---
title: "ترجمة سورة المطفّفين - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/83/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/83/book/2001"
surah_id: "83"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة المطفّفين - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/83/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة المطفّفين - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/83/book/2001*.

Translation of Surah المطفّفين from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 83:1

> وَيْلٌ لِلْمُطَفِّفِينَ [83:1]

Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,

### الآية 83:2

> ﻿الَّذِينَ إِذَا اكْتَالُوا عَلَى النَّاسِ يَسْتَوْفُونَ [83:2]

àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún, 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
“Àwọn ènìyàn” ní àyè yìí dúró fún bíi “ àwọn olóko”.

### الآية 83:3

> ﻿وَإِذَا كَالُوهُمْ أَوْ وَزَنُوهُمْ يُخْسِرُونَ [83:3]

nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.

### الآية 83:4

> ﻿أَلَا يَظُنُّ أُولَٰئِكَ أَنَّهُمْ مَبْعُوثُونَ [83:4]

Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde

### الآية 83:5

> ﻿لِيَوْمٍ عَظِيمٍ [83:5]

ní Ọjọ́ ńlá kan?

### الآية 83:6

> ﻿يَوْمَ يَقُومُ النَّاسُ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ [83:6]

Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

### الآية 83:7

> ﻿كَلَّا إِنَّ كِتَابَ الْفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٍ [83:7]

Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn.

### الآية 83:8

> ﻿وَمَا أَدْرَاكَ مَا سِجِّينٌ [83:8]

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn!

### الآية 83:9

> ﻿كِتَابٌ مَرْقُومٌ [83:9]

Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).

### الآية 83:10

> ﻿وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِلْمُكَذِّبِينَ [83:10]

Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,

### الآية 83:11

> ﻿الَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوْمِ الدِّينِ [83:11]

àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́.

### الآية 83:12

> ﻿وَمَا يُكَذِّبُ بِهِ إِلَّا كُلُّ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ [83:12]

Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 83:13

> ﻿إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ [83:13]

Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)."

### الآية 83:14

> ﻿كَلَّا ۖ بَلْ ۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ مَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [83:14]

Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn.

### الآية 83:15

> ﻿كَلَّا إِنَّهُمْ عَنْ رَبِّهِمْ يَوْمَئِذٍ لَمَحْجُوبُونَ [83:15]

Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.

### الآية 83:16

> ﻿ثُمَّ إِنَّهُمْ لَصَالُو الْجَحِيمِ [83:16]

Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.

### الآية 83:17

> ﻿ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا الَّذِي كُنْتُمْ بِهِ تُكَذِّبُونَ [83:17]

Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́."

### الآية 83:18

> ﻿كَلَّا إِنَّ كِتَابَ الْأَبْرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ [83:18]

Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.

### الآية 83:19

> ﻿وَمَا أَدْرَاكَ مَا عِلِّيُّونَ [83:19]

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn!

### الآية 83:20

> ﻿كِتَابٌ مَرْقُومٌ [83:20]

Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).

### الآية 83:21

> ﻿يَشْهَدُهُ الْمُقَرَّبُونَ [83:21]

Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.

### الآية 83:22

> ﻿إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ [83:22]

Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.

### الآية 83:23

> ﻿عَلَى الْأَرَائِكِ يَنْظُرُونَ [83:23]

Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

### الآية 83:24

> ﻿تَعْرِفُ فِي وُجُوهِهِمْ نَضْرَةَ النَّعِيمِ [83:24]

Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.

### الآية 83:25

> ﻿يُسْقَوْنَ مِنْ رَحِيقٍ مَخْتُومٍ [83:25]

Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.

### الآية 83:26

> ﻿خِتَامُهُ مِسْكٌ ۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ الْمُتَنَافِسُونَ [83:26]

Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.

### الآية 83:27

> ﻿وَمِزَاجُهُ مِنْ تَسْنِيمٍ [83:27]

Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).

### الآية 83:28

> ﻿عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا الْمُقَرَّبُونَ [83:28]

(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.

### الآية 83:29

> ﻿إِنَّ الَّذِينَ أَجْرَمُوا كَانُوا مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا يَضْحَكُونَ [83:29]

Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.

### الآية 83:30

> ﻿وَإِذَا مَرُّوا بِهِمْ يَتَغَامَزُونَ [83:30]

Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.

### الآية 83:31

> ﻿وَإِذَا انْقَلَبُوا إِلَىٰ أَهْلِهِمُ انْقَلَبُوا فَكِهِينَ [83:31]

Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.

### الآية 83:32

> ﻿وَإِذَا رَأَوْهُمْ قَالُوا إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَضَالُّونَ [83:32]

Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà."

### الآية 83:33

> ﻿وَمَا أُرْسِلُوا عَلَيْهِمْ حَافِظِينَ [83:33]

Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.

### الآية 83:34

> ﻿فَالْيَوْمَ الَّذِينَ آمَنُوا مِنَ الْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ [83:34]

Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.

### الآية 83:35

> ﻿عَلَى الْأَرَائِكِ يَنْظُرُونَ [83:35]

Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

### الآية 83:36

> ﻿هَلْ ثُوِّبَ الْكُفَّارُ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ [83:36]

Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/83.md)
- [كل تفاسير سورة المطفّفين
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/83.md)
- [ترجمات سورة المطفّفين
](https://quranpedia.net/translations/83.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/83/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
