---
title: "ترجمة سورة الأعراف - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/7/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/7/book/2001"
surah_id: "7"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الأعراف - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/7/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الأعراف - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/7/book/2001*.

Translation of Surah الأعراف from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 7:1

> المص [7:1]

’Alif lām mīm sọ̄d.

### الآية 7:2

> ﻿كِتَابٌ أُنْزِلَ إِلَيْكَ فَلَا يَكُنْ فِي صَدْرِكَ حَرَجٌ مِنْهُ لِتُنْذِرَ بِهِ وَذِكْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ [7:2]

Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (nìyí). Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí iyèméjì wà nínú ọkàn rẹ nípa rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ àti ìrántí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 7:3

> ﻿اتَّبِعُوا مَا أُنْزِلَ إِلَيْكُمْ مِنْ رَبِّكُمْ وَلَا تَتَّبِعُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ ۗ قَلِيلًا مَا تَذَكَّرُونَ [7:3]

Ẹ tẹ̀lé ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn wòlíì (èṣù) lẹ́yìn Rẹ̀. Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

### الآية 7:4

> ﻿وَكَمْ مِنْ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا فَجَاءَهَا بَأْسُنَا بَيَاتًا أَوْ هُمْ قَائِلُونَ [7:4]

Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́! Ìyà Wa dé bá wọn ní òru tàbí nígbà tí wọ́n ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.

### الآية 7:5

> ﻿فَمَا كَانَ دَعْوَاهُمْ إِذْ جَاءَهُمْ بَأْسُنَا إِلَّا أَنْ قَالُوا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ [7:5]

Igbe ẹnu wọn kò jẹ́ kiní kan nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn ju pé wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."

### الآية 7:6

> ﻿فَلَنَسْأَلَنَّ الَّذِينَ أُرْسِلَ إِلَيْهِمْ وَلَنَسْأَلَنَّ الْمُرْسَلِينَ [7:6]

Nítorí náà, dájúdájú A óò bi àwọn tí A ránṣẹ́ sí léèrè (nípa ìjẹ́pè). Dájúdájú A ó sì bi àwọn Òjíṣẹ́ léèrè (nípa ìjíṣẹ́).

### الآية 7:7

> ﻿فَلَنَقُصَّنَّ عَلَيْهِمْ بِعِلْمٍ ۖ وَمَا كُنَّا غَائِبِينَ [7:7]

Dájúdájú A óò ròyìn (iṣẹ́ ọwọ́ wọn) fún wọn pẹ̀lú ìmọ̀. Àwa kò ṣàì wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀).

### الآية 7:8

> ﻿وَالْوَزْنُ يَوْمَئِذٍ الْحَقُّ ۚ فَمَنْ ثَقُلَتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [7:8]

Òdodo ni òṣùwọ̀n Ọjọ́ yẹn. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí àwọn òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.

### الآية 7:9

> ﻿وَمَنْ خَفَّتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ بِمَا كَانُوا بِآيَاتِنَا يَظْلِمُونَ [7:9]

Ẹnikẹ́ni tí àwọn òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣ’ẹ̀mí ara wọn lófò nítorí pé wọ́n ń ṣàbòsí sí àwọn āyah Wa.

### الآية 7:10

> ﻿وَلَقَدْ مَكَّنَّاكُمْ فِي الْأَرْضِ وَجَعَلْنَا لَكُمْ فِيهَا مَعَايِشَ ۗ قَلِيلًا مَا تَشْكُرُونَ [7:10]

Dájúdájú A fun yín ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. A sì ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu fún yín lórí rẹ̀. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá.

### الآية 7:11

> ﻿وَلَقَدْ خَلَقْنَاكُمْ ثُمَّ صَوَّرْنَاكُمْ ثُمَّ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ لَمْ يَكُنْ مِنَ السَّاجِدِينَ [7:11]

Dájúdájú A da yín, lẹ́yìn náà A ya àwòrán yín, lẹ́yìn náà A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam." Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, tí kò sí nínú àwọn olùforíkanlẹ̀.

### الآية 7:12

> ﻿قَالَ مَا مَنَعَكَ أَلَّا تَسْجُدَ إِذْ أَمَرْتُكَ ۖ قَالَ أَنَا خَيْرٌ مِنْهُ خَلَقْتَنِي مِنْ نَارٍ وَخَلَقْتَهُ مِنْ طِينٍ [7:12]

(Allāhu) sọ pé: "Kí ni ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí i nígbà tí Mo pa á láṣẹ fún ọ." (Èṣù) wí pé: "Èmi lóore jùlọ sí òun; iná ni O fi dá èmi, O sì dá òun láti ara erùpẹ̀ amọ̀."

### الآية 7:13

> ﻿قَالَ فَاهْبِطْ مِنْهَا فَمَا يَكُونُ لَكَ أَنْ تَتَكَبَّرَ فِيهَا فَاخْرُجْ إِنَّكَ مِنَ الصَّاغِرِينَ [7:13]

(Allāhu) sọ pé: "Sọ̀kalẹ̀ kúrò níbí nítorí pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ láti ṣègbéraga níbí. Nítorí náà, jáde dájúdájú ìwọ ń bẹ nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ."

### الآية 7:14

> ﻿قَالَ أَنْظِرْنِي إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ [7:14]

. (Èṣù) wí pé: "Lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé àwọn ènìyàn dìde."

### الآية 7:15

> ﻿قَالَ إِنَّكَ مِنَ الْمُنْظَرِينَ [7:15]

(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ ń bẹ nínú àwọn tí A óò lọ́ lára."

### الآية 7:16

> ﻿قَالَ فَبِمَا أَغْوَيْتَنِي لَأَقْعُدَنَّ لَهُمْ صِرَاطَكَ الْمُسْتَقِيمَ [7:16]

(Èṣù) wí pé: "Fún wí pé O ti fi mí sínú anù, èmi yóò jókòó dè wọ́n ní ọ̀nà tààrà Rẹ.

### الآية 7:17

> ﻿ثُمَّ لَآتِيَنَّهُمْ مِنْ بَيْنِ أَيْدِيهِمْ وَمِنْ خَلْفِهِمْ وَعَنْ أَيْمَانِهِمْ وَعَنْ شَمَائِلِهِمْ ۖ وَلَا تَجِدُ أَكْثَرَهُمْ شَاكِرِينَ [7:17]

Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi yóò wá bá wọn láti iwájú wọn, láti ẹ̀yìn wọn, láti ọ̀tún wọn àti òsì wọn. Ìwọ kò sì níí rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ní olùdúpẹ́ (fún Ọ)."

### الآية 7:18

> ﻿قَالَ اخْرُجْ مِنْهَا مَذْءُومًا مَدْحُورًا ۖ لَمَنْ تَبِعَكَ مِنْهُمْ لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنْكُمْ أَجْمَعِينَ [7:18]

(Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò níbí (kí o sì di) alábùkù, ẹni-àlédànù. Dájúdájú ẹnikẹ́ni t’ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú Èmi yóò fi gbogbo yín kún inú iná Jahanamọ."

### الآية 7:19

> ﻿وَيَا آدَمُ اسْكُنْ أَنْتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ فَكُلَا مِنْ حَيْثُ شِئْتُمَا وَلَا تَقْرَبَا هَٰذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ [7:19]

Ādam, kí ìwọ àti ìyàwó rẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Nítorí náà, ẹ máa jẹ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí nítorí kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.

### الآية 7:20

> ﻿فَوَسْوَسَ لَهُمَا الشَّيْطَانُ لِيُبْدِيَ لَهُمَا مَا وُورِيَ عَنْهُمَا مِنْ سَوْآتِهِمَا وَقَالَ مَا نَهَاكُمَا رَبُّكُمَا عَنْ هَٰذِهِ الشَّجَرَةِ إِلَّا أَنْ تَكُونَا مَلَكَيْنِ أَوْ تَكُونَا مِنَ الْخَالِدِينَ [7:20]

Èṣù sì kó ròyíròyí bá àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ohun tí A fi pamọ́ nínú ìhòhò ara wọn hàn wọ́n. Ó sì wí pé: "Olúwa ẹ̀yin méjèèjì kò kọ igi yìí fun yín bí kò ṣe pé kí ẹ̀yin méjèèjì má baà di mọlāika tàbí kí ẹ̀yin méjèèjì má baà di olùṣegbére."

### الآية 7:21

> ﻿وَقَاسَمَهُمَا إِنِّي لَكُمَا لَمِنَ النَّاصِحِينَ [7:21]

Ó sì búra fún àwọn méjèèjì pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn fún ẹ̀yin méjèèjì."

### الآية 7:22

> ﻿فَدَلَّاهُمَا بِغُرُورٍ ۚ فَلَمَّا ذَاقَا الشَّجَرَةَ بَدَتْ لَهُمَا سَوْآتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِنْ وَرَقِ الْجَنَّةِ ۖ وَنَادَاهُمَا رَبُّهُمَا أَلَمْ أَنْهَكُمَا عَنْ تِلْكُمَا الشَّجَرَةِ وَأَقُلْ لَكُمَا إِنَّ الشَّيْطَانَ لَكُمَا عَدُوٌّ مُبِينٌ [7:22]

Ó sì tan àwọn méjèèjì jẹ. Nígbà tí àwọn méjèèjì tọ́ igi náà wò, ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bora wọn. Olúwa àwọn méjèèjì sì pè wọ́n pé: "Ǹjẹ́ Èmi kò ti kọ igi náà fun ẹ̀yin méjèèjì? (Ṣé) Èmi kò sì ti sọ fún ẹ̀yin méjèèjì pé ọ̀tá pọ́nńbélé ni Èṣù jẹ́ fun yín?"

### الآية 7:23

> ﻿قَالَا رَبَّنَا ظَلَمْنَا أَنْفُسَنَا وَإِنْ لَمْ تَغْفِرْ لَنَا وَتَرْحَمْنَا لَنَكُونَنَّ مِنَ الْخَاسِرِينَ [7:23]

Àwọn méjèèjì sọ pé: "Olúwa wa, a ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí wa. Tí O ò bá foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa, dájúdájú a máa wà nínú àwọn ẹni òfò." 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Láti āyah 19 sí 24 nínú sūrah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó ṣẹlẹ̀ sí bàbá ńlá wa Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá ńlá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) nípa bí àwọn méjèèjì ṣe jẹ èso igi tí Allāhu kọ̀ fún wọn láti jẹ. Ó tún wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:35-39 àti sūrah Tọ̄hā; 20:120-123. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn okùnfà ìṣìnà fún gbogbo àwọn kristiẹni pátápátá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ìgbàgbọ́ wọn fi forí sánpọ́n láti ìpìlẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò kúkú ṣàdédé pe àwọn kristiẹni ní olùṣìnà nínú sūrah al-Fātihah, Allāhu kò sì ṣàdédé kọ̀ fún àwa mùsùlùmí láti mú wọn ní ọ̀rẹ́, yálà ọ̀rẹ́ àyò tàbí ọ̀rẹ́ lásán, tí kì í bá ṣe pé ìgbàgbọ́ wọn dúró sórí àwọn ìṣìnà gban̄kọgban̄kọ méje kan. 
Ìkíní; àwọn kristiẹni di olùṣìnà bẹ̀rẹ̀ láti ara sísọ pé gbogbo àwọn ọmọ Ànábì Ādam jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam jẹ láti ọjọ́ ìbí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Ìkejì; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé wọ́n kan Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mọ́ igi àgbélébùú. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé “wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ àgbélébùú…” Ìkẹta; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé ìgbàlà wà nínú ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú àti pé ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ànábì Ādam tí wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ ègún èso tí òun àti ìyàwó rẹ̀ jẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n tún ṣe gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú ti pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rẹ́ fún gbogbo àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí igi àgbélébùú. Allāhu sì sọ pé ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmìíràn mọ́ tirẹ̀. Ìkẹrin; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún nítorí pé, wọ́n gbà pé ìkíní kejì wọn nìkan ni kò ní ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àti pé wọ́n tún gbàgbọ́ pé, ìkíní kejì wọn ni kò dá ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rí. Allāhu sì sọ pé kò sí ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Òun. Ìkarùn-ún; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ọmọ Ọlọ́hun. Allāhu sì sọ pé Òun kò bímọ, Òun kò sì fi ẹnì kan kan ṣọmọ. Ìkẹfà: àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹ̀yàmẹ̀yà láààrin àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ṣàì gbàgbọ́ nínú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí wọ́n sì ń fi ẹnu àbùkù t’ó lágbára kàn òun pẹ̀lú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ mìíràn tí Allāhu rán níṣẹ́ sáyé. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé àwọn t’ó ń ṣẹ̀yàmẹ̀yà láààrin àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ ni ojúlówó aláìgbàgbọ́. Ìkeje: àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe ń tọwọ́bọ tírà tí Allāhu fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti tírà tí Allāhu fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lójú, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí oríṣiríṣi tírà méjèèjì náà fi pọ̀ lórí igbá, tí wọn kò sì yé yí wọn padà sí ìfẹ́-inú wọn lórúkọ “àtúnṣe” látìgbàdégbà. Allāhu sì sọ pé ègbé ni fún àwọn t’ó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun. 
Wàyí nípa ìṣìnà àwọn kristiẹni lórí èso tí Ànábì Ādam àti Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ, kókó mẹ́fà wọ̀nyí ni òdodo nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kókó kìíní: bàbá ńlá wa Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá ńlá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ èso igi náà. Jíjẹ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn àwọn méjèèjì nìkan, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àwọn ọmọ wọn kan kan. Kókó kejì: àwọn méjèèjì tọrọ àforíjìn lórí àṣìṣe náà, Allāhu sì foríjìn àwọn méjèèjì. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:37 àti sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:19-23. Kókó kẹta: Allāhu ti forí jìn àwọn méjèèjì pátápátá ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó ṣọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:120-123. Kókó kẹrin: ìsọ̀kalẹ̀ àwọn méjèèjì sórí ilẹ̀ ayé yìí wá sí ìmúṣẹ nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Allāhu pé Òun fẹ́ dá àrólé kan sórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:30. Kókó karùn-ún: kò sí ẹnì kan kan t’ó jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ náà láti ara àwọn méjèèjì nítorí pé, Allāhu ti forí jìn àwọn méjèèjì pátápátá. Kókó kẹfà: àdámọ́ tí Allāhu dámọ́ ìṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ṣoṣo ni àwọn ọmọ rẹ̀ jogún pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nítorí pé, Allāhu ti fi àdámọ́ ìtẹ̀lé-àṣẹ àti ìyapa àṣẹ sínú ìṣẹ̀dá wa láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àdámọ́ méjèèjì náà sì ti wà lára Ànábì Ādam láti ọjọ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti ṣíwájú ọjọ́ èso t’ó jẹ́. Nítorí náà, tí a bá tẹ̀lé àṣẹ Allāhu, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá yapa àṣẹ Allāhu, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn ìyapa àṣẹ Rẹ̀, tí a sì tọrọ àforínjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá lo ìkápá tí Allāhu fún wa láti lè tẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá sì lo ìkápá tí Allāhu fún wa láti tẹ̀lé ìfẹ́-inú wa, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àmọ́ tí a bá kùnà láti ronú pìwàdà lórí ìyapa àṣẹ Allāhu, tí a ò sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, kì í ṣe Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’a fi jọ. Nítorí náà, ìyàtọ̀ wà láààrin sísọ pé a jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti sísọ pé a jogún àwọn àdámọ́ ìyapa àṣẹ àti ìtọrọ-àforíjìn láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ní ti jíjẹ ogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, ìyẹn ń fi dídi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ru ẹlòmíìràn rinlẹ̀. Àbòsì ńlá sì nìyẹn. Allāhu kì í sì ṣe Ọba alábòsí. Ní ti jíjẹ ogún àdámọ́ ìyapa àṣẹ àti ìtọrọ-àforíjìn láti ara Ànábì Ādam, ìyẹn ń fi dídi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ru ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn. Déédé àti dọ́gba sì nìyẹn. Allāhu sì ni Ọba Onídéédé. 
Síwájú sí i, lára ohun t’ó ń ṣàfi hàn ìṣìnà àwọn kristiẹni lórí èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, tí wọ́n sì sọ gbogbo ọmọ rẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀ èso nípasẹ̀ rẹ̀, òhun ni pé, àwọn ìjọ tí Allāhu parẹ́ ṣíwájú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ṣé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ādam àti ìyàwó rẹ̀ jẹ ni tàbí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn dá lẹ́ṣẹ̀? Allāhu kò pa ìjọ kan run rí bí kò ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọwọ́ wọn. Bákan náà, àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò ì bàlágà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan lọ́rùn wọn títí wọ́n fi máa bàlágà. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá nígbà náà nìkan lẹ́ṣẹ̀ tí ó máa wà lọ́rùn wọn. Nítorí náà, kò sí ègún kan kan lórí àwọn ọmọ Ànábì Ādam nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ. Bákan náà, kò sí ẹni tí kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tara tirẹ̀ rí nínú gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, kódà t’ó fi mọ́ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, ọmọ ènìyàn ni, kì í ṣe ọmọ Ọlọ́hun. Àrọ́mọdọ́mọ Ànábì Ādam ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), kò ṣàì jogún àwọn àdámọ́ lára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé al-Ƙur’ān kò sí fún kíka ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ lọ́rùn - ṣebí ẹni ẹ̀ṣà jùlọ ni gbogbo wọn, - ọ̀wọ́ ohun tí Allāhu bá sọ fún wa nípa wọn nìkan l’ó kúkú kàn wá jùlọ nínú ọ̀rọ̀ wọn. Tí a ò bá rí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan nípa ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú al-Ƙur’ān, kò túmọ̀ sí pé òun náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kan kan rí. Ṣebí a ò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan kà nínú al-Ƙur’ān nípa àwọn Ànábì mìíràn, gẹ́gẹ́ bí Ànábì Lūt, Ànábì Sọ̄lih, Ànábì Ṣu‘aeb, Ànábì Ya‘ƙūb, Ànábì ’Ishāƙ, Ànábì ’Ismọ‘īl, Ànábì Yahyā, Ànábì Yūṣa‘u àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ (aleehim salām). Bákan náà, èyí kò túmọ̀ sí pé wọn kò jogún àwọn àdámọ́ òkè wọ̀nyẹn lára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), bẹ́ẹ̀ sì ni pé, àìrí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan kà nípa wọn kò sọ wọ́n di olúwa àti olùgbàlà. Kíyè sí i, ẹ̀dá Ọlọ́hun kúkú ni àwọn mọlā’ika, àmọ́ kò sí àdámọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá nínú ìṣẹ̀dá tiwọn. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ìyẹn kò sọ ẹnikẹ́ni nínú wọn di olúwa àti olùgbàlà, yálà mọlāika Jibrīl, ẹni tí àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ “Ẹ̀mí Mímọ́” tàbí mọlāika mìíràn. Nítorí náà, olùtàbùkù Ànábì Ādam ni ẹni tí ó bá ń sọ pé àwa ọmọ rẹ̀ jogún ègún èso t’ó jẹ lára rẹ̀. Irú ẹni náà kì í ṣọmọ rere. W-Allāhu ’a‘lam.

