---
title: "ترجمة سورة الأنفال - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/8/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/8/book/2001"
surah_id: "8"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة الأنفال - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/8/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة الأنفال - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/8/book/2001*.

Translation of Surah الأنفال from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 8:1

> يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْأَنْفَالِ ۖ قُلِ الْأَنْفَالُ لِلَّهِ وَالرَّسُولِ ۖ فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَصْلِحُوا ذَاتَ بَيْنِكُمْ ۖ وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ [8:1]

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 8:2

> ﻿إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ الَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ اللَّهُ وَجِلَتْ قُلُوبُهُمْ وَإِذَا تُلِيَتْ عَلَيْهِمْ آيَاتُهُ زَادَتْهُمْ إِيمَانًا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ [8:2]

Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.

### الآية 8:3

> ﻿الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ [8:3]

(Àwọn ni) àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.

### الآية 8:4

> ﻿أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَهُمْ دَرَجَاتٌ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَمَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ [8:4]

Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àwọn ipò gíga, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.

### الآية 8:5

> ﻿كَمَا أَخْرَجَكَ رَبُّكَ مِنْ بَيْتِكَ بِالْحَقِّ وَإِنَّ فَرِيقًا مِنَ الْمُؤْمِنِينَ لَكَارِهُونَ [8:5]

Gẹ́gẹ́ bí Olúwa rẹ ṣe mú ọ jáde (lọ sí ojú ogun) láti inú ilé rẹ pẹ̀lú òdodo, dájúdájú igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ ni ẹ̀mí wọn kọ̀ ọ́.

### الآية 8:6

> ﻿يُجَادِلُونَكَ فِي الْحَقِّ بَعْدَمَا تَبَيَّنَ كَأَنَّمَا يُسَاقُونَ إِلَى الْمَوْتِ وَهُمْ يَنْظُرُونَ [8:6]

Wọ́n sì ń takò ọ́ níbi òdodo lẹ́yìn tí ó ti fojú hàn (sí wọn) àfi bí ẹni pé wọ́n ń wà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ikú, tí wọ́n sì ń wò ó (báyìí).

### الآية 8:7

> ﻿وَإِذْ يَعِدُكُمُ اللَّهُ إِحْدَى الطَّائِفَتَيْنِ أَنَّهَا لَكُمْ وَتَوَدُّونَ أَنَّ غَيْرَ ذَاتِ الشَّوْكَةِ تَكُونُ لَكُمْ وَيُرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُحِقَّ الْحَقَّ بِكَلِمَاتِهِ وَيَقْطَعَ دَابِرَ الْكَافِرِينَ [8:7]

(Rántí) nígbà tí Allāhu ṣàdéhùn ọ̀kan nínú àwọn ìjọ méjèèjì fun yín pé ó máa jẹ́ tiyín, ẹ̀yin sì ń fẹ́ kí ìjọ tí kò dira ogun jẹ́ tiyín. Allāhu sì fẹ́ mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ó sì (fẹ́) pa àwọn aláìgbàgbọ́ run pátápátá

### الآية 8:8

> ﻿لِيُحِقَّ الْحَقَّ وَيُبْطِلَ الْبَاطِلَ وَلَوْ كَرِهَ الْمُجْرِمُونَ [8:8]

nítorí kí (Allāhu) lè fi òdodo (’Islām) rinlẹ̀ ní òdodo, kí Ó sì lè paná irọ́ (ìbọ̀rìṣà), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (ọ̀ṣẹbọ) ìbáà kórira rẹ̀.

### الآية 8:9

> ﻿إِذْ تَسْتَغِيثُونَ رَبَّكُمْ فَاسْتَجَابَ لَكُمْ أَنِّي مُمِدُّكُمْ بِأَلْفٍ مِنَ الْمَلَائِكَةِ مُرْدِفِينَ [8:9]

(Rántí) nígbà tí ẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa yín, Ó sì da yín lóhùn pé dájúdájú Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan nínú àwọn mọlāika t’ó máa wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.

### الآية 8:10

> ﻿وَمَا جَعَلَهُ اللَّهُ إِلَّا بُشْرَىٰ وَلِتَطْمَئِنَّ بِهِ قُلُوبُكُمْ ۚ وَمَا النَّصْرُ إِلَّا مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ [8:10]

Allāhu kò sì ṣe (ìrànlọ́wọ́ àwọn mọlāika) lásán bí kò ṣe nítorí kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú àti nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe kan àfi láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 8:11

> ﻿إِذْ يُغَشِّيكُمُ النُّعَاسَ أَمَنَةً مِنْهُ وَيُنَزِّلُ عَلَيْكُمْ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً لِيُطَهِّرَكُمْ بِهِ وَيُذْهِبَ عَنْكُمْ رِجْزَ الشَّيْطَانِ وَلِيَرْبِطَ عَلَىٰ قُلُوبِكُمْ وَيُثَبِّتَ بِهِ الْأَقْدَامَ [8:11]

(Rántí) nígbà tí (Allāhu) ta yín ní òògbé lọ (kí ó lè jẹ́) ìfọ̀kànbalẹ̀ (fun yín) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó tún sọ omi kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀ nítorí kí Ó fi lè fọ̀ yín mọ́ (pẹ̀lú ìwẹ̀ ọ̀ran-anyàn), àti nítorí kí Ó fi lè mú èròkerò Èṣù (bí àlá ìbálòpò ojú oorun) kúrò fun yín àti nítorí kí Ó lè kì yín lọ́kàn àti nítorí kí Ó lè mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin.

