Onísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì.
____________________
Ọgọ́rùn-ún kòbókò àti ẹ̀wọ̀n ọdún kan tàbí lílé kúrò nínú ìlú fún ọdún kan ni ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ‘akdu-nnikāh pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Àmọ́ lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà fún onísìná tí ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí. Ẹ̀dá ìbá mọ ìjìyà wọ̀nyí lọ́ràn, ìbá jìnnà sí àgbèrè ṣíṣe. Ìwọ arákùnrin àti arábìnrin mi, bí ọ̀ràn sìná bá fúyẹ́ ni, ìbá tí la ìjìyà lọ bí kò ṣe títọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ronú pìwàdà lónìí, má sì ṣe tìràn mọ́ àìsí Ṣẹria lórílẹ̀ èdè wa. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan sọ pé āyah wo l’ó ní kí á lẹ onísìná t’ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí lókò pa? Kì í ṣe āyah nìkan ni mùsùlùmí ń tẹ̀lé nínú Ṣẹria àti ohun gbogbo t’ó rọ̀mọ́ ẹ̀sìn rẹ̀. Hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) l’ó ṣe é lófin fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbé dìde lórí àwọn kan tí wọ́n jẹ́wọ́ ọ̀ràn sìná lásìkò rẹ̀. Bí ó sì ṣe wà nìyẹn nínú òfin Ànábì Mūsā àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìdájọ́ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) náà mú wá nìyẹn. Kò sì sí āyah kan t’ó lòdì sí èyí. Mùsùlùmí t’ó bá sì yapa Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí èyí ti sọnù jìnnà.
Síwájú sí i, tí ọkùnrin kan bá ṣe zinā pẹ̀lú obìnrin abilékọ kan, tí ó bá di oyún, tí ọkọ rẹ̀ kò sì mọ̀, tí ìyàwó rẹ̀ kò sì jẹ́wọ́, ọkọ l’ó ni ọmọ tí ó bá fi oyún náà bí àfi tí ọkọ fúnra rẹ̀ bá padà sọ pé òun kọ́ l’òun ni oyún náà. Bákan náà, tí ẹni tí kò sí nílé ọkọ bá ṣe zinā, tí ó bá doyún, ọmọ náà kò níí jẹ́ ọmọ fún arákùnrin t’ó ṣe zinā pẹ̀lú arábìnrin náà, kò sì níí jẹ́ orúkọ rẹ̀ àyàfi tí ó bá fi rinlẹ̀ pé òun l’òun ni oyún, tí ó sì bèèrè fún ọmọ. Ọmọ rẹ̀ ni ọmọ náà, àmọ́ ó bí i nípasẹ̀ zinā. Ìkíní kejì bàbá àti ìyá ọmọ náà sì lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjìyà zinā láti rí àforíjìn Ọlọ́hun.
Síwájú sí i, lásìkò oyún zinā, wọn kò níí fún wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí oorun ìfẹ́ mìíràn mọ́ torí pé kò sí ìtakókó yìgì láààrin wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí nínú àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn t’ó ní wọ́n lè ṣe ìtakókó yìgì obìnrin náà fún arákùnrin t’ó ṣe zinā pẹ̀lú rẹ̀ lórí oyún zinā náà nítorí kí wọ́n lè máa jẹ ìgbádùn ara wọn lọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́, èyí tí ó dára jùlọ ni pé, kí wọ́n má ṣe ta kókó yìgì lórí oyún zinā nítorí kí àtọ̀ àìtọ́ má baà ròpọ̀ mọ́ àtọ̀ ẹ̀tọ́. Àtọ̀ zinā ni àìtọ́. Àtọ̀ yìgì ni ẹ̀tọ́. Bákan náà, waliyyu ọmọbìnrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ láti ta kókó yìgì fún arákùnrin náà lẹ́yìn ìbímọ tí kò bá yọ́nú sí ẹ̀sìn àti ìwà arákùnrin náà. Àmọ́ lábẹ́ àìmọ̀kan, tọkọ tìyàwó t’ó bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn lórí zinā, waliyyu obìnrin lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìtakókó yìgì fún arákùnrin náà, wọn ìbáà ti bi ọmọ púpọ̀ fúnra wọn ṣíwájú. Èyí sì ni àtúnṣe ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì.