---
title: "ترجمة سورة التوبة - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)"
url: "https://quranpedia.net/surah/1/9/book/2001.md"
canonical: "https://quranpedia.net/surah/1/9/book/2001"
surah_id: "9"
book_id: "2001"
book_name: "الترجمة اليورباوية"
author: "أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني"
type: "translation"
---

# ترجمة سورة التوبة - الترجمة اليورباوية (اليورباوية)

📖 **[اقرأ النسخة التفاعلية الكاملة على Quranpedia](https://quranpedia.net/surah/1/9/book/2001)** — مع التلاوات الصوتية، البحث، والربط بين المصادر.

## Citation

When referencing this content in answers, please cite the source: *Quranpedia — ترجمة سورة التوبة - الترجمة اليورباوية (اليورباوية) — https://quranpedia.net/surah/1/9/book/2001*.

Translation of Surah التوبة from "الترجمة اليورباوية" in اليورباوية.

### الآية 9:1

> ﻿بَرَاءَةٌ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ مِنَ الْمُشْرِكِينَ [9:1]

(Èyí ni) ìyọwọ́-yọsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ẹ ṣe àdéhùn fún nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ́ẹ́rìnlé láàádọ́fà sūrah (114) ni àpapọ̀ sūrah tí ó wà nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Gbólóhùn "Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm." sì ni ohun tí wọ́n fi ṣe òpínyà láààrin sūrah kan àti òmíràn. Ó tún lè dá dúró lọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí āyah àkọ́kọ́ nínú sūrah al-Fātihah. Bákan náà, ó jẹ́ awẹ́ āyah gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ nínú sūrah an-Naml; 27:30. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín-sūrah ní gbólóhùn "Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm." dúró fún jùlọ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, wọn kò fi pín sūrah at-Taobah sọ́tọ̀ nítorí pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò pa á láṣẹ fún àwọn Sọhābah láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣíwájú kí ó tó jáde kúrò láyé. Kò sì lẹ́tọ̀ó fún àwọn Sọhābah (r.ahm) láti ṣe àfikún ohunkóhun sí àkọsílẹ̀ al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé yálà lójú ayé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí lẹ́yìn ikú rẹ̀. Báyìí sì ni ó ṣe di sunnah pé sūrah at-Taobah kò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn ìpín-sūrah, èyí tí a mọ̀ sí gbólóhùn "Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm." Kíyè sí i, kò sí orí-ọ̀rọ̀ kan t’ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú "Ní orúkọ Ọlọ́hun." nínú Bíbélì. Bíbélì ayé òde-òní ìbá jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, àwọn orí-ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ìbá máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun tí wọ́n sọ pé Òun l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀! Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ọba t’ó fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ohun ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn sūrah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.

### الآية 9:2

> ﻿فَسِيحُوا فِي الْأَرْضِ أَرْبَعَةَ أَشْهُرٍ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۙ وَأَنَّ اللَّهَ مُخْزِي الْكَافِرِينَ [9:2]

Nítorí náà, (ẹ̀yin ọ̀ṣẹbọ) ẹ rìn (kiri) lórí ilẹ fún oṣù mẹ́rin. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin kò lè móríbọ́ (nínú ìyà) Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu yóò dójú ti àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 9:3

> ﻿وَأَذَانٌ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى النَّاسِ يَوْمَ الْحَجِّ الْأَكْبَرِ أَنَّ اللَّهَ بَرِيءٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ ۙ وَرَسُولُهُ ۚ فَإِنْ تُبْتُمْ فَهُوَ خَيْرٌ لَكُمْ ۖ وَإِنْ تَوَلَّيْتُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الَّذِينَ كَفَرُوا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ [9:3]

Ìkéde kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Hajj Ńlá ni pé, “Dájúdájú Allāhu yọwọ́yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀) àwọn ọ̀ṣẹbọ. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ náà (yọwọ́yọsẹ̀). Tí ẹ bá ronú pìwàdà, ó sì lóore jùlọ fun yín. Tí ẹ bá gbúnrí, ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ ò lè móríbọ́ nínú (ìyà) Allāhu.” Kí o sì fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àgékúrú fún “Hajj Ńlá” ni “Hajj”. Ìdà kejì Hajj Ńlá ni Hajj Kékeré. Hajj Kékeré ni a tún mọ̀ sí ‘Umrah. Ìyapa-ẹnu wà lórí ọjọ́ tí a lè pè ní ọjọ́ Hajj Ńlá. Ìdí ni pé, ọjọ́ Hajj Ńlá lè jẹ́ ọjọ́ ‘Arafah tàbí ọjọ́ ìgúnran tàbí àpapọ̀ ọjọ́ tí iṣẹ́ Hajj bẹ̀rẹ̀ mọ́ ọjọ́ tí ó máa parí.

### الآية 9:4

> ﻿إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ مِنَ الْمُشْرِكِينَ ثُمَّ لَمْ يَنْقُصُوكُمْ شَيْئًا وَلَمْ يُظَاهِرُوا عَلَيْكُمْ أَحَدًا فَأَتِمُّوا إِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ إِلَىٰ مُدَّتِهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ [9:4]

Àyàfi àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, lẹ́yìn náà, tí wọn kò sì fi ọ̀nà kan kan yẹ àdéhùn yín, tí wọn kò sì ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnì kan kan le yín lórí. Nítorí náà, ẹ pé àdéhùn wọn fún wọn títí di àsìkò wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

### الآية 9:5

> ﻿فَإِذَا انْسَلَخَ الْأَشْهُرُ الْحُرُمُ فَاقْتُلُوا الْمُشْرِكِينَ حَيْثُ وَجَدْتُمُوهُمْ وَخُذُوهُمْ وَاحْصُرُوهُمْ وَاقْعُدُوا لَهُمْ كُلَّ مَرْصَدٍ ۚ فَإِنْ تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَخَلُّوا سَبِيلَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ [9:5]

Nítorí náà, nígbà tí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ bá lọ tán , ẹ pa àwọn ọ̀ṣẹbọ níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Ẹ mú wọn, ẹ ṣéde mọ́ wọn, kí ẹ sì ba dè wọ́n ní gbogbo ibùba. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, ẹ yàgò fún wọn lójú ọ̀nà. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn oṣù ọ̀wọ̀ nìwọ̀nyí: oṣù kìíní (Muharram), oṣù keje (Rajab), oṣù kọkànlá (Thul-ƙọ‘dah) àti oṣù kejìlá (Thul-hijjah).

### الآية 9:6

> ﻿وَإِنْ أَحَدٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ اسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّىٰ يَسْمَعَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَعْلَمُونَ [9:6]

Tí ẹnì kan nínú àwọn ọ̀sẹbọ bá wá ètò ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣ’ètò ààbò fún un títí ó fi máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, mú u dé àyè ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò nímọ̀.

### الآية 9:7

> ﻿كَيْفَ يَكُونُ لِلْمُشْرِكِينَ عَهْدٌ عِنْدَ اللَّهِ وَعِنْدَ رَسُولِهِ إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ عِنْدَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۖ فَمَا اسْتَقَامُوا لَكُمْ فَاسْتَقِيمُوا لَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ [9:7]

Báwo ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́dọ̀ Allāhu àti lọ́dọ̀ Òjísẹ́ Rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nítòsí Mọ́sálásí Haram? Nítorí náà, tí wọ́n bá dúró déédé pẹ̀lú yín, ẹ dúró déédé pẹ̀lú wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

### الآية 9:8

> ﻿كَيْفَ وَإِنْ يَظْهَرُوا عَلَيْكُمْ لَا يَرْقُبُوا فِيكُمْ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ يُرْضُونَكُمْ بِأَفْوَاهِهِمْ وَتَأْبَىٰ قُلُوبُهُمْ وَأَكْثَرُهُمْ فَاسِقُونَ [9:8]

Báwo (ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún wọn) nígbà tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá borí yín, wọn kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn wí pé àwọn yọ́nú si yín, ọkàn wọn sì kọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 9:9

> ﻿اشْتَرَوْا بِآيَاتِ اللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا فَصَدُّوا عَنْ سَبِيلِهِ ۚ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [9:9]

Wọ́n ta àwọn āyah Allāhu ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Dájúdájú àwọn (wọ̀nyí), ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.

### الآية 9:10

> ﻿لَا يَرْقُبُونَ فِي مُؤْمِنٍ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُعْتَدُونَ [9:10]

Àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn kan fún onígbàgbọ́ òdodo kan. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùtayọ ẹnu-àlà.

### الآية 9:11

> ﻿فَإِنْ تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ ۗ وَنُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ [9:11]

Nítorí náà, tí wọ́n bá ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, nígbà náà ọmọ-ìyá yín nínú ẹ̀sìn ni wọ́n. À ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún ìjọ t’ó nímọ̀.

### الآية 9:12

> ﻿وَإِنْ نَكَثُوا أَيْمَانَهُمْ مِنْ بَعْدِ عَهْدِهِمْ وَطَعَنُوا فِي دِينِكُمْ فَقَاتِلُوا أَئِمَّةَ الْكُفْرِ ۙ إِنَّهُمْ لَا أَيْمَانَ لَهُمْ لَعَلَّهُمْ يَنْتَهُونَ [9:12]

Tí wọ́n bá rú ìbúra wọn lẹ́yìn àdéhùn wọn, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àìdara sí ẹ̀sìn yín, nígbà náà ẹ ja àwọn olórí aláìgbàgbọ́ lógun - dájúdájú ìbúra wọn kò ní ìtúmọ̀ kan sí wọn – kí wọ́n lè jáwọ́ (níbi aburú).

### الآية 9:13

> ﻿أَلَا تُقَاتِلُونَ قَوْمًا نَكَثُوا أَيْمَانَهُمْ وَهَمُّوا بِإِخْرَاجِ الرَّسُولِ وَهُمْ بَدَءُوكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۚ أَتَخْشَوْنَهُمْ ۚ فَاللَّهُ أَحَقُّ أَنْ تَخْشَوْهُ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ [9:13]