### الآية 8:12

> ﻿إِذْ يُوحِي رَبُّكَ إِلَى الْمَلَائِكَةِ أَنِّي مَعَكُمْ فَثَبِّتُوا الَّذِينَ آمَنُوا ۚ سَأُلْقِي فِي قُلُوبِ الَّذِينَ كَفَرُوا الرُّعْبَ فَاضْرِبُوا فَوْقَ الْأَعْنَاقِ وَاضْرِبُوا مِنْهُمْ كُلَّ بَنَانٍ [8:12]

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ fi mọ àwọn mọlāika pé dájúdájú Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ fi ẹsẹ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀. Èmi yóò ju ẹ̀rù sínú ọkàn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ẹ máa gé (wọn) lókè ọrùn. Kí ẹ sì máa gé gbogbo ọmọ ìka wọn.

### الآية 8:13

> ﻿ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ شَاقُّوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ وَمَنْ يُشَاقِقِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَإِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ [8:13]

Ìyẹn nítorí pé wọ́n tako (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tako (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.

### الآية 8:14

> ﻿ذَٰلِكُمْ فَذُوقُوهُ وَأَنَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَابَ النَّارِ [8:14]

Ìyẹn (nìyà tayé). Nítorí náà, ẹ tọ́ ọ wò. Àti pé dájúdájú ìyà Iná ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 8:15

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمُ الَّذِينَ كَفَرُوا زَحْفًا فَلَا تُوَلُّوهُمُ الْأَدْبَارَ [8:15]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń wọ́ jáde níkọ̀ níkọ̀, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ pẹ̀yìn dà sí wọn (láti ságun).

### الآية 8:16

> ﻿وَمَنْ يُوَلِّهِمْ يَوْمَئِذٍ دُبُرَهُ إِلَّا مُتَحَرِّفًا لِقِتَالٍ أَوْ مُتَحَيِّزًا إِلَىٰ فِئَةٍ فَقَدْ بَاءَ بِغَضَبٍ مِنَ اللَّهِ وَمَأْوَاهُ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ [8:16]

Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìn dà sí wọn ní ọjọ́ yẹn, yàtọ̀ sí ẹni t’ó yẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan (láti túnra mú) fún ogun tàbí ẹni t’ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ (mùsùlùmí láti fún wọn ní ìró ọ̀tẹlẹ̀-múyẹ́), dájúdájú (aságun) ti padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.

### الآية 8:17

> ﻿فَلَمْ تَقْتُلُوهُمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ قَتَلَهُمْ ۚ وَمَا رَمَيْتَ إِذْ رَمَيْتَ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ رَمَىٰ ۚ وَلِيُبْلِيَ الْمُؤْمِنِينَ مِنْهُ بَلَاءً حَسَنًا ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ [8:17]

Ẹ̀yin kọ́ l’ẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ l’o jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkò nítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, àṣẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) t’ó ń bẹ lára òkò tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jù lu àwọn kèfèrí l’ó gba ẹ̀mí wọn. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.

### الآية 8:18

> ﻿ذَٰلِكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ مُوهِنُ كَيْدِ الْكَافِرِينَ [8:18]

Ìyẹn (báyẹn). Dájúdájú Allāhu máa sọ ète àwọn aláìgbàgbọ́ di lílẹ.

### الآية 8:19

> ﻿إِنْ تَسْتَفْتِحُوا فَقَدْ جَاءَكُمُ الْفَتْحُ ۖ وَإِنْ تَنْتَهُوا فَهُوَ خَيْرٌ لَكُمْ ۖ وَإِنْ تَعُودُوا نَعُدْ وَلَنْ تُغْنِيَ عَنْكُمْ فِئَتُكُمْ شَيْئًا وَلَوْ كَثُرَتْ وَأَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُؤْمِنِينَ [8:19]

Tí ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) bá ń wá ìdájọ́, dájúdájú ìdájọ́ ti kò le yín lórí. Tí ẹ bá jáwọ́ (níbi ogun), ó sì dára jùlọ fun yín. Tí ẹ bá tún padà (síbi ogun), A máa padà (ran àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́wọ́); àkójọ yín kò sì níí rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan, ìbáà pọ̀. Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 8:20

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَوَلَّوْا عَنْهُ وَأَنْتُمْ تَسْمَعُونَ [8:20]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ẹ bá ń gbọ́ (āyah) lọ́wọ́.

### الآية 8:21

> ﻿وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ قَالُوا سَمِعْنَا وَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ [8:21]

Ẹ má se dà bí àwọn tí wọ́n wí pé: “A gbọ́.” Wọn kò sì gbọ́.

