fẹ̀, ṣíṣe àtakò sí āyah kan, pípa ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān tì láti tẹ̀lé ìròrí, ìṣe àti àṣà ìgbà-àìmọ̀kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ṣókí, ẹni t’ó ń yẹ āyah al-Ƙur’ān síbi òmíràn ni ẹni tí kò tẹ̀lé àwọn äyah al-Ƙur’ān ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ àti ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àpẹẹrẹ igun kìíní ni àwọn oníbídíà bíí àwọn sūfī, àwọn Ahmadi àti àwọn oníjálàbí. Àpẹẹrẹ igun kejì ni àwọn ọ̀ṣẹbọ, àwọn kristiẹni àti àwọn yẹhudi.

### الآية 41:41

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالذِّكْرِ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّهُ لَكِتَابٌ عَزِيزٌ [41:41]

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà t’ó lágbára.

### الآية 41:42

> ﻿لَا يَأْتِيهِ الْبَاطِلُ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَلَا مِنْ خَلْفِهِ ۖ تَنْزِيلٌ مِنْ حَكِيمٍ حَمِيدٍ [41:42]

Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀. Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, kò sí tírà sánmọ̀ kan tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irọ́ wà nínú al-Ƙur’ān ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀. Kò sì níí sí tírà kan kan lẹ́yìn rẹ̀ tí ó máa pe al-Ƙur’ān nírọ́. Ní ṣókí, kò sí ẹni tí ó lè rí āyah kan pè ní irọ́ nínú al-Ƙur’ān. Èyí jẹ́ ààbò mímọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi bo al-Ƙur’ān yàtọ̀ sí àwọn tírà yòókù. Àwọn tírà yòókù, bíi Bíbélì, ni ọwọ́kọ́wọ́ ti wọ inú wọn ní ìbámú sí sūrah al-Baƙọrah; 2:75 àti 79 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Ìdí nìyí tí àjọ aláṣẹ atẹbíbélìtà “The Bible Societies” fi tú bíbélì ní àṣírí nínú ọ̀rọ̀ ìṣaájú tí wọ́n kọ fún “Revised Standard Version” pé: “Àwọn ìwé bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì wáyé láti inú ojúlówó èdè Hébérù àti èdè Greek tààrà. Títúmọ̀ ìwé bíbélì t’ó sì jẹ́ àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ni iṣẹ́ ọwọ́ William Tyndale. Ó fojú winá àtakò t’ó lágbára. Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó fínnú-fíndọ̀ dojú ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú bíbélì rú, wọ́n sì pa á láṣẹ pé kí wọ́n dáná sun àwọn májẹ̀mu titun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ “àwọn ìtúmọ̀ tí kì í ṣe òdodo”. Arákùnrin náà padà bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀, wọ́n pa á níta gban̄gba, wọ́n kangi ikú fún un, wọ́n sì dáná sun ún lórí rẹ̀ ní October 1536. Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí Tyndale ṣe ló padà di ìpìlẹ̀ ìtọ́kasí fún àwọn bíbélì tí wọ́n ń padà túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì… Àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ bíbélì ti King James Version ṣe àkíyèsí sí àwọn èyí tí wọ́n ti ṣe ṣíwájú; … Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí King James Version ṣe tún ní àléébù t’ó burú gan-an nínú. Láààrin 19 sẹ́ńtúrì, ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ bíbélì àti ṣíṣe àwárí àwọn àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ bíbélì tí ó lọ́jọ́ lórí ju èyí tí king James Version gbé iṣẹ́ ìtúmọ̀ bíbélì tirẹ̀ lé lórí, ó fi hàn kedere pé àwọn àlèébù wọ̀nyí pọ̀ púpọ̀ gan-an, wọ́n sì lágbára gan-an dé ibi pé ó bèèrè fún àtúnṣe àwọn ìtúmọ̀ tí wọ́n túmọ̀ bíbélì sí…"

### الآية 41:43

> ﻿مَا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدْ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِنْ قَبْلِكَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٍ [41:43]

Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀).