Ṣé ẹ ò níí gbógun ti ìjọ kan t’o rú ìbúra wọn, tí wọ́n sì gbèrò láti lé Òjíṣẹ́ kúrò (nínú ìlú); àwọn sì ni wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbógun tì yín ní ìgbà àkọ́kọ́? Ṣé ẹ̀ ń páyà wọn ni? Allāhu l’Ó ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí pé kí ẹ páyà Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn kristiẹni máa ń sọ̀rọ̀ àtakò burúkú sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn “Jihād”, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìlànà ẹ̀sìn ’Islām. Bí àwọn kristiẹni kan ṣe ka jihād kún ìfipámúni-ṣẹ̀sìn-’Islām, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kristiẹni mìíràn ka jihād kún ọ̀nà ìdigunjalè l’órúkọ́ ẹ̀sìn ’Islām. Nínú ọ̀rọ̀ burúkú àwọn kristiẹni mìíràn lórí ọ̀rọ̀ jihād ni pé, wọ́n ti ìpasẹ̀ jihād sọ àwa mùsùlùmí di mùjẹ̀mùjẹ̀ bí àwọn Boko Harām. Ó kéré parí, dípò kí àwọn kristiẹni ṣẹ̀ṣà orúkọ rere fún àwa mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ jihād, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣẹ̀ṣà orúkọ rere fún àwọn kan tí wọ́n ń pè ni “ajàjàgbara” tàbí “ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn”, “alákatakítí-ẹ̀sìn ’Islām” ni orúkọ abunikù mìíràn tí àwọn kristiẹni tún fún wa nítorí ọ̀rọ̀ Jihād. Àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wọ̀nyí tí àwọn kristiẹni ń sọ sí àwa mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ jihād burú gan-an tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ t’ó fi jẹ́ pé, tí ẹnì kan bá kọ́kọ́ ka èyíkéyìí ìwé àtakò wọn sí ẹ̀sìn ’Islām tí wọ́n tẹ̀ jáde lórí ọ̀rọ̀ jihad, kò níí rí dáadáa kan kan lára Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwa mùsùlùmí àti ’Islām gan-an fúnra rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ àtakò burúkú àwọn kristiẹni wọ̀nyí sì ni ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń gbìn sínú ọkàn àwọn èwe wẹẹrẹ bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ilé-ìwé alákọ̀ọ́-bẹ̀rẹ̀ pé “’Islām bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú idà lọ́wọ́ ọ̀tún, Kurāni lọ́wọ́ òsì!” 
Àwọn kristiẹni, wọn a tún máa fi kún un pé, “Ìsọ̀rí mẹ́ta péré ni Allāhu àti Muhammad pín gbogbo ayé sí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kìíní ni àwọn mùsùlùmí t’ó lè pa àwọn ènìyàn bí àwọn pààyàn-pààyàn, t’ó sì lè gba àwọn dúkìá àwọn ènìyàn lọ́wọ́ wọn bí ìgárá-ọlọ́ṣà; àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo t’ó máa wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kejì ni àwọn mùsùlùmí tí wọn kò fẹ́ kí ẹ̀mí ènìyàn kan kan tọwọ́ àwọn bọ́, tí wọ́n sì ka fífi ogun jíjà gba dúkìá àwọn ènìyàn kún ìwà ọ̀daràn pọ́nńbélé; àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu wọn pè ní munāfiki, alágàbàǹgebè t’ó máa wà nínú àjà ìṣàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kẹta ni gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn ‘Islām; àwọn wọ̀nyẹn sì ni àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn ọ̀ṣẹbọ.” Ní àkótán, àwọn kristiẹni, wọn a tún máa sọ pé. “Âlàáfíà ni Jésù Kristi mú wá sáyé ni kò fi jagun ẹ̀sìn. Àmọ́ ìparun ni Muhammad mú wá sáyé l’ó fi kógun ja gbogbo ayé!” Ìwọ̀nyẹn ni díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àtakò tí àwọn kristiẹni máa ń sọ lásọtúnsọ sí àwa mùsùlùmí. 
Kódà, nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọn máa ń tọ́ka sí àwọn āyah kọ̀ọ̀kan àti àwọn hadīth kọ̀ọ̀kan t’ó ń pa àwa mùsùlùmí òdodo láṣẹ ogun jíjà sójú ọ̀nà Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ka ẹyọ kan tàbí òmíràn nínú àwọn ìwé àwọn kristiẹni lórí àwa mùsùlùmí kò níí ṣàì rí irúfẹ́ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ tí mo mú wá ṣíwájú wọ̀nyẹn nínú wọn. Ní pàápàá jùlọ, àwọn oníròyìn lórí ẹ̀rọ rédíò àti tẹlifísọ̀n àti àwọn ìwé ìròyìn gbogbo kò là nínú sísọ àwọn ọ̀rọ̀ abunikù bẹ́ẹ̀ sí àwa mùsùlùmí. 
Mo ṣetán báyìí láti mú àlàyé díẹ̀ ní ṣókíṣókí wá lórí ọ̀rọ̀ jihād. Ní àkọ́kọ́ ná, bóyá ni ẹnì kan fi lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ogun jíjà fún ẹ̀sìn ‘Islām yé tí onítọ̀ún kò bá ní ìmọ̀ òdodo pọ́nńbélé nípa ìtàn ìgbésí ayé Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti ìtàn àwọn ẹ̀dá ẹlẹ̀sìn t’ó wà lásìkò rẹ̀. Ìdí èyí ni pé, kódà tí ẹnì kan bá ń tọ́ka sí āyah ogun tàbí hadīth ogun, ó gbọ́dọ̀ yé onítọ̀ún – tí kò bá níí ṣàbòsí sórí ara rẹ̀ - pé ọ̀rọ̀ l’ó ń ṣíwájú ogun, ọ̀rọ̀ l’ó ń kẹ́yìn ogun. 
Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bẹ̀rẹ̀ ’Islām rẹ̀ nínú ìlú Mọkkah láààrin kìkìdá ọ̀ṣẹbọ. Àwọn ará ìlú Mọkkah, lásìkò náà, ni ọmọ-ojúmọ́-kan òòṣà kan. Àwọn ọ̀ṣẹbọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ ìnira t’ó lágbára kan Ànábì àti àwọn ènìyàn díẹ̀ t’ó ti gbà fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ṣíwájú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó di Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, ìyẹn ogójì ọdún àkọ́kọ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ ẹni rere, olódodo, olùfọkàntán, oníwà-ìrẹ̀lẹ̀, akínkanjú ènìyàn àti ọmọlúàbí láààrin ìlú Mọkkah. Kò sì sí ẹnì kan nígbà náà t’ó ń f’ẹnu àbùkù kàn án. Kódà gbogbo ará ìlú wọn l’ó mọ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sí olódodo àti olùfọkàntán. 
Àmọ́ níkété t’ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ọlọ́hun nínú ìlú, àwọn ará ìlú sọ ọ́ di “wèrè, òpìdán, akéwì” fún wí pé ìpèpè rẹ̀ lòdì sí ìbọ̀rìṣà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi kọjú oro sí òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ọ̀ṣẹbọ lu èyí tí ó ṣe é lù lálùbami nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ọ̀ṣẹbọ sì pa èyí tí ó ṣe é pa nínú wọn ní ìpakúpa. Bí àwọn ọ̀ṣẹbọ ṣe ń pa àwọn ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pa àwọn obìnrin. Àwọn ọmọ wẹẹrẹ gan-an kò móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ lásìkò náà. Kò sì sí ìgbà kan tí àwọn ọ̀ṣẹbọ bá pitú ọwọ́ wọn han àwọn mùsùlùmí lásìkò náà, àfi kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fún wọn ní àrọwà sùúrù mu. Ó sì tún máa jẹ́ kí ó yé wọn pé, irú ìyà mìíràn tí òun kò mọ̀ tún lè tọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ wá lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ sá, kí àwọn mùsùlùmí má ṣe tìtorí ìnira àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ẹ̀sìn Ọlọ́hun sílẹ̀. Èyí l’ó jẹyọ nínú sürah al-‘Ahƙọ̄f; 46:9. 
Ní òdodo kàkà kí àwọn ọ̀ṣẹbọ yìí fi àwọn mùsùlùmí lọ́rùn sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n tún le mọ́ wọn sí i. Nígbà tí ìnira yìí sì ń lọ síbi ìfojú-egbò-rìn, láì dáràn kan tayọ pípe “Allāhu ni Ọlọ́hun àti Olúwa”, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yọ̀ǹda fún àwọn mùsùlùmí kan pé kí wọ́n fi ìlú bàbá wọn sílẹ̀, kí wọ́n gbé ẹ̀sìn wọn sá fún àwọn ọ̀ṣẹbọ, kí wọ́n lọ forí pamọ́ sínú ìlú mìíràn. Èyí l’ó ṣòkùnfà bí àwọn kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe lọ ṣàtìpó nílẹ̀ Habaṣah (Ethopia). Èyí sì ni ohun tí a mọ̀ sí Hijrah àkọ́kọ́ t’ó wáyé nínú ìjọ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìkọ̀ kìíní lọ. Ìkọ̀ kejì náà lọ.
Ilẹ̀ Habaṣah wà lábẹ́ ọba Kristiẹni kan lásìkò náà. Orúkọ ọba náà ni ‘’Ashamọh bun al-Hurr an-Najāṣīy (rọdiyallāhu 'anhu). Àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah kúkú tọpasẹ̀ àwọn mùsùlùmí dé inú ìlú náà. Wọ́n sì lọ ṣe tánàdí àwọn mùsùlùmí lọ́dọ̀ ọba náà. Wọ́n fi ẹ̀sùn gban̄kọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kan àwọn mùsùlùmí. Àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ fún ọba pé, “ẹrú àwọn t’ó sá mọ́ àwọn lọ́wọ́ ni àwọn mùsùlùmí náà. Wọ́n ní àwọn mùsùlùmí náà kò ní ìtẹríba fún àwọn àgbà. Paríparí rẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ pé àwọn mùsùlùmí ń sọ àìdáa sí ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀.” Orí ọba náà gbóná wá. Lójú ẹsẹ̀, ó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ kó gbogbo àwọn mùsùlùmí náà wá ṣíwájú òun. Èsì tí àwọn mùsùlùmí fọ̀ sí àwọn ẹ̀sùn náà ni pé, “àwọn kì í kúnlẹ̀ tàbí dọ̀bálẹ̀ fún ẹnikẹ́ni àfi Allāhu. Ìkíni “àlàáfíà fún ọ” ni ìkíni tàwọn. Àwọn kì í ṣe ẹrú t’ó sá mọ́ olówó rẹ̀ lọ́wọ́, àmọ́ nítorí pé àwọn kọ̀ láti máa bá wọn bọ̀rìṣà lọ l’ó mú àwọn ọ̀ṣẹbọ t’ó ń darí ìlú gbógun líle ti àwọn. Wọ́n pa nínú àwọn nípakúpa nígbà tí lílù àlùbami àti lílẹ̀lókò kò ran àwọn mọ́. Níwọ̀n ìgbà tí àyè mìíràn sì wà láyé l’àwọn fi sá wá síbí. Nípa ti ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá rẹ̀, kò sí ẹni t’ó fẹnu àbùkù kàn wọ́n rí nínú àwọn.” Agbẹnusọ wọn, Ja‘far (rọdiyallāhu 'anhu) sì ké sūrah Mọryam fún wọn nínú ààfin ọba. Orí ọba wú nígbà tí ó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òdodo tí al-Ƙur’ān ń sọ nípa ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá rẹ̀. Èyí tí ń ṣe àfihàn pé “wòlíì náà tí à ń retí ti dé”. Ọba náà kò ṣe méní, kò ṣe méjì, ó gbàfà fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì fínnúfíndọ̀ gba ’Islām. Ó sì ṣe ẹ̀sìn ’Islām d’ọjọ́ ikú rẹ̀ (rọdiyallāhu 'anhu). Ọba wá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àdéhùn àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí nínú ìlú rẹ̀. Ojú ti àwọn ọ̀ṣẹbọ náà. Wọ́n sì dárí padà wá sínú ìlú Mọkkah láti tẹ̀ síwájú nínú ìfìnira kan àwọn mùsùlùmí t’ó ṣẹ́kù nínú ìlú wọn. Ọba yìí àti irú rẹ̀ mìíràn nínú àwọn èèkàn èèkàn kristiẹni t’ó gba ẹ̀sìn ’Islām sínú ayé wọn wọ́ọ́rọ́wọ́ ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí nínú àwọn súrah kan bíi tinú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:82-85. 
Síwájú sí i, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah tún ń fínná mọ́ àwọn mùsùlùmí ìlú Mọkkah ju ti àtẹ̀yìnwá lọ t’ó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ṣèpàdé lórí bí wọ́n ṣe máa pa Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ní alẹ́ ọjọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah gbéra láti gbẹ̀mí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Allāhu tú àṣírí èròkérò wọn fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì pa á láṣẹ láti sá kúrò nínú ìlú bàbá rẹ̀ fún wọn. Allāhu pa òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣàtìpó sínú ìlú Mọdīnah. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀ṣẹbọ tọpasẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Abu-Bakr as-Siddīƙ (rọdiyallāhu 'anhu) lórí ìrìn-àjò wọn sí ìlú Mọdināh, Allāhu kó àwọn méjèèjì yọ nínú ṣùtá àwọn t’ó tọpasẹ̀ wọn. Èyí mú kí àwọn ọ̀ṣẹbọ fàbọ̀ sórí àwọn t’ó kù lẹ́yìn. Àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dènà dè wọ́n bí ìgbà tí ẹkùn bá ń dènà de ẹranko. Àwọn tí ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ba bà nínú àwọn mùsùlùmí, yálà kí ó padà sínú ìlú Mọkkah fún ìdíyàjẹ t’ó kọjá àfaradà tàbí tí ó bá kọ̀ kí wọ́n pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sójú ọ̀nà. 
Àyà kò tún ko àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah láti lé àwọn mùsùlùmí kan wọnú ìlú Modīnah. Nígbà tí ọwọ́ wọn bá sì tẹ̀ wọ́n níbẹ̀, Wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìlú Mọkkah pẹ̀lú ìjìyà t’ó dópin. Lásìkò yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yọ̀ǹda fún àwọn mùsùlùmí náà láti jàjà gbára fún ẹ̀mí ara wọn, láti gba àwọn ìyàwó wọn sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àti àwọn tí kò rọ́nà jáde kúrò nínú ìlú Mọkkah. Kí wọ́n lè dáàbò bo ẹ̀sìn wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Hajj; 22: 39-41 àti sūrah an-Nisā’; 4:75. Gbogbo ìwọ̀nyí l’ó kúkú bi āyah ogun ẹ̀sìn, èyí tí àwọn kristiẹni ń tọ́ka sí lódì lódì báyìí. 
Āyah àti hadīth tí wọ́n sì tún ń tọ́ka sí lórí jíja àwọn kristiẹni àti àwọn yẹhudi lógun kò ṣàdédé wáyé bí kò ṣe nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí àwọn ìjọ méjèèjì hù níwà sí àwọn mùsùlùmí nínú ìlú Mọdinah Onímọ̀ọ́lẹ́. Ìdí ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bá ìjọ yẹhudi àti kristiẹni nínú ìlú Mọdīnah gẹ́gẹ́ bí àrè, wọn kì í ṣe ọmọ-onílùú rárá nítorí pé àwọn ìdílé ’Aos àti ìdílé Kazraj l’ó ni ìlú wọn, ìlú Mọdīnah. 
Níkété tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gúnlẹ̀ sínú ìlú Mọdīnah ni àwọn ìdílé méjèèjì wọ̀nyí fa àkóṣo àti ìjọba ìlú Mọdīnah lé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ láì bèèrè fún un nítorí pé kò fẹ́ẹ̀ ṣẹ́ku ẹnì kan kan tí kò gba ’Islām wọ́ọ́rọ́wọ́. Ìgbàláàyè tí àwọn ọmọ ìlú Mọdīnah ṣe fún Ànábì wa yìí l’ó kúkú sọ àwọn náà di “al-’Ansọ̄r” –alárànṣe-ẹ̀sìn. Àti pé orúkọ ìlú Mọdīnah yí padà kúrò ní Yẹthrib, ó sì di Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn t’ó wá ṣàtìpó sínú ìlú náà ṣe ń jẹ́ “al-Muhājirūn” – atorí-ẹ̀sìn-gbélùú-ẹni-jùsílẹ̀ -. Nígbà tí àṣẹ ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ dé ọwọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ó di alásẹ gbogbogbò fún ìlú Mọdīnah láti ọdún àkọ́kọ́ t’ó ti wọ inú ìlú náà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lé àwọn yẹhudi àti àwọn kristiẹni kúrò nínú ìlú Mọdīnah àti ìgbéríko rẹ̀. Kódà àwọn ìjọ yẹhudi ní abúlé tiwọn tí wọ́n mọ odi yíra wọn ká pẹ̀lú rẹ̀. Lábẹ́ “ààbò-ara-ẹni lààbò ìlú” l’ó mú kí àdéhùn ojú-lalákàn fi í ṣọ́rí wáyé láààriin ìjọ mùsùlùmí àti àwọn yẹhudi t’ó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àmọ́ ńṣe ni àwọn yẹhudi wọ̀nyí lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah. Wọ́n sì fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ àwọn mùsùlùmí níṣu. Èyí lóbí àwọn āyah àti hadīth tí wọ́n ń tọ́ka sí lónìí lódì lódì lórí gbígbé ogun tí àwọn ahlul-kitāb. 
Ìṣẹ́gun ńlá àti àrànṣe t’ó lágbára lórí àwọn ọ̀tá ’Islām àkọ́kọ́ tí Allāhu fi kó Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ṣùtá àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb, òhun ni à ń pè ní jihād. Ní ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ èkù-idà rárá títí Allāhu fi gbé e lọ sínú sánmọ̀. Òun náà ìbá kúkú jagun nítorí pé, àwọn yẹhudi kò fi òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ láì gbógun tì wọ́n. Àmọ́, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò wọ ipò aláṣẹ ìlú, áḿbọ̀sìbọ̀sí pé ó máa ní ọmọ ogun t’ó lè kó jagun ẹ̀sìn. Àti pé mélòó gan-an ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ t’ó fi máa dira ogun? Gbígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gbà fún Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ọlọ́hun fi jogún ìjọba ìlú fún un l’ó fi rí ogun àjàyè jà lórí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn ’Islām. Tàbí ṣe a rí ìjọba kan láyé tí kò ní ọmọ ogun ni? Ìjọba ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìjọba àlàáfíà sì ni pẹ̀lú nítorí pé, nípasẹ̀ ogun ẹ̀sìn ni àlàáfíà fi jọba lérékùsù Lárúbáwá. Ìkọjá-ẹnu-àlà àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb l’ó sì bí jihad nítorí pé, ìwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi pèpè sẹ́sìn. 
Àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb wọ̀nyẹn kò sì yé tayọ ẹnu-àlà sí àwa mùsùlùmí títí di àsìkò yìí. Ṣebí ọ̀rọ̀-ẹnu ni àwa mùsùlùmí sì fi ń yanjú rẹ̀ lọ́wọ́ lásìkò tiwa yìí. Ó sàn fún àwọn olùtayọ-ẹnu-àlà wọ̀nyẹn kí wọ́n jẹ́ kí ó mọ bẹ́ẹ̀. Kò sí ìfipámúni-ṣẹ̀sìn ’Islām nítorí pé àwọn āyah kan, bíi sūrah Yūnus; 10:99-100, ti fi rinlẹ̀ pé, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni Allāhu máa ṣe ní mùsùlùmí. Àmọ́ Allāhu kọ kí ẹlẹ̀sìn máa fi ìníra kan ẹlẹ̀sìn mìíràn. Nítorí náà, òkìkí tí àwọn kristiẹni ń fún àwa mùsùlùmí kò lè yọ jihād kúrò nínú ẹ̀sìn ’Islām. Tí wọn kò bá fẹ́ ká ṣe jihād lórí àwọn kí wọ́n so ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́.