### الآية 8:22

> ﻿۞ إِنَّ شَرَّ الدَّوَابِّ عِنْدَ اللَّهِ الصُّمُّ الْبُكْمُ الَّذِينَ لَا يَعْقِلُونَ [8:22]

Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí t’ó burú jùlọ ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn adití, ayaya tí kò ṣe làákàyè.

### الآية 8:23

> ﻿وَلَوْ عَلِمَ اللَّهُ فِيهِمْ خَيْرًا لَأَسْمَعَهُمْ ۖ وَلَوْ أَسْمَعَهُمْ لَتَوَلَّوْا وَهُمْ مُعْرِضُونَ [8:23]

Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu mọ oore kan lára wọn ni, ìbá jẹ́ kí wọ́n gbọ́. Tí (Allāhu) bá sì fún wọn gbọ́ ni, dájúdájú wọn máa pẹ̀yìn dà, wọn yó sì máa gbúnrí.

### الآية 8:24

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اسْتَجِيبُوا لِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ إِذَا دَعَاكُمْ لِمَا يُحْيِيكُمْ ۖ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَحُولُ بَيْنَ الْمَرْءِ وَقَلْبِهِ وَأَنَّهُ إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ [8:24]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́pè ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́, nígbà tí ó bá pè yín síbi n̄ǹkan tí ó máa mu yín ṣẹ̀mí. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń ṣèdíwọ́ láààrin ènìyàn àti ọkàn rẹ̀. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ko yín jọ sí.

### الآية 8:25

> ﻿وَاتَّقُوا فِتْنَةً لَا تُصِيبَنَّ الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْكُمْ خَاصَّةً ۖ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ [8:25]

Ẹ ṣọrá fún àdánwò kan tí kò níí mọ lórí àwọn t’ó ṣàbòsí nínú yín nìkan. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.

### الآية 8:26

> ﻿وَاذْكُرُوا إِذْ أَنْتُمْ قَلِيلٌ مُسْتَضْعَفُونَ فِي الْأَرْضِ تَخَافُونَ أَنْ يَتَخَطَّفَكُمُ النَّاسُ فَآوَاكُمْ وَأَيَّدَكُمْ بِنَصْرِهِ وَرَزَقَكُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ [8:26]

Ẹ rántí pé nígbà tí ẹ̀yin kéré, tí wọ́n ń fojú tínrín yín lórí ilẹ̀, tí ẹ sì ń páyà pé àwọn ènìyàn máa ji yín gbé lọ, nígbà náà (Allāhu) ṣe ibùgbé fun yín (nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀), Ó sì fi àrànṣe Rẹ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fun yín. Ó tún pèsè fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

### الآية 8:27

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَخُونُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ وَتَخُونُوا أَمَانَاتِكُمْ وَأَنْتُمْ تَعْلَمُونَ [8:27]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jàǹbá (ọ̀ran-anyàn) Allāhu àti (sunnah) Òjíṣẹ́; ẹ má ṣe jàǹbá àwọn àgbàfipamọ́ yín, ẹ sì mọ (ìjàǹbá).

### الآية 8:28

> ﻿وَاعْلَمُوا أَنَّمَا أَمْوَالُكُمْ وَأَوْلَادُكُمْ فِتْنَةٌ وَأَنَّ اللَّهَ عِنْدَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ [8:28]

Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín, àti pé dájúdájú Allāhu ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

### الآية 8:29

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنْ تَتَّقُوا اللَّهَ يَجْعَلْ لَكُمْ فُرْقَانًا وَيُكَفِّرْ عَنْكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ [8:29]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fun yín ní ọ̀nà àbáyọ. Ó máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fun yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́lá t’ó tóbi.

### الآية 8:30

> ﻿وَإِذْ يَمْكُرُ بِكَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِيُثْبِتُوكَ أَوْ يَقْتُلُوكَ أَوْ يُخْرِجُوكَ ۚ وَيَمْكُرُونَ وَيَمْكُرُ اللَّهُ ۖ وَاللَّهُ خَيْرُ الْمَاكِرِينَ [8:30]

(Rántí) nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń déte sí ọ láti dè ọ́ mọ́lẹ̀ tàbí láti pa ọ́ tàbí láti yọ ọ́ kúrò nínú ìlú; wọ́n ń déte, Allāhu sì ń déte. Allāhu sì lóore jùlọ nínú àwọn adéte. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe adéte. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15 àti sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.

### الآية 8:31

> ﻿وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا قَالُوا قَدْ سَمِعْنَا لَوْ نَشَاءُ لَقُلْنَا مِثْلَ هَٰذَا ۙ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ [8:31]

Nígbà tí A bá ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gbọ́. Tí ó bá jẹ́ pé a bá fẹ́ ni. àwa náà ìbá sọ irú èyí. Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

### الآية 8:32

> ﻿وَإِذْ قَالُوا اللَّهُمَّ إِنْ كَانَ هَٰذَا هُوَ الْحَقَّ مِنْ عِنْدِكَ فَأَمْطِرْ عَلَيْنَا حِجَارَةً مِنَ السَّمَاءِ أَوِ ائْتِنَا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ [8:32]

(Rántí) nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu, tí ó bá jẹ́ pé èyí ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ, rọ òjò òkúta lé wa lórí láti sánmọ̀ tàbí kí O mú ìyà ẹlẹ́ta-eléro kan wá bá wa.”