### الآية 7:24

> ﻿قَالَ اهْبِطُوا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ وَلَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ [7:24]

(Allāhu) sọ pé: "Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fun yín ní orí ilẹ̀ fún ìgbà (díẹ̀).”

### الآية 7:25

> ﻿قَالَ فِيهَا تَحْيَوْنَ وَفِيهَا تَمُوتُونَ وَمِنْهَا تُخْرَجُونَ [7:25]

(Allāhu) sọ pé: “Lórí ilẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣẹ̀mí, lórí rẹ̀ ni ẹ̀yin yóò máa kú sí, A ó sì mu yín jáde láti inú rẹ̀.”

### الآية 7:26

> ﻿يَا بَنِي آدَمَ قَدْ أَنْزَلْنَا عَلَيْكُمْ لِبَاسًا يُوَارِي سَوْآتِكُمْ وَرِيشًا ۖ وَلِبَاسُ التَّقْوَىٰ ذَٰلِكَ خَيْرٌ ۚ ذَٰلِكَ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ لَعَلَّهُمْ يَذَّكَّرُونَ [7:26]

Ọmọ (Ànábì) Ādam, dájúdájú A ti sọ aṣọ kalẹ̀ fun yín, tí ó máa bo ìhòhò yín àti ohun àmúṣọrọ̀. Aṣọ ìbẹ̀rù Allāhu, ìyẹn l’ó sì lóore jùlọ. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

### الآية 7:27

> ﻿يَا بَنِي آدَمَ لَا يَفْتِنَنَّكُمُ الشَّيْطَانُ كَمَا أَخْرَجَ أَبَوَيْكُمْ مِنَ الْجَنَّةِ يَنْزِعُ عَنْهُمَا لِبَاسَهُمَا لِيُرِيَهُمَا سَوْآتِهِمَا ۗ إِنَّهُ يَرَاكُمْ هُوَ وَقَبِيلُهُ مِنْ حَيْثُ لَا تَرَوْنَهُمْ ۗ إِنَّا جَعَلْنَا الشَّيَاطِينَ أَوْلِيَاءَ لِلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ [7:27]

Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù kó ìfòòró ba yín gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yọ àwọn òbí yín méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó gba aṣọ kúrò lára àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ìhòhò wọn hàn wọ́n. Dájúdájú ó ń ri yín; òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (ń ri yín) ní àyè tí ẹ̀yin kò ti rí wọn. Dájúdájú Àwa fi Èṣù ṣe ọ̀rẹ́ fún àwọn tí kò gbàgbọ́.

### الآية 7:28

> ﻿وَإِذَا فَعَلُوا فَاحِشَةً قَالُوا وَجَدْنَا عَلَيْهَا آبَاءَنَا وَاللَّهُ أَمَرَنَا بِهَا ۗ قُلْ إِنَّ اللَّهَ لَا يَأْمُرُ بِالْفَحْشَاءِ ۖ أَتَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ [7:28]

Nígbà tí wọ́n bá sì ṣe ìbàjẹ́ kan, wọ́n á wí pé: "A bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ni. Allāhu l’Ó sì pa á láṣẹ fún wa." Sọ pé: "Dájúdájú Allāhu kì í p’àṣẹ ìbàjẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?"

### الآية 7:29

> ﻿قُلْ أَمَرَ رَبِّي بِالْقِسْطِ ۖ وَأَقِيمُوا وُجُوهَكُمْ عِنْدَ كُلِّ مَسْجِدٍ وَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ ۚ كَمَا بَدَأَكُمْ تَعُودُونَ [7:29]

Sọ pé: “Olúwa mi p’àṣẹ ṣíṣe déédé. Kí ẹ sì dojú yín kọ (Allāhu) ní gbogbo mọ́sálásí. Ẹ pè É (kí ẹ jẹ́) olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe da yín (tí ẹ fi di alààyè), ẹ máa padà (di alààyè lẹ́yìn ikú yín).”

### الآية 7:30

> ﻿فَرِيقًا هَدَىٰ وَفَرِيقًا حَقَّ عَلَيْهِمُ الضَّلَالَةُ ۗ إِنَّهُمُ اتَّخَذُوا الشَّيَاطِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ مُهْتَدُونَ [7:30]

Apá kan ni Ó fi mọ̀nà, apa kan sì ni ìṣìnà kò lé lórí. (Nítorí pé) dájúdájú wọ́n mú àwọn èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.

### الآية 7:31

> ﻿۞ يَا بَنِي آدَمَ خُذُوا زِينَتَكُمْ عِنْدَ كُلِّ مَسْجِدٍ وَكُلُوا وَاشْرَبُوا وَلَا تُسْرِفُوا ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ [7:31]

Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ wọ (aṣọ) ọ̀ṣọ́ yín nígbàkígbà tí ẹ bá ń lọ sí mọ́sálásí. Ẹ jẹ, ẹ mu, kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà.

### الآية 7:32

> ﻿قُلْ مَنْ حَرَّمَ زِينَةَ اللَّهِ الَّتِي أَخْرَجَ لِعِبَادِهِ وَالطَّيِّبَاتِ مِنَ الرِّزْقِ ۚ قُلْ هِيَ لِلَّذِينَ آمَنُوا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا خَالِصَةً يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ [7:32]

Sọ pé: “Ta l’ó ṣe ọ̀ṣọ́ Allāhu, tí Ó mú jáde fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan dáadáa nínú arísìkí ní èèwọ̀?” Sọ pé: “Ó wà fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú ìṣẹ̀mí ayé. Tiwọn nìkan sì ni l’Ọ́jọ́ Àjíǹde." Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀.”

### الآية 7:33

> ﻿قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالْإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَنْ تُشْرِكُوا بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَأَنْ تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ [7:33]

Sọ pé: "Ohun tí Olúwa mi ṣe ní èèwọ̀ ni àwọn ìwà ìbàjẹ́ – èyí t’ó fojú hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́ –, ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ọ̀tẹ̀ ṣíṣe láì lẹ́tọ̀ọ́, bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ – èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún – àti ṣíṣe àfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu."

### الآية 7:34

> ﻿وَلِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٌ ۖ فَإِذَا جَاءَ أَجَلُهُمْ لَا يَسْتَأْخِرُونَ سَاعَةً ۖ وَلَا يَسْتَقْدِمُونَ [7:34]

Àkókò kan ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan; nígbà tí àkókò wọn bá sì dé, wọn kó lè sún un síwájú di àkókò kan, wọn kò sì lè fà á sẹ́yìn.

### الآية 7:35

> ﻿يَا بَنِي آدَمَ إِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ رُسُلٌ مِنْكُمْ يَقُصُّونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِي ۙ فَمَنِ اتَّقَىٰ وَأَصْلَحَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ [7:35]

Ọmọ (Ànábì) Ādam, nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ nínú yín bá wá ba yín, tí wọn yóò máa ka àwọn āyah Mi fun yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Mi), tí ó sì ṣàtúnṣe, kò níí sí ìbẹ̀rù kan fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́.

### الآية 7:36

> ﻿وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَاسْتَكْبَرُوا عَنْهَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ [7:36]

Àwọn t’ó bá sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

### الآية 7:37

> ﻿فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ ۚ أُولَٰئِكَ يَنَالُهُمْ نَصِيبُهُمْ مِنَ الْكِتَابِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءَتْهُمْ رُسُلُنَا يَتَوَفَّوْنَهُمْ قَالُوا أَيْنَ مَا كُنْتُمْ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۖ قَالُوا ضَلُّوا عَنَّا وَشَهِدُوا عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ أَنَّهُمْ كَانُوا كَافِرِينَ [7:37]

Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí t’ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Ìpín àwọn wọ̀nyẹn nínú kádàrá yóò máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa yóò wá bá wọn, tí wọn yóò gba ẹ̀mí wọn. Wọn yó sì sọ pé: "Níbo ni àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀yin ń pè lẹ́yìn Allāhu wà?" Wọn yóò wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́." Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.”

### الآية 7:38

> ﻿قَالَ ادْخُلُوا فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِكُمْ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ فِي النَّارِ ۖ كُلَّمَا دَخَلَتْ أُمَّةٌ لَعَنَتْ أُخْتَهَا ۖ حَتَّىٰ إِذَا ادَّارَكُوا فِيهَا جَمِيعًا قَالَتْ أُخْرَاهُمْ لِأُولَاهُمْ رَبَّنَا هَٰؤُلَاءِ أَضَلُّونَا فَآتِهِمْ عَذَابًا ضِعْفًا مِنَ النَّارِ ۖ قَالَ لِكُلٍّ ضِعْفٌ وَلَٰكِنْ لَا تَعْلَمُونَ [7:38]

(Allāhu) sọ pé: "Ẹ wọlé ti àwọn ìjọ t’ó ti ré kọjá lọ ṣíwájú yín nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn (tí wọ́n ti wà) nínú Iná." Ìgbàkígbà tí ìjọ kan bá wọ (inú Iná), wọn yóò máa ṣẹ́bi fún àwọn ìjọ rẹ̀ (t’ó ti wà níbẹ̀ ṣíwájú wọn), títí di ìgbà tí gbogbo wọn yóò fi pàdé ara wọn nínú Iná. (Ìgbà yìí ni) àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn yóò wí fún àwọn ẹni ìṣáájú wọn pé: "Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ṣì wá lọ́nà. Nítorí náà, fún wọn ni ìlọ́po ìyà méjì nínú Iná." (Allāhu) sọ pé: "Ìkọ̀ọ̀kan (yín) l’ó ní ìlọ́po ìyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀."

### الآية 7:39

> ﻿وَقَالَتْ أُولَاهُمْ لِأُخْرَاهُمْ فَمَا كَانَ لَكُمْ عَلَيْنَا مِنْ فَضْلٍ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْسِبُونَ [7:39]

Àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn yó sí wí fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn pé: "Kò sí àjùlọ kan fun yín lórí wa. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."

### الآية 7:40

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَاسْتَكْبَرُوا عَنْهَا لَا تُفَتَّحُ لَهُمْ أَبْوَابُ السَّمَاءِ وَلَا يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ حَتَّىٰ يَلِجَ الْجَمَلُ فِي سَمِّ الْخِيَاطِ ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُجْرِمِينَ [7:40]

Dájúdájú àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, Wọn kò níí ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ fún wọn. Wọn kò sì níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra títí ràkúnmí yóò wọ inú ihò abẹ́rẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.

### الآية 7:41

> ﻿لَهُمْ مِنْ جَهَنَّمَ مِهَادٌ وَمِنْ فَوْقِهِمْ غَوَاشٍ ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الظَّالِمِينَ [7:41]

Ìtẹ́ wà fún wọn nínú iná Jahanamọ. Òrùlé sì wà fún wọn ní òkè wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.

### الآية 7:42

> ﻿وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ [7:42]

Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ lódodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere - A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀ - àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

### الآية 7:43

> ﻿وَنَزَعْنَا مَا فِي صُدُورِهِمْ مِنْ غِلٍّ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهِمُ الْأَنْهَارُ ۖ وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي هَدَانَا لِهَٰذَا وَمَا كُنَّا لِنَهْتَدِيَ لَوْلَا أَنْ هَدَانَا اللَّهُ ۖ لَقَدْ جَاءَتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِالْحَقِّ ۖ وَنُودُوا أَنْ تِلْكُمُ الْجَنَّةُ أُورِثْتُمُوهَا بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ [7:43]

A ó sì mú inúnibíni kúrò nínú ọkàn wọn. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fi wá mọ̀nà yìí. Àwa ìbá tí mọ̀nà, tí kì í bá ṣe pé Allāhu tọ́ wa sí ọ̀nà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá.” Wọ́n sì máa pè wọ́n pé: “Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fun yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

### الآية 7:44

> ﻿وَنَادَىٰ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ أَصْحَابَ النَّارِ أَنْ قَدْ وَجَدْنَا مَا وَعَدَنَا رَبُّنَا حَقًّا فَهَلْ وَجَدْتُمْ مَا وَعَدَ رَبُّكُمْ حَقًّا ۖ قَالُوا نَعَمْ ۚ فَأَذَّنَ مُؤَذِّنٌ بَيْنَهُمْ أَنْ لَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الظَّالِمِينَ [7:44]

Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò pe àwọn èrò inú Iná pé: "A ti rí ohun tí Olúwa wa ṣe àdéhùn rẹ̀ fún wa ní òdodo. Ǹjẹ́ ẹ̀yin náà rí ohun tí Olúwa yín ṣe àdéhùn (rẹ̀ fun yín) ní òdodo?" Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Olùpèpè kan yó sì pèpè láààrin wọn pé: "Kí ibi dandan Allāhu máa bẹ lórí àwọn alábòsí."