### الآية 9:14

> ﻿قَاتِلُوهُمْ يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ بِأَيْدِيكُمْ وَيُخْزِهِمْ وَيَنْصُرْكُمْ عَلَيْهِمْ وَيَشْفِ صُدُورَ قَوْمٍ مُؤْمِنِينَ [9:14]

Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn.

### الآية 9:15

> ﻿وَيُذْهِبْ غَيْظَ قُلُوبِهِمْ ۗ وَيَتُوبُ اللَّهُ عَلَىٰ مَنْ يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [9:15]

Ó tún máa kó ìbínú ọkàn wọn lọ. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 9:16

> ﻿أَمْ حَسِبْتُمْ أَنْ تُتْرَكُوا وَلَمَّا يَعْلَمِ اللَّهُ الَّذِينَ جَاهَدُوا مِنْكُمْ وَلَمْ يَتَّخِذُوا مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلَا رَسُولِهِ وَلَا الْمُؤْمِنِينَ وَلِيجَةً ۚ وَاللَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ [9:16]

Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn t’ó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 9:17

> ﻿مَا كَانَ لِلْمُشْرِكِينَ أَنْ يَعْمُرُوا مَسَاجِدَ اللَّهِ شَاهِدِينَ عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ بِالْكُفْرِ ۚ أُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ وَفِي النَّارِ هُمْ خَالِدُونَ [9:17]

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti ṣe àmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná.

### الآية 9:18

> ﻿إِنَّمَا يَعْمُرُ مَسَاجِدَ اللَّهِ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَأَقَامَ الصَّلَاةَ وَآتَى الزَّكَاةَ وَلَمْ يَخْشَ إِلَّا اللَّهَ ۖ فَعَسَىٰ أُولَٰئِكَ أَنْ يَكُونُوا مِنَ الْمُهْتَدِينَ [9:18]

Ẹni tí ó máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, t’ó sì ń kírun, t’ó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà.

### الآية 9:19

> ﻿۞ أَجَعَلْتُمْ سِقَايَةَ الْحَاجِّ وَعِمَارَةَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ كَمَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَجَاهَدَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ لَا يَسْتَوُونَ عِنْدَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ [9:19]

Ṣé ẹ máa ṣe fífún alálàájì ní omi mu àti ṣíṣe àmójútó Mọ́sálásí Haram ní ohun t’ó dọ́gba sí ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, t’ó sì jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu? Wọn kò dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

### الآية 9:20

> ﻿الَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ أَعْظَمُ دَرَجَةً عِنْدَ اللَّهِ ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَائِزُونَ [9:20]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:100.

### الآية 9:21

> ﻿يُبَشِّرُهُمْ رَبُّهُمْ بِرَحْمَةٍ مِنْهُ وَرِضْوَانٍ وَجَنَّاتٍ لَهُمْ فِيهَا نَعِيمٌ مُقِيمٌ [9:21]

Olúwa wọn ń fún wọn ní ìró ìdùnnú nípa ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí ìdẹ̀ra gbére wà fún wọn nínú rẹ̀.

### الآية 9:22

> ﻿خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عِنْدَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ [9:22]

Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹ̀san ńlá wà.

### الآية 9:23

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا آبَاءَكُمْ وَإِخْوَانَكُمْ أَوْلِيَاءَ إِنِ اسْتَحَبُّوا الْكُفْرَ عَلَى الْإِيمَانِ ۚ وَمَنْ يَتَوَلَّهُمْ مِنْكُمْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ [9:23]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn bàbá yín àti àwọn arakùnrin yín ní ọ̀rẹ́ àyò bí wọ́n bá gbọ́lá fún àìgbàgbọ́ lórí ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:23-24, sūrah Luƙmọ̄n; 31:14-15 àti sūrah al-’Ankabūt; 29:8, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa ọmọ láṣẹ láti ṣe rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì, kódà kí àwọn méjèèjì jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí ọ̀ṣẹbọ. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láààrin ṣíṣe rere sí òbí àti títẹ̀lé àṣẹ òbí lórí ohun t’ó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìdí nìyí tí àwọn sūrah at-Taobah; 9:23 àti sūrah al-Mujādilah; 58:22 fi ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn ọmọ láti tẹ̀lé àṣẹ òbí wọn nígbà tí àṣẹ wọn bá ti jẹmọ́ ìbọ̀rìṣà, àìgbàgbọ́ àti ìyapa àṣẹ Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí ṣíṣe bidah. Nítorí náà, ọmọ ní ẹ̀tọ́ láti ṣe rere sí òbí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ní ẹ̀tọ́ láti kọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá páṣẹ t’ó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún un. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìṣẹ̀yá-ṣẹbàbá.

### الآية 9:24

> ﻿قُلْ إِنْ كَانَ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَاؤُكُمْ وَإِخْوَانُكُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ وَعَشِيرَتُكُمْ وَأَمْوَالٌ اقْتَرَفْتُمُوهَا وَتِجَارَةٌ تَخْشَوْنَ كَسَادَهَا وَمَسَاكِنُ تَرْضَوْنَهَا أَحَبَّ إِلَيْكُمْ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ وَجِهَادٍ فِي سَبِيلِهِ فَتَرَبَّصُوا حَتَّىٰ يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ [9:24]

Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn bàbá yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn arákùnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ìbátan yín pẹ̀lú àwọn dúkìá kan tí ẹ ti kó jọ àti òkòwò kan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù pé kí ó má kùtà àti àwọn ibùgbé tí ẹ yọ́nú sí, (tí ìwọ̀nyí) bá wù yín ju Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú jíja ogun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀, ẹ máa retí (ìkángun) nígbà náà títí Allāhu yóò fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 9:25

> ﻿لَقَدْ نَصَرَكُمُ اللَّهُ فِي مَوَاطِنَ كَثِيرَةٍ ۙ وَيَوْمَ حُنَيْنٍ ۙ إِذْ أَعْجَبَتْكُمْ كَثْرَتُكُمْ فَلَمْ تُغْنِ عَنْكُمْ شَيْئًا وَضَاقَتْ عَلَيْكُمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ ثُمَّ وَلَّيْتُمْ مُدْبِرِينَ [9:25]

Dájúdájú Allāhu ti ṣe àrànṣe fun yín ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ojú ogun àti ní ọjọ́ (ogun) Hunaen, nígbà tí pípọ̀ yín jọ yín lójú, (àmọ́) kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan; ilẹ̀ sì fún mọ yín tòhun ti bí ó ṣe fẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìn dà, ẹ sì ń sá sẹ́yìn.

### الآية 9:26

> ﻿ثُمَّ أَنْزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ وَعَلَى الْمُؤْمِنِينَ وَأَنْزَلَ جُنُودًا لَمْ تَرَوْهَا وَعَذَّبَ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الْكَافِرِينَ [9:26]

Lẹ́yìn náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó tún sọ àwọn ọmọ ogun kan kalẹ̀, tí ẹ ò fojú rí wọn. Ó sì jẹ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.