### الآية 8:33

> ﻿وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمْ وَأَنْتَ فِيهِمْ ۚ وَمَا كَانَ اللَّهُ مُعَذِّبَهُمْ وَهُمْ يَسْتَغْفِرُونَ [8:33]

Allāhu kò níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí ìwọ sì ń bẹ láààrin wọn. Allāhu kò sì níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn.

### الآية 8:34

> ﻿وَمَا لَهُمْ أَلَّا يُعَذِّبَهُمُ اللَّهُ وَهُمْ يَصُدُّونَ عَنِ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ وَمَا كَانُوا أَوْلِيَاءَهُ ۚ إِنْ أَوْلِيَاؤُهُ إِلَّا الْمُتَّقُونَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [8:34]

Kò sí ìdí tí Allāhu kò fi níí jẹ wọ́n níyà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn lórí kúrò nínú Mọ́sálásí Haram. Àti pé àwọn ọ̀ṣẹbọ kọ́ ni alámòjúútó rẹ̀. Kò sí alámòjúútó kan fún un bí kò ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

### الآية 8:35

> ﻿وَمَا كَانَ صَلَاتُهُمْ عِنْدَ الْبَيْتِ إِلَّا مُكَاءً وَتَصْدِيَةً ۚ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ [8:35]

Ìjọ́sìn àwọn ọ̀ṣẹbọ ní Ilé (Kaabah) kò sì tayọ ṣíṣú ìfé àti pípa àtẹ́wọ́. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ jẹ́ aláìgbàgbọ́.

### الآية 8:36

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ لِيَصُدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۚ فَسَيُنْفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيْهِمْ حَسْرَةً ثُمَّ يُغْلَبُونَ ۗ وَالَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ يُحْشَرُونَ [8:36]

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n ń ná dúkìá wọn nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n sì ń ná a lọ (bẹ́ẹ̀). Lẹ́yìn náà, ó máa di àbámọ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, A sì máa borí wọn. Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, inú iná Jahanamọ ni A máa kó wọn jọ sí

### الآية 8:37

> ﻿لِيَمِيزَ اللَّهُ الْخَبِيثَ مِنَ الطَّيِّبِ وَيَجْعَلَ الْخَبِيثَ بَعْضَهُ عَلَىٰ بَعْضٍ فَيَرْكُمَهُ جَمِيعًا فَيَجْعَلَهُ فِي جَهَنَّمَ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ [8:37]

nítorí kí Allāhu lè ya àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹni ire àti nítorí kí Ó lè kó àwọn ẹni ibi papọ̀; apá kan wọn mọ́ apá kan, kí Ó sì lè rọ́ gbogbo wọn papọ̀ pátápátá (sójú kan náà), Ó sì máa fi wọ́n sínú iná Jahanamọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.

### الآية 8:38

> ﻿قُلْ لِلَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ يَنْتَهُوا يُغْفَرْ لَهُمْ مَا قَدْ سَلَفَ وَإِنْ يَعُودُوا فَقَدْ مَضَتْ سُنَّتُ الْأَوَّلِينَ [8:38]

Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun t’ó ti ré kọjá fún wọn. Tí wọ́n bá tún padà (síbẹ̀, àpèjúwe) ìparun àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá (ní ìkìlọ̀ fún wọn).

### الآية 8:39

> ﻿وَقَاتِلُوهُمْ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتْنَةٌ وَيَكُونَ الدِّينُ كُلُّهُ لِلَّهِ ۚ فَإِنِ انْتَهَوْا فَإِنَّ اللَّهَ بِمَا يَعْمَلُونَ بَصِيرٌ [8:39]

Ẹ jà wọ́n lógun títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́, gbogbo ẹ̀sìn yó sì lè jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 8:40

> ﻿وَإِنْ تَوَلَّوْا فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَوْلَاكُمْ ۚ نِعْمَ الْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ النَّصِيرُ [8:40]

Tí wọ́n bá sì gbúnrí (kúrò nínú ìgbàgbọ́), ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláfẹ̀yìntì yín. Ó dára ní Aláfẹ̀yìntì. Ó sì dára ní Alárànṣe.

