Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.1 Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.2 Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ l’ó ní àkọsílẹ̀.
____________________
1 Kíyè sí i, àwọn kan ń sọ pé gbólóhùn yìí “Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.” ń tọ́ka sí pé “Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ ìyàwó, ó sì ti bímọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Nítorí náà, ó ti kú. Kò sì níí padà wá sáyé mọ́.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ fífi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀. Àti pé, ìrònú wọn nípa gbólóhùn náà jẹ́ ìrònú ọpọlọ lásán, kò sì sí ìtọ́sọ́nà nínú rẹ̀ nítorí àwọn ìdí pàtàkì márùn-ún wọ̀nyí: Ìdí àkọ́kọ́; Kò kọ́kọ́ sí tírà tafsīr àwọn onisunnah t’ó sọ pé gbólóhùn náà dúró fún pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ ìyàwó tàbí pé ó ti bímọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah l’ó ń fá ìtúmọ̀ gbólóhùn náà síbẹ̀. Ìdí kejì: Gbólóhùn náà dúró sórí àdámọ́ tí Allāhu fi sára gbogbo ọmọ Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kì í ṣe àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nìkan ni wọn yóò máa fẹ́ ìyàwó tàbí bímọ. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ṣe gbogbo ẹ̀dá t’ó wá sáyé l’ó rí ìyàwó fẹ́? Tàbí ṣe gbogbo ẹni t’ó sì rí ìyàwó fẹ́ l’ó rí ọmọ bí? Ìdí kẹta; Kì í ṣe nítorí ìfirinlẹ̀ pé kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun tí kò fẹ́ ìyàwó rí tàbí tí kò bímọ rí ni Allāhu fi mú ọ̀rọ̀ náà wá nítorí pé, ó wà nínú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ tí kò fẹ́ ìyàwó, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa bímọ. Àpẹẹrẹ ni Ànábì Yahya ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú sūrah āli-’Imrọ̄n 3:39. Ìdí kẹrin; Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbólóhùn náà fọ èsì fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni. Àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó ń sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní òdodo ni kò yẹ kó jẹ́ òjíṣẹ́ abara tí ó máa fẹ́ ìyàwó, kò sì yẹ fún un láti máa bímọ.”, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe mú ọ̀rọ̀ wọn wá nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:94. Ìdí karùn-ún: Ìbá jẹ́ pé āyah náà jẹmọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ni, ìbá tí sí hadīth kan kan t’ó máa fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Hadīth lórí ìpadàbọ̀ rẹ̀ kò sì mọ ní ẹyọ kan. Nítorí náà, ṣé àwọn t’ó ń lo gbólóhùn náà fún àìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé mọ ìtúmọ̀ al-Ƙur’ān ju Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ ni tàbí wọ́n kàn jẹ́ asòòkùn-sẹ́sìn ni?! 2 “àmì kan” nínú āyah yìí dúró fún ìyà kan tàbí ìparun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Òjíṣẹ́ náà. Kíyè sí i, “àmì kan” láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún lè jẹ́ “iṣẹ́ ìyanu” tàbí “ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”.