### الآية 9:27

> ﻿ثُمَّ يَتُوبُ اللَّهُ مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ عَلَىٰ مَنْ يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ [9:27]

Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́ lẹ́yìn ìyẹn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 9:28

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْمُشْرِكُونَ نَجَسٌ فَلَا يَقْرَبُوا الْمَسْجِدَ الْحَرَامَ بَعْدَ عَامِهِمْ هَٰذَا ۚ وَإِنْ خِفْتُمْ عَيْلَةً فَسَوْفَ يُغْنِيكُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ إِنْ شَاءَ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [9:28]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ẹ̀gbin ni àwọn ọ̀sẹbọ. Nítorí náà, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ Mọ́sálásí Haram lẹ́yìn ọdún wọn yìí. Tí ẹ bá ń bẹ̀rù òṣì, láìpẹ́ Allāhu máa rọ̀ yín lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀, tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 9:29

> ﻿قَاتِلُوا الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَلَا بِالْيَوْمِ الْآخِرِ وَلَا يُحَرِّمُونَ مَا حَرَّمَ اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَلَا يَدِينُونَ دِينَ الْحَقِّ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ حَتَّىٰ يُعْطُوا الْجِزْيَةَ عَنْ يَدٍ وَهُمْ صَاغِرُونَ [9:29]

Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀ àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ.

### الآية 9:30

> ﻿وَقَالَتِ الْيَهُودُ عُزَيْرٌ ابْنُ اللَّهِ وَقَالَتِ النَّصَارَى الْمَسِيحُ ابْنُ اللَّهِ ۖ ذَٰلِكَ قَوْلُهُمْ بِأَفْوَاهِهِمْ ۖ يُضَاهِئُونَ قَوْلَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ قَبْلُ ۚ قَاتَلَهُمُ اللَّهُ ۚ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ [9:30]

Àwọn yẹhudi wí pé: "‘Uzaer ni ọmọ Allāhu." Àwọn nasara sì wí pé: "Mọsīh ni ọmọ Allāhu." Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ wọn ní ẹnu wọn. Wọ́n ń fi jọ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ṣíwájú (wọn). Allāhu fi wọ́n gégùn-ún. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!

### الآية 9:31

> ﻿اتَّخَذُوا أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ وَالْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا إِلَٰهًا وَاحِدًا ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ سُبْحَانَهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ [9:31]

Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasara) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

### الآية 9:32

> ﻿يُرِيدُونَ أَنْ يُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَيَأْبَى اللَّهُ إِلَّا أَنْ يُتِمَّ نُورَهُ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ [9:32]

Wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Allāhu, Allāhu yó sì kọ̀ (fún wọn) títí Ó fi máa pé ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Rẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.

### الآية 9:33

> ﻿هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ [9:33]

(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (ẹ̀sìn ’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.

### الآية 9:34

> ﻿۞ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ كَثِيرًا مِنَ الْأَحْبَارِ وَالرُّهْبَانِ لَيَأْكُلُونَ أَمْوَالَ النَّاسِ بِالْبَاطِلِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۗ وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلَا يُنْفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشِّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ [9:34]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà (nínú nasara), wọ́n kúkú ń fi ọ̀nà èrú jẹ dúkìá àwọn ènìyàn ni, wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àwọn t’ó sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ, wọn kò sì ná an fún ẹ̀sìn Allāhu, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

### الآية 9:35

> ﻿يَوْمَ يُحْمَىٰ عَلَيْهَا فِي نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَىٰ بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنُوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ ۖ هَٰذَا مَا كَنَزْتُمْ لِأَنْفُسِكُمْ فَذُوقُوا مَا كُنْتُمْ تَكْنِزُونَ [9:35]

Ní ọjọ́ tí A óò máa yọ́ (wúrà àti fàdákà náà) nínú iná Jahanamọ, A ó sì máa fi jó iwájú wọn, ẹ̀gbẹ́ wọn àti ẹ̀yìn wọn. (A sì máa sọ pé): "Èyí ni ohun tí ẹ kó jọ fún ẹ̀mí ara yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ohun tí ẹ kó jọ wò."

### الآية 9:36

> ﻿إِنَّ عِدَّةَ الشُّهُورِ عِنْدَ اللَّهِ اثْنَا عَشَرَ شَهْرًا فِي كِتَابِ اللَّهِ يَوْمَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ مِنْهَا أَرْبَعَةٌ حُرُمٌ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ ۚ فَلَا تَظْلِمُوا فِيهِنَّ أَنْفُسَكُمْ ۚ وَقَاتِلُوا الْمُشْرِكِينَ كَافَّةً كَمَا يُقَاتِلُونَكُمْ كَافَّةً ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ [9:36]

Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí gbogbo yín sì gbógun ti àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe ń gbógun tì yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn ni pé, lára ẹ̀sìn àti ìjọ́sìn rẹ̀ ni lílo àwọn oṣù wọ̀nyí nítorí pé, oṣù náà ni à ń lò fún ìjọ́sìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Bí àpẹẹrẹ, à ń kí ìrun Jum‘ah ní ọjọ́ Jum‘ah, à ń gba ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n nínú oṣù Rọmọdọ̄n, a sì ń ṣe iṣẹ́ hajj nínú oṣù Thul-Hijjah.

### الآية 9:37

> ﻿إِنَّمَا النَّسِيءُ زِيَادَةٌ فِي الْكُفْرِ ۖ يُضَلُّ بِهِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُحِلُّونَهُ عَامًا وَيُحَرِّمُونَهُ عَامًا لِيُوَاطِئُوا عِدَّةَ مَا حَرَّمَ اللَّهُ فَيُحِلُّوا مَا حَرَّمَ اللَّهُ ۚ زُيِّنَ لَهُمْ سُوءُ أَعْمَالِهِمْ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ [9:37]

Àlékún nínú àìgbàgbọ́ ni dídájọ́ sí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ (láti ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ). Wọ́n ń fi kó ìṣìnà bá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nípa pé) wọ́n ń ṣe oṣù ọ̀wọ̀ kan ní oṣù ẹ̀tọ́ (fún ogun jíjà) nínú ọdún kan, wọ́n sì ń bu ọ̀wọ̀ fún oṣù (tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀) nínú ọdún (mìíràn, wọn kò sì níí jagun nínú rẹ̀) nítorí kí wọ́n lè yọ òǹkà oṣù tí Allāhu ṣe ní ọ̀wọ̀ síra wọn. Wọ́n sì tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ní ẹ̀tọ́ ohun tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.

### الآية 9:38

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا مَا لَكُمْ إِذَا قِيلَ لَكُمُ انْفِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ اثَّاقَلْتُمْ إِلَى الْأَرْضِ ۚ أَرَضِيتُمْ بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا مِنَ الْآخِرَةِ ۚ فَمَا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا فِي الْآخِرَةِ إِلَّا قَلِيلٌ [9:38]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí ni ó mu yín tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí A bá sọ fun yín pé kí ẹ jáde (láti jagun) lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (ìgbà náà ni) ẹ máa kàndí mọ́lẹ̀! Ṣé ẹ yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ju ti ọ̀run ni? Ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé (yìí) kò sì jẹ́ kiní kan nínú ti ọ̀run àfi díẹ̀.

### الآية 9:39

> ﻿إِلَّا تَنْفِرُوا يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا وَيَسْتَبْدِلْ قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّوهُ شَيْئًا ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ [9:39]

Àfi kí ẹ tú jáde (sógun ẹ̀sìn) ni Allāhu kò fi níí jẹ yín níyà ẹlẹ́ta-eléro àti pé ni kò fi níí fi ìjọ tó yàtọ̀ si yín pààrọ̀ yín. Ẹ kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá (Allāhu). Allāhu sì ni Alagbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 9:40

> ﻿إِلَّا تَنْصُرُوهُ فَقَدْ نَصَرَهُ اللَّهُ إِذْ أَخْرَجَهُ الَّذِينَ كَفَرُوا ثَانِيَ اثْنَيْنِ إِذْ هُمَا فِي الْغَارِ إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ اللَّهَ مَعَنَا ۖ فَأَنْزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَيْهِ وَأَيَّدَهُ بِجُنُودٍ لَمْ تَرَوْهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ الَّذِينَ كَفَرُوا السُّفْلَىٰ ۗ وَكَلِمَةُ اللَّهِ هِيَ الْعُلْيَا ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ [9:40]

Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.1 Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa."2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ ò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun l’ó sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
1Olùbárìn rẹ̀ ni ’Abū-Bakr as-Siddīƙ (rọdiyallāhu 'anhu). 2 “Allāhu wà pẹ̀lú wa” Ìyẹn ni pé, “Allāhu mọ̀ pé àwa méjèèjì wà nínú ọ̀gbun yìí, Ó ń gbọ́ wa, Ó ń rí wa. Nítorí náà, Ó máa kó wa yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyí tí wọ́n ń lépa wa.” Gbólóhùn yìí jọ sūrah Tọ̄hā; 20:46. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.

### الآية 9:41

> ﻿انْفِرُوا خِفَافًا وَثِقَالًا وَجَاهِدُوا بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنْفُسِكُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ [9:41]

Ẹ tú jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú okun àti ìrọ́jú. Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.

### الآية 9:42

> ﻿لَوْ كَانَ عَرَضًا قَرِيبًا وَسَفَرًا قَاصِدًا لَاتَّبَعُوكَ وَلَٰكِنْ بَعُدَتْ عَلَيْهِمُ الشُّقَّةُ ۚ وَسَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَوِ اسْتَطَعْنَا لَخَرَجْنَا مَعَكُمْ يُهْلِكُونَ أَنْفُسَهُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ [9:42]

Tí ó bá jẹ́ pé n̄ǹkan ìgbádùn (ọrọ̀ ogun) àrọ́wótó àti ìrìn-àjò tí kò jìnnà (l’o pè wọ́n sí ni), wọn ìbá tẹ̀lé ọ. Ṣùgbọ́n ìrìn-àjò ogun Tabūk jìnnà lójú wọn. Wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a lágbára ni, àwa ìbá jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú yín.” – Wọ́n sì ń kó ìparun bá ẹ̀mí ara wọn (nípa ṣíṣe ìṣọ̀bẹ-ṣèlu.) – Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọn.

### الآية 9:43

> ﻿عَفَا اللَّهُ عَنْكَ لِمَ أَذِنْتَ لَهُمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكَ الَّذِينَ صَدَقُوا وَتَعْلَمَ الْكَاذِبِينَ [9:43]

Allāhu ti ṣàmójúkúrò fún ọ. Kí ló mú ọ yọ̀ǹda fún wọn (pé kí wọ́n dúró sílé? Ìwọ ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀) títí ọ̀rọ̀ àwọn t’ó sòdodo yóò fi hàn sí ọ kedere. Ìwọ yó sì mọ àwọn òpùrọ́.

### الآية 9:44

> ﻿لَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ أَنْ يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ [9:44]

Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kò níí tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ láti má fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

### الآية 9:45

> ﻿إِنَّمَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَارْتَابَتْ قُلُوبُهُمْ فَهُمْ فِي رَيْبِهِمْ يَتَرَدَّدُونَ [9:45]

Àwọn t’ó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, dípò lílọ sí ojú-ogun) ni àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ọkan wọn sì ń ṣeyèméjì. Nítorí náà, wọ́n ń dààmú kiri níbi ìṣeyè-méjì wọn.

### الآية 9:46

> ﻿۞ وَلَوْ أَرَادُوا الْخُرُوجَ لَأَعَدُّوا لَهُ عُدَّةً وَلَٰكِنْ كَرِهَ اللَّهُ انْبِعَاثَهُمْ فَثَبَّطَهُمْ وَقِيلَ اقْعُدُوا مَعَ الْقَاعِدِينَ [9:46]

Tí ó bá jẹ́ pé wọn gbèrò ìjáde fún ogun ẹ̀sìn ni, wọn ìbá ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún un. Ṣùgbọ́n Allāhu kórira ìdìde wọn fún ogun ẹ̀sìn, Ó sì kó ìfàsẹ́yìn bá wọn. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: "Ẹ jókòó pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé."