### الآية 8:41

> ﻿۞ وَاعْلَمُوا أَنَّمَا غَنِمْتُمْ مِنْ شَيْءٍ فَأَنَّ لِلَّهِ خُمُسَهُ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ إِنْ كُنْتُمْ آمَنْتُمْ بِاللَّهِ وَمَا أَنْزَلْنَا عَلَىٰ عَبْدِنَا يَوْمَ الْفُرْقَانِ يَوْمَ الْتَقَى الْجَمْعَانِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ [8:41]

Ẹ mọ̀ pé ohunkóhun tí ẹ bá kó ní ọrọ̀ ogun, dájúdájú ti Allāhu ni ìdá márùn-ún rẹ̀. Ó sì wà fún Òjíṣẹ́ àti ẹbí (rẹ̀) àti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá), tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa ní Ọjọ́ ìpínyà, ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé (lójú ogun Badr). Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 8:42

> ﻿إِذْ أَنْتُمْ بِالْعُدْوَةِ الدُّنْيَا وَهُمْ بِالْعُدْوَةِ الْقُصْوَىٰ وَالرَّكْبُ أَسْفَلَ مِنْكُمْ ۚ وَلَوْ تَوَاعَدْتُمْ لَاخْتَلَفْتُمْ فِي الْمِيعَادِ ۙ وَلَٰكِنْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا لِيَهْلِكَ مَنْ هَلَكَ عَنْ بَيِّنَةٍ وَيَحْيَىٰ مَنْ حَيَّ عَنْ بَيِّنَةٍ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ [8:42]

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀yin wà ní etí kòtò t’ó súnmọ́ (ìlú Mọdīnah), àwọn (kèfèrí) sì wà ní etí kòtò t’ó jìnnà sí (ìlú Mọdīnah), àwọn kèfèrí kan t’ó ń gun n̄ǹkan ìgùn (bọ̀ láti ìrìn-àjò òkòwò), wọ́n sì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ tiyín. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin àti àwọn kèfèrí jọ mú ọjọ́ fún ogun náà ni, ẹ̀yin ìbá yapa àdéhùn náà, ṣùgbọ́n (ogun náà ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ; nítorí kí ẹni tí ó máa parun (sínú àìgbàgbọ́) lè parun nípasẹ̀ ẹ̀rí t’ó yanjú, kí ẹni t’ó sì máa yè (nínú ìgbàgbọ́ òdodo) lè yè nípasẹ̀ ẹ̀rí t’ó yanjú. Àti pé dájúdájú Allāhu kúkú ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 8:43

> ﻿إِذْ يُرِيكَهُمُ اللَّهُ فِي مَنَامِكَ قَلِيلًا ۖ وَلَوْ أَرَاكَهُمْ كَثِيرًا لَفَشِلْتُمْ وَلَتَنَازَعْتُمْ فِي الْأَمْرِ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ سَلَّمَ ۗ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ [8:43]

(Rántí) nígbà tí Allāhu fi wọ́n hàn ọ́ nínú àlá rẹ (pé wọ́n) kéré. Tí ó bá jẹ́ pé Ó fi wọ́n hàn ọ́ (pé wọ́n) pọ̀ ni, ẹ̀yin ìbá ṣojo, ẹ̀yin ìbá sì ṣàríyànjiyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n Allāhu ko (yín) yọ. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

### الآية 8:44

> ﻿وَإِذْ يُرِيكُمُوهُمْ إِذِ الْتَقَيْتُمْ فِي أَعْيُنِكُمْ قَلِيلًا وَيُقَلِّلُكُمْ فِي أَعْيُنِهِمْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا ۗ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ [8:44]

(Rántí) nígbà tí Ó ń fi wọ́n hàn yín pé wọ́n kéré lójú yín - nígbà tí ẹ pàdé (lójú ogun) – Ó sì mú ẹ̀yin náà kéré lójú tiwọn náà, nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

### الآية 8:45

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمْ فِئَةً فَاثْبُتُوا وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ [8:45]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé ìjọ (ogun) kan, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní (òǹkà) púpọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.

### الآية 8:46

> ﻿وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ ۖ وَاصْبِرُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِينَ [8:46]

Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe jara yín níyàn (nípa ogun ẹ̀sìn) nítorí kí ẹ má baà ṣojo àti nítorí kí agbára yín má baà kúrò lọ́wọ́ yín. Ẹ ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù.

### الآية 8:47

> ﻿وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ خَرَجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ بَطَرًا وَرِئَاءَ النَّاسِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۚ وَاللَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطٌ [8:47]

Ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó jáde kúrò nínú ilé wọn pẹ̀lú fáààrí àti ṣekárími. Wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 8:48

> ﻿وَإِذْ زَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ وَقَالَ لَا غَالِبَ لَكُمُ الْيَوْمَ مِنَ النَّاسِ وَإِنِّي جَارٌ لَكُمْ ۖ فَلَمَّا تَرَاءَتِ الْفِئَتَانِ نَكَصَ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ وَقَالَ إِنِّي بَرِيءٌ مِنْكُمْ إِنِّي أَرَىٰ مَا لَا تَرَوْنَ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ ۚ وَاللَّهُ شَدِيدُ الْعِقَابِ [8:48]

(Rántí) nígbà tí Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, ó sì wí pé: “Kò sí ẹni tí ó máa borí yín lónìí nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú èmi ni aládùúgbò yín.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìjọ ogun méjèèjì fojú kanra wọn, ó padà sẹ́yìn, ó sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, ó wí pé: "Dájúdájú èmi ti yọwọ́-yọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yín. Dájúdájú èmi ń rí ohun tí ẹ̀yin kò rí. Èmi ń pàyà Allāhu. Allāhu sì le níbi ìyà."

