---
title: "ترجمة سورة الصف - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/61/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/61/book/2001"
surah_id: "61"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الصف - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/61/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الصف - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/61/book/2001*.

Translation of Surah الصف from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 61:1

> سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ [61:1]

Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 61:2

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفْعَلُونَ [61:2]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí kí ni ẹ ṣe ń sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe níṣẹ́?

### الآية 61:3

> ﻿كَبُرَ مَقْتًا عِنْدَ اللَّهِ أَنْ تَقُولُوا مَا لَا تَفْعَلُونَ [61:3]

Ó jẹ́ ohun ìbínú t’ó tóbi ní ọ̀dọ̀ Allāhu pé kí ẹ sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe.

### الآية 61:4

> ﻿إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِهِ صَفًّا كَأَنَّهُمْ بُنْيَانٌ مَرْصُوصٌ [61:4]

Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn t’ó ń jagun fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí wọ́n tò ní) ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ẹni pé ogiri ilé tí wọ́n lẹ̀ pọ̀ mọ́ra wọn ni wọ́n.

### الآية 61:5

> ﻿وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ لِمَ تُؤْذُونَنِي وَقَدْ تَعْلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ ۖ فَلَمَّا زَاغُوا أَزَاغَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ [61:5]

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ óò ṣe fi ìnira kàn mí. Ẹ sì kúkú mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni èmi jẹ́ si yín." Nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ (kúrò níbi òdodo), Allāhu yẹ ọkàn wọn. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 61:6

> ﻿وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِنْ بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُبِينٌ [61:6]

(Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd." Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, wọ́n á wí pé: "Idán pọ́nńbélé ni èyí."
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Láti ọ̀dọ̀ Jubaer ọmọ Mut‘im, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hī, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún Àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim).

### الآية 61:7

> ﻿وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُوَ يُدْعَىٰ إِلَى الْإِسْلَامِ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ [61:7]

Ta sì ni ó ṣàbòsí t’ó tayọ ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tí wọ́n sì ń pè é sínú ’Islām! Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

### الآية 61:8

> ﻿يُرِيدُونَ لِيُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَاللَّهُ مُتِمُّ نُورِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ [61:8]

Wọ́n ń gbèrò láti fi (ọ̀rọ̀) ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ Allāhu. Allāhu yó sì mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn kárí, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.

### الآية 61:9

> ﻿هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ [61:9]

(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.

### الآية 61:10

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ تِجَارَةٍ تُنْجِيكُمْ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ [61:10]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

### الآية 61:11

> ﻿تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَتُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنْفُسِكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ [61:11]

Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.

### الآية 61:12

> ﻿يَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَيُدْخِلْكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ [61:12]

(Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé t’ó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

### الآية 61:13

> ﻿وَأُخْرَىٰ تُحِبُّونَهَا ۖ نَصْرٌ مِنَ اللَّهِ وَفَتْحٌ قَرِيبٌ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ [61:13]

Àti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn,) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun t’ó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.

### الآية 61:14

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا أَنْصَارَ اللَّهِ كَمَا قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ لِلْحَوَارِيِّينَ مَنْ أَنْصَارِي إِلَى اللَّهِ ۖ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنْصَارُ اللَّهِ ۖ فَآمَنَتْ طَائِفَةٌ مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَكَفَرَتْ طَائِفَةٌ ۖ فَأَيَّدْنَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَىٰ عَدُوِّهِمْ فَأَصْبَحُوا ظَاهِرِينَ [61:14]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún ẹ̀sìn Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: "Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa ẹ̀sìn Allāhu?" Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: "Àwa ni alárànṣe fún ẹ̀sìn Allāhu." Igun kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbà á gbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āl ‘Imrọ̄n; 3:55.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/61.md)
- [كل تفاسير سورة الصف
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/61.md)
- [ترجمات سورة الصف
](https://quranpedia.net/translations/61.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/61/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