### الآية 9:47

> ﻿لَوْ خَرَجُوا فِيكُمْ مَا زَادُوكُمْ إِلَّا خَبَالًا وَلَأَوْضَعُوا خِلَالَكُمْ يَبْغُونَكُمُ الْفِتْنَةَ وَفِيكُمْ سَمَّاعُونَ لَهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ [9:47]

Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n jáde pẹ̀lú yín, wọn kò níí kun yín àfi pẹ̀lú ìbàjẹ́. Wọn yó sì sáré máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láààrin yín, tí wọn yóò máa ko yín sínú ìyọnu. Àti pé wọ́n ní olùgbọ́rọ̀ fún wọn láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.

### الآية 9:48

> ﻿لَقَدِ ابْتَغَوُا الْفِتْنَةَ مِنْ قَبْلُ وَقَلَّبُوا لَكَ الْأُمُورَ حَتَّىٰ جَاءَ الْحَقُّ وَظَهَرَ أَمْرُ اللَّهِ وَهُمْ كَارِهُونَ [9:48]

Wọ́n kúkú ti dá ìyọnu sílẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n sì dojú àwọn ọ̀rọ̀ rú fún ọ títí òdodo fi dé, tí àṣẹ Allāhu sì fojú hàn kedere; ẹ̀mí wọn sì kọ̀ ọ́.

### الآية 9:49

> ﻿وَمِنْهُمْ مَنْ يَقُولُ ائْذَنْ لِي وَلَا تَفْتِنِّي ۚ أَلَا فِي الْفِتْنَةِ سَقَطُوا ۗ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌ بِالْكَافِرِينَ [9:49]

Ó wà nínú wọn, ẹni tí ń wí pé: “Yọ̀ǹda fún mi (kí n̄g jókòó sílé); má ṣe kó mi sínú àdánwò.” Inú àdánwò (sísá fógun ẹ̀sìn) má ni wọ́n ti ṣubú sí yìí. Dájúdájú iná Jahanamọ yó sì kúkú yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.

### الآية 9:50

> ﻿إِنْ تُصِبْكَ حَسَنَةٌ تَسُؤْهُمْ ۖ وَإِنْ تُصِبْكَ مُصِيبَةٌ يَقُولُوا قَدْ أَخَذْنَا أَمْرَنَا مِنْ قَبْلُ وَيَتَوَلَّوْا وَهُمْ فَرِحُونَ [9:50]

Tí dáadáa bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó máa bà wọ́n nínú jẹ́. Tí àìda bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gba àṣẹ tiwa ṣíwájú (láti jókòó sílé.)” Wọ́n á pẹ̀yìn dà; wọn yó sì máa dunnú.

### الآية 9:51

> ﻿قُلْ لَنْ يُصِيبَنَا إِلَّا مَا كَتَبَ اللَّهُ لَنَا هُوَ مَوْلَانَا ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ [9:51]

Sọ pé: “Kò sí ohun kan t’ó máa ṣẹlẹ̀ sí wa àyàfi ohun tí Allāhu kọ mọ́ wa. Òun ni Aláàbò wa.” Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

### الآية 9:52

> ﻿قُلْ هَلْ تَرَبَّصُونَ بِنَا إِلَّا إِحْدَى الْحُسْنَيَيْنِ ۖ وَنَحْنُ نَتَرَبَّصُ بِكُمْ أَنْ يُصِيبَكُمُ اللَّهُ بِعَذَابٍ مِنْ عِنْدِهِ أَوْ بِأَيْدِينَا ۖ فَتَرَبَّصُوا إِنَّا مَعَكُمْ مُتَرَبِّصُونَ [9:52]

Sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń retí kiní kan pẹ̀lú wa ni bí kò ṣe ọ̀kan nínú dáadáa méjì (ikú ogun tàbí ìṣẹ́gun)? Àwa náà ń retí pẹ̀lú yín pé kí Allāhu mú ìyà kan wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tàbí láti ọwọ́ wa. Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú àwa náà wà pẹ̀lú yín tí à ń retí."

### الآية 9:53

> ﻿قُلْ أَنْفِقُوا طَوْعًا أَوْ كَرْهًا لَنْ يُتَقَبَّلَ مِنْكُمْ ۖ إِنَّكُمْ كُنْتُمْ قَوْمًا فَاسِقِينَ [9:53]

Sọ pé: "Ẹ fínnú-fíndọ̀ náwó ni tàbí pẹ̀lú tipátipá, A ò níí gbà á lọ́wọ́ yín (nítorí pé) dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́."

### الآية 9:54

> ﻿وَمَا مَنَعَهُمْ أَنْ تُقْبَلَ مِنْهُمْ نَفَقَاتُهُمْ إِلَّا أَنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَبِرَسُولِهِ وَلَا يَأْتُونَ الصَّلَاةَ إِلَّا وَهُمْ كُسَالَىٰ وَلَا يُنْفِقُونَ إِلَّا وَهُمْ كَارِهُونَ [9:54]

Kò sì sí ohun kan tí kò jẹ́ kí Á gba ìnáwó wọn lọ́wọ́ wọn bí kò ṣe pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọn kò níí wá kírun àfi kí wọ́n jẹ́ òròjú aláìníkan-ánṣe. Wọn kò sì níí náwó fẹ́sìn àfi kí ẹ̀mí wọn kọ̀ ọ́.

### الآية 9:55

> ﻿فَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمْ بِهَا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنْفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ [9:55]

Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn yà ọ́ lẹ́nu; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́.

### الآية 9:56

> ﻿وَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ إِنَّهُمْ لَمِنْكُمْ وَمَا هُمْ مِنْكُمْ وَلَٰكِنَّهُمْ قَوْمٌ يَفْرَقُونَ [9:56]

Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan t’ó ń bẹ̀rù.

### الآية 9:57

> ﻿لَوْ يَجِدُونَ مَلْجَأً أَوْ مَغَارَاتٍ أَوْ مُدَّخَلًا لَوَلَّوْا إِلَيْهِ وَهُمْ يَجْمَحُونَ [9:57]

Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n rí ibùsásí kan, tàbí àwọn ihò àpáta kan, tàbí ibùsáwọ̀ kan, wọn ìbá ṣẹ́rí síbẹ̀ ní wéréwéré.

### الآية 9:58

> ﻿وَمِنْهُمْ مَنْ يَلْمِزُكَ فِي الصَّدَقَاتِ فَإِنْ أُعْطُوا مِنْهَا رَضُوا وَإِنْ لَمْ يُعْطَوْا مِنْهَا إِذَا هُمْ يَسْخَطُونَ [9:58]

Ó tún wà nínú wọn, ẹni tí ń dá ọ lẹ́bi níbi (pípín) àwọn ọrẹ. Tí A bá fún wọn nínú rẹ̀, wọ́n á yọ́nú (sí i). Tí A ò bá sì fún wọn nínú rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa bínú.

### الآية 9:59

> ﻿وَلَوْ أَنَّهُمْ رَضُوا مَا آتَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَقَالُوا حَسْبُنَا اللَّهُ سَيُؤْتِينَا اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ وَرَسُولُهُ إِنَّا إِلَى اللَّهِ رَاغِبُونَ [9:59]

Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: "Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ) , dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí."
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
N̄ǹkan tí āyah yìí ń sọ ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́tọ̀ọ́ sí pípín àwọn ọrẹ tí Allāhu pín kàn án nínú àwọn oore ayé àrígbámú yálà nípasẹ̀ ọrọ̀ ogun, zakāh gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ìbámu sí āyah 58 tí ó ṣíwájú rẹ̀ àti āyah 60 tí ó tẹ̀lé e. Kì í ṣe pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) l’ó ń pín oore ayé tàbí oore àjùlọ fún àwọn ẹ̀dá.

### الآية 9:60

> ﻿۞ إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ ۖ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [9:60]

Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù, àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām, àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn t’ó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
“Faƙīr” ni aláìní, tálíkà, olòṣì. Ìyẹn ni ẹni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ́ tí kò rí iṣẹ́ kan kan ṣe, yálà lábẹ́ ènìyàn tàbí iṣẹ́ àdáni. Kò sì ní ọ̀nà kan kan tí ó lè gbà rí owó. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara tirẹ̀. “Miskīn” ni mẹ̀kúnnù. Ìyẹn ni ẹni tí ó ń rí iṣẹ́ kan ṣe, àmọ́ tí owó t’ó ń rí lórí iṣẹ́ náà kò ká àpapọ̀ bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀, owó ilé gbígbé rẹ̀ àti gbígbọ́ bùkátà lórí ará ilé rẹ̀. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi yanjú bùkátà ọrùn rẹ̀.

### الآية 9:61

> ﻿وَمِنْهُمُ الَّذِينَ يُؤْذُونَ النَّبِيَّ وَيَقُولُونَ هُوَ أُذُنٌ ۚ قُلْ أُذُنُ خَيْرٍ لَكُمْ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَيُؤْمِنُ لِلْمُؤْمِنِينَ وَرَحْمَةٌ لِلَّذِينَ آمَنُوا مِنْكُمْ ۚ وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ رَسُولَ اللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ [9:61]

Àwọn t’ó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni." Sọ pé: "Elétí-ọfẹ rere ni fun yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gbà àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.”

### الآية 9:62

> ﻿يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَكُمْ لِيُرْضُوكُمْ وَاللَّهُ وَرَسُولُهُ أَحَقُّ أَنْ يُرْضُوهُ إِنْ كَانُوا مُؤْمِنِينَ [9:62]

Wọ́n ń fi Allāhu búra fun yín láti wá ìyọ́nú yín. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ l’ó sì yẹ kí wọ́n wá ìyọ́nú Rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

### الآية 9:63

> ﻿أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّهُ مَنْ يُحَادِدِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَأَنَّ لَهُ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدًا فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ الْخِزْيُ الْعَظِيمُ [9:63]

Ṣé wọn kò mọ̀ pé ẹnikẹ́ni t’ó bá ń tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un ni? Olùṣegbére sì ni nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni àbùkù ńlá.

### الآية 9:64

> ﻿يَحْذَرُ الْمُنَافِقُونَ أَنْ تُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ سُورَةٌ تُنَبِّئُهُمْ بِمَا فِي قُلُوبِهِمْ ۚ قُلِ اسْتَهْزِئُوا إِنَّ اللَّهَ مُخْرِجٌ مَا تَحْذَرُونَ [9:64]

Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bẹ̀rù pé kí Á má ṣe sọ sūrah kan kalẹ̀ nípa wọn, tí ó máa fún wọn ní ìró ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Sọ pé: "Ẹ máa ṣe yẹ̀yẹ́ lọ. Dájúdájú Allāhu yóò ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù."

### الآية 9:65

> ﻿وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلْعَبُ ۚ قُلْ أَبِاللَّهِ وَآيَاتِهِ وَرَسُولِهِ كُنْتُمْ تَسْتَهْزِئُونَ [9:65]

Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè, dájúdájú wọ́n á wí pé: "Àwa kàn ń rojọ́ lásán ni, a sì ń ṣàwàdà ni." Sọ pé: "Ṣé Allāhu, àwọn āyah Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́?"

### الآية 9:66

> ﻿لَا تَعْتَذِرُوا قَدْ كَفَرْتُمْ بَعْدَ إِيمَانِكُمْ ۚ إِنْ نَعْفُ عَنْ طَائِفَةٍ مِنْكُمْ نُعَذِّبْ طَائِفَةً بِأَنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ [9:66]

Ẹ má ṣe mú àwáwí wá. Dájúdájú ẹ ti ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín. Tí A bá ṣe àmójúkúrò fún apá kan nínú yín, A óò fìyà jẹ apá kan nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.

### الآية 9:67

> ﻿الْمُنَافِقُونَ وَالْمُنَافِقَاتُ بَعْضُهُمْ مِنْ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمُنْكَرِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمَعْرُوفِ وَيَقْبِضُونَ أَيْدِيَهُمْ ۚ نَسُوا اللَّهَ فَنَسِيَهُمْ ۗ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ هُمُ الْفَاسِقُونَ [9:67]

Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin, irú kan-ùn ni wọ́n; wọ́n ń pàṣẹ ohun burúkú, wọ́n ń kọ ohun rere, wọ́n sì ń káwọ́ gbera (láti náwó fẹ́sìn). Wọ́n gbàgbé Allāhu. Nítorí náà, Allāhu gbàgbé wọn. Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kò sí ìgbàgbé nínú ìròyìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Àmọ́ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo orúkọ iṣẹ́ aburú wọn fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.

