---
title: "ترجمة سورة الجن - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/72/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/72/book/2001"
surah_id: "72"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الجن - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/72/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الجن - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/72/book/2001*.

Translation of Surah الجن from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 72:1

> قُلْ أُوحِيَ إِلَيَّ أَنَّهُ اسْتَمَعَ نَفَرٌ مِنَ الْجِنِّ فَقَالُوا إِنَّا سَمِعْنَا قُرْآنًا عَجَبًا [72:1]

Sọ pé: "Wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé dájúdájú ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú tẹ́tí (sí al-Ƙur’ān)." Wọ́n sì sọ pé: "Dájúdájú àwa gbọ́ al-Ƙur’ān ìyanu.

### الآية 72:2

> ﻿يَهْدِي إِلَى الرُّشْدِ فَآمَنَّا بِهِ ۖ وَلَنْ نُشْرِكَ بِرَبِّنَا أَحَدًا [72:2]

Ó ń ṣètọ́sọ́nà síbi ìmọ̀nà. Nítorí náà, a gbà á gbọ́. Àwa kò sì níí fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa wa.

### الآية 72:3

> ﻿وَأَنَّهُ تَعَالَىٰ جَدُّ رَبِّنَا مَا اتَّخَذَ صَاحِبَةً وَلَا وَلَدًا [72:3]

Àti pé dájúdájú títóbi Olúwa wa ga. Kò fi ẹnì kan kan ṣe aya àti ọmọ.

### الآية 72:4

> ﻿وَأَنَّهُ كَانَ يَقُولُ سَفِيهُنَا عَلَى اللَّهِ شَطَطًا [72:4]

Dájúdájú òmùgọ̀ nínú wa máa ń sọ ìsọkúsọ nípa Allāhu.

### الآية 72:5

> ﻿وَأَنَّا ظَنَنَّا أَنْ لَنْ تَقُولَ الْإِنْسُ وَالْجِنُّ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا [72:5]

Dájúdájú àwa sì ń rò pé ènìyàn àti àlùjànnú kò níí pa irọ́ mọ́ Allāhu ni.

### الآية 72:6

> ﻿وَأَنَّهُ كَانَ رِجَالٌ مِنَ الْإِنْسِ يَعُوذُونَ بِرِجَالٍ مِنَ الْجِنِّ فَزَادُوهُمْ رَهَقًا [72:6]

Àti pé dájúdájú àwọn ọkùnrin kan nínú ènìyàn máa ń fi àwọn ọkùnrin kan nínú àwọn àlùjànnú wá ààbò. Àwọn àlùjànnú sì ṣe àlékún aburú fún wọn.

### الآية 72:7

> ﻿وَأَنَّهُمْ ظَنُّوا كَمَا ظَنَنْتُمْ أَنْ لَنْ يَبْعَثَ اللَّهُ أَحَدًا [72:7]

Dájúdájú àwọn àlùjànnú lérò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ènìyàn náà ṣe lérò pé Allāhu kò níí gbé ẹnì kan kan dìde (lẹ́yìn ikú).

### الآية 72:8

> ﻿وَأَنَّا لَمَسْنَا السَّمَاءَ فَوَجَدْنَاهَا مُلِئَتْ حَرَسًا شَدِيدًا وَشُهُبًا [72:8]

Dájúdájú àwa wá (ọ̀rọ̀ àyọ́gbọ́) wá sí sánmọ̀, a sì bá a tí ó ti kún fún àwọn ẹ̀ṣọ́ t’ó lágbára àti àwọn ògúnná.

### الآية 72:9

> ﻿وَأَنَّا كُنَّا نَقْعُدُ مِنْهَا مَقَاعِدَ لِلسَّمْعِ ۖ فَمَنْ يَسْتَمِعِ الْآنَ يَجِدْ لَهُ شِهَابًا رَصَدًا [72:9]

Dájúdájú àwa máa ń jókòó síbẹ̀ ní àwọn ibùdó kan fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni t’ó bá jọ́rọ̀ gbọ́ lásìkò yìí, ó máa rí ògúnná t’ó ti lúgọ dè é.

