Àti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) t’ó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà.


الصفحة التالية
Icon