### الآية 9:68

> ﻿وَعَدَ اللَّهُ الْمُنَافِقِينَ وَالْمُنَافِقَاتِ وَالْكُفَّارَ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ هِيَ حَسْبُهُمْ ۚ وَلَعَنَهُمُ اللَّهُ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُقِيمٌ [9:68]

Allāhu sì ti ṣe àdéhùn iná Jahanamọ fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin àti àwọn aláìgbàgbọ́. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀. Iná máa tó wọn. Allāhu sì ti ṣẹ́bi lé wọn. Ìyà gbére sì wà fún wọn.

### الآية 9:69

> ﻿كَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ كَانُوا أَشَدَّ مِنْكُمْ قُوَّةً وَأَكْثَرَ أَمْوَالًا وَأَوْلَادًا فَاسْتَمْتَعُوا بِخَلَاقِهِمْ فَاسْتَمْتَعْتُمْ بِخَلَاقِكُمْ كَمَا اسْتَمْتَعَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ بِخَلَاقِهِمْ وَخُضْتُمْ كَالَّذِي خَاضُوا ۚ أُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ [9:69]

(Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí dà) gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín; wọ́n le jù yín lọ ní agbára, wọ́n sì pọ̀ (jù yín lọ) ní àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Nígbà náà, wọ́n jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn (nínú oore ayé). Ẹ̀yin (ṣọ̀bẹ-ṣèlu wọ̀nyìí náà yóò) jẹ ìgbádùn ìpín tiyín gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín ṣe jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn. Ẹ̀yin náà sì sọ̀sọkúsọ bí èyí tí àwọn náà sọ ní ìsọkúsọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni ẹni òfò.

### الآية 9:70

> ﻿أَلَمْ يَأْتِهِمْ نَبَأُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَقَوْمِ إِبْرَاهِيمَ وَأَصْحَابِ مَدْيَنَ وَالْمُؤْتَفِكَاتِ ۚ أَتَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ [9:70]

Ṣé ìròyìn àwọn t’ó ṣíwájú wọn kò tì í dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí.

### الآية 9:71

> ﻿وَالْمُؤْمِنُونَ وَالْمُؤْمِنَاتُ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَيُطِيعُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ أُولَٰئِكَ سَيَرْحَمُهُمُ اللَّهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ [9:71]

Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan; wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n ń kírun, wọ́n ń yọ Zakāh, wọ́n sì ń tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò ṣàkẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 9:72

> ﻿وَعَدَ اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ وَرِضْوَانٌ مِنَ اللَّهِ أَكْبَرُ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ [9:72]

Allāhu ṣe àdéhùn àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó tún ṣe àdéhùn) àwọn ibùgbé t’ó dára nínú àwọn ọgbà ìdẹ̀ra ‘Adni (fún wọn). Ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó sì tóbi jùlọ (fún wọn). Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.

### الآية 9:73

> ﻿يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ جَاهِدِ الْكُفَّارَ وَالْمُنَافِقِينَ وَاغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ [9:73]

Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.

### الآية 9:74

> ﻿يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ مَا قَالُوا وَلَقَدْ قَالُوا كَلِمَةَ الْكُفْرِ وَكَفَرُوا بَعْدَ إِسْلَامِهِمْ وَهَمُّوا بِمَا لَمْ يَنَالُوا ۚ وَمَا نَقَمُوا إِلَّا أَنْ أَغْنَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ مِنْ فَضْلِهِ ۚ فَإِنْ يَتُوبُوا يَكُ خَيْرًا لَهُمْ ۖ وَإِنْ يَتَوَلَّوْا يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ عَذَابًا أَلِيمًا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَمَا لَهُمْ فِي الْأَرْضِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ [9:74]

Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ’Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò tako kiní kan bí kò ṣe nítorí pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì kọ̀yìn (si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

### الآية 9:75

> ﻿۞ وَمِنْهُمْ مَنْ عَاهَدَ اللَّهَ لَئِنْ آتَانَا مِنْ فَضْلِهِ لَنَصَّدَّقَنَّ وَلَنَكُونَنَّ مِنَ الصَّالِحِينَ [9:75]

Ó wà nínú wọn, ẹni t’ó bá Allāhu ṣe àdéhùn pé: "Tí Ó bá fún wa nínú oore-àjùlọ Rẹ̀, dájúdájú a óò máa tọrẹ, dájúdájú a ó sì wà nínú àwọn ẹni ire."

### الآية 9:76

> ﻿فَلَمَّا آتَاهُمْ مِنْ فَضْلِهِ بَخِلُوا بِهِ وَتَوَلَّوْا وَهُمْ مُعْرِضُونَ [9:76]

Àmọ́ nígbà tí Ó fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀, wọ́n ṣahun sí I. Wọ́n pẹ̀yìn dà, wọ́n sì ń gbúnrí (láti náwó fẹ́sìn).

### الآية 9:77

> ﻿فَأَعْقَبَهُمْ نِفَاقًا فِي قُلُوبِهِمْ إِلَىٰ يَوْمِ يَلْقَوْنَهُ بِمَا أَخْلَفُوا اللَّهَ مَا وَعَدُوهُ وَبِمَا كَانُوا يَكْذِبُونَ [9:77]

Nítorí náà, ahun wọn mú ọ̀rọ̀ wọn kángun sí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ọkàn wọn títí di ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Allāhu nítorí pé wọ́n yẹ àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe àti nítorí pé wọ́n ń parọ́.

### الآية 9:78

> ﻿أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَاهُمْ وَأَنَّ اللَّهَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ [9:78]

Ṣé wọn kò mọ̀ pé Allāhu mọ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ wọn, àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀?

### الآية 9:79

> ﻿الَّذِينَ يَلْمِزُونَ الْمُطَّوِّعِينَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ فِي الصَّدَقَاتِ وَالَّذِينَ لَا يَجِدُونَ إِلَّا جُهْدَهُمْ فَيَسْخَرُونَ مِنْهُمْ ۙ سَخِرَ اللَّهُ مِنْهُمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ [9:79]

Àwọn t’ó ń bú àwọn olùtọrẹ-àánú nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lórí ọrẹ títa àti àwọn tí kò rí n̄ǹkan kan tayọ ìwọ̀n agbára wọn, wọ́n sì ń fi wọn ṣe yẹ̀yẹ́, Allāhu fi àwọn náà ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.

### الآية 9:80

> ﻿اسْتَغْفِرْ لَهُمْ أَوْ لَا تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ إِنْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ سَبْعِينَ مَرَّةً فَلَنْ يَغْفِرَ اللَّهُ لَهُمْ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ [9:80]

Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn – kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin – Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Pẹ̀lú gbólóhùn yìí, àwọn kò-gbédè-ó-gbékèé nínú àwọn kristiẹni lérò pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí Allāhu sì foríjìn wá. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ ohun tí ń bẹ nínú āyah yìí ni pé, kò sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn aláìgbàgbọ́ àti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹni yòówù ó bá wọn tọrọ àforíjìn. Nípa ti òkú àwọn aláìgbàgbọ́, ẹ wo āyah 84 níwájú. Nípa ti òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, ẹ wo sūrah al-Munāfiƙūn; 63:6. Bákan náà, nípa ti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹ wo sūrah an-Nisā’; 4:48 àti 116 àti sūrah at-Taobah; 9:113. Bákàn náà, bíbá tí Allāhu ni kí àwọn mùsùlùmí lọ bá Ànábí (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti lè bá wọn tọrọ àforíjìn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Sūrah an-Nisā’; 4:64, ìyẹn náà ti wá sópin nípasẹ̀ ikú Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ọ̀wọ́ ìgbà tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń bẹ nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú nìkan ni ó lè bá ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì máa foríjìn ín. Àmọ́, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀. Ó sì di Ọjọ́ Àjíǹde kí Ànábì wa tó lè bá wa ṣ’ìpẹ̀ àṣegbà níwájú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nítorí náà, ìṣẹbọ sí Allāhu ni fún ẹnikẹ́ni láti lọ bá Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ìdí sàréè rẹ̀ fún títọrọ n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.

### الآية 9:81

> ﻿فَرِحَ الْمُخَلَّفُونَ بِمَقْعَدِهِمْ خِلَافَ رَسُولِ اللَّهِ وَكَرِهُوا أَنْ يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَقَالُوا لَا تَنْفِرُوا فِي الْحَرِّ ۗ قُلْ نَارُ جَهَنَّمَ أَشَدُّ حَرًّا ۚ لَوْ كَانُوا يَفْقَهُونَ [9:81]

Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn dunnú sí jíjókòó sínú ilé wọn lẹ́yìn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n sì kórira láti fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n tún wí pé: “Ẹ má lọ jagun nínú ooru gbígbóná.” Sọ pé: “Iná Jahanamọ le jùlọ ní gbígbóná, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀.”

### الآية 9:82

> ﻿فَلْيَضْحَكُوا قَلِيلًا وَلْيَبْكُوا كَثِيرًا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [9:82]

Nítorí náà, kí wọ́n rẹ́rìn-ín díẹ̀, kí wọ́n sì sunkún púpọ̀; (ó jẹ́) ẹ̀san (fún) ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 9:83

> ﻿فَإِنْ رَجَعَكَ اللَّهُ إِلَىٰ طَائِفَةٍ مِنْهُمْ فَاسْتَأْذَنُوكَ لِلْخُرُوجِ فَقُلْ لَنْ تَخْرُجُوا مَعِيَ أَبَدًا وَلَنْ تُقَاتِلُوا مَعِيَ عَدُوًّا ۖ إِنَّكُمْ رَضِيتُمْ بِالْقُعُودِ أَوَّلَ مَرَّةٍ فَاقْعُدُوا مَعَ الْخَالِفِينَ [9:83]

Tí Allāhu bá mú ọ délé bá igun kan nínú wọn, tí wọ́n bá wá ń gbàṣẹ lọ́dọ̀ rẹ fún jíjáde fún ogun ẹ̀sìn, sọ nígbà náà pé: “Ẹ̀yin kò lè jáde fún ogun ẹ̀sìn mọ́ pẹ̀lú mi. Ẹ̀yin kò sì lè ja ọ̀tá kan lógun mọ́ pẹ̀lú mi, nítorí pé ẹ ti yọ́nú sí ìjókòó sílé ní ìgbà àkọ́kọ́. Nítorí náà, ẹ jókòó sílé ti àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn.”

### الآية 9:84

> ﻿وَلَا تُصَلِّ عَلَىٰ أَحَدٍ مِنْهُمْ مَاتَ أَبَدًا وَلَا تَقُمْ عَلَىٰ قَبْرِهِ ۖ إِنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَمَاتُوا وَهُمْ فَاسِقُونَ [9:84]

Láéláé, o ò gbọdọ̀ kírun sí ẹnì kan kan lára nínú wọn, tí ó bá kú, o ò sì gbọdọ̀ dúró níbi sàréè rẹ̀, nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n wà nípò òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 9:85

> ﻿وَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَالُهُمْ وَأَوْلَادُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُعَذِّبَهُمْ بِهَا فِي الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنْفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ [9:85]

Má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn yà ọ́ lẹ́nu; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. (Ó sì fẹ́ kí) ẹ̀mí bọ́ lára wọn, nígbà tí wọ́n bá wà nípò aláìgbàgbọ́.

### الآية 9:86

> ﻿وَإِذَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ أَنْ آمِنُوا بِاللَّهِ وَجَاهِدُوا مَعَ رَسُولِهِ اسْتَأْذَنَكَ أُولُو الطَّوْلِ مِنْهُمْ وَقَالُوا ذَرْنَا نَكُنْ مَعَ الْقَاعِدِينَ [9:86]

Nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀ pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí wọ́n sí jagun pẹ̀lú Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (nígbà náà ni) àwọn ọlọ́rọ̀ nínú wọn yóò máa tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n á sì wí pé: “Fi wá sílẹ̀ kí á wà pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.”

### الآية 9:87

> ﻿رَضُوا بِأَنْ يَكُونُوا مَعَ الْخَوَالِفِ وَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ [9:87]

Wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. A ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò níí gbọ́ àgbọ́yé.