### الآية 41:44

> ﻿وَلَوْ جَعَلْنَاهُ قُرْآنًا أَعْجَمِيًّا لَقَالُوا لَوْلَا فُصِّلَتْ آيَاتُهُ ۖ أَأَعْجَمِيٌّ وَعَرَبِيٌّ ۗ قُلْ هُوَ لِلَّذِينَ آمَنُوا هُدًى وَشِفَاءٌ ۖ وَالَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ فِي آذَانِهِمْ وَقْرٌ وَهُوَ عَلَيْهِمْ عَمًى ۚ أُولَٰئِكَ يُنَادَوْنَ مِنْ مَكَانٍ بَعِيدٍ [41:44]

Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe al-Ƙur’ān ní n̄ǹkan kíké ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá ni, wọn ìbá wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n ṣe àlàyé àwọn āyah rẹ̀?" Báwo ni al-Ƙur’ān ṣe lè jẹ́ èdè mìíràn (yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá), nígbà tí Ànábì (Muhammad s.a.w.) jẹ́ Lárúbáwá? Sọ pé: "Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìwòsàn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Àwọn tí kò sì gbàgbọ́, èdídí wà nínú etí wọn. Fọ́júǹfọ́jú sì wà nínú ojú wọn sí (òdodo al-Ƙur’ān). Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n sì ń pè (síbi òdodo al-Ƙur’ān) láti àyè t’ó jìnnà. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọ nù jìnnà.

### الآية 41:45

> ﻿وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَاخْتُلِفَ فِيهِ ۗ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ مُرِيبٍ [41:45]

A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.

### الآية 41:46

> ﻿مَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا ۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ [41:46]

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn.

### الآية 41:47

> ﻿۞ إِلَيْهِ يُرَدُّ عِلْمُ السَّاعَةِ ۚ وَمَا تَخْرُجُ مِنْ ثَمَرَاتٍ مِنْ أَكْمَامِهَا وَمَا تَحْمِلُ مِنْ أُنْثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلْمِهِ ۚ وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ أَيْنَ شُرَكَائِي قَالُوا آذَنَّاكَ مَا مِنَّا مِنْ شَهِيدٍ [41:47]

Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: "Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?" Wọ́n á wí pé: "Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé O ní akẹgbẹ́.)"

### الآية 41:48

> ﻿وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَدْعُونَ مِنْ قَبْلُ ۖ وَظَنُّوا مَا لَهُمْ مِنْ مَحِيصٍ [41:48]

Ohun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé kò sí ibùsásí kan fún àwọn.

### الآية 41:49

> ﻿لَا يَسْأَمُ الْإِنْسَانُ مِنْ دُعَاءِ الْخَيْرِ وَإِنْ مَسَّهُ الشَّرُّ فَيَئُوسٌ قَنُوطٌ [41:49]

Ènìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná.

### الآية 41:50

> ﻿وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ رَحْمَةً مِنَّا مِنْ بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَا أَظُنُّ السَّاعَةَ قَائِمَةً وَلَئِنْ رُجِعْتُ إِلَىٰ رَبِّي إِنَّ لِي عِنْدَهُ لَلْحُسْنَىٰ ۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِمَا عَمِلُوا وَلَنُذِيقَنَّهُمْ مِنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ [41:50]

Dájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: "Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀." Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà t’ó nípọn tọ́ wò.

### الآية 41:51

> ﻿وَإِذَا أَنْعَمْنَا عَلَى الْإِنْسَانِ أَعْرَضَ وَنَأَىٰ بِجَانِبِهِ وَإِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ فَذُو دُعَاءٍ عَرِيضٍ [41:51]

Àti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ.

### الآية 41:52

> ﻿قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كَانَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ثُمَّ كَفَرْتُمْ بِهِ مَنْ أَضَلُّ مِمَّنْ هُوَ فِي شِقَاقٍ بَعِيدٍ [41:52]

Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)" Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa t’ó jìnnà (sí òdodo)!

### الآية 41:53

> ﻿سَنُرِيهِمْ آيَاتِنَا فِي الْآفَاقِ وَفِي أَنْفُسِهِمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُ الْحَقُّ ۗ أَوَلَمْ يَكْفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ [41:53]

A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan?

### الآية 41:54

> ﻿أَلَا إِنَّهُمْ فِي مِرْيَةٍ مِنْ لِقَاءِ رَبِّهِمْ ۗ أَلَا إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ مُحِيطٌ [41:54]

Gbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/41.md)
- [كل تفاسير سورة فصّلت
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/41.md)
- [ترجمات سورة فصّلت
](https://quranpedia.net/translations/41.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/41/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