### الآية 8:49

> ﻿إِذْ يَقُولُ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ غَرَّ هَٰؤُلَاءِ دِينُهُمْ ۗ وَمَنْ يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَإِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ [8:49]

(Rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àrùn ń bẹ nínú ọkàn wọn wí pé: “Ẹ̀sìn àwọn wọ̀nyí tàn wọ́n jẹ.” Ẹnikẹ́ni t’ó bá gbáralé Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 8:50

> ﻿وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ يَتَوَفَّى الَّذِينَ كَفَرُوا ۙ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَارَهُمْ وَذُوقُوا عَذَابَ الْحَرِيقِ [8:50]

Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn mọlāika bá ń gba ẹ̀mí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ni, tí wọ́n ń lu ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé), “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”

### الآية 8:51

> ﻿ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ [8:51]

Ìyẹn nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì ṣíwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀).

### الآية 8:52

> ﻿كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ ۙ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ فَأَخَذَهُمُ اللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ شَدِيدُ الْعِقَابِ [8:52]

(Ìṣesí àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn - wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu. - Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ó le níbi ìyà.

### الآية 8:53

> ﻿ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ لَمْ يَكُ مُغَيِّرًا نِعْمَةً أَنْعَمَهَا عَلَىٰ قَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا مَا بِأَنْفُسِهِمْ ۙ وَأَنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ [8:53]

Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà ìdẹ̀ra tí Ó ṣe fún ìjọ kan títí wọn yóò fi ṣe ìyípadà n̄ǹkan tí ń bẹ lọ́dọ̀ ara wọn. Dájúdájú Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 8:54

> ﻿كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ ۙ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ فَأَهْلَكْنَاهُمْ بِذُنُوبِهِمْ وَأَغْرَقْنَا آلَ فِرْعَوْنَ ۚ وَكُلٌّ كَانُوا ظَالِمِينَ [8:54]

(Ìṣesí àwọn aláìmoore) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Olúwa wọn nírọ́. Nítorí náà, A pa wọ́n run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; A sì tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì sínú agbami. Gbogbo wọn sì jẹ́ alábòsí.

### الآية 8:55

> ﻿إِنَّ شَرَّ الدَّوَابِّ عِنْدَ اللَّهِ الَّذِينَ كَفَرُوا فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ [8:55]

Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí t’ó burú jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́.

### الآية 8:56

> ﻿الَّذِينَ عَاهَدْتَ مِنْهُمْ ثُمَّ يَنْقُضُونَ عَهْدَهُمْ فِي كُلِّ مَرَّةٍ وَهُمْ لَا يَتَّقُونَ [8:56]

Àwọn tí o bá ṣe àdéhùn nínú wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń tú àdéhùn wọn ní gbogbo ìgbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù (Allāhu),

### الآية 8:57

> ﻿فَإِمَّا تَثْقَفَنَّهُمْ فِي الْحَرْبِ فَشَرِّدْ بِهِمْ مَنْ خَلْفَهُمْ لَعَلَّهُمْ يَذَّكَّرُونَ [8:57]

yálà tí ọwọ́ yín bá bà wọ́n lójú ogun, (ẹ pa wọ́n) kí ẹ sì (fi ogun) tú àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ká nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí;

### الآية 8:58

> ﻿وَإِمَّا تَخَافَنَّ مِنْ قَوْمٍ خِيَانَةً فَانْبِذْ إِلَيْهِمْ عَلَىٰ سَوَاءٍ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْخَائِنِينَ [8:58]

tàbí tí o bá sì ń páyà ìwà ìjàǹbá láti ọ̀dọ̀ ìjọ kan, ju àdéhùn wọn sílẹ̀ fún wọn kí ẹ dì jọ mọ̀ pé kò sí àdéhùn kan mọ́ láààrin ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn oníjàǹbá.

### الآية 8:59

> ﻿وَلَا يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا سَبَقُوا ۚ إِنَّهُمْ لَا يُعْجِزُونَ [8:59]

Kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé àwọn ti gbawájú. Dájúdájú wọn kò lè mórí bọ́ (nínú ìyà).

