---
title: "ترجمة سورة الإنسان - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/76/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/76/book/2001"
surah_id: "76"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الإنسان - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/76/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الإنسان - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/76/book/2001*.

Translation of Surah الإنسان from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 76:1

> هَلْ أَتَىٰ عَلَى الْإِنْسَانِ حِينٌ مِنَ الدَّهْرِ لَمْ يَكُنْ شَيْئًا مَذْكُورًا [76:1]

Ṣebí àkókò kan nínú ìgbà ti ré kọjá lórí ènìyàn tí (ènìyàn) kò jẹ́ kiní kan tí wọ́n ń dárúkọ?

### الآية 76:2

> ﻿إِنَّا خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ نُطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَاهُ سَمِيعًا بَصِيرًا [76:2]

Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara àtọ̀ t’ó ròpọ̀ mọ́ra wọn (láti ara ọkùnrin àti obìnrin), kí Á lè dán an wò. A sì ṣe é ní olùgbọ́, olùríran.

### الآية 76:3

> ﻿إِنَّا هَدَيْنَاهُ السَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرًا وَإِمَّا كَفُورًا [76:3]

Dájúdájú A fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n; Ó lè jẹ́ olùdúpẹ́, ó sì lè jẹ́ aláìmoore.

### الآية 76:4

> ﻿إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ سَلَاسِلَ وَأَغْلَالًا وَسَعِيرًا [76:4]

Dájúdájú Àwa pèsè àwọn ẹ̀wọ̀n, àjàgà àti Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 76:5

> ﻿إِنَّ الْأَبْرَارَ يَشْرَبُونَ مِنْ كَأْسٍ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا [76:5]

Dájúdájú àwọn ẹni rere, wọn yóò máa mu omi kan nínú ife. Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (omi náà) ni káfúrà.

### الآية 76:6

> ﻿عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا عِبَادُ اللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفْجِيرًا [76:6]

Omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan ni, tí àwọn ẹrúsìn Allāhu yóò máa mu, tí wọn yó sì máa mú un ṣàn jáde dáadáa (sí ibi tí wọ́n bá fẹ́).

### الآية 76:7

> ﻿يُوفُونَ بِالنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُ مُسْتَطِيرًا [76:7]

Wọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an.

### الآية 76:8

> ﻿وَيُطْعِمُونَ الطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِ مِسْكِينًا وَيَتِيمًا وَأَسِيرًا [76:8]

Tòhun ti bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ sí (ọrọ̀ tó), wọ́n ń fún mẹ̀kúnnù, ọmọ òrukàn àti ẹrú ní oúnjẹ jẹ.

### الآية 76:9

> ﻿إِنَّمَا نُطْعِمُكُمْ لِوَجْهِ اللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنْكُمْ جَزَاءً وَلَا شُكُورًا [76:9]

(Wọ́n sì ń sọ pé:) "Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín.

### الآية 76:10

> ﻿إِنَّا نَخَافُ مِنْ رَبِّنَا يَوْمًا عَبُوسًا قَمْطَرِيرًا [76:10]

Dájúdájú àwa ń páyà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wa ọjọ́ kan tí (ẹ̀dá yóò) fajú ro kókó."

### الآية 76:11

> ﻿فَوَقَاهُمُ اللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ الْيَوْمِ وَلَقَّاهُمْ نَضْرَةً وَسُرُورًا [76:11]

Nítorí náà, Allāhu yóò ṣọ́ wọn níbi aburú ọjọ́ yẹn. Ó sì máa fún wọn ni ìtutù ojú àti ìdùnnú.

### الآية 76:12

> ﻿وَجَزَاهُمْ بِمَا صَبَرُوا جَنَّةً وَحَرِيرًا [76:12]

Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san Ọgbà Ìdẹ̀ra àti aṣọ àlárì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù.

### الآية 76:13

> ﻿مُتَّكِئِينَ فِيهَا عَلَى الْأَرَائِكِ ۖ لَا يَرَوْنَ فِيهَا شَمْسًا وَلَا زَمْهَرِيرًا [76:13]

Wọn yóò máa rọ̀gbọ̀ kú sórí àwọn ibùsùn wọn. Wọn kò sì níí rí òòrùn tàbí òtútù.

### الآية 76:14

> ﻿وَدَانِيَةً عَلَيْهِمْ ظِلَالُهَا وَذُلِّلَتْ قُطُوفُهَا تَذْلِيلًا [76:14]

Àwọn òòji (inú Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò súnmọ́ wọn. A sì máa mú àwọn esò ibẹ̀ súnmọ́ àrọ́wọ́tó wọn ní ti sísúnmọ́.

### الآية 76:15

> ﻿وَيُطَافُ عَلَيْهِمْ بِآنِيَةٍ مِنْ فِضَّةٍ وَأَكْوَابٍ كَانَتْ قَوَارِيرَا [76:15]

Àti pé wọn yóò máa gbé ife ìmumi ńlá tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà àti àwọn ife ìmumi kékeré tí ó jẹ́ aláwo káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.

