ﯠ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
ﯤﯥ
ﰀ
(Allāhu búra pẹ̀lú) atẹ́gùn t’ó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ tààrà.
ﯧﯨ
ﰁ
(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ẹ̀ṣújò t’ó wúwo rinrin.
ﯪﯫ
ﰂ
(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn.
ﯭﯮ
ﰃ
(Ó búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika t’ó ń pín n̄ǹkan (tí Ó ti pín fún ẹ̀dá).
Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín.
Àti pé dájúdájú Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.
(Allāhu tún búra pẹ̀lú) sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́.
Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ t’ó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān).
Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).
ﭟﭠ
ﰉ
Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́;
àwọn ni wọ́n wà nínú àìmọ̀kan, àwọn onígbàgbé,
tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.
Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.
Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.
Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.
Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.
Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.
Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni?
Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín wà nínú sánmọ̀.
Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Òun náà sọ pé: "Àlàáfíà (fun yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn."
Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù ọlọ́ràá (àyangbẹ).
Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni?"
Nígbà náà, ó ní ìpáyà wọn nínú ọkàn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe páyà." Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin onímọ̀ kan.
Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: "Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!"
Wọ́n sọ pé: "Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀."
(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?"
Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni
nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.
Wọ́n ti fàmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ."
Nítorí náà, A mú àwọn t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).
A ò sì rí nínú (ìlú náà) tayọ ilé kan t’ó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.
A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn t’ó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.
Ṣùgbọ́n (Fir‘aon) gbúnrí pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí)."
Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.
(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn,
kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kó sọ ọ́ di bí èso rírún túútú.
(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: "Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná."
Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, igbe ìparun mú wọ́n; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.
Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.
Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò.
Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò.
Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. Àwọn olùtẹ́lẹ̀-sílẹ̀ sì dára.
Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn t’ó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè ni."
Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-àlà ni wọ́n ni.
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe alábùkù.
Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.
Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.
Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.
Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).
Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.