Sọ pé: "Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé."
____________________
Àwọn Kristiẹni lérò pé gbólóhùn tí Allāhu pa Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láṣẹ láti sọ yìí “Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin.” túmọ̀ sí pé “Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa já sí lọ́run!” Ìtúmọ̀ t’ó lòdì sí òdidi al-Ƙur’ān ni ìtúmọ̀ tí àwọn kristiẹni ń lò fún āyah náà.
Ní àkọ́kọ́ ná, àwọn āyah méjì t’ó ṣíwájú āyah yìí ń sọ nípa ìhà àìgbàgbọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ kọ sí al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Lórí inúfu-àyàfu ni ọ̀wọ́ àwọn t’ó gba al-Ƙur’ān gbọ́ wà lásíkò náà nítorí pé, wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí yọwọ́ kọ́wọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lásìkò náà, ipò ọ̀lẹ ni àwọn mùsùlùmí wà nínú ìlú náà. Kò sí ohun t’ó wá lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ sínú ’Islām tayọ kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, ní ti òdodo, Allāhu l’Ó fi iṣẹ́ mímọ́ rán òun. Òun kò sì tayọ iṣẹ́ jíjẹ́ náà. Àmọ́ irú ọwọ́ ìyà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa gbé ko òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn òun lójú lásìkò náà, òun kò mọ̀ nítorí pé oríṣiríṣi ọwọ́ ni irúfẹ́ wọn ti yọ sí àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Bí àpẹẹrẹ, ṣebí àwọn ọ̀tá ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó pète pèrò láti kàn án pa mọ́ orí igi àgbélébùú. Àmọ́ tí Allāhu kò gbà fún wọn. Bákan náà, àwọn ọ̀ṣẹbọ l’ó ju Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sínú iná. Àmọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kó ọ yọ. Àwọn ọ̀tá òdodo kúkú pa Ànábì Zakariyā àti Ànábì Yahyā (aleehimọ̄-salām), bàbá àti ọmọ! A rí nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kù lókò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí ni ìtúmọ̀ t’ó wà fún “Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” Ìyẹn ni pé, Allāhu kò fi ìmọ̀ mọ̀ mí nípa irú iyá tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa gbé dìde sí èmi àti ẹ̀yin.
Àwọn ọ̀ṣẹbọ sì kúkú nawọ́ oníran-ànran ìyà sí wọn títí àwọn mùsùlùmí fi gbé ẹ̀sìn wọn kúrò nínú ìlú nígbà náà. Èyí tí a mọ̀ sí hijrah. Lẹ́yìn náà, ogun ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò yé fi ìnira, ìjìyà àti pípa han àwọn mùsùlùmí ni èèmọ̀ ìfojú-egbò-rìn. Mọ̀ dájú pé, kò sí Ànábì kan nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun (ahm.s.w.) tí kò mọ̀ pé, inú ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀wọ́ àwọn t’ó bá tẹ̀lé e lẹ́yìn ní ọ̀nà t’ó dára máa já sí ní ọ̀run.
Ṣíwájú sí i, Allāhu ló fi iṣẹ́ rán Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí ó bá jẹ́ pé ìtúmọ̀ tí àwọn kristiẹni fún āyah náà l’ó bá jẹ́ òdodo, “èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí Allāhu máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” ni ìbá jẹ́ àgbékalẹ̀ rẹ̀. Bákan náà, a ìbá tí rí Lárúbáwá ẹyọ kan t’ó máa gbà fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí pé, pẹ̀lú èdè wọn ni Allāhu fi sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀.
Ní àkótán, āyah náà ń fi rinlẹ̀ fún wa pé, iṣẹ́ tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ fáyé kò yàtọ̀ sí ti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (ahm.s.w). Bákan náà, āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn tí kò tẹ̀lé ohun kan tayọ ìfẹ́-inú wọn tàbí ìwé tí kò sí ojúlówó rẹ̀ mọ́ níta.


الصفحة التالية
Icon