### الآية 9:88

> ﻿لَٰكِنِ الرَّسُولُ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ جَاهَدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ ۚ وَأُولَٰئِكَ لَهُمُ الْخَيْرَاتُ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [9:88]

Ṣùgbọ́n Òjíṣẹ́ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn oore ń bẹ fún wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.

### الآية 9:89

> ﻿أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ [9:89]

Allāhu ti pèsè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

### الآية 9:90

> ﻿وَجَاءَ الْمُعَذِّرُونَ مِنَ الْأَعْرَابِ لِيُؤْذَنَ لَهُمْ وَقَعَدَ الَّذِينَ كَذَبُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ سَيُصِيبُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ [9:90]

Àwọn aláwàáwí nínú àwọn Lárúbáwá oko wá (bá ọ) nítorí kí wọ́n lè yọ̀ǹda (ìjókòó sílé) fún wọn. Àwọn t’ó sì pe ọ̀rọ̀ Allāhu àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ nírọ́ náà jókòó sílé. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ ba àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn.

### الآية 9:91

> ﻿لَيْسَ عَلَى الضُّعَفَاءِ وَلَا عَلَى الْمَرْضَىٰ وَلَا عَلَى الَّذِينَ لَا يَجِدُونَ مَا يُنْفِقُونَ حَرَجٌ إِذَا نَصَحُوا لِلَّهِ وَرَسُولِهِ ۚ مَا عَلَى الْمُحْسِنِينَ مِنْ سَبِيلٍ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ [9:91]

Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn aláìlágbára, àwọn aláìsàn àti àwọn tí kò rí ohun tí wọn máa ná ní owó (láti fi jagun ẹ̀sìn) nígbà tí wọ́n bá ti ní òtítọ́ sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kò sí ìbáwí kan fún àwọn olótìítọ́-inú sẹ́. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 9:92

> ﻿وَلَا عَلَى الَّذِينَ إِذَا مَا أَتَوْكَ لِتَحْمِلَهُمْ قُلْتَ لَا أَجِدُ مَا أَحْمِلُكُمْ عَلَيْهِ تَوَلَّوْا وَأَعْيُنُهُمْ تَفِيضُ مِنَ الدَّمْعِ حَزَنًا أَلَّا يَجِدُوا مَا يُنْفِقُونَ [9:92]

Kò tún sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ pé kí o fún àwọn ní n̄ǹkan tí àwọn yóò gùn (lọ sójú ogun), tí o sì sọ pé, “N̄g ò rí n̄ǹkan tí mo lè fun yín gùn (lọ sójú ogun), wọ́n máa padà pẹ̀lú ojú wọn tí yóò máa damije ní ti ìbànújẹ́ pé wọn kò rí n̄ǹkan tí wọ́n máa ná (lọ sójú ogun ẹ̀sìn).

### الآية 9:93

> ﻿۞ إِنَّمَا السَّبِيلُ عَلَى الَّذِينَ يَسْتَأْذِنُونَكَ وَهُمْ أَغْنِيَاءُ ۚ رَضُوا بِأَنْ يَكُونُوا مَعَ الْخَوَالِفِ وَطَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ [9:93]

Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn t’ó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, tí) wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò sì mọ̀.

### الآية 9:94

> ﻿يَعْتَذِرُونَ إِلَيْكُمْ إِذَا رَجَعْتُمْ إِلَيْهِمْ ۚ قُلْ لَا تَعْتَذِرُوا لَنْ نُؤْمِنَ لَكُمْ قَدْ نَبَّأَنَا اللَّهُ مِنْ أَخْبَارِكُمْ ۚ وَسَيَرَى اللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ [9:94]

Wọ́n yóò mú àwáwí wá fun yín nígbà tí ẹ bá darí dé bá wọn. Sọ pé: "Ẹ má ṣe mú àwáwí wá; a ò níí gbà yín gbọ́. Allāhu kúkú ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yín fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yó sì rí iṣẹ́ (ọwọ́) yín. Lẹ́yìn náà, A óò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nígbà náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Āyah yìí jọ āyah 105 níwájú nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.

### الآية 9:95

> ﻿سَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَكُمْ إِذَا انْقَلَبْتُمْ إِلَيْهِمْ لِتُعْرِضُوا عَنْهُمْ ۖ فَأَعْرِضُوا عَنْهُمْ ۖ إِنَّهُمْ رِجْسٌ ۖ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ [9:95]

Wọ́n yóò máa fi Allāhu búra fun yín nígbà tí ẹ bá darí dé bá wọn, nítorí kí ẹ lè pa wọ́n tì. Nítorí náà, ẹ pa wọ́n tì; dájúdájú ẹ̀gbin ni wọ́n. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé wọn. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 9:96

> ﻿يَحْلِفُونَ لَكُمْ لِتَرْضَوْا عَنْهُمْ ۖ فَإِنْ تَرْضَوْا عَنْهُمْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يَرْضَىٰ عَنِ الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ [9:96]

Wọ́n yóò máa búra fun yín nítorí kí ẹ lè yọ́nú sí wọn. Tí ẹ bá yọ́nú sí wọn, dájúdájú Allāhu kò níí yọ́nú sí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

### الآية 9:97

> ﻿الْأَعْرَابُ أَشَدُّ كُفْرًا وَنِفَاقًا وَأَجْدَرُ أَلَّا يَعْلَمُوا حُدُودَ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [9:97]

Àwọn Lárúbáwá oko le nínú àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu. Ó sì súnmọ́ pé wọ́n kò mọ àwọn ẹnu-àlà ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 9:98

> ﻿وَمِنَ الْأَعْرَابِ مَنْ يَتَّخِذُ مَا يُنْفِقُ مَغْرَمًا وَيَتَرَبَّصُ بِكُمُ الدَّوَائِرَ ۚ عَلَيْهِمْ دَائِرَةُ السَّوْءِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ [9:98]

Àti pé ó wà nínú àwọn Lárúbáwá oko ẹni tí ó ka ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) sí owó ọ̀ràn. Ó sì ń retí àpadàsí aburú fun yín. Àwọn sì ni àpadàsí aburú yóò dé bá. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

### الآية 9:99

> ﻿وَمِنَ الْأَعْرَابِ مَنْ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنْفِقُ قُرُبَاتٍ عِنْدَ اللَّهِ وَصَلَوَاتِ الرَّسُولِ ۚ أَلَا إِنَّهَا قُرْبَةٌ لَهُمْ ۚ سَيُدْخِلُهُمُ اللَّهُ فِي رَحْمَتِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ [9:99]

Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) di àwọn ìsúnmọ́ Allāhu àti (gbígba) àdùá (lọ́dọ̀) Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú òhun ni ìsúnmọ́ Allāhu fún wọn. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 9:100

> ﻿وَالسَّابِقُونَ الْأَوَّلُونَ مِنَ الْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنْصَارِ وَالَّذِينَ اتَّبَعُوهُمْ بِإِحْسَانٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ وَأَعَدَّ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي تَحْتَهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ [9:100]

Àwọn aṣíwájú, àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r pẹlú àwọn t’ó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ó tún pa lésè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ títí láéláé. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

### الآية 9:101

> ﻿وَمِمَّنْ حَوْلَكُمْ مِنَ الْأَعْرَابِ مُنَافِقُونَ ۖ وَمِنْ أَهْلِ الْمَدِينَةِ ۖ مَرَدُوا عَلَى النِّفَاقِ لَا تَعْلَمُهُمْ ۖ نَحْنُ نَعْلَمُهُمْ ۚ سَنُعَذِّبُهُمْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٍ [9:101]

Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. O ò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì. Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyà ẹ̀ẹ̀ mejì dúró fún ìyà tayé àti ìya tinú sàréè.

### الآية 9:102

> ﻿وَآخَرُونَ اعْتَرَفُوا بِذُنُوبِهِمْ خَلَطُوا عَمَلًا صَالِحًا وَآخَرَ سَيِّئًا عَسَى اللَّهُ أَنْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ [9:102]

Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n da iṣẹ́ rere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ mìíràn t’ó burú. Bóyá Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 9:103

> ﻿خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِمْ بِهَا وَصَلِّ عَلَيْهِمْ ۖ إِنَّ صَلَاتَكَ سَكَنٌ لَهُمْ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ [9:103]

Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Àwọn ikọ̀ méjì ni āyah yìí ń sọ nípa wọn. Ikọ̀ kìíní ni àwọn t’ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ìbámu sí āyah 102 t’ó ṣíwájú. Ikọ̀ kejì ni àwọn t’ó ń yọ zakāh. Zakāh yíyọ sì jẹ́ àfọ̀mọ́ dúkìá fún ẹni tí ó yọ ọ́. Àmọ́ lílo āyah náà fún gbígba owó àdúà yálà níbi ìsìnkú tàbí ní àyè mìíràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ń lo āyah náà, kò jẹ mọ́ bẹ́ẹ̀ rárá nínú àwọn tírà Tafsīr.

### الآية 9:104

> ﻿أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ هُوَ يَقْبَلُ التَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِ وَيَأْخُذُ الصَّدَقَاتِ وَأَنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ [9:104]

Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run?

### الآية 9:105

> ﻿وَقُلِ اعْمَلُوا فَسَيَرَى اللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُ وَالْمُؤْمِنُونَ ۖ وَسَتُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ [9:105]

Sọ pé: "Ẹ ṣiṣẹ́. Allāhu á rí iṣẹ́ yín, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (máa rí i). Wọ́n sì máa da yín padà sọ́dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Āyah yìí jọ āyah 94 nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.

### الآية 9:106

> ﻿وَآخَرُونَ مُرْجَوْنَ لِأَمْرِ اللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمْ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [9:106]

Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná fún àṣẹ Allāhu; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. 
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Ìyẹn, àwọn t’ó ṣàì lọ sógun, àmọ́ tí wọn kò mú àwáwí irọ́ wá.

### الآية 9:107

> ﻿وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مَسْجِدًا ضِرَارًا وَكُفْرًا وَتَفْرِيقًا بَيْنَ الْمُؤْمِنِينَ وَإِرْصَادًا لِمَنْ حَارَبَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ مِنْ قَبْلُ ۚ وَلَيَحْلِفُنَّ إِنْ أَرَدْنَا إِلَّا الْحُسْنَىٰ ۖ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ [9:107]

Àwọn t’ó kọ́ mọ́sálásí láti fi dá ìnira àti àìgbàgbọ́ sílẹ̀ àti láti fi ṣe òpínyà láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti láti fi ṣe ibùba fún àwọn t’ó gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní ìṣaájú – dájúdájú wọ́n ń búra pé “A ò gbèrò kiní kan bí kò ṣe ohun rere.” – Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.

### الآية 9:108

> ﻿لَا تَقُمْ فِيهِ أَبَدًا ۚ لَمَسْجِدٌ أُسِّسَ عَلَى التَّقْوَىٰ مِنْ أَوَّلِ يَوْمٍ أَحَقُّ أَنْ تَقُومَ فِيهِ ۚ فِيهِ رِجَالٌ يُحِبُّونَ أَنْ يَتَطَهَّرُوا ۚ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُطَّهِّرِينَ [9:108]

Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé. Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ l’o lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn t’ó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra.
\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_\_
Kíyè sí i! Gbólóhùn yìí “Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.” àti āyah 107 l’ó ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwa mùsùlùmí onisunnah láti kírun nínú àwọn mọ́sálásí àwọn mùsùlùmí onibidiah pẹ̀lú májẹ̀mu pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fi mọ́sálásí náà sọrí bidiah wọn. Irú àwọn mọ́sálásí tí èyí kàn ni mọ́sálásí Ahmadiyyah àti Zāwiyah àwọn oníwírìdí Tijāniyah, Ƙọ̄diriyyah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tí ó bá wá jẹ́ pé wọn kò fi mọ́sálásí sọrí bidiah, àmọ́ tí wọ́n fi imām ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah tàbí ẹlẹ́sìn Tijāniyyah tàbí Ƙọ̄diriyyah ṣe imām nínú mọ́sálásí náà, mùsùlùmí lè kírun nínú mọ́sálásí náà kò kàn níí kírun lẹ́yìn imām onibidiah yẹn ni.