### الآية 7:45

> ﻿الَّذِينَ يَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا وَهُمْ بِالْآخِرَةِ كَافِرُونَ [7:45]

(Àwọn ni) àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì tún ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

### الآية 7:46

> ﻿وَبَيْنَهُمَا حِجَابٌ ۚ وَعَلَى الْأَعْرَافِ رِجَالٌ يَعْرِفُونَ كُلًّا بِسِيمَاهُمْ ۚ وَنَادَوْا أَصْحَابَ الْجَنَّةِ أَنْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ ۚ لَمْ يَدْخُلُوهَا وَهُمْ يَطْمَعُونَ [7:46]

Gàgá yóò wà láààrin èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná. Àwọn ènìyàn kan máa wà lórí ògiri (gàgá náà), wọn yó sì dá ẹnì kọ̀ọ̀kan (ìjọ méjèèjì) mọ̀ pẹ̀lú àmì wọn. Wọn yóò pe àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Kí àlàáfíà máa bẹ fun yín.” Wọn kò ì wọ (inú) rẹ̀, wọ́n sì ti ń jẹ̀rankàn (rẹ̀).

### الآية 7:47

> ﻿۞ وَإِذَا صُرِفَتْ أَبْصَارُهُمْ تِلْقَاءَ أَصْحَابِ النَّارِ قَالُوا رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا مَعَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [7:47]

Nígbà tí wọ́n bá yíjú wọn sí ọ̀gangan àwọn èrò inú Iná, wọn yóò sọ pé: “Olúwa wa, má fi wá sọ́dọ̀ àwọn ìjọ alábòsí.”

### الآية 7:48

> ﻿وَنَادَىٰ أَصْحَابُ الْأَعْرَافِ رِجَالًا يَعْرِفُونَهُمْ بِسِيمَاهُمْ قَالُوا مَا أَغْنَىٰ عَنْكُمْ جَمْعُكُمْ وَمَا كُنْتُمْ تَسْتَكْبِرُونَ [7:48]

Àwọn èrò orí ògiri (gàgá náà), yóò pe àwọn ènìyàn kan tí wọ́n mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn, wọn yó sì sọ pé: “Ohun tí ẹ kójọ nílé ayé àti ṣíṣe ìgbéraga yín sí ìgbàgbọ́ òdodo kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ mọ́ (báyìí)”

### الآية 7:49

> ﻿أَهَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ أَقْسَمْتُمْ لَا يَنَالُهُمُ اللَّهُ بِرَحْمَةٍ ۚ ادْخُلُوا الْجَنَّةَ لَا خَوْفٌ عَلَيْكُمْ وَلَا أَنْتُمْ تَحْزَنُونَ [7:49]

(Allāhu) yóò sọ fún èrò inú Iná pé: “Ṣé àwọn (èrò orí ògiri) wọ̀nyí ni ẹ̀yin ń búra pé Allāhu kò níí ṣíjú àánú wò? (Nítorí náà, ẹ̀yin èrò orí ògiri) ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò níí sí ìbẹ̀rù kan fun yín. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.”

### الآية 7:50

> ﻿وَنَادَىٰ أَصْحَابُ النَّارِ أَصْحَابَ الْجَنَّةِ أَنْ أَفِيضُوا عَلَيْنَا مِنَ الْمَاءِ أَوْ مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ ۚ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ حَرَّمَهُمَا عَلَى الْكَافِرِينَ [7:50]

Èrò inú Iná yóò pe èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Ẹ fún wa nínú omi tàbí nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín.” Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe méjèèjì ní èèwọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

### الآية 7:51

> ﻿الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَهُمْ لَهْوًا وَلَعِبًا وَغَرَّتْهُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۚ فَالْيَوْمَ نَنْسَاهُمْ كَمَا نَسُوا لِقَاءَ يَوْمِهِمْ هَٰذَا وَمَا كَانُوا بِآيَاتِنَا يَجْحَدُونَ [7:51]

Àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn wọn di ìranù àti eré ṣíṣe, ìṣẹ̀mí ayé sì kó ẹ̀tàn bá wọn, ní òní ni A óò gbàgbé wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ wọn ti òní yìí àti (bí) wọ́n ṣe ń tako àwọn āyah Wa.

### الآية 7:52

> ﻿وَلَقَدْ جِئْنَاهُمْ بِكِتَابٍ فَصَّلْنَاهُ عَلَىٰ عِلْمٍ هُدًى وَرَحْمَةً لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ [7:52]

A kúkú ti mú tírà kan wá bá wọn, tí A ṣàlàyé rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 7:53

> ﻿هَلْ يَنْظُرُونَ إِلَّا تَأْوِيلَهُ ۚ يَوْمَ يَأْتِي تَأْوِيلُهُ يَقُولُ الَّذِينَ نَسُوهُ مِنْ قَبْلُ قَدْ جَاءَتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِالْحَقِّ فَهَلْ لَنَا مِنْ شُفَعَاءَ فَيَشْفَعُوا لَنَا أَوْ نُرَدُّ فَنَعْمَلَ غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ ۚ قَدْ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ [7:53]

Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀? Lọ́jọ́ tí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá dé, àwọn t’ó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́.

### الآية 7:54

> ﻿إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ ۗ أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ ۗ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ [7:54]

Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé tí kò dáwọ́ dúró láààrin òru àti ọ̀sán lójoojúmọ́ tí ìkíni fi wà nípò ohun t’ó ń wá ìkejì rẹ̀.

### الآية 7:55

> ﻿ادْعُوا رَبَّكُمْ تَضَرُّعًا وَخُفْيَةً ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ [7:55]

Ẹ pe Olúwa yín pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ohùn jẹ́ẹ́jẹ́. Dájúdájú (Allāhu) kò fẹ́ràn àwọn alákọyọ.

### الآية 7:56

> ﻿وَلَا تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ بَعْدَ إِصْلَاحِهَا وَادْعُوهُ خَوْفًا وَطَمَعًا ۚ إِنَّ رَحْمَتَ اللَّهِ قَرِيبٌ مِنَ الْمُحْسِنِينَ [7:56]

Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ẹ pe Allāhu pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìrètí. Dájúdájú àánú Allāhu súnmọ́ àwọn olùṣe-rere.

### الآية 7:57

> ﻿وَهُوَ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا أَقَلَّتْ سَحَابًا ثِقَالًا سُقْنَاهُ لِبَلَدٍ مَيِّتٍ فَأَنْزَلْنَا بِهِ الْمَاءَ فَأَخْرَجْنَا بِهِ مِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ ۚ كَذَٰلِكَ نُخْرِجُ الْمَوْتَىٰ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ [7:57]

Òun ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn (t’ó jẹ́) ìró ìdùnnú ṣíwájú àánú Rẹ̀, títí (atẹ́gùn náà) yóò fi gbé ẹ̀ṣújò t’ó wúwo, tí A sì máa wọ́ ọ lọ sí òkú ilẹ̀. Nígbà náà, A máa fi sọ omi kalẹ̀. A sì máa mú oríṣiríṣi èso jáde. Báyẹn ni A ó ṣe mú àwọn òkú jáde nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.

### الآية 7:58

> ﻿وَالْبَلَدُ الطَّيِّبُ يَخْرُجُ نَبَاتُهُ بِإِذْنِ رَبِّهِ ۖ وَالَّذِي خَبُثَ لَا يَخْرُجُ إِلَّا نَكِدًا ۚ كَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَشْكُرُونَ [7:58]

(Ilẹ̀) ìlú t’ó dára, àwọn irúgbìn rẹ̀ yóò jáde pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Èyí tí kò sì dára, (irúgbìn rẹ̀) kò níí jáde àfi (díẹ̀) pẹ̀lú ìnira. Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà fún ìjọ t’ó ń dúpẹ́.

### الآية 7:59

> ﻿لَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ [7:59]

Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú mò ń bẹ̀rù ìyà Ọjọ́ Ńlá fun yín."

### الآية 7:60

> ﻿قَالَ الْمَلَأُ مِنْ قَوْمِهِ إِنَّا لَنَرَاكَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ [7:60]

Àwọn àgbààgbà nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: "Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé."

### الآية 7:61

> ﻿قَالَ يَا قَوْمِ لَيْسَ بِي ضَلَالَةٌ وَلَٰكِنِّي رَسُولٌ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ [7:61]

Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, kò sí ìṣìnà kan lọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 7:62

> ﻿أُبَلِّغُكُمْ رِسَالَاتِ رَبِّي وَأَنْصَحُ لَكُمْ وَأَعْلَمُ مِنَ اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ [7:62]

. Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mò ń fun yín ní ìmọ̀ràn rere. Àti pé ohun tí ẹ ò mọ̀ ni èmi mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu.

### الآية 7:63

> ﻿أَوَعَجِبْتُمْ أَنْ جَاءَكُمْ ذِكْرٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَلَىٰ رَجُلٍ مِنْكُمْ لِيُنْذِرَكُمْ وَلِتَتَّقُوا وَلَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ [7:63]

Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí Wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín nítorí kí ó lè kìlọ̀ fun yín; nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí A lè kẹ yín?"

### الآية 7:64

> ﻿فَكَذَّبُوهُ فَأَنْجَيْنَاهُ وَالَّذِينَ مَعَهُ فِي الْفُلْكِ وَأَغْرَقْنَا الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا عَمِينَ [7:64]

Wọ́n sì pè é lópùrọ́. Nítorí náà, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì tẹ àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ rì. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ t’ó fọ́jú (sí òdodo).

### الآية 7:65

> ﻿۞ وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمْ هُودًا ۗ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۚ أَفَلَا تَتَّقُونَ [7:65]

A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ará ‘Ād, arákùnrin wọn, Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?"

### الآية 7:66

> ﻿قَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ قَوْمِهِ إِنَّا لَنَرَاكَ فِي سَفَاهَةٍ وَإِنَّا لَنَظُنُّكَ مِنَ الْكَاذِبِينَ [7:66]

Àwọn àgbààgbà t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú agọ̀. Àti pé dájúdájú à ń rò pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.”

### الآية 7:67

> ﻿قَالَ يَا قَوْمِ لَيْسَ بِي سَفَاهَةٌ وَلَٰكِنِّي رَسُولٌ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ [7:67]

Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, kò sí agọ̀ kan lára mi, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 7:68

> ﻿أُبَلِّغُكُمْ رِسَالَاتِ رَبِّي وَأَنَا لَكُمْ نَاصِحٌ أَمِينٌ [7:68]

Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Èmi sì ni onímọ̀ràn rere, olùfọkàntán fun yín.

### الآية 7:69

> ﻿أَوَعَجِبْتُمْ أَنْ جَاءَكُمْ ذِكْرٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَلَىٰ رَجُلٍ مِنْكُمْ لِيُنْذِرَكُمْ ۚ وَاذْكُرُوا إِذْ جَعَلَكُمْ خُلَفَاءَ مِنْ بَعْدِ قَوْمِ نُوحٍ وَزَادَكُمْ فِي الْخَلْقِ بَسْطَةً ۖ فَاذْكُرُوا آلَاءَ اللَّهِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ [7:69]

Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí Wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín, nítorí kí ó lè kìlọ̀ fun yín? Ẹ rántí nígbà tí (Allāhu) fi yín ṣe àrólé lẹ́yìn ìjọ (Ànábì) Nūh. Ó tún ṣe àlékún agbára fun yín nínú ìṣẹ̀dá (yín). Nítorí náà, ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, nítorí kí ẹ lè jèrè."

### الآية 7:70

> ﻿قَالُوا أَجِئْتَنَا لِنَعْبُدَ اللَّهَ وَحْدَهُ وَنَذَرَ مَا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُنَا ۖ فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ [7:70]

Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí á lè jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo àti nítorí kí á lè pa ohun tí àwọn bàbá ńlá wa ń jọ́sìn fún tì? Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

### الآية 7:71

> ﻿قَالَ قَدْ وَقَعَ عَلَيْكُمْ مِنْ رَبِّكُمْ رِجْسٌ وَغَضَبٌ ۖ أَتُجَادِلُونَنِي فِي أَسْمَاءٍ سَمَّيْتُمُوهَا أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمْ مَا نَزَّلَ اللَّهُ بِهَا مِنْ سُلْطَانٍ ۚ فَانْتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُمْ مِنَ الْمُنْتَظِرِينَ [7:71]

Ó sọ pé: “Ìyà àti ìbínú kúkú ti sọ̀kalẹ̀ sórí yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣé ẹ óò máa jà mí níyàn nípa àwọn orúkọ (òrìṣà) kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fún lórúkọ - Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un? – Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”

### الآية 7:72

> ﻿فَأَنْجَيْنَاهُ وَالَّذِينَ مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَقَطَعْنَا دَابِرَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۖ وَمَا كَانُوا مُؤْمِنِينَ [7:72]

Nítorí náà, pẹ̀lú àánú láti ọ̀dọ̀ Wa, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là. A sì pa àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ run; wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 7:73

> ﻿وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا ۗ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ قَدْ جَاءَتْكُمْ بَيِّنَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ هَٰذِهِ نَاقَةُ اللَّهِ لَكُمْ آيَةً ۖ فَذَرُوهَا تَأْكُلْ فِي أَرْضِ اللَّهِ ۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ [7:73]

A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ìran Thamūd, arákùnrin wọn, Sọ̄lih. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín; èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. (Ó jẹ́) àmì kan fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ aburú kàn án nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baà jẹ yín.

### الآية 7:74

> ﻿وَاذْكُرُوا إِذْ جَعَلَكُمْ خُلَفَاءَ مِنْ بَعْدِ عَادٍ وَبَوَّأَكُمْ فِي الْأَرْضِ تَتَّخِذُونَ مِنْ سُهُولِهَا قُصُورًا وَتَنْحِتُونَ الْجِبَالَ بُيُوتًا ۖ فَاذْكُرُوا آلَاءَ اللَّهِ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ [7:74]

Ẹ tún rántí nígbà tí (Allāhu) ṣe yín ní àrólé lẹ́yìn àwọn ara ‘Ād. Ó sì fun yín ní ilé ìgbé lórí ilẹ̀; ẹ̀ ń kọ́ ilé ńláńlá sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àpáta. Ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, kí ẹ sì má ṣe rìn lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 7:75

> ﻿قَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا مِنْ قَوْمِهِ لِلَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا لِمَنْ آمَنَ مِنْهُمْ أَتَعْلَمُونَ أَنَّ صَالِحًا مُرْسَلٌ مِنْ رَبِّهِ ۚ قَالُوا إِنَّا بِمَا أُرْسِلَ بِهِ مُؤْمِنُونَ [7:75]

Àwọn àgbààgbà t’ó ṣègbéraga nínú ìjọ rẹ̀ wí fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín, (ìyẹn) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú wọn, pé: "Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé dájúdájú Sọ̄lih ni Òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán an níṣẹ́.”

### الآية 7:76

> ﻿قَالَ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا بِالَّذِي آمَنْتُمْ بِهِ كَافِرُونَ [7:76]

Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ẹ̀yin gbàgbọ́.”