### الآية 76:16

> ﻿قَوَارِيرَ مِنْ فِضَّةٍ قَدَّرُوهَا تَقْدِيرًا [76:16]

Ife aláwo tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà ni (wọ́n). A sì ṣe wọ́n níwọ̀n-níwọ̀n (tí ó ṣe wẹ́kú ohun tí wọ́n fẹ́ mu).

### الآية 76:17

> ﻿وَيُسْقَوْنَ فِيهَا كَأْسًا كَانَ مِزَاجُهَا زَنْجَبِيلًا [76:17]

Àti pé wọn yóò máa fún wọn ní ife ọtí kan mu nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (ọtí náà) ni atalẹ̀.

### الآية 76:18

> ﻿عَيْنًا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلْسَبِيلًا [76:18]

Nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra (wọn yóò tún máa mu) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí À ń pè ní omi salsabīl.

### الآية 76:19

> ﻿۞ وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيْتَهُمْ حَسِبْتَهُمْ لُؤْلُؤًا مَنْثُورًا [76:19]

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí gbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. Nígbà tí ìwọ bá sì rí wọn, ìwọ yóò kà wọ́n kún òkúta olówó iyebíye tí wọ́n tàn kalẹ̀.

### الآية 76:20

> ﻿وَإِذَا رَأَيْتَ ثَمَّ رَأَيْتَ نَعِيمًا وَمُلْكًا كَبِيرًا [76:20]

Nígbà tí ìwọ bá sì wo ibẹ̀ yẹn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), ìwọ yóò rí ìdẹ̀ra àti ọlá t’ó tóbi.

### الآية 76:21

> ﻿عَالِيَهُمْ ثِيَابُ سُنْدُسٍ خُضْرٌ وَإِسْتَبْرَقٌ ۖ وَحُلُّوا أَسَاوِرَ مِنْ فِضَّةٍ وَسَقَاهُمْ رَبُّهُمْ شَرَابًا طَهُورًا [76:21]

Aṣọ ara wọn ni aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ ewéko àti aṣọ alágbàáà. A sì máa fi ẹ̀gbà-ọwọ́ onífàdákà ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́. Olúwa wọn yó sì fún wọn ní ohun mímu mímọ́ mu.

### الآية 76:22

> ﻿إِنَّ هَٰذَا كَانَ لَكُمْ جَزَاءً وَكَانَ سَعْيُكُمْ مَشْكُورًا [76:22]

Dájúdájú èyí jẹ́ ẹ̀san fun yín. Iṣẹ́ yín sì já sí ọpẹ́.

### الآية 76:23

> ﻿إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا عَلَيْكَ الْقُرْآنَ تَنْزِيلًا [76:23]

Dájúdájú Àwa l’A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ díẹ̀díẹ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.

### الآية 76:24

> ﻿فَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعْ مِنْهُمْ آثِمًا أَوْ كَفُورًا [76:24]

Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Má ṣe tẹ̀lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìmoore kan nínú wọn.

### الآية 76:25

> ﻿وَاذْكُرِ اسْمَ رَبِّكَ بُكْرَةً وَأَصِيلًا [76:25]

Rántí orúkọ Olúwa rẹ ní àárọ̀ àti ní àṣálẹ́.

### الآية 76:26

> ﻿وَمِنَ اللَّيْلِ فَاسْجُدْ لَهُ وَسَبِّحْهُ لَيْلًا طَوِيلًا [76:26]

Àti ní òru, forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní òru fún ìgbà pípẹ́.

### الآية 76:27

> ﻿إِنَّ هَٰؤُلَاءِ يُحِبُّونَ الْعَاجِلَةَ وَيَذَرُونَ وَرَاءَهُمْ يَوْمًا ثَقِيلًا [76:27]

Dájúdájú àwọn wọ̀nyí fẹ́ràn ayé. Wọ́n sì ń pa ọjọ́ t’ó wúwo tì sẹ́yìn wọn.

### الآية 76:28

> ﻿نَحْنُ خَلَقْنَاهُمْ وَشَدَدْنَا أَسْرَهُمْ ۖ وَإِذَا شِئْنَا بَدَّلْنَا أَمْثَالَهُمْ تَبْدِيلًا [76:28]

Àwa l’A ṣẹ̀dá wọn. A sì ṣe wọ́n ní alágbára. Nígbà tí A bá sì fẹ́, A óò fi irú wọn (mìíràn) pààrọ̀ wọn ní ti ìpààrọ̀.

### الآية 76:29

> ﻿إِنَّ هَٰذِهِ تَذْكِرَةٌ ۖ فَمَنْ شَاءَ اتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِ سَبِيلًا [76:29]

Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà tọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.

### الآية 76:30

> ﻿وَمَا تَشَاءُونَ إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا [76:30]

Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (kiní kan) àfi tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’ankabūt; 29: 21.

### الآية 76:31

> ﻿يُدْخِلُ مَنْ يَشَاءُ فِي رَحْمَتِهِ ۚ وَالظَّالِمِينَ أَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا [76:31]

Ó máa fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ rẹ̀. (Ní ti) àwọn alábòsí, Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/76.md)
- [كل تفاسير سورة الإنسان
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/76.md)
- [ترجمات سورة الإنسان
](https://quranpedia.net/translations/76.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/76/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