### الآية 72:10

> ﻿وَأَنَّا لَا نَدْرِي أَشَرٌّ أُرِيدَ بِمَنْ فِي الْأَرْضِ أَمْ أَرَادَ بِهِمْ رَبُّهُمْ رَشَدًا [72:10]

Dájúdájú àwa kò sì mọ̀ bóyá aburú ni wọ́n gbà lérò pẹ̀lú àwọn t’ó wà lórí ilẹ̀ tàbí Olúwa wọn gbèrò ìmọ̀nà fún wọn.

### الآية 72:11

> ﻿وَأَنَّا مِنَّا الصَّالِحُونَ وَمِنَّا دُونَ ذَٰلِكَ ۖ كُنَّا طَرَائِقَ قِدَدًا [72:11]

Dájúdájú àwọn ẹni rere wà nínú wa. Àwọn mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn tún wà nínú wa. A wà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

### الآية 72:12

> ﻿وَأَنَّا ظَنَنَّا أَنْ لَنْ نُعْجِزَ اللَّهَ فِي الْأَرْضِ وَلَنْ نُعْجِزَهُ هَرَبًا [72:12]

Dájúdájú àwa mọ àmọ̀dájú pé àwa kò lè mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Àwa kò sì lè sá mọ́ Ọn lọ́wọ́.

### الآية 72:13

> ﻿وَأَنَّا لَمَّا سَمِعْنَا الْهُدَىٰ آمَنَّا بِهِ ۖ فَمَنْ يُؤْمِنْ بِرَبِّهِ فَلَا يَخَافُ بَخْسًا وَلَا رَهَقًا [72:13]

Dájúdájú nígbà tí a gbọ́ nípa ìmọ̀nà (láti inú al-Ƙur’ān), a gbà á gbọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Olúwa rẹ̀ gbọ́, kí ó má bẹ̀rù àdínkù (ẹ̀san rere) àti (àlékún) aburú. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, wọn kò níí dín ẹ̀san iṣẹ́ rere onígbàgbọ́ òdodo kù, wọn kò sì níí fi kún àṣìṣe rẹ̀. Àti pé, àforíjìn Allāhu súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí lórí àwọn àṣìṣe náà.

### الآية 72:14

> ﻿وَأَنَّا مِنَّا الْمُسْلِمُونَ وَمِنَّا الْقَاسِطُونَ ۖ فَمَنْ أَسْلَمَ فَأُولَٰئِكَ تَحَرَّوْا رَشَدًا [72:14]

Dájúdájú àwọn mùsùlùmí wà nínú wa. Àwọn arúfin náà wà nínú wa. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ’Islām, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣe àwárí ìmọ̀nà."

### الآية 72:15

> ﻿وَأَمَّا الْقَاسِطُونَ فَكَانُوا لِجَهَنَّمَ حَطَبًا [72:15]

Ní ti àwọn arúfin, àwọn ni wọ́n máa jẹ́ igi ìkoná fún iná Jahanamọ.”

### الآية 72:16

> ﻿وَأَنْ لَوِ اسْتَقَامُوا عَلَى الطَّرِيقَةِ لَأَسْقَيْنَاهُمْ مَاءً غَدَقًا [72:16]

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n dúró ṣinṣin lójú ọ̀nà (’Islām) ni, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní omi púpọ̀ mu.

### الآية 72:17

> ﻿لِنَفْتِنَهُمْ فِيهِ ۚ وَمَنْ يُعْرِضْ عَنْ ذِكْرِ رَبِّهِ يَسْلُكْهُ عَذَابًا صَعَدًا [72:17]

Nítorí kí Á lè fi dán wọn wò ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa rẹ̀, Ó máa mú un wọ inú ìyà ìnira.

### الآية 72:18

> ﻿وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللَّهِ أَحَدًا [72:18]

Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nínú ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí kalmọh “mọsājid” dúró fún àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ni iwájú orí àti góńgórí imú, àtẹ́lẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì àti orí ọmọníkasẹ̀ méjéèjì. Èèwọ̀ ni fún ẹ̀dá lati fi ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ wọ̀nyí jọ́sìn tàbí kí ẹnikẹ́ni. Sa‘īd ọmọ Jubaer sọ pé, “Wọ́n sọ āyah yìí kalẹ̀ nípa àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni pé, dájúdájú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ má lò wọ́n láti fi jọ́sìn fún ẹlòmíìràn lẹ́yìn Allāhu.” (Tafsīr Ibn Kathīr) Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:34.