### الآية 7:77

> ﻿فَعَقَرُوا النَّاقَةَ وَعَتَوْا عَنْ أَمْرِ رَبِّهِمْ وَقَالُوا يَا صَالِحُ ائْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِنْ كُنْتَ مِنَ الْمُرْسَلِينَ [7:77]

Nítorí náà, wọ́n gún abo ràkúnmí náà pa. Wọ́n sì tàpá sí àṣẹ Olúwa wọn. Wọ́n sì wí pé: “Sọ̄lih, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.”

### الآية 7:78

> ﻿فَأَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دَارِهِمْ جَاثِمِينَ [7:78]

Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.

### الآية 7:79

> ﻿فَتَوَلَّىٰ عَنْهُمْ وَقَالَ يَا قَوْمِ لَقَدْ أَبْلَغْتُكُمْ رِسَالَةَ رَبِّي وَنَصَحْتُ لَكُمْ وَلَٰكِنْ لَا تُحِبُّونَ النَّاصِحِينَ [7:79]

Nígbà náà, (Sọ̄lih) ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, mo kúkú ti jẹ́ iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mo sì ti fun yín ní ìmọ̀ràn rere ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ràn àwọn onímọ̀ràn rere.”

### الآية 7:80

> ﻿وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ أَتَأْتُونَ الْفَاحِشَةَ مَا سَبَقَكُمْ بِهَا مِنْ أَحَدٍ مِنَ الْعَالَمِينَ [7:80]

(Rántí Ànábì) Lūt, nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ óò máa ṣe ìbàjẹ́ ni tí kò sí ẹnì kan nínú àwọn ẹ̀dá t’ó ṣe irú rẹ̀ rí?

### الآية 7:81

> ﻿إِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الرِّجَالَ شَهْوَةً مِنْ دُونِ النِّسَاءِ ۚ بَلْ أَنْتُمْ قَوْمٌ مُسْرِفُونَ [7:81]

Dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) ń lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) dípò àwọn obìnrin! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni yín."

### الآية 7:82

> ﻿وَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَنْ قَالُوا أَخْرِجُوهُمْ مِنْ قَرْيَتِكُمْ ۖ إِنَّهُمْ أُنَاسٌ يَتَطَهَّرُونَ [7:82]

Kí sì ni ó jẹ́ èsì ìjọ rẹ̀ bí kò ṣe pé, wọ́n wí pé: “Ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ìlú yín, dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn kan t’ó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”

### الآية 7:83

> ﻿فَأَنْجَيْنَاهُ وَأَهْلَهُ إِلَّا امْرَأَتَهُ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ [7:83]

Nígbà náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.

### الآية 7:84

> ﻿وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ مَطَرًا ۖ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُجْرِمِينَ [7:84]

A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Wo bí ìkángun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí!

### الآية 7:85

> ﻿وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا ۗ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ قَدْ جَاءَتْكُمْ بَيِّنَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ فَأَوْفُوا الْكَيْلَ وَالْمِيزَانَ وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ بَعْدَ إِصْلَاحِهَا ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ [7:85]

(A tún rán ẹnì kan) sí àwọn ará Mọdyan, arákùnrin wọn, Ṣu‘aeb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ìyẹn sì lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 7:86

> ﻿وَلَا تَقْعُدُوا بِكُلِّ صِرَاطٍ تُوعِدُونَ وَتَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ مَنْ آمَنَ بِهِ وَتَبْغُونَهَا عِوَجًا ۚ وَاذْكُرُوا إِذْ كُنْتُمْ قَلِيلًا فَكَثَّرَكُمْ ۖ وَانْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ [7:86]

Ẹ má ṣe lúgọ sí gbogbo ọ̀nà láti máa dẹ́rùba àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń ṣẹ́rí ẹni t’ó gbagbọ́ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ẹ sì ń fẹ́ k’ó wọ́. Ẹ rántí o, nígbà tí ẹ kéré (lóǹkà), Allāhu sọ yín di púpọ̀. Ẹ sì wo bí ìkángun àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ṣe rí.

### الآية 7:87

> ﻿وَإِنْ كَانَ طَائِفَةٌ مِنْكُمْ آمَنُوا بِالَّذِي أُرْسِلْتُ بِهِ وَطَائِفَةٌ لَمْ يُؤْمِنُوا فَاصْبِرُوا حَتَّىٰ يَحْكُمَ اللَّهُ بَيْنَنَا ۚ وَهُوَ خَيْرُ الْحَاكِمِينَ [7:87]

Tí ó bá jẹ́ pé igun kan nínú yín gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́, tí igun kan kò sì gbàgbọ́, nígbà náà ẹ ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ láààrin wa. Òun sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.

### الآية 7:88

> ﻿۞ قَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا مِنْ قَوْمِهِ لَنُخْرِجَنَّكَ يَا شُعَيْبُ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَكَ مِنْ قَرْيَتِنَا أَوْ لَتَعُودُنَّ فِي مِلَّتِنَا ۚ قَالَ أَوَلَوْ كُنَّا كَارِهِينَ [7:88]

Àwọn àgbààgbà t’ó ṣègbéraga nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú a máa lé ìwọ Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ jáde kúrò nínú ìlú wa tàbí ẹ gbọ́dọ̀ padà sínú ẹ̀sìn wa.” (Ṣu‘aeb) sọ pé: "Ṣé (ẹ máa dá wa padà sínú ìbọ̀rìṣà) t’ó sì jẹ́ pé ẹ̀mí wa kọ̀ ọ́?"

### الآية 7:89

> ﻿قَدِ افْتَرَيْنَا عَلَى اللَّهِ كَذِبًا إِنْ عُدْنَا فِي مِلَّتِكُمْ بَعْدَ إِذْ نَجَّانَا اللَّهُ مِنْهَا ۚ وَمَا يَكُونُ لَنَا أَنْ نَعُودَ فِيهَا إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ رَبُّنَا ۚ وَسِعَ رَبُّنَا كُلَّ شَيْءٍ عِلْمًا ۚ عَلَى اللَّهِ تَوَكَّلْنَا ۚ رَبَّنَا افْتَحْ بَيْنَنَا وَبَيْنَ قَوْمِنَا بِالْحَقِّ وَأَنْتَ خَيْرُ الْفَاتِحِينَ [7:89]

Dájúdájú a ti dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tí a bá fi lè padà sínú ẹ̀sìn yín lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti yọ wá kúrò nínú rẹ̀. Àti pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti padà sínú rẹ̀ àfi tí Allāhu, Olúwa wa bá fẹ́. Olúwa wa gbòòrò tayọ gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú ìmọ̀. Allāhu l’a gbáralé. Olúwa wa, ṣe ìdájọ́ láààrin àwa àti ìjọ wa pẹ̀lú òdodo, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́."

### الآية 7:90

> ﻿وَقَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ قَوْمِهِ لَئِنِ اتَّبَعْتُمْ شُعَيْبًا إِنَّكُمْ إِذًا لَخَاسِرُونَ [7:90]

Àwọn àgbààgbà t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé Ṣu‘aeb, nígbà náà ẹ̀yin ti di ẹni òfò nìyẹn.”

### الآية 7:91

> ﻿فَأَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دَارِهِمْ جَاثِمِينَ [7:91]

Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Oríṣi ìyà méjì wọ̀nyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi jẹ ìjọ Ànábì Ṣu‘aeb ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām); ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì (sūrah Hūd; 11:94) àti ẹ̀ṣújò iná (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:189).

### الآية 7:92

> ﻿الَّذِينَ كَذَّبُوا شُعَيْبًا كَأَنْ لَمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۚ الَّذِينَ كَذَّبُوا شُعَيْبًا كَانُوا هُمُ الْخَاسِرِينَ [7:92]

Àwọn t’ó pe Ṣu‘aeb lópùrọ́ sì dà bí ẹni tí kò gbé nínú ìlú wọn rí; àwọn t’ó pe Ṣu‘aeb lópùrọ́ ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò.

### الآية 7:93

> ﻿فَتَوَلَّىٰ عَنْهُمْ وَقَالَ يَا قَوْمِ لَقَدْ أَبْلَغْتُكُمْ رِسَالَاتِ رَبِّي وَنَصَحْتُ لَكُمْ ۖ فَكَيْفَ آسَىٰ عَلَىٰ قَوْمٍ كَافِرِينَ [7:93]

Nítorí náà, (Ṣu‘aeb) ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, mo kúkú ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mo sì ti fun yín ní ìmọ̀ràn rere. Báwo ni èmi yóò ṣe tún máa banújẹ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”

### الآية 7:94

> ﻿وَمَا أَرْسَلْنَا فِي قَرْيَةٍ مِنْ نَبِيٍّ إِلَّا أَخَذْنَا أَهْلَهَا بِالْبَأْسَاءِ وَالضَّرَّاءِ لَعَلَّهُمْ يَضَّرَّعُونَ [7:94]

A ò rán Ànábì kan sí ìlú kan láì jẹ́ pé A fi ìpọ́njú àti ìnira kan àwọn ará ìlú náà nítorí kí wọ́n lè rawọ́-rasẹ̀ (sí Allāhu).

### الآية 7:95

> ﻿ثُمَّ بَدَّلْنَا مَكَانَ السَّيِّئَةِ الْحَسَنَةَ حَتَّىٰ عَفَوْا وَقَالُوا قَدْ مَسَّ آبَاءَنَا الضَّرَّاءُ وَالسَّرَّاءُ فَأَخَذْنَاهُمْ بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ [7:95]

Lẹ́yìn náà, A fi (ohun) rere rọ́pò aburú (fún wọn) títí wọ́n fi pọ̀ (lóǹkà àti lọ́rọ̀). Wọ́n sì wí pé: “Ọwọ́ ìnira àti ìdẹ̀ra kúkú ti kan àwọn bàbá wa rí.” Nítorí náà, A gbá wọn mú lójijì, wọn kò sì fura.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ, wọn kò gbàgbọ́ pé àìgbàgbọ́ l’ó kó ìparun bá àwọn bàbá wọn. Èrò-ọkàn wọn ni pé, bí ọ̀rọ̀ ilé ayé ṣe rí ni pé, ènìyàn máa jìyà, ó sì máa jọrọ̀. Èrò-ọkàn wọn yìí mú wọn won̄koko mọ́ ìbọ̀rìṣà. Àwọn náà sì di ẹni ìparun bíi tàwọn bàbá wọn.

### الآية 7:96

> ﻿وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْقُرَىٰ آمَنُوا وَاتَّقَوْا لَفَتَحْنَا عَلَيْهِمْ بَرَكَاتٍ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ وَلَٰكِنْ كَذَّبُوا فَأَخَذْنَاهُمْ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [7:96]

Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ará ìlú náà gbàgbọ́ lódodo ni, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), A ìbá ṣínà àwọn ìbùkún fún wọn láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n pe òdodo nírọ́. Nígbà náà, A mú wọn nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 7:97

> ﻿أَفَأَمِنَ أَهْلُ الْقُرَىٰ أَنْ يَأْتِيَهُمْ بَأْسُنَا بَيَاتًا وَهُمْ نَائِمُونَ [7:97]

Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní alẹ́ ni, nígbà tí wọ́n bá ń sùn lọ́wọ́?

### الآية 7:98

> ﻿أَوَأَمِنَ أَهْلُ الْقُرَىٰ أَنْ يَأْتِيَهُمْ بَأْسُنَا ضُحًى وَهُمْ يَلْعَبُونَ [7:98]

Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní ìyálẹ̀ta ni, nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré lọ́wọ́?

### الآية 7:99

> ﻿أَفَأَمِنُوا مَكْرَ اللَّهِ ۚ فَلَا يَأْمَنُ مَكْرَ اللَّهِ إِلَّا الْقَوْمُ الْخَاسِرُونَ [7:99]

Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu ni? Kò mà sí ẹni t’ó máa fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu àfi ìjọ olófò.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.

### الآية 7:100

> ﻿أَوَلَمْ يَهْدِ لِلَّذِينَ يَرِثُونَ الْأَرْضَ مِنْ بَعْدِ أَهْلِهَا أَنْ لَوْ نَشَاءُ أَصَبْنَاهُمْ بِذُنُوبِهِمْ ۚ وَنَطْبَعُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ [7:100]

Ṣé kò hàn sí àwọn t’ó jogún ilẹ̀ lẹ́yìn àwọn onílẹ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ ni), Àwa ìbá fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn mú wọn, Àwa ìbá sì fi èdídí bo ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́rọ̀ (mọ́).

### الآية 7:101

> ﻿تِلْكَ الْقُرَىٰ نَقُصُّ عَلَيْكَ مِنْ أَنْبَائِهَا ۚ وَلَقَدْ جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا كَانُوا لِيُؤْمِنُوا بِمَا كَذَّبُوا مِنْ قَبْلُ ۚ كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ الْكَافِرِينَ [7:101]

Àwọn ìlú wọ̀nyí ni À ń fún ọ ní ìró nínú ìròyìn wọn. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yánjú wá bá wọn. (Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ náà,) wọn kò kúkú níí gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ t’ó ṣíwájú wọn) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó ṣíwájú ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó tẹ̀lé wọn ṣe. Irú kan-ùn ni gbogbo wọn. Ìdí sì nìyí tí ìkọ̀ọ̀kan ìjọ aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn ṣe parun. Ẹ tún wo sūrah Yūnus; 10:74.

### الآية 7:102

> ﻿وَمَا وَجَدْنَا لِأَكْثَرِهِمْ مِنْ عَهْدٍ ۖ وَإِنْ وَجَدْنَا أَكْثَرَهُمْ لَفَاسِقِينَ [7:102]

Àwa kò rí pípé àdéhùn ní ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn. Àti pé ńṣe ni A rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ní òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 7:103

> ﻿ثُمَّ بَعَثْنَا مِنْ بَعْدِهِمْ مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَظَلَمُوا بِهَا ۖ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ [7:103]

Lẹ́yìn náà, A gbé (Ànábì) Mūsā dìde lẹ́yìn wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àbòsí sí àwọn àmì náà. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ṣe rí.

### الآية 7:104

> ﻿وَقَالَ مُوسَىٰ يَا فِرْعَوْنُ إِنِّي رَسُولٌ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ [7:104]

(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Fir‘aon, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 7:105

> ﻿حَقِيقٌ عَلَىٰ أَنْ لَا أَقُولَ عَلَى اللَّهِ إِلَّا الْحَقَّ ۚ قَدْ جِئْتُكُمْ بِبَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّكُمْ فَأَرْسِلْ مَعِيَ بَنِي إِسْرَائِيلَ [7:105]

Dandan ni fún mi pé èmi kò níí ṣàfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo. Mo sì kúkú ti mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá mi lọ."

### الآية 7:106

> ﻿قَالَ إِنْ كُنْتَ جِئْتَ بِآيَةٍ فَأْتِ بِهَا إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ [7:106]

(Fir‘aon) wí pé: “Tí o bá jẹ́ ẹni t’ó mú àmì kan wá, mú un jáde tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”

### الآية 7:107

> ﻿فَأَلْقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعْبَانٌ مُبِينٌ [7:107]

Nígbà náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.

### الآية 7:108

> ﻿وَنَزَعَ يَدَهُ فَإِذَا هِيَ بَيْضَاءُ لِلنَّاظِرِينَ [7:108]

Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ, ó sì di funfun (gbòlà) fún àwọn olùwòran.

### الآية 7:109

> ﻿قَالَ الْمَلَأُ مِنْ قَوْمِ فِرْعَوْنَ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ عَلِيمٌ [7:109]

Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.

