Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáẹ̀nsì tako āyah yìí nítorí pé, àìmọ̀ye n̄ǹkan l’ó wà tí kò ṣe é pín sí ìsọ̀rí akọ àti abo.”
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, mùsùlùmí kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀tàn pẹ̀lú àbá tàbí irọ́. Àbá àti irọ́ ni èyíkéyìí ọ̀rọ̀ tàbí ìròrí t’ó bá yapa sí al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ìpasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sáẹ̀nsì kan, tàbí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ kan tàbí ìmọ̀ ìròrí kan tàbí èyíkéyìí ìmọ̀ kan lòdì sí āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé.
Ó ṣuwọ̀n kí àwọn kristiẹni dákẹ́ ẹnu wọn nípa ìtúmọ̀ āyah al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí pé, ńṣe ni wọ́n ń dá ọ̀ràn kún ọ̀ràn. Wọ́n sì ń fira wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aláìmọ̀kan t’ó gbópọn. Nínú al-Ƙur’ān kalmọh “zaoj” jẹyọ ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àpapọ̀ rẹ̀ lé ní ọgbọ̀n. “’Azwāj” ni ọ̀pọ̀, “zaoj” ni ẹyọ. “Zaoj” sì ń túmọ̀ sí akọ tàbí abo nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn tàbí ọmọ bíbí, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Najm; 53:45 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:39.
Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí ọkọ tàbí aya nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó. Ìtúmọ̀ ti “aya” l’ó sì pọ̀ jùlọ fún zaoj nínú al-Ƙur’ān.
Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí ìkíní-kejì tàbí ẹnì kejì nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ènìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:102.
Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí èjì ọ̀kán-yà (n̄ǹkan kan náà méjì, àmọ́ tí ìkíní kejì yàtọ̀ síra wọn ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí akọ àti abo, n̄ǹkan dídùn àti n̄ǹkan kíkorò, n̄ǹkan tútù àti n̄ǹkan gbígbóná, n̄ǹkan mímu àti n̄ǹkan jíjẹ) tàbí èjì onídàkejì (n̄ǹkan méjì tí ìkíní kejì dúró fún ọ̀rọ̀ àti ìdà kejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sánmọ̀ àti ilẹ̀, ènìyàn àti àlùjọ̀nnú, ọ̀sán àti òru, ìmọ́lẹ̀ àti òòkùn, ìṣìnà àti ìmọ̀nà, òòrùn àti òṣùpá. Ìtúmọ̀ wọ̀nyí ni zaoj mú wá nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ àti sūrah ath-Thāriyāt; 51:49 àti nínú ar-Rahmọ̄n; 55:45.
Síwájú sí i, “zaoj” tún túmọ̀ sí oníran-ànran tàbí oríṣiríṣi. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí èso mímu tàbí èso jíjẹ kan tí ó máa jẹ́ oríṣiríṣi. Ìtúmọ̀ olóríṣiríṣi tún lọ lábẹ́ āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Nítorí náà, zaoj kò pọn dandan kí ó ní ìtúmọ̀ akọ àti abo nìkan. Oríṣiríṣi ni “zaoj”; akọ jẹ oríṣi kan, abo jẹ́ oríṣi kan, àwọ̀ jẹ oríṣi kan, èdè jẹ́ oríṣi kan, adùn jẹ́ oríṣi kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. “Zaoj” ni n̄ǹkan oríṣi méjì, “ ’azwāj” ni n̄ǹkan oríṣiríṣi.


الصفحة التالية
Icon