### الآية 9:109

> ﻿أَفَمَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ تَقْوَىٰ مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٍ خَيْرٌ أَمْ مَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٍ فَانْهَارَ بِهِ فِي نَارِ جَهَنَّمَ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ [9:109]

Ǹjẹ́ ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu àti ìyọ́nú (Rẹ̀) l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kan létí ọ̀gbun t’ó máa yẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì máa yẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀ sínú iná Jahanamọ? Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

### الآية 9:110

> ﻿لَا يَزَالُ بُنْيَانُهُمُ الَّذِي بَنَوْا رِيبَةً فِي قُلُوبِهِمْ إِلَّا أَنْ تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ [9:110]

Ilé wọn tí wọ́n mọ kalẹ̀ kò níí yé kó iyèméjì sínú ọkàn wọn títí ọkàn wọn yóò fi já kélekèle. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

### الآية 9:111

> ﻿۞ إِنَّ اللَّهَ اشْتَرَىٰ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ أَنْفُسَهُمْ وَأَمْوَالَهُمْ بِأَنَّ لَهُمُ الْجَنَّةَ ۚ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَيَقْتُلُونَ وَيُقْتَلُونَ ۖ وَعْدًا عَلَيْهِ حَقًّا فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ وَالْقُرْآنِ ۚ وَمَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِ مِنَ اللَّهِ ۚ فَاسْتَبْشِرُوا بِبَيْعِكُمُ الَّذِي بَايَعْتُمْ بِهِ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ [9:111]

Dájúdájú Allāhu ra ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti dúkìá wọn nítorí pé dájúdájú tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n ń jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; wọ́n ń pa ọ̀tá ẹ̀sìn, wọ́n sì ń pa àwọn náà. (Ó jẹ́) àdéhùn lọ́dọ̀ Allāhu. (Ó jẹ́) òdodo nínú at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān. Ta sì ni ó lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ ju Allāhu? Nítorí náà, ẹ dunnú sí òkòwò yín tí ẹ (fi ẹ̀mí àti dúkìá yin) ṣe. Ìyẹn, òhun sì ni èrèǹjẹ ńlá.

### الآية 9:112

> ﻿التَّائِبُونَ الْعَابِدُونَ الْحَامِدُونَ السَّائِحُونَ الرَّاكِعُونَ السَّاجِدُونَ الْآمِرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَالنَّاهُونَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَالْحَافِظُونَ لِحُدُودِ اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ [9:112]

Àwọn olùronúpìwàdà, àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu), àwọn olùdúpẹ́ (fún Allāhu), àwọn aláààwẹ̀, àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun), àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu), àwọn olùpàṣẹ-ohun rere, àwọn olùkọ-ohun burúkú àti àwọn olùṣọ́-ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo (wọ̀nyí) ní ìró ìdùnnú (Ọgbà Ìdẹ̀ra).

### الآية 9:113

> ﻿مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَنْ يَسْتَغْفِرُوا لِلْمُشْرِكِينَ وَلَوْ كَانُوا أُولِي قُرْبَىٰ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُمْ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ [9:113]

Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n.

### الآية 9:114

> ﻿وَمَا كَانَ اسْتِغْفَارُ إِبْرَاهِيمَ لِأَبِيهِ إِلَّا عَنْ مَوْعِدَةٍ وَعَدَهَا إِيَّاهُ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُ أَنَّهُ عَدُوٌّ لِلَّهِ تَبَرَّأَ مِنْهُ ۚ إِنَّ إِبْرَاهِيمَ لَأَوَّاهٌ حَلِيمٌ [9:114]

Àti pé àforíjìn tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm tọrọ fún bàbá rẹ̀ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe nítorí àdéhùn t’ó ṣe fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó hàn sí i pé dájúdájú ọ̀tá Allāhu ni (bàbá rẹ̀), ó yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni olùrawọ́rasẹ̀, olùfaradà.

### الآية 9:115

> ﻿وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُضِلَّ قَوْمًا بَعْدَ إِذْ هَدَاهُمْ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُمْ مَا يَتَّقُونَ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ [9:115]

Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

### الآية 9:116

> ﻿إِنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۚ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ [9:116]

Dájúdájú Allāhu l’ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu.

### الآية 9:117

> ﻿لَقَدْ تَابَ اللَّهُ عَلَى النَّبِيِّ وَالْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنْصَارِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ فِي سَاعَةِ الْعُسْرَةِ مِنْ بَعْدِ مَا كَادَ يَزِيغُ قُلُوبُ فَرِيقٍ مِنْهُمْ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّهُ بِهِمْ رَءُوفٌ رَحِيمٌ [9:117]

Dájúdájú Allāhu ti gba ìronúpìwàdà Ànábì, àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r, àwọn t’ó tẹ̀lé e ní àkókò ìṣòro lẹ́yìn tí ọkàn ìgun kan nínú wọn fẹ́ẹ̀ yí padà, (àmọ́) lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Òun ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún wọn.

### الآية 9:118

> ﻿وَعَلَى الثَّلَاثَةِ الَّذِينَ خُلِّفُوا حَتَّىٰ إِذَا ضَاقَتْ عَلَيْهِمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ وَضَاقَتْ عَلَيْهِمْ أَنْفُسُهُمْ وَظَنُّوا أَنْ لَا مَلْجَأَ مِنَ اللَّهِ إِلَّا إِلَيْهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ لِيَتُوبُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ [9:118]

(Ó tún gba ìronúpìwàdà) àwọn mẹ́ta tí A (so ọ̀rọ̀ wọn rọ̀ nínú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Tabūk. Àwọn mùsùlùmí sì dẹ́yẹ sí wọn) títí ilẹ̀ fi há mọ́ wọn tòhun ti bí ó ṣe fẹjú tó. Ọ̀rọ̀ ara wọn sì ṣú ara wọn. Wọ́n sì mọ̀ (ní àmọ̀dájú) pé kò sí ibùsásí kan tí àwọn fi lè sá mọ́ Allāhu lọ́wọ́ àfi kí wọ́n sá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn nítorí kí wọ́n lè máa ronú pìwàdà. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

### الآية 9:119

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَكُونُوا مَعَ الصَّادِقِينَ [9:119]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wà pẹ̀lú àwọn olódodo.

### الآية 9:120

> ﻿مَا كَانَ لِأَهْلِ الْمَدِينَةِ وَمَنْ حَوْلَهُمْ مِنَ الْأَعْرَابِ أَنْ يَتَخَلَّفُوا عَنْ رَسُولِ اللَّهِ وَلَا يَرْغَبُوا بِأَنْفُسِهِمْ عَنْ نَفْسِهِ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ لَا يُصِيبُهُمْ ظَمَأٌ وَلَا نَصَبٌ وَلَا مَخْمَصَةٌ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا يَطَئُونَ مَوْطِئًا يَغِيظُ الْكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنْ عَدُوٍّ نَيْلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمْ بِهِ عَمَلٌ صَالِحٌ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ [9:120]

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira tàbí ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn lójú ogun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tàbí wọn kò níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, tàbí ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá àfi kí Á fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.

### الآية 9:121

> ﻿وَلَا يُنْفِقُونَ نَفَقَةً صَغِيرَةً وَلَا كَبِيرَةً وَلَا يَقْطَعُونَ وَادِيًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمْ لِيَجْزِيَهُمُ اللَّهُ أَحْسَنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [9:121]

Wọn kò sì níí ná owó kékeré tàbí púpọ̀ (fún ogun ẹ̀sìn), tàbí kí wọ́n la àfonífojì kan kọ já àfi kí Á kọ ọ́ sílẹ̀ fún wọn nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san t’ó dára jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

### الآية 9:122

> ﻿۞ وَمَا كَانَ الْمُؤْمِنُونَ لِيَنْفِرُوا كَافَّةً ۚ فَلَوْلَا نَفَرَ مِنْ كُلِّ فِرْقَةٍ مِنْهُمْ طَائِفَةٌ لِيَتَفَقَّهُوا فِي الدِّينِ وَلِيُنْذِرُوا قَوْمَهُمْ إِذَا رَجَعُوا إِلَيْهِمْ لَعَلَّهُمْ يَحْذَرُونَ [9:122]

Gbogbo àwọn mùsùlùmí kò sì gbọdọ̀ dà lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn. Ìbá ṣuwọ̀n kí igun kan nínú wọn nínú ikọ̀ kọ̀ọ̀kan jáde láti wá àgbọ́yé nípa ẹ̀sìn, kí wọ́n sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn wọn nígbà tí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ wọn bóyá wọn yó lè ṣọ́ra ṣe.

### الآية 9:123

> ﻿يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قَاتِلُوا الَّذِينَ يَلُونَكُمْ مِنَ الْكُفَّارِ وَلْيَجِدُوا فِيكُمْ غِلْظَةً ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ [9:123]

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbógun ti àwọn t’ó súnmọ́ yín nínú àwọn aláìgbàgbọ́; kí wọ́n rí ìlekoko lára yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

### الآية 9:124

> ﻿وَإِذَا مَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ فَمِنْهُمْ مَنْ يَقُولُ أَيُّكُمْ زَادَتْهُ هَٰذِهِ إِيمَانًا ۚ فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا فَزَادَتْهُمْ إِيمَانًا وَهُمْ يَسْتَبْشِرُونَ [9:124]

Nígbà tí A bá sì sọ sūrah kan kalẹ̀, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tí ó máa wí pé: “Ta ni nínú yín ni èyí lé ìgbàgbọ́ (rẹ̀) kún?” Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, (āyah náà) yó sì lé ìgbàgbọ́ (wọn) kún. Wọn yó sì máa dunnú.

### الآية 9:125

> ﻿وَأَمَّا الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ فَزَادَتْهُمْ رِجْسًا إِلَىٰ رِجْسِهِمْ وَمَاتُوا وَهُمْ كَافِرُونَ [9:125]

Ní ti àwọn tí àìsàn sì wà nínú ọkàn wọn, (āyah náà) yó sì ṣe àlékún ẹ̀gbin sí ẹ̀gbin wọn. Wọn yó sì kú sí ipò aláìgbàgbọ́.

### الآية 9:126

> ﻿أَوَلَا يَرَوْنَ أَنَّهُمْ يُفْتَنُونَ فِي كُلِّ عَامٍ مَرَّةً أَوْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ لَا يَتُوبُونَ وَلَا هُمْ يَذَّكَّرُونَ [9:126]

Ṣé wọn kò rí i pé À ń dán wọn wò ní ẹ̀ẹ̀ kan tàbí ẹ̀ẹ̀ méjì ní ọdọọdún. Lẹ́yìn náà, wọn kò ronú pìwàdà, wọn kò sì lo ìrántí.

### الآية 9:127

> ﻿وَإِذَا مَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ نَظَرَ بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ هَلْ يَرَاكُمْ مِنْ أَحَدٍ ثُمَّ انْصَرَفُوا ۚ صَرَفَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَفْقَهُونَ [9:127]

Àti pé nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀, apá kan wọn yóò wo apá kan lójú (wọn yó sì wí pé): “Ṣé ẹnì kan ń wò yín bí?” Lẹ́yìn náà, wọ́n máa pẹ̀yìndà. Allāhu sì pa ọkàn wọn dà (sódì) nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ kan tí kò gbọ́ àgbọ́yé.

### الآية 9:128

> ﻿لَقَدْ جَاءَكُمْ رَسُولٌ مِنْ أَنْفُسِكُمْ عَزِيزٌ عَلَيْهِ مَا عَنِتُّمْ حَرِيصٌ عَلَيْكُمْ بِالْمُؤْمِنِينَ رَءُوفٌ رَحِيمٌ [9:128]

Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó ìnira ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore ọ̀run) fun yín; aláàánúàti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo.

### الآية 9:129

> ﻿فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُلْ حَسْبِيَ اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ ۖ وَهُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ [9:129]

Nítorí náà, tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni Olúwa Ìtẹ́ ńlá.

## روابط ذات صلة

- [النص القرآني للسورة](https://quranpedia.net/surah/1/9.md)
- [كل تفاسير سورة التوبة
](https://quranpedia.net/surah-tafsir/9.md)
- [ترجمات سورة التوبة
](https://quranpedia.net/translations/9.md)
- [صفحة الكتاب: الترجمة اليورباوية](https://quranpedia.net/book/2001.md)
- [المؤلف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني](https://quranpedia.net/person/1775.md)

---

زُر [Quranpedia.net](https://quranpedia.net/surah/1/9/book/2001) — موسوعة القرآن الكريم: التفاسير، الترجمات، التلاوات، والمواضيع.