### الآية 7:110

> ﻿يُرِيدُ أَنْ يُخْرِجَكُمْ مِنْ أَرْضِكُمْ ۖ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ [7:110]

Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni." (Fir‘aon wí pé: ) “Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?” 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:34.

### الآية 7:111

> ﻿قَالُوا أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَأَرْسِلْ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ [7:111]

Wọ́n sì wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú,

### الآية 7:112

> ﻿يَأْتُوكَ بِكُلِّ سَاحِرٍ عَلِيمٍ [7:112]

(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ."

### الآية 7:113

> ﻿وَجَاءَ السَّحَرَةُ فِرْعَوْنَ قَالُوا إِنَّ لَنَا لَأَجْرًا إِنْ كُنَّا نَحْنُ الْغَالِبِينَ [7:113]

Àwọn òpìdán sì dé wá bá Fir‘aon. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú ẹ̀san gbọ́dọ̀ wà fún wa tí àwa bá jẹ́ olùborí.”

### الآية 7:114

> ﻿قَالَ نَعَمْ وَإِنَّكُمْ لَمِنَ الْمُقَرَّبِينَ [7:114]

Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú ẹ̀yin gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”

### الآية 7:115

> ﻿قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِمَّا أَنْ تُلْقِيَ وَإِمَّا أَنْ نَكُونَ نَحْنُ الْمُلْقِينَ [7:115]

(Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, o máa (kọ́kọ́) ju ọ̀pá sílẹ̀ ni, tàbí àwa ni a máa (kọ́kọ́) jù ú sílẹ̀.”

### الآية 7:116

> ﻿قَالَ أَلْقُوا ۖ فَلَمَّا أَلْقَوْا سَحَرُوا أَعْيُنَ النَّاسِ وَاسْتَرْهَبُوهُمْ وَجَاءُوا بِسِحْرٍ عَظِيمٍ [7:116]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, wọ́n fi pidán lójú àwọn ènìyàn. Wọ́n sì ṣẹ̀rùbà wọ́n. Wọ́n wá pẹ̀lú idán ńlá.

### الآية 7:117

> ﻿۞ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَلْقِ عَصَاكَ ۖ فَإِذَا هِيَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ [7:117]

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” Nígbà náà, ó sì ń gbé ohun tí wọ́n ti pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.

### الآية 7:118

> ﻿فَوَقَعَ الْحَقُّ وَبَطَلَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [7:118]

Nítorí náà, òdodo dé. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì bàjẹ́.

### الآية 7:119

> ﻿فَغُلِبُوا هُنَالِكَ وَانْقَلَبُوا صَاغِرِينَ [7:119]

Nítorí náà, A borí wọn níbẹ̀ yẹn. Wọ́n sì darí wálé ní ẹni yẹpẹrẹ.

### الآية 7:120

> ﻿وَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سَاجِدِينَ [7:120]

Iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wólẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

### الآية 7:121

> ﻿قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ الْعَالَمِينَ [7:121]

Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,

### الآية 7:122

> ﻿رَبِّ مُوسَىٰ وَهَارُونَ [7:122]

Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn."

### الآية 7:123

> ﻿قَالَ فِرْعَوْنُ آمَنْتُمْ بِهِ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّ هَٰذَا لَمَكْرٌ مَكَرْتُمُوهُ فِي الْمَدِينَةِ لِتُخْرِجُوا مِنْهَا أَهْلَهَا ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ [7:123]

Fir‘aon wí pé: “Ẹ ti gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú èyí ni ète kan tí ẹ ti hun nínú ìlú nítorí kí ẹ lè kó àwọn ará ìlú jáde kúrò nínú rẹ̀. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

### الآية 7:124

> ﻿لَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُمْ مِنْ خِلَافٍ ثُمَّ لَأُصَلِّبَنَّكُمْ أَجْمَعِينَ [7:124]

Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”

### الآية 7:125

> ﻿قَالُوا إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنْقَلِبُونَ [7:125]

Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa sì ni a máa fàbọ̀ sí.

### الآية 7:126

> ﻿وَمَا تَنْقِمُ مِنَّا إِلَّا أَنْ آمَنَّا بِآيَاتِ رَبِّنَا لَمَّا جَاءَتْنَا ۚ رَبَّنَا أَفْرِغْ عَلَيْنَا صَبْرًا وَتَوَفَّنَا مُسْلِمِينَ [7:126]

Àti pé o ò tako kiní kan lára wa láti fìyà jẹ wá bí kò ṣe nítorí pé a gba àwọn àmì Olúwa wa gbọ́ nígbà tí ó dé bá wa. Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu. Kí O sì pa wá sípò mùsùlùmí."

### الآية 7:127

> ﻿وَقَالَ الْمَلَأُ مِنْ قَوْمِ فِرْعَوْنَ أَتَذَرُ مُوسَىٰ وَقَوْمَهُ لِيُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ وَيَذَرَكَ وَآلِهَتَكَ ۚ قَالَ سَنُقَتِّلُ أَبْنَاءَهُمْ وَنَسْتَحْيِي نِسَاءَهُمْ وَإِنَّا فَوْقَهُمْ قَاهِرُونَ [7:127]

Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: "Ṣé ìwọ yóò fi Mūsā àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti nítorí kí ó lè pa ìwọ àti àwọn òrìṣà rẹ tì?" (Fir‘aon) wí pé: "A óò máa pa àwọn ọmọkùnrin wọn ni. A ó sì máa dá àwọn ọmọbìnrin wọn sí. Dájúdájú àwa ni alágbára lórí wọn."

### الآية 7:128

> ﻿قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ اسْتَعِينُوا بِاللَّهِ وَاصْبِرُوا ۖ إِنَّ الْأَرْضَ لِلَّهِ يُورِثُهَا مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۖ وَالْعَاقِبَةُ لِلْمُتَّقِينَ [7:128]

(Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ fi Allāhu wá ìrànlọ́wọ́, kí ẹ sì ṣe sùúrù. Dájúdájú ti Allāhu ni ilẹ̀. Ó sì ń jogún rẹ̀ fún ẹni t’Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ìgbẹ̀yìn (rere) sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)."

### الآية 7:129

> ﻿قَالُوا أُوذِينَا مِنْ قَبْلِ أَنْ تَأْتِيَنَا وَمِنْ بَعْدِ مَا جِئْتَنَا ۚ قَالَ عَسَىٰ رَبُّكُمْ أَنْ يُهْلِكَ عَدُوَّكُمْ وَيَسْتَخْلِفَكُمْ فِي الْأَرْضِ فَيَنْظُرَ كَيْفَ تَعْمَلُونَ [7:129]

Wọ́n sọ pé: “Wọ́n ni wá láraṣíwájú kí o tó wá bá wa àti lẹ́yìn tí o dé bá wa.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò pa àwọn ọ̀tá yín run. Ó sì máa fi yín rọ́pò (wọn) lórí ilẹ̀. Nígbà náà, (Allāhu) yó sì wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.”

### الآية 7:130

> ﻿وَلَقَدْ أَخَذْنَا آلَ فِرْعَوْنَ بِالسِّنِينَ وَنَقْصٍ مِنَ الثَّمَرَاتِ لَعَلَّهُمْ يَذَّكَّرُونَ [7:130]

Dájúdájú A gbá ènìyàn Fir‘aon mú pẹ̀lú ọ̀dá òjò àti àdínkù t’ó bá àwọn èso nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

### الآية 7:131

> ﻿فَإِذَا جَاءَتْهُمُ الْحَسَنَةُ قَالُوا لَنَا هَٰذِهِ ۖ وَإِنْ تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ يَطَّيَّرُوا بِمُوسَىٰ وَمَنْ مَعَهُ ۗ أَلَا إِنَّمَا طَائِرُهُمْ عِنْدَ اللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [7:131]

Nígbà tí ohun rere bá dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Tiwa ni èyí.” Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á ṣàfitì aburú náà sọ́dọ̀ (Ànábì) Mūsā àti ẹni t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Kíyè sí i, àmì aburú wọn kúkú wà (nínú kádàrá wọn) lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.

### الآية 7:132

> ﻿وَقَالُوا مَهْمَا تَأْتِنَا بِهِ مِنْ آيَةٍ لِتَسْحَرَنَا بِهَا فَمَا نَحْنُ لَكَ بِمُؤْمِنِينَ [7:132]

Wọ́n sì wí pé: “Ohunkóhun tí o bá mú wá fún wa ní àmì láti fi pidán fún wa, àwa kò níí gbà ọ́ gbọ́.”

### الآية 7:133

> ﻿فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمُ الطُّوفَانَ وَالْجَرَادَ وَالْقُمَّلَ وَالضَّفَادِعَ وَالدَّمَ آيَاتٍ مُفَصَّلَاتٍ فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا مُجْرِمِينَ [7:133]

Nítorí náà, A sì fi ẹ̀kún omi, àwọn eṣú, àwọn kòkòrò iná, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti ẹ̀jẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àwọn àmì tí ń tẹ̀léra wọn, t’ó fojú hàn. Ńṣe ni wọ́n tún ṣègbéraga; wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 7:134

> ﻿وَلَمَّا وَقَعَ عَلَيْهِمُ الرِّجْزُ قَالُوا يَا مُوسَى ادْعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِنْدَكَ ۖ لَئِنْ كَشَفْتَ عَنَّا الرِّجْزَ لَنُؤْمِنَنَّ لَكَ وَلَنُرْسِلَنَّ مَعَكَ بَنِي إِسْرَائِيلَ [7:134]

Nígbà tí ìyà sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí, wọ́n wí pé: “Mūsā, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe fún ọ. Dájúdájú tí o bá fi lè gbé ìyà náà kúrò fún wa (pẹ̀lú àdúà rẹ), dájúdájú a máa gbà ọ́ gbọ́, dájúdájú a sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá ọ lọ.”

### الآية 7:135

> ﻿فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُمُ الرِّجْزَ إِلَىٰ أَجَلٍ هُمْ بَالِغُوهُ إِذَا هُمْ يَنْكُثُونَ [7:135]

Nígbà tí A gbé ìyà náà kúrò fún wọn fún àkókò kan tí wọn yóò lò (nínú ìṣẹ̀mí wọn), nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.

### الآية 7:136

> ﻿فَانْتَقَمْنَا مِنْهُمْ فَأَغْرَقْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ بِأَنَّهُمْ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَكَانُوا عَنْهَا غَافِلِينَ [7:136]

Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn, A sì tẹ̀ wọ́n rì sínú agbami odò nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.

### الآية 7:137

> ﻿وَأَوْرَثْنَا الْقَوْمَ الَّذِينَ كَانُوا يُسْتَضْعَفُونَ مَشَارِقَ الْأَرْضِ وَمَغَارِبَهَا الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا ۖ وَتَمَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ الْحُسْنَىٰ عَلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ بِمَا صَبَرُوا ۖ وَدَمَّرْنَا مَا كَانَ يَصْنَعُ فِرْعَوْنُ وَقَوْمُهُ وَمَا كَانُوا يَعْرِشُونَ [7:137]

A sì jogún àwọn ibùyọ òòrùn lórí ilẹ̀ ayé àti ibùwọ̀ òòrùn rẹ̀, tí A fi ìbùnkún sí, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fojú tínrín. Ọ̀rọ̀ Olúwa Rẹ, t’ó dára sì kò lé àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù. A sì pa ohun tí Fir‘aon àti ìjọ rẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé run.

### الآية 7:138

> ﻿وَجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتَوْا عَلَىٰ قَوْمٍ يَعْكُفُونَ عَلَىٰ أَصْنَامٍ لَهُمْ ۚ قَالُوا يَا مُوسَى اجْعَلْ لَنَا إِلَٰهًا كَمَا لَهُمْ آلِهَةٌ ۚ قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ تَجْهَلُونَ [7:138]

A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄‘īl la agbami odò já. Nígbà náà, wọ́n kọjá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n dúró ti àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì wí pé: “Mūsā, ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan.” (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni ìjọ aláìmọ̀kan. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nínú ẹ̀rí t’ó ń fi rinlẹ̀ pé iṣẹ́-ìyanu kì í sábà mú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn di onígbàgbọ́ òdodo ni āyah yìí wa. Ǹjẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì ìyanu tí àwọn ọmọ ’Isrọ’īl ti f’ojú ara wọn rí bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí wọ́n ti ń bọ̀ títí dé ibi tí wọ́n dé yìí, ṣé ó tún yẹ kí wọ́n máa bèèrè fún òrìṣà kan kan? Ṣé òrìṣà l’ó ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ bọ̀ ni tàbí Allāhu Alágbára? Nítorí náà, àwọn aláìmoore àti aláìníkan-ánṣe l’ó máa ń wá iṣẹ́ ìyanu kiri. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ti tó fún ẹni t’ó níkan-ánṣe. Ẹ wo sūrah Yūnus; 10 :96-97.

### الآية 7:139

> ﻿إِنَّ هَٰؤُلَاءِ مُتَبَّرٌ مَا هُمْ فِيهِ وَبَاطِلٌ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [7:139]

Dájúdájú àwọn wọ̀nyí máa parun lórí ohun tí wọ́n ń ṣe (yìí). Irọ́ sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”

### الآية 7:140

> ﻿قَالَ أَغَيْرَ اللَّهِ أَبْغِيكُمْ إِلَٰهًا وَهُوَ فَضَّلَكُمْ عَلَى الْعَالَمِينَ [7:140]

(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Ṣé kí èmi tún ba yín wá ọlọ́hun kan tí ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni? Òun l’Ó sì ṣe àjùlọ oore fun yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).

### الآية 7:141

> ﻿وَإِذْ أَنْجَيْنَاكُمْ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ ۖ يُقَتِّلُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُمْ بَلَاءٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَظِيمٌ [7:141]

(Ẹ rántí) nígbà tí A là yín lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, wọ́n ń pa àwọn ọmọkùnrin yín tààrà, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín."

### الآية 7:142

> ﻿۞ وَوَاعَدْنَا مُوسَىٰ ثَلَاثِينَ لَيْلَةً وَأَتْمَمْنَاهَا بِعَشْرٍ فَتَمَّ مِيقَاتُ رَبِّهِ أَرْبَعِينَ لَيْلَةً ۚ وَقَالَ مُوسَىٰ لِأَخِيهِ هَارُونَ اخْلُفْنِي فِي قَوْمِي وَأَصْلِحْ وَلَا تَتَّبِعْ سَبِيلَ الْمُفْسِدِينَ [7:142]

Àti pé A yan ọgbọ̀n òru fún (Ànábì) Mūsā. A tún fi mẹ́wàá kún un. Nítorí náà, àkókò (tí) Olúwa Rẹ̀ (yóò fi bá a sọ̀rọ̀ sì máa) parí ní òru ogójì. (Ànábì) Mūsā sọ fún arákùnrin rẹ̀, Hārūn, pé: “Rólé dè mí láààrin àwọn ènìyàn mi. Kí o máa ṣe àtúnṣe. Má sì ṣe tẹ̀lé ọ̀nà àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”

### الآية 7:143

> ﻿وَلَمَّا جَاءَ مُوسَىٰ لِمِيقَاتِنَا وَكَلَّمَهُ رَبُّهُ قَالَ رَبِّ أَرِنِي أَنْظُرْ إِلَيْكَ ۚ قَالَ لَنْ تَرَانِي وَلَٰكِنِ انْظُرْ إِلَى الْجَبَلِ فَإِنِ اسْتَقَرَّ مَكَانَهُ فَسَوْفَ تَرَانِي ۚ فَلَمَّا تَجَلَّىٰ رَبُّهُ لِلْجَبَلِ جَعَلَهُ دَكًّا وَخَرَّ مُوسَىٰ صَعِقًا ۚ فَلَمَّا أَفَاقَ قَالَ سُبْحَانَكَ تُبْتُ إِلَيْكَ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُؤْمِنِينَ [7:143]

Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un, Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó tají, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi.)
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.