### الآية 72:19

> ﻿وَأَنَّهُ لَمَّا قَامَ عَبْدُ اللَّهِ يَدْعُوهُ كَادُوا يَكُونُونَ عَلَيْهِ لِبَدًا [72:19]

Dájúdájú nígbà tí ẹrúsìn Allāhu dìde dúró t’ó ń pe Allāhu, àwọn àlùjànnú fẹ́ẹ̀ máa dìfún-ùn-ùnfún lọ́dọ̀ rẹ̀ (láti tẹ́tí sí al-Ƙur’ān).

### الآية 72:20

> ﻿قُلْ إِنَّمَا أَدْعُو رَبِّي وَلَا أُشْرِكُ بِهِ أَحَدًا [72:20]

Sọ pé: "Olúwa mi ni mò ń pè. Àti pé èmi kò níí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Un."

### الآية 72:21

> ﻿قُلْ إِنِّي لَا أَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا رَشَدًا [72:21]

Sọ pé: "Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fun yín."

### الآية 72:22

> ﻿قُلْ إِنِّي لَنْ يُجِيرَنِي مِنَ اللَّهِ أَحَدٌ وَلَنْ أَجِدَ مِنْ دُونِهِ مُلْتَحَدًا [72:22]

Sọ pé: "Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan t’ó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀.

### الآية 72:23

> ﻿إِلَّا بَلَاغًا مِنَ اللَّهِ وَرِسَالَاتِهِ ۚ وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَإِنَّ لَهُ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا [72:23]

Àfi (kí n̄g ṣe) ìkédé (t’ó wá) láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ (t’Ó fi rán mi). Ẹnikẹ́ni t’ó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ń bẹ fún un. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé.

### الآية 72:24

> ﻿حَتَّىٰ إِذَا رَأَوْا مَا يُوعَدُونَ فَسَيَعْلَمُونَ مَنْ أَضْعَفُ نَاصِرًا وَأَقَلُّ عَدَدًا [72:24]

(Aláìgbàgbọ́ kò níí yé ṣàì gbàgbọ́) títí di ìgbà tí wọ́n yóò fi rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. Nígbà náà, wọn yóò mọ ta ni ó lẹ jùlọ ní alárànṣe, tí ó sì kéré jùlọ ní òǹkà.

### الآية 72:25

> ﻿قُلْ إِنْ أَدْرِي أَقَرِيبٌ مَا تُوعَدُونَ أَمْ يَجْعَلُ لَهُ رَبِّي أَمَدًا [72:25]

Sọ pé: "Èmi kò mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín ti súnmọ́ tàbí Olúwa mi yóò fún un ní àkókò (t’ó jìnnà).

### الآية 72:26

> ﻿عَالِمُ الْغَيْبِ فَلَا يُظْهِرُ عَلَىٰ غَيْبِهِ أَحَدًا [72:26]

Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan

### الآية 72:27

> ﻿إِلَّا مَنِ ارْتَضَىٰ مِنْ رَسُولٍ فَإِنَّهُ يَسْلُكُ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ رَصَدًا [72:27]

àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà t’ó jẹ́ Òjísẹ́. Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀ 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i, nígbà tí a bá sọ fún àáfà t’ó ń woṣẹ́ pé, “kò lè rí ìkọ̀kọ̀ kan kan wò nínú ohun t’ó pamọ́ fún ẹ̀dá.” Ó máa sọ pé, “ṣebí òjíṣẹ́ ni òun. Òun lè rí ìkọ̀kọ̀ nígbà náà.” Ẹ má ṣe jẹ́ kí ó tàn yín jẹ. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì àti òpin àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sí àáfà kan kan tí Allāhu ń fi iṣẹ́ ìmísí rán mọ́. Èṣù àlùjànnú ni àwọn àáfà t’ó ń woṣẹ́ bá dòwò pọ̀. Òjíṣẹ́ àlùjànnú ni irú wọn, wọn kì í ṣe “òjíṣẹ́ Ọlọ́hun”.

### الآية 72:28

> ﻿لِيَعْلَمَ أَنْ قَدْ أَبْلَغُوا رِسَالَاتِ رَبِّهِمْ وَأَحَاطَ بِمَا لَدَيْهِمْ وَأَحْصَىٰ كُلَّ شَيْءٍ عَدَدًا [72:28]

nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/72.md)
- [كل تفاسير سورة الجن
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/72.md)
- [ترجمات سورة الجن
](https://quranpedia.net/translations/72.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/72/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