### الآية 8:60

> ﻿وَأَعِدُّوا لَهُمْ مَا اسْتَطَعْتُمْ مِنْ قُوَّةٍ وَمِنْ رِبَاطِ الْخَيْلِ تُرْهِبُونَ بِهِ عَدُوَّ اللَّهِ وَعَدُوَّكُمْ وَآخَرِينَ مِنْ دُونِهِمْ لَا تَعْلَمُونَهُمُ اللَّهُ يَعْلَمُهُمْ ۚ وَمَا تُنْفِقُوا مِنْ شَيْءٍ فِي سَبِيلِ اللَّهِ يُوَفَّ إِلَيْكُمْ وَأَنْتُمْ لَا تُظْلَمُونَ [8:60]

Ẹ pèsè sílẹ̀ dè wọ́n n̄ǹkan ìjà tí agbára yín ká nínú n̄ǹkan àmúṣagbára àti àwọn ẹṣin orí ìso, tí ẹ̀yin yóò fi máa dẹ́rù ba ọ̀tá Allāhu àti ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn mìíràn yàtọ̀ sí wọn, tí ẹ̀yin kò mọ̀ wọ́n – Allāhu sì mọ̀ wọ́n. – Ohunkóhun tí ẹ bá ná lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A óò san án padà fun yín ní kíkún; A ò sì níí ṣe àbòsí fun yín.

### الآية 8:61

> ﻿۞ وَإِنْ جَنَحُوا لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ [8:61]

Tí wọ́n bá tẹ̀ síbi (ètò) àlàáfíà (fún dídá ogun dúró), ìwọ náà tẹ̀ síbẹ̀, kí o sì gbáralé Allāhu. Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 8:62

> ﻿وَإِنْ يُرِيدُوا أَنْ يَخْدَعُوكَ فَإِنَّ حَسْبَكَ اللَّهُ ۚ هُوَ الَّذِي أَيَّدَكَ بِنَصْرِهِ وَبِالْمُؤْمِنِينَ [8:62]

Tí wọ́n bá tún fẹ́ tàn ọ́ jẹ, dájúdájú Allāhu á tó ọ. Òun ni Ẹni tí Ó fi àrànṣe Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ràn ọ́ lọ́wọ́.

### الآية 8:63

> ﻿وَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ ۚ لَوْ أَنْفَقْتَ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مَا أَلَّفْتَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ أَلَّفَ بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ [8:63]

Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Tí ó bá jẹ́ pé o ná gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá, ìwọ kò lè pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Ṣùgbọ́n Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn, dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 8:64

> ﻿يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَسْبُكَ اللَّهُ وَمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ [8:64]

Ìwọ Ànábì, Allāhu ti tó ìwọ àti àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 8:65

> ﻿يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَرِّضِ الْمُؤْمِنِينَ عَلَى الْقِتَالِ ۚ إِنْ يَكُنْ مِنْكُمْ عِشْرُونَ صَابِرُونَ يَغْلِبُوا مِائَتَيْنِ ۚ وَإِنْ يَكُنْ مِنْكُمْ مِائَةٌ يَغْلِبُوا أَلْفًا مِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَفْقَهُونَ [8:65]

Ìwọ Ànábì, gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìyànjú lórí ogun ẹ̀sìn. Tí ogún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ọgọ́rùn-ún bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún nínú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé.

### الآية 8:66

> ﻿الْآنَ خَفَّفَ اللَّهُ عَنْكُمْ وَعَلِمَ أَنَّ فِيكُمْ ضَعْفًا ۚ فَإِنْ يَكُنْ مِنْكُمْ مِائَةٌ صَابِرَةٌ يَغْلِبُوا مِائَتَيْنِ ۚ وَإِنْ يَكُنْ مِنْكُمْ أَلْفٌ يَغْلِبُوا أَلْفَيْنِ بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ مَعَ الصَّابِرِينَ [8:66]

Nísisìn yìí, Allāhu ti ṣe é ní fífúyẹ́ fun yín. Ó sì mọ̀ pé dájúdájú àìlágbára ń bẹ fun yín. Nítorí náà, tí ọgọ́rùn-ún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ẹgbẹ̀rún kan bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún méjì pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Allāhu sì wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù.

### الآية 8:67

> ﻿مَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَنْ يَكُونَ لَهُ أَسْرَىٰ حَتَّىٰ يُثْخِنَ فِي الْأَرْضِ ۚ تُرِيدُونَ عَرَضَ الدُّنْيَا وَاللَّهُ يُرِيدُ الْآخِرَةَ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ [8:67]

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti ní ẹrú ogun (kí ó sì tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀) títí ó fi máa ṣẹ́gun (wọn) tán pátápátá lórí ilẹ̀. Ẹ̀yin ń fẹ́ ìgbádùn ayé, Allāhu sì ń fẹ́ ọ̀run. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 8:68

> ﻿لَوْلَا كِتَابٌ مِنَ اللَّهِ سَبَقَ لَمَسَّكُمْ فِيمَا أَخَذْتُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ [8:68]

Tí kì í bá ṣe ti àkọsílẹ̀ kan t’ó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni, ọwọ́ ìyà ńlá kò bá tẹ̀ yín nípa n̄ǹkan tí ẹ gbà (ní owó ìtúsílẹ̀).