### الآية 7:144

> ﻿قَالَ يَا مُوسَىٰ إِنِّي اصْطَفَيْتُكَ عَلَى النَّاسِ بِرِسَالَاتِي وَبِكَلَامِي فَخُذْ مَا آتَيْتُكَ وَكُنْ مِنَ الشَّاكِرِينَ [7:144]

(Allāhu) sọ pé: "Mūsā, dájúdájú Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Mi àti ọ̀rọ̀ Mi. Nítorí náà, gbá ohun tí Mo fún ọ mú. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́."

### الآية 7:145

> ﻿وَكَتَبْنَا لَهُ فِي الْأَلْوَاحِ مِنْ كُلِّ شَيْءٍ مَوْعِظَةً وَتَفْصِيلًا لِكُلِّ شَيْءٍ فَخُذْهَا بِقُوَّةٍ وَأْمُرْ قَوْمَكَ يَأْخُذُوا بِأَحْسَنِهَا ۚ سَأُرِيكُمْ دَارَ الْفَاسِقِينَ [7:145]

A sì kọ gbogbo n̄ǹkan fún un sínú àwọn wàláà. (Ó jẹ́) wáàsí àti àlàyé ọ̀rọ̀ fún gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣàmúlò rẹ̀ dáradára. Kí o sì pa ìjọ rẹ láṣẹ pé kí wọ́n ṣàmúlò n̄ǹkan dáadáa t’ó ń bẹ nínú rẹ̀. Èmi yóò fi ilé àwọn arúfin hàn yín. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ilé àwọn arúfin nínú āyah yìí lè jẹ́ ìlú àwọn ìjọ tí wọ́n ti parẹ́ ṣíwájú, èyí tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl yóò padà gbà kọjá lórí ìrìn-àjò wọn, ìyẹn bí ìlú àwọn ìjọ Ànábì Nūh, ìran ‘Ād àti ìran Thamūd. Kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lè mọ ìkángun àwọn arúfin. Bákàn náà, ilé àwọn arúfin nínú āyah yìí lè jẹ́ àbọ̀ àwọn arúfin ní ọ̀run. Èyí sì ni Iná.

### الآية 7:146

> ﻿سَأَصْرِفُ عَنْ آيَاتِيَ الَّذِينَ يَتَكَبَّرُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَإِنْ يَرَوْا كُلَّ آيَةٍ لَا يُؤْمِنُوا بِهَا وَإِنْ يَرَوْا سَبِيلَ الرُّشْدِ لَا يَتَّخِذُوهُ سَبِيلًا وَإِنْ يَرَوْا سَبِيلَ الْغَيِّ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلًا ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَكَانُوا عَنْهَا غَافِلِينَ [7:146]

Èmi yóò ṣẹ́rí àwọn t’ó ń ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ kúrò níbi àwọn àmì Mi. Tí wọ́n bá sì rí gbogbo àmì, wọn kò níí gbà á gbọ́. Tí wọ́n bá rí ọ̀nà ìmọ̀nà, wọn kò níí mú un ní ọ̀nà. Tí wọ́n bá sì rí ọ̀nà ìṣìnà, wọn yóò mú un ní ọ̀nà. Ìyẹn nítorí pé wọ́n pe àwọn àmì Wa nírọ́; wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.

### الآية 7:147

> ﻿وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَلِقَاءِ الْآخِرَةِ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ ۚ هَلْ يُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [7:147]

Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan ni bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́?

### الآية 7:148

> ﻿وَاتَّخَذَ قَوْمُ مُوسَىٰ مِنْ بَعْدِهِ مِنْ حُلِيِّهِمْ عِجْلًا جَسَدًا لَهُ خُوَارٌ ۚ أَلَمْ يَرَوْا أَنَّهُ لَا يُكَلِّمُهُمْ وَلَا يَهْدِيهِمْ سَبِيلًا ۘ اتَّخَذُوهُ وَكَانُوا ظَالِمِينَ [7:148]

Àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā, lẹ́yìn rẹ̀ (nígbà tí ó fi lọ bá Allāhu sọ̀rọ̀), wọ́n mú nínú ọ̀ṣọ́ wọn (láti fi ṣe) ère ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi, ó sì ń dún (bíi màálù). Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú kò lè bá wọn sọ̀rọ̀ ni, kò sì lè fi ọ̀nà mọ̀ wọ́n? Wọ́n sì sọ ọ́ di àkúnlẹ̀bọ. Wọ́n sì jẹ́ alábòsí.

### الآية 7:149

> ﻿وَلَمَّا سُقِطَ فِي أَيْدِيهِمْ وَرَأَوْا أَنَّهُمْ قَدْ ضَلُّوا قَالُوا لَئِنْ لَمْ يَرْحَمْنَا رَبُّنَا وَيَغْفِرْ لَنَا لَنَكُونَنَّ مِنَ الْخَاسِرِينَ [7:149]

Nígbà tí ó di àbámọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ tán, wọ́n sì rí i pé àwọn ti ṣìnà, wọ́n wí pé: “Tí Olúwa wa kò bá ṣàánú wa, kí Ó sì foríjìn wá, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn ẹni òfò.”

### الآية 7:150

> ﻿وَلَمَّا رَجَعَ مُوسَىٰ إِلَىٰ قَوْمِهِ غَضْبَانَ أَسِفًا قَالَ بِئْسَمَا خَلَفْتُمُونِي مِنْ بَعْدِي ۖ أَعَجِلْتُمْ أَمْرَ رَبِّكُمْ ۖ وَأَلْقَى الْأَلْوَاحَ وَأَخَذَ بِرَأْسِ أَخِيهِ يَجُرُّهُ إِلَيْهِ ۚ قَالَ ابْنَ أُمَّ إِنَّ الْقَوْمَ اسْتَضْعَفُونِي وَكَادُوا يَقْتُلُونَنِي فَلَا تُشْمِتْ بِيَ الْأَعْدَاءَ وَلَا تَجْعَلْنِي مَعَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ [7:150]

Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sì padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ fi rólé dè mí lẹ́yìn mi burú. Ṣé ẹ ti kánjú pa àṣẹ Olúwa yín tì ni?" Ó sì ju àwọn wàláà sílẹ̀, ó gbá orí arákùnrin rẹ̀ mú, ó sì ń wọ́ ọ mọ́ra. (Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi ò, dájúdájú àwọn ènìyàn ni wọ́n fojú tínrín mi, wọ́n sì fẹ́ẹ̀ pa mí. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ̀ mí. Má sì ṣe mú mi mọ́ ìjọ alábòsí.”

### الآية 7:151

> ﻿قَالَ رَبِّ اغْفِرْ لِي وَلِأَخِي وَأَدْخِلْنَا فِي رَحْمَتِكَ ۖ وَأَنْتَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ [7:151]

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, foríjin èmi àti arákùnrin mi. Kí O sì fi wá sínú ìkẹ́ Rẹ. Ìwọ sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

### الآية 7:152

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ اتَّخَذُوا الْعِجْلَ سَيَنَالُهُمْ غَضَبٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَذِلَّةٌ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُفْتَرِينَ [7:152]

Dájúdájú àwọn t’ó sọ (ère) ọmọ màálù di àkúnlẹ̀bọ, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àti ìyẹpẹrẹ yóò bá wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn aládapa irọ́ ní ẹ̀san.

### الآية 7:153

> ﻿وَالَّذِينَ عَمِلُوا السَّيِّئَاتِ ثُمَّ تَابُوا مِنْ بَعْدِهَا وَآمَنُوا إِنَّ رَبَّكَ مِنْ بَعْدِهَا لَغَفُورٌ رَحِيمٌ [7:153]

Àwọn t’ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ aburú, lẹ́yìn náà tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú lẹ́yìn èyí Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 7:154

> ﻿وَلَمَّا سَكَتَ عَنْ مُوسَى الْغَضَبُ أَخَذَ الْأَلْوَاحَ ۖ وَفِي نُسْخَتِهَا هُدًى وَرَحْمَةٌ لِلَّذِينَ هُمْ لِرَبِّهِمْ يَرْهَبُونَ [7:154]

Nígbà tí ìbínú (Ànábì) Mūsā sì wálẹ̀, ó mú àwọn wàláà náà. Ìmọ̀nà àti àánú ń bẹ nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù Olúwa wọn.

### الآية 7:155

> ﻿وَاخْتَارَ مُوسَىٰ قَوْمَهُ سَبْعِينَ رَجُلًا لِمِيقَاتِنَا ۖ فَلَمَّا أَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ قَالَ رَبِّ لَوْ شِئْتَ أَهْلَكْتَهُمْ مِنْ قَبْلُ وَإِيَّايَ ۖ أَتُهْلِكُنَا بِمَا فَعَلَ السُّفَهَاءُ مِنَّا ۖ إِنْ هِيَ إِلَّا فِتْنَتُكَ تُضِلُّ بِهَا مَنْ تَشَاءُ وَتَهْدِي مَنْ تَشَاءُ ۖ أَنْتَ وَلِيُّنَا فَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا ۖ وَأَنْتَ خَيْرُ الْغَافِرِينَ [7:155]

(Ànábì) Mūsā sì yan àádọ́rin ọkùnrin nínú ìjọ rẹ̀ fún àkókò tí A fún un (láti wá tọrọ àforíjìn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ibi àpáta Sīnā’), ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì sì gbá wọn mú, ó sọ pé: “Olúwa mi, tí O bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ ìbá ti pa àwọn àti èmi rẹ́ ṣíwájú (kí á tó wá síbí); ṣé Ìwọ yóò pa wá rẹ́ nítorí ohun tí àwọn òmùgọ̀ nínú wa ṣe ni? Kí ni ohun (tí wọ́n ṣe) bí kò ṣe àdánwò Rẹ; Ò ń fi ṣi ẹni tí O bá fẹ́ lọ́nà, O sì ń tọ́ ẹni tí O bá fẹ́ sọ́nà. Ìwọ ni Aláàbò wa. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn aláforíjìn.

### الآية 7:156

> ﻿۞ وَاكْتُبْ لَنَا فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الْآخِرَةِ إِنَّا هُدْنَا إِلَيْكَ ۚ قَالَ عَذَابِي أُصِيبُ بِهِ مَنْ أَشَاءُ ۖ وَرَحْمَتِي وَسِعَتْ كُلَّ شَيْءٍ ۚ فَسَأَكْتُبُهَا لِلَّذِينَ يَتَّقُونَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَالَّذِينَ هُمْ بِآيَاتِنَا يُؤْمِنُونَ [7:156]

Kí O sì kọ àkọsílẹ̀ rere fún wa ní ayé yìí àti ní ọ̀run. Dájúdájú àwa ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìyà Mi, Mo ń fi jẹ ẹni tí Mo bá fẹ́. Àti pé ìkẹ́ Mi gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ. Èmi yó sì kọ (ìkẹ́ Mi) mọ́ àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Mi), tí wọ́n sì ń yọ Zakāh àti àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn āyah Wa.”

### الآية 7:157

> ﻿الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الرَّسُولَ النَّبِيَّ الْأُمِّيَّ الَّذِي يَجِدُونَهُ مَكْتُوبًا عِنْدَهُمْ فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ يَأْمُرُهُمْ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَاهُمْ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُحِلُّ لَهُمُ الطَّيِّبَاتِ وَيُحَرِّمُ عَلَيْهِمُ الْخَبَائِثَ وَيَضَعُ عَنْهُمْ إِصْرَهُمْ وَالْأَغْلَالَ الَّتِي كَانَتْ عَلَيْهِمْ ۚ فَالَّذِينَ آمَنُوا بِهِ وَعَزَّرُوهُ وَنَصَرُوهُ وَاتَّبَعُوا النُّورَ الَّذِي أُنْزِلَ مَعَهُ ۙ أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [7:157]

Àwọn t’ó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa léèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn t’ó wúwo) àti àjàgà t’ó ń bẹ lọ́rùn wọn kúrò fún wọn; àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
"Àjàgà ọrùn wọn ni èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gbékọ́ ọrùn ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n wí pé “Dídì ni ọwọ́ Allāhu wà” gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’dah; 5:64." (Tọbariy)

### الآية 7:158

> ﻿قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ جَمِيعًا الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ النَّبِيِّ الْأُمِّيِّ الَّذِي يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَكَلِمَاتِهِ وَاتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ [7:158]

Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni t’Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà."

### الآية 7:159

> ﻿وَمِنْ قَوْمِ مُوسَىٰ أُمَّةٌ يَهْدُونَ بِالْحَقِّ وَبِهِ يَعْدِلُونَ [7:159]

Ó wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ìjọ kan t’ó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà. Wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:83-85.

### الآية 7:160

> ﻿وَقَطَّعْنَاهُمُ اثْنَتَيْ عَشْرَةَ أَسْبَاطًا أُمَمًا ۚ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ إِذِ اسْتَسْقَاهُ قَوْمُهُ أَنِ اضْرِبْ بِعَصَاكَ الْحَجَرَ ۖ فَانْبَجَسَتْ مِنْهُ اثْنَتَا عَشْرَةَ عَيْنًا ۖ قَدْ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٍ مَشْرَبَهُمْ ۚ وَظَلَّلْنَا عَلَيْهِمُ الْغَمَامَ وَأَنْزَلْنَا عَلَيْهِمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ ۖ كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ ۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ [7:160]

A sì pín wọn sí ìran méjìlá ní ìjọ-ìjọ. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wá omi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, pé: “Fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ na àpáta.” (Ó ṣe bẹ́ẹ̀) orísun omi méjìlá sì ṣẹ́yọ lára rẹ̀. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ti dá ibùmu wọn mọ̀. A tún fi ẹ̀ṣújò ṣíji bò wọ́n. A sọ (ohun mímu) mọ́nnù àti (ohun jíjẹ) salwā kalẹ̀ fun wọ́n. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín. Wọn kò sì ṣe àbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

### الآية 7:161

> ﻿وَإِذْ قِيلَ لَهُمُ اسْكُنُوا هَٰذِهِ الْقَرْيَةَ وَكُلُوا مِنْهَا حَيْثُ شِئْتُمْ وَقُولُوا حِطَّةٌ وَادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا نَغْفِرْ لَكُمْ خَطِيئَاتِكُمْ ۚ سَنَزِيدُ الْمُحْسِنِينَ [7:161]

(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí. Ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì sọ pé: ‘Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.’ Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba. A máa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.”

### الآية 7:162

> ﻿فَبَدَّلَ الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ قَوْلًا غَيْرَ الَّذِي قِيلَ لَهُمْ فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِجْزًا مِنَ السَّمَاءِ بِمَا كَانُوا يَظْلِمُونَ [7:162]

Àwọn t’ó ṣàbòsí kúkú yí ọ̀rọ̀ náà padà sí òmíràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. A sì sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ń ṣe àbòsí.

### الآية 7:163

> ﻿وَاسْأَلْهُمْ عَنِ الْقَرْيَةِ الَّتِي كَانَتْ حَاضِرَةَ الْبَحْرِ إِذْ يَعْدُونَ فِي السَّبْتِ إِذْ تَأْتِيهِمْ حِيتَانُهُمْ يَوْمَ سَبْتِهِمْ شُرَّعًا وَيَوْمَ لَا يَسْبِتُونَ ۙ لَا تَأْتِيهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ نَبْلُوهُمْ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ [7:163]

Bi wọ́n léèrè nípa ìlú t’ó wà ní ẹ̀bádò, nígbà tí wọ́n kọjá ẹnu-àlà nípa ọjọ́ Sabt, nígbà tí ẹja wọn ń wá bá wọn ní ọjọ́ Sabt wọn, wọ́n sì máa léfòó sí ojú odò, ọjọ́ tí kì í bá sì ṣe ọjọ́ Sabt wọn, wọn kò níí wá bá wọn. Báyẹn ni A ṣe ń dán wọn wò nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ọjọ́ Sabt ni ọjọ́ ìsinmi fún ìjọ náà.

