nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe! Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?
____________________
Àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ Tafsīr túmọ̀ “mọ̄” t’ó jẹyọ nínú
“وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ” yìí sí “mọ̄-maosūlah’. Ìtúmọ̀ yìí l’a lò nínú āyah yìí. Ìtúmọ̀ náà sì dúró lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn mìíràn sì túmọ̀ “mọ̄” yìí sí “mọ̄-nnāfiyah. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbólóhùn náà máa túmọ̀ sí pé, “nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀, kì í sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?” Ìtúmọ̀ kejì dúró lé iṣẹ́ Allāhu lórí ìṣẹ̀dá n̄ǹkan oko. Ìyẹn ni pé, àdáyébá ni gbogbo èso. Kò sí èso kan tí ìṣẹ̀dá rẹ wá láti ọwọ́ àgbẹ̀.