### الآية 8:69

> ﻿فَكُلُوا مِمَّا غَنِمْتُمْ حَلَالًا طَيِّبًا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ [8:69]

Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí ẹ kó ní ọrọ̀ ogun (tí ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti) n̄ǹkan dáadáa. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 8:70

> ﻿يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُلْ لِمَنْ فِي أَيْدِيكُمْ مِنَ الْأَسْرَىٰ إِنْ يَعْلَمِ اللَّهُ فِي قُلُوبِكُمْ خَيْرًا يُؤْتِكُمْ خَيْرًا مِمَّا أُخِذَ مِنْكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ [8:70]

Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn t’ó ń bẹ lọ́wọ́ yín nínú àwọn ẹrú ogun pé, “Tí Allāhu bá mọ dáadáa kan nínú ọkàn yín, Ó máa fun yín ní ohun t’ó dára ju ohun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.”

### الآية 8:71

> ﻿وَإِنْ يُرِيدُوا خِيَانَتَكَ فَقَدْ خَانُوا اللَّهَ مِنْ قَبْلُ فَأَمْكَنَ مِنْهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [8:71]

Tí wọ́n bá sì ń gbèrò ìjàǹbá sí ọ, wọ́n kúkú ti jàǹbá Allāhu ṣíwájú. Ó sì fún ọ lágbára lórí wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 8:72

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالَّذِينَ آوَوْا وَنَصَرُوا أُولَٰئِكَ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَلَمْ يُهَاجِرُوا مَا لَكُمْ مِنْ وَلَايَتِهِمْ مِنْ شَيْءٍ حَتَّىٰ يُهَاجِرُوا ۚ وَإِنِ اسْتَنْصَرُوكُمْ فِي الدِّينِ فَعَلَيْكُمُ النَّصْرُ إِلَّا عَلَىٰ قَوْمٍ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ مِيثَاقٌ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ [8:72]

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn t’ó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (t’ó lè jogún ara wọn). Àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (t’ó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fun yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ tí àwọn mùsùlùmí di alátìpó sínú ìlú Mọdīnah, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń fa ará Mọkkah kọ̀ọ̀kan lé ará Mọdīnah kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti sọ́ra wọn di ọ̀rẹ́ t’ó máa fẹ́ẹ̀ dà bí ẹbí. Nípasẹ̀ èyí, ìkíní kejì ń jogún ara wọn lẹ́yìn ikú. Ní àsìkò yìí, àwọn tí kò ì kúrò nínú Mọkkah láti wá ṣe àtìpó ní ìlú Mọdīnah nínú àwọn mùsùlùmí di ẹni tí kò lè jogún ẹbí rẹ̀ t’ó wà nínú ìlú Mọdīnah àfi tí òun náà bá gbé ìlú Mọkkah jù sílẹ̀. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, hijrah ṣíṣe sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ láti inú ẹbí kan fún ẹni t’ó ṣe hijrah. Àìṣe hijrah sì sọ ogún jíjẹ di èèwọ̀ láti inú ẹbí kan náà fún ẹni tí kò ṣe hijrah, wọn ìbáà dìjọ jẹ́ mùsùlùmi. Fífi hijrah sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ sì wà bẹ́ẹ̀ títí wọ́n fi ṣí ìlú Mọkkah. Níkété tí wọ́n ṣí ìlú Mọkkah, tí hijrah ṣíṣe láti Mọkkah Alápọ̀n-ọ́nlé sí Mọdinah Onímọ̀ọ́lẹ̀ kásẹ̀ nílẹ́, nígbà náà ẹbí nìkan l’ó ní ìpín àdáyanrí nínú ogún ẹbí rẹ̀. Wọn kò si fi hijrah ṣíṣe pín ogún fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní ìbámu sí āyah 75 nínú sūrah yìí. Lẹ́yìn náà, àwọn āyah ogún pípín fún àwọn ẹbí sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’.

### الآية 8:73

> ﻿وَالَّذِينَ كَفَرُوا بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ إِلَّا تَفْعَلُوهُ تَكُنْ فِتْنَةٌ فِي الْأَرْضِ وَفَسَادٌ كَبِيرٌ [8:73]

Àwọn aláìgbàgbọ́; apá kan wọn ni alátìlẹ́yìn apá kan. Àfi kí ẹ̀yin náà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfòòró àti ìbàjẹ́ t’ó tóbi kò fi níí wà lórí ilẹ̀.

### الآية 8:74

> ﻿وَالَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَالَّذِينَ آوَوْا وَنَصَرُوا أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ [8:74]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti àwọn t’ó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; ní ti òdodo àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn.

### الآية 8:75

> ﻿وَالَّذِينَ آمَنُوا مِنْ بَعْدُ وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا مَعَكُمْ فَأُولَٰئِكَ مِنْكُمْ ۚ وَأُولُو الْأَرْحَامِ بَعْضُهُمْ أَوْلَىٰ بِبَعْضٍ فِي كِتَابِ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ [8:75]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo lẹ́yìn (wọn), tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú yín, àwọn wọ̀nyẹn náà wà lára yín. Àti pé àwọn ìbátan, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí apá kan (nípa ogún jíjẹ) nínú Tírà Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/8.md)
- [كل تفاسير سورة الأنفال
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/8.md)
- [ترجمات سورة الأنفال
](https://quranpedia.net/translations/8.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/8/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