### الآية 7:164

> ﻿وَإِذْ قَالَتْ أُمَّةٌ مِنْهُمْ لِمَ تَعِظُونَ قَوْمًا ۙ اللَّهُ مُهْلِكُهُمْ أَوْ مُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ قَالُوا مَعْذِرَةً إِلَىٰ رَبِّكُمْ وَلَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ [7:164]

(Rántí) nígbà tí ìjọ kan nínú wọn wí pé: “Nítorí kí ni ẹ fí ń ṣe wáàsí fún ìjọ kan tí Allāhu máa parẹ́ tàbí tí Ó máa jẹ níyà líle?” Wọ́n sọ pé: “(Kí ó lè jẹ́) àwáwí lọ́dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu) ni.”

### الآية 7:165

> ﻿فَلَمَّا نَسُوا مَا ذُكِّرُوا بِهِ أَنْجَيْنَا الَّذِينَ يَنْهَوْنَ عَنِ السُّوءِ وَأَخَذْنَا الَّذِينَ ظَلَمُوا بِعَذَابٍ بَئِيسٍ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ [7:165]

Nígbà tí wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n fi ṣèrántí fún wọn, A gba àwọn t’ó ń kọ aburú là. A sì fi ìyà t’ó le jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 7:166

> ﻿فَلَمَّا عَتَوْا عَنْ مَا نُهُوا عَنْهُ قُلْنَا لَهُمْ كُونُوا قِرَدَةً خَاسِئِينَ [7:166]

Nígbà tí wọ́n tayọ ẹnu-àlà níbi ohun tí A kọ̀ fún wọn, A sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni ìgbéjìnnà sí ìkẹ́.”

### الآية 7:167

> ﻿وَإِذْ تَأَذَّنَ رَبُّكَ لَيَبْعَثَنَّ عَلَيْهِمْ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ يَسُومُهُمْ سُوءَ الْعَذَابِ ۗ إِنَّ رَبَّكَ لَسَرِيعُ الْعِقَابِ ۖ وَإِنَّهُ لَغَفُورٌ رَحِيمٌ [7:167]

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ ọ́ di mímọ̀ pé dájúdájú Òun yóò gbé ẹni tí ó máa fi ìyà burúkú jẹ wọ́n dìde sí wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 7:168

> ﻿وَقَطَّعْنَاهُمْ فِي الْأَرْضِ أُمَمًا ۖ مِنْهُمُ الصَّالِحُونَ وَمِنْهُمْ دُونَ ذَٰلِكَ ۖ وَبَلَوْنَاهُمْ بِالْحَسَنَاتِ وَالسَّيِّئَاتِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ [7:168]

A pín wọn lórí ilẹ̀ sí ìjọ-ìjọ; àwọn ẹni rere wà nínú wọn, àwọn mìíràn tún wà nínú wọn. A sì fi àwọn ohun rere àti ohun burúkú dán wọn wò kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).

### الآية 7:169

> ﻿فَخَلَفَ مِنْ بَعْدِهِمْ خَلْفٌ وَرِثُوا الْكِتَابَ يَأْخُذُونَ عَرَضَ هَٰذَا الْأَدْنَىٰ وَيَقُولُونَ سَيُغْفَرُ لَنَا وَإِنْ يَأْتِهِمْ عَرَضٌ مِثْلُهُ يَأْخُذُوهُ ۚ أَلَمْ يُؤْخَذْ عَلَيْهِمْ مِيثَاقُ الْكِتَابِ أَنْ لَا يَقُولُوا عَلَى اللَّهِ إِلَّا الْحَقَّ وَدَرَسُوا مَا فِيهِ ۗ وَالدَّارُ الْآخِرَةُ خَيْرٌ لِلَّذِينَ يَتَّقُونَ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ [7:169]

Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn; wọ́n jogún Tírà (Taorāt àti ’Injīl), wọ́n sì ń gba (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) oore ilé ayé yìí (láti kọ ìkọkúkọ sínú rẹ̀), wọ́n sì ń wí pé: “Wọn yóò foríjìn wá.” Tí (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) oore irú rẹ̀ bá tún wá bá wọn, wọ́n máa gbà á. Ṣé A kò ti bá wọn ṣe àdéhùn nínú Tírà pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo? Wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀! Ilé ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

### الآية 7:170

> ﻿وَالَّذِينَ يُمَسِّكُونَ بِالْكِتَابِ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجْرَ الْمُصْلِحِينَ [7:170]

Àwọn t’ó ń mú Tírà lò dáradára, tí wọ́n ń kírun, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san àwọn t’ó ń ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ wọn) ráre.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:83-85

### الآية 7:171

> ﻿۞ وَإِذْ نَتَقْنَا الْجَبَلَ فَوْقَهُمْ كَأَنَّهُ ظُلَّةٌ وَظَنُّوا أَنَّهُ وَاقِعٌ بِهِمْ خُذُوا مَا آتَيْنَاكُمْ بِقُوَّةٍ وَاذْكُرُوا مَا فِيهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ [7:171]

(Rántí) nígbà tí A gbé àpáta ga sókè orí wọn, ó sì dà bí ibòji. Wọ́n sì lérò pé ó máa wó lu àwọn mọ́lẹ̀, (A sì sọ fún wọn pé): “Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáadáa, kí ẹ sì máa rántí ohun t’ó ń bẹ nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).”

### الآية 7:172

> ﻿وَإِذْ أَخَذَ رَبُّكَ مِنْ بَنِي آدَمَ مِنْ ظُهُورِهِمْ ذُرِّيَّتَهُمْ وَأَشْهَدَهُمْ عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ أَلَسْتُ بِرَبِّكُمْ ۖ قَالُوا بَلَىٰ ۛ شَهِدْنَا ۛ أَنْ تَقُولُوا يَوْمَ الْقِيَامَةِ إِنَّا كُنَّا عَنْ هَٰذَا غَافِلِينَ [7:172]

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ādam, Ó fa àrọ́mọdọ́mọ wọn jáde láti (ìbàdí ní) ẹ̀yìn (bàbá ńlá) wọn, Ó sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí lórí ara wọn pé: “Ṣé Èmi kọ́ ni Olúwa yín ni?” Wọ́n sọ pé: “Rárá – (Ìwọ ni Olúwa wa) - a jẹ́rìí sí i.” Nítorí kí ẹ má baà sọ ní Ọjọ́ Àjíǹdé pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa èyí."

### الآية 7:173

> ﻿أَوْ تَقُولُوا إِنَّمَا أَشْرَكَ آبَاؤُنَا مِنْ قَبْلُ وَكُنَّا ذُرِّيَّةً مِنْ بَعْدِهِمْ ۖ أَفَتُهْلِكُنَا بِمَا فَعَلَ الْمُبْطِلُونَ [7:173]

Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Àwọn bàbá wa ló kúkú bá Allāhu wá akẹgbẹ́ ṣíwájú (wa), àwa sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ lẹ́yìn wọn (ni a fi wò wọ́n kọ́ṣe pẹ̀lú àìmọ̀kan). Ṣé Ìwọ yóò pa wá run nítorí ohun tí àwọn t’ó ń tẹ̀lé irọ́ ṣe ni?”

### الآية 7:174

> ﻿وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ وَلَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ [7:174]

Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Wa, nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).

### الآية 7:175

> ﻿وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ الَّذِي آتَيْنَاهُ آيَاتِنَا فَانْسَلَخَ مِنْهَا فَأَتْبَعَهُ الشَّيْطَانُ فَكَانَ مِنَ الْغَاوِينَ [7:175]

Ka ìròyìn ẹni tí A fún ní àwọn āyah Wa fún wọn, tí ó yọra rẹ̀ sílẹ̀ níbi àwọn āyah náà. Nítorí náà, Èṣù tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ó sì wà nínú àwọn olùṣìnà.

### الآية 7:176

> ﻿وَلَوْ شِئْنَا لَرَفَعْنَاهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُ أَخْلَدَ إِلَى الْأَرْضِ وَاتَّبَعَ هَوَاهُ ۚ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ الْكَلْبِ إِنْ تَحْمِلْ عَلَيْهِ يَلْهَثْ أَوْ تَتْرُكْهُ يَلْهَثْ ۚ ذَٰلِكَ مَثَلُ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ فَاقْصُصِ الْقَصَصَ لَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ [7:176]

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.

### الآية 7:177

> ﻿سَاءَ مَثَلًا الْقَوْمُ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَأَنْفُسَهُمْ كَانُوا يَظْلِمُونَ [7:177]

Ìjọ tí ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, wọ́n burú ní àfiwé. Ara wọn sì ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

### الآية 7:178

> ﻿مَنْ يَهْدِ اللَّهُ فَهُوَ الْمُهْتَدِي ۖ وَمَنْ يُضْلِلْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ [7:178]

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì ṣì lọ́nà, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.

### الآية 7:179

> ﻿وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرًا مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ ۖ لَهُمْ قُلُوبٌ لَا يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لَا يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لَا يَسْمَعُونَ بِهَا ۚ أُولَٰئِكَ كَالْأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ [7:179]

Dájúdájú A ti dá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àlùjànnú fún iná Jahanamọ (nítorí pé) wọ́n ní ọkàn, wọn kò sì fi gbọ́ àgbọ́yé; wọ́n ní ojú, wọn kò sì fi ríran; wọ́n ní etí, wọn kò sì fi gbọ́ràn. Àwọn wọ̀nyẹn dà bí ẹran-ọ̀sìn. Wọ́n wulẹ̀ sọnù jùlọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni afọ́nú-fọ́ra.

### الآية 7:180

> ﻿وَلِلَّهِ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ فَادْعُوهُ بِهَا ۖ وَذَرُوا الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي أَسْمَائِهِ ۚ سَيُجْزَوْنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [7:180]

Ti Allāhu ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn t’ó ń yẹ̀ kúrò níbi àwọn orúkọ Rẹ̀ tì. A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹní tí ó ń yẹ̀ kúrò nínú àwọn orúkọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ẹni tí ó ń fi àwọn orúkọ òrìṣà, orúkọ àlùjànnú tàbí raohāniyah, orúkọ Jésù Kristi, orúkọ àwọn ṣeeu àti orúkọ àwọn mọlāika ṣàdúà dípò àwọn orúkọ Allāhu. Ẹní tí ó ń yẹ̀ kúrò nínú àwọn orúkọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún ni ẹni tí ó ń fi àwọn orúkọ t’ó lòdì sí ‘aƙidah ’Islām pe Allāhu tàbí ròyìn Rẹ̀. Ẹni tí ó bá ṣe ìwọ̀nyẹn ti di ẹlẹbọ ńlá. Ní òdodo ni pé, àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn t’ó ga jùlọ wà fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). A ò sì lè mọ gbogbo wọn tán nítorí pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi àwọn kan pamọ́ fún wa. Àmọ́ àkójá rẹ̀ ni pé, mùsùlùmí kò gbọ́dọ̀ pé Allāhu, kò sì gbọ́dọ̀ ròyìn Allāhu àyàfi pẹ̀lú àwọn orúkọ kan àti àwọn ìròyìn kan tí Allāhu fi pe ara Rẹ̀, tí Ó sì fi ròyìn ara Rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān àti èyí tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi pè É tàbí tí ó fi ròyìn Rẹ̀ (subhānahu wa ta'ālā).

### الآية 7:181

> ﻿وَمِمَّنْ خَلَقْنَا أُمَّةٌ يَهْدُونَ بِالْحَقِّ وَبِهِ يَعْدِلُونَ [7:181]

Ó wà nínú àwọn tí A dá, ìjọ kan t’ó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà, wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

### الآية 7:182

> ﻿وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا سَنَسْتَدْرِجُهُمْ مِنْ حَيْثُ لَا يَعْلَمُونَ [7:182]

Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò níí mọ̀.

### الآية 7:183

> ﻿وَأُمْلِي لَهُمْ ۚ إِنَّ كَيْدِي مَتِينٌ [7:183]

Èmi yóò lọ́ wọn lára. Dájúdájú ète Mi lágbára. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.

### الآية 7:184

> ﻿أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا ۗ مَا بِصَاحِبِهِمْ مِنْ جِنَّةٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا نَذِيرٌ مُبِينٌ [7:184]

Ṣé wọn kò ronú jinlẹ̀ ni? Kò sí wèrè kan kan lára ẹni wọn (ìyẹn, Ànábì s.a.w.). Ta sì ni bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.

### الآية 7:185

> ﻿أَوَلَمْ يَنْظُرُوا فِي مَلَكُوتِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا خَلَقَ اللَّهُ مِنْ شَيْءٍ وَأَنْ عَسَىٰ أَنْ يَكُونَ قَدِ اقْتَرَبَ أَجَلُهُمْ ۖ فَبِأَيِّ حَدِيثٍ بَعْدَهُ يُؤْمِنُونَ [7:185]

Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Gbólóhùn yìí "Nígbà náà, “hadīth wo” ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?" àti irú rẹ̀ t’ó wà nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:6, àwọn kan lérò pé ó ń túmọ̀ sí pé, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú hadīth Ànábì kan kan, áḿbọ̀sìbọ́sí pé a óò máa fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. 
Èsì: Wọ́n ti dojú ìtúmọ̀ āyah náà rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ pátápátá. Ní àkọ́kọ́ ná, ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ t’ó wà nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ba‘dahu” (lẹ́yìn rẹ̀) ń dúró fún n̄ǹkan méjì. Ìkíní: Ó dúró fún “ọjọ́ ikú àti ọjọ́ Àjíǹde”. Ìkejì: Ó ń dúró fún al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Tí ó bá dúró fún “ọjọ́ ikú àti ọjọ́ Àjíǹde”, ìtúmọ̀ gbólóhùn “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” máa túmọ̀ sí pé, “ọ̀rọ̀ wo nínú ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ ikú wọn bá dé tàbí lẹ́yìn tí ọjọ́ Àjíǹde bá ṣẹlẹ̀? Bí wọ́n bá padà gba ọ̀rọ̀ al-Ƙu’ān gbọ́ lọ́jọ́ ikú wọn tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde, kò lè wúlò fún wọn mọ́, kò sì lè rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ mọ́ nítorí pé, kò sí ìronúpìwàdà mọ́ tí ikú bá ti dé bá ẹ̀dá, kò sì sí ìronúpìwàdà mọ́ fún ẹ̀dá lọ́jọ́ Àjíǹde.” Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah yìí àti nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 nítorí pé, ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ikú ni gbólóhùn t’ó ṣíwájú nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Bákan náà, ọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó pe ọjọ́ Àjíǹde nírọ́ l’ó ṣíwájú gbólóhùn náà nínú sūrah al-Mursalāt.
Tí ó bá sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ náà ń dúró fún al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ gbólóhùn “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” máa túmọ̀ sí pé, ọ̀rọ̀ irọ́ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí al-Ƙur’ān ti mú ọ̀rọ̀ òdodo wá? Ṣé àwọn ìròrí ìgbà àìmọ́kan àti àwọn àṣà àìmọ́kan èyí tí ìran ẹnì kọ̀ọ̀kan jogún bá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá ńlá wọn tí wọn kì í ṣe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, ṣé àwọn ìròrí wọn àti àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọn ni wọn yóò máa lò lẹ́yìn al-Ƙur’ān? Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:6 nítorí pé gbólóhùn t’ó ṣíwájú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa bí al-Ƙur’ān ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ òdodo. Èyí wá túmọ̀ sí pé, bí ènìyàn kò bá gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ òdodo al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ irọ́ oríṣiríṣi l’ó máa kù ú kù tí ó máa gbàgbọ́ nínú rẹ̀. 
Nítorí náà, “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” kò fi ọ̀nà kan kan túmọ̀ sí pé kí á má gbàgbọ́ nínú hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹnikẹ́ni kò wulẹ̀ lè gbọ́ àgbọ́yé al-Ƙur’ān àfi pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwọn hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Tí ẹnì kan bá sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn hadīth Ànábì wa Muhammad t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, onítọ̀ún ti wọ ipò kèfèrí títí ó máa fi ronú pìwàdà.

### الآية 7:186

> ﻿مَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَلَا هَادِيَ لَهُ ۚ وَيَذَرُهُمْ فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ [7:186]

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un. (Allāhu) yó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.

### الآية 7:187

> ﻿يَسْأَلُونَكَ عَنِ السَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَاهَا ۖ قُلْ إِنَّمَا عِلْمُهَا عِنْدَ رَبِّي ۖ لَا يُجَلِّيهَا لِوَقْتِهَا إِلَّا هُوَ ۚ ثَقُلَتْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا تَأْتِيكُمْ إِلَّا بَغْتَةً ۗ يَسْأَلُونَكَ كَأَنَّكَ حَفِيٌّ عَنْهَا ۖ قُلْ إِنَّمَا عِلْمُهَا عِنْدَ اللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ [7:187]

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé ìgbà wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn Àkókò rẹ̀ àfi Òun. Ó ṣòro (láti mọ̀) fún àwọn ará sánmọ̀ àti ará ilẹ̀. Kò níí dé ba yín àfi lójijì.” Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè bí ẹni pé ìwọ nímọ̀ nípa rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.”

### الآية 7:188

> ﻿قُلْ لَا أَمْلِكُ لِنَفْسِي نَفْعًا وَلَا ضَرًّا إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ ۚ وَلَوْ كُنْتُ أَعْلَمُ الْغَيْبَ لَاسْتَكْثَرْتُ مِنَ الْخَيْرِ وَمَا مَسَّنِيَ السُّوءُ ۚ إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ [7:188]

Sọ pé: “Èmi kò ní agbára àǹfààní tàbí ìnira kan tí mo lè fi kan ara mi àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé mo ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, èmi ìbá ti kó ohun púpọ̀ jọ nínú oore ayé (sí ọ̀dọ̀ mi) àti pé aburú ayé ìbá tí kàn mí. Ta ni èmi bí kò ṣe olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.”

### الآية 7:189

> ﻿۞ هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَجَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا لِيَسْكُنَ إِلَيْهَا ۖ فَلَمَّا تَغَشَّاهَا حَمَلَتْ حَمْلًا خَفِيفًا فَمَرَّتْ بِهِ ۖ فَلَمَّا أَثْقَلَتْ دَعَوَا اللَّهَ رَبَّهُمَا لَئِنْ آتَيْتَنَا صَالِحًا لَنَكُونَنَّ مِنَ الشَّاكِرِينَ [7:189]

(Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó da yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Ó sì dá aya fún un láti ara rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ̀gbádùn ìgbépọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí ọkọ súnmọ́ ìyàwó rẹ̀, tí ó sì ru ẹrù (àtọ̀) fífúyẹ́. Ó sì rù ú kiri. Nígbà tí ó sì diwọ́ disẹ̀ sínú tán, àwọn méjèèjì pe Allāhu Olúwa wọn pé: “Tí O bá fún wa ni ọmọ rere (t’ó pé ní ẹ̀dá), dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”

### الآية 7:190

> ﻿فَلَمَّا آتَاهُمَا صَالِحًا جَعَلَا لَهُ شُرَكَاءَ فِيمَا آتَاهُمَا ۚ فَتَعَالَى اللَّهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ [7:190]

Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ta ni ọkọ àti ìyàwó nínú āyah yìí? Kí sì ni ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn? Àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pín sí méjì lórí ìbéèrè àkọ́kọ́. Igun kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām fi rinlẹ̀ pé Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) ni àwọn ọkọ àti ìyàwó tí āyah náà ń tọ́ka sí ní ìbámu sí āyah 189 t’ó síwájú. Igun kejì sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé āyah 189 t’ó síwájú ń tọ́ka sí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā), àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn ni āyah 190 ń tọ́ka sí. Wọ́n ní ìdí nìyí tí ọ̀rọ̀-ìṣe t’ó parí āyah 190 fi wá pẹ̀lú ẹ̀hun ọ̀pọ̀, èyí tí ó ń fi hàn pé tọkọ tìyàwó yẹn kò mọ ní ènìyàn méjì pèrè. Wọ́n fi kún un pé, ìbá jẹ́ pé Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí ni, ẹ̀hun èjì tí ó máa dúró fún ọ̀wọ́ àwọn méjèèjì nìkan ni kò bá parí āyah náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú āyah 189 t’ó ṣíwájú. 
Ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn ni sísọ ọmọ náà ni orúkọ tí ó fi àìmoore hàn sí Allāhu. Bí àpẹẹrẹ, kí Allāhu fún ènìyàn lọ́mọ, kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams, ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh, ‘abdur-Rahmọ̄n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 
Wàyí, wọ́n ṣe àfitì ìtàn kan sí ọ̀dọ̀ ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu). Ìtàn náà wà nínú àwọn tírà tafsīr kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ibn Kathīr ka ìtàn náà mọ́ ara ìtàn irọ́ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl. Àmọ́ ìtàn tí ẹnu kùn yìí kúkú ni àwọn tí wọ́n gbà pé Ànábì Ādam (alaehi sọlāt wa salām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallahu anhā) ni tọkọ tìyàwó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí rí mú lò láti fi túmọ̀ āyah náà. Kókó ìtàn náà ni pé, nígbà tí ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) lóyún, Èṣù wá ba á ní àwòrán ènìyàn, ó sì sọ fún un pé, “Tí kò bá fẹ́ bí àwòrán ẹranko lọ́mọ tàbí tí kò bá fẹ́ kí ọmọ náà kú ní òpóǹló, kí ó sọ ọmọ náà ní “ ‘abdul-hārith”. Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) kò dá a lóhùn, kò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀. Ó bí ọmọ. Ọmọ náà sì kú. Ó tún ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà kejì. Àmọ́ nígbà tí ó lóyún ìkẹta, kò fẹ́ kí ó kú. Wọ́n sì sọ ọmọ náà ní “ ‘abdul-hārith”! Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pè ní ẹbọ nítorí pé, wọ́n tẹ̀lé àṣẹ t’ó yapa sí àṣẹ Allāhu pé wọn kò gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Èṣù. Kì í ṣe pé wọ́n gbé ẹbọ fún Èṣù láti fi wá ààbò fún ọmọ náà. Láti ìgbà náà l’ó ti di èèwọ̀ pọ́nńbélé nínú ìlànà ìsọmọlórúkọ láti ṣe àfitì “ẹrú” sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn lẹ́yìn Allāhu. Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí bí àwọn méjèèjì ṣe tẹ̀lé àṣẹ Èṣù níbi sísọ ọmọ wọn ní orúkọ tí Èṣù mú wá fún wọn, kì í ṣe pé wọ́n bímọ tán wọ́n wá ń bọ Èṣù bí àwọn kan ṣe máa ń bọ ìbejì. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì tẹ́wọ́ gba ìronùpìwàdà wọn. 
Tí àwọn kristiẹni bá wá tàbùkù Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) nípa èyí, ṣebí Jésù tẹ̀lé àṣẹ Èṣù ni Èṣù fi rí òun náà mú lọ káàkiri láti dán olúwa wọn wò! Jésù Kristi kúkú tẹ̀lé àṣẹ Èsù nínú àwọn bíbélì, àmọ́ kò forí balẹ̀ fún Èṣù rárá. Ìyẹn wà nínú ìwé Luku 4: 1-13. Nítorí náà, Allāhu nìkan ṣoṣo ni kò lè ṣàṣìṣe.

### الآية 7:191

> ﻿أَيُشْرِكُونَ مَا لَا يَخْلُقُ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ [7:191]

Ṣé wọn yóò sọ n̄ǹkan tí kò lè dá n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ Rẹ̀, A sì ṣẹ̀dá wọn ni?

### الآية 7:192

> ﻿وَلَا يَسْتَطِيعُونَ لَهُمْ نَصْرًا وَلَا أَنْفُسَهُمْ يَنْصُرُونَ [7:192]

Àwọn òrìṣà kò lè ṣe àrànṣe kan fún àwọn abọ̀rìṣà. Àti pé àwọn òrìṣà gan-an kò lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n.

### الآية 7:193

> ﻿وَإِنْ تَدْعُوهُمْ إِلَى الْهُدَىٰ لَا يَتَّبِعُوكُمْ ۚ سَوَاءٌ عَلَيْكُمْ أَدَعَوْتُمُوهُمْ أَمْ أَنْتُمْ صَامِتُونَ [7:193]

Tí ẹ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, wọn kò níí tẹ̀lé yín. Bákan náà ni fun yín; ẹ pè wọ́n tàbí ẹ̀yin dákẹ́ ẹnu (fún wọn).

### الآية 7:194

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ عِبَادٌ أَمْثَالُكُمْ ۖ فَادْعُوهُمْ فَلْيَسْتَجِيبُوا لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ [7:194]

Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹrú bí irú yin ni wọ́n. Nítorí náà, ẹ pè wọ́n wò, kí wọ́n da yín lóhùn tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

### الآية 7:195

> ﻿أَلَهُمْ أَرْجُلٌ يَمْشُونَ بِهَا ۖ أَمْ لَهُمْ أَيْدٍ يَبْطِشُونَ بِهَا ۖ أَمْ لَهُمْ أَعْيُنٌ يُبْصِرُونَ بِهَا ۖ أَمْ لَهُمْ آذَانٌ يَسْمَعُونَ بِهَا ۗ قُلِ ادْعُوا شُرَكَاءَكُمْ ثُمَّ كِيدُونِ فَلَا تُنْظِرُونِ [7:195]

Ṣé wọ́n ní ẹsẹ̀ tí wọ́n lè fi rìn ni? Tàbí ṣé wọ́n ní ọwọ́ tí wọ́n lè fi gbá n̄ǹkan mú? Tàbí ṣé wọ́n ní ojú tí wọ́n lè fi ríran? Tàbí ṣé wọ́n ní etí tí wọ́n lè fi gbọ́rọ̀? Sọ pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín, lẹ́yìn náà kí ẹ déte sí mi, kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára.

### الآية 7:196

> ﻿إِنَّ وَلِيِّيَ اللَّهُ الَّذِي نَزَّلَ الْكِتَابَ ۖ وَهُوَ يَتَوَلَّى الصَّالِحِينَ [7:196]

Dájúdájú Alátìlẹ́yìn mi ni Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà náà kalẹ̀. Àti pé Òun l’Ó ń ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn ẹni rere.

### الآية 7:197

> ﻿وَالَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَكُمْ وَلَا أَنْفُسَهُمْ يَنْصُرُونَ [7:197]

Àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe àrànṣe fun yín. Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n.

### الآية 7:198

> ﻿وَإِنْ تَدْعُوهُمْ إِلَى الْهُدَىٰ لَا يَسْمَعُوا ۖ وَتَرَاهُمْ يَنْظُرُونَ إِلَيْكَ وَهُمْ لَا يُبْصِرُونَ [7:198]

Tí ẹ bá sì pè wọ́n sínú ìmọ̀nà, wọn kò níí gbọ́. Ò ń rí wọn pé wọ́n ń wò ọ́ ni, (ṣùgbọ́n) wọn kò ríran.

### الآية 7:199

> ﻿خُذِ الْعَفْوَ وَأْمُرْ بِالْعُرْفِ وَأَعْرِضْ عَنِ الْجَاهِلِينَ [7:199]

Ṣàmójúkúrò, pàṣẹ ohun rere, kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìmọ̀kan.

### الآية 7:200

> ﻿وَإِمَّا يَنْزَغَنَّكَ مِنَ الشَّيْطَانِ نَزْغٌ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ ۚ إِنَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ [7:200]

Tí ìbínú òdì kan bá sì ṣẹ́rí sínú ọkàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èṣù, sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ní Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 7:201

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ اتَّقَوْا إِذَا مَسَّهُمْ طَائِفٌ مِنَ الشَّيْطَانِ تَذَكَّرُوا فَإِذَا هُمْ مُبْصِرُونَ [7:201]

Dájúdájú àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu), nígbà tí ròyíròyí kan bá ṣẹlẹ̀ sí wọn láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí wọ́n bá rántí (Allāhu), nígbà náà ojú wọn yó sì ríran (rí òdodo).

### الآية 7:202

> ﻿وَإِخْوَانُهُمْ يَمُدُّونَهُمْ فِي الْغَيِّ ثُمَّ لَا يُقْصِرُونَ [7:202]

(Àmọ́ ní ti) àwọn ọmọ ìyá (Èṣù), ńṣe ni àwọn Èṣù yóò máa kún wọn lọ́wọ́ nínú ìṣìnà. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dáràn mọ níwọ̀n.

### الآية 7:203

> ﻿وَإِذَا لَمْ تَأْتِهِمْ بِآيَةٍ قَالُوا لَوْلَا اجْتَبَيْتَهَا ۚ قُلْ إِنَّمَا أَتَّبِعُ مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ مِنْ رَبِّي ۚ هَٰذَا بَصَائِرُ مِنْ رَبِّكُمْ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ [7:203]

Nígbà tí o ò bá mú àmì wá bá wọn, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kò ṣe ṣe àdáhun rẹ̀?” Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi ni mò ń tẹ̀lé. (al-Ƙur’ān) yìí sì ni àwọn ẹ̀rí t’ó dájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ sì ni fún àwọn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 7:204

> ﻿وَإِذَا قُرِئَ الْقُرْآنُ فَاسْتَمِعُوا لَهُ وَأَنْصِتُوا لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ [7:204]

Nígbà tí wọ́n ba ń ke al-Ƙur’ān, ẹ tẹ́tí sí i, kí ẹ sì dákẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín.

### الآية 7:205

> ﻿وَاذْكُرْ رَبَّكَ فِي نَفْسِكَ تَضَرُّعًا وَخِيفَةً وَدُونَ الْجَهْرِ مِنَ الْقَوْلِ بِالْغُدُوِّ وَالْآصَالِ وَلَا تَكُنْ مِنَ الْغَافِلِينَ [7:205]

Ṣe ìrántí Olúwa Rẹ nínú ẹ̀mí rẹ pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ìbẹ̀rù (Allāhu), kò sì níí jẹ́ ọ̀rọ̀ ariwo, ní òwúrọ̀ àti àṣálẹ́. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn olùgbàgbéra (nípa ìrántí Allāhu).

### الآية 7:206

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ عِنْدَ رَبِّكَ لَا يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِهِ وَيُسَبِّحُونَهُ وَلَهُ يَسْجُدُونَ ۩ [7:206]

Dájúdájú àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, wọn kì í jọra wọn lójú láti jọ́sìn fún Un. Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ fún Un.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/7.md)
- [كل تفاسير سورة الأعراف
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/7.md)
- [ترجمات سورة الأعراف
](https://quranpedia.net/translations/7.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